Awọn ipilẹ mẹta ẹsin islam ati awọn ẹri wọn (⮫)


الأصول الثلاثة وأدلتها

 Awọn ipilẹ mẹta ẹsin islam ati awọn  ẹri wọn

بسم الله الرحمن الرحيم

Mo bẹrẹ ni orukọ Ọlọhun Ọba Alaanujulọ Aladipele-ẹsan-rere

 [IPILẸ ALAKỌKỌ: MIMỌ ỌLỌHUN ỌBA]

Mọ daju “Ọlọhun ki O kẹ ọ” pe ọranyan l’o jẹ lori wa pe ki a kọ nipa awọn ohun ayẹwo mẹrin kan:-

Alakọkọ ni imọ; Oun ni pe ki a mọ Ọlọhun, ki a si mọ anabi Rẹ, ki a si mọ nipa ẹsin Islam pẹlu awọn ẹri rẹ.

Ẹlẹẹkeji ni ki a maa fi imọ naa sisẹ.

Ẹlẹẹkẹta ni ipepe lọ sidi rẹ.

Ẹlẹẹkẹrin ni sise suuru lori inira ti n bẹ ninu rẹ.

Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} والعصر . إن الإنسان لفي خسر. إلا الذين آمنوا وعملوا الصالحات وتواصوا بالحق وتواصوا بالصبر {.

« Mo fi igba bura* Dajudaju awọn eniyan n bẹ ninu ofo* Afi awọn ti wọn ni igbagbọ-ododo, ti wọn si n se daadaa, ti wọn si n gba ara wọn niyanju lati maa sọ otitọ, ti wọn si n gba ara wọn niyanju lati maa se suuru ».

Imam Shaafi’i “ki Ọlọhun t’O ga O kẹ ẹ” sọ pe: « Iba se pe Ọlọhun kò sọ awijare kankan kalẹ le awọn ẹda Rẹ lori yatọ si Suura yii nikan ni, dajudaju ko ba to wọn ».

Imam Bukhari naa “ki Ọlọhun t’O ga O kẹ ẹ” sọ pe: Akọle ẹkọ kan -pe-: Ọranyan ni ki imọ o siwaju ọrọ ati isẹ. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} فاعلم أنه لا إله إلا الله واستغفر لذنبك {. [سورة محمد، آية: (19)].

« Nitori naa mọ daju pe kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ki o si maa tọrọ aforijin ẹsẹ rẹ …» . [Qur’aan, Suuratu Muhammad: 19]. Imọ l’O fi bẹrẹ siwaju ọrọ ati isẹ.

 [Awọn nnkan mẹta ti o jẹ ọranyan pe ki a kọ nipa wọn]

Mọ daju “Ọlọhun ki O kẹ ọ” pe ọranyan l’o jẹ lori gbogbo Musulumi-kunrin ati Musulumi-binrin pe ki wọn o kọ nipa awọn nnkan mẹta wọnyi, ki wọn o si maa fi wọn sisẹ:

Akọkọ ni pe Ọlọhun Ọba da wa, O si rọ wa lọrọ, ati pe kò fi wa silẹ lasan, sugbọn kaka bẹẹ nse l’O ran ojisẹ kan si wa, ẹnikẹni t’o ba tẹle ojisẹ yii yoo wọ Al-Janna -ọgba idẹra-, ẹniyowu t’o ba si kọ tiẹ yoo wọ ina. Eri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إنا أرسلنا إليكم رسولا شاهداً عليكم كما أرسلنا إلى فرعون رسولاً. فعصى فرعون الرسول فأخذناه أخذا وبيلاً {. [سورة المزمل، (15، 16)].

« Dajudaju Awa ti ran ojisẹ kan si yin ti o jẹ olujẹri le yin lori, gẹgẹ bi A ti se ran ojisẹ kan si Firiauna. Sugbọn Firiauna kọ ti ojisẹ naa, nitori naa A fi iya jẹ ẹ ni iya ti o le ». [Qur’aan, Muzzamil, 15,16].

Ẹẹkeji ni pe Ọlọhun Ọba kò ni I yọnu si pe ki ẹnikan o fi nnkan kan se orogun fun Un ninu ijọsin rara, yala -nnkan naa jẹ- malaika kan ti O se l’ẹni t’o sunmọ Oun ni o, tabi anabi kan ti O ran nisẹ; ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وأن المساجد لله فلا تدعوا مع الله أحداً {. [سورة الجن، (18)].

« Dajudaju ti Ọlọhun ni awọn Masalasi “aye ikirun” i se, nitori naa ẹ kò gbọdọ pe ẹnikan kan pẹlu Ọlọhun Ọba ». [Qur’aan: Al’jinn: 18].

Ẹẹkẹta ni pe kò tọ rara fun ẹni t’o n tẹle ti ojisẹ yii, ti o si n se Ọlọhun laaso pe ki o mu ẹnikan ti o tako ti Ọlọhun ati ti ojisẹ Rẹ ni ọrẹ matimati, koda ki oluwaarẹ o jẹ mọlẹbi ti o sunmọ eniyan ju; ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} لا تجد قوما يؤمنون بالله واليوم الآخر يوادون من حاد الله ورسوله ولو كانوا آباءهم أو أبناءهم أو إخوانهم أو عشيرتهم، أولئك كتب في قلوبهم الإيمان وأيدهم بروح منه، ويدخلهم جنات تجري من تحتها الأنهار خالدين فيها، رضي الله عنهم ورضوا عنه، أولئك حزب الله، ألآ إن حزب الله هم المفلحون{. [سورة المجادلة، (22)].

« Iwọ kò ni i ri awọn eniyan kan ti wọn gba Ọlọhun ati ọjọ ikẹyin gbọ ti wọn yoo maa nifẹ si awọn ti wọn tako Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ, koda k’o se pe awọn obi wọn ni wọn i se, tabi awọn ọmọ wọn, tabi awọn ọmọ-iya wọn, tabi awọn ibatan wọn, awọn wọnyi ni Ọlọhun ti fi igbagbọ-ododo rinlẹ sinu ọkan wọn, O si fi ẹmi kan lati ọdọ Rẹ ran wọn lọwọ, yoo mu wọn wọ ọgba-idẹra eyi ti awọn odo n san labẹ rẹ, ibẹ ni wọn yoo maa bẹ laelae, Ọlọhun yọnu si wọn, awọn naa si yọnu si I, awọn wọnyi ni ijọ Ọlọhun, tẹti ki o gbọ, dajudaju ijọ Ọlọhun ni yoo jere » . [Qur’aan, Mujaadalah, 22].

Mọ daju “Ọlọhun ki O fi ọ mọna lọ sibi titẹle tiẸ” pe ẹsin Islam ti i se ẹsin ti o tọna geerege, eyi ti i se ẹsin Anabi Ibrahim ni ki o maa sin Ọlọhun nikan soso pẹlu sise afọmọ ijọsin naa fun Un, eleyii ni Ọlọhun fi pa gbogbo awọn eniyan lasẹ, ati pe oun gan-an ni ohun ti O titori rẹ da wọn, gẹgẹ bi Ọba-giga Naa ti sọ pe:

} وما خلقت الجن والإنس إلا ليعبدون {. [سورة الذاريات، (56)].

« N kò sẹda awọn alujannu ati awọn eniyan afi nitori ki wọn o le baa maa jọsin fun Mi ». [Qur’aan, Adzaariyaat, 56].

Itumọ: « Ki wọn o le baa maa jọsin fun Mi » ni pe ki wọn o se Mi ni ọkan soso.

Eyi t’o tobi ju ninu ohun ti Ọlọhun fi pa ni lasẹ ni TAWHEED, eyi ti i se sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu gbogbo ijọsin.

Bẹẹ ni eyi t’o tobi ju ninu ohun ti O kọ fun ni lati se ni SHIR’K -ẹbọ-, eyi ti i se pipe ẹlomiran pẹlu Rẹ. Ẹri rẹ ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} واعبدوا الله ولا تشركوا به شيئاً {. [سورة النساء (36)].

« Ẹ maa jọsin fun Ọlọhun, ẹ kò si gbọdọ fi nnkan kan se orogun fun Un » . [Qur’aan, Al-Nisaa’i 36].

Ti wọn ba bi ọ leere pe: Ki ni awọn ipilẹ mẹta ti o se pe ọranyan l’o jẹ lori eniyan lati mọ wọn?.

F’esi pe: Ki ẹru o mọ Oluwa rẹ, ati ẹsin rẹ -Islam-, ati anabi rẹ Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Ti wọn ba bi ọ leere pe: Ta ni Oluwa rẹ?; dahun pe: Ọlọhun Ọba -Allahu- ni Oluwa mi, Ẹni ti N tọju mi ati gbogbo awọn ẹda lapapọ pẹlu idẹra Rẹ, Oun si ni mo n jọsin fun, n kò ni ẹlomiran ti mo n jọsin fun yatọ si I. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} الحمد لله رب العالمين {. [سورة الفاتحة (2)].

« Gbogbo ẹyin ti Ọlọhun ni i se, Oluwa “Olutọju” gbogbo ẹda ». [Qur’aan, Al-Fatihah: 2]. Gbogbo ohun ti o yatọ si Ọlọhun, ẹda Ọlọhun ni wọn i se, bẹẹ ni ọkan ninu awọn ẹda Ọlọhun naa ni mi.

Ti wọn ba wa bi ọ leere pe: Ki ni ohun ti o fi mọ Oluwa rẹ?; sọ pe: -Mo mọ Ọn- pẹlu awọn ami Rẹ, ati awọn ẹda Rẹ, ati pe ninu awọn ami Rẹ wọnyi ni: Ọsan, ati oru, oorun, ati osupa, bẹẹ ni ninu awọn ẹda Rẹ ni: Awọn sanma mejeeje, ati awọn ilẹ mejeeje, ati awọn ti wọn n bẹ ninu wọn, ati awọn ti wọn n bẹ ni aarin mejeeji, ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} ومن آياته الليل والنهار والشمس والقمر لا تسجدوا للشمس ولا للقمر واسجدوا لله الذي خلقهن إن كنتم إياه تعبدون {. [سورة فصلت (37)].

« Ati pe ninu awọn ami Rẹ ni oru ati ọsan, oorun ati osupa wa, ẹ kò gbọdọ fi ori kanlẹ fun oorun tabi osupa rara, Ọlọhun ti O da wọn ni ki ẹ maa fi ori kanlẹ fun, b’o ba jẹ pe Oun nikan ni ẹ n sin ». [Qur’aan, Al-Fusilat: 37].

Bakan naa ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إن ربكم الله الذي خلق السماوات والأرض في ستة أيام ثم استوى على العرش يغشي الليل النهار يطلبه حثيثا والشمس والقمر والنجوم مسخرات بأمره ألآ له الخلق والأمر تبارك الله رب العالمين {. [سورة الأعراف (54)].

« Dajudaju Oluwa yin ni Ọlọhun ti O da awọn sanma ati ilẹ laarin ọjọ mẹfa, lẹyin naa O wa se dọgba lori aga ọla Rẹ “Al-Arsh”, O N fi oru bo ọsan mọlẹ, o si n tẹle e laiduro, o si tẹ oorun ati osupa ati awọn irawọ lori ba pẹlu asẹ Rẹ, tẹti ki o gbọ, Oun l’O ni dida ẹda ati asẹ, ibukun ni fun Ọlọhun Oluwa gbogbo ẹda ». [Qur’aan, Al-A’araaf: 54].

] الرب [ Ar-Rab ni: Ẹni-ajọsin-fun. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} يا أيها الناس اعبدوا ربكم الذي خلقكم والذين من قبلكم لعلكم تتقون. الذي جعل لكم الأرض فراشا والسماء بناء وأنزل من السماء ماء فأخرج به من الثمرات رزقا لكم فلا تجعلوا لله أندادا وأنتم تعلمون{. [سورة البقرة. (22،23)].

« Ẹyin eniyan ẹ maa sin Oluwa yin ti O da yin ati awọn ti wọn siwaju yin, ki ẹ le baa jẹ ẹni ti yoo maa paya Rẹ. Ẹni ti O se ilẹ fun yin ni itẹ, ti O si se sanma fun yin ni aja, O n rọ ojo fun yin lati sanma, O si n fi omi naa mu awọn irugbin jade, -O se e- ni ipese fun yin, nitori naa ẹ kò gbọdọ wa awọn orogun fun Ọlọhun, nigba ti ẹyin naa mọ -pe kò ni orogun kankan- ». [Qur’aan, Baqarah: 22, 23].

Ibn Khatheer “ki Ọlọhun t’O ga O kẹ ẹ” sọ pe: « Ẹlẹda awọn nnkan wọnyi l’O lẹtọ si ijọsin ».

Awọn orisirisi ijọsin ti Ọlọhun fi pa ni lasẹ gẹgẹ bi Islam -igbafa fun Ọlọhun-, ati Iimaan -igbagbọ-ododo-, ati lh’saan -daadaa sise-; bakan naa sise adua, ati ibẹru Ọlọhun, ati irankan oore Rẹ, ati gbigbẹkẹle E, ati sise ojukokoro idẹra Rẹ, ati ibẹru iya Rẹ, ati itẹriba fun Un, ati ipaya Rẹ, ati isẹripada si ọdọ Rẹ -ironupiwada-, ati titọrọ iranlọwọ, ati wiwa isadi, ati kike gbajare lọ si ọdọ Rẹ, ati iduran, ati ileri, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn orisirisi ijọsin ti Ọlọhun fi pa ni lasẹ, ti Ọlọhun ni gbogbo wọn i se. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وأن المساجد لله فلا تدعوا مع الله أحداً {. [سورة الجن، (18)].

« Dajudaju ti Ọlọhun ni awọn Masalasi “aye ikirun” i se, nitori naa ẹ kò gbọdọ maa pe ẹnikan kan pẹlu Ọlọhun ». [Qur’aan, Al’Jinn: 18]. Tori naa ẹnikẹni t’o ba sẹri nnkan kan ninu awọn ijọsin wọnyi si ọdọ ẹlomiran yatọ si Ọlọhun, onitọun di ọsẹbọ alaigbagbọ. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun ti O ga t’o sọ pe:

} ومن يدع مع الله إلها آخر لا برهان له به فإنما حسابه عند ربه إنه لا يفلح الكافرون {. [سورة المؤمنون، (117)].

« Ẹnikẹni ti o ba n pe ọlọhun miiran pẹlu Ọlọhun Ọba, kò si awijare kan ti o le ri mu wa nipa rẹ, tori naa ọdọ Oluwa rẹ ni isiro rẹ wa, dajudaju awọn alaigbagbọ kò ni i sori-ire ». [Qur’aan, Al-Mu’minuna: 117].

O tun wa ninu ẹgbawa-ọrọ -lati ọdọ Anabi- pe:

(( الدعاء مخ العبادة )).

« Adua ni paapaa ijọsin ». Ẹri eleyii n bẹ ninu ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وقال ربكم ادعوني أستجب لكم إن الذين يستكبرون عن عبادتي سيدخلون جهنم داخرين {. [سورة غافر، (60)].

« Ati pe Oluwa yin sọ pe: Ẹ maa pe Mi, N O maa da yin lohun, dajudaju awọn ti wọn n se igberaga sẹri kuro nibi ijọsin fun Mi, laipẹ wọn yoo wọ ina Jahannama ni ẹni yẹpẹrẹ ». [Qur’aan, Al’Gaafir: 60].

Ẹri ibẹru Ọlọhun ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} فلا تخافوهم وخافون إن كنتم مؤمنين {. [سورة آل عمران (175)].

« Tori naa ẹ ma se bẹru wọn rara, Emi ni ki ẹ maa bẹru, ti ẹ ba jẹ olugbagbọ-ododo ». [Qur’aan, Al-Imraan: 175].

Ẹri irankan -oore Ọlọhun- ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} فمن كان يرجو لقاء ربه فليعمل عملاً صالحاً ولا يشرك بعبادة ربه أحداً {. [سورة الكهف، (110)].

« Nitori naa ẹnikẹni ti ba n rankan atipade Oluwa rẹ, ki o maa se isẹ rere, ki o si ma se fi ẹnikan se orogun pẹlu Oluwa rẹ ninu ijọsin ». [Qur’aan, Al-kah’f: 110].

Ẹri gbigbẹkẹle Ọlọhun Ọba ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وعلى الله فتوكلوا إن كنتم مؤمنين {. [سورة المائدة، (23)].

« Ọlọhun nikan ni ki ẹ gbẹkẹle, ti ẹ ba jẹ olugbagbọ-ododo ». [Qur’aan, Al-Maa’idah: 23].

Ati ọrọ Rẹ t’o ni:

} ومن يتوكل على الله فهو حسبه {. [سورة الطلاق، (3)].

« Ati pe ẹnikẹni t’o ba gbẹkẹle Ọlọhun, Oun yoo to o … ». [Qur’aan, Al-Talaaq: 3].

Ẹri lori sise ojukokoro ikẹ Ọlọhun, ati ti ibẹru iya Rẹ, ati ti itẹriba fun Un ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إنهم كانوا يسارعون في الخيرات ويدعوننا رغباً ورهباً وكانوا لنا خاشعين {. [سورة الأنبياء، (90)].

« Dajudaju wọn a maa yara si awọn rere -ni sise-, ti wọn n si maa pe Wa, ni ti sise ojukokoro ati ibẹru, wọn si jẹ olutẹriba fun Wa ». [Qur’aan, Al-Anbiyaa’i: 90].

Ẹri lori ipaya Ọlọhun Ọba ni ọrọ Ọlọhun t’o sọ pe:

} فلا تخشوهم واخشوني {. [سورة البقرة، (150)].

« Nitori naa ẹ ma se paya wọn, Emi ni ki ẹ maa paya». [Qur’aan, Al-Baqarah: 150].

Ẹri isẹri-pada si ọdọ Ọlọhun ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وأنيبوا إلى ربكم وأسلموا له {. [سورة الزمر، (54)].

« Ẹ sẹri pada si ọdọ Oluwa yin, ki ẹ si gbafa fun Un». [Qur’aan, Al’Zumar: 54].

Ẹri nipa wiwa iranlọwọ lọdọ Ọlọhun ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إياك نعبد وإياك نستعين {. [سورة الفاتحة، (5)].

« Iwọ nikan ni a o maa sin, ọdọ Rẹ nikan ni a o si ti maa wa iranlọwọ ». [Qur’aan, Al’Fatihah: 5].

Bakan naa o wa ninu ẹgbawa-ọrọ -lati ọdọ Anabi- pe:

(( إذا استعنت فاستعن بالله )).

« Nigba ti o ba n wa iranlọwọ, wa iranlọwọ ni ọdọ Ọlọhun ».

Ẹri nipa sisadi Ọlọhun ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} قل أعوذ برب الناس. ملك الناس {. [سورة الناس (1،2)].

« Sọ pe: Mo sadi Oluwa awọn eniyan. Ọba awọn eniyan ». [Qur’aan, An’Naas: 1,2].

Ẹri lori kike gbajare lọ si ọdọ Ọlọhun ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إذ تستغيثون ربكم فاستجاب لكم {. [سورة الأنفال، (9)].

« Nigba ti ẹ ke gbajare lọ si ọdọ Oluwa yin, O si da yin lohun ». [Qur’aan, Al-Anfaal: 9].

Ẹri lori didu ẹran ni ọrọ Ọlọhun t’O ga ti o sọ pe:

} قل إن صلاتي ونسكي ومحياي ومماتي لله رب العالمين. لا شريك له وبذلك أمرت وأنا أول المسلميْن {. [سـورة الأنعـــام، (162،163)].

« Sọ pe: Dajudaju irun mi, ati iparan-jọsin mi, isẹmi ati iku mi, ti Ọlọhun Ọluwa gbogbo ẹda ni wọn i se. Kò si orogun kankan fun Un, eyi ni ohun ti a fi pa mi lasẹ, tori naa emi ni akọkọ awọn olugbafa fun Ọlọhun ». [Qur’aan, Al-An’aam, 162,163].

O tun wa ninu Sunna Anabi pe:

(( لعن الله من ذبح لغير الله )).

« Ọlọhun Ọba sẹbi le ẹnikẹni ti o duran fun nnkan kan miiran yatọ si Ọlọhun ».

Ẹri ileri ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} يوفون بالنذر ويخافون يوما كان شره مستطيراً {. [سورة الإنسان، (7)].

« Wọn a maa mu ileri wọn sẹ, wọn si n bẹru ọjọ kan ti aburu rẹ jẹ ohun ti yoo maa fo pẹrẹpẹrẹ ». [Qur’aan, Al-Insaan: 7].

 IPILẸ KEJI

 MIMỌ NIPA ẸSIN ISLAM PẸLU AWỌN ẸRI RẸ

Islam ni ijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun nipa sise E ni ọkan soso ninu ijọsin, ati igbafa fun Un pẹlu titẹle asẹ Rẹ, ati imọpa-mọsẹ kuro ninu ẹbọ sise. Ipele mẹta si ni i: [ISLAM], ati [IIMAAN], ati [IH’SAAN], bẹẹ ni ọkọọkan ninu awọn ipele mẹtẹẹta wọnyi l’o ni awọn origun tiẹ.

 IPELE AKỌKỌ: ISLAM

Awọn origun Islam jẹ marun un:

1- Ijẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ati pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i se.

2- Gigbe irun duro.

3- Yiyọ Zaka.

4- Gbigba aawẹ.

5- Lilọ se Haji ni ile Ọlọhun alapọnle.

Ẹri ijẹri ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} شهد الله أنه لا إله إلا هو والملائكة وأولوا العلم قائما بالقسط لا إله إلا هو العزيز الحكيم {. [سورة آل عمران، (18)].

« Ọlọhun jẹri pe kò si ọba kan t’o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Oun, bakan naa awọn Malaika ati awọn oni-mimọ -naa jẹri bẹẹ-, Ọba Oluse-dọgba, kò si ọba kan t’o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si I, Ọba Alagbara Ọlọgbọn ». [Qur’aan, Al-Im’raan: 18]. Itumọ rẹ si ni pe: Kò si ohun ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Olohun nikan soso; tori pe [LAA ILAAHA] “kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun”, o n le gbogbo nnkan miiran ti wọn n sin lẹyin Ọlọhun Ọba jinna, sugbọn [ILLA -L-LAH] “yatọ si Ọlọhun -Allahu-” oun n fi ẹsẹ gbogbo ijọsin rinlẹ fun Ọlọhun nikan soso, kò si orogun kan fun Un ninu ijọsin, gẹgẹ bi kò ti se ni orogun kankan ninu ijọba Rẹ, ati pe alaye rẹ ti yoo se afihan rẹ yekeyeke ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وإذ قال إبراهيم لأبيه وقومه إنني برآء مما تعبدون. إلا الذي فطرني فإنه سيهدين. وجعلها كلمة باقية في عقبه لعلهم يرجعون{. [سورة الزخرف، (26-28)].

« Nigba ti Ibrahim sọ fun baba rẹ ati awọn eniyan rẹ pe: Dajudaju emi kò lọwọ ninu ohun ti ẹ n sin. Afi Ẹni t’O pilẹ da mi, dajudaju Oun ni yoo fi ọna mọ mi. Ati pe o se e ni gbolohun kan ti yoo sẹku lẹyin rẹ fun awọn arọmọdọmọ rẹ; ki wọn o le baa sẹri pada ». [Qur’aan, Al’Zukh’ruf: 26-28].

Ati ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} قل يا أهل الكتاب تعالوا إلى كلمة سواء بيننا وبينكم أن لا نعبد إلا الله ولا نشرك به شيئا ولا يتخذ بعضنا بعضاً أربابا من دون الله فإن تولوا فقولوا اشهدوا بأنا مسلمون {. [سورة آل عمران، (64)].

« Sọ pe: Ẹyin oni-tira -Yahudi ati Nasaara- ẹ wa sibi gbolohun kan ti o dọgba laarin wa ati laarin yin pe: A kò gbọdọ jọsin fun nnkan miiran yatọ si Ọlọhun, a kò si gbọdọ fi nnkan kan se orogun fun Un rara, ati pe apa kan wa kò gbọdọ mu apa keji ni awọn oluwa lẹyin Ọlọhun, sugbọn ti wọn ba pẹyinda -ti wọn lodi si eleyii-, ẹ sọ fun wọn pe: Ẹ jẹri pe Musulumi ni a wa i se ». [Qur’aan, Al-Im’raan: 64].

Ẹri lori ijẹri pe ojisẹ Ọlọhun ni Muhammad ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} لقد جاءكم رسول من أنفسكم عزيز عليه ما عنتم حريص عليكم بالمؤمنين رؤوف رحيم {. سورة التوبة، (128).

« Dajudaju ojisẹ kan ti wa ba yin lati inu yin, ohun ti yoo ni yin lara jẹ ohun ti i maa n soro fun un -lati fara da-, o si jẹ oluse-ojukokoro lori yin -nipa atifi yin mọna ti o tọ-, o si jẹ alaanu onikẹ fun awọn olugbagbọ-ododo ». [Qur’aan, Al-Tawbah: 128].

Itumọ ijẹri pe ojisẹ Ọlọhun ni Muhammad ni: Titẹle asẹ rẹ, ati gbigba a gbọ nipa awọn iroyin ti o fun wa, ati jijinna si awọn ohun ti o kọ fun ni lati se t’o si ke mọ ni nipa rẹ, ki a si ma se sin Ọlọhun pẹlu nnkan kan yatọ si ohun ti o se lofin fun wa.

Ẹri lori irun ati Zaka ati alaye Tawheed ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وما أمروا إلا ليعبدوا الله مخلصين له الدين حنفاء ويقيموا الصلاة ويؤتوا الزكاة وذلك دين القيمة {. [سورة البينة، (5)].

« A kò fi nnkan kan pa wọn lasẹ ju pe ki wọn o maa jọsin fun Ọlọhun lọ, ki wọn o si maa se afọmọ ẹsin naa fun Un, ki wọn o si jẹ ẹni t’o fi ọna ti kò tọ silẹ, ki wọn o si maa gbe irun duro, ki wọn o si maa yọ Zaka, eleyii ni ẹsin ti o duro dọgba ». [Qur’aan, Al-Bayyinah: 5].

Ẹri aawẹ gbigba ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} يا أيها الذين آمنوا كتب عليكم الصيام كما كتب على الذين من قبلكم لعلكم تتقون {. [سورة البقرة، (183)].

« Ẹyin olugbagbọ-ododo, a se aawẹ gbigba ni ọranyan le yin lori gẹgẹ bi a ti se se e ni ọranyan lori awọn ti wọn siwaju yin, ki ẹ le baa maa paya Ọlọhun». [Qur’aan, Al-Baqarah: [183].

Ẹri ti Haji ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} ولله على الناس حج البيت من استطاع إليه سبيلا ومن كفر فإن الله غني عن العالمين {. [سورة آل عمران، (97)].

« Ọlọhun se irin-ajo Haji lọ si ile Rẹ ni ọranyan lori awọn eniyan, -fun- ẹni t’o ba ni agbara lati rin irin-ajo lọ sibẹ; ẹnikẹni t’o ba wa se aigbagbọ, dajudaju Ọlọhun rọrọ ju gbogbo ẹda lọ ». [Suuratu Aal-Imraan: 97].

 IPELE KEJI: [IIMAAN]

Iimaan “igbagbọ-ododo” pẹka si ọna mọkanlelaadọrin, ati pe eyi ti o ga ju ninu awọn ẹka rẹ wọnyi ni: LAA ILAAHA ILLA -L-LAH “kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun”, eyi ti o si kere ju ninu wọn ni: Mimu ohun ti o le pa ni lara kuro loju-ọna, bẹẹ ni ẹka kan ni itiju i se ninu awọn ẹka igbagbọ-ododo.

Mẹfa si ni awọn opo tiẹ:

1- Ki o gba Ọlọhun gbọ.

2- Ati awọn Malaika Rẹ.

3- Ati awọn tira Rẹ.

4- Ati awọn ojisẹ Rẹ.

5- Ati ọjọ ikẹyin.

6- Ati akọsilẹ -kadara-, oore rẹ, ati aburu rẹ.

Ẹri lori awọn opo mẹfẹẹfa wọnyi ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} ليس البر أن تولوا وجوهكم قبل المشرق والمغرب ولكن البر من آمن بالله واليوم الآخر والملائكة والكتاب والنبيين {. [سورة البقرة، (177)].

« Ki i se daadaa sise ni ki ẹ maa yi oju yin si ibula-oorun tabi ibuwọ rẹ; sugbọn oluse-daadaa ni ẹni ti o gba Ọlọhun gbọ, ati ọjọ ikẹyin, ati awọn Malaika, ati awọn tira, ati awọn anabi … ». [Qur’aan, Al-Baqarah, [177].

Ẹri ti akọọlẹ “kadara” ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إنا كل شيء خلقناه بقدر {. [سورة القمر، (49)].

« Dajudaju Awa sẹda gbogbo nnkan pata pẹlu ebubu -kadara- ». [Qur’aan, Al-Qamar: 49].

 IPELE KẸTA: [IH’SAAN]

Ih’saan -daadaa sise-, opo kan ni oun ni: Ki o maa jọsin fun Ọlọhun bi ẹni pe o n ri I, ti iwọ kò ba si ri I, -ki o mọ daju pe- Oun N ri ọ. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إن الله مع الذين اتقوا والذين هم محسنون {. [ســورة النحـل، (128)].

« Dajudaju Ọlọhun N bẹ pẹlu awọn ti wọn n paya Rẹ, ati awọn ti wọn jẹ oluse-daadaa ». [Qur’aan, Al-Nahal: 128].

Ati ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} وتوكل على العزيز الرحيم. الذي يراك حين تقوم. وتقلبك في الساجدين. إنه هو السميع العليم {. [سورة الشعراء، (217-220)].

« Ba Ọba Alagbara Alaanu duro. Ẹni t’O N ri ọ nigba ti o n dide -lati kirun-, ati iyirapada rẹ ninu awọn oluforikanlẹ. Dajudaju Oun ni Olugbọrọ Olumọ ». [Qur’aan, Al-Shuaraa’i: 217-220].

Ati ọrọ Ọba t’O ga t’o sọ pe:

} وما تكون في شأن وما تتلو منه من قرآن ولا تعملون من عمل إلا كنا عليكم شهوداً إذ تفيضون فيه {. [سورة يونس، (61)].

« Ati pe iwọ kò ni i maa bẹ ninu isesi kan, bẹẹ si ni o kò ni i maa ka nnkan kan ninu Al-Qur’aani, ati pe ẹ kò ni i maa se isẹ kan afi ki Awa o jẹ ẹlẹri le yin lori nigba ti ẹ ba n se e …». [Qur’aan, Yunus: 61].

Ẹri lati inu Sunna ni ẹgbawa-ọrọ Malaika Jibreel t’o gbajumọ, o wa lati ọdọ Umar Ibn Al-Khataab, “ki Ọlọhun O yọnu si i”, o ni:

(( بينما نحن جلوس عند النبي ﷺ‬ إذ طلع علينا رجل شديد بياض الثياب شديد سواد الشعر، لا يرى عليه أثر السفر، ولا يعرفه منا أحد، فجلس إلى النبي ﷺ‬ ، فأسند ركبتيه إلى ركبتيه، ووضع كفّيه على فخذيه، وقال: يا محمد، أخبرني عن الإسلام، فقال: (( أن تشهد أن لا إله إلا الله وأن محمداً رسول الله، وتقيم الصلاة، وتؤتي الزكاة، وتصوم رمضان، وتحج البيت إن استطعت إليه سبيلاً ) قال: صدقت، فعجبنا له يسأله ويصدقه، قال: أخبرني عن الإيمان، قال: (( أن تؤمن بالله، وملائكته، وكتبه، ورسله، واليوم الآخر، وبالقدر خيره وشـره ) قال: أخبرني عن الإحسان، قال: (( أن تعبد الله كأنك تراه، فإن لم تكن تراه فإنه يراك ) قال: أخبرني عن الساعة، قال: (( ما المسؤول عنها بأعلم من السائل ) قال: أخبرني عن أماراتها، قال: (( أن تلد الأمة ربتها، وأن ترى الحفاة العراة العالة رعاء الشاء يتطاولون في البنيان ) قال: فمضى، فلبثت مليا، فقال: (( يا عمر أتدرون من السائل؟ ) قلنا: الله ورسوله أعلم، قال: (( هذا جبريل أتاكم يعلمـكم أمـر دينكم )). [رواه مسلم].

« Nigba ti a jokoo lọdọ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” ọkunrin kan yọ si wa lojiji, asọ rẹ funfun gboo, irun rẹ si dudu kirikiri, eniyan kò tilẹ le ri ami irin-ajo lara rẹ, bẹẹ ni ẹnikan wa kò mọ ọn ti tẹlẹ, titi ti o fi jokoo si ọdọ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, o si fi orunkun rẹ mejeeji ti ti Anabi, o si gbe ọwọ rẹ mejeeji lori itan [ara] rẹ mejeeji, o wa sọ pe: Iwọ Muhammad! fun mi niro nipa Islam?, Anabi ni: « Islam ni ki o jẹri pe kò si ọba kan t’o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun Ọba, ati pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i se, ki o si maa gbe irun duro, ki o maa yọ Zaka, ki o si maa gba aawẹ Ramadan, ki o si lọ bẹ ile Ọlọhun wo fun isẹ Haji ti o ba ni agbara ọna atilọ sibẹ ». O ni: Ododo ni o sọ. O ya wa lẹnu fun un pe oun l’o se ibeere, oun kan naa l’o si n se idajọ pe ododo ni esi ti wọn fun oun. O sọ pe: Fun mi ni iroyin nipa Iimaani “igbagbọ-ododo”?, Anabi ni: « Iimaani “igbagbọ-ododo” ni ki o gba Ọlọhun gbọ, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati akọsilẹ “kadara”, daadaa rẹ ati aburu rẹ ». O ni fun mi niro nipa Ih’saan “daadaa sise”?, Anabi ni: « Ih’saan “daadaa sise” ni ki o maa sin Ọlọhun gẹgẹ bi ẹni wi pe o n ri I, ti iwọ kò ba ri I, -ki o mọ daju pe- Oun N ri ọ ». O ni: Fun mi niro nipa ọjọ igbende?, Anabi ni: « Ẹni ti o n bi leere nipa rẹ kò mọ nipa rẹ ju iwọ ti o n beere nipa rẹ lọ ». O ni: Fun mi ni iroyin nipa awọn ami rẹ?, Anabi ni: « Ki ẹru-binrin o maa bi ọga rẹ lọmọ, ati ki o ri awọn alairi-bata-wo-sẹsẹ, awọn arin-hoho, awọn alaini, awọn darandaran, ti wọn yoo maa se idije lori kikọ awọn ile giga giga ». Lẹyin eyi ni ọkunrin yii wa pẹyinda, mo si jokoo fun igba pipẹ, Anabi wa sọ pe: « Iwọ Umar, njẹ ẹ wa mọ onibeere yii bi? ». A wi pe: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn mọ; Anabi ni: « Malaika Jibreel ni in, nse l’o wa ba yin lati fi ọrọ ẹsin yin ye yin ». [Muslim l’o gbe e jade].

 IPILẸ KẸTA

 MIMỌ NIPA ANABI YIN MUHAMMAD IKẸ ATI ỌLA ỌLỌHUN ỌBA K’O MAA BA A

Oun ni Muhammad ọmọ Abdullah, ọmọ Abdul Muttalib, ọmọ Haashim, ninu iran Quraish ni Haashim ti jade, ọkan ninu awọn Larubawa si ni awọn Quraish i se, bẹẹ ni awọn Larubawa jẹ apa kan ninu awọn arọmọdọmọ Anabi Ismaail ọmọ Anabi Ibrahim Al-Khaleel “ẹni ti Ọlọhun fẹran de gongo” eyi t’o lọla ju ninu ikẹ ati igẹ Ọlọhun k’o maa ba oun ati Anabi wa. Ọdun mẹtalelọgọta ni Anabi wa lo laye, o lo ogoji ọdun ninu rẹ siwaju ki Ọlọhun O to se e ni anabi, o si fi ọdun mẹtalelogun ninu rẹ jẹ ojisẹ Ọlọhun ati anabi Rẹ, ohun ti Ọlọhun fi se e ni anabi ni -ibẹrẹ Suura- Iq’ra’a; ati pe ohun ti O fi se e ni ojisẹ ni -Suura- Al-Mudathir.

Makkah ni ilu rẹ, Ọlọhun ran an nisẹ pẹlu sise ikilọ fun awọn eniyan pe ki wọn o jinna si ẹbọ sise “Shir’k”, ki o si maa pepe lọ sidi sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin “Tawheed”. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} يا أيها المدثر. قم فأنذر. وربك فكبر. وثيابك فطهر. والرجز فاهجر. ولا تمنن تستكثر. ولربك فاصبر {. [سـورة المدثر، (1-7)].

« Iwọ ti o da asọ bori mọlẹ. Dide ki o maa se ikilọ. Ki o si maa gbe Oluwa rẹ ga. Ki o si mọ asọ rẹ. Ki o si jinna si awọn oosa. Ma si se maa bun’yan ni ẹbun lati gba ọpọ. Ki o si maa se suuru nitori Oluwa rẹ ». [Qur’aan, Al-Muddathir: 1-7].

Itumọ: « Dide ki o maa se ikilọ » ni pe: Ki o maa se ikilọ fun awọn eniyan pe ki wọn o jinna si wiwa orogun fun Ọlọhun ninu ijọsin “Shir’k”, ki o si maa pepe lọ sidi sise Ọlọhun laaso ninu ijọsin “Tawheed”, ati pe itumọ: « Maa gbe Oluwa rẹ ga » ni pe: Maa gbe E tobi pẹlu sise E laaso ninu ijọsin “Tawheed”. Bẹẹ ni itumọ: « Mo asọ rẹ » ni pe: Ki o mọ awọn isẹ rẹ kuro ninu wiwa orogun fun Ọlọhun ninu ijọsin “Shir’k”. Bakan naa itumọ: « Jinna si awọn oosa » ni pe: Ki o pa awọn oosa ati awọn ti wọn n sin wọn ti, ki o si yọpa-yọsẹ kuro lọdọ wọn ati awọn ti n sin wọn. Ojisẹ Ọlọhun se ọdun mẹwa gbako lori ipepe lọ sidi Tawheed “sise Ọlọhun laaso ninu ijọsin”, lẹyin ọdun mẹwa yii ni Ọlọhun gbe e gun sanma, O si se awọn irun marun un ni ọranyan le e lori, o si kirun fun ọdun mẹta ni ilu Makkah, lẹyin naa ni Ọlọhun pa a lasẹ pe ki o se Hijirah -isipopada- lọ silu Madinah.

Hijirah ni: Isipopada lati ilu ẹbọ lọ si ilu Islam.

Ọranyan ni isipopada yii jẹ lori ijọ yii -ijọ Anabi Muhammad-, ati pe kò ni i yee maa bẹ titi ọjọ igbende.

Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إن الذين توفاهم الملائكة ظالمي أنفسهم قالوا فيم كنتم قالوا كنا مستضعفين في الأرض قالوا ألم تكن أرض الله واسعة فتهاجروا فيها فأولئك مأواهم جهنم وساءت مصيراً. إلا المستضعفين من الرجال والنساء والولدان لا يستطيعون حيلة ولا يهتدون سبيلا. فأولئك عسي الله أن يعفو عنهم وكـان الله عفوا غفورا {. [سورة النساء، (97-99)].

« Dajudaju awọn ti awon Malaika pa ni asiko ti wọn jẹ ẹni ti o se abosi fun ori ara wọn, wọn o wi fun wọn pe: Ibo ni ẹ wa -ipo wo ni ẹ wa ti iku fi wa ba yin-?. Wọn o sọ pe: A jẹ ẹni ti wọn sọ di ọlẹ -alailagbara- lori ilẹ. Njẹ ilẹ Ọlọhun kò wa gbooro to bi, ti ẹ fi le se isipopada ninu rẹ lati ibikan si ibomiran bi?. Tori naa awọn wọnyi ibupadasi wọn ni ina Jahannama, o si buru ni apadasi. Afi awọn ti wọn sọ wọn di alailagbara ninu awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọ kee-kee-kee ti wọn kò lọgbọn kan -ti wọn le da- ti wọn kò si mọ ọna kan -ti wọn le gba sa lọ-. Awọn wọnyi Ọlọhun yoo se amojukuro fun wọn, Ọlọhun jẹ Alamojukuro, Alaforijin ». [Qur’aan, Al-Nisaa’i: 97-99].

Ati ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} يا عبادي الذين آمنوا إن أرضي واسعة فإياي فاعبدون {. [سورة العنكبوت، (56)].

« Ẹyin ẹru Mi ti ẹ gbagbọ lododo, dajudaju ile Mi gbooro, nitori naa Emi nikan ni ki ẹ maa jọsin fun ». [Qur’aan, Al-Ankabuut, 56].

Al-Bagawi “ki Ọlọhun O kẹ ẹ” sọ pe: Idi ti aayah yii fi sọ kalẹ ni awọn Musulumi ti wọn wa ni Makkah, ti wọn kò i ti i se Hijirah, O pe wọn pẹlu orukọ igbagbọ-ododo “Iimaani”.

Ẹri Hijirah lati inu Sunna ni ọrọ Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”  t’o sọ pe:

(( لا تنقطع الهجرة حتى تنقطع التوبة، ولا تنقطع التوبة حتى تطلع الشمس من مغربها )).

« Hijirah kò ni i yee maa bẹ titi ti gbigba ironupiwada kò fi ni i si mọ, bẹẹ ni gbigba ironupiwada kò ni i tan titi ti oorun yoo fi gba ibuwọ rẹ yọ ».

Lẹyin ti Anabi ti fi ilu Madinah se ibugbe ni Ọlọhun pa a lasẹ pẹlu awọn ti o sẹku ninu awọn ofin Islam, gẹgẹ bi Zaka, aawẹ, Haji, irun pipe, ogun atigbẹsinga “Jihaad”, ifooro ẹni lati maa se daadaa, ati kikọ fun ni lati se aidaa, ati awọn nnkan miiran t’o yatọ si awọn wọnyi ninu awọn ofin Islam; Anabi tun lo ọdun mẹwa lori eleyii.

Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” si ti ku, sugbọn ẹsin rẹ -Islam- n bẹ, ẹsin rẹ naa niyi, kò si oore kan rara afi ki o jẹ pe o ti tọka si i fun awọn ijọ rẹ, bẹẹ ni kò si aburu kan rara afi ki o jẹ pe o ti se ikilọ fun wọn nipa rẹ.

Oore ti o tọka rẹ fun awọn ijọ rẹ ni Tawheed “sise Ọlọhun laaso ninu ijọsin”, ati gbogbo ohun ti Ọlọhun Ọba fẹ, ti O si yọnu si. Aburu ti o si se ikilọ fun wọn nipa rẹ ni Shir’k “wiwa orogun fun Ọlọhun ninu ijọsin”, ati gbogbo nnkan ti Ọlọhun kọ, ati eyi ti kò fẹ.

Ọlọhun ran an si gbogbo awọn eniyan lapapọ, O si se titẹle e ni ọranyan lori gbogbo awọn eniyan ati awọn alujannu; ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} قل يا أيها الناس إني رسول الله إليكم جميعا {. [سـورة الأعراف،  (158)].

« Sọ pe: Ẹyin eniyan, dajudaju emi jẹ ojisẹ Ọlọhun ti O ran si yin lapapọ ». [Qur’aan, Al-Aaraaf: 158].

Ati pe Ọlọhun Ọba fi Anabi wa yii pe ẹsin Rẹ; ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} اليوم أكملت لكم دينكم وأتممت عليكم نعمتي ورضيت لكم الإسلام دينا {. [سورة المائدة، (3)].

« Mo ti pe ẹsin yin fun yin loni yii, Mo si pe idẹra Mi le yin lori, ati pe Mo yọnu si Islam l’ẹsin fun yin». [Qur’aan, Al-Maa’idah: 3].

Ẹri lori iku Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} إنك ميت وإنهم ميتون. ثم إنكم يوم القيامة عند ربكم تختصمون {. [سورة الزمر: 30، 31].

« Dajudaju ẹni ti yoo ku ni iwọ i se, bakan naa ẹni ti yoo ku ni awọn naa i se. Lẹyin naa ti o ba di ni ọjọ igbende ọdọ Oluwa yin ni ẹ o ti maa ba ara yin se ariyanjiyan ». [Qur’aan, Al-Zumar, 30,31].

Lẹyin ti awọn eniyan ba ku Ọlọhun O gbe wọn dide -ni ọjọ igbende-, ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} منها خلقناكم وفيها نعيدكم ومنها نخرجكم تارة أخرى {. [سورة طه، 55].

« Lati ara ilẹ ni A ti da yin, inu rẹ naa ni A O da yin pada si, ati pe ninu rẹ ni A O si ti yọ yin jade ni igba keji ». [Qur’aan, Taaha: 55].

Ati ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} والله أنبتكم من الأرض نباتا. ثم يعيدكم فيها ويخرجكم إخراجا {. [سورة نوح، 17، 18].

« Ọlọhun l’O mu yin jade lati inu ilẹ ni mumu-jade. Lẹyin naa yoo da yin pada si inu rẹ, yoo si tun yọ yin jade kuro ninu rẹ ni yiyọ-jade ». [Qur’aan, Nuuh: 17,18].

Lẹyin igbende yii a o se isiro fun wọn, a o si san wọn ni ẹsan lori awọn isẹ wọn; ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} ولله ما في السماوات وما في الأرض ليجزي الذين أساؤوا بما عملوا ويجزي الذين أحسنوا بالحسنى {. [سورة النجم، 31].

« Ti Ọlọhun ni ohun ti n bẹ ni awọn sanma ati ohun t’o wa ni ilẹ, ki O le san awọn ti wọn se aburu ni ẹsan isẹ wọn, ki O si le san awọn ti wọn se daadaa ni ẹsan ti o dara ju ». [Qur’aan, Al-Naj’m: 31].

Ẹnikẹni ti o ba pe igbende nirọ di alaigbagbọ “keferi”. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} زعم الذين كفروا أن لن يبعثوا قل بلى وربي لتبعثن ثم لتنبؤن بما عملتم وذلك على الله يسير {. [سورة التغابن، 7].

« Awọn alaigbagbọ lero pe a kò ni i gbe awọn dide, sọ pe: Kò ri bẹẹ, mo fi Ọlọhun bura pe dajudaju a o gbe yin dide, lẹyin naa a o fun yin niro nipa ohun ti ẹ se nisẹ, ohun ti o rọrun ni eleyii jẹ fun Ọlọhun ». [Qur’aan, Al-Tagaabun: 7].

Ọlọhun ran gbogbo awọn ojisẹ Rẹ lati jẹ olufun-ni-niro-idunnu, ati oluse-ikilọ-fun-ni; ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} رسلا مبشرين ومنذرين لئلا يكون للناس على الله حجة بعد الرسل{. [سورة النساء، (165)].

« Awọn ojisẹ ti wọn jẹ olufun-ni-niro-idunnu ati oluse-ikilọ-fun-ni, nitori ki awijare kan o ma baa si fun awọn eniyan lọdọ Ọlọhun lẹyin -t’O ti ran- awọn ojisẹ wọnyi ». [Qur’aan, Al-Nisaa’i: 165].

Ẹni akọkọ -ninu awọn ojisẹ Ọlọhun Ọba wọnyi- ni Nuhu “alaafia Ọlọhun k’o maa ba a”, ẹni ikẹyin wọn si ni Muhammad “ikẹ ati ọla Ọlọhun k’o maa ba a”, oun si ni opin awọn anabi; ẹri lori wi pe Nuhu ni akọkọ awọn ojisẹ Ọlọhun ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} إنا أوحينا إليك كما أوحينا إلى نوح والنبيين من بعده {. [سورة النساء، 163].

« Dajudaju Awa ransẹ si ọ -Muhammad- gẹgẹ bi A ti se ransẹ si Nuhu ati awọn anabi ti wọn wa lẹyin rẹ ». [Qur’aan, Al-Nisaa’i: 163].

Gbogbo awọn ijọ kọọkan ni Ọlọhun ran ojisẹ Rẹ si, bẹrẹ lati ori Anabi Nuhu titi o fi de ori Anabi Muhammad lati maa pa wọn lasẹ pe ki wọn o maa jọsin fun Ọlọhun nikan soso, ki o si maa kọ fun wọn lati jọsin fun awọn oosa. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} ولقد بعثنا في كل أمة رسولا أن اعبدوا الله واجتنبوا الطاغوت {. [سورة النحل، 36].

« Dajudaju A ti ran ojisẹ kan si gbogbo ijọ kọọkan pe ki wọn o maa jọsin fun Ọlọhun, ki wọn o si jinna si awọn oosa ». [Qur’aan, Al-Nah’l: 36].

Ati pe Ọlọhun se e ni ọranyan lori gbogbo awọn ẹru Rẹ pe ki wọn o se aigbagbọ si awọn Taagut “oosa tabi esu”, ki wọn o si gba Ọlọhun gbọ lododo.

Ibn Al-Qayyim “ki Ọlọhun t’O ga O kẹ ẹ” sọ pe: Itumọ At-Taagut ni: Gbogbo ohun ti eniyan ba ti gbe kọja aye rẹ, yala nnkan naa jẹ ohun ti awọn eniyan n jọsin fun -lẹyin Ọlọhun- ni o, tabi ẹni ti wọn n wari fun, tabi ẹni ti wọn n gbọrọ si lẹnu, ati pe awọn Taagut naa pọ lọ jantirẹrẹ, sugbọn marun un ni awọn olori wọn:

1- Esu ti Ọlọhun le jinna kuro ninu ikẹ Rẹ.

2- Ẹni ti wọn n jọsin fun ti o si yọnu si i.

3- Ẹni ti n pe awọn eniyan lọ sidi pe ki wọn o maa jọsin fun oun.

4- Ẹni ti o l’oun mọ nnkan kan ninu imọ ohun ti o pamọ.

5- Ẹni ti n fi nnkan miiran t’o yatọ si Al-Qur’aani ti Ọlọhun sọ kalẹ se ofin.

Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o sọ pe:

} لا إكراه في الدين قد تبين الرشد من الغي فمن يكفر بالطاغوت ويؤمن بالله فقد استمسك بالعوة الوثقى لا انفصام لها والله سميع عليم{. [سورة البقرة، 256].

« Kò si ifagbaramuni kan ninu ẹsin, dajudaju ọna imọna ti f’oju han yatọ si ti isina, nitori naa ẹnikẹni t’o ba se aigbagbọ si Al-Taagut -esu ati awọn oosa yoku- ti o si gba Ọlọhun gbọ, onitọun ti gba okun ti o yi ti kò le ja mu, Ọlọhun ni Olugbọrọ Olumọ ». [Qur’aan, Al-Baqarah, 256]. Eleyii ni itumọ: LAA ILAAHA ILLA -L-LAH “kò si ọba kan ti o tọ pe ki a fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun Ọba”.

O si wa ninu ọrọ Anabi pe

(( رأس الأمر الإسلام، وعموده الصـلاة، وذروة سنامه الجهاد في سبيل الله )).

« Koko ọrọ naa ni Islam “igbafa fun Ọlọhun”, opo-mulero rẹ si ni irun kiki, eyi ti o si jẹ aye t’o ga ju ti ike ẹyin rẹ ni Jihaad “jija ogun si oju ona Ọlọhun” ». Ọlọhun Ọba l’O mọ.

Awon ipilẹ mẹta naa ti pe.

___