Odi iso musulumi ti o wa lati inu Al-Quraani ati Sunnah ()

Sa’id Bn Ali Bn Wahf Al-Qahtaani

 

|

 Odi iso musulumi ti o wa lati inu Al-Quraani ati Sunnah

Dokita Saheed omo Aliy omo Wahf Al-Qohtooni

Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun.

 Oro itisiwaju

Dajudaju gbogbo eyin ti Allaah ni, a nyin In a si tun nwa iranlowo Re, a si tun nwa aforijin Re,atipe a nsadi Olohun kuro nibi awon aburu emi wa, ati awon aburu ise wa,eniti Olohun ba ti fi mona ko si eniti o le so o nu,atipe entiti Olohun ba sonu ko si eniti o le fi mona,mo si njeri wipe ko si eniti ijosin tosi yato si Allaah ni Oun nikan soso ko si orogun fun Un, mo si tun njeri wipe dajudaju Anabi wa Muhammad eru Allaah ni ojise Re si tun ni,ki ike Olohun ati ola Re maa ba a ati awon ara ile re ati awon saabe re, ati eniti o ba tele won pelu daada titi di ojo esan, ki Olohun si se ola fun won ni opolopo

ni eyin igba na:

Eleyi ni iwe kekere ti mo se e ni soki lati inu tira mi to nje: Iranti ati Adura ati Iwosan pelu Ruqiya ninu Al-Quraani ati Sunnahmo ge kuru nibe abala ti iranti; ki o le baa fuye lati mu lowo ni awon irin ajo.mo si fi mo lori ti oro nipa ti iranti, mo si fi mo nipa sise alaye awon hadiith re pelu didaruko ipile kan tabi meji ninu eyiti o wa nibi ipile tira yi,atipe eniti o ba ngbero lati mo saabe ti o gba hadiith wa tabi alekun nipa re, o pon dandan fun un ki o seri pada sibi ipile tira yiimo si tun nbe Allaah ti O gbonngbon pelu awon oruko Re ti o daa, ati awon iroyin re ti o ga ki o se e ni nkan ti yio mo kanga nitori ti E nikan, ki O si se mi ni anfaani pelu re ninu isemi aye mi, ati leyin iku mi, ki O si se eniti o ba ka a ni anfaani pelu e, tabi eniti o ba te e, tabi eniti o ba je okunfa titan kale reAtipe dajudaju Olohun Oba ti mimo nbe fun ni O ni nkan ti a so yii Oun ni O si ni agbara ni ori reki Olohun Oba o se ike ati ige fun anabi wa Muhammad ati awon ara ile re ati awon saabe re ati gbogbo eniti o ba tele won pelu daada titi di ojo esan

olukowe

O ko iwe yi ninu osu Sofar

 Ola ti nbe fun mimaa ranti Olohun

Olohun Allaah ti ola Re ga so bayi wipe:

E maa ranti Mi, Emi naa yio maa ranti yin, atipe e maa dupe fun Mi, e ma se aimoore si Mi

A pe eyin ti e gba Olohun gbo ni ododo e maa ranti Olohun ni riranti ti o po

Ati awon ti won maa ndaruko Olohun ni opolopo, Olohun pese fun won aforijin ati esan ti o tobi

Ranti Olohun Oba re ninu emi re ni iraworase ati ni jeeje ati lai gbe ohun soke, ni aaro ati ni irole, atipe ma se wa ni ara awon afonufora

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Apejuwe eniti o nranti Olohun re ati eniti kii ranti Olohun re da gege bi apejuwe alaaye ati oku niO tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:E je ki n fun yin ni iro nipa eyiti o loore ju ninu ise yin, ati eyiti o mo kanga ju ninu re lodo eniti o ni yin ati eyiti o ga ju ninu awon ipo yin, ati eyi ti o loore fun yin ju wura ti fadaka lo ati eyiti o loore fun yin ju ki e da oju ko awon ota yin ki e maa be won lori ati ki won maa be yin lori lo, won so pe beeni, o so pe: iranti Olohun Oba ti O gaO tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Olohun ti ola Re ga so pe: Emi wa nibi erongba eru Mi si Mi atipe Emi wa pelu re nigbati o ba nranti Mi ninu emi re, Emi naa yio ranti re ninu emi Mi, atipe ti o ba ranti Mi ni akojopo kan emi naa yio ranti re ni akojopo ti o loore juwon lo, atipe ti o ba sunmo Mi ni odiwon ika meta si meerin, Emi naa yio sunmo on ni odiwon igunwo. Atipe ti o ba sunmo Mi ni odiwon igunwo, Emi yio sunmo on ni odiwon nina apa mejeeji gbalaja, atipe ti o ba wa ba mi ti o rin, Emi yio lo ba a ni eniti yio maa yaraLati odo Abdullaah omo Busri – ki Olohun yonu si i -:Dajudaju okunrin kan so pe: ire ojise Olohun awon ofin Islaam ti po fun mi pupo, wa fun mi niro nkankan ti maa gbamu, o so pe: ahon re ko gbodo ye ni nkan ti yio maa tutu lati ara iranti OlohunO tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Eniti o ba ka arafi kan ninu tira Allaah, laada kan nbe fun un pelu re, atipe laada kan pelu ilopo mewa re ni, emi ko so pe Alif, Lam, Mim je arafi kan sugbon Alif arafi kan, Laam arafi kan, Miim arafi kanlati odo Uqubah omo Amri – ki Olohun yonu si i – o so pe:ojise Olohun –ki ike ati ola Olohun maa ba a– jadeawa si wa ni aaye to nje "Suf'fa" ewo ninu yin lo feran lati maa lo ni ojoojumo si aaye ti a npe ni "But'aan" tabi lo si aaye ti a npe ni "Al-Aqiik" ti o wa muwa lati ibe rakunmi meji ti eyin re gba igba, ti ko ni jepe pelu ese tabi jija okun ebi? a wa so pe: iwo ojise Olohun! a feran bee, o wa so pe: se enikan ninun yin ko wa ni losi mosalaasi, ki o loo ko tati ki o ka aayah meji ninu tira Olohun Obi ti o gbongbon eleyi loore fun un ju rakunmi meji lo, atipe meta si loore fun un ju rakunmi meta lo, ti meerin naa si loore fun un ju rakunmi meerin lo, ati awon onka re ninu rakunmiO tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Eniti o ba joko ni ijoko kan ti ko si ranti Olohun nibe, yio je adinku fun un ni odo Olohun, atipe eniti o ba sun ni ibusun kan ti ko si ranti Olohun nibe yio je adinku fun un lodo OlohunO tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Awon ijo kan ko ni joko ni ibujoko kan ti won ko ranti Olohun Oba nibe, ti won ko si se asalaatu fun anabi won ayaafi ki o je adinku fun won, ti o ba wu ﷻ‬ yio fi iya je won, ti o ba si wu ﷻ‬ yio se aforijin fun wonO tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Ko si awon ijo kan ti won o dide ni ibujoko kan, ti won ko si daruko Olohun nibe, ayafi ki won o dide pelu eyi ti o dabi oku ketekete, yio si je abamo fun won

 Awon adura ti a ba ji lati oju orun

Eyin ti Olohun Oba ni, eniti O ji wa leyin igba ti O pa wa, Oun naa si ni yoo gbe wa dide ni alukiyaamo

Ko si enikankan ti ijosin to si ayaafi Allah nikan, ko si orogun fun un, ti E ni ola nse, ti E ni eyin nse, Oun ni alagbara lori gbogbo nkan, mimo fun Allaah, eyin ti Allaah ni, ko si si eniti ijosin tosi ayafi Allaah,atipe Allaah ni O tobi ju, atipe ko si ogbon ko si agbara ayafi pelu Allaah Oba ti O ga ju ti O si tobi, Olohun Oba mi, se aforijin fun mi

Gbogbo eyin ti Olohun Oba ni Eniti o fun mi ni alaafia ni ara mi, ti O si da emi mi pada fun mi, ti O si yonda fun mi lati ranti Re

Dajudaju o nbe nibi dida sanmo ati ile ati iyapa oru ati osan awon ami fun awon oni laakai

Awon ti won se pe won ma nranti Mi ni ori iduro ati ni ori ijoko ati ni ifegbelele won, won si ma nronu nipa dida awon sanmo ati ile, won wa nso pe Ire Oluwa wa, Iwo ko da eleyi lasan, mimo fun O, so wa kuro ninu iya ina

Ire Oluwa wa dajudaju eniti O ba fisi ina, O ti yepere re, ko si si oluralowo fun awon alabosi

Ire Oluwa wa dajudaju awa gbo olupepe to npepe si igbagbo pe e gba Olohun Oba yin gbo, awa si gbagbo, Ire Oluwa wa fi ori awon ese wa jin wa, bawa pa awon asise wa re, atipe pawa pelu awon eniire

Ire Oluwa wa fun wa ni ohun ti O se adehun fun wa lati odo awon ojise Re, ki o si ma yepere wa ni ojo aliqiyaamo, dajudaju Ire kii yi adehun pada

Olohun Oba won wa dawon loun pe dajudaju Emi ko ni fi ise osise Kankan ninu yin rare ninu okunrin tabi obinrin, apakan yin lara apakan ni, atipe lara awon ti won se hijira ti won si le won jade kuro ninu ile won, ti won fi ara ni won ni oju ona Mi, atipe ti won jagun ti won si pa won, dajudaju Emi yio ba won pa gbogbo asise won re, atipe dajudaju Emi yio fi won si inu ogba idera ti awon akeremodo nsan ni abe won, eyi je esan lati odo Allaah atipe Allaah ni esan ti o dara ju lo wa lodo Re

Ma jeki o tan o je isesi awon ti won nse keferi ni ilu

Igbadun kekere ni, atipe ibuserisi won inu ina jahannama ni, eleyi si buru ni ibusun

Sugbon awon ti won beru Olohun Oba won, awon alujannah ti awon akeremodo nsan ni abe re nbe fun won, won yio maa se gbere nibe, eleyi je nkan ikona alejo lati odo Allaah, atipe ohun ti nbe ni odo Allaah ni o loore ju fun awon eniire

Atipe dajudaju o nbe ninu awon ti a fun ni tira eniti o ni igbagbo pelu Allaah ati ohun ti a sokale fun yin ati ohun ti a sokale fun won ti won si beru Allaah, won o ki nra awon aayah Olohun pelu owo pooku, awon won yi esan won nbe lodo Olohun won, dajudaju Olohun Allaah yara ni isiro

Eyin onigbagba ododo e se ifarada, ki e si tun maa se ifarada ju awon ota lo, ki e si tun duro sinsin, ki e si tun beru Olohun ki e le ba jere

 Adura wiwo aso

Ope ni fun Allaah ti o fi ewu yi wo mi ti O se pese re fun mi laise pelu ogbon tabi agbara lati odo mi

 Adura lati wo aso tuntun

Ire Olohun Allaah ti E ni eyin nse, Iwo ni O da a wo mi, mo nbeere awon ore Re ni odo Re ati awon oore ti won se aso yi fun, atipe mo fi E wa iso kuro nibi aburu re ati aburu ti won se e fun

 Adura ti a ma nse fun eniti o ba wo aso tuntun

Waa lo o gbo atipe Olohun Oba yio si fi omiran paro

Wo aso tuntun ki o si maa semi ni eni iyin, ki o si ku ni "shahiidi".

 Ohun ti eeyan o so ti o ba bo aso re sile

Pelu oruko olohun.

 Adura wiwo ile egbin

Pelu oruko Olohun, Ire Olohun Allaah dajudaju emi sadi O kuro nibi awon ako alujannu ati awon abo re

 Adura jijade ninu ile egbin

Mo toro aforijin Re

 Iranti Olohun siwaju aluwaala

Pelu oruko olohun.

 Adura leyin igbati a ba pari aluwala

Mo njeri pe ko si Oba kan ti ijosin to si ayafi Allaah ni Oun nikan, ko si orogun fun Un, atipe mo jeri pe dajudaju Anabi Muhammad erusin Olohun ni ojise Re si ni

Ire Olohun semi ni ara awon ti o maa tuuba, atipe semi lara awon ti o maa se imora

Mimo fun Ire Olohun Oba ati pelu eyin Re, mo jeri pe ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo, mo nwa aforijin Re, mo si ntuuba losi odo Re

 Adura ti a ba fe jade kuro ninu ile

Pelu oruko Olohun, mo gbarale Olohun, ko si si ikapa ati agbara kankan ayafi pelu Allaah

Ire Olohun Oba dajudaju emi sa di O nibi ki nsonu tabi ki won somi nu, tabi ki nye ese gere tabi ki won yemi lese gere, tabi ki nse abosi eniyan tabi ki won se abosi simi, tabi ki nwu iwa aimokan tabi ki won wu iwa aimokan simi

 Adura nigba ti a ba fe wole

Pelu oruko Olohun ni a fi wole atipe pelu oruko Re ni a fi jade atipe Allaah Oluwa wa ni a gbara le, leyin igbayen ki o wa salamo si awon ara ile

 Adura lilo si mosalasi

Ire Olohun fi imole si inu okan mi, ki O si fi imole si ori ahon mi, ki O si fi imole si igboran mi, ki O si fi imole sibi iriran mi, ki O si fi imole si oke mi, ki O si fi imole si isale mi, ki O si fi imole si apa otun mi, ki O si fi imole si apa alaafia mi, ki O si fi imole si iwaju mi, ki O si fi imole si eyin mi, ki O si fi imole si inu emi mi, ki O si se imole mi ni titobi, ki O si se imole fun mi, ki O si semi ni imole, Ire Oluwa Allaah fun mi ni imole, ki O si fi imole si inu isan ara mi, atipe se imole si inu eran ara mi, ki O si fi imole si inu eje mi, ki o si fi imole si inu irun mi, ki o si fi imole si awo ara mi

Ire Oluwa fi imole si inu saare mi, ki O si fi imole si inu eegun mi, ki o si se alekun imole fun mi, se alekun imole fun mi, ki O si tami lore imole lori imole

 Adura wiwo mosalasi

Yio bere pelu ese otun re, yio wa so pe:

Mo wa iso pelu Olohun Oba ti O tobi, ati pelu iwaju Re alaponle, ati agbara Re ti o ti nbe tipe kuro ni odo shaytaan eni eko, mo bere pelu oruko Allaah, ki ike ati ola si maa ba ojise Olohun, Ire Oluwa si ilekun ike Re fun mi

 Adura jijade kuro ni mosalaasi

Yio bere pelu ese osi re, yio wa so pe: Pelu oruko Allaah, ki ike ati ige ko si maa ba ojise Olohun, Ire Oluwa dajudaju emi nbeere ninu ola Re, Ire Oluwa so mi kuro ni odo shaitaan eni eko

 Adura pipe irun

Yio maa so iru nkan ti eniti o nperun nso, ayafi igbati oba de ibi ti "HAYYA ALAS-SOLAAT ati HAYYA ALAL-FALAAH"

yo wa ma so ni be pe "LA HAOLA WALAA QUWWATA ILLAA BILLAAH" ko si ogban ko si si agabra ayafi pelu Allah

Yo si wa ma sope: atipe emi jeri pe ko si eniti ijosin to si ju Allah lo ni Oun nikan kosi orogun fun Un, atipe anabi Muhammad erusin Re ni ojise Re si ni pelu, mo yonu si Allah ni oluwa atipe mo yonu si Muhammad ni ojise atipe mo yonu si Islaam ni esin

Yio ma so iyen leyin igbati eniti o nperun ba so pe "LAA ILAAHA ILLAL LAAH".

Yo wa se asalatu fun anabi- ki ike ati ola olohun ko maa ba a- leyin igbati o ba pari dida aperun loun

Yo wa so bayii pe: ire Oluwa Oba ti O ni ipepe ti o pe yi,ati irun ti won gbe duro yi, fun anabi wa Muhammad ni aga wasila ati ola, atipe gbe e dide ni aye eleyin eyiti O ti se adehun re fun un, dajudaju Ire kii ye adehun

Yio se adurafun arare laarin irun pipe ati ikaamo, toripe dajudaju adura sise nigbayen won o nii da a pada

 Adura bibere irun

Ire Oluwa, se igbejina laarin mi ati awon ese mi gege bi O se se igbejina laarin ibuyo orun ati ibuwo orun, ire oluwa fomi mo kuro ninu awon ese mi gege bi won se maa nfo aso funfun mo kuro ni ibi idoti, ire oluwa fomi kuro nibi ese mi pelu yinyin ati omi ati omitutu

Mimo Re Ire Oluwa pelu eyin Re, atipe oruko Re ni ibukun, ati wipe ola Re ga, atipe ko si eniti ijosin tosi yato si Iwo.

Mo da oju mi ko eni ti O da sanmo ati ile ni oluse E ni okan soso , atipe emi o se ebo, dajudaju irun mi ati ijosin mi ati isemi mi ati kiku mi ti Olohun Oba agbalaye ni kosi orogun fun Un, atipe eyi ni won pami lase atipe emi wa ninu awon musulumi, Ire ni Oluwa ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo, Ire ni Oluwa mi, emi ni eru re, mo se abosi ara mi atipe mo jewo ese mi atipe fi ori ese mi jinmi lapapo, atipe dajudaju kosi eni ti o le fori ese jin yan ayafi Iwo, atipe fimi mona nibi awon iwa ti o daa, ko si eni ti o le fini mona ayafi Iwo, dari awon iwa buburu kuro ni odo mi ko si eni ti o le dari e kuro ni odo mi ayafi Iwo, mo je ipe Re ni ajetunje atipe mo wa iranlowo Re, atipe gbogbo ore patatpata wa ni owo Re atipe aburu won ki fi i ti si odo Re, atipe emi wa pelu Re ati odo Re, iwo je Onibukun ti O ga, mo wa aforijin Re, mo si tuuba lo si odo Re Ire Oluwa

Oluwa Jubril ati Mikail ati Israafiil, Ire ti O da sanmo ati ile ti O je olumo nipa ohun ti o wa nikoko ati eyiti o han. Ire ni yio se idajo laarin awon eru Re nibi ohun ti won se iyapa enu si, fimi mona nibi ohun ti won yapa enu si ninu otito pelu iyonda Re, dajudaju Ire ni o maa nfi eniti o ba wu O mona losi oju ona ti o to

Allah ni O tobi ju, Allah ni O tobi ju Allah ni O tobi ju, eyin pupo ti Olohun ni, eyin pupo ti Olohun ni eyin pupo ti Olohun ni, atiwipe mimo Olohun Oba ni owo aaro ati ni owo asale (ni eemeta) mowa iso pelu Allah kuro ni odo shaitaan: kuro nibi fife ategun re ati fife ategun pelu ito ati fifi owo kan Re

Ire Oluwa, ti E ni eyin, Iwo ni imole awon sanmo ati ile ati awon ti o wa ninu won, atipe ti E ni eyin, Ire ni O mu sanmo ati ile duro ati oun ti o wa ninu won atipe ti E ni eyin, Ire ni Oluwa awon sanmo ati ile ati eniti o waninu won atipe ti E ni eyin, ti E ni nini awon sanmo ati ile ati ohun ti o wa ni inu won. Atipe ti E ni eyin, ti E ni nini sanmo ati ile ati awon ti o wa ninu won atipe ti E ni eyin,Ire ni eni ti O ni sanmo ati ile atipe ti E ni eyin, Ire ni Oba ododo ati wipe adehun Re ododo ni, atipe oro Re ododo ni atipe pipade Re ododo ni atiwipe alujanna ododo ni atipe ina Re ododo ni atipe awon anabi ododo ni won, atipe anabi wa Muhammed – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ododo ni, atipe ojo al'qiyaama ododo ni, Ire ni mo gbafun, atipe Ire ni mo gbe ara le, atipe Ire ni mo gbagbo ati pe odo Re ni mo seri okan pada si, atipe pelu oruko Re ni mo fi n dojuko ota, atipe odo Re ni mo gbe idajo wa atipe odo Re ni mo nseri idajo si, fi ori jinmi gbogbo ohun ti mo se si iwaju ati ohun ti mo se si eyi ati ohun ti mo se ni ipamo ati ohun ti mo se ni gbangba ati ohun ti O mo nipa re ju mi lo, Ire ni O maa nti nkan siwaju atipe Ire ni O maa nti nkan si eyin, ko si eni ti ijosin tosi ayafi Ire, Ire ni Oluwa mi kosi eniti ijosin tosi ayafi Iwo, atipe kosi agbara ati ogbon kan ayafi pelu Allah

 Adura Rukuu

Mimo Oluwa mi ti O tobi. Ni eemeta

Mimo Re Iwo Oluwa wa ati pelu eyin Re, Oluwa fi orijin mi

Ire ni Oba Eleyin Eniti O mo kanga, Oluwa awon malaika ati Jubril

Ire Oluwa ni mo rukuu fun, Ire ni mo gbagbo atipe Ire ni mo juwo juse fun. Igboran mi teriba fun O, ati iriran mi ati opolo mi ati eegun mi ati isan mi ati ohun ti ese mi duro lelori

Mimo fun Eni ti O ni ipa ati ola ati motomoto ati titobi

 Adura gbigbori kuro ni rukuu

Oluwa gbo ohun eni ti o yinIn.

Ire Oluwa wa, atipe ti E ni eyin, eyin ti o po ti o dara ti o si ni alubarika ninu

Ohun ti o kun awon sanmo ati ohun ti o kun ile ati ohun to wa larin awon mejeeji ati kikun ohun ti O ba nfe ni eyin re, Ire ni O ni eto si eyin ati iyi, O ni eto si i ju ohun ti eru n so lo, atipe gbogbo wa eru Re ni wa. Ire Oluwa, kosi oludena fun nkan ti O ba fun ni, atipe kosi olufunni ni ohun ti O ba ko funni atipe oro kole wulo fun oloro ni odo Re.

 Adura fifi ori kanle

Mimo fun Oluwa mi ti O gaju. Ao wi i ni eemeta

Mimo fun Ire Oluwa mi, Ire Oluwa, Oluwa wa ati pe pelu eyin Re, Ire Oluwa, fi orijin mi

Ire ni Oba Eleyin Eniti O mo kanga, Oluwa awon malaika ati Jubril

Ire Oluwa, Ire ni mo fi ori kanle fun, Ire si ni mo gbagbo, Ire ni mo juwo juse sile fun, ori mi kanle fun Eniti O se eda re ti O si ya aworan re, ti O si yo igboran re ati iriran re, ibukun ni fun Allah eni ti O dara ju ni adeda

Mimo fun eniti o ni ipa ati ola ati motomoto ati totobi

Ire Oluwa fi ori gbogbo ese mi jinmi, eyi ti o kere ati eyi ti o po, ati ibere re ati opin re, eyi ti o pamo ati eyi ti o han.

Ire Oluwa mo wa iso pelu iyonu Re kuro nibi ibinu Re, pelu amoju kuro Re kuro ni bi iya Re, atipe mo fi E wa iso kuro nibi iya Re, mi o le se onka eyin fun O, gegebi O se se e fun ara Re naa ni O se ri.

 Adura ijoko laarin iforikanle meji

Ire Oluwa mi fi ori jin mi, Ire Oluwa mi fi ori jin mi

Ire Oluwa fi ori jinmi atipe ki O kemi atipe ki O fimi mona, atipe ki O tun mi se, ki O si fun mi ni alaafia, ki O si fi arisiki fun mi ki O si gbemiga.

 Adura fifori kanle kike Al-quran

Ori mi kanle fun Eni ti O da a, ti O si yo igboran re ati iriran re pelu ogbon Re ati agbara Re, ibukun ni fun Allah Eniti O dara ju ni adeda

Ire Oluwa, fi ko akosile laada fun mi ni odo Re, atipe fi gbe ese kuro fun mi atipe ba mi se e ni nkan ipamo ni odo Re atipe tewo gba a ni owo mi, gege bi O se tewo gba a ni odo eru Re anabi Daud

 Sise Ataaya

Gbogbo kiki ti Allah ni ati gbogbo eyin ati ohun gbogbo ti o dara,alaafia Olohun ki o maa ba e ire anabi ati ike Allah ati alubarika Re, alaafia ki o maa ba wa ati awon erusin Allah ti won je eni ti E. Mo jeri pe ko si eniti ijosin to si ayafi Allah, mo si jeri pe anabi Muhammed eru Re ni atipe ojise Re ni

Sise asalatu fun anabi- ki ike Olohun ati ola Re maa ba a- leyin ataaya

Ire Oluwa se asalatu fun anabi Muhammad ati awon ara ile anabi Muhammad gege bi O se se ike fun anabi Ibrahim ati awon ara ile Ibrahim dajudaju Iwo ni Oba Eleyin ti O gbonngbon, Ire Oluwa se ibukun fun anabi wa Muhammad ati awon ara ile anabi Muhammad gege bi O se se ibukun fun anabi Ibrahim ati awon ara ile anabi Ibrahim, dajudaju Ire ni Oba Eleyin, Oba ti O gbonngbon

Ire Oluwa, se ike fun anabi Muhammad ati awon iyawo re ati awon aromodomo re gege bi O se se ike fun awon araale Ibrahim, wa se ibukun fun anabi Muhammad ati awon iyawo re ati awon aromodomo re gegebi O se se ibukun fun awon araale anabi Ibrahim, dajudaju Ire ni Oba Eleyin Oba ti O gbonngbon

 Adura ti a maa nse leyin ataaya ti o gbeyin ki a to salamo

Ire Oluwa dajudaju emi wa iso pelu Re kuro nibi iya saare ati kuro nibi iya jahanama ati kuro nibi fitina isemi aiye ati fitina ti iku ati kuro nibi aburu fitina Masiihud-Dajjaal

Ire Olohun, dajudaju emi nfi O wa iso kuro nibi iya saare atipe mo nfi E wa iso kuro nibi fitina Massihud-Dajjaal, atipe emi nfi E wa iso nibi fitina aiye tabi ti iku, Ire Oluwa dajudaju emi nwa iso pelu Re nibi ohun ti o le fa ese ati ohun ti o le fa gbes.

Ire Oluwa dajudaju emi se abosi si emi ara mi ni abosi ti o po, atipe kosi eniti o le se aforijin awon ese ayafi Iwo, atipe fi orijin mi ni ti aforijin ti odo Re ki O si ke mi, dajudaju Ire ni Oba alaforijin Onikee

Ire Oluwa fi ori jin mi ohun ti mo ti se siwaju ati si eyinati ohun ti mo se ni koko ati ohun ti mo se ni gbangba ati ohun ti mo se ni aseju, ati ohun ti O mo nipa Re ju emi lo, Ire ni O maa nti nkan siwaju Ire ni O si maa nti nkan si eyin, kosi eniti ijosin to si ayafi Iwo

Ire Oluwa ran mi lowo lori iranti Re ati ida ope fun O ati sise ijosin Re daadaa

Ire Oluwa dajudaju emi nwa iso pelu Re kuro nibi ahun sise, mo si nwa iso pelu Re kuro nibi ojo sise, atipemo nfi E wa iso kuro nibi didami pada si isemi ti o ti lo ile, atipe mo fi E wa iso kuro nibi fitina idamu ile aiye ati iya saare

Ire Oluwa dajudaju emi ntoro alujanna ni odo Re mo si nfi E wa iso kuro nibi ina

Ire Oluwa pelu mimo ti O mo koko ati agbara Re lori eda, dami siti O ba mo pe isemi ni o loore fun mi ju, ati pe pami ti O ba mo wipe iku ni o loore fun mi ju, Ire Oluwa dajudaju emi ntoro iberu ni odo Re nikoko ati nigbangba, mo si ntoro ni odo Re oro ododo ni asiko iyonu ati asiko ibinu atipe mo ntoro Iwontuwonsi ni odo Re nibi oro ati osi, atipe mo ntoro ola tabi idera ti ko nii tan, atipe mo ntoro itutu oju ti ko nii ja ni odo Re, atipe mo ntoro iyonu leyin idajo ni odo Re, mo ntoro isemi tutu leyin iku ni odo Re, atipe mo ntoro adun wiwo oju Re, atipe mo ntoro imaa jeran pipade Re lai nii si inira ti o nfara niyan ati laisi idaamu ti o nsoninu, Ire Oluwa, sewa loso pelu oso igbagbo atipe sewa ni olumona eni to nfini mona

Ire Olohun mo n be O, Ire Olohun Iwo ni Okan, Iwo ni Aaso Ajironukan, ti ko bimo ti enikankan o si bi I, ti ko si ni akegbe, pe ki O fori awon ese mi jin mi; toripe Iwo ni Alaforijin Onike

Ire Olohun dajudaju emi nbeere lowo Re pelu mimo daju wipe ti E ni eyin nse ko si eniti ijosin to si ayafi Ire nikan soso, ko si orogun fun O, Oba ti maa nse idekun fun ni, Ire ti O ko seda awon sanmo ati ile, Ire Oba ti O ni gbigbonngbon ati tita oore ti o ga ju, Ire Oba Alaaye Ire Oba ti nmoju to gbogbo nkan, dajudaju emi nbeere alujanna lowo Re, mo si nfi O wa isora kuro nibi ina

Ire Olohun dajudaju emi nbeere lowo Re pelu wipe mo njeeri wipe ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo, Oba Aso, Oba Ajironukan ti o je wipe ko bimo, won o si bi I, ko si si enikankan ti o se deede Re

 Awon adua leyin ti a ba salamo nibi irun

Mo ntoro aforijin lowo Allah (a o wi i ni eemeta) Ire Oluwa, Ire ni Oba alaafia atipe odo Re ni Alafia ti nwa, Ire je Onibukun Ire Oba ti O ni gbigbonngbon ati oore aponle

Ko si eniti ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola se, atipe ti E ni eyin se, atipe O je alagbara lori gbogbo nkan (a o wi i ni eemeta) Ire Oluwa, kosi oludena fun nkan ti O ba fun ni, atipe kosi olufunni ni ohun ti O ba ko funni atipe oro kole wulo fun oloro ni odo Re.

Ko si eniti ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola se, atipe ti E ni eyin se, atipe O je alagbara lori gbogbo nkan, ko si ogbon ko si agbara ayafi pelu Allaah, ko si eniti ijosin to si ayafi Allaah nikan atipe awa ko nii sin elomii yato si I. Ti E ni ike nse, ti E ni ola nse atipe ti E ni eyin to rewa nse, ko si eniti ijosin to si ayafi Allaah ni eniti a nse afomo esin fun Un, koda ki awon keferi o korira bee

Mimo Olohun Oba Allahatipe eyin ti Allah nii se, atipe Olohun Oba Allah ni O tobi ju (a o wi i ni igba metalelogbon) Ko si eniti ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola se, atipe ti E ni eyin se, atipe O je alagbara lori gbogbo nkan

Mo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orun

So wipe Olohun okan soso ni

Allahu ni Oba Ajironukan

Ko bimo, enikankan ko si bi I

Ko si si afiwe kankan fun Un ninu gbogbo nkan toda

Mo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe mo wa isora pelu Oba ti O ni imole asunba nigba ti o ba yoNibi aburu awon nkan ti O daAti nibi aburu okunkun nigba ti o ba kun biribiriAti nibi awon aburu awon ti won maa n ta oda sinu kokoAti nibi aburu awon onikeeta nigba ti won ba n se keetaMo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe {ire ojise} mo wa isora pelu Olohun Oba to ni awon eeyanOba ti O je wipe Oun ni Oba ti O ni agbara lori gbogbo awon eeyan patapataOba ti awon eeyan maa njosin fun lododo ni oun nikanNibi aburu shaetan ti maa nko royiroyi ba eeyan ti o si maa n sa pamoEleyi ti maa nko royiroyi sinu okan omoniyanAti nibi aburu awon alujannnu ati aburu ti eeyan

leyin irun kookan

Olohun Oba Allah ti ko si eni ti ijosin to si ayafi Oun, Oba Abemi Oba ti o moju to gbogbo nkan, kii toogbe bee si ni kii sun, ti E ni gbogbo ohun to nbe ni sanmo ati ile, kosi eniti o le sipe ni odo Re ayafi pelu iyonda Re. O mo ohun ti o n be ni iwaju won ati ohun ti nbe ni eyin won, atipe won ko rokirika nkankan ninu imo Re ayafi pelu ohun ti O ba fe, aga Re fe tayo awon sanmo ati ile, atipe siso awon mejeji ko ko inira ba A, atipe Oun ni Oba ti O gaju ti O si tobiLeyin irun kookan

Ko si eniti ijosin to si ayafi Allaah ni Oun nikan ko ni orogun, ti E ni ola atipe ti E ni eyin, O maa nda emi si, O si maa n pa emi, Oun ni Alagbara lori gbogbo nkan. (a o so o ni igba mewa) leyin irun magrib ati irun subhi

Ire Oluwa dajudaju emi ntoro imo ti o sanfaani ni odo Re, ati arisiki ti o mo, ati ise to je atewogba, yoo mo so bee leyin igba ti o ba salamo leyin irun asunba

 Adua Irun ti a fi maa nye nkan wo boya o daa abi ko daa (irun istihara)

Jabri omo Abdulahi – ki Olohun yonu si awon mejeeji – so pe:Ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun maa ba a – je eniti o maa n ko wa ni "ISTIKHAARA"Nibi gbogbo alamori patapata gege bi o se maa nko wa ni surah ninu Al-quran, o wanso pe:

Ti enikan ninu yin ba gbero alamori kan, ki o kirun rakah meji laise irun oranyan, leyin naa ki o wa so bayi pe: Ire Oluwa, emi nwa sisa esa ni odo Re pelu imo Re, mo si nwa agbara ni odo Re pelu agbara Re, atipe emintoro ola Re ti o tobi, tori pe dajudaju Ire ni O ni agbara emi o ni agbara, atipe Ire ni O mo emi o mo, atipe Iwo ni O nimo nipa awon koko, Ire Oluwa ti o ba je wipe Iwo ba mo pe alamori yii (yio wa daruko bukata re), ni o ba ni oore fun mi ninu esin mi ati igbesi aiye mi ati ni igbeyin oro mi tabi akoko re tabi igbeyin re, tabi ti isin tabi ti ojo iwaju re, ki O ya kadara re fun mi atipe ki O se e ni irorun fun mi, leyin naa ki o wa fi barika si i fun mi, atipe ti O ba mo wipe alamori yi ba je aburu fun mi ninu esin mi tabi igbesi aye mi ati igbeyin alamori mi tabi o so pe – ni ti isin yin tabi ojo iwaju mi – ki O ya seri re pada kuro ni odo mi atipe ki O kadara ore fun mi nibi ti o ba wa, leyinna ki O wa fun mi ni itelorun pelu e.

Enikeni ti o ba wa esa lati odo Adeda ko nii kabamo, ti o si tun fi oro lo awon eda ti won je muumini to si duro sinsin ninu alamori reOlohun Oba ti O ga ti so wipe:Atipe ire anabi maa ba won jiroro nibi alamori, atipe ti o ba ti wa pinnu, ki o wa gbarale Allah.

 Awon Adura Aro Ati Ale

Ti Olohun Oba Allah ni eyin nse ni Oun nikan atipe ike ati ige ko maa ba enitiko si anabi mii leyin re

Mo fi Olohun Allah Oba wa iso kuro nibi shaitoon eni egbe eni eko

Olohun Oba Allah ti ko si eni ti ijosin to si ayafi Oun, Oba Abemi Oba ti o moju to gbogbo nkan, kii toogbe bee si ni kii sun, ti E ni gbogbo ohun to nbe ni sanmo ati ile, kosi eniti o le sipe ni odo Re ayafi pelu iyonda Re. O mo ohun ti o n be ni iwaju won ati ohun ti nbe ni eyin won, atipe won ko rokirika nkankan ninu imo Re ayafi pelu ohun ti O ba fe, aga Re fe tayo awon sanmo ati ile, atipe siso awon mejeji ko ko inira ba A, atipe Oun ni Oba ti O gaju ti O si tobi

Mo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe Olohun okan soso niAllahu ni Oba AjironukanKo bimo, enikankan ko si bi IKo si si afiwe kankan fun Un ninu gbogbo nkan todaMo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe mo wa isora pelu Oba ti O ni imole asunba nigba ti o ba yoNibi aburu awon nkan ti O daAti nibi aburu okunkun nigba ti o ba kun biribiriAti nibi awon aburu awon ti won maa n ta oda sinu kokoAti nibi aburu awon onikeeta nigba ti won ba n se keetaMo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe {ire ojise} mo wa isora pelu Olohun Oba to ni awon eeyanOba ti O je wipe Oun ni Oba ti O ni agbara lori gbogbo awon eeyan patapataOba ti awon eeyan maa njosin fun lododo ni oun nikanNibi aburu shaetan ti maa nko royiroyi ba eeyan ti o si maa n sa pamoEleyi ti maa nko royiroyi sinu okan omoniyanAti nibi aburu awon alujannnu ati aburu ti eeyan

A maa so eleyi nigba meta

A ji si aye gbogbo ola si je ti Olohun, ope nifun Olohun, ko si Oba ti ijosin tosi ni ododo ayafi Olohun ni Oun nikan. Ko si orogun fun Olohun ninu ola Re, ti E ni ola nse, ti E ni iyin ati ogo nse, Oun ni Alagbara Olukapa lori gbogbo nkan ,Olohun Oba mi, mo toro oore ti nbe ninu ojo oni lodo Re, ati oore ti nbe leyin ojo oni, mo fi Iwo Olohun wa isora kuro ninu aburu ti nbe ninu ojo oni ati aburu ti nbe leyin re, mo fi Iwo Olohun Oba wa isora kuro nibi oroju ara, ati aburu imaa se motomoto, mo fi Iwo Olohun wa isora kuro nibi iya ina ati iya inu saare.

Ire Olohun Oba, pelu agbara Re ni a fi ji saye, pelu agbara Re naa ni a fi di ale, pelu agbara Re naa ni a fi nsemi, pelu agbara Re naa ni ao fi ku, odo Re ni a o fi abo si.

Iwo Olohun Oba ,iwo ni Olohun Oba mi, Oluseda mi, ko si eniti ijosin to si ni ododo ayafi Iwo nikan, Iwo ni O seda mi emi si ni erusin re, mo wa lori adehun Re ni bi agbara mi base mo, mo fi Iwo Olohun Oba wa isora kuro nibi aburu ti mo ba fi owo mi se, mo jewo gbogbo idera Re ti O se lemi lori, mo si jewo gbogbo ese mi, fori ese mi jin mi, dajudaju ko si eniti o le forijin eeyan ayafi Iwo Olohun Oba.

Iwo Olohun Oba, mo ji saye leniti n fi O jeri, mo si n fi awon ti won gbe aga ola Re dani ati awon Malaika ati gbogbo awon eda Re jeri wipe Iwo ni Olohun,ko si eniti ijosin tosi lododo afi Iwo nikan, ko si si orogun pelu re ati dajudaju Anabi Muhammad eru Re ni bee sini ojise Re ni. Ao wi gbolohun yii ni eemerin.

Iwo Olohun, gbogbo nkan to ba ji pelu mi ninu ike, gbogbo re odo Re nikan ni o ti wa, ko si orogun pelu Re, tiRe ni iyin ati ope.

Olohun, se Iwosan fun mi ni ara mi, Olohun, se Iwosan fun mi nibi igboran mi, Olohun se iwosan fun mi nibi irina mi, ko si eniti ijosin tosi lododo ayafi Iwo Olohun, Olohun, mo fi O wa isora kuro nibi iwa keferi ati osi ,ati wipe mo fi O wa isora kuro ninu iya saare, ko si enikan ti ijosin to si ni ododo ayafi Iwo nikan. Ao wi eleyii ni igba meta.

Iwo Olohun ni Oba ti O tomi, ko si enikankan ti ijosin to si ni ododo ayafi Oun, Oun ni mo gbarale, Oun si ni Oba to ni aga ati alaarashi to tobi. A o so eleyii nigba meje.

Iwo Olohun, emi ntoro amojukuro Re ati ini Alafia ara ni aye ati orun, Olohun emi ntoro ni odo Re amojukuro Re ati ike Re ninu aye mi ati orun mi, ati araale mi ati lori dukia mi, Olohun ba mi gbe aleebu mi pamo ki O si fi aya mi bale nibi gbogbo ohun ti npami laya, Olohun fi iso Re so mi ni iwaju mi, ati ni eyin mi, ati otun mi, ati osi mi, ati ni oke mi, mo si fi O wa isora nibi ki a yo mi pa lati isale mi.

Mo pe Iwo Olohun, Iwo ti O ni mimo nkan ti o pamo ati nkan ti o han, Oluseda awon sanmo ati awon ile, Oluni gbogbo nkan ati Olukapa le e lori, mo jeri lododo wipe ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo, mo fi O wa isora kuro nibi aburu emi mi, ati nibi aburu shaytoon ati isebo si Olohun tii maa n peni lo sidi re, ati kuro nibi ki n se ara mi ni aburu tabi ki n se e si musulumi.

Mo bere pelu oruko Olohun Oba ti o je wipe nkankan ko lee ko inira ba oruko Re ni sanma ati ile, Oun ni Oba ti o gbo ti O si ni mimo.. Ao so eleyi nigba meta.

Mo yonu si Allaah ni Olohun mi, mo yonu si Islaam ni esin mi, mo yonu si Muhammad ni anabi. Ao so eleyi ni igba meta.

Mo pe Iwo Oba Alaaye, Iwo Oba Oludaduro, aanu Re ni mo fi n wa iranlowo, ba mi tun gbogbo oro mi se, ma da mi da ara mi ni odiwon iseju akan.

A ji saye, Agbara si je ti Olohun, Oba gbogbo agbanlaaye, mope Iwo Olohun, emi ntoro oore ti nbe ni ojo eni ni owo Re, isipaya daadaa ibe, ati aranse ibe, ati imole ibe, mo fi Iwo Olohun wa isora kuro nibi ojo oni ati aburu ti nbe leyin re.

A ji saye lori esin Islam, ati lori gbolohun ise afomo Olohun, ati lori esin ti Olohun fi ran anabi Muhammad, ati loju ona anabi wa Ibrahim, ti o je eni ti o gba fun Olohun ti o jupa juse sile fun Olohun, Ko si si ninu oluse ebo si Olohun.

Afomo ni fun Olohun, ati ope niti Olohun. Ao so eleyii nigba Ogorun.

Kosi eniti ijosin tosi ni ododo ayafi Allah ni Oun nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ikapa, ti E ni eyin, Oun naa ni alagbara lori gbogbo nkan… Ao wi eleyii nigba mewa abi leekan soso, nigba ti oju ba n row a.

Ko si enikankan ti ijosin to si ni ododo ayafi Allah lOun nikan, kosi orugun fun Un, ti E ni ola ti E ni ope, Oun naa ni alagbara lori gbogbo nkan… Ao wi eleyi ti a ba ji nigba ogorun.

Mimo ni fun Olohun, ope ni fun Un, ni iye onka eda Re ati niye bi Olohun se yonu to, ati ni odiwon aga ola Re, ati ni odiwon taada oro Re.

Olohun, mo ntoro ni odo Re, imo to sanfani ati ariziki to mo kanga ati ise ti yio ni atewogba… Ao so eleyii nigba ti eru ba ji

Mo wa aforijin wa si odo Olohun, mo si wa ituuba lo si do Re,.. Ao so eleyii nigba ogorun ni ojoojumo

Mo fi oruko Olohun to pe wa isora kuro nibi aburu nkan ti O da… Ao so eleyii ni eemeta ni irole.

Olohun, bani se ike ati ola fun Anabi wa Muhammed… Ao se eleyii leemewa

 Eleyii ni iranti ti a maa nse ki a to sun

Ojise Olohun yio pa atelewo re mejeeji po, yio wa ta oda si aarin won, yi o wa ke awon ayah to nbo yi si won laarin:

Mo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe Olohun okan soso niAllahu ni Oba AjironukanKo bimo, enikankan ko si bi IKo si si afiwe kankan fun Un ninu gbogbo nkan todaMo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe mo wa isora pelu Oba ti O ni imole asunba nigba ti o ba yoNibi aburu awon nkan ti O daAti nibi aburu okunkun nigba ti o ba kun biribiriAti nibi awon aburu awon ti won maa n ta oda sinu kokoAti nibi aburu awon onikeeta nigba ti won ba n se keetaMo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orunSo wipe {ire ojise} mo wa isora pelu Olohun Oba to ni awon eeyanOba ti O je wipe Oun ni Oba ti O ni agbara lori gbogbo awon eeyan patapataOba ti awon eeyan maa njosin fun lododo ni oun nikanNibi aburu shaetan ti maa nko royiroyi ba eeyan ti o si maa n sa pamoEleyi ti maa nko royiroyi sinu okan omoniyan

Ati nibi aburu awon alujannnu ati aburu ti eeyan

Leyin eleyi ni yio wa fi owo re ra ibi ti o ba lagbara mo nibi gbogbo arare, yio bere si ni maa fi mejeeji ra ori re, ati oju re, ati ibi ti owoja re bade nibi ara re, yio se eleyi leemeta

Olohun Oba Allah ti ko si eni ti ijosin to si ayafi Oun, Oba Abemi Oba ti o moju to gbogbo nkan, kii toogbe bee si ni kii sun, ti E ni gbogbo ohun to nbe ni sanmo ati ile, kosi eniti o le sipe ni odo Re ayafi pelu iyonda Re. O mo ohun ti o n be ni iwaju won ati ohun ti nbe ni eyin won, atipe won ko rokirika nkankan ninu imo Re ayafi pelu ohun ti O ba fe, aga Re fe tayo awon sanmo ati ile, atipe siso awon mejeji ko ko inira ba A, atipe Oun ni Oba ti O gaju ti O si tobi

Ojise nigbagbo si ohun ti won sokale fun un lati odo Olohun Oba re, ati pe awon olugbagbo ododo naa nigbagbo si ohun ti won sokale fun ojise, gbogbo won ni won ni igbagbo ninu Olohun ati awon malaika Re, ati awon tira Re, ati awon ojise Re, a o nii se iyato Kankan ninu awon ojise Re, awon olugbagbo ododo yio so wipe a gbo ti E Oluwa wa, a si tele ase Re, fori ese wa jin wa, Olohun wa, odo Re naa ni ifi abo si

Olohun ko la nkankan bo emi kan lorun ayafi ohun ti o ni agbara re, ti emi ni yio maa je ise rere toba se, oun naa lo ni ohun aburu ti o ba se, Olohun Oba ma se fi iya je wa nigba ti a ba gbagbe nkan abi ti a ba se asise, Olohun Oba wa, ma gbe eru ese le wa lori, gege bi O se gbe e le awon ti o ti saaju wa lori, Olohun ma se di eru ti a o nii le gbe ru wa, ni amojukuro fun wa, se aforiji ese wa, si ke wa, Iwo ni Oluwa wa, je ki a bori gbogbo ijo keferi

Pelu oruko Iwo Olohun Oba aseda mi, mo fi egbe mi le ile, pelu oruko Re naa ni ma fi gbe e dide pada, ti O ba gba emi mi, ba mi se ike re, ti O ba si da emi mi si, ba mi fi iso Re so o, pelu iso re ti o fi nso awon erusin Re rere

Olohun Oba Iwo ni O da emi mi, Iwo naa ni O O si pa a, ti E ni pipa ati yiye re nse, ti O ba ji I, ba mi fi iso Re so o, ti O ba si pa a, ba mi forijin in  Mo pe Iwo Olohun, mo toro ini alekun Alafia lodo Re.

Olohun so mi nibi iya Re ni ojo ti O maa gbe erusin Re dide

Pelu oruko Iwo Olohun ni maa fi ku ati pe oun naa ni maa fi semi

Mimo ni fun Olohun (Yio se eleyii nigba metalelogbon), ope ni fun Olohun (Yio se eleyii nigba metalelogbon), Olohun ni O to bi julo (yio wi eleyi nigba merinlelogbon)

Mo pe Iwo Olohun Oluni sanmo mejeeje, Oluni ile mejeeje, Oluni aga al-arashi to tobi, Olohun wa, Oba gbogbo nkan, Olumu eso ati koro hu jade, Oluso taorah ati injiil ati al-fur'qooni ti nse Al kuraani kale, mo fi O wa isora kuro nibi aburu gbogbo nkan to je pe aaso ori re nbe lowo Re, mo pe Iwo Olohun Iwo ni Oba akoko ti nkankan ko gbawaju Re, Iwo ni Oba igbeyin ti nkankan ko si leyin Re, Iwo ni Oba ti O han, ko si nkankan ni oke Re, Iwo ni Oba ti o pamo, ti ko si nkankan ti o pamo ju O lo, ba wa san gbese orun wa ki O si la wa kuro ninu osi

Gbogbo ope ni fun Olohun ti O fun wa ni jije ati mimu, ti O si to wa kuro nibi gbogbo nkan, O si gbawa mora nibi gbogbo nkan, melo ni ogoro eniti ko ni eniti o le to o, ti ko si ni eniti o le gba a mora si odo

Mo pe Iwo Olohun, Iwo ti O ni mimo nkan ti o pamo ati nkan ti o han, Oluseda awon sanmo ati awon ile, Oluni gbogbo nkan ati Olukapa le e lori, mo jeri lododo wipe ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo, mo fi O wa isora kuro nibi aburu emi mi, ati nibi aburu shaytoon ati isebo si Olohun tii maa n peni lo sidi re, ati kuro nibi ki n se ara mi ni aburu tabi ki n se e si musulumi.

Yio ka Alif lam mim, ti SURATU SAJDAH ati SURATUL- MULK

Olohun mo fa emi mi le O lowo, mo si fa oro mi le O lowo,mo wa da oju mi ko odo Re, mo fi eyin ti O leniti nwa oore ti si tu nfoya, kosi ibusalo si Kankan ayaafi odo Re nikan soso, mo ni igbagbob si tira Re ti O sokale ati pelu anabi Re ti O rannse

 Eleyii ni adura ti a maa nse nigba ti a ba yira pada ni oru

Ko si enikeni ti ijosin tosi lododo aya fi Allah Oba okan soso, Oba Olubori, Oba ti O ni awon sanmo ati ile ati ohun to nbe laarin awon mejeeji, Oba abiyi Oba Alaforijin julo

 Eleyii ni adura ti eeyan maa nse ti eyan ba ni ipaya kan ni oju orun abi eniti won ba fi adanwo ipa aayun se

Mo n fi awon gbolohun Olohun ti o pe wa isora kuro nibi ibinu Re ati ifiya jeni Re, ati aburu awon eru Re, ati nibi royiroyi awon esu ati ki won wa si odo mi.

 Ohun ti eniti Oba la ala yoo se

Yio ta oda si egbe osi re nigba metaYio fi Olohun wa isora kuro nibi odo esu ati aburu nkan ti o ri…. Yio se eleyii ni emeta otootoKo ni so fun eni KankanYio paro egbe ti o fi sunO le dide lati kirun ti o ba fe be

 Eleyi ni adura ti a maa nse nibi witr ti a maa n pe ni (kunuutul-witr)

Olohun, fi mi mona ninu awon ti O fi mona, fun mi ni alaafia ninu awon ti O fun ni alaafia, ba mi moju to oro mi ninu awon ti O moju to oro won, fi oore ibukun si ohun ti O fun mi, so mi nibi aburu ohun ti o se ni idajo, Iwo ni O maa n dajo enikankan kii dajo fun O, dajudaju eniti O ba fe kii te, eni ti O ba n ba sota kii niyi,ibukun ni fun O giga si ni fun O.

Olohun, mo fi iyonu Re wa isora kuro ni ibinu Re, mo fi ini amojukuro Re wa isora kuro nibi ifiyajeni Re, mo fi O wa isora kuro lodo Re, mi o le se isiro eyin ti nbe fun O, bi O se yin ara Re naa ni O se ri.

Olohun Oba wa, Iwo nikan ni a o maa josin fun, Iwo ni a o maa kirun fun, ti a o si maa foribale fun, odo Re ni a o maa sure tete wa, a n rankan ike Re, a npaya iya Re, dajudaju iya Re yio le awon oluse keferi ba, Olohun a nwa iranlowo Re, a si nwa aforijin Re, daadaa la fi nse eyin fun O, a o nii se keferi si Iwo Olohun, a ni igbagbo si Iwo Olohun, a nteriba fun O, a bopa bose kuro nibi eniti o ba n se keferi si O

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti a ba salamo leyin irun witiri

Mimo ni fun Olohun Olola, Oba Mimo… A o so o ni igba meta

Eleeketa yio so o sita pelu fi fa ohun re gun ti yio si so pe: Oluwa ti O ni awon malaika ati Jibriil oga won

 Eleyii ni adura ibanuje

Olohun dajudaju emi ni eru Re, omo erukunrin Re, ati omo erubinrin Re, aaso ori mi nbe lowo Re, idajo Re yoo se lemi lori, ipebubu Re naa ba mi lara mu, mo fi gbogbo oruko Re be O, awon oruko ti O pe ara Re, abi ti O so o kale sinu tira Re, abi ti O fi mo enikan ninu awon eda Re, abi ti O fi pamo sinu imo koko lodo Re, ki O se Al'quraani ni ohun ti yio se iregbede okan mi, ati imole aya mi, ati ohun ti yio si ibanuje mi danu, ati ohun ti yio mu edun okan mi lo

Olohun mo fi O wa isora kuro nibi aibale-okan ati ibanuje ati ikagara ati ikoroju, ati sise ahun ati sise ojo, ati eru gbese, ati ki awon omoniyan bori mi

 Eleyii ni adura ti a maa se nigba idaamu

Ko si Oba Kankan ti ijosin to si ni ododo ayafi Allah, Oba ti o tobi, Oba Onisuuru, ko si enikankan ti ijosin ododo to si ayafi Allah, Oba ti O ni aga Al- Arashi ti o to bi julo, kosi enikankan ti ijosin to si ni ododo ayafi Allah Oba ti O ni awon sanmo mejeeje ati ile mejeeje, ati aga Al-arashi Alaponle

Olohun, ike Re ni mo se agbekele re, ma se da mi da ara mi laarin kadiju ki a la a, ba mi tun gbogbo alamori mi se, ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo

Ko si enikankan ti ijosin to si lododo ayafi Iwo Olohun, mimo fun O, dajudaju emi wa ninu awon alabosi

Allahu mi Olohun Oba mi, mi o si ni mu orogun pelu Re rara

 Eleyii ni adura ti a fi maa n koju ota abi eni ti o ni agbara

Olohun, a n fi O si oke aya won ki won ma le de odo wa rara, a si fi o wa isora kuro nibi aburu won

Olohun Iwo ni Alafeyinti mi, Iwo ni Alaranse mi, Iwo ni n o fi maa ti ete ota danu, Iwo ni n o si fi bori won, Iwo ni n o si fi ma aba won ja

Olohun to wa, mondala Re ni Alamojuto.

 Eleyi ni adura eniti o ba nberu abosi alase

Mo pe Iwo Olohun, Oba ti O ni awon sanmo mejeeje, Oba ti O ni aga Al-arashi ti o tobi, je Oluranlowo fun mi lori lagbaja omo lagbaja, ati awon ijo re ninu awon eda ti O da, ki eniKankan ninu won ma se yara se mi ni aburu, eni ti o ba wa iranlowo Re yoo leke, eyin Iwo Olohun gbonngbon, atipe ko si enikankan ti ijosin to si ni ododo ayafi Iwo

Olohun ni Oba ti O tobi julo, Olohun ni agbara ju gbogbo eda Re lo patapata, Olohun ni agbara ju ohun ti mo n beru ti mo si n sora fun lo, mo fi Olohun wa iso, Oba ti ko si eniti ijosin to si ni ododo ayafi Oun, Oba Olumu sanmo mejeeje dani, ti ko je ki won subu si ori ile, ayafi pelu iyonda Re, mo fi wa isora kuro nibi aburu eru Re lagbaja ati awon omo ogun re, ati awon olutele re, ati awon ijo re ninu awon alujannu ati eeyan, Olohun je oluranmise kuro nibi aburu won, eyin Re tobi, iranlowo Re biyi, oruko Re ni ibukun, ko si eniti ijosin t osi ni ododo yato si Iwo…. A o wi eleyii ni igba meta

 Imaa sebi le ori awon ota

Olohun Oba ti O so Al'qurani kale Oba Oluse isirokiakia, ba mi bori awon ijo yii, Olohun bami bori won, ba mi mi won titi

 Nkan ti eniti o ba nberu awon ijo kan maa so

Olohun la mi kuro lowo won pelu ohun ti o ba wu Iwo Olohun

 Eleyin ni adura eniti royi royi ba se ninu igbabo

Yio fi Olohun wa isoraYio kuro nibi ohun ti o nse royi royi siYio si so bayi wipe: Mo ni igbagbo si Olohun ati awon ojise ReYio ke oro Olohun to ni:Olohun ni Oba akoko, Oun ni Olugbeyin, Oun ni eni ti O han, Oun ni eniti O pamo, Oun ni eniti O ni mimo pelu gbogbo nkan

 Adua sisan gbese

Olohun fi halaali Re tomi kuro nibi nkan haram Re, ki O si fi ola Re somi di oloro kuro nibi ohun ti o ba yato si O.

Olohun mo fi O wa isora kuro nibi aibale-okan ati ibanuje ati ikagara ati ikoroju, ati sise ahun ati sise ojo, ati eru gbese, ati ki awon omoniyan bori mi

 Eleyii ni adura eni ti o nse royiroyi nibi irun ati nibi kike nkan

Mo fi Olohun wa isora kuro nibi odo esu eniti won maa nle ni oko, yio si ta oda si apa re osi ni eemeta

 Eleyini adura eni alamori oro kan ba le fun

Olohun kosi nkan to le rorun ayafi ohun ti O ba se ni irorun, iwo ni O si maa nso ilekoko di irorun ti o ba fe

 Eleyi ni adura ti eniti o ba da ese yio so ati ohun ti yio se

Ko si eyikeyi ninu eru kan ti o ba da ese kan, to ba wa se aluwala daadaa leyin eleyi yio dide, yio si gbe rakah irun meji duro leyin eleyii yio wa aforiji Olohun, ko nii se gbogbo eleyii ayafi ki Olohun se aforijin ese re

 Eleyi ni adura ti a fi maa n le esu danu ati awon royiroyi re

Ifi Olohun wa isora kuro ni odo shaytan (esu)

Pipe irun

 Mimo se awon adhkaar (iranti) ati mimo ke kurani alaponle

Eleyii ni adura ti a maa nse ti ohun ti ko ba yo omoniyan ninu ba sele tabi nigba ti apa re ko b aka oro ara re mo.

Olohun ti kadara bi nkan o se lo, ati pe ohun ti o si wu ﷻ‬ ni O se.

 Kiki eniti o bimo ati esi ti eniti o bimo naa maa fo

Olohun yio fi ibukun si ore ti O ta o yii , o dupe fun eniti O fun o ni ore naa, omo naa yio si dagba, Olohun yio ro o ni oro daadaa omo naaEni ti won ki pelu gbolohun yii yio so bayi wipe:Olohun yio fi alubarika fun o, yi o si fi alubarika le o lori, Olohun yio si san o ni esan oloore, Olohun yio ta o ni iru ore naa, yio je ki esan re o kun keke

 Adura ti a maa n fi wa isora fun awon omo keekeekee

Ojise Olohun maa nwa isora fun Hassan ati Hussein, ki Olohun bani yonu si awon mejeeji pelu ko so bayii wipe:Mo nfi awon gbolohun Olohun Oba ti o pe wa isora fun eyin mejeeji kuro ni odo shaytan (esu) ati eranko tabi kokoro oloro, ati kuro nibi gbogbo oju-koju.

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti a ba lo se abewo si alaare

O o nii ri aburu, aisan yii yoo je afomo kuro ninu ese fun e ti Olohun ba fe.Mo be Olohun ti O tobi, Oba ti O ni aga Alaarashi ti o tobi, ki O se iwosan fun o

 Ola ti nbe fun mima be alaisan wo

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:

Ti omoniyan ba lo se abewo omo-iya re ti o je musulumi, yio maa rin ni oju ona alujana titi yio fi joko sibe, ti o ba wa joko, ike Olohun yio bo o daru, ti o ba je wipe ojumomo ni o fi lo, awon egberun lona aadorin malaika ni won o maa sadura fun un titi yio fi lele, ti o ba je irole ni o ba lo, awon egberun lona aadorin malaika ni yio maa sadura fun un titi yio fi mojumo

 Eleyii ni adura ti alaare to ti ja okan kuro nibi igbesi aye re maa se.

Olohun, fori jin mi ki O si tun kemi, ki O si dami po mo alabarin to ga julo

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba -je enikan tojewipe nigba iku re, o n ti owo re mejeeji bo inu omi, yio si fi mejeeji pa oju re yio wa so wipe:

Ko si Oba Kankan ti ijosin ododo tosi ayafi Olohun, Dajudaju ihunrira nbe fun iku

Ko si Oba ti ijosin tosi ni ododo ayafi Olohun, ati pe Olohun Oba ni Oba ti o tobi julo, ko si Oba ti ijosin tosi ni ododo ayafi Olohun ni oun nikan ti ko si orogun fun Un, ko si Oba ti ijosin tosi ni ododo ayafi Olohun, Oba to ja si wipe ti E ni ola nse, ti E ni ope nse, ko si eniti ijosin tosi ni ododo ayafi Olohun, ko si ete Kankan ati agbara kan ti yio maa be ayafi pelu Olohun

 Eleyii ni mimo fi gbolohun le eniti o n poka iku lenu

Eniti o ba je wipe gbolohun to wi keyin ni "ko si Oba Kankan ti ijosin tosi ni ododo ayafi Olohun, iru enibe yio wo alujana

 Eleyii ni adura eniti won ba fi adanwo kan

Odo Olohun ni awa ti wa, odo Re ni a o si seri pada, Olohun, san mi ni esan nibi adanwo ti o sele si mi yii, ohun ti o dara ju u lo ni ki o fi ropo fun mi

 Eleyii ni adura sise ti a ba fe pa oju oku de

Olohun forijin lagbaja (a o daruko re) gbe ipo re ga laarin awon olumona, se arole fun un lori awon ti o seku ninu awon aromodomo re, fori jin wa ati oun naa, Iwo Olohun Oba agbanlaaye, ba ni fe saare re fun un, ki O si ba ni tan imole sinu saare re fun un.

 Eleyii ni adua ti a maa n se nibi irun kiki si oku lara

Olohun ba ni forijin in, ki O si bani ke e, bani se amojukuro fun un, bani pon isokale re sinu saare re le, bani fe iho inu saare re fun un, bani fo o mo pelu omi ati yinyin ati omi ti o tutu, Olohun bani mo on kuro ninu ese gege bi a se maa n mo aso funfun kuro nibi egbin, Olohun bani fi ile to daaju ile re lo ropo fun un ati awon alabagbeere to dara ju aye re lo, ati aya ti o dara ju aya re lo, Olohun bani mu u wo alujanna, ba ni so o kuro nibi iya saare ati iya ina.

Olohun forijin eniti o nsemi ninu wa ati oku wa, ati eniti o wa ati eniti ko lee wa, ati omo kekere inu wa ati agbalagba, ati okunrin inu wa ati obinrin inu wa, Olohun, eniti O ba da emi re si ninu wa, ba ni je ki o maa semi ninu esin Islam, eniti O ba pa ninu wa, ba ni pa a lori ini igbagbo, Olohun ma je ki a padanu esan re, Olohun ma je ki a sonu leyin iku re.

Olohun dajudaju lagbaja omo lagbaja ti wa ni abe aabo Re bayii, o si ti wa ninu iso Re pelu, ba ni so o kuro ninu fitina saare ati iya ina, Iwo ni O ni pipe adehun ati ododo, fi ori jin in ki O si ke e tori pe Iwo ni Alaforijin Onikee.

Olohun eni yi ni erusin re ati omo erubinrin re, o ni bukata si ike re, ko si ohun ti O fe fi iya re se, ti o ba je pe olusedaadaa ni, bani se alekun daadaa re, ti o ba je eniibi, ba ni se amojukoro nibe fun un

 Adua fun omode ti o siwaju awon obi re fi aye sile

Olohun so o kuro nibi iya saare

Ti o ba si tun so pe:Olohun ba ni se e ni asiwaju nkan ifipamo rere fun awon obi re mejeeji, ati olusipe ti won o gba ipe re, Olohun ba ni fi je ki osuwon awon obi reo kun keke, je ki laada won o po daadaa, ba ni da a po pelu awon enirere ninu awon olugbagbo ododo, ba ni fi si abe itoju anabi Ibrahim, Olohun ba ni so o pelu ike Re kuro ninu iya ina Jaheem, Olohun ba ni jogun ile ti o dara ju ile ti o ti kuro lo fun un, ati araale ti o dara araale re lo, Olohun forijin awon asiwaju wa ti won ti lo ati awonomowere iru wa ti won ti lo ati awon ti won saaju wa pelu igbagbo. A le wi eleyii naa.

Olohun se e ni araawaju ati asiwaju ati esan

 Adura ibanikedun

Titi Olohun ni nkan ti O ba gba, ti E naa ni ohun ti O ba fun ni, gbogbo nkan wa lodo Olohun pelu akoko kan pato, yaa se suuru ki o si fi esan ti sodo Olohun.Ti o ba so bayii naa:Olohun yio ba ni je ki laada re o opo, yio ba ni se idaro re fun eyan re ni nkan rere, yio bani forijin oku re. Eleyii naa tun da

 Eleyii ni adura ti a ma n se ti a ba fe ki oku wo inu saare

A gbe e sinu sare pelu oruko Olohun ati ni ori sunnah ojise Olohun

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti a ba sin oku tan

Olohun bani forijin in, Olohun bani fi ahon re mule

 Adura ti a maa nse ti a ba lo se abewo awon saare

Alaafia Olohun ki o maa ba eyin olugbe ibi ninu mumini ati musulumi, bi Olohun ba fe awa naa fee ba yin nibi, Olohun yio ba ni ke awon olugbawaju inu wa ati awon ti won nbo leyin, A be Olohun fun awa ati eyin naa ini amojukuro Olohun

 Eyi ni adura ti a maa nse ti afefe ba nfe

Olohun mo ntoro ore inu afefe yii, mo si fi O wa isora kuro nibi aburu inu afefe yii

Olohun, Emi ntoro lowo Re oore afefe yii ati oore ti nbe ninu re ati oore ti won fi ran afefe naa, mo si n fi O wa iso kuro nibi aburu afefe yii, ati aburu to wa ninu afefe yii, ati aburu ti won ranse re wipe ki o lo se.

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti ara ba san

Mimo ni fun eniti ara nse afomo fun pelu ope dudu re, mimo ni fun eniti awon malaika nse afomo lata ra biberu re.

 Laraadura ti a fi maa ntoro ojo riro

Iwo Olohun ro ojo fun wa ni ojo ti yoo ba wa mu idaamu wa kuro, ti igbeyin re yoo si dara, ojo ti yoo mu ki ile o ruwe, ti yoo si se wa ni anfaani, ti ko nii ni wa lara, ro o fun wa laipe, ma se je ki o pe.

Iwo Olohun ro ojo fun wa, Iwo Olohun ro ojo fun wa, Iwo Olohun ro ojo fun wa.

Olohun fun awon erusin Re ni omi mu, Olohun fun awon daaba re ni omi mu, Olohun fon ike re ka, Olorun bani ji ilu re to ti di oku.

 Eleyii ni adura ti a ba ri ojo

Olohun bani se ojo yii ni ohun ti yio wulo, ti yio se anfani

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti ojo ba ro tan

Olohun ro ojo fun wa pelu ola ati ike Re

 Ninu Adura ti a maa nse nigba ti a ba fe ki ojo o wawo

Iwo Olohun, awon ayika wa ni ki o maa ro o si ma se ro o le wa lori, je ki o maa ro sori awon ile giga ati awon oke keekeekee, ati si inu awon afonufoji ati sara awon itakun igi.

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti a ba ri iletesu

Olohun Ni O tobi julo, Olohun je ki o yo lewa lori pelu ifokanbale ati ini igbagbo, ati ti ola ati igba ifa fun Olohun, ati ifini se konge sibi ohun ti O nife si, Olohun wa ati Olohun re ni Allaah

 Eleyii ni adura ti a maa nse ti alaawe ba fe sinu

Ongbe ti lo bayii, awon isan si ti tutu, laada si ti fi ese mule ti Olohun ba fe

Olohun, emi nbe O pelu ike Re to je wipe o ko gbogbo nkan sinu wipe ki O se aforijin fun mi

 Adura ti a maa nse siwaju ki a to jeun

Ti enikookan yin ba fe jeun ki o ya sowipe: "mo bere pelu oruko Olohun, ti o ba gbagbe ki o wi i ni ibere ki o ya tete so wipe " mo be re pelu oruko Olohun ni ibere re ati ni ipari re

Eniti Olohun ba fun ni ounje je ki o yaa so bayii wipe:"Olohun ba ni fi ibukun sinu ounje yii, ki O si fun wa ni eyiti o dara ju u lo je, eniti Olohun ba fun ni wara mu ki o yaa so wipe, Olohun bani fi alubarika sinu re ki O si se alekun re fun wa.

 Eleyii ni adura ti a maa nse nigba ti a ba jeun tan

Ope ni fun Olohun ti o se wipe O fun mi ni ounje yii je ti O si pese re fun mi ti ko ki n se ete Kankan lati odo mi ati agbara

Ope ni fun Olohun, o pe topo to daa to si ni ibukun ninu, ope ti n ko le du ti yoo fi dogba pelu oore ti Olohun se fun mi, ope ti ko se e pati ti ko si see ma se rara.

 Adua ti Alejo yio se fun eniti o fun un ni ounje

Olohun bami fi ibukun sibi ohun ti o se ni ije fun won, bani fi ori ese won ji won ki o si ba ni se ike won

Eleyii ni adura ti a maa nse fun eniti o fun wa ni ounje tabi mimu

Olohun bani se jije fun eni to fun mi ni jije, ba ni se mimu fun eni to fun mi lomi mu.

 Adura ti eeyan maa nse nigbati eeyan ba sinu lodo awon ara ile kan.

Awon alaawe sinu lodo yin, awon eniire si je ounje yin, awon malaika si ti se adura fun yin.

 Sise adura alaawe nigbati ounje ba de ti ko si tii sinu.

Ti won ba pe enikookan yin si ounje ki o ya je ipe, ti o ba wa je eniti o gba aawe ki o se adura, ti o ba wa je eniti ko gba aawe ki o yaa jeun.Itumo (falyusolli) ni pe: ki o ya se adura.

 Ohun ti alaawe maa nso nigbati enikan ba bu u.

Dajudaju alaawe ni mi, dajudaju alaawe ni mi.

 Adura ti a maa nse nigbati a ba ri eyi ti o ba koko pon ninu eso.

Ire Olohun Oba, fi alubarika sibi eso wa fun wa, wa tun fi alubarika si ilu wa fun wa, wa tun fi alubarika sibi soohu wa fun wa, wa tun fi alubarika sibi mudu wa fun wa.

 Adura ti a ba sin.

Ti enikookan yin ba sin, ko ya so pe: "Alhamdulillaah" ope ni fun Olohun, ki omo iya re tabi ore re o wa so fun un pe: "Yarhamukalloohu" Olohun a ke e, ti o ba wa so fun un pe: "Yarhamukalloohu", ki o ya so pe: Yahdiikumulloohu wa yuslihu baalakum" Olohun a fi yin mona yio si tun alamori yin se.

 Ohun ti a ma nso fun keferi nigbati o ba sin ti o si dupe fun Olohun

Olohun a fi yin mona yio si tun isesi yin se.

 Adua sise fun eniti o ba fe iyawo.

Olohun a fun e ni alubarika, yio si tun se alubarika le o lori, yio si fi oore si idapo yin.

 Adua eniti o fe iyawo ati rira nkan ogun.

Ti enikan ninu yin ba fe omobinrin, tabi ti o ba ra eru kan, ki o ya so pe: Ire Olohun dajudaju emi nbeere lowo Re daada re, ati daada ti O da mo on, mo wa nfi O wa iso kuro nibi aburu re, ati aburu ti O da mo on, ti o ba tun wa ra rakunmi kan ki o ya gba sonso ike eyin re mu, ki o si so iru adua oke yi.

 Adua sise siwaju wiwole to iyawo eni.

Pelu oruko Olohun, Ire Olohun, le shaitoon jina siwa, ki O si le shaitoon jina si nkan ti O fun wa.

 Adua inu bibi.

Mo fi Olohun Oba wa iso kuro lodo shaitoon eniti a maa nju oko mo.

 Adua ti eniti o ba ri eniti won fi adanwo kan ma nse.

Ope ni fun Olohun Oba ti O mu mi lara da kuro nibi nkan ti O fi se adanwo fun o, ti O si dami lola lori opolopo ninu awon nkan ti o da ni ti didalola.

 Nkan ti won ma nso nibi ijoko.

Lati odo Ibnu Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe:Won maa nka fun ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nibi ijoko kan ni igba ogorun siwaju ki o to dide: Ire Olohun se aforijin fun mi, ki O si gba tuuba mi, dajudaju Ire ni Oba ti maa ngba tuuba ti si maa nfi ori jinni.

 Ohun ti maa npa asise ijoko re.

Mimo fun O Ire Olohun, ati pe ti E ni ope nse,mo jeri wipe ko si olujosin fun mii yato si O, mo wa aforijin Re mo si tun tuuba lo si odo Re.

 Adua sise fun eniti o ba so pe Olohun a fi ori jin e.

Ati iwo na.

 Adua sise fun eniti o ba se daada fun e.

Olohun a san e ni esan daada.

 Ohun ti Olohun fi maa nso eeyan kuro lowo Dajjaal.

Eniti o ba ha aaya mewa ni ibere Suuratul Kahf, won a so o kuro lowo Dajjaal.Ati iwasora pelu Olohun kuro nibi fitina re ni ipari ataaya igbeyin nibi gbogbo irun kookan.

 Adua sise fun eniti o ba so pe: dajudaju mo nife re nitori ti Olohun.

Eniti o titori e nife mi yio nife iwo na.

 Adua sise fun eniti o ba fi dukia re lo o.

Olohun a fun e ni alubarika lori awon araale re ati dukia re.

 Adua ti eeyan maa nse fun eniti o ba ya ni lowo nigbati a ba fe san owo naa pada.

Olohun a fun o ni alubarika lori awon ara ile re ati dukia re, dajudaju esan yiya nkan naa ni didupe ati sisan an pada.

 Adua ipaya kuro nibi ebo.

Ire Olohun dajudaju mo fi O wa iso kuro nibi ki nse ebo pelu Re ti mo si mo, mo wa wa aforijin Re nibi nkan ti mi o mo.

 Adua sise fun eniti o ba so wipe Olohun a fun e ni alubarika.

Olohun a fun iwo naa ni alubarika.

 Adua kikorira mima ro ero aburu tabi ero daadaa latara eye.

Ire Olohun, ko si eye kankan ti o le se anfaani tabi ni eeyan lara leyin Iwo Olohun, ko si si daada kan ayafi titi Iwo Olohun, ko si si olujosin fun mii ayafi Iwo.

 Adua gigun nkan.

Pelu oruko Olohun, eyin ti Olohun niMimo fun eniti o ro eleyi fun wa ti o si je wipe awa o ni ikapa le e lori.Atipe dajudaju awa odo Olohun wa ni a maa seri pada si.Gbogbo eyin ti Olohun ni, gbogbo eyin ti Olohun ni, gbogbo eyin ti Olohun ni, Olohun Oba tobi, Olohun Oba tobi, Olohun Oba tobi, mimo Re Olohun Oba, dajudaju emi ti se abosi emi ara mi, wa se aforijin fun mi, toripe tajudaju ko si eniti o le se aforijin awon ese ayafi Iwo.

 Adua irin-ajo.

Olohun Oba tobi, Olohun Oba tobi, Olohun Oba tobiMimo fun eniti o ro eleyi fun wa ti o si je wipe awa o ni ikapa le e lori.Atipe dajudaju awa odo Olohun wa ni a maa seri pada si.Ire Olohun dajudaju awa nbeere lowo Re nibi irin-ajo wa yi daada ati ipaya, ati ninu ise eyiti O yonu si, Ire Olohun se irin-ajo wa yi ni irorun fun wa, sun jijina re mo wa, Ire Olohun, Iwo ni Aladuroti ninu irin-ajo, Iwo si ni Arole lodo awon ara ile, Ire Olohun, dajudaju emi nfi O wa iso kuro nibi idaamudaabo irin-ajo, ati kuro nibi irisi ibanuje, ati apadabo aburu nibi dukia ati ara ile.Ti o ba wa seri pada yio so won yio wa fi kun won pe:A nseri pada, a nwa tutuuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun Un.

 Adua wiwo abule tabi ilu.

Ire Olohun Oba ti O ni sanmo mejeeje ati awon nkan ti won se booji bo, ati Oba ti O ni awon ile mejeeje ati awon nkan ti won gbe lori, ati Oba ti O ni awon esu ati awon ti won ti so nu, ati Oba ti O ni awon ategun ati awon nkan ti won ngbe fo, mo nbeere lowo Re daada abule yi, ati daada awon ara inu re, ati daada ti o wa nibe, mo wa nfi O wa iso kuro nibi aburu re, ati aburu awon ara ibe, ati aburu ti o wa nibe.

 Adua wiwo inu oja.

Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso, ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E si ni eyin nse, Oun ni njini Oun ni si npani, Oun si ni Oba ti nsemi ti ko si nii ku, owo Re ni gbogbo daada wa, Oun sini Oba ti O ni ikapa lori gbogbo nkan.

 Adua sise nigbati nkan ogun ba da lule.

Pelu oruko olohun.

 Adua ti arin irin-ajo ma nse fun eniti o wa nile.

Mo fi yin le Olohun Oba lowo Eniti o se wipe nkan ti a ba fun Un so kii sonu.

 Adua ti eniti o wa nile ma nse fun arin irin-ajo.

Mo fi esin re le Olohun lowo, ati afunnso re, ati awon igbeyin ise re.

Olohun a fun o ni iberu Re, yio si fi ori ese re jin o, yio si ro daada fun o ni ibikibi ti o ba wa.

 Gbigbe Olohun tobi ati sise afomo fun Un nigbati eeyan ba nrin irin-ajo.

Jaabir so – ki Olohun yonu si i -:

A je enikan ti o je wipe ti a ba gun oke, a maa gbe Olohun tobi, ti a ba si so kale a maa se afomo fun Un.

 Adua ti arin irinajo maa nse nigbati o ba rin ni asiko saari.

Olugbo oro kan mu eyin mi fun Olohun de etigbo elomiran, ati dida adanwo Re lori wa, Ire Olohun wa wa pelu wa, ki O si se ola fun wa, mo je eniti nwa iso pelu Olohun kuro nibi ina.

 Adua sise nigbati o ba so kale si aaye kan nibi irin-ajo tabi eyiti o yato si i.

Mo wa isora pelu awon oruko Olohun eleyi ti o pe kuro nibi aburu nkan ti O da.

 Iranti sise nigbati eeyan ba nseri pada lati irinajo.

Yio gbe Olohun tobi ni gbogbo aaye ti o ba ga ni eemeta, leyinna yio wa so pe:

Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso, ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun si ni Oba ti O ni ikapa lori gbogbo nkan, a nseri pada, a nwa tituuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun un, Olohun sika adehun Re, O si ran eru Re lowo, O si segun awon Al-A'azaab ni Oun nikan.

 Ohun ti eniti alamori ti o dun mo ninu tabi ti o korira ba de ba a maa so.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – je eniti o ma nso nigbati alamori ti o dun mo on ba de ba a pe:Ope ni fun Olohun Oba ti o se wipe pelu idera Re ni gbogbo daada fi maa npe.Ti alamori ti o korira ba si de ba a yio so pe:Ope ni fun Olohun Oba lori gbogbo isesi.

 Ola ti o nbe fun mima se asalaatu fun anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a -

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Eniti o ba se asalaatu kan fun emi anabi mewa re ni Olohun o fi da pada fun un.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:E ma so saare mi di odun atipe e maa se asalaatu fun mi; toripe dajudaju asalaatun yin o maa bami ni aaye kaye ti e ba wa.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Ahun eyan ni eniti won daruko mi lodo re ti ko si le se asalaatu fun mi.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Dajudaju o nbe fun Olohun awon malaika ti won ma nrin orile kaakiri won si ma nmu kiki awon ijomi wa ba mi.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Ko si enikankan ti yio salaamo simi ayaafi ki Olohun da emi pada simi lara titi maa fi da a loun salamo re.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

E ma so saare mi di odun atipe e maa se asalaatu fun mi; toripe dajudaju asalaatun yin o maa bami ni aaye kaye ti e ba wa.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Ahun eyan ni eniti won daruko mi lodo re ti ko si le se asalaatu fun mi.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Dajudaju o nbe fun Olohun awon malaika ti won ma nrin orile kaakiri won si ma nmu kiki awon ijomi wa ba mi.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Ko si enikankan ti yio salaamo simi ayaafi ki Olohun da emi pada simi lara titi maa fi da a loun salamo re.

 Mima fon salamo ka.

Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:

Ee le wo Aljannah afi ki e gba Olohun gbo, ee le gba Olohun gba afi ki e nife arayin, ee wa je ki ntoka yin si nkankan ti o je wipe ti e ba se e ee nife arayin, e maa fon salamo ka laarin ara yin.

Nkan meta kan nbe eniti o ba ko o jo niti paapa o ti ko igbagbo jo: I maa se dogba ndogba dori emi re, ati I maa fon salamo ka fun gbogbo aye, ati I maa na ninu kosi.

Lati odo Abdullaah omo Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji - :Dajudaju aarakunrin kan bi anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – leere wipe iru islaamu wo lo fi ndaa ju? O so pe: ki o maa fun awon eeyan ni ounje, ki o si maa salaamo si eniti o ma ati eniti oo mo.

Dajudaju aarakunrin kan bi anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – leere wipe iru islaamu wo lo fi ndaa ju? O so pe: ki o maa fun awon eeyan ni ounje, ki o si maa salaamo si eniti o ma ati eniti oo mo.

 Bawo ni a se ma nda keferi loun nigbati o ba salamo.

Ti awon ti a fun ni tira ba salaamo siyin ki e fun won lesi pe: "WA ALAIKUM" ati eyin naa.

 Adua sise nibi gbigbo kiko akuko ati ihan ketekete.

Ti e ba gbo ti akuko ba ko ki e ya beere lowo Olohun ninu ola Re; toripe dajudaju o ri malaika kan ni ti e ba si gbo ti ketekete han ki e ya wa iso pelu Olohun kuro lodo shaitoon tori dajudaju o ri shaitoon kan ni.

 Adua ti eeyan ma nse nigbati eeyan ba gbo gbigbo gbigbo awon aja ni oru.

Ti e ba gbo gbigbo awon aja ati ihan ketekete ni oru ki eya wa isora pelu Olohun kuro lodo won; toripe dajudaju won nri ohun ti eyin o ri ni.

 Adua ti waa se fun eniti o ba bu.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Ire Olohun eyikeyi muumini ti mo ba bu u se e ni ohun ti yio fi sun mo O fun un ni ijo agbende.

Ire Olohun eyikeyi muumini ti mo ba bu u se e ni ohun ti yio fi sun mo O fun un ni ijo agbende.

 Ohun ti Musulumi o maa so nigbati o ba yin Musulumi.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Ti enikookan yin ba je eniti o nyin ore re ti ko si ibuye ko ya so pe: mo nlero re bee Olohun lo si ma amodaju re, mio si se afoma enikankan le Olohun lowo, mo nlero re – ti o ba mo nkan yen – bai bai.

Ti enikookan yin ba je eniti o nyin ore re ti ko si ibuye ko ya so pe: mo nlero re bee Olohun lo si ma amodaju re, mio si se afoma enikankan le Olohun lowo, mo nlero re – ti o ba mo nkan yen – bai bai.

 Ohun ti Musulumi maa so nigbati won ba nse afomo re.

Ire Olohun ma fiya jemi pelu ohun ti wo nso, wa fi ori jin mi nibi ohun ti won o ma, wa semi ni eeyan daada ju bi won se lero lo.

 Bawo ni eniti o gbe Arami Hajj tabi Umurah o se maa se labbaika.

Labbaikal laahummo labbaik, labbaika laa sheriika laka labbaik, innal amda, wan ni'imata, laka wal mul'k, laa sheriika lak.

 Mimaa gbe Olohun tobi nigbati o ba de ibi okuta dudu.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – rokirika ile Olohun lori rakunmi gbogbo igba ti o ba ti de ibi origun yio na nkan ti o wa ni owo re si i yio si gbe Olohun tobi.

 Adun ti a ma nse laarin Ruknul Yamaaniy ati Ajarul Aswad.

Robbana aatina fid duniya asanatan wa aakhirati asanatan wa qina adhaaban naar.  Olohun wa se daada fun wa ni aye ki o si se daada fun wa ni ojo ikehin ki o si lawa kuro ninu iya ina.

 Adua diduro lori Safa ati Marwa.

Nigbati anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – sunmo Safa o ka:Innas sofa wal marwata min sha'aairil laah.  Dajudaju Safa ati Marwa ninu awon aaye ami Olohun lo wa.Maa bere pelu ohun ti Olohun bere pelu e.O wa bere pelu Sofa o si gun un titi ti o fi ri ile, o si da oju ko qiblah, o si se Olohun lokan, o si gbe E tobi, o si so pe:Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun sini oba ti o ni ikapa lori gbogbo nkan, a nseri pada, a nwa tutuuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun un, Olohun sika adehun Re, O si ran eru Re lowo, O si segun awon Al-A'azaab ni Oun nikan.Leyinna o wa se adua laari re. o so iru eleyi ni eemeta, Al-Hadiith.

Innas sofa wal marwata min sha'aairil laah.  Dajudaju Safa ati Marwa ninu awon aaye ami Olohun lo wa.

Maa bere pelu ohun ti Olohun bere pelu e.

O wa bere pelu Sofa o si gun un titi ti o fi ri ile, o si da oju ko qiblah, o si se Olohun lokan, o si gbe E tobi, o si so pe:

Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun sini oba ti o ni ikapa lori gbogbo nkan, a nseri pada, a nwa tutuuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun un, Olohun sika adehun Re, O si ran eru Re lowo, O si segun awon Al-A'azaab ni Oun nikan.

Leyinna o wa se adua laari re. o so iru eleyi ni eemeta, Al-Hadiith.

O tun wa ninu e pe: o si tun se ni Marwa gegebi o se se ni Sofa.

 Adua ti a ma nse ni ojo Arafa.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Adua ti o loore ju ni adua ijo Arafa atipe eyiti o loore tie mi pelu awon anabi to saaju mi so ni: "laa ilaaha illal laahu wahdahu laa shariika lahi, lahul mulku wa lahul amdu wa huwa ala kulli shaihin qodiir"Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun sini oba ti o ni ikapa lori gbogbo.

Adua ti o loore ju ni adua ijo Arafa atipe eyiti o loore tie mi pelu awon anabi to saaju mi so ni: "laa ilaaha illal laahu wahdahu laa shariika lahi, lahul mulku wa lahul amdu wa huwa ala kulli shaihin qodiir"Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun sini oba ti o ni ikapa lori gbogbo.

 Iranti sise ni Al-Mash'aril Araam.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – gun nkan ogun re ti nje Al-Qos'waah titi ti o fi de Al-Mash'aril Araam (Muzdalifa) ni o wa da oju ko Qibla o si se adua, o si gbe Olohun tobi, o si so pe ko si olujosin fun kankan ayaafi Olohun, o si se E lokan ko si ye ko gbo ni eniti o duro titi ti o fi mole gan an, o wa lo siwaju ki oorun to yo.

 Gbigbe Olohun tobi pelu oko kookan nibi lile oko.

Yio gbe Olohun tobi ni gbogbo igba ti o ba nju oko kookan ni awon aaye meteeta ti a ti ma nju oko, leyinna yio sun siwaju, yio o duro yio si se adua ni eniti o da oju ko qibla, leniti yio gbe owo re mejeeji soke nibi aaye iju oko alakoko ati eleekeji.

Ama nibi aaye iju oko ti o gbeyin yio ju u, yio si gbe Olohun tobi nibi ojo kookan yio si maa lo ko si nii duro nibe.

 Adua ti eeyan ma nse ti eeyan ba ri nkan eemo tabi nkan idunnu.

"Subhaanallooh"  Mimo fun Olohun

"Alloohu Akbar"  Olohun tobi.

 Ohun ti eniti alamori ti o dun mo on ba de ba a maa se.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – je eniti o ma nfi ori kanle nigbati alamori ti o dun ma an ba de ba a leniti o fi ndupe fun Olohun ti ola Re ga.

 Ohun ti eniti o ba kefin irora kan ni ara re maa se ati ohun ti o maa so.

Gbe owo re le ibiti o nro e ninu ara re ki o wa so pe: Bismillaah ni eemeta, ki o tun wa so ni eemeje pe: Ahuudhu bil laahi wa qud'rotihi min sharri ma ajidu wa uhaadhir. Mo fi Olohun wa iso ati ikapa re kuro nibi ohun mo nri ati ohun ti mo nsora fun.

 Adua ti eniti o ba nberu ki aburu ma kan nkan pelu oju re ma nse.

Ti enikookan yi ba ri ohun ti o wu u ni ara omoya re, tabi ni odo ara re, tabi nibi dukia re ki o ya se adua alubarika si i toripe ojukoju nbe niti paapa.

 Ohun ti a ma nso nibi ipayinkeke

Laa ilaaha illal laah!

 Ohun ti eniti o fe pa eran tabi ti o fe gun eran ma nso.

Pelu oruko Olohun atipe Olohun tobi, Ire Olohun odo Re lo ti wa tire naa si nii se, Ire Olohun, tewo gba a ni owo mi.

 Ohun ti eeyan maa nso lati da ete awon alagidi ashaitaani pada.

Mo wa isora pelu awon gbolohunOlohun ti o pe ti o se wipe ko si enirere kan tabi eniibu kan ti o tayo re: kuro nibi aburu ohun ti O da, ati ohun ti O so di bibe, ati nibi aburu ohun ti nsokale lati sanmo, ati nibi aburu ohun ti ngun sanmo lo, ati nibi aburo ohun ti o da sile, ati nibi aburu ohun ti njade lati inu re, ati nibi aburu fitina oru ati osan, ati nibi aburu gbogbo awon isele ti nsele loru yato si isele daada Ire Oba Ajokeaye.

 Wiwa aforijin ati tituuba.

Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Mo fi Olohun bura dajudaju emi maa nwa aforijin Olohun, mo si maa ntuuba losi odo Re ni ojoojumo ni ohun ti o ju igba aadorin lo.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Mo pe eyin eeyan e tuuba losi odo Olohun toripe dajudaju emi maa ntuuba lo si odo Re ni ojoojumo ni igba ogorun.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Eniti o ba so pe: "Astagfirulloohal aziimal ladhii laa ilaaha illaa uwal ayyul qoyyuum wa atuubu ilaihi", Olohun yio fi ori ese re jin in koda ki o sa kuro loju ogun.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Asiko ti Olohun ma nsun mo eru Re ju ni aarin gbungbun oru ti o kehin, ti o ba wa ni ikapa lati maa be ninu eniti yio maa ranti Olohun ni asiko yen yan maa be nibe.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Asiko ti eru ma nsunmo Olohun Oba re julo ni igbati o je eniti o fi ori kanle ki e ya po ni adua.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Dajudaju a maa nbo ori okan mi, atipe dajudaju emi ma nwa aforijin Olohun ni igba ogorun ni ojoojumo.

Mo fi Olohun bura dajudaju emi maa nwa aforijin Olohun, mo si maa ntuuba losi odo Re ni ojoojumo ni ohun ti o ju igba aadorin lo.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Mo pe eyin eeyan e tuuba losi odo Olohun toripe dajudaju emi maa ntuuba lo si odo Re ni ojoojumo ni igba ogorun.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Eniti o ba so pe: "Astagfirulloohal aziimal ladhii laa ilaaha illaa uwal ayyul qoyyuum wa atuubu ilaihi", Olohun yio fi ori ese re jin in koda ki o sa kuro loju ogun.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Asiko ti Olohun ma nsun mo eru Re ju ni aarin gbungbun oru ti o kehin, ti o ba wa ni ikapa lati maa be ninu eniti yio maa ranti Olohun ni asiko yen yan maa be nibe.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Asiko ti eru ma nsunmo Olohun Oba re julo ni igbati o je eniti o fi ori kanle ki e ya po ni adua.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Dajudaju a maa nbo ori okan mi, atipe dajudaju emi ma nwa aforijin Olohun ni igba ogorun ni ojoojumo.

 Ola ti nbe fun mima se afomo ati mimaa fi eyin fun Olohun ati mimaa se laa ilaha illal laah ati mimaa gbe Olohun tobi.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Eniti o ba so pe: "Subhaanalloohi wa bi amdihi" ni igba ogorun ni ojumo kan won a pa gbogbo ese re re koda ko se deede igbi okun.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Eniti o ba so pe: "Laa ilaaha illaal laahu wahdahu laa shariika lahu, lahul mulku, wa lahul amdu, wa uwa ala kulli shaihin qodiir" ni eemewa, o da gegebi eniti o tu okun lorun emi meerin ninu omo Anabi Ismaahiil.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Gbolohun meji kan nbe won fuye lori ahon, won wuwo ninu osuwon, won je ohun ti Oba Ar-Rahmaan nife si: "Subhaanalloohi wa bi amdihi subhaanalloohil adhiim".O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Ki n maa wi so pe: "Subhaanalloohu, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha ilaal laahu, wallaahu akbar" o je nkan ti mo nife si ju gbogbo nkan ti oorun nyo le lori lo.O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Nje enikookan yin le kagara lati ko oro daada egberun ni ojoojumo.Ni onibeere kan ba bi i leere ninu awon ti won joko ti i : bawo ni enikookan wa sele ko oro daada egberun?O sope: yio ma se afomo ni nigba ogorun, won o si ko daada egberun fun un tabi ki won pa ese egberun re fun un.

Eniti o ba so pe: "Subhaanalloohi wa bi amdihi" ni igba ogorun ni ojumo kan won a pa gbogbo ese re re koda ko se deede igbi okun.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Eniti o ba so pe: "Laa ilaaha illaal laahu wahdahu laa shariika lahu, lahul mulku, wa lahul amdu, wa uwa ala kulli shaihin qodiir" ni eemewa, o da gegebi eniti o tu okun lorun emi meerin ninu omo Anabi Ismaahiil.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Gbolohun meji kan nbe won fuye lori ahon, won wuwo ninu osuwon, won je ohun ti Oba Ar-Rahmaan nife si: "Subhaanalloohi wa bi amdihi subhaanalloohil adhiim".

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Ki n maa wi so pe: "Subhaanalloohu, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha ilaal laahu, wallaahu akbar" o je nkan ti mo nife si ju gbogbo nkan ti oorun nyo le lori lo.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Nje enikookan yin le kagara lati ko oro daada egberun ni ojoojumo.

Ni onibeere kan ba bi i leere ninu awon ti won joko ti i : bawo ni enikookan wa sele ko oro daada egberun?

O sope: yio ma se afomo ni nigba ogorun, won o si ko daada egberun fun un tabi ki won pa ese egberun re fun un.

Eniti o ba so pe: "Subhaanalloohil adhiim wa bi amdihi" won o gbin igi ope kan fun un ninu aljannah.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Ire Abdullaah omo Qois! O o wa je ki ntoka re si pepe oro kan ninu awon pepe oro aljannah? Mo si so pe: mo fe bee ire ojise Olohun, o so pe: so pe: : "La aola wala quwwata illa billah"O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:Gbolohun ti Olohun Oba nife si ju meerin ni: "Subhaanalloohu, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha illaal laah, wal loohu akbar", ko si inira nibi ki o bere pelu eyikeyi ti o ba wu o ninu e.

Ire Abdullaah omo Qois! O o wa je ki ntoka re si pepe oro kan ninu awon pepe oro aljannah? Mo si so pe: mo fe bee ire ojise Olohun, o so pe: so pe: : "La aola wala quwwata illa billah"

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe:

Gbolohun ti Olohun Oba nife si ju meerin ni: "Subhaanalloohu, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha illaal laah, wal loohu akbar", ko si inira nibi ki o bere pelu eyikeyi ti o ba wu o ninu e.

Larubawa oko kan wa ba ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o si so pe: ko mi ni gbolohun kan ti maa ma wi i. o so pe: so pe: "Laa ilaaha illal laah wahdahu la shariika lahu, Allaahu akbar kabiira, wal amdu lillaahi kathiira, subhaanalloohi robbil aalamiin, laa aola wa laa quwwata illa bil laahil aziizil akiim, o so pe: gbogbo eleyi ti Oba mi ni, ewo wa ni ti temi? O so pe: so pe: "Allaahummo igfirli, war'amni, wahdini, war'zukni.

Ti enikan ba gba Islaam, anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – maa ko o ni irun kiki, leyinna yio tun wa pa a lase ki o maa se adua pelu awon gbolohun wonyi:Ire Olohun fi ori jin mi, si kemi, si fimi mona, si se alaafia fun mi, si pese ijeemu fun mi.

Ire Olohun fi ori jin mi, si kemi, si fimi mona, si se alaafia fun mi, si pese ijeemu fun mi.

Dajudaju eyiti o fi nlola ju ninu adua ni: Alhamdulillaah, atipe eyiti o fi nlola ju ninu iranti ni: Laa ilaaha illaal laah.

Nkan ti nje Al-Baaqiyaatus-Soolihaatu ni: "Subhaanallooh, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha illaal laahu, walloohu akbar, wala aola wala quwwata illaa billaah".

 Bawo ni anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – se ma nse afomo?

Egbawa yi wa lati odo Abdullaah omo Abbaas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe:Mo ri anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ti nse afomo pelu owo re.Ninu afikun kan: pelu owo otun re.

Mo ri anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ti nse afomo pelu owo re.

Ninu afikun kan: pelu owo otun re.

 Ninu awon oniranran daada ati awon eko ti o kun.

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Ti ile ba ti nsu – tabi ti e ba ti di irole – ki e ya ko awon omo yin ro nibi ki won maa jade, toripe dajudaju awon esu ma nfonka orile nigbanaa, ti wakati kan ba ti wa lo ninu oru, e le wa tu won sile, ki e si ti awon ilekun yin, ki e si se iranti oruko Olohun; toripe dajudaju esu o lee si ilekun kan ti won ti ti, ki e si tun de ori awon kete omi yin, ki e si se iranti oruko Olohun, ki e si bo awon igba yin, ki e si se iranti oruko Olohun, ki baa je wipe ki e kan fi nkankan le e ni ori, ki e si pa awon atupa yin.

Ti ile ba ti nsu – tabi ti e ba ti di irole – ki e ya ko awon omo yin ro nibi ki won maa jade, toripe dajudaju awon esu ma nfonka orile nigbanaa, ti wakati kan ba ti wa lo ninu oru, e le wa tu won sile, ki e si ti awon ilekun yin, ki e si se iranti oruko Olohun; toripe dajudaju esu o lee si ilekun kan ti won ti ti, ki e si tun de ori awon kete omi yin, ki e si se iranti oruko Olohun, ki e si bo awon igba yin, ki e si se iranti oruko Olohun, ki baa je wipe ki e kan fi nkankan le e ni ori, ki e si pa awon atupa yin.

Ki Olohun bawa se ike ati alubarika fun anabi wa Muhammad, ati awon ara ile re ati awon saabe re lapapo.