Ẹsin Isilaamu Eleyii ni akọsilẹ soki kan nipa ẹsin Isilaamu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu Alikuraani alapọnle pẹlu Sunnah Anọbi ()

 

Ẹsin Isilaamu Eleyii ni akọsilẹ soki kan nipa ẹsin Isilaamu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu Alikuraani alapọnle pẹlu Sunnah Anọbi : Tira pataki to ko alaye nipa ẹsin Isilaamu sinu, to nṣalaye eyi ti o pataki ju ninu awọn ìpìlẹ, ẹkọ ati awọn ẹwa rẹ lati inu awọn iwe-ẹri ipile; eyi tii ṣẹ Alikuraani alapọnle ati Sunnah Anọbi. Tira yii eyi ti a fi nba gbogbo ẹniti o ti balaga sọrọ, yala o jẹ musulumi tabi kii tiẹ ṣe musulumi, to si wa ni ede onikaluku wọn, ko le baa wulo ni gbogbo asiko, aaye ati oniruuru iṣesi tabi ipo ti wọn ba wa. Ẹda kan niyi ti o ko awọn ẹri lati inu Alikurani ati Sunnah Anọbi sinu

|

  Ẹsin Isilaamu    Eleyii ni akọsilẹ soki kan nipa ẹsin Isilaamu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu Alikuraani alapọnle pẹlu Sunnah Anọbi

Tira pataki to ko alaye nipa ẹsin Isilaamu sinu, to nṣalaye eyi ti o pataki ju ninu awọn ìpìlẹ, ẹkọ ati awọn ẹwa rẹ lati inu awọn iwe-ẹri ipile; eyi tii ṣẹ Alikuraani alapọnle ati Sunnah Anọbi. Tira yii eyi ti a fi nba gbogbo ẹniti o ti balaga sọrọ, yala o jẹ musulumi tabi kii tiẹ ṣe musulumi, to si wa ni ede onikaluku wọn, ko le baa wulo ni gbogbo asiko, aaye ati oniruuru iṣesi tabi ipo ti wọn ba wa.

Ẹda kan niyi ti o ko awọn ẹri lati inu Alikurani ati Sunnah Anọbi sinu



 ·       Ẹsin Isilaamu ni iṣẹ naa ti Allah fi ranṣẹ si gbogbo eniyan. Paapaajulọ Oun ni iṣẹ ayeraye ti o sijẹ opin awọn iransẹ Oluwa Allah

Ẹsin Isilaamu ni lẹta Allah si gbogbo eniyan patapata. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: A ò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀. Suratu Sabai: 28 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Irẹ Anọbi sọ pe mo pe ẹyin eniyan (ki ẹ mọ wipe) dajudaju Emi ni iransẹ Allah si gbogbo yin patapata Suratul A'raf: 158 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fun yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. Suratu Nisai: 170

Ẹsin Isilaamu ni ifiranṣẹ Allah ti o jẹ ti ayeraye, Oun naa ni igbeyin awọn ifiranṣẹ Oluwa wa. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: (Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. Suratul Ahzab: 40

 ·       Ẹsin Isilaamu kii ṣe ẹsin adayanri fun awọn ẹya tabi awọn ijọ kan pato. Ṣugbọn O jẹ ẹsin Allah fun gbogbo eniyan patapata

Ẹsin Isilaamu kiiṣe ẹsin adayanri fun awọn ẹya tabi awọn ijọ kan pato. Ṣugbọn O jẹ ẹsin Allah fun gbogbo eniyan patapata. Akọkọ aṣẹ ti Allah pa ninu Alikuraani alapọnle ni gbolohun Rẹ ti ọla Rẹ ga julọ to sọ pe; Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná). Suratul Baqara: 21 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Mo pe gbogbo ẹyin eniyan, ẹ paya Oluwa yin Ẹni ti O da yin lati ara ẹmi kan ṣoṣo, ti O si tun da iyawo rẹ lati ara rẹ, ti O wa mu jade ni yanturu lati ara awọn mejeeji ọpọlọpọ ọkunrin ati obinrin Suratu Nisai: 1 Egbawa ọrọ wa lati ẹnu Ibnu Umar ki Allah yọnu si awọn mejeeji pe Anọbi- ki ikẹ ati ola Allah maa ba a- ba awọn eeyan sọrọ lọjọ ti o ṣi ilu Makkah, O sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, dajudaju Ọlọhun ti gbe igberaga awọn keferi alaimọkan to ti ṣiwaju ati fifi babanla ṣe iyanran kuro l'ori yin. Leni, gbogbo eniyan jẹ iran meji: ẹniire, olupaya Ọlọhun ti yoo jẹ alapọnle lọdọ Allah, ati obilẹjẹ eniyan, oloriburuku ti yoo jẹ ẹni-yẹpẹrẹ lọdọ Ọlọhun. Gbogbo eniyan jẹ arọmọdọmọ Aadamo, bẹẹ Ọlọhun si da Aadama latara erupẹ. Allah sọ pe: Mo pe gbogbo ẹyin eniyan, dajudaju Awa ni A da'yin l'ọkunrin l'obinrin, bẹẹ nii a si ṣe yin ni iran-iran ati idile-idile ki ẹ le fi maa da ara yin mọ. Dajudaju alapọnle eniyan julọ laarin yin ni ẹni naa ti o ba npaya Ọlọhun julọ. Dajudaju Ọlọhun ni Onimimọ julọ Oloye julọ. Suratul Hujuraat: 13. Tirimidhi lo gbaa wa, nọmba (3270) O o lee ri ofin kan to nṣe adayanri awọn eeyan kan tabi awọn ijọ kan latara wiwo iran wọn tabi ijọ wọn tabi ẹya won, yala ninu awọn ofin Alikuraani alapọnle tabi awọn aṣẹ Anọbi alapọnle (ki ikẹ ati ola Allah maa ba a).

 ·       Isilaamu ni ifiranṣẹ Allah, eyi ti O wa lati pe awọn iṣẹ awọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ to ti kọja, eyi ti O fi ran wọn si awọn ijọ wọn, ki ikẹ ati ola Allah maa ba awọn ojiṣẹ Ọlọhun wọnyii.

Isilaamu ni ifiranṣẹ Allah, eyi ti O wa lati pe awọn iṣẹ awọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ to ti kọja, eyi ti O fi ran wọn si awọn ijọ wọn, ki ikẹ ati ola Allah maa ba awọn ojiṣẹ Ọlọhun wọnyii. Olohun ti ola Re ga so pe: Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūﷺ‬. Suratul Nisai: 163 Ẹsin yii ti Ọlọhun fun Ojiṣẹ Nla Muhammad- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- ni imisi rẹ, Oun naa ni ẹsin ti Ọlọhun Ọba ṣe ni ilana ẹsin fun awọn Anọbi ti won ti kọja, ti O si pa'wọn lasẹ rẹ. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: (Allāhu) ṣe ní òfin fun yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà). Suratu Shura: 13 Eleyii ti Ọlọhun fún Ojiṣẹ Nla Muhammad- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- ni imisi rẹ jẹ ajẹri fun awọn tira Ọlọhun to ti kọja gẹgẹ bii Taoreta ati Injila ko too di pe madaru wọnu awọn mejeeji. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Suratu Fatir: 31

 ·       Gbogbo awọn Anọbi patapata- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba wọn- ẹsin kan ṣoṣo ni ẹsin wọn, bo tilẹ jẹ pe ilana iṣẹsin wọn ya lọtọọtọ.

Gbogbo awọn Anọbi patapata ki ikẹ ati aanu Allah maa ba wọn, ẹsin kan ṣoṣo ni ẹsin wọn, bo tilẹ jẹ pe ilana iṣẹsin wọn ya lọtọọtọ. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn t’ó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fun yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fun yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí. Suratul Maidat: 48 Ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: Emi gan-an ni mo lẹtọ si Isa ọmọ Maryam julọ laarin awọn eeyan laye ati lọrun. Bẹẹ, apejuwe awọn Anọbi da gẹgẹ bi awọn ọmọ ọbakan, ti iya wọn yatọ, ṣugbọn ọkan ṣoṣo ni ẹsin wọn. Imam Bukhari lo gbaa wa, nọmba (3443)

 ·       Gẹgẹ bi gbogbo awọn Anọbi: Nuha, Ibrahim, Musa, Sulayman ati Dawuda ṣe pepe, bẹẹ naa ni Isilaamu ṣe pepe si inigbagbọ pe ẹni to njẹ Oluwa ni Allah, Aṣẹda, Olufunilarisiki, Ayeni, Apani, Ọlọla-gongo, Oun naa nii Oludari gbogbo nkan, Oun nikan yii naa ni Alaanu, Onikẹ to ga julọ.

Gẹgẹ bi gbogbo awọn Anọbi: Nuha, Ibrahim, Musa, Sulayman ati Dawuda ṣe pepe, bẹẹ naa ni Isilaamu ṣe pepe si ninigbagbọ pe ẹni to njẹ Oluwa ni Allah, Aṣẹda, Olufunilarisiki, Ayeni, Apani, Ọlọla-gongo, Oun naa nii Oludari gbogbo nkan, Oun nikan yii naa ni Alaanu, Onikẹ to ga julọ. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo? Suratu Fatir: 3 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: "Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?" Suratu Yunusa: 31 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí Ó máa dá a padà (lẹ́yìn ikú), tí Ó sì ń pèsè fun yín láti sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo." Suratu Naml: 64

Gbogbo awọn Anọbi ati ojiṣẹ pata ni a gbe dide pẹlu iponlogo sisin Allah nikan ṣoṣo. Allah ti ọla Rẹ ga ju sọ pe Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn t’ó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí? Suratul Nahl: 36 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.” Suratul Anbiyaa: 25 Allah fun wa niro nipa Nuha- ki ikẹ ati igẹ Allah maa ba a- pe Oun naa jiṣẹ pe: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú mò ń bẹ̀rù ìyà Ọjọ́ Ńlá fun yín." Suratul A'raf: 59 Bẹẹ nii aayo Ọlọhun tii ṣe Ibrahim- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- gẹgẹ bi Allah ṣe fun wa niro nipa rẹ pe o sọ pe: (Rántí Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì páyà Rẹ̀. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.” Suratul Ankabut: 16 Anọbi Salihu- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- gẹgẹ bi Allah ṣe sọ nipa rẹ pe o sọ pe: Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín; èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. (Ó jẹ́) àmì kan fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ aburú kàn án nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baà jẹ yín. Suratul A'raf: 73 Anọbi Shuaib- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- gẹgẹ bi Allah ṣe sọ nipa rẹ pe o sọ pe: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ìyẹn sì lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Suratul A'raf: 85

Ni igba akọkọ ti Ọlọhun ba Anọbi Musa- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- sọrọ, Ọba ti mimọ n bẹ fun sọ fun un pe: Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi. Suratu Ta-ha: 13-14. Bẹẹ nii Allah sọrọ lẹni ti n fun ni niro nipa Anọbi Musa- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a-, O sọ pe Oun gan-an paapaa fi Ọlọhun wa iṣọ, O sọ pe "Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò gba Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́ gbọ́. Suratu Ghafir: 27 Allah fun wa niro nipa Al-Masiihu- ki ikẹ ati igẹ Allah maa ba a- pe Oun naa so pe: Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà." Aal Im’raan/51 Allah fun wa niro nipa Al-Masiihu- ki ikẹ ati igẹ Allah maa ba a- pe o so pe: Mo pe ẹyin ọmọ Israẹli, ẹ maa sin Allah tii ṣe Oluwa mi ati tiyin naa. Dajudaju ẹnikẹni ti o ba mu orogun pọ mọ Ọlọhun dajudaju Ọlọhun ti ṣe Alijannah ni eewọ fun irufẹ ẹni naa, ibugbe rẹ si ni inu Ina ko si ni si oluranlọwọ kankan fun awọn ọṣẹbọ alabosi naa. ( Suratul-Maa'idah : 72)

Koda gan-an paapaa, to fi mọ Taoreta ati Injila, ikanpamọ sisin Ọlọhun nikan ṣoṣo jẹyọ ninu awọn mejeeji. Ọrọ Anọbi Musa- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- jẹyọ ninu iwe Deuteronomy pe Gbọ irẹ Isirẹli, Oluwa Ọlọhun wa Oluwa ọkanṣoṣo nii Ikanpamọ ọrọ imọlọhun lọkan jẹyọ ninu iwe Maaku nibi ti Messiah- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- ti nsọ pe: Dajudaju akọkọ ofin ni pe: Gbọ, irẹ Isirẹli, Oluwa Ọlọhun wa Oluwa ọkanṣoṣo nii

Ọlọhun ti ọla ati iyi Rẹ gbọngbọn ṣalaye pe gbogbo awọn Anọbi ni a fi iṣẹ pataki tii ṣe ipepe sibi imọlọhun lọkan ran. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Suratul Nahl: 36 Allah tun sọ pe: Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun t’ó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi t’ó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo." Suratul Ahqaf: 4 Alufa agba Saadi- ki Allah ba ni kẹ ẹ- sọ pe: O jẹ ki a mọ wipe iyan ti awọn ọṣẹbọ nja nipa awọn oriṣa wọn, won o ni ẹri tabi itọka lori rẹ, ṣugbọn wọn kan ngbara le aba irọ lasan, irori to ti kúta ati laakai to ti bajẹ ni i. Ohun ti yoo tọka ailẹsẹ nlẹ rẹ fun Ọ naa ni nigba ti a ba jọ iṣesi wọn yẹbẹyẹbẹ, ti a tọ gbogbo imọ wọn ati awọn iṣẹ wọn ti a si woye si iṣesi awọn nkan ti wọn nlo igbesi aye wọn le lori lati maa sin, njẹ awọn nkan yii ṣe wọn ni anfaani kankan laye tabi lọrun Tayseer Alkareem Almannan: oju-ewe 779

 ·       Ọlọhun Allah ti mimọ n bẹ fun-un ti ọla Rẹ sí ga julọ ni Aṣẹda, Oun naa ni O lẹtọ si ijọsin ni Oun nikan, ati wipe a o gbọdọ sin eyikeyi  nkan miran mọ Ọn.

Ọlọhun ni ẹni naa ti o lẹtọ si ki a maa sin-In ni Oun nikan ti a o gbọdọ si sin ẹlomin mọ Ọn. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná). (Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà, Ó sọ omi òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fun yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́). Suratul Bakarat: 21-22 Ẹni ti O da wa ati awọn iran eniyan to ti kọja, ti O si ṣe ilẹ ni pẹrẹsẹ to tun nsọ omi kalẹ lati sanmọ to si fi nmu oniranran irugbin ti a fi nṣe arisiki jade, Oun nikan naa lo lẹtọ si ijọsin. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo? Suratu Fatir: 3 Ẹni to nda ẹda to si tun npese ijẹ-imu Oun nikan ṣoṣo lo lẹtọ si ijọsin. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín; kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan. Suratul An'am: 102

Gbogbo nkankinkan ti awọn eniyan ba nsin lẹyin Ọlọhun ko lẹtọ si ijọsin nitori nkan bẹẹ ko nikapa nkankan to ṣe deede ọmọnaagun yala ninu sanmọ tabi l'ori ilẹ, bẹẹ nkan kii ṣe amugbalẹgbẹ fun Allah nibi nkankan, kii sii ṣe oluranlọwọ tabi onigbunwọ fun Ọlọhun. Bawo wa ni wọn yoo ṣe wa maa pe nkan mọ Ọlọhun tabi ki won o maa gbe e sipo amugbalẹgbẹ fun-Un. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ olúwa) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn. Suratu Sabai: 22

Allah ti mimọ mbẹ fun ti ọla Rẹ sí ga ni Ẹni ti O da gbogbo ẹda, ti O si mu-un jade latara aisi. Dajudaju mimaabẹ awọn nkan yii jẹ ẹri pataki to ntọka bibẹ Rẹ (Oun Allah), to si ntọka jijẹ oludari ati lilẹtọ si ijọsin Rẹ. Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé). Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fun yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó láròjinlẹ̀. Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀. Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀. Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè. Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀. TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀. Oun (Allah) yii naa ni Ẹni naa ti O pilẹ iṣẹda bẹẹ ti yoo si tun da a pada (lẹyin igba ti wọn ba ti ku ti wọn parẹ mọlẹ) koda dida wọn pada rọrun fun-un pupọ ju bibẹrẹ iṣẹda gan-an lọ Suratu Rum: 20-27

Namuruusu jiyan nipa bibẹ Oluwa Rẹ, ni Anọbi Ibrahim- ki ikẹ ati igẹ Allah maa ba a- gẹgẹ bi Allah ṣe fun wa niro nipa rẹ ba sọ fun-un pe: Anọbi Ibrahim si sọ fun-un pe, dajudaju Ọlọhun lo nmu Oorun jade lati ibuyọ rẹ, irẹ mu-un jade lati ibuwọ rẹ, irọ alainigbagbọ yii ba han gbangba, bẹẹ Allah kii fi ọna mọ awọn alabosi eniyan. Suratul Bakarat: 258 Gege bee naa ni Anọbi Ibrahim- ki ikẹ ati igẹ Allah maa ba a- se fi ẹri rinlẹ fun awọn eeyan rẹ pe dajudaju Allah ni Ẹni naa ti O fi ọna mọ oun, Oun ni O n fun oun ni jijẹ ati mimu, to si n fun oun ni alaafia nigba ti oun ba ṣe aarẹ, bẹẹ Oun nikan naa ni O mu oun ṣẹmi ti yoo si mu oun kuro l'ayé (nigba ti asiko ba to) O sọ pe: (Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí; Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu; Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn; Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè; Suratu shuaraa: 78- 81 Ọlọhun tun sọrọ ni Eni ti n fun ni niro nipa Anọbi Musa- ki ikẹ ati igẹ Allah maa ba a- wipe Oun gan-an ba Faraoh ṣe ifẹrijiyan to si sọ fun-un pe: Oluwa re Oun naa nii Ẹni ti O yanju fun gbogbo nkan eto iṣẹda rẹ bẹẹ ti O si fun-un ni ọgbọn atinuda rẹ. Suratu Ta-ha: 50

Ọlọhun wa tẹ gbogbo nkan to mbẹ ninu sanmọ ati ilẹ loriba fun ọmọniyan, O si fi oriṣiriṣi idẹra rọkirika rẹ nitori ki ọmọniyan le maa sin Ọlọhun nikan lai nii ṣe keferi si I. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Ṣé ẹ ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ fun yín, Ó sì pé àwọn ìkẹ́ Rẹ̀ fun yín ní gban̄gba àti ní kọ̀rọ̀? Ó sì wà nínú àwọn ènìyàn ẹni t’ó ń jiyàn nípa Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (nínú sunnah Ànábì s.a.w.) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) t’ó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn). Suratu Lukman: 20 Gẹgẹ bi Allah ṣe tẹ gbogbo nkan to n bẹ ninu sanmọ ati ilẹ loriba fun ọmọniyan, gẹgẹ bẹẹ naa ni O da a ti O si pese gbogbo nkan ti o le ni bukata si gẹgẹ bi igbọran, iriran ati irọnu ọkan ki o le baa kọ imọ eyi ti yoo ṣee lanfaani ti yoo si tọka Oluwa ati Aṣẹda rẹ si i. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Allāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un). Suratu Nahl: 78

Dajudaju Ọlọhun ti mimọ ati giga julọ n bẹ fun ni O da gbogbo awọn agbaye yii, ni O si da ọmọniyan ti O si pese gbogbo nkan to le bukata si gẹgẹ bi awọn orikerike ati okun-ara, bẹẹ naa ni O pese gbogbo awọn nkan ti yoo maa ran-an lọwọ lati lanfaani ṣiṣe ẹsin ati riri orilẹ gbe fun-un, bẹẹ ni O si rọ gbogbo nkan to n bẹ ninu sanmọ ati ilẹ fun-un.

Allah si fi ṣiṣẹda gbogbo awọn eda ti o tobi wọnyii ṣe ẹri to ntọka jijẹ Oludari ati Alamojuto Rẹ, eyi to ntọka si pipondandan mimaa sin-In. Oun (Allah) ti mimọ ati giga julọ n bẹ fun sọ pe: Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: "Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?" Suratu Yunus: 31 Ọba ododo ti mimọ n bẹ fun-Un tun sọ pe Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun t’ó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi t’ó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo." Suratul Ahqaf: 4 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: O da sanmọ laini opo kankan gẹgẹ bi ẹyin ṣe n ri i, O si fi awon oke nlanla ti ilẹ ki o ma baa mi tabi yẹ gẹrẹ mọ yin lẹsẹ, O si fọn oriṣiriṣi daaba sori rẹ, A si nsọ omi kalẹ lati sanmọ ti a fi nmu oniranran eso didun jade ninu rẹ (ilẹ). Eleyii ni iṣẹda ti Allah ṣe, ẹ wa fi han mi eyikeyi nkan ti awọn to yatọ si I da. Too, ọrọ naa ni pe awọn alabosi ti wa l'ori anu to han gbangba Suratu Lukman: 10-11 Ọba ododo ti mimọ n bẹ fun-Un tun sọ pe Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni. Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn àpótí ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí? Suratu Tur: 35-37 Onimimọ agba Sa'diy sọ pe: Eleyii gan-an ni fífi ẹri lọlẹ fun wọn labẹ nkankan ti wọn o le ni ọna kankan ju ki wọn o ju ọwọ silẹ fún ododo ọrọ, Lai sí bẹẹ wọn yoo di ẹni ti o tapa si nkan ti o ba laakai ati ẹsin mu. Tafsiri Ibnu Sa'di: oju ewe 816

 ·       Allah ni O da gbogbo nkan to n bẹ ninu Aye yala awọn nkan ti a ri tabi eyi ti a ko ri. Gbogbo nkan to ti yatọ si I (Allah) ni yoo maa jẹ ẹda kan ninu awọn ẹda Rẹ, O si da sanmọ ati ilẹ ni ijọ mẹfa

Allah ni O da gbogbo nkan to n bẹ ninu Aye yala awọn nkan ti a ri tabi eyi ti a ko ri. Gbogbo nkan to ti yatọ si I (Allah) ni yoo maa jẹ ẹda kan ninu awọn ẹda Rẹ, Olohun ti ola Re ga so pe: Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí. Suratu Ra'd: 16 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: {Oun (Allah) a si tun maa da nkan ti ẹ o mọ} Suratu Nahl: 8

Allah si da sanmọ ati ilẹ ni ọjọ mẹfa. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan t’ó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan t’ó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Suratul Hadid: 4 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje). Suratu Qaf: 38

 ·       Allah ti mimọ ati giga ọla n bẹ fun-Un ko ni igbakeji yala nipa ọla tabi iṣẹda tabi idari tabi ijọsin bo tii wu ko mọ

Allah ti mimọ ati giga ọla n bẹ fun-Un ni Olukapa gbogbo ọla ti ko ni orogun nibi iṣẹda tabi ọla tabi idari bo tilẹ wu ki o mọ, Olohun ti ola Re ga so pe: Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun t’ó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi t’ó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo." Suratul Ahqaf: 4 Alufa agba Saadi- ki Allah ba ni kẹ ẹ- sọ pe: Itumọ ọrọ yii ni pe, sọ fun awọn ti wọn mu awọn oriṣa ati ere ti wọn o lagbara kankan lati ṣe gẹgẹ bii anfaani tabi inira tabi ipani tabi iyeni tabi ijini dide ni orogun fun Allah, sọ fun wọn lati ṣalaye lilẹ awọn oriṣa wọn, ati wipe awọn oriṣa naa ko lẹtọ si nkankan ninu ijọsin, sọ fun wọn pe "ẹ fi eyikeyi nkan ti wọn ba da l'ori ilẹ tabi ninu sanmọ han mi, tabi ti wọn ni ifọwọkun kankan nibi dida sanmọ". Njẹ wọn tilẹ da nkankan ninu sanmọ ati ilẹ bi? Se wọn da oke ni? Nje wọn tilẹ sọ pe ki odo o maa ṣan? Nje awọn ni wọn fọn awọn ẹranko sori ilẹ? Nje awọn ni wọn tilẹ jẹ ki awọn igi o maa hu jade? Ewo gan-an ni ikunlọwọ wọn n bẹ nibẹ ninu awọn nkan wọnyii? Ko si ikunlọwọ wọn kankan nibẹ gẹgẹ bi awọn funra wọn ṣe gba bẹẹ ka ma tiẹ tii sọ nipa ijẹri awọn miran. Eleyii gan-an ni ẹri laakai to muna doko l'ori wipe sisin awọn nkan miran yatọ si Allah, irufẹ ijọsin bẹẹ otubantẹ nii, ko l'ẹsẹ nlẹ.

Lẹyin naa lo tun wa sọ pe koda ko tun si ẹri imisi to n gbe ero ati iṣe wọn lẹyin. Oun (Allah) sọ pe {E mu Tira kan ṣiwaju eleyii wa} Iyẹn ni pe tira ti o njẹri si imorogun pọ mọ Ọlọhun "tabi oripa ẹri to jẹ ti mimọ" ti a jogun lati ọdọ awọn ojiṣẹ to pàṣẹ bẹẹ. Ohun ti a mọ pẹlu ẹri to ntọka si i ni pe wọn o to bẹẹ lati mu u wa lati ọdọ eyikeyi ojiṣẹ Ọlọhun, koda gan-an paapaa a tun nfi ọwọ rẹ sọya to si dani l'oju pe gbogbo ojiṣẹ pata lo n pepe sibi imo Olọhun wọn lọkan ti wọn si n kọ imorogun pọ mọ Ọlọhun fun awọn eeyan. Eleyii gan-an naa nii eyi to tobi ju ninu imọ ti ẹgbawa rẹ wa lati akata wọn. Tafsiri Ibnu Sa'di: oju ewe 779

Allah ti mimọ ati giga ọla n bẹ fún, Oun ni Olukapa gbogbo ọla, ko si igbakeji fun-Un ninu ọla Rẹ. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Sọ pe mo pe Irẹ Ọlọhun Olukapa gbogbo ọla, Irẹ ni O n fi ọla fun ẹni ti o ba wu Ọ, bẹẹ ti O si ma n gba ọla kuro lọwọ ẹni ti o ba wu Ọ, Irẹ lo n gbe iyi fun ẹni ti o ba wu Ọ bẹẹ ti O si ma nrẹ ẹni ti o ba wu Ọ nilẹ, lọwọ Rẹ ni gbogbo oore n bẹ, dajudaju Irẹ ni Alagbara lori gbogbo nkan. Aal Im’raan/26 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọrọ ti O si nṣalaye pe ti E ni ọla ti o pe nṣe lọjọ Alukiyamọ: Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní? Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni." Suratu Ghafir: 16

Allah ti mimọ ati giga ọla n bẹ fun-Un ko ni igbakeji yala nipa ọla tabi iṣẹda tabi idari tabi ijọsin bo tii wu ko mọ, Olohun ti ola Re ga so pe: Kí o sì sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò yẹpẹrẹ áḿbọ̀sìbọ́sí pé Ó máa wá bùkátà sí olùrànlọ́wọ́.” Gbé títóbi fún Un gan-an. Suratul Israa: 111 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n. Suratul Furqan: 2 Oun nikan ni O ni ikapa gbogbo nkan, gbogbo nkan miran yatọ si I si jẹ ẹda ọwọ Rẹ, Oun naa ni O n dari gbogbo iṣesi ati alaamọri. Ẹni ti O ṣe pe bayii ni iroyin Rẹ, Oun gan-an ni o di ọranyan lati maa jọsin fun, bẹẹ jijọsin fun nkan miran yatọ si I jẹ iwa aipe laakai ati imorogun mọ Ọlọhun eleyi ti yoo ba aye ati orun ẹda je. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe Wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ yẹhudi tàbí nasara kí ẹ mọ̀nà.” Sọ pé: "Rárá, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (lẹ̀sìn), olùdúró-déédé, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ." Suratul Bakarat: 135 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ta l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́. Suratu Nisai: 125 Ọlọhun ododo ti mimọ n bẹ fun Un tun ṣalaye pe ẹnikẹni to ba n tẹle ọna miran yatọ si ilana ẹsin Anọbi Ibrahim aayo Ọlọhun- ki ikẹ ati aanu Allah maa ba a- pe iru ẹni bẹẹ lo wu'wa agọ si ẹmi ara rẹ. Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe: Ta sì ni ó máa kọ ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sílẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gọ ẹ̀mí ara rẹ̀. A kúkú ti ṣà á lẹ́ṣà n’ílé ayé. Dájúdájú ó tún wà nínú àwọn ẹni rere ní ọ̀run. Suratul Bakarat: 130

 ·       Ati pe Alloohu Oba ti mimo n be fun Un, ko bi omo, won ko si bi I, ko si si akegbe ati alafijo Kankan fun Un.

Ati pe Alloohu Oba ti mimo n be fun Un, ko bi omo, won ko si bi I, ko si si akegbe ati alafijo Kankan fun Un, Oba Ododo ti ola Re ga ti mimo si n be fun Un so pe: Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo. Allāhu ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn). Kò bímọ. Wọn kò sì bí I. Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́." Suuratul Ikhlaas: 1-4. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀? Suuratu Maryam: 65. Oba Ododo ti ipo Re gbongbon so pe: (Òun ni) Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ṣẹ̀dá àwọn obìnrin fun yín láti ara yín. Ó tún ṣẹ̀dá àwọn abo ẹran-ọ̀sìn láti ara àwọn akọ ẹran-ọ̀sìn. Ó ń mu yín pọ̀ sí i (nípa ìṣẹ̀dá yín ní akọ-abo). Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran. Suuratu Shuuroh: 11.

 ·       Ati pe Alloohu ti mimo n be fun Un ti ola Re si tun ga O ki n sokale si inu nkankan, ko si ki n di abara si inu nkankan ninu eda Re.

Ati pe Alloohu ti mimo n be fun Un ti ola Re si tun ga O ki n sokale si inu nkankan, ko si ki n di abara si inu nkankan ninu eda Re, ko si di ẹyọkan pelu nkankan; iyen sele nitori pe dajudaju Alloohu ni Oba adeda, ati pe nkan ti o ba yato si I eda ni, ati pe Oun ni Oba ti yoo seku, ti nkan ti o ba si yato si I yoo pada di titan. Nitori naa Alloohu O ki n sokale si inu nkankan ninu eda Re, ati pe nkankan o le sokale si inu paapa Re, mimo fun Un, ati pe Oba Alloohu ti mimo n be fun Un tobi ju gbogbo nkan lo, O si tun kanka ju gbogbo nkan lo, Oba Alloohu ti ola Re ga sọ ni Ẹni ti n tako eniti o ba n lero wipe Alloohu sokale si inu Al-Masiih (Eesa): Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Sọ pé: “Ta sì l’ó ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam, àti ìyá rẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?” Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Suuratul Maaidah: 17. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí ẹ bá dojú kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ƙiblah Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀. Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, (àmọ́) tiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni (Allāhu). Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Suuratul Bakorah: 115-117. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ." (88). Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá. Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dà wó lulẹ̀ gbì fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé. (91). Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn. Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà. Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan. Suuratu Maryam: 88-95. Allah tun sọ pe: Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn ﷻ‬́n. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi. Suuratul Baqorah: 255. Nitori naa, Eni ti O ba ri bayii, ti ẹda Rẹ naa si ri báyìí, bawo ni yoo se wa sokale si ara okan ninu won? Tabi ki o mu un ni omo? Tabi ki o se e ni olujosin fun pelu Re?

 ·       Alloohu ti mimo n be fun Un ti ola Re si tun ga je Aláàánú Onike si awon eru Re, fun idi eyi O ran awon ojise, O si tun so awon tira kale

Alloohu ti mimo n be fun Un ti ola Re si tun ga ni Alaaanu Onike  awon eru Re, ati pe ninu ikẹ Re si awon eru Re ni pe O ran awon ojise si won, O si tun so awon tira kale; lati fi yo won kuro nibi awon okunkun aigbagbo ati imaa se orogun, lo si ibi imole ṣiṣe Ọlọhun lokan ati imọna, Alloohu ti ola Re ga so pe: Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè mu yín kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fun yín. Suuratul Hadiid: 9.

Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá. Suuratul Anbiyaah: 107. Ati pe Oba Alloohu tun pa anabi Re lase ki o fun awon erusin ni iro wipe Oun ni Oba Alaforijin Onike, nitori naa, Oba Alloohu ti ola Re ga so pe: Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. Suuratul Hijr: 49. Ati pe ninu aanu Re ati ike Re ni pe Oun naa ni O maa n mu inira kuro ti O si maa n so oore kale fun awon eru Re, Oba Alloohu ti ola Re ga so pe: Tí Allāhu bá mú ìnira bá ọ, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun. Tí Ó bá sì gbèrò oore kan pẹ̀lú rẹ, kò sí ẹni tí ó lè dá oore Rẹ̀ padà. Ó ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. Suuratu Yuunus: 107.

 ·       Alloohu Oun ni Oluwa Onikẹ, Oun nikan ni Ẹni tí yóò ṣe iṣiro gbogbo ẹda ni ọjọ igbende nigba ti Yóò gbe gbogbo wọn dide lati inu saare wọn, ti Yíò sí san èèyàn kọọkan ní ẹsan pẹlu nkan ti o ba ṣe ninu dáadáa tàbí aidara, ẹnití o ba sì ṣe àwọn iṣẹ olóore ti o si jẹ Mu'mini, idẹkùn gbere n bẹ fún un, ati pe ẹnití o ba ṣe aigbagbo ti o si tun ṣe awọn iṣẹ aburu, iya ti o tobi n bẹ fún un ni ọjọ ìkẹhìn.

Alloohu Oun ni Oluwa Onikẹ, Oun nikan ni Ẹni tí yíò ṣe iṣiro gbogbo ẹda ni ọjọ igbedide nigba ti Yóò gbe gbogbo dide lati inu saare wọn, ti Yíò sí san èèyàn kọọkan ní ẹsan pẹlu nkan ti o ba ṣe ninu dáadáa tàbí aidara, ẹnití o ba sì ṣe àwọn iṣẹ olóore ti o si jẹ Mu'mini, idẹkùn gbere n bẹ fún un, ati pe ẹni tí o ba ṣe aigbagbo ti o si tun ṣe awọn iṣẹ aburu, iya ti o tobi n bẹ fún un ni ọjọ ìkẹhìn. Ati pe ninu pipe déédéé Ọlọhun ti mimọ n bẹ fún Un ti ọla Rẹ sì tún ga ati ọgbọn Rẹ ati ikẹ Rẹ pẹlu awọn ẹda Rẹ ni wipe O ṣe ayé yìí ni ilé iṣẹ, ti O sí ṣe ilé keji ni nkan ti ẹsan ati iṣiro máa wáyé ni ibẹ; titi ti olusedaadaa o fi gba ẹsan dáadáa rẹ, ti olùṣe aidaa, alabosi ati olukoja ààlà o si jẹ ìyá ikọja ààlà ati abosi rẹ; ati pe dajudaju àlámọrí yìí awọn ẹmi kan le máa ro wipe ko sunmọ ki o ṣẹlẹ, nitori naa, Ọlọhun ti fi awọn ẹri ti o pọ lelẹ ti wọn tọka sí wipe dajudaju igbedide òdodo ni ko si iyemeji ni inú rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó jí i, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Suuratun Fussilat: 39. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fun yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí ó máa kú (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn t’ó dára jáde. Suuratul Hajj: 5. Alloohu Oba Ododo so ninu āyah yìí awọn ẹri làákàyè meta ti ntọka sí igbedide, awọn naa ni:

Dajudaju ọmọniyan Olohun da a ni igba àkọ́kọ́ lati ara erupẹ, Ẹni tí O da a lati ara erupẹ Oun naa ni Olukapa lati da a pada si aaye nigba ti o ba di erupẹ.

Ẹni tí O da eeyan lati ara omi lọ́gbọ́lọ́gbọ́, O kapa lati da ọmọniyan pada si aaye lẹ́yìn iku rẹ.

Dajudaju Ẹni tí Ó ye ilẹ̀ pẹ̀lú òjò lẹ́yìn iku rẹ, O ni ikapa lori jiji àwọn eeyan lẹ́yìn iku won, ati pe o wa ninu aaya yii ẹ̀rí ti o tobi lori ikagara Kuraani bá ẹni tí ó bá fẹ́ mú irú rẹ̀ wá. Ati pe bawo ni aaya yii ṣe ko sinu- ti ko si kii ṣe nkan ti o gun- àwọn ẹ̀rí laakaye mẹta ti o han lori ọrọ kan ti o tobi.

Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bí kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀. Suuratul Anbiyaah: 104 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa. Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: "Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?" Sọ pé: "Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá. Suuratu yāsīn: 78-79. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ? Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé. Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde. Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn (30). Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀. Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin (32). Suuratun Nāziāt: 27-30. Oba Ododo sí ṣe alaye wipe dajudaju iseda èèyàn ko ni agbara to iseda sanmọ ati ilẹ ati nkan ti o wa laarin mejeeji. Nitori naa, Ẹnití o kapa lati da awon sanmọ ati ilẹ ko lee kagara lati da ọmọnìyàn pada ni eekeji.

 ·       Alloohu ti mimọ n bẹ fún Un ti ola Re Si tun ga da Anobi Ādam lati ara erupẹ, O wa je ki awon aromodomo re o maa po si leyin re. Nitori naa, awọn èèyàn patapata bákan náà ni won ni ipilẹ wọn, ko sì ọlá fún iran kan lori iran kan, ko sì tun sí fún ìjọ kan lori ijọ kan ayaafi pẹlu ìbẹrù Alloohu

Alloohu ti mimọ n bẹ fún Un ti ola Re Si tún ga da Anobi Ādam lati ara erupẹ, O wa je ki awon aromodomo re o maa po si leyin re. Nitori naa, awọn ènìyàn patapata bákan náà ni won ni ipilẹ wọn, ko sì ọlá fún iran kan lori iran kan, ko sì tun sí fún ìjọ kan lori ijọ kan ayaafi pẹlu ìbẹrù Alloohu. Alloohu ti ola Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán. Suuratul Hujirōt: 13. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A ò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A ò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu. Suuratu Fātir: 11. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè. Suuratu Gāfir: 67. Ati pe Alloohu ti ola Rẹ ga sọ ni Ẹni tí n se alaye wipe dajudaju Oun da Al-Masīh pẹlu aṣẹ wí bẹ́ẹ̀ jẹ bẹẹ,  gegebi O se da Ādam pẹlu aṣẹ wí bẹ́ẹ̀ jẹ bẹẹ, Alloohu ti ola Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀. Aal Im’raan/59 Ati pe mo ti so saaju nibi ìpínrọ keji (2) wipe dajudaju Anabi - kí ike ati ola Olohun máa bá a - se alaye wipe dajudaju ọmọnìyàn bákan náà ni won ti ko sì ọlá fún enikan lori ẹnikan ayaafi pẹlu ìbẹrù Alloohu.

 ·       Ati pe gbogbo ọmọ kọọkan ní won bi sí inú adamọ (Esin Islaam).

Ati pe gbogbo ọmọ kọọkan ní won bi sí inú adamọ (Esin Islaam), Alloohu ti ola Rẹ ga sọ pe: Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sì sí ìyípadà fún ẹ̀dá Allāhu. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀. Suuratur Rūm: 30. Ati pe Al-Haneefiyyah oun ni ilana Anabi Ibraheem Ààyò Olohun - kí ola ko máa bá a - Alloohu ti ola Rẹ ga sọ pe: Lẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ. Suuratun Nahl: 123. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Ko si ọmọ Kankan ti wọn bi ayaafi ki wọn o bi i si ori adamọ (Esin Islaam), obi re mejeeji ni wọn yóò sọ ọ di Yahudi, tabi ki wọn o sọ ọ di Nasorah, tabi ki wọn o sọ ọ di Majuusiy, gẹgẹ bi ẹranko  ṣe maa n bi ẹranko ti gbogbo ẹ̀yà ara rẹ pe, ti e o si nii ri adinku Kankan ni ara rẹ”. Leyin náà Abu Uroyrah - ki Olohun ọ yónú sí i - n sọ pé: ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sì sí ìyípadà fún ẹ̀dá Allāhu. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀. Suuratur Rūm: 30. Sohiihu ti Al-Bukhaar 4775 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Ẹ tẹti, dajudaju Oluwa mi pa mi ni ase ki n fi mo yin nkan ti é ṣe aimokan nipa re ninu nkan ti O fi mo mi ni òní mi, gbogbo dukia ti Mo ba fi tọrẹ fún ẹrú kan ẹtọ ni fún un, ati pe dajudaju Mo da awon eru Mi ni Musulumi, ni àwọn èṣù ba wa ba won ti won sì mu wọn lọ kuro ninu ẹsin wọn, ti won sì se nkan ti Mo se ni ẹtọ ni eewọ fún wọn, ti won sì tún pa won ni àṣẹ kí wọn o mu nǹkan ti Mi o sọ ẹ̀rí kankan kalẹ fún ni orogun pẹlu Mi. Muslim ni o gba a wa 2865.

 ·       Ko sí ẹnikeni ninu awọn eeyan ti won bi ni ẹlẹsẹ,  tabi eniti n jogun ẹsẹ ẹnití ọ yato sí i.

Ko sí ẹnikeni ninu awọn ènìyàn ti won bi ni ẹlẹsẹ,  tabi eniti n jogun ẹsẹ ẹni tí ọ yato sí i, ati pe Oba Alloohu ti ola Re ga ti fún wa ní ìró nipa wipe dajudaju Anabi Ādam - kí ola ko máa bá a - nigba ti o yapa àṣẹ Ọlọhun ti oun pelu iyawo rẹ Awahu sí je ninu èso igi, o ka abamo o si tuuba o si beere aforijin Ọlọhun, Olohun wa fi mo on ki o maa wí awọn gbólóhùn kan ti o daa, o si wí i, Ọlọhun si gba tuuba awọn mejeeji, Olohun ti ola re ga sọ pe: A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.” Àmọ́ Èṣù yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: "Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fun yín lórí ilẹ̀ fún ìgbà (díẹ̀).” Lẹ́yìn náà, (Ànábì) Ādam rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run. A sọ pé : “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́. Suuratul Baqorah (35-38). Ati pe nigbati Olohun ti gba tuuba Anabi Ādam - kí ola ko máa bá a - won o ka a sì ẹnití o ni ese mo, lati igba yen, aromodomo rẹ o le jogún ẹ̀ṣẹ̀  ti o ti yẹ kuro pẹlu tituubah. Ati pe ipilẹ ni wipe ọmọnìyàn o le ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí o yato sí i, Olohun ti ola Re ga sọ pe: Ẹ̀mí kan kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí Suuratul Anām: 164.

Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹnikẹ́ni t’ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì ṣìnà, ó ń ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. A ò sì níí jẹ àwọn ẹ̀dá níyà títí A fi máa gbé òjíṣẹ́ kan dìde (sí wọn). Suuratul Isrāi: 15. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan. Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá. Suuratu Fātir: 18.

 ·       Ati pe nǹkan ti a torí rẹ dá àwọn ènìyàn naa ni: Jijosin fún Olohun ni Oun nikan.

Ati pe nǹkan ti a torí rẹ dá àwọn ènìyàn naa ni: Jijosin fún Olohun ni Oun nikan soso. Olohun ti ola Rẹ ga sọ pe: Ati wipe mi o da awọn alijannu ati awọn eeyan (fun nkan miran) bi kii ṣe ki wọn le maa sin Mi Suuratudh Dhāriyāt: 56.

 ·       Islam pon omoniyan le- ati okunrin ati obinrin- o si se agbateru fun un nibi gbogbo iwo re, o si se e ni ẹni tí won o bi leere nípa gbogbo awọn nkan ti o sesa re fúnra rẹ àti àwọn iṣẹ rẹ ati awọn ìwà rẹ, o si tun n dì ru u abajade eyikeyi iṣẹ ti o ba le fi ko inira ba ẹ̀mi ara rẹ tabi ti o le ko inira ba elomiiran.

Esin Islaam pọn ọmọnìyàn le - okunrin ati obinrin - nitori naa, Oba Alloohu ti ola Rẹ ga da ọmọnìyàn ki o le je arole lori ilẹ, Olohun ti ola Rẹ ga sọ pe: (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀. Suuratul Baqorah: 30.

Apọnle yìí kò gbogbo ọmọ Anọbi Ādam sinu, Olohun ti ola Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí A dá. Suuratul Isrāi: 70 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ. Suuratur Tīn: 4.

Olohun kọ̀ fún ọmọnìyàn kuro nibi ki o sọ ara re di omoleyin eniyepere fún olùjọsìn fún kan tabi ẹni ti wọn n tẹ̀lé kan, tabi ẹni tí wọ́n n tẹ̀lé àṣẹ rẹ kan leyin Alloohu, Olohun ti ola Rẹ ga sọ pe: Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ (tó yẹ kí wọ́n ní sí) Allāhu. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàbòsí lè rí ìgbà tí wọ́n máa rí Ìyà náà ni, (wọn ìbá mọ̀ pé) dájúdájú gbogbo agbára ń jẹ́ ti Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.(Rántí) nígbà tí àwọn tí wọ́n tẹ̀lé (nínú àìgbàgbọ́) máa yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó tẹ̀lé wọn; (nígbà tí) wọ́n bá fojú rí Ìyà, tí ohun t’ó so wọ́n pọ̀ sì já pátápátá. Suuratul Baqorah: 165-166. Olohun ti ola re ga sọ ti O fi n se alaye isesi awon omoleyin ati awọn ti won n tẹ̀lé pelu ibaje ni ojo igbende: Àwọn t’ó ṣègbéraga yó sì wí fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ pé: “Ṣé àwa l’a ṣẹ yín lórí kúrò nínú ìmọ̀nà lẹ́yìn tí ó dé ba yín? Rárá o! Ọ̀daràn ni yín ni.” Àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ yó sì wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Rárá! Ète òru àti ọ̀sán (láti ọ̀dọ̀ yín lókó bá wa) nígbà tí ẹ̀ ń pa wá ní àṣẹ pé kí á ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí á sì sọ (àwọn kan) di ẹgbẹ́ Rẹ̀.” Wọ́n fi àbámọ̀ wọn pamọ́ nígbà tí wọ́n rí ìyà. A sì kó ẹ̀wọ̀n sí ọrùn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́? Suuratu Sabai: 32 - 33.

Ati pe ninu pípé deede Olohun ti mimọ n bẹ fún Un ti ola Rẹ sì tún ga ni ojo igbedide ni ki awon olupepe ati awọn asiwaju asọninu o ru awọn ẹsẹ wọn ati awọn ẹsẹ awon ti won ṣì lọ́nà ti ko sì ìmọ fún wọn, Olohun ti ola Rẹ ga sọ pe: (Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú. Suuratun Nahl: 25.

Ati pe Islaam ti se agbateru fún ọmọnìyàn gbogbo iwọ̀ rẹ ní ayé àti ní ọjọ ìkẹhìn, ati pe eyi ti o tobi julọ ninu awọn iwọ̀ ti Islaam se agbateru re ti o si se alaye re fún ọmọnìyàn ni: Iwọ̀ Olohun lori ọmọnìyàn ati iwọ̀ ọmọnìyàn lori Olohun Nitori naa, won gba wa lati ọdọ Muādh - ki Olohun yonu sí i - o sọ pe: Mo wa leyin Anobi - kí ike ati ola Olohun máa bá a - lori nkan ọ̀gùn, o wá so pe: Irẹ Muādh, mo sọ pe: Mo n jẹ ipe rẹ oriire sì ni ti e, leyin náà o so nkan ti o jo bee ni èèmeta: "Ǹjẹ́ o mọ iwọ̀ Olohun lori awon ẹrú?", mo sọ pé: Rárá, o sọ pe: "Iwọ̀ Olohun lori awon eru ni ki won o maa josin fún Un ki wọn o si ma mu nkankan mii mo on ni orogun", leyin náà o rin fun wákàtí kan, ni o wá sọ pe: "Irẹ Muādh", mo sọ pé: Mo n jẹ ipe rẹ oriire sì ni ti e, o sọ pe: Ǹjẹ́ o mo iwọ̀ awon eru lori Olohun ti won ba ti se ìyẹn: Oun naa ni ki O ma fi iya jẹ won". Sọhiihu ti Buhari 6840

Islaam se agbateru fún ọmọnìyàn ẹsin re ti o jẹ ododo ati aromodomo re ati dukia rẹ ati omoluabi rẹ. O sọ – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a– pe: "Dajudaju Olohun se ni eewọ lẹ yin lori, awon ẹjẹ yín, àti àwọn dukia yin, ati awọn omoluabi yin, gegebi jije eewọ ọjọ yin yii, ni oṣù yin yii, ni ilu yin yii. Sọhiihu ti Buhari 6501 Ati pe dajudaju Òjíṣẹ Ọlọhun - kí ike ati ola Olohun máa bá a - ti Kede adehun ti o tobi yii nibi Hajj idagbere eleyi ti awọn ti won le ni ẹgbẹ̀rún lọna ọgọ́rùn-ún ninu awon saabe gaani rẹ, o si tun paara itumo yii, o si tun kanpá mọ ọn ni ọjọ́ ìgúnran ninu Hajj idagbere.

Islaam se ọmọnìyàn ni ẹni tí won o bi leere nípa gbogbo awọn nkan ti o sesa re fúnra rẹ àti àwọn iṣẹ rẹ ati awọn ìwà rẹ, Olohun ti ola Rẹ ga sọ pe: Ènìyàn kọ̀ọ̀kan ni A ti la àyànmọ́ àti ìwé iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀. Suuratul Isrāi: 13 Iyẹn ni wipe nkan ti o ba ṣe ninu dáadáa tàbí aburu Ọlọhun a jẹ ki o wa pẹ̀lú rẹ ti ko sì ni tayọ rẹ̀ lọ sí ọdọ ẹni tí o yatọ sí i, nitori naa wọn o nii se isiro rẹ pẹlu iṣẹ ẹnití o yatọ sí i, won o si ni se isiro ẹnití o yatọ sí i pẹlu iṣẹ rẹ. Ọlọhun ti ola Rẹ ga sọ pe: Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀. Suuratul Inshiqōq: 6 Allah tun sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn. Fussilat:46

Ati pe Islaam n dì ru ọmọnìyàn abajade eyikeyi iṣẹ ti o ba le fi ko inira ba ẹ̀mi ara rẹ tabi ti o le ko inira ba elomiiran, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, ó dá a fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. Suuratun Nisāi: 111 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Suuratul Māidah: 32. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Won o nii pa ẹ̀mi kan ni ti abosi ayaafi ki ipin kan ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ o maa bẹ lori ọmọ Anabi Ādam alakọkọ, torípé oun ni ẹni akọkọ ti o fi ilana pipa èèyàn lelẹ. Sohiihu Muslim: 5150

 ·       Islaam se okunrin ati obinrin ni deede ara wọn nibi iṣẹ ati ojuse ati ẹsan.

Islaam se okunrin ati obinrin ni deede ara wọn nibi iṣẹ ati ojuse ati ẹsan, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn l’ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí èékán kóró dàbínù fún wọn. Suuratun Nisāi: 124 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t’ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn. Suuratun Nahl: 97. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè àrísìkí fún wọn nínú rẹ̀ láì la ìṣírò lọ. Suuratu Qāfir: 40. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùpáyà Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùpáyà Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n. Suuratul A'azāb: 35.

 ·       Islaam pọn obìnrin le, o si ka wọn kun pe bákan náà ni wọ́n ṣe ri pẹ̀lú awọn ọkunrin, o si ṣe inawo ni dandan lori ọkùnrin ti o ba ni ikapa, ìnáwó ọmọbìnrin jẹ dandan lori bàbá rẹ, ti ìyá si jẹ dandan lórí ọmọkùnrin rẹ tí ó bá ti bàlágà ti o si ni ikapa, ti ìyàwó si jẹ dandan lori ọkọ rẹ.

Islam ka àwọn obìnrin kun pe bákan náà ni wọ́n ṣe ri pẹ̀lú awọn ọkunrin Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ pe: "Dajudaju awọn obinrin ri bákan náà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin" Tirmiziy ni o gba a wa (113)

Ninu apọnle Islaam fún obìnrin ni wipe Islaam ṣe inawo ìyá ni dandan lori ọmọ rẹ ti o ba jẹ ẹnití o ni ikapa. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Ọwọ tí ba n fún ni òkè ni máa n gbe, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ti ninawo le wọn lórí kàn ọ́: ìyá rẹ, ati baba rẹ, ati ọmọ'ya rẹ l'obinrin, ati ọmọ'ya l'ọkunrin, ati awọn ẹbí rẹ ti wọn sunmọ ọ jù, lẹ́yìn náà àwọn ti wọn tun sunmọ ọ tẹ̀lé wọn". Imaamu Ahmad lo gba a wa. Ati pe alaye ipo awọn òbí mejeeji sí n bọ pẹlu iyọnda Ọlọhun ni ìpínrọ ẹ̀lẹẹ̀kọkandìnlọgbọ̀n (29).

Ati pe ninu apọnle Islaam fún obìnrin ni wipe o ṣe e ni dandan fún ọkọ láti maa náwó lórí ìyàwó rẹ ti o ba jẹ ẹni tí o ni ikapa, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Kí ọlọ́rọ̀ ná nínú ọrọ̀ rẹ̀. Ẹni tí A sì díwọ̀n arísìkí rẹ̀ fún (níwọ̀nba), kí ó ná nínú ohun tí Allāhu fún un. Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi n̄ǹkan tí Ó fún un. Allāhu yó sì mú ìrọ̀rùn wá lẹ́yìn ìnira. Suuratut Tolāq: 7 Arakunrin kan bi Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá - leere wipe: Kí ni iwọ ìyàwó lórí ọkọ rẹ? O sọ pe: "kí ọ maa fún ùn ni oúnjẹ nígbà tí o ba n jẹun, kí o si tun máa fún ùn ni aṣọ wọ nígbà tí o ba n wọ aṣọ, ati pe oo gbọdọ gba a ni oju, oo sì gbọdọ sọ ọrọ burúkú sí i. Imaamu Ahmad lo gba a wa. Òjíṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ l'ẹniti n ṣe alaye díẹ̀ ninu awọn iwọ awọn obinrin lórí àwọn ọkọ wọn. O pon dandan le yin lori fun awon iyawo yin jije mimu won ati aso wiwo won pelu daadaa (ohun ti e ti ba saaba) Sohiihu ti Muslim O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: O ti to ni ẹ̀ṣẹ̀ fun omoniyan ki o fi eniti o n fun ni ounje rare. Imaamu Ahmad ni o gba a wa. Al khatoobiy so wipe: Gbolohun re ti o so pe: “mon yaquut” ohun ti o gba lero ni eniti jije-mimu re je dandan le e ni ori, atipe itumo re dabi wipe o so fun olutọrẹ wipe: ma se tore pelu nkan ti ko to awon ara ile re je ni ajeseku leniti o n reti ẹsan pelu re; iyen le pada di ese ti o ba fi won rare.

Ninu aponle ti Islaam se fun obinrin ni wipe o se inawo omobinrin ni dandan lori baba re, Oba Alloohu ti ola Re ga so wipe: Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà t’ó dára Suuratul Baqorah: 233 Alloohu wa se alaye wipe o je dandan lori baba ti won bi omo fun, fifun omo  re ni ounje ati aso pelu daadaa (nkan ti won ti ba saaba). Ti won ba ba yin fun omo ni oyan, ki e ya fun won ni awon owo oya won. Suuratut Tolaaq: 6. Alloohu wa se owo oya ifun omo ni oyan ni dandan lori baba; o wa toka si wipe inawo omo lori baba lo wa, ati wipe gbolohun Alwaladu (omo) o ko okunrin ati obinrin sinu. Atipe o nbe ninu hadith ti o n bo yii itoka lori jije dandan inawo iyawo ati omo re lori baba. Lati odo Aaisha – ki Alloohu yonu si i -: dajudaju arabinrin Hindu so fun Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – wipe: dajudaju baba Sufyaan je enikan ti o ni ahun,  ti mo si maa n bukaata si ki n mu ninu owo re, o so pe (Anabi): “Mu ninu owo re nkan ti yóò to iwo pelu omo re ni ibamu si nkan ti e ti ba saaba. Bukhaari ni o gba a wa. Anabi  ti o je ọlọrẹ naa si se alaye ola ti n be fun nina owo lori awon omobinrin ati awọn ọmọ-ìyá lobinrin, Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – wa so wipe: “Enikeni ti o ba toju omobinrin meji tabi meta, tabi ọmọ-ìyá lobinrin meji tabi meta titi ti won fi ja kuro lodo re (boya won ku ni tabi won ni oko), tabi ki o ku saaju won, emi pelu re o wa bayii. O (Anabi) wa se apejuwe wiwapo won pelu ika ifabela re ati ti aarin. As silsilah As sohiiha 296.

 ·       Iku kii se titan gbere,  ati pe iku a maa pa ara ati emi, iku emi si ni pipinya re kuro ni ara, leyin naa yoo pada si ara leyin igbedide ojo Alukiyaamọ,  ati pe Emi o ni bo si ara miran leyin iku ko si nii pada sinu ara mii (akudaaya).

Iku kii se titan gbere, Olohun ti Ola Re ga so wipe: Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A fi tì yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.” Suuratus Sajdah: 11 Atipe iku a maa pa ara ati emi, iku emi si ni pipinya re kuro ni ara, leyin naa yio pada si ara leyin igbedide ojo Alukiyaamọ, Olohun ti Ola Re ga so wipe: Allāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀. Suuratuz Zumar: 42. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Dajudaju ti won ba ti gba emi irina naa maa n tele e”. Muslim ni o gba a wa pelu ẹgbawa rẹ mejeeji Ati pe leyin iku omoniyan o kuro ni ile iṣẹ́ lo si ile ẹsan, Olohun ti Ola Re ga so pe: Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Suuratu Yuunus: 4

Ati pe ẹ̀mí o ni bo si ara miran leyin iku ko si da (akudaaya), pipe apemora akudaaya si je nkan ti laakaye ati igbọnmọ ko tọka si, ati pe ko si egbawa Kankan ti o n jẹrii si adisokan yii lati odo awon Anabi Olohun – ki alaafia maa je ti gbogbo won.

 ·       Islaam n pepe lo si ibi nini igbagbo pelu awon ipile igbagbo ti o tobi, awon naa ni nini igbagbo si Olohun ati awon Malaaika Rẹ, ati nini igbagbo si awon iwe Olohun gẹ́gẹ́ bíi Taoreeta ati Injiila ati Zabuura – siwaju ki won o to yi oro inu won pada – ati Alukurani, ati nini igbagbo si gbogbo awon Anabi ati awon Ojise- ki ola maa ba gbogbo won- ati ki a ni igbagbo si ẹni ti o kẹyin won, oun naa ni Muhammad Ojise Olohun, igbeyin awon Anabi ati awon Ojise, ati nini igbagbo si ojo ikẹyin, ki a si tun mo wipe kani isemi ile-aye je opin ni; ere ponbele ni isemi ati bibẹ o ba jẹ, ati nini igbagbo si kadara.

Islaam n pepe lo si ibi nini igbagbo si awon ipile igbagbo ti o tobi, eleyi ti gbogbo awon Anabi ati Ojise – ki ola o maa ba won – pepe si, awon naa ni:

Alakoko: Nini igbagbo si Alloohu ni Oluwa, Adeda, Olupese-arisiki, Oludari-aye, ati pe Oun nikan ni O lẹ́tọ̀ọ́ si ijosin, ati pe jijosin fun gbogbo nkan ti o ba ti yato si I ibaje ni, ati pe gbogbo nkan ti won ba n josin fun yato si I ibaje ni, ijosin o si lẹ́tọ̀ọ́ ayaafi fun Un, ijosin o si le daa ayaafi fun Un. Alaye awon eri oro yii si ti saaju nibi ipinrọ kejo (8).

Olohun – mimo fun Un – daruko awon ipile ti o tobi yii ninu awon aaya ti o pọ ni ààyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ninu AL-Quraan ti o tobi, ninu re ni gbólóhùn Olohun ti O so pe: Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.” Suuratul Baqara: 285 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Kì í ṣe ohun rere ni kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni t’ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ànábì. Tòhun ti ìfẹ́ tí olùṣe-rere ní sí owó, ó tún ń fi owó náà tọrẹ fún àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù, onírìn-àjò (tí agara dá), àwọn atọrọjẹ àti (ìtúsílẹ̀) l’óko ẹrú. (Ẹni rere) yó máa kírun, yó sì máa yọ Zakāh. (Ẹni rere ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn wọn ṣe nígbà tí wọ́n bá ṣe àdéhùn àti àwọn onísùúrù nígbà àìríná-àìrílò, nígbà àìlera àti l’ójú ogun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe (iṣẹ́) òdodo. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùbẹ̀rù (Allāhu). Suuratul Baqara: 177 Alloohu si pepe lo si ibi nini igbagbo si awon ipile yii, O si tun se alaye wipe eniti o ba se aigbagbo si i, o ti sina ni isina ti o jina tefetefe, Oba Alloohu ti ola Re ga so pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà tefétefé. Suuratun-Nisai: 136. Ninu Hadith ti o wa lati ọdọ Umar omo Al-Khatoob – ki Alloohu ba wa yonu si i – o so pe: Laarin igba ti a joko si odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ni ojo kan, ni arakunrin kan ba wole to wa wa, aso re si funfun gboo, irun ori re si dudu kirikiri, ko si apere arinrin-ajo Kankan lara re, enikankan o si mon on ninu wa. Titi ti o fi joko si odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o wa fi orunkun re mejeeji ti orunkun Anabi mejeeji, o si gbe owo re mejeeji le ori itan re mejeeji, o wa so pe: Ire Muhammad, fun mi niro nipa Islam. Ojise Olohun – ki ike ati ola Oloun maa ba a – wa so pe: ohun ti nje Islam ni ki o jeri wipe ko si oba Kankan ayafi Allaah ati pe Muhammad ojise Allaah ni, ki o si maa gbe irun duro, ki o si maa yo zakah, ki o si maa lo si ile Olohun ti o ba ni ikapa ipese ti o fi le lo. O so pe: ododo lo so. O wa ya wa lenu fun un, oun ni nbi i leere ibeere, oun lo tun nso fun un wipe ododo lo so! O so pe: fun mi niro nipa Al-Iimaan {Igbagbo}. O so pe: ki o gba Olohun Oba gbo ati awon Malaika Re ati awon tira Re ati awon ojise Re ati ojo ikehin, ki o si ni igbagbo si kadara daada re ni ati aida re. O so pe: ododo lo so. O so pe: fun mi niro nipa Al-I'isaan {Sise daada}. O so pe: ki o maa josin fun Olohun gegebi wipe o nri I, ti oo ba waa ri I dajudaju Oun ri o. O so pe: fun mi niro nipa As-saahah {Igbati aye a pare}. O so pe: eniti a nbi leere nipa re ko ni imo ju eniti o nbeere lo. O sope: fun mi niro nipa awon amin ti aa maa ri ti aye ba ti fe pare. O so pe: ki eru maa bi olowo re, ati ki o maa ri awon arin ma wo bata ati awon arin ihoho ati awon alaini ti won a maa fi ile giga se iyanran. Leyin naa ni o wa lo, ni mo wa ko ara ro die, leyin naa ni o wa so pe: ire Umar, nje o mo eniti o nbeere ibeere? Mo so pe: Olohun ati ojise Re nikan lo mo on, o so pe: dajudaju Jubriil ni o wa bayin lati wa fi esin yin mo yin. Sohiihu Muslim: 8 Ninu Hadith yii, Jubril – ki ola maa ba a – wa si odo Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o si bi i leere nipa awon ipo esin, awon naa si ni: Al-Islaam ati Al-Imaan ati Al-Ihsaan. Ojise ti nse Muhammad – ki ike ati ola Olohun maa ba a – si fesi fun un, leyin naa Anọbi Muhammad – ki ike ati ola Olohun maa ba a – fun awon saabe re – ki Olohun yonu si won –  ni iro wipe Jubril ni ẹni yẹn, o wa lati wa fi esin won mo won. Eleyii oun naa Esin Islaam ti o je oro atorunwa ti Jubril – ki ola o maa ba a – mu wa, ti Anọbi Muhammad – ki ike ati ola Olohun maa ba a – si mu un de etigbo awon eeyan, ti  awon saabe re – ki Olohun yonu si won – si ha a, won si tun mu un de etigbo awon eeyan leyin re.

Eleekeji: Ninu igbagbo si awon Malaika, ati pe awon (malaika) agbaye kan ti a ko fi oju ri ni won, Alloohu da won, O si se won lori aworan kan ti a se adayanri, O si gbe awon ise ti o tobi le won ni owo, ninu eyi ti o gbongbon julo ninu awon ise won ni mimu awon oro atorunwa de odo awon Ojise ati awon Anabi – ki ola o maa ba won – eniti o si gbonngbon julo ninu awon Malaaika ni Jubril – ki ola o maa ba a – ati pe ninu ohun ti o ntoka si sisokale Jubril pelu mimu imisi (wah’y) wa ba awon Ojise – ki ike ati ola o maa ba won – ni gbolohun Olohun ti ola Re ga ti o wi pe: (Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.” Suuratun Nahl: 2. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé. Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) ti wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́. As-Shuaraa' 192-196

Eleeketa: Nini igbagbo si awon Tira Olohun (Atorunwa) gegebi At-Taorah ati Al-Injiil ati Az-Zabuur – siwaju ki won to yi oro inu re pada – ati Al-Quraan, Olohun ti Ola Re ga so pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà tefétefé. Suuratun-Nisai: 136. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ Taorāh àti ’Injīl kalẹ̀ ní ìṣaájú. Ìmọ̀nà sì ni fún àwọn ènìyàn.1 Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.2 Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà t’ó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san. Suuratu Al Imraan: 3-4. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.” Suuratul Baqara: 285 Allah tun sọ pe: Sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa pẹ̀lú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.” Aal Im’raan/84

Eleekerin: Nini igbagbo si gbogbo awon Anabi ati awon Ojise – ki ola o maa ba won – ati nini adisokan pelu wipe dajudaju gbogbo won Ojise ni won lati odo Olohun ti won n mu awon afiranse Olohun ati esin Re ati ofin Re de etigbo awon ijo won, Olohun ti Ola Re ga so pe: Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.” Suuratul Baqorah: 136. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.” Suuratul Baqara: 285 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.” Aal Im’raan/84

Ati pe ki o si ni igbagbo pelu ikehin won, Oun naa ni Muhammad Ojise Olohun, igbeyin awon Anabi ati awon Ojise – ki ike ati ola o maa ba won – Olohun ti Ola Re ga so pe: (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì pé: (Ẹ lo) èyí tí Mo bá fun yín nínú Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) yóò dé ba yín; ó máa fi èyí t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí." Aal Im’raan/81

Esin Islaam se ni dandan nini igbagbo si gbogbo awon Anabi ati awon Ojise lapapo, o si tun se e ni dandan nini igbagbo si ikehin won, oun naa ni Ojise ti nse Muhammad – ki ike ati ola Olohun maa ba a – Olohun ti Ola Re ga so pe: Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Suuratul Ma’idah: 68. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlu-l-kitāb, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan t’ó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.” Aal Im’raan/64

Ati pe enikeni ti o ba se aigbagbo si Anabi kan, o ti se aigbagbo si gbogbo awon Anabi ati awon Ojise – ki ola o maa ba won – tori naa ni Olohun fi so ni Eni ti O n fun wa ni iro nipa idajo Re lori ijo Anabi  Nuuh – ki ola o maa ba a: Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Suuratush Shuarah: 105. Ohun ti a si mo ni wipe Anabi Nuuh – ki ola o maa ba a – ojise kan ko saaju re, toun ti bee nigbati awon ijo re pe e ni iro, ipe e ni iro won yii je ipe gbogbo awon Anabi ati Ojise ni iro; nitoripe ipepe won eyokan ni ogongo ti won si n pepe si eyokan ni.

Eleekarun: Nini igbagbo si ojo ikehin, oun naa ni ojo igbedide, ni ipari ile-aye yii, Olohun yoo pa Malaika to n jẹ Isroofiil – ki ola o maa ba a- ni ase ki o fun feere kíkú, ti gbogbo nkan ti Olohun ba si fe yoo si ku, Olohun ti Ola Re ga so pe: Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún ikú. Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn. Suuratu Zumar: 68. Ati pe ti gbogbo awon ti o wa ni awon sanmo ati awon ti won wa ni ile ba ti ku, dajudajun Olohun yoo ka awon sanmo ati ile ko gegebi o se wa ninu gbolohun Re ti O wipe: (Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bí kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀. Suuratul Anbiyaah: 104 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Wọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. Suuratuz Zumar: 67 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Alloohu – ti O biyi ti O gbonngbon – yoo ka awon sanmo ni ojo igbedide kóróbójó, leyin naa yoo gba won mu pelu owo otun Re, leyin naa ni yoo wa so pe: Emi ni Oba Onikapa gbogbo nkan, nibo ni awon afipamuni-aye wa? Nibo ni awon oluse-igberaga wa? Leyin naa yoo gba awon ile mu pelu owo alaafia Re, leyin naa yoo wa so pe:  Emi ni Oba Onikapa gbogbo nkan, nibo ni awon afipamuni-aye wa? Nibo ni awon oluse-igberaga wa? Muslim ni o gba a wa.

Leyin naa Olohun yoo pa Malaika ni ase ki o fọn feere ni eekeji, nigba naa ni won yoo dide ti won yoo si maa wo sun, Olohun ti Ola Re ga so pe: Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn. Suuratu Zumar: 68. Nigbati Olohun ba gbe awon eda dide, yoo ko won jo fun isiro. Olohun ti Ola Re ga so pe: (Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ t’ó rọrùn fún Wa. Suuratu Qof: 44. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní? Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni." Suratu Ghafir: 16 Ati pe ni ojo yii, Olohun yóò se isiro gbogbo eniyan patapata, yoo si gba esan fun eniti won bosi lowo eniti o bo o si, yoo wa san gbogbo eniyan ni esan pelu nkan ti o se, Olohun ti Ola Re ga so pe: Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́. Suuratu Gaafir: 17. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Suuratun Nisai: 40. Olohun ti Ola Re ga tun so pe: (Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.) Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i. Suuratu Zalzalah: 7-8. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò. Suuratul Anbiyaah: 47.

Leyin igbedide ati isiro, esan yoo sele, eni ti o ba ṣe daadaa, idekun gbere ti ko nii kúrò ni n be fun un, ẹni tí o ba se aburu ati aigbagbo, iya n be fun un. Olohun ti ola Re ga so pe: Gbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa nírọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún. Suuratul Hajj: 56-57. Ati pe a maa lọ mo wipe kani isemi ile-aye je opin ni; isemi ati bibe o ba je iranu ponnbele. Olohun ti Ola Re ga so pe: Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?” Suuratul Muh’minuun: 115.

Eleekefa: Nini igbagbo si kadara, oun ni wipe o je dandan nini igbagbo wipe Olohun ti ni imo nipa nkan ti o ti sele, ati nkan ti n sele lowo, ati nkan ti yoo pada sele ninu aye yii, ati pe Olohun ti kọ gbogbo nkan siwaju ki O to da awon sanmo ati ile. Olohun ti Ola Re ga so pe: Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú. Suuratul An’aam: 59. Ati pe dajudaju imo Olohun ti rokirika gbogbo nkan. Olohun ti Ola Re ga pe: Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ méje àti ilẹ̀ ní (òǹkà) irú rẹ̀. Àṣẹ ń sọ̀kalẹ̀ láààrin wọn nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àti pé dájúdájú Allāhu fi ìmọ̀ rọ̀gbà yí gbogbo n̄ǹkan ká. Suuratu Tolaq: 12. Ati pe dajudaju alamori Kankan o ni sele ni aye yii ayaafi ki Olohun ti gbero re ki O si ti fẹ ẹ, ki O si ti seda re, ki O si ti se awon okunfa re ni irorun. Olohun ti Ola Re ga so pe: (Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n. Suratul Furqan: 2 O si n be fun Un nibi iyen ijinle oye ti o peye, eleyi ti imo omoniyan o le de ibe. Olohun ti Ola Re ga so pe: Ìjìnlẹ̀ òye t’ó péye ni; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. suuratul Qomar: 5. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn t’ó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Suuratu Ruum: 27. Olohun Oba si tun royin ara Re pelu ọgbọ́n, O si pe ara Re ni Ọlọ́gbọ́n. Olohun ti Ola Re ga so pe: Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Aal Im’raan/18 Olohun ti Ola Re ga si tun so ni Eni ti O n fun wa ni iro nipa Anabi Eesa – ki ola Olohun ki o maa ba a – wipe yóò ba Olohun soro ni ojo igbedide leniti yoo maa so pe: Tí O bá jẹ wọ́n níyà, dájúdájú ẹrú Rẹ ni wọ́n. Tí O bá sì forí jìn wọ́n, dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Suuratul Maa’idah: 118. Olohun ti ola Re ga tun so fun Anabi Musa – ki ola Olohun maa ba a – nígbà ti O (Alloohu) pe e (Musa) ti o (Musa) wa ni ẹgbẹ òkè Tuur: Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Suuratu Naml: 9.

O si tun royin Al-Qur’aan ti o tobi pelu ogbon. Olohun ti ola Re ga so pe: ’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán. Suuratu Huud: 1. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ìyẹn wà nínú ohun tí Olúwa rẹ fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n (al-Ƙur’ān). Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu kí wọ́n má baà jù ọ́ sínú iná Jahanamọ ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀. Suuratul Is’raah: 39.

 ·       Àti pé awon Anabi Olohun won ti so won kuro nibi sise asise  – ki ola o maa ba won – nibi nkan ti won n mu de etigbo awon eeyan nipa Olohun, won si tun so won kuro nibi gbogbo nkan ti o ba ti tako laakaye tabi nkan ti iwa to dáa ba tako, ati pe awon Anabi Olohun won je eniti a ti la mimu awon ase Olohun de odo awon ẹrú Re bọ lọrun, ati pe awon Anabi Olohun ko si nkankan fun won ninu awon ìròyìn jijẹ oluwa tabi ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ si ìjọsìn; bi kii se pe abara ni won gegebi awon abara yoku ti Olohun si n mu imisi awon oro Re wa ba won.

Ati pe awon Anabi Olohun won ti so won kuro nibi sise asise– ki ola o maa ba won– nibi nkan ti won n mu de etigbọ awon eeyan nipa Olohun; toripe dajudaju Olohun maa n ṣẹsa àwọn ti o ba dáa jù nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ lati mu oro Re de etigbo awon eeyan. Olohun ti ola Re ga so pe: Allāhu l’Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran. Suuratul Hajj: 75. Allah tun sọ pe: Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn). Aal-Imraan 33 Allah tun sọ pe: (Allāhu) sọ pé: "Mūsā, dájúdájú Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Mi àti ọ̀rọ̀ Mi. Nítorí náà, gbá ohun tí Mo fún ọ mú. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́." Suuratul A’arof: 144. Ati pe awon Ojise – ki ike ati ola maa ba won – mo wipe nkan ti o n so kale wa ba won, imisi ti Olohun ni, won si tun maa n ri awon Malaaika nígbà ti won ba n sokale pelu imisi naa. Olohun ti ola Re ga so pe: Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà t’ó jẹ́ Òjísẹ́. Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀ nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan. Suuratul Jinn: 26-28. Olohun si tun pa won ni ase pelu mimu oro Re de etigbo awon eeyan. Olohun ti ola Re ga so pe: Ìwọ Òjíṣẹ́, fi gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ jíṣẹ́. Tí o ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jíṣẹ́ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (láti ṣe ọ́ ní aburú). Al-Maaidah 67 Allah tun sọ pe: (A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Suuratun Nisai: 165.

Awon Ojise Olohun – ki ike ati ola maa ba won – maa n bẹru Olohun ni iberu ti o ni agbara, won si maa n paya Re, won o lee fi kun awon oro Re, won o si yo kuro ninu re, Olohun ti ola Re ga so pe: Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni, Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún. Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀. Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa). Suuratul Aaqqah: 44-47. Ibnu Katheer – ki Olohun ke e – so pe: Olohun ti ola Re ga n so pe: Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan mọ́ Wa ni {iyen ni wipe: Muhammad – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ti o ba ri bi won se n lero ni, pe o je eniti n paro mo Wa, ti o wa se alekun nibi ise ti A fi ran an tabi o yo kuro ni inu re, tabi ki o so nkankan lati odo ara re, ki o wa se afiti re si odo Wa – leyiti ko si ri bi won se lero – A o ba kanju fi iya je e, iyen ni o faa ti O fi so pe}: Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún. {won so pe: itumo re ni wipe, A maa fi ìyà jẹ ẹ pẹ̀lú apa ọtun; toripe ìyẹn le gan ni ifiyajeni, awon kan ni: Itumo re ni wipe A máa gba a mu pelu owo otun re. Allah tun sọ pe: (Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l’o sọ fún àwọn ènìyàn pé: "Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?" Ó sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. N̄g ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sọ ohun kan fún wọn bí kò ṣe ohun tí O pa mí láṣẹ rẹ̀ pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín." Mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn níwọ̀n ìgbà tí mò ń bẹ láààrin wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí O gbà mí kúrò lọ́wọ́ wọn, Ìwọ ni Olùṣọ́ lórí wọn. Ìwọ sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan Suuratul Maaidah 116-117

Ninu ola Olohun ti o se fun awon Anabi Re ati awon Ojise Re – ki ike ati ola ki o maa ba won – ni pe Olohun fi ẹsẹ won rinle nibi mimu awon oro Re de etigbo awon eeyan. Olohun ti ola Re ga so pe: Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ (54) dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára (55). Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà. Huud 54-56 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn t’ó yàtọ̀ sí i nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò. Tí kò bá jẹ́ pé A fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ ni, dájúdájú o fẹ́ẹ̀ fi n̄ǹkan díẹ̀ tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn. Nígbà náà, Àwa ìbá jẹ́ kí o tọ́ ìlọ́po (ìyà) ìṣẹ̀mí ayé àti ìlọ́po (ìyà lẹ́yìn) ikú wò. Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tí ó máa gbà ọ́ sílẹ̀ níbi ìyà Wa. AL-ISROO 73-75 Àwọn aaya yii ati awọn eyi ti o siwaju re n jẹri, o si n tọ́ka si pe Kuraani nkan ti o sọkalẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo agbalaye ni; toripe ti o ba jẹ pe odo Anọbi Muhammad – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni o ti wa ni, i ba ti fi iru ọ̀rọ̀ ti o da oju rẹ kọ ọ yii sinu rẹ.

Ọlọhun Ọba ti ola Rẹ ga maa n sọ àwọn ojisẹ Rẹ kuro nibi aburu àwọn eeyan, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ìwọ Òjíṣẹ́, fi gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ jíṣẹ́. Tí o ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jíṣẹ́ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (láti ṣe ọ́ ní aburú). Al-Maaidah 67 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fun yín bá lágbara lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́. Yunus 71 Ọlọhun Ọba ti ola Rẹ ga sọ nípa anọbi Musa – ki àlàáfíà Ọlọhun maa ba a- pe: Àwọn méjèèjì sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-àlà.” Allāhu) sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín).” Too'haa 45-46 Ọlọhun Ọba ti ola Rẹ ga ṣàlàyé pe Oun maa sọ àwọn ojisẹ Rẹ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn ti wọn ko nii ri aburu kankan fi ṣe wọn, O tun sọ pe Oun maa dáàbò bo imisi Rẹ, wọn ko ni i le e kun, wọn ko si nii din-in ku, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: “Dajudaju Awa (Ọlọhun Allah)  ni a sọ Iranti (Alukurani) kalẹ, dajudaju awa naa ni Oludaabo bo o. Al-Hijr 9

Àwọn anọbi – ki ikẹ Ọlọhun máa bá wọn- ẹni tí a sọ kúrò níbi nkan ti o ba yapa làákàyè àti ìwà ni wọ́n, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ ni Eni ti n fọ anọbi Muhammad mọ wipe: Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé. Al-Qalam 4 O tun sọ bákan náà nípa rẹ̀ pé: Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè. At-Takwiir 22 Ìyẹn ri bẹẹ tori ki wọn le jẹ isẹ ti wọn ran wọn dáadáa, àwọn anọbi Ọlọhun si nìyí, A la jijise àwọn àṣẹ ti Ọlọhun ba pa fun awon ẹrú Rẹ bo wọn lọrun, wọn ko ni nkankan ninu ìròyìn jijẹ Oluwa tabi jijẹ ẹni tí o lẹtọ si ìjọsìn, abara ni wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn abara to ku, Ọlọhun maa n fi iṣẹ iranse Rẹ ranse si wọn, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: “Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fun yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé, Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé. Ibrahim 11 Ọlọhun tun sọ ni Eni ti n pa ojiṣẹ Rẹ Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) láṣẹ pe ki o sọ fún àwọn ìjọ rẹ pe: Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀.” Al-Kahf 110

 ·       Islam n pepe si ìjọsìn fun Olohun nìkan ṣoṣo pẹ̀lú àwọn ipilẹ ìjọsìn ńlá bii: IRUN ti o se pe oun naa ni diduro ati titẹ kọkọrọ ati fifi ori kanlẹ, ati iranti Ọlọhun ati yiyin-In ati adua, ọmọniyan yoo maa ki irun naa ni ẹẹmarun ni ojoojumọ, ko si si opinya kankan laarin awọn ti wọn n ki i, ati olówò ati talika, adarí ati ẹni tí wọ́n n dari, gbogbo wọn maa to ni saafu kan naa ninu irun. Bákan náà ni ZAKAT tii ṣe odiwọn kékeré ninu dukia ni ibamu si awọn májẹ̀mú ati ipebubu tí Ọlọhun ti pebubu rẹ, ti o jẹ dandan ninu dúkìá àwọn ọlọrọ, ti wọn maa yọ fun awọn alaini ati awọn mìíràn ni ẹẹkan ni ọdún. Bákan náà ni AAWẸ tí í ṣe kiko ẹnu ro nibi awọn nkan tii ba aawẹ jẹ ninu oṣu Ramadan, ni eyi ti o maa n re erongba ati sùúrù ninu ẹ̀mí. Bákan náà ni HAJJ tii ṣe lílọ si ilé Oluwa ni ilu Mẹka ni ẹẹkan ni ìgbésí ayé fun ẹni tí ó bá ni ikapa. Ninu Hajj yii, gbogbo èèyàn maa ri bákan náà nibi ìdojúkọ Ọlọhun Adẹda, ti ko si nii si pe ẹnikan wa ni ipò tí o ga ju ẹlòmíràn lọ.

Islam n pepe si ijọsin fun Ọlọhun pẹlu awọn ìjọsìn ńlá ati nkan ti o yàtọ̀ sí i nínú àwọn ìjọsìn. Àwọn ìjọsìn ńlá yii, Ọlọhun ṣe wọn ni ọranyan lori gbogbo àwọn anọbi ati awọn ojiṣẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn - eyi ti o tobi ju nínú àwọn ìjọsìn náà ni:

Akọkọ: IRUN, Ọlọhun ṣe e ni ọranyan lori awọn Musulumi gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe e ni ọranyan lori awọn anọbi ati awọn ojiṣẹ (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn). Ọlọhun pa anọbi Ibrahim tii ṣe aayo Rẹ láṣẹ pe ki o fọ ilé naa mọ fun àwọn tí wọn fẹ ṣe tawaf ati awọn olukirun ti wọn n tẹ kọkọrọ ti wọn si n fi ori balẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe Ilé (Kaaba) ní àyè tí àwọn ènìyàn yóò máa wá àti àyè ìfàyàbalẹ̀. Kí ẹ sì mú ibùdúró ’Ibrọ̄hīm ní ibùkírun. A sì pa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl láṣẹ pé “Ẹ ṣe Ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, àwọn olùkóraró sínú rẹ̀ àti àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún, àwọn olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun). Al-Baqara 125 Ọlọhun tun ṣe e ni ọranyan fun Musa nibi ipepe àkọ́kọ́ ti Ọlọhun pe Musa, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā. Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi. Suratu Ta-ha: 12-14. Anọbi Isa- ki ikẹ Ọlọhun máa ba a- sọ pe Ọlọhun pa oun láṣẹ irun ati zakat, o wa sọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ṣe fun wa ni iro pe: Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé). Maryam 31 Irun ninu Islam naa ni diduro ati titẹ kọkọrọ, ati iforikanlẹ ati iranti Ọlọhun ati yiyin-In ati adua, ọmọniyan yoo maa ki i ni ẹẹmarun ni ojoojumọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin. Kí ẹ sì dúró (kírun gẹ́gẹ́ bí) olùtẹríba fún Allāhu, láì níí sọ̀rọ̀ (mìíràn lórí ìrun). Al-Baqara 238 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Gbé ìrun kíkí dúró ní (ìgbà tí) òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí alẹ́ yóò fi lẹ́. Àti pé ìrun Subh, dájúdájú ìrun Subh jẹ́ ohun tí (àwọn mọlāika alẹ́ àti ọ̀sán) yóò jẹ́rìí sí. AL-ISROO 78 O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: “Ti ẹ ba ti wa ni rukuu ki ẹ gbe Ọluwa tobi nibẹ, ti ẹ ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ gbìyànjú láti ṣe adua nibẹ, nkan ti o tọ́ ni ki wọn gba adua yin Sohiihu ti Muslim

Ẹlẹẹkeji: Zakat, Ọlọhun ṣe e ni ọranyan lórí àwọn Musulumi gẹ́gẹ́ bí O ṣe ṣe e ni ọranyan fún àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ ti wọn ṣíwájú (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn), oun naa ni odiwọn kékeré nínú dúkìá ni ibamu si awọn májẹ̀mú ati awọn ipebubu ti Ọlọhun pebubu rẹ, ti o jẹ dandan ninu dúkìá àwọn ọlọrọ, ti wọn maa fun àwọn aláìní àti àwọn tí wọn yàtọ̀ si wọn ni ẹẹkan ni ọdun, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀. At-Taobah 103 Nígbà tí Anọbi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a – ran Muaz- ki Ọlọhun yọnu si i- lọ si Yemen, o sọ fun un pe: "Dájúdájú ìwọ yóò wa ba àwọn ìjọ kan ti a fun ni tira, pe wọn lọ sibi ijẹri pe ko si ẹni kankan ti o lẹtọ si ijọsin ni ododo ayafi Allaah, ati pe emi o, ojiṣẹ Ọlọhun ni mi, ti wọn ba ti wa tẹle ọ fun ìyẹn, jẹ ki wọn mọ pe Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ṣe irun wákàtí maarun ni ọranyan le wọn lori ni ojoojumọ, ti wọn ba ti wa tẹle ọ fun ìyẹn, jẹ ki wọn mọ pe Ọlọhun ṣe zakat yíyọ ninu dúkìá wọn ni ọranyan le wọ́n lori, wọ́n maa gba a lọ́wọ́ àwọn olowo wọn, wọn maa fun àwọn talika wọn, ti wọn ba ti wa tẹle ọ fun ìyẹn, sọra fun eyi ti o ba níye lórí ninu awọn dúkìá wọn, wa ṣọra fun ipepe ẹni tí a ṣe abosi fun, tori ko si gaga kankan laarin rẹ ati Ọlọhun " Tirmiziy ni o gba a wa (625)

Ẹlẹẹkẹta: AAWẸ, Ọlọhun ṣe e ni ọranyan fun àwọn Musulumi gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe e ni ọranyan fun àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ ti wọn ṣíwájú, kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu). Al-Baqara 183 Oun naa ni kiko ara ro kuro nibi awọn nkan to n ba aawẹ jẹ ni ọsan oṣu Ramadan. Aawẹ si nìyí, o maa n re erongba ati sùúrù sinu ẹ̀mí ni O sọ – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a– pe: "Olohun ti O biyi ti O gbọnngbọn n sọ wipe: Èmi ni mo ni aawẹ, Èmi naa si ni maa sẹsan rẹ, yoo fi adùn rẹ silẹ, ati jíjẹ rẹ, àti mimu rẹ, nítorí Mi, aawẹ si niyii, gaga ni o jẹ, ìdùnnú meji si ni o n bẹ fun alaawẹ: ikini nígbà tí ó bá fẹ́ ṣinu, ikeji ni nígbà tí ó bá maa pade Olúwa rẹ" Sohiihu ti Al-Bukhaar 7492

Ẹlẹẹkẹrin: AL-HAJJ, Ọlọhun ṣe e ni ọranyan fun àwọn Musulumi gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ṣe e ni ọranyan fun àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ ti wọn ṣíwájú – kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn - Ọlọhun wa pa Anọbi Ibrahim láṣẹ pe ki o pepe fun hajj, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀. Wọn yó sì máa gun àwọn ràkúnmí wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn Al-Hajj 27 Ọlọhun wa pa a láṣẹ pe ki o fọ Kaaba mọ fun àwọn alalaaji, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀. Al-Hajj 26

HAJJ: Oun naa ni lílọ si ile Olúwa ni Mẹka Alapọnle fun àwọn iṣẹ kan ti a mọ ni ẹẹkan ni ìgbésí ayé fún ẹni tí ó bá ni ikapa. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́,dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá. Aal Im’raan/97 Ni hajj ni àwọn alalaaji Musulumi ti maa n kójọ ni ààyè kan ṣoṣo lẹniti wọn n ṣe àfọ̀mọ́ ìjọsìn fun Adẹda. Gbogbo àwọn alalaaji maa n ṣiṣẹ́ hajj wọn ni ọna ti o jọra ti ko si ìyàtọ̀ agbegbe ati ọlaju ati isẹmi níbẹ̀

 ·       Lara àwọn nkan ti o maa n jẹ ki ìjọsìn o da yàtọ̀ ju nínú Islam ni àwọn ọna ti a n gba ṣe e, àti àwọn àsìkò rẹ, àti àwọn májẹ̀mú rẹ, Ọlọhun ṣe e ni òfin, O si mu u de ọdọ ojiṣẹ Rẹ, abara kankan ko si le e kun tabi din in ku titi di òní, gbogbo àwọn ìjọsìn ńlá ńlá yii ni gbogbo àwọn Anọbi naa pepe si, ki ọlà Ọlọhun lọ máa bá wọn.

Lara àwọn nkan ti o maa n jẹ ki ìjọsìn o da yàtọ̀ ju nínú Islam ni àwọn ọna ti a n gba ṣe e, àti àwọn àsìkò rẹ, àti àwọn májẹ̀mú rẹ, Ọlọhun ṣe e ni òfin, O si mu u de ọdọ ojiṣẹ Rẹ, abara kankan ko si le e kun tabi din in ku titi di òní, Olohun ti ola Re ga so pe: Mo parí ẹ̀sìn yín fun yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fun yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fun yín (Al'Maa'idah 3) Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām). Az-Zukhruf 43 Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ nípa irun pé : Nígbà tí ẹ bá parí ìrun, kí ẹ ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní ìdúró, ìjókòó àti ìdùbúlẹ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá sì fọkàn balẹ̀ (ìyẹn nígbà tí ẹ bá wọnú ìlú), kí ẹ kírun (ní pípé). Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. An-Nisa 103 Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ nípa àwọn ibi tí a maa yọ zakat si wipe: Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù, àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām, àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn t’ó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. At-Taobah 60 Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ nípa aawẹ pe: Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀ 1 (tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà 2 fún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ìlú rẹ̀ nínú yín nínú oṣù náà, 3 kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) ní àwọn ọjọ́ mìíràn. Allāhu fẹ́ ìrọ̀rùn fun yín, kò sì fẹ́ ìnira fun yín. Ẹ pé òǹkà (ọjọ́ ààwẹ̀), kí ẹ sì gbé títóbi fún Allāhu nítorí pé Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ fún Un. Al-Baqara 185 Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ nípa hajj pé : Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí A ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ dídá àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò t’ó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè. Al-Baqara 197 Gbogbo àwọn ìjọsìn ńlá yii ni gbogbo àwọn Anọbi pátá pepe si, ki ọlà Ọlọhun maa ba wọn

 ·       Ojiṣẹ ẹsin Isilaamu naa ni Muhammad ọmọ Abdullaah ti o wa nínú àwọn arọmọdọmọ Ismail ọmọ Ibrahim (ki ọlà Ọlọhun maa ba wọn). Wọn bi i si ìlú Mẹka ni ọdún 571 ti hijra, wọn gbe e dide ni ojiṣẹ nibẹ, o ṣi ṣe hijra lati ibẹ lọ sí ìlú Mẹdina. Ko ba àwọn ìjọ rẹ kópa nibi alaamọri oosa, ṣùgbọ́n ó máa ń ba wọn kópa nibi àwọn iṣẹ́ ti o gbọnngbọn. Ìwà rẹ dara ṣíwájú ki o to di ojiṣẹ ti àwọn ìjọ rẹ si maa n pe e ni olufọkantan. Ọlọhun gbe e dìde ni ojiṣẹ nigba ti o pe ọmọ ogoji ọdún, O si kun un lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn nkan ìyanu ńlá, eyi ti o tobi ju nínú rẹ naa ni Alukurani Alapọnle, oun si ni o tobi ju ninu awọn àmì àwọn Anọbi, oun naa ṣi ni àmì ti o n ṣẹku ninu awọn àmì àwọn Anọbi títí di òní. Nígbà tí Ọlọhun pe ẹsin fun un, ti ojiṣẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- náà si jẹ ẹ bi o ṣe tọ ati bí ó ṣe yẹ, o kú ni ọmọ ọdún mẹta lé ni ọgọta, wọ́n sin in sí ìlú Mẹdina, oun si ni igbẹyin àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ, Ọlọhun gbe e dìde pẹ̀lú imọna àti ẹsin òdodo, lati mu àwọn ènìyàn kúrò nínú òkùnkùn ibọrisa, aigbagbọ, ati aimọkan, lọ sibi imọlẹ imọ Ọlọhun lọkan ati ìgbàgbọ́, Ọlọhun si jẹri si i pe Oun ni Oun gbe e dìde láti maa pepe sibẹ pẹ̀lú iyọnda Rẹ.

Ojiṣẹ ẹsin Isilaamu naa ni Muhammad ọmọ Abdullaah ti o wa nínú àwọn arọmọdọmọ Ismail ọmọ Ibrahim (ki ọlà Ọlọhun maa ba wọn). Wọn bi i si ìlú Mẹka ni ọdún 571 ti hijra, wọn gbe e dide ni ojiṣẹ nibẹ, o ṣi ṣe hijra lati ibẹ lọ sí ìlú Mẹdina. Àwọn eeyan rẹ máa ń pe e ni olufọkantan, Ko ba àwọn ìjọ rẹ kópa nibi alaamọri oosa, ṣùgbọ́n ó máa ń ba wọn kópa nibi àwọn iṣẹ́ ti o gbọnngbọn, o si ni ìwà ti o dara gan ṣíwájú ki o to di ojiṣẹ, Olúwa rẹ royin rẹ pẹ̀lú ìwà ti o dára gan, O sọ nípa rẹ̀ pe: Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé. Al-Qalam 4 Ọlọhun gbe e dide ni ojiṣẹ nígbà tí ó pé ọmọ ogójì ọdún, O si kun un lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àmì ńlá, èyí tí ó tóbi jù nínú rẹ̀ náà ni Kuraani Alapọnle Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Ko si Anọbi kan nínú àwọn Anọbi Ọlọhun afi kí Ọlọhun fun un ni àmì tí àwọn èèyàn a torí irú rẹ gba a gbọ, àmọ́ nkan ti wọn fún èmi ni imisi tí Ọlọhun mi i si mi, mo wa n ni ìrètí pé ki n jẹ ẹni tí olutẹle rẹ yóò pọ̀ ju nínú àwọn Anọbi ni ọjọ igbende alukiyaamọ" Sohiihul-Bukhaariy Alukurani ni imisi Ọlọhun si ojiṣẹ Rẹ- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- Ọlọhun sọ nípa rẹ pe: Èyí ni Tírà náà, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìmọ̀nà ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu); Al-Baqara 2 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nípa rẹ̀ pé: Ṣé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀. An-Nisaa 82 Ọlọhun pe àwọn alujannu ati awọn ènìyàn nija lati mu irú rẹ wa, Ọlọhun sọ pe: Sọ pé: “Dájúdájú tí àwọn ènìyàn àti àlùjànnú bá para pọ̀ láti mú irú al-Ƙur’ān yìí wá, wọn kò lè mú irú rẹ̀ wá, apá kan wọn ìbáà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún apá kan." AL-ISROO 88 Ọlọhun tún pe wọn nija lati mu suura mẹwa ninu irú rẹ wa, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo.” Huud 13 Ọlọhun tun pe wọn nija lati mu suura ẹyọkan bii irú rẹ wa, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa, nítorí náà, ẹ mú sūrah kan wá bí irú rẹ̀, kí ẹ sì pe àwọn ẹlẹ́rìí yín, yàtọ̀ sí Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo. Al-Baqara 23

Alukurani nìkan ni àmì ti o ṣẹku nínú àwọn àmì àwọn Anọbi títí di òní, nígbà tí Ọlọhun pé ẹsin fun ojiṣẹ Rẹ ti ojiṣẹ naa si jẹ bi o ṣe tọ àti bí ó ṣe yẹ, lẹ́yìn náà ni o ku ni ọmọ ọdún mẹ́ta lé ni ọgọta, wọ́n sì sin in si ìlú Mẹdina, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a.

Anọbi Muhammad- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni igbẹyin àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: (Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. Suratul Ahzab: 40 Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọ́nú si i- wípé ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Dájúdájú àpèjúwe mi ati àpèjúwe àwọn Anọbi ti wọn ṣíwájú mi, o da gẹgẹ bi àpèjúwe arákùnrin kan ti o kọ ilé kan dáadáa, ti o wa ku síbi ààyè bíríkì kan ni origun kan lára ilé náà, ti àwọn èèyàn wa bẹrẹ si nii rọkirika ilé náà ti wọn si n se eemọ latara rẹ, ti wọn wa n sọ pé ṣe wọn ko nii gbé bíríkì yii síbẹ̀ ni? O sọ pe: Èmi ni bíríkì náà, èmi ni òpin àwọn Anọbi" Sohiihul-Bukhaariy Nínú Bíbélì, Anọbi Isa- ki ọlà Ọlọhun maa ba a- sọ lẹniti n fun ni ni iro ìdùnnú nípa Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) Òkúta naa ti àwọn ọmọle kọ silẹ ni o wa di orí igun ilé náà, ṣé ẹyin ko ka nínú àwọn Tira naa pe: Anọbi Isa sọ fun wọn pe láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni èyí tí wá, eemọ si ni ó jẹ́ ni ojú wa. Ninu ìwé Taoreeta to n bẹ ni oni, o wa nínú ẹ pe Ọlọhun sọ fún Anọbi Musa pe: Maa gbé Anọbi kan bíi ìwọ dìde ni aarin àwọn ọmọ ìyá wọn, Maa fi ọrọ Mi si i lẹnu, yóò máa ba wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú gbogbo nkan ti mo ba pa a láṣẹ ki o sọ

Ọlọhun gbe Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- dide pẹ̀lú imọna ati ẹsin òdodo, Ọlọhun si jẹri si i pe orí òdodo ni o wa, ati pe Oun gbe  e dìde ni olupepe si òdodo pẹ̀lú iyọnda Rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ṣùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí. An-Nisaa 166 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí. Al-Fat'h 28 Ọlọhun gbe e dide pẹ̀lú imọna láti mu àwọn ènìyàn kúrò nínú àwọn òkùnkùn ibọrisa àti aigbagbọ ati aimọkan bọ sínú imọlẹ imọ Ọlọhun lọkan ati ìgbàgbọ́, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu ń fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìmọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àwọn n̄ǹkan) tí Allāhu yọ́nú sí, àwọn ọ̀nà àlàáfíà. (Allāhu) yó sì mú wọn jáde láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà (’Islām). Al-Maa'ida 16 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: ’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè mú àwọn ènìyàn kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa wọn. (Wọn yó sì bọ́) sí ọ̀nà Alágbára, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí), Ibrahim 1

 ·       Sheria Islam ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa naa ni òpin àwọn iṣẹ-riran ti Ọlọhun ati awọn òfin Rẹ, oun si ni òfin ti o pe ti dídára ẹsin ọmọniyan ati ayé rẹ n bẹ nibẹ, o si n sọ: Ẹsin àwọn èèyàn, ati ẹjẹ wọn, ati dúkìá wọn, ati làákàyè wọn, àti àwọn ọmọ wọn, o si ti pa gbogbo òfin ti o ṣíwájú rẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin tí ó ṣíwájú naa ṣe pa ara wọn rẹ.

Sheria Islam ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa naa ni òpin àwọn iṣẹ-riran ti Ọlọhun ati awọn òfin Rẹ, Ọlọhun si fi iṣẹ-riran yii pe ẹsin, ti idẹra si pari lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbígbé Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- dide ni Ojiṣẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Mo parí ẹ̀sìn yín fun yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fun yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fun yín. (Al'Maa'idah 3)

Òfin Islam ni òfin pípé ti dídára ẹ̀sìn ọmọniyan ati ayé wọn n bẹ nínú ẹ; torí pé ó kó gbogbo nkan to n bẹ nínú àwọn òfin tí ó ṣíwájú sínú ti o si pé wọn, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà, ó sì ń fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo t’ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san t’ó tóbi wà fún wọn. AL-ISROO 9 Òfin Islam wa gbe ẹrù wúwo ti wọn di ru àwọn ìjọ tí wọ́n saaju kúrò fún àwọn ènìyàn, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àwọn t’ó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa léèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn t’ó wúwo) àti àjàgà t’ó ń bẹ lọ́rùn wọn kúrò fún wọn; àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè. Al-A'rọọf 157

Òfin Islam ni o pa gbogbo òfin tí ó ṣíwájú rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn t’ó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fun yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fun yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí. Suratul Maidat: 48 Alukurani ti o ko òfin sínú wa láti jẹrii si èyí tí ó jẹ́ òdodo ninu awọn tira Ọlọhun ti o ṣíwájú, ati lati dajọ le wọn lori, ati lati pa wọn rẹ

 ·       Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii tẹ́wọ́ gba ẹsin kankan yàtọ̀ sí Islām ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa, ẹni tí ó bá gba ẹsin míràn yàtọ̀ sí Islām, wọn ko lee gba a lọ́wọ́ ẹ lailai

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii tẹ́wọ́ gba ẹsin kankan yàtọ̀ sí Islām ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa lẹ́yìn tí Ọlọhun ti gbe e dìde ni Ojiṣẹ, ẹni tí ó bá wa ẹsin míràn yàtọ̀ sí Islām, wọn kò nii gba a lọ́wọ́ rẹ lailai Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò. Aal-Imraan 85 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti kristiẹni) kò yapa ẹnu (sí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Ẹni t’ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́. Aal-Imraan 19 Islam yii ni ẹsin Anọbi Ibrahim tii ṣe ààyò Ọlọhun, ki ọlà Ọlọhun maa ba a, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ta sì ni ó máa kọ ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sílẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gọ ẹ̀mí ara rẹ̀. A kúkú ti ṣà á lẹ́ṣà n’ílé ayé. Dájúdájú ó tún wà nínú àwọn ẹni rere ní ọ̀run. Suratul Bakarat: 130 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ta l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́. Suratu Nisai: 125 Ọlọhun wa pa Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- láṣẹ ki o sọ pe: Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi ti fi ọ̀nà tààrà (’Islām) mọ̀ mí, ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.” Al-An'aam 161

 ·       Alukurani Alapọnle ni tira ti Ọlọhun fi ránṣẹ́ si Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- oun si ni ọrọ Olúwa gbogbo àgbáyé, Ọlọhun pe àwọn èèyàn ati alujannu nija lati mu irú rẹ wa, tabi suura kan nínú irú rẹ, ipenija naa ṣi n bẹ titi di òní. Alukurani si n fesi fun àwọn ìbéèrè pàtàkì ti o pọ ti o n ko idamudaabo ba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ninu awọn èèyàn. Alukurani yii nkan ti a sọ ni titi di òní pẹ̀lú èdè Lárúbáwá ti o fi sọkalẹ, ti arafi kankan ko si dinku níbẹ̀, wọ́n tẹ ẹ jáde, wọ́n sì fọn ọn ka, tira nla ni tii ko agara ba ẹni tí ó bá fẹ́ mu irú rẹ wa, nǹkan ti o lẹ́tọ̀ọ́ si kíkà ni tabi kika ongbifọ àwọn ìtumọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bẹẹ naa ni ìlànà Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ati ẹkọ rẹ ati ìtàn ìgbésí ayé rẹ, gbogbo ẹ ni wọ́n ṣọ tí wọ́n si gbe de ọdọ wa ni ibamu si sisẹntẹle lati ọdọ àwọn ti wọn maa n gba ẹgbawa ti wọn ṣee fi ọkan tan. Wọn tẹ oun naa jáde pẹ̀lú èdè Lárúbáwá tii ṣe èdè Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a), wọn si túmọ̀ rẹ si ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn èdè. Alukurani ati Sunna ni ipilẹ kan ṣoṣo fun àwọn idajọ Islam ati awọn òfin rẹ. Wọn kii mu Islam latara ìwà àwọn ti wọn n pe apemọra rẹ, bi ko ṣe wipe wọn maa n mu u latara imisi ti Ọlọhun tii ṣe Alukurani ati Sunna.

Alukurani Alapọnle ni tira ti Ọlọhun fi ránṣẹ́ si Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ti o jẹ ọmọ Lárúbáwá pẹ̀lú èdè Lárúbáwá, oun naa si ni ọrọ Olúwa gbogbo àgbáyé, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé. As-Shuaraa' 192-195 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú ò ń gba al-Ƙur’ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀. An-Nam'l 6 Alukurani yii wọn sọ ọ kalẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọhun, o si n jẹrii si òdodo àwọn tira Ọlọhun ti o ṣíwájú rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Al-Ƙur’ān yìí kì í ṣe n̄ǹkan tí ó ṣe é dáhun (láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn) lẹ́yìn Allāhu, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣe àlàyé (àwọn) Tírà náà. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. (Ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. Yunus 37 Alukurani tun maa n ṣàlàyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ ti àwọn yẹhudi àti nasara yapa le lórí nínú ẹsin wọn, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí yóò máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí. An-Nam'l 76 Alukurani ko àwọn ẹri sínú, ni èyí tí yóò jẹ ki àwíjàre wa lórí àwọn ènìyàn pátápátá nibi mímọ àwọn òdodo nípa Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, àti ẹ̀sìn Rẹ ati ẹsan Rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: A sì ti ṣe gbogbo àkàwé fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí. Az-Zumar 27 Allah tun sọ pe: A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan, ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí. An-Nah'l 89

Alukurani Alapọnle maa n fèsì fún àwọn ìbéèrè pàtàkì ti o pọ ti o maa n ko idamudaabo ba ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn ènìyàn. Alukurani Alapọnle maa n ṣàlàyé bi Ọlọhun ṣe da sanmọ àti ilẹ̀, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kò rí i pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀ pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀ pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti inú omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni? Al-Anbiyaa 30 Báwo wá ni Ọlọhun ṣe da ọmọniyan, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fun yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí ó máa kú (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn t’ó dára jáde. Al-Hajj 5 Ibo ni ọmọniyan maa ṣẹri padà sí, kini ẹsan olùṣe-rere àti alaburu lẹ́yìn isẹmi yii, a ti dárúkọ àwọn ẹri lórí ọrọ yii ṣíwájú nínú ipinrọ ti nọ́mbà rẹ̀ jẹ́ (20), ǹjẹ́ ayé yìí kan wà lásán nípasẹ̀ anfaani ni abi bibẹ rẹ ni ìdí pàtàkì kan? Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? Al-A'roof: 185 Allah tun sọ pe: Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?” Suuratul Muh’minuun: 115.

Alukurani je nkan ti a sọ titi di òní pẹ̀lú èdè ti o fi sọkalẹ, Olohun ti ola Re ga so pe: “Dajudaju Awa (Ọlọhun Allah)  ni a sọ Iranti (Alukurani) kalẹ, dajudaju awa naa ni Oludaabo bo o. Al-Hijr 9 Arafi kan ko dínkù ninu ẹ, o si soro ki itakora wa nínú ẹ, tàbí adinku tabi jijirọ, Olohun ti ola Re ga so pe: Ṣé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀. An-Nisaa 82 Nkan ti wọn tẹ jáde ti wọn si pin káàkiri ni, Tira ńlá ni tii ko agara ba ẹni tí ó bá fẹ́ mú irú rẹ̀ wá, o lẹtọ si láti maa ka a tàbí láti máa tẹti si i tabi lati máa ka ìtumọ̀ rẹ̀ ti wọn tu si èdè míràn. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ naa ni a ṣe ṣọ sunna Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ati ẹkọ rẹ ati ìtàn ìgbésí ayé rẹ, ti wọn si gbe e de ọdọ wa ni ìbámu si sisẹntẹle àwọn ti wọn maa n gba ìtàn wa ti a le fi ọkàn tan. Wọn tẹ oun naa jáde pẹ̀lú èdè Lárúbáwá ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ, wọn si túmọ̀ rẹ̀ si èdè tí ó pọ. Alukurani ati Sunna, méjèèjì naa ni ipilẹ kan ṣoṣo fun àwọn ìdájọ́ ati ofin Islam, a kii mu Islam latara ìwà àwọn Musulumi, ibi ti a ti maa n mu u naa ni imisi ti ọdọ Ọlọhun ti ko le si àṣìṣe níbẹ̀, oun naa ni Kuraani ati Sunna Anọbi Muhammad (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a). Ọlọhun sọ nípa Kuraani pe: Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà t’ó lágbára. Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀. Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn Fussilat: 41 42 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nípa Sunna pe Imisi lati ọdọ Ọlọhun ni: Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fun yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fun yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Al-Hash'ﷺ‬: 7

 ·       Islam n pàṣẹ ṣíṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì kódà ki wọn ma jẹ Musulumi, o si tun pàṣẹ ṣíṣe dáadáa si awọn ọmọ náà pẹ̀lú.

Islam n pàṣẹ ṣíṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé. Al-Isroo: 23 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì – (A sọ) pé: “Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì.” Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá. Luqman: 14 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí." Al-Ah'qoof: 15 Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọ́nú si i- o sọ pe: Arákùnrin kan wa ba Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- o ba sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, tani o lẹtọ si ki n maa fi dáadáa ba a lo pọ jù nínú àwọn èèyàn? O sọ pe: "Iya rẹ", o sọ pe: Leyin naa tani? O sọ pe: "Leyin naa iya rẹ", o sọ pe: Lẹ́yìn náà tani? O sọ pe: "Lẹ́yìn náà iya rẹ", o so pe: Lẹ́yìn náà tani? O sọ pe: "Lẹ́yìn náà bàbá rẹ". Sohiihu ti Muslim

Àṣẹ ṣíṣe dáadáa si awọn òbí yii wa fun gbogbo òbí, bóyá wọn jẹ Musulumi ni abi wọn kii ṣe Musulumi. Lati ọdọ Asmaa ọmọbìnrin Abubakr, o sọ pe: "Iya mi ti o jẹ ọṣẹbọ wa ba mi pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ ni asiko ti àwọn Kureeṣi gbe àdéhùn pẹ̀lú Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mo wa bi Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- léèrè pe:" Iya mi wa ba mi, o si n fẹ ki n ṣe dáadáa si oun, ṣe ki n ṣe e si i? O sọ pe:" Bẹẹni, ṣe dáadáa si i". Sohiihul-Bukhaariy Ti àwọn òbí rẹ ba wa gbìyànjú láti jẹ ki o fi Islam silẹ bọ sínú Kèfèrí, Islam n pa a láṣẹ pe ko gbọdọ tẹle wọn nibi ìyẹn, àmọ́ ki o ṣi maa ṣe dáadáa si wọn. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.1 Fi dáadáa bá àwọn méjèèjì lò pọ̀ ní ilé ayé. Kí o sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Mi (ní ti ìronúpìwàdà). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Luqman: 15

Islam ko kọ fun Musulumi láti máa ṣe daadaa si mọlẹbi rẹ ti wọn jẹ ọṣẹbọ tabi awọn ti wọn kii ṣe mọlẹbi rẹ lópin ìgbà ti wọn ko ba ti gbógun ti i. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu kò kọ̀ fun yín nípa àwọn tí kò gbé ogun tì yín nípa ẹ̀sìn, tí wọn kò sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, pé kí ẹ ṣe dáadáa sí wọn, kí ẹ sì ṣe déédé sí wọn. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-déédé. Al-Mum'tahanah: 8

Islam n pàṣẹ ṣíṣe dáadáa si awọn ọmọ, àṣẹ ti o tóbi ju ti Islām n pa bàbá náà ni ki o fi iwọ ti Ọlọhun ni lori awọn ọmọ rẹ mọ won, gẹgẹ bi Ojiṣẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ṣe sọ fun ọmọ ọmọ-ìyá baba rẹ tii ṣe Abdullaah ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- pe: "Irẹ ọmọdékùnrin yìí, tabi irẹ ọmọdékùnrin kékeré yìí, ṣe ki n kọ ẹ ni àwọn gbólóhùn kan ti Ọlọhun a jẹ ki o ṣe àǹfààní fun ẹ? Ni mo ba sọ pe: Bẹẹni, o sọ pe:"Sọ Ọlọhun, Ọlọhun yoo ṣọ ìwọ naa, ṣọ Ọlọhun, waa ri I ni iwájú rẹ, jẹ ki Ọlọhun mọ ọ ni ìgbà ti ara ba dẹ ọ, Oun náà yóò mọ ọ nígbà ilekoko, ti o ba fẹ béèrè nkan, Ọlọhun ni ki o bi, ti o ba fẹ wa iranlọwọ, Ọlọhun ni ki o wa iranlọwọ Rẹ". Ahmad ni o gba a wa 4/287

Ọlọhun pa àwọn òbí méjèèjì láṣẹ pé ki wọn kọ àwọn ọmọ wọn ni nkan ti yóò ṣe wọ́n ni anfaani ninu alaamọri ẹ̀sìn wọn ati ayé wọn. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika t’ó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn. Suuratut-Tah'riim: 6 Lati ọdọ Aliy- ki Ọlọhun yọ́nú si i- nibi gbólóhùn Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti O sọ pe: {ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná} O n sọ pe: "Ẹ kọ wọn ni ẹkọ, ẹ fi ìmọ̀ mọ wọn" Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- pa bàbá láṣẹ láti kọ ọmọ rẹ ni Irun; ki o le gba rírè lórí ẹ. Anọbi- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: (Ẹ maa pa àwọn ọmọ yin láṣẹ láti maa kírun ti wọn ba ti pé ọmọ ọdún méje) Abu Daud ni o gba a wa. O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: "Gbogbo yin ni alamojuto, gbogbo yin si ni a maa bi leere nípa nkan ti a ni ki ẹ mojuto. Alamojuto ni adarí, a si maa bi i léèrè nipa àwọn ti o mojuto, alamojuto ni ọkùnrin jẹ fun awon ará-ilé rẹ, a si maa bi i léèrè nípa àwọn ti o n mojuto, alamojuto ni obìnrin jẹ ni ilé ọkọ rẹ, a si maa bi i léèrè nípa nkan ti o mojuto, alamojuto ni ọmọ-ọdọ jẹ fun dúkìá olówó rẹ, a si maa bi i léèrè nípa nkan ti o mojuto, gbogbo yin pátá ni alamojuto, a si maa bi yin léèrè nípa nkan ti e mojuto" Sọhiihu Ibnu Hibbaan 4490

Islam pa bàbá láṣẹ láti maa náwó lórí àwọn ọmọ rẹ̀ ati awọn ará-ilé rẹ, a si ti sọ nkan ti o jẹ mọ́ bayẹn nibi ipinrọ (18), Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ṣàlàyé ọlá ti o n bẹ fun ninawo lórí ọmọ, o sọ pe: "Diinaari ti o lọla ju ti ọmọkùnrin maa n na ni: Diinaari ti o n na fun àwọn ti o n bọ́, ati diinaari ti o n ná fun nkan-ọ̀gùn rẹ ni ojú ọ̀nà Ọlọhun, ati diinaari ti o n ná fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ni ojú ọ̀nà Ọlọhun". Abu Qilaaba wa sọ pe: O bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí èèyàn n bọ́, lẹ́yìn náà Abu Qilaaba wa sọ pé: Ọkùnrin wo wa ni laada rẹ yóò tóbi ju ti ẹni tí n náwó fún àwọn ọmọ kéékèèké ti o n bọ́ ti wọn ko fi nii maa ṣe nkan ti kò tọ́, tabi ki Ọlọhun jẹ ki wọn fi wúlò, tabi ki o rọ̀ wọn lọ́rọ̀ Sohiihu Muslim: 994

 ·       Islām n pàṣẹ déédéé nibi ọ̀rọ̀ ati iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn títí tí ó fi dé orí àwọn ọ̀tá.

Ìròyìn déédéé n bẹ fun Ọlọhun níbi ìṣe ati ṣíṣètò Rẹ láàrin àwọn ẹrú Rẹ, O si wa ni oju ọna tí o tọ́ nibi nkan ti O pàṣẹ rẹ ati nibi nkan ti O kọ̀, ati nibi nkan ti O dá, ati nibi nkan ti O kádàrá, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Aal Im’raan/18 Ọlọhun n pàṣẹ déédéé, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Sọ pé: “Olúwa mi p’àṣẹ ṣíṣe déédé. Al-A'roof: 29 Gbogbo àwọn Ojiṣẹ ati awọn Anọbi pátá- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn- ni wọn mu déédéé wá, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa. A sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn àti òṣùwọ̀n nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). Al-Hadiid: 25 Òṣùwọ̀n náà ni déédéé nibi ọ̀rọ̀ àti ìṣe.

Islam n pàṣẹ ki a ṣe déédéé si gbogbo àwọn ènìyàn níbi ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́, kódà ti o fi dórí àwọn ọ̀tá. Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí òdodo nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí nítorí ti Allāhu, kódà kí (ẹ̀rí jíjẹ́ náà) tako ẹ̀yin fúnra yín tàbí àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí; yálà ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí aláìní. Allāhu súnmọ́ (yín) ju àwọn méjèèjì lọ. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú láti má ṣe déédé. Tí ẹ bá yí ojú-ọ̀rọ̀ sódì tàbí tí ẹ bá gbúnrí kúrò (níbi déédé), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. An-Nisaa: 135 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-àlà nítorí pé wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-àlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà. Al-Maa'ida: 2 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí ti Allāhu ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí òdodo nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti má ṣe déédé. Ẹ ṣe déédé, òhun l’ó súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Al-Maa'ida: 8 Ǹjẹ́ o le ri iru pipaṣẹ jíjẹ́rìí òdodo ati ọrọ òdodo yii nínú àwọn òfin àwọn ìjọ òde òní tabi nínú àwọn ẹsin ti àwọn èèyàn n sìn bi, kódà ki o jẹ pe èèyàn maa jẹ́rìí le ara rẹ lórí tabi lórí àwọn òbí rẹ tàbí lori awọn mọ̀lẹ́bí rẹ, njẹ o tun le ri pipaṣẹ déédéé pẹ̀lú ọ̀tá àti ọ̀rẹ́ nínú wọn bi.

Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- pàṣẹ déédéé láàárín àwọn ọmọ Lati ọdọ Aamir, o sọ pe: Mo gbọ ti An-Nu'maan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọ́nú si awọn méjèèjì- n sọ lori Munbari pe: Bàbá mi fun mi ni ẹbun kan, ni Amrat ọmọbìnrin Rowaahat wa sọ pé: Mi o nii yọ́nú si i titi ti wàá fi fi Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- jẹ́rìí si i. Ni o ba wa ba Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- o wa sọ pe: Mo fun ọmọ mi ti Amrat ọmọbìnrin Rowaahat bi fun mi ni ẹ̀bùn, ni Amrat wa pa mi láṣẹ pe ki n fi ìwọ Ojiṣẹ Ọlọhun jẹ́rìí si i, Ojiṣẹ Ọlọhun wa sọ pé: "Ǹjẹ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ to ṣẹku ni o fun ni irú èyí?" O sọ pe: Rara, O sọ pe: "Ẹ páyà Ọlọhun, ki ẹ si ṣe déédéé láàárín àwọn ọmọ yín". O sọ pe: O padà, o si da ẹ̀bùn rẹ padà. Sohiihu ti Al-Bukhaar 2587

Ìyẹn ni pe ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn àti ìlú ko le ni ojútùú àyàfi pẹ̀lú déédéé, àwọn ènìyàn ko le ni ifayabalẹ lórí ẹsin wọn, ati ẹjẹ wọn, àti àwọn ọmọ wọn, ati ọmọlúwàbí wọn, ati dúkìá wọn, ati awọn ìlú wọn, àyàfi pẹ̀lú déédéé, tori ẹ ni o ṣe jẹ pe nígbà tí àwọn Kèfèrí Mẹ́kà fún ilẹ̀ mọ àwọn Musulumi nínú ìlú Mẹ́kà, Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- pa wọn láṣẹ lati ṣe hijira lọ si ìlú Ábáṣà, o si sọ ìdí ti o fi ni ki wọn lọ si ìlú naa, toripe ọba onidéédéé wa nibẹ ti kii gba ki wọn ṣe àbòsí fun ẹni kankan ni ọdọ rẹ.

 ·       Islām n pàṣẹ ṣíṣe dáadáa si gbogbo ẹ̀dá pátá, o si n pèpè lọ síbi àwọn ìwà dáadáa àti àwọn iṣẹ́ rere.

Islām n pàṣẹ ṣíṣe dáadáa si gbogbo ẹ̀dá pátá, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). An-Nah'l 90 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Àwọn t’ó ń ná owó wọn nígbà ìdẹ̀ra àti nígbà ìnira, àwọn tí ń gbé ìbínú mì, àwọn alámòjúúkúrò fún àwọn ènìyàn níbi àṣìṣe; Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere. Aal Im’raan/134 Ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: "Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe ṣíṣe dáadáa ni ọranyan lórí gbogbo nkan, ti ẹ ba fẹ pa nkan, ki ẹ pa a dáadáa, ti ẹ ba fẹ dú nkan, ki ẹ du u dáadáa, ki ẹni kọọkan yin jẹ ki ọ̀bẹ rẹ mú dáadáa, ki o si tètè kó ìsinmi bá nkan ti o fẹ́ dú" Sohiihu Muslim: 1955

Islam n pepe si ìwà dáadáa àti iṣẹ́ rere, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nínú ìròyìn Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- nínú àwọn Tírà ti o ṣíwájú pé: Àwọn t’ó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa léèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn t’ó wúwo) àti àjàgà t’ó ń bẹ lọ́rùn wọn kúrò fún wọn; àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè. Al-A'rọọf 157 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Irẹ Aishat, dájúdájú Ọba ti O rọ̀ ni Ọlọhun, O si nífẹ̀ẹ́ si rírọ̀, O si maa n fún ni ní nkan látàrí rírọ̀ nkan ti Ko le fún ni látàrí líle ati nkan ti Ko nii fún ni lórí nkan ti o ba ti yàtò si i" Sohiihu Muslim: 2593 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Dájúdájú Ọlọhun ṣe ni eewọ fun yin: Sísẹ àwọn ìyá, àti sísin àwọn ọmọbìnrin láàyè, ati kíkọ nkan ti Ọlọhun ni ki á ná, ati bíbéèrè fun nkan ti èèyàn ko ni ẹ̀tọ́ nínú ẹ, O si tun ṣe ni eewọ fún yin: gbọyi-sọyi, ati apọju ìbéèrè, ati rira owó láre" Sọhiihu ti Buhari 2408 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Ẹ o nii wọ Alujanna títí tí ẹ fi máa gbagbọ, ẹ o nii gbagbọ títí tí ẹ fi maa nífẹ̀ẹ́ ara yín, ṣé ki n tọka yin si nkankan ti ẹ ba ti ṣe e, ẹ maa nífẹ̀ẹ́ ara yín? Ẹ maa fọn salamọ ka láàrin ara yín" Sọhiihu ti Muslim 54

 ·       Islam n pàṣẹ ki a ní àwọn ìwà ẹlẹyìn bíi òdodo, ati pípé àmàánnà, ati ìkóraró nibi nkan ti ko dára, ati ìtìjú, ati ìgboyà, ati ninawo, ati títọrẹ, ati ríran ẹni tí ó ní bukaata lọ́wọ́, àti ríran ẹni tí ó wa nínú ibanujẹ lọ́wọ́, àti bíbọ́ ẹni tí ebi ń pa, ati jíjẹ́ alamuleti rere, ati dida ẹbí pọ̀, ati ki káàánú àwọn ẹranko.

Islam n pàṣẹ ki a ní àwọn ìwà ẹlẹyìn, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: (Wọ́n gbé mi dìde láti pé àwọn ìwà tí ó dára) Sọhiihul Adabil Mufrad 207 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Dájúdájú nínú àwọn ti mo nífẹ̀ẹ́ si ju nínú yín, ti ibùjókòó wọn yoo si sunmọ mi ju ni ọjọ igbende, àwọn naa ni àwọn ti ìwà wọn dára jù nínú yin, àwọn ti mo sì korira ju nínú yín, ti ibùjókòó wọn yóò si jìnà si mi ju ni ọjọ́ igbende, àwọn naa ni àwọn ẹlẹjọ-wẹwẹ, ati awọn alasọtan-ọrọ, ati awọn al-mutafay'hiquun, wọn sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, a ti mọ àwọn ẹlẹjọ-wẹwẹ ati awọn alasọtan-ọrọ, àwọn wo wa ni al-mutafay'hiquun? O sọ pe: Àwọn naa ni àwọn onigberaga. As-Silsilatu As-Sohiiha 791 Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọ́nú si awọn méjèèjì- o sọ pe: "Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- kii ṣe onisọkusọ, kii sii mọ̀-ọ́n-mọ̀ sọ isọkusọ", o maa n sọ pé: "Dájúdájú ninu awọn ti wọn lóore jù nínú yín náà ni àwọn ti ìwà wọn dára jù nínú yín". Sohiihu ti Al-Bukhaar 3559 Àti àwọn nkan ti o yàtọ̀ si yẹn nínú àwọn Aaya ati Hadiisi ti o n tọ́ka si pé Islām n ṣeni lojukokoro ìwà rere àti iṣẹ́ rere lapapọ.

Nínú nkan ti Islam n pàṣẹ rẹ náà ni: Ododo, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Òdodo di ọwọ yin, torí pé òdodo máa n tọ́ni sọ́nà lọ sí dáadáa ni, dáadáa si máa n tọ́ni sọ́nà lọ sí Alijanna ni, ọmọniyan ko nii yé má sọ òdodo tí yóò sì máa wá òdodo kiri títí tí wọn fi máa kọ sí ọdọ Ọlọhun pé olódodo ni i" Sohiihu Muslim: 2607

Nínú nkan ti Islam pàṣẹ rẹ náà ni: Pípé àmọ̀ọ́nnà, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn An-Nisaa: 58

Nínú nkan ti Islam pàṣẹ rẹ náà ni: Kikoraró níbi nkan ti ko bójú mu, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Àwọn mẹ́ta kan n bẹ, ẹtọ ni fun Ọlọhun ki O ràn wọ́n lọ́wọ́: O dárúkọ nínú wọn: Ẹni tí ó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ti o n gbèrò láti kóra ró níbi nkan ti ko bójú mu" Sunanu Tirmiziy 1655 Nínú àdúrà ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- máa n ṣe ni pe: "Irẹ Ọlọhun, mo n tọrọ lọ́wọ́ Rẹ, imọna, ati ìpayà, àti kíkóraró níbi nkan ti ko bójú mu, àti rírọrọ̀" Sohiihu Muslim: 2721

Nínú nkan ti Islam n pàṣẹ rẹ náà ni ìtìjú, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Ìtìjú ko nii mu nkankan wá ayafi oore" Sohiihu ti Al-Bukhaar 6117 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Gbogbo ẹ̀sìn ni o ni ìwà tiẹ̀, ìwà Isilaamu náà ni ìtìjú" Al-Bayhaqiy ni o gbe e jáde nínú SHUABUL IIMAAN 6/2619

Nínú nkan ti Islam pàṣẹ rẹ naa ni ìgboyà, láti ọ̀dọ̀ Anas- ki Ọlọhun yọ́nú si i- o sọ pe: "Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- jẹ ẹni tí ó dáa jù nínú àwọn ènìyàn ti o si tun gboya jù nínú àwọn ènìyàn ti o si tun n tọrẹ ju nínú àwọn ènìyàn, ẹru ba àwọn ará Mẹdina ni ọjọ́ kan ti Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- si gbawájú wọn lórí ẹṣin" Sohiihu ti Al-Bukhaar 2820 Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- maa n wa ìṣọ́ra pẹ̀lú Ọlọhun kúrò níbi ojo, o maa n sọ pé: "Irẹ Ọlọhun, mo n sádi Ọ kúrò níbi ojo" Sohiihu ti Al-Bukhaar 6374

Nínú nkan ti Islam n pàṣẹ rẹ náà ni ninawo àti titọrẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àpèjúwe àwọn t’ó ń ná owó wọn fún ẹ̀sìn Allāhu dà bí àpèjúwe kóró èso kan tí ó hu ṣiri méje jáde, tí ọgọ́rùn-ún kóró sì wà lára ṣiri kọ̀ọ̀kan. Allāhu yó ṣe àdìpèlé fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀. Al-Baqara 261 Ìwà Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- náà ni titọrẹ, láti ọ̀dọ̀ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn méjèèjì- o sọ pe: "Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni o n tọrẹ jù nínú àwọn èèyàn, ìgbà ti o tun maa n tọrẹ ju ni inu Ramadan, nígbà tí Jibrīl ba wa pàdé rẹ, Jibrīl si maa n pàdé rẹ ni gbogbo òru Ramadan títí ti yóò fi tán, Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- máa n ka Kuraani fún un, ti Jibrīl ba ti wa pàdé rẹ, o jẹ ẹni tí máa n tọrẹ pẹ̀lú oore ju atẹgun ti a rán niṣẹ lọ" Sohiihu ti Al-Bukhaar 1902

Nínú nkan ti Islām n pàṣẹ rẹ naa ni ríran ẹni tí ó ní bukaata lọ́wọ́, àti ríran ẹni tí ó wa nínú ibanujẹ lọ́wọ́, àti bíbọ́ ẹni tí ebi ń pa, ati jíjẹ́ alamuleti rere, ati dida ẹbí pọ̀, ati ki káàánú àwọn ẹranko. Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọ́nú si awọn méjèèjì- o wi pe arákùnrin kan bi Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- léèrè pé: "Èwo nínú Islam ni o lóore jù?", o sọ pe: "Ki o máa fún ni ni oúnjẹ jẹ, ki o si maa salamọ si ẹni ti o mọ̀ àti ẹni tí oo mọ̀". Sohiihu ti Al-Bukhaar 12 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Láàrin ìgbà tí arákùnrin kan n rìn ni ojú ọ̀nà, ni òògbẹ wa n gbẹ ẹ́ gidigan, ni o wa ri kànǹga kan, ni o wa ko sínú rẹ, o si mu omi, lẹ́yìn náà ni o jáde kúrò nínú rẹ, ni o ba rí ajá kan ti o yọ ahọ́n síta ti o n jẹ erupẹ látàrí òùngbẹ. Arákùnrin náà wa sọ pé: "Bi òùngbẹ ṣe gbẹ mi tó náà ni o ṣe gbẹ ajá yii náà, ni o ba ko sínú kannga, o wa bu omi kún inú bàtà aláwọ rẹ, o wa fi ẹnu rẹ di i mú, o si fun ajá náà ni omi mu, Ọlọhun si dupẹ fun un, O si fi orí jin in". Wọn sọ pé: "Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ǹjẹ́ a ó tun maa gba láádá latara àwọn ẹranko ni bí? O sọ pé:" Bẹẹni, gbogbo nkan ti o ba ti ni ẹ̀dọ̀ tútù ni láádá bẹ nibẹ". Sọhiihu Ibnu Hibbaan 544 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Ẹni ti ba n ṣiṣẹ́ láti pèsè fun opó àti aláìní da gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń jagun sí ojú ọ̀nà Ọlọhun tàbí ẹni tí ń dìde kírun ní òru tàbí ẹni tí ń gba aawẹ ni ọ̀sán" Sọhiihu ti Buhari 5353

Islam n kan iwọ̀ ẹbí nípá, o si n ṣe dída ẹbí pọ̀ ní dandan, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀). Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn t’ó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀). Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀. Al-Ah'zaab: 6 O kìlọ̀ kúrò níbi jíjá okùn ẹbí, o si so o papọ mọ ṣíṣe ibajẹ ni orílẹ̀, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ǹjẹ́ kò súnmọ́ tí ẹ̀yin (aláìsàn ọkàn wọ̀nyí) bá dé’pò àṣẹ, pé ẹ ò níí ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti pé ẹ ò níí já okùn-ìbí yín? Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn. Muhammad: 22-23 Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Ẹni ti ba n ja okùn-ìbí ko nii wọ Alujanna". Sohiihu Muslim: 2556 Àwọn ẹbí ti o di dandan ki a so wọn pọ̀ náà ni: Àwọn òbí méjèèjì, àwọn ọmọ-ìyá lọ́kùnrin, àti àwọn ọmọ-ìyá lóbìnrin, ati awọn ọmọ-ìyá bàbá lọ́kùnrin, àti àwọn ọmọ-ìyá bàbá lóbìnrin, àti àwọn ọmọ-ìyá ìyá lọ́kùnrin, àti àwọn ọmọ-ìyá ìyá lóbìnrin.

Islam n kan iwọ̀ alamuleti nípá kódà kí ó jẹ́ Kèfèrí, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò t’ó súnmọ́ àti aládùúgbò t’ó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti ẹni tí agara dá lórí ìrìn-àjò àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga, afọ́nnu. An-Nisaa: 36 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: (Jibrīl kò yẹ̀ kò gbò ní ẹni tí ń pa mí láṣẹ láti máa ṣe dáadáa sí aládùúgbò títí tí mo fi lérò pé yóò sọ ọ di ẹni tí yóò jogún) Sọhiihu ti Abu Daa'ud 5152

 ·       Islam ṣe nkan ti ó dára nínú nkan jíjẹ ati nkan mímu ní ẹ̀tọ́, o si tun pàṣẹ mimọ ọkàn àti ara àti ilé, torí ẹ ni o ṣe ṣe ìgbéyàwó ní ẹtọ gẹ́gẹ́ bí àwọn Anọbi- ki ọlà máa bá wọn- ṣe pàṣẹ rẹ̀, gbogbo nkan ti o dara ni wọn máa n pàṣẹ rẹ̀.

Islam ṣe nkan ti ó dára nínú nkan jíjẹ ati nkan mímu ní ẹ̀tọ́, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Mo pe ẹyin ènìyàn, dájúdájú Ọlọhun Ọba ti O dára ni, Ko si nii gba nkankan ayafi nkan ti o ba dára, dájúdájú Ọlọhun pa àwọn Mumini láṣẹ pẹ̀lú nkan ti O fi pa àwọn Ojiṣẹ láṣẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:" Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́". Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: "Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín, kí ẹ sì dúpẹ́ fún Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún". O sọ pe: Lẹ́yìn náà ni o wa dárúkọ arákùnrin náà ti o máa ṣe ìrìn-àjò gan, ti irun orí rẹ rí wúruwùru, ti ara rẹ jẹ kìkì eruku, o wa n tẹ́wọ́ rẹ méjèèjì si sanmọ pe: Irẹ Olúwa mi, Irẹ Olúwa mi, èèwọ̀ si ni nkan ti o n jẹ, eewọ ni nkan ti o wọ̀, eewọ ni nkan ti o n mu, wọn tún tọ ọ dàgbà pẹ̀lú nkan eewọ, báwo ni wọn o ṣe gba adua irú ẹni bẹ́ẹ̀ Sohiihu Muslim: 1015 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Sọ pé: “Ta l’ó ṣe ọ̀ṣọ́ Allāhu, tí Ó mú jáde fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan dáadáa nínú arísìkí ní èèwọ̀?” Sọ pé: “Ó wà fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú ìṣẹ̀mí ayé. Tiwọn nìkan sì ni l’Ọ́jọ́ Àjíǹde." Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀.” Al-A'roof: 32

Islam pàṣẹ mimọ ọkàn àti ara àti ilé, torí ẹ ni o ṣe ṣe ìgbéyàwó ní ẹtọ gẹ́gẹ́ bí àwọn Anọbi- ki ọlà máa bá wọn- ṣe pàṣẹ rẹ̀, gbogbo nkan ti o dara ni wọn máa n pàṣẹ rẹ̀. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fun yín láti ara yín. Ó fun yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, wọn yó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ìdẹ̀ra Allāhu? An-Nahl: 72 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́. Òrìṣà ni kí o jìnnà sí. Al-Muddathir: 4-5 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: (Ẹni tí odiwọn ọmọ iná-igún nínú ìgbéraga ba n bẹ nínú ọkàn rẹ ko nii wọ Alijanna. Arákùnrin kan sọ pé: Èèyàn ti o ba wa nífẹ̀ẹ́ sí ki aṣọ rẹ dáa àti ki bàtà rẹ dáa ńkọ́. O sọ pe: Ọlọhun Ọba ti O rẹwà ni, O si nífẹ̀ẹ́ si ẹwà, ìgbéraga ni kíkọ òdodo àti yiyẹpẹrẹ àwọn ènìyàn) Sohiihu Muslim: 91

 ·       Islām ṣe àwọn ipilẹ àwọn nkan ti a ṣe ni eewọ ni eewọ, gẹgẹ bii ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, àti ṣíṣe Kèfèrí, ati sísin àwọn ooṣa, ati sisọ ohun ti èèyàn ò mọ̀ nípa Ọlọhun, àti pípa àwọn ọmọ, ati pípa ẹ̀mí ti a pọnle, àti ṣíṣe ibajẹ ni orílẹ̀, àti idán, ati ìwà ibajẹ ti o fi ojú hàn ati èyí tí ó pamọ, àti ṣìná, ati ki ọkùnrin maa ba ọkùnrin ẹgbẹ́ rẹ ni aṣepọ, o ṣe èlé ni eewọ àti jíjẹ okunbete, àti àwọn nkan ti wọn ba dú fún àwọn ooṣa, o ṣe ẹran ẹlẹ́dẹ̀ ni eewọ, àti àwọn ẹgbin ti o ṣẹ́kù, o ṣe jíjẹ dúkìá ọmọ orukan ni eewọ, ati didin òṣùwọ̀n kù, o ṣe jija okùn-ìbí ni eewọ. Àwọn Anọbi pátá- ki ọlà maa ba wọn- ni wọn fi ẹnu ko lori ṣíṣe àwọn nkan eewọ yii ni eewọ.

Islām ṣe àwọn ipilẹ àwọn nkan ti a ṣe ni eewọ ni eewọ, gẹgẹ bii ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, àti ṣíṣe kèfèrí, ati sísin àwọn ooṣa, ati sisọ ohun ti èèyàn ò mọ̀ nípa Ọlọhun, àti pípa àwọn ọmọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Sọ pé: "Ẹ wá kí n̄g ka ohun tí Olúwa yín ṣe ní èèwọ̀ fun yín; pé kí ẹ má ṣe fí n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I, (kí ẹ sì ṣe) dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì, kí ẹ sì má ṣe pa àwọn ọmọ yín nítorí (ìbẹ̀rù) òṣì, – Àwa ni À ń pèsè fun ẹ̀yin àti àwọn – kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ àwọn ìwà ìbájẹ́ – èyí t’ó hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́, - àti pé kí ẹ sì má ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè. Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn àyàfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ títí ó fi máa dàgbà. Ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n pé dáadáa. A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tí ẹ bá sọ̀rọ̀, ẹ ṣe déédé, ìbáà jẹ́ ìbátan. Kí ẹ sì pé àdéhùn Allāhu. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí. Al-An'aam 151-152 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Sọ pé: "Ohun tí Olúwa mi ṣe ní èèwọ̀ ni àwọn ìwà ìbàjẹ́ – èyí t’ó fojú hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́ –, ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ọ̀tẹ̀ ṣíṣe láì lẹ́tọ̀ọ́, bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ – èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún – àti ṣíṣe àfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu." Al-A'roof: 33

Islam ṣe pípa ẹ̀mí ti a pọ́nlé ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu- àlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san). Al-Isroo: 33 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀. Al-Furqaan: 68

Islam ṣe ibajẹ lórí ilẹ̀ ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Al-A'rọọf 56 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nípa Anọbi Shuaib- ki ọlà Ọlọhun maa ba a- wípé o sọ fún àwọn ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ìyẹn sì lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Suratul A'raf: 85

Islam ṣe idán ni eewọ, Ọba Òdodo ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé." TOO'HAA 69 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: "Ẹ jìnà sí nkan méje ti o maa n fa ìparun, wọn sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, kini àwọn nkan naa? O sọ pe: Iwa orogun pẹ̀lú Ọlọhun, ati idán, ati pípa ẹ̀mí ti Ọlọhun ṣe ni eewọ afi pẹ̀lú ẹtọ, ati jíjẹ riba, ati jíjẹ dúkìá ọmọ orukan, ati sisalọ fun ogun jíjà, ati pípa irọ́ ṣina mọ àwọn ọmòluabi l'obinrin, àwọn ti wọn gbagbọ l'ododo, àwọn ti sina ko si lórí ọkàn wọn Sohiihu ti Al-Bukhaar 6857

Islam ṣe ìwà ìbàjẹ́ ti o hàn àti èyí tí o pamọ ni eewọ, ati sina, ati ki ọkùnrin méjì maa ba ara wọn ṣe lọkọ-laya, a si ti sọ síwájú ni ìbẹ̀rẹ̀ ipinrọ yii àwọn aaya ti o tọka si ìyẹn, Islām si ṣe riba ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì fi ohun t’ó ṣẹ́kù nínú èlé sílẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Tí ẹ ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lọ mọ̀ pé ogun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (ń bọ̀ wá ba yín). Tí ẹ bá sì ronú pìwàdà, tiyín ni ojú-owó yín. Ẹ ò níí ṣàbòsí (sí wọn). Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín. Al-Baqara 278-279 Ọlọhun ko ṣe ìlérí ìyà pẹ̀lú ogun fun ẹlẹṣẹ kankan gẹ́gẹ́ bí O ṣe ṣe e fún ẹni tí o n gba èlé; toripe o n bẹ nibi èlé iba ẹ̀sìn jẹ, ati ìlú, ati dúkìá, ati ẹ̀mí.

Islam ṣe jíjẹ okunbete ni eewọ, ati nkan ti wọn ba du fun oosa, o si ṣe ẹran ẹlẹdẹ ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: A ṣe é ní èèwọ̀ fun yín ẹran òkúǹbete, àti ẹ̀jẹ̀, àti ẹran ẹlẹ́dẹ̀, àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tí kì í ṣe Allāhu, àti ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa, àti ẹran tí wọ́n lù pa, àti ẹran tí ó ré lulẹ̀ kú, àti ẹran tí wọ́n kàn pa àti èyí tí ẹranko abìjàwàrà jẹ kù àfi èyí tí ẹ bá rí dú (ṣíwájú kí ó tó kú) àti èyí tí wọ́n pa sídìí òrìṣà. Èèwọ̀ sì ni fun yín láti yẹṣẹ́ wò. Ìwọ̀nyí ni ìbàjẹ́ (Al'Maa'idah 3)

Islam ṣe mímu ọtí ni eewọ ati awọn nkan ẹgbin to ku, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí, tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò, ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ Èṣù ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè. Ohun tí Èṣù ń fẹ́ ni pé ó máa dá ọ̀tá àti ìkórira sílẹ̀ láààrin yín níbi ọtí àti tẹ́tẹ́. Ó sì fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi ìrántí Allāhu àti níbi ìrun kíkí. Ṣé ẹ̀yin kò níí jáwọ́ (níbi iṣẹ́ Èṣù) ni? Al-Maa'ida 90-91 A ti sọ síwájú ninu ipinrọ ti nọ́mbà rẹ̀ jẹ́ (31) wípé Ọlọhun sọ pe lara àwọn ìròyìn Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ninu Taoreeta ni pe yóò ṣe àwọn nkan àìdáa ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àwọn t’ó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa léèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn t’ó wúwo) àti àjàgà t’ó ń bẹ lọ́rùn wọn kúrò fún wọn Al-A'rọọf 157

Islam ṣe jíjẹ dúkìá ọmọ orukan ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn. Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan burúkú pààrọ̀ n̄ǹkan dáadáa. Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. An-Nisaa 2 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú àwọn t’ó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò. An-Nisaa 10

Islam ṣe didin òṣùwọ̀n ku ni eewọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún, nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù. Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde Al-Mutaffifiin 1-4

Islām ṣe jija okun ẹbí ni eewọ, a ti sọ síwájú nínú ipinrọ tí nọ́mbà rẹ̀ jẹ́ (31) àwọn aaya ati hadiisi to n tọ́ka si ìyẹn, àwọn Anọbi ati awọn Ojiṣẹ pátápátá- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn- ni wọ́n fi ẹnu ko lori ṣiṣe àwọn nkan eewọ yii ni eewọ

 ·       Islām n kọ àwọn ìwà burúkú bii irọ́, irẹjẹ, ìjànbá, ẹtanjẹ, keeta, ète aburú, olè-jíjà, tẹnbẹlẹkun, ati àbòsí, Islam kọ gbogbo ìwà ti ko dára.

Islam n kọ àwọn ìwà burúkú ni àpapọ̀, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Má ṣe kọ párìkẹ́ rẹ sí ènìyàn. Má sì ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú fáàrí. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn gbogbo onígbèéraga, onífáàrí. Luqman 18 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Dájúdájú nínú àwọn ti mo nífẹ̀ẹ́ si ju nínú yín, ti ibùjókòó wọn yoo si sunmọ mi ju ni ọjọ igbende, àwọn naa ni àwọn ti ìwà wọn dára jù nínú yin, àwọn ti mo sì korira ju nínú yín, ti ibùjókòó wọn yóò si jìnà si mi ju ni ọjọ́ igbende, àwọn naa ni àwọn ẹlẹjọ-wẹwẹ, ati awọn alasọtan-ọrọ, ati awọn al-mutafay'hiquun, wọn sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, a ti mọ àwọn ẹlẹjọ-wẹwẹ ati awọn alasọtan-ọrọ, àwọn wo wa ni al-mutafay'hiquun? O sọ pe: Àwọn naa ni àwọn onigberaga. As-Silsilatu As-Sohiiha 791

Islam kọ irọ́ pípa, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́. Gaafir 28 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹ ṣọ́ra fun irọ́ pípa, torí pé irọ maa n sun ni lọ sibi ẹ̀ṣẹ̀ ni, ẹ̀ṣẹ̀ si nìyí, o maa n sun ni lọ inú iná ni, ọmọniyan ko nii yẹ ko nii gbo lẹniti yoo maa pa irọ́, ti yoo tun maa wa gbogbo ọna láti pa irọ́, títí wọn yóò fi kọ ọ ni ọdọ Ọlọhun pé opurọ ni. Sohiihu Muslim: 2607 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Àmì ti a fi n da munafiki mọ mẹta ni: Ti o ba sọrọ yóò parọ, ti o ba ṣe àdéhùn yóò yapa, ti wọn ba gbára le e yóò janba Sọhiihu ti Buhari 6095

Islām kọ irẹjẹ O wa ninu Hadiisi pe Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- kọjá níbi tí òkìtì oúnjẹ kan wa, o wa ki ọwọ́ rẹ bọ inú oúnjẹ naa, ni ọwọ́ rẹ̀ wa tutù, o wa sọ pé: Kini eléyìí, irẹ oluta-ounjẹ? O sọ pe: Òjó ni o pa a irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: I ba dára ki o jẹ ki èyí ti ojo pa yìí wa lókè ki awọn èèyàn lè ri i, ẹnikẹ́ni ti o ba ti wuwa irẹjẹ ki i ṣe ara ìjọ mi. Sohiihu Muslim: 102

Islam kọ ìjàmbá àti ẹtanjẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jàǹbá (ọ̀ran-anyàn) Allāhu àti (sunnah) Òjíṣẹ́; ẹ má ṣe jàǹbá àwọn àgbàfipamọ́ yín, ẹ sì mọ (ìjàǹbá). Al-Anfaal 27 Allah tun sọ pe: (Àwọn ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn. Ar-Ra'd 20 Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- máa n sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ ti wọn ba jáde pe: Ẹ lọ jagun, ẹ o gbọdọ ji mu nínú ọrọ̀ ogun síwájú ki wọn o tó pin in, ẹ o gbọ́dọ̀ jàǹbá àdéhùn, ẹ o gbọ́dọ̀ ṣe ẹni tí ẹ bá pa ni ìṣekúṣe, ẹ o gbọ́dọ̀ pa ọmọ ti ko bai tii bàlágà. Sọhiihu ti Muslim 1731 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Nkan mẹẹrin kan n bẹ, ẹni tí wọn ba ti wà lára rẹ̀, o ti di munafiki pọnnbele, ẹni ti ìròyìn kan nínú ẹ ba ti wa lára rẹ, o ti ni ìròyìn nínú ìwà munafiki lára nìyẹn títí yóò fi fi í sílẹ̀: Ti wọn ba fi ọkàn tan an yóò jàǹbá, ti o ba sọrọ yoo parọ, ti o ba ṣe àdéhùn yóò yapa, ti o ba ba èèyàn ja yóò pa irọ́ Sohiihu ti Al-Bukhaar 34

Islam kọ keeta, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Tàbí wọ́n ń ṣe ìlara àwọn ènìyàn lórí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ ni? Dájúdájú A fún àwọn ẹbí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah). A sì fún wọn ní ìjọba t’ó tóbi. An-Nisaa 54 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A fún ní Tírà ń fẹ́ láti da yín padà sípò kèfèrí lẹ́yìn tí ẹ ti ní ìgbàgbọ́ òdodo, ní ti kèéta láti inú ẹ̀mí wọn, (àti) lẹ́yìn tí òdodo (’Islām) ti fojú hàn sí wọn. Nítorí náà, ẹ foríjìn wọ́n, kí ẹ ṣàmójú kúrò fún wọn (nípa ìnira tí wọ́n ń fi kàn yín) títí Allāhu yó fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá (láti ja wọ́n lógun). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Al-Baqara 109 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Àrùn àwọn ìjọ ti wọn ṣíwájú yín ti rìn wọ ààrin yín: Ìlara ati ikorira, oun naa si ni olufa-nkan, mi o sọ pe o maa fa orí o, ṣùgbọ́n ẹsin ni o maa fa, mo fi Ẹni ti ẹ̀mí mi n bẹ lọ́wọ́ Rẹ̀ búra, ẹ o le wọ alujanna titi ti ẹ maa fi ni ìgbàgbọ́, ẹ o si nii gbagbọ títí ti ẹ o fi nífẹ̀ẹ́ ara yín, ṣe ki n fun yin ni iro nípa nkan ti yóò fi ìyẹn rinlẹ̀ fun yin? Ẹ maa fọn salamọ ka láàrin yin. Sunanu Tirmiziy 2510

Islam kọ ète aburu, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Báyẹn ni A ṣe sọ àwọn àgbà kan di ọ̀daràn ìlú nínú ìlú kọ̀ọ̀kan, nítorí kí wọ́n lè máa dète níbẹ̀. Wọn kò sì dète sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí ara wọn, wọn kò sì fura. An-Aam 123 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe àwọn yẹhudi gbìyànjú láti pa Anọbi Isa- ki ọlà Ọlọhun maa ba a- wọn da ète, Ọlọhun naa si da ète si wọn, Ọlọhun wa ṣe àlàyé pé iya ète aburú ko nii ko le ẹni kan lórí afi oniṣẹ aburu, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: "Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá. Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí." Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte. (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ (kúrò lọ́wọ́ wọn).1 Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́.2 Mo sì máa fi àwọn t’ó tẹ̀lé ọ borí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ yapa ẹnu sí. Aal-Imraan 52-55 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe àwọn ìjọ Anọbi Solih gbèrò láti pa a, wọn da ète, Ọlọhun naa si da ète si wọn, O si pa wọn run ati ìjọ wọn lapapọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Wọ́n wí (fúnra wọn) pé: “Kí á dìjọ fí Allāhu búra pé dájúdájú a máa pa òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní òru. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa sọ fún ẹbí rẹ̀ pé ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣojú wa. Dájúdájú olódodo sì ni àwa.” Wọ́n déte gan-an, Àwa náà sì déte gan-an, wọn kò sì fura. Wo bí àtubọ̀tán ète wọn ti rí. Dájúdájú A pa àwọn àti ìjọ wọn run pátápátá. An-Nam'l 49-51

Islam kọ olè-jíjà, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: Oniṣina ko nii maa ṣe ṣina nígbà tí ó bá n ṣe e ki o tun maa jẹ onigbagbọ, olè ko nii maa jalè nígbà tí ó bá n jalè ki o tún máa jẹ onigbagbọ, ọmuti naa ko nii maa jẹ onigbagbọ nígbà tí ó bá n mu ọtí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ààyè ṣi wa fun ẹni tí o ṣe àwọn nkan wọnyi lati tuuba lẹyin ti o ba ṣe e tan. Sọhiihu ti Buhari 6810

Islam kọ ìkọjá-ààlà, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí. An-Nah'l 90 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Dájúdájú Ọlọhun ránṣẹ́ si mi pe ki ẹ maa tẹrí ba fun ara yín ti ẹni kankan ko fi nii maa ṣe àbòsí fún ẹlòmíràn, ti ẹni kankan ko si tun nii maa ṣe faari si ẹlomiran Sọhiihu ti Abu Daaud 4895

Islam kọ àbòsí, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí Aal-Imraan 57 Allah tun sọ pe: Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè. Al-An'aam 21 Allah tun sọ pe: (Ní ti) àwọn alábòsí, Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n. Al-In'saan 31 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Àwọn mẹ́ta kan n bẹ ti wọn ko nii da ipepe wọn padà: Aṣiwaju ti o jẹ onideede, ati alaawẹ titi yóò fi ṣinu, ati ipepe ẹni tí a ṣe àbòsí sí, torí pé ipepe rẹ wọn yóò gbe e gorí ẹsujo, wọn yoo wa ṣi àwọn ilẹkun sánmọ̀ fun un, Olúwa ti O ni agbára ti O gbọnngbọn yóò wa sọ pe: Mo fi agbára Mi búra, bo pẹ bo ya Maa ran ẹ lọ́wọ́. Muslim ni o gbe e jáde (2749) ni ṣókí pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀, ati Tirmiziy (2526) pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀, ati Ahmad (8043) tiẹ̀ si ni gbólóhùn náà. Nígbà tí Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- rán Muaz lọ si Yemen, lára nkan ti ó sọ fún un ni pé: ṣọ́ra fun ipepe ẹni tí a ṣe àbòsí si, torí pé ko si gaga láàrin rẹ àti aarin Ọlọhun Sohiihu ti Al-Bukhaar 1496 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹ tẹti ẹ gbọ́, ẹnikẹ́ni ti o ba ṣe àbòsí fún ẹni tí a ṣe àdéhùn fun nínú àwọn Kèfèrí, tabi o din ẹtọ rẹ ku, tabi o la nkan ti ko lágbára bọ ọ lọrun, tàbí o gba nkankan lọ́wọ́ rẹ̀ ti inú rẹ ko dun si, èmi (Anọbi) gan ni màá ba onítọ̀hún ja ni ọjọ igbende alukiyaamọ. Sunanu Abu Daaud 3052 Islam- gẹ́gẹ́ bí ìwọ naa ti ri i- o n kọ gbogbo ìwà ti ko dára tàbí ibalopọ ti àbòsí.

 ·       Islām n kọ ibalopọ ti owó ti èlé ba wa ninu ẹ, tabi ìnira, tabi ẹtanjẹ, tabi àbòsí, tàbí irẹjẹ, tàbí nkan ti o ba le ṣe okunfa inira ti o maa kárí àwùjọ ati awọn ọmọ ìlú ati ẹni kọọkan.

Islām n kọ ibalopọ ti owó ti èlé ba wa ninu ẹ, tabi ìnira, tabi ẹtanjẹ, tabi àbòsí, tàbí irẹjẹ, tàbí nkan ti o ba le ṣe okunfa inira ti o maa kárí àwùjọ ati awọn ọmọ ìlú ati ẹni kọọkan. A ti dárúkọ ṣíwájú ni ìbẹ̀rẹ̀ ipinrọ yii àwọn Aaya ati Hadiisi ti o n ṣe èlé ni eewọ, tabi àbòsí, tabi irẹjẹ, tabi ibajẹ ni orilẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àwọn t’ó ń fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin nípa n̄ǹkan tí wọn kò ṣe, dájúdájú wọ́n ti ru ẹrù (ọ̀ràn) ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé. Al-Ah'zaab 58 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn. Fussilat:46 O wa ninu Sunna pe: "Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ṣe ìdájọ́ pe ki èèyàn ma ṣe nkan ti o le mu ìnira wa, ki èèyàn ma ṣe fi ara ni ẹni ti o ba fi ara ni èèyàn pada Sunanu Abu Daaud Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o ma ṣe fi ṣuta kan alamuleti rẹ, ẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o yaa maa pọn àlejò rẹ le, ẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o yaa maa sọ dáadáa jáde ni ẹnu tabi ki o dakẹ. Ninu ẹgbawa miran, o wa nibẹ pe: Ki o yaa maa ṣe dáadáa si alamuleti rẹ. Sohiihu Muslim: 47 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Wọn fi ìyà jẹ arábìnrin kan látàrí olongbo kan ti o ti mọ ẹwọn titi o fi kú, o si ti ara rẹ̀ wọ iná, ko fun un ni oúnjẹ, ko si fun un ni nkan mu, o de e mọlẹ, ko si tu u silẹ ki o maa jẹ nínú kòkòrò ilẹ̀. Sohiihu ti Al-Bukhaar 3482 Eleyii nipa ẹni tí ó fi suta kan olongbo, ka mai tii sọ ẹni tí o fi suta kan ọmọniyan. Lati ọdọ Ibnu Umar, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- gun minbari, o wa pe pẹ̀lú ohun òkè lẹniti o sọ pe: Mo pe ẹyin ti ẹ gba Islām pẹ̀lú ahọ́n ti ìgbàgbọ́ koi tii de ọkàn yin, e o gbọdọ̀ fi suta kan àwọn Musulumi, ẹ o si gbọdọ bu wọn, ẹ o si gbọdọ maa wa ọna lati fi àléébù wọn han, torí pé ẹni tí ó bá n wa ọna láti fi àléébù ọmọ ìyá rẹ ti o jẹ Musulumi han, Ọlọhun yóò fi àléébù tiẹ̀ náà hàn, ẹni tí Ọlọhun ba si fi àléébù rẹ hàn, yóò dójú ti i, kódà ki o wa nínú yàrá rẹ, o sọ pe: Ibnu Umar wo Kaaba ni ọjọ kan ni o wa sọ pe: O ma tobi o! ọwọ rẹ naa si tobi!, ṣùgbọ́n onigbagbọ ni ọwọ ju ọ lọ ni odo Olohun. Tirmiziy ni o gbe e jade (2032), ati Ibnu Hibbaan (5763) Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹnikẹ́ni ti o ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ́ ìkẹyìn, ko gbọdọ fi suta kan alamuleti rẹ, ẹnikẹ́ni ti o ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o maa pọn àlejò rẹ le, ẹnikẹ́ni ti o ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa jáde lẹnu tabi ki o dakẹ. Sohiihu ti Al-Bukhaar 6018 Lati ọdọ Abu Huraira, lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- o sọ pé: Ǹjẹ́ ẹyin mọ tani oloṣi? Wọn sọ pé oloṣi ninu wa, irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, oun naa ni ẹni tí ko ni owó ti ko si ni dúkìá. O sọ pe: "Dájúdájú oloṣi ninu ijọ mi ni ẹni tí yóò wa ni ọjọ́ igbende pẹ̀lú aawẹ àti irun ati saka, yóò tun wa wá pẹ̀lú pe o ti bu eléyìí, o parọ ṣina mọ eléyìí, o jẹ dukia eléyìí ni ọna aitọ, wọn yóò wa da a joko sílẹ̀, eleyii yóò gba ninu iṣẹ-rere rẹ, tọun naa yóò gba ninu iṣẹ-rere rẹ, ti iṣẹ-rere ba ti wa tan ṣíwájú ki o to san gbese gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti o wa lọrun rẹ, wọn yóò mu nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóò da a le e lórí, wọn yóò wa ju u sínú iná" Muslim ni o gbe e jade (2581), ati Tirmiziy (2418), ati Ahmad (8029), ti ẹ si ni gbólóhùn náà.

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Ẹka igi kan n bẹ ni ojú ọna ti o n ko suta ba àwọn èèyàn, arákùnrin kan si mu u kúrò lọ́nà, o si ti ara rẹ wọ alujanna" Buhari ni o gbe e jade (652) pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ, ati Muslim (1914) pẹ̀lú nkan ti o jọ bẹ́ẹ̀, ati Ibnu Maajah (3682), ati Ahmad (10432) ti àwọn méjèèjì si ni gbólóhùn náà, mímú suta kuro lọna maa n mu èèyàn wọ alujanna, kini o wa lérò pe o maa ṣẹlẹ̀ si ẹni tí n fi suta kan àwọn èèyàn, ti o si n ba ayé wọn jẹ

 ·       Islām wa lati wa da aabo bo làákàyè ati lati ṣe gbogbo nkan ti o ba le ba a jẹ ni eewọ gẹ́gẹ́ bí mímu ọtí, o pàtàkì làákàyè, o ṣe e ni okunfa lila nkan bọni lọrun, o si la a kúrò nibi àjàgà itankitan ati ibọrisa. Ko si si awọn àṣírí ikọkọ kankan ninu Islām, bẹ́ẹ̀ si ni ko si awọn idajọ kankan ti o wa fun àwọn ipò kan nikan ti ko kan òmíràn, gbogbo àwọn ìdájọ́ rẹ ati òfin rẹ pátá ni o ba làákàyè ti o ni alaafia mu, o si wa ni ibamu si nkan ti déédéé ati ọgbọn n tọka si.

Islam wa pẹ̀lú dídá ààbò bo làákàyè, o si pàtàkì rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀. Al-Isroo 36 Dandan ni fun ọmọniyan ki o dáàbò bo làákàyè rẹ, torí ẹ ni Islām ṣe ṣe ọtí àti oogun olóró ni eewọ, mo si ti sọ nípa ṣíṣe ọtí ni eewọ ni ipinrọ ti nọ́mbà rẹ jẹ (34), ti ọpọlọpọ nínú àwọn aaya Kuraani si maa n parí pẹ̀lú gbólóhùn Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe: nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè Al-Baqara 242 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ìṣẹ̀mí ayé kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe eré àti ìranù. Ọgbà Ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni? Al-An'aam 32 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè. Yuusuf: 2 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga wa ṣàlàyé pe imọna ati ọgbọn, ko si ẹni ti yóò ṣe àǹfààní latara méjèèjì ju àwọn oni làákàyè lọ, àwọn naa si ni àwọn ọlọ́gbọ́n, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní òye ìjìnlẹ̀. Ẹni tí A bá sì fún ní òye ìjìnlẹ̀, A kúkú ti fún un ní oore púpọ̀. Ẹnì kan kò níí lo ìrántí àfi àwọn onílàákàyè. Al-Baqara: 269

Fun ìdí eyi ni Islam ṣe ṣe làákàyè ni okùnfà lila nkan bọni lọrun, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: "Wọn ti gbe kálámù sókè nibi nkan mẹ́ta kan: Ẹni ti o n sun títí yóò fi jí, ati ọmọkekere titi yóò fi bàlágà, ati weere titi yóò fi ni làákàyè" Buhari gbe e jade lẹniti o ti parẹ ninu awọn ti wọn gba a wa pẹ̀lú gbólóhùn amọdaju síwájú hadiisi (5269) pẹ̀lú nkan ti o jọ bẹ́ẹ̀. Abu Daaud gbe e jade lai pa ẹni kankan rẹ ninu awọn ti wọn gba a wa (4402), tiẹ si ni gbólóhùn naa, ati Tirmiziy (1423), ati An-Nasaa'i ninu (As-Sunanul Kubrọ) (7346), ati Ahmad (956) pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀, ati Ibnu Maajah (2042) ni ṣókí O la a kúrò nibi àjàgà itankitan ati ibọrisa, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nipa iṣesi àwọn ìjọ bi wọn ṣe dirọ mọ àwọn itankitan, ati bi wọn ṣe kọ òdodo ti o wa lati ọdọ Ọlọhun: Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn." Az-Zukhruf: 23 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nípa Anọbi Ibrahim- ki ọlà Ọlọhun maa ba a- wipe o sọ fun àwọn ìjọ rẹ pe: Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì lọ́rùn ṣe jẹ́ ná?” Wọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.” Al-Anbiyaa 52-53 Islam wa, o si pa àwọn èèyàn láṣẹ pe ki wọn fi jijọsin fun àwọn ooṣa silẹ, ki wọn si bọpa-bọsẹ kuro nibi awọn itankitan ti wọn jogún lati ọdọ àwọn bàbá wọn ati awọn baba-baba wọn, ki wọn si tẹle ojú ọna àwọn Ojiṣẹ (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn).

Àwọn àṣírí ikọkọ kankan ko si nínú Islām, bẹ́ẹ̀ si ni ko si awọn idajọ ti o wa fun eeyan ti won wa ni ipò kan nìkan ti ko kan òmíràn ninu ẹ Wọn bi Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọ́nú si i- léèrè, oun si ni ọmọ ọmọ-iya baba Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- o si tun jẹ ọkọ ọmọ rẹ, wọn bi i léèrè pé: Ǹjẹ́ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- da yin sa lẹsa pẹ̀lú nkankan bi? O sọ pé: Ko da wa sa lẹsa pẹ̀lú nkankan ti ko wa kan gbogbo àwọn èèyàn pátápátá àyàfi nkan ti n bẹ ninu apo idà mi yìí, o sọ pe: O ba mu ìwé kan jáde ti wọn kọ sínú rẹ pé: Ọlọhun ṣẹ ibi le ẹni ti o ba du nkan fun nkan ti o yatọ si Ọlọhun, Ọlọhun tun ṣẹ ibi le ẹni tí o ba paarọ àmì ààlà ilẹ̀, Ọlọhun tun ṣẹ ibi le ẹni tí ó bá ṣẹ ibi le bàbá rẹ̀, Ọlọhun tun ṣẹ ibi le ẹni tí o ba n dáàbò bo ọ̀daràn" Sohiihu Muslim: 1978 Gbogbo àwọn ìdájọ́ Islām ati òfin rẹ pátá ni o ba làákàyè ti o ni alaafia mu, o si wa ni ibamu si nkan ti déédéé ati ọgbọn n tọka si.

 ·       Àwọn ẹ̀sìn irọ, ti àwọn ti wọn n ṣe e ko ba ni agbọye àwọn àtakò ti o wa ninu ẹ, ati awọn nkan ti o tako làákàyè, àwọn àlùfáà ẹ̀sìn naa yoo jẹ ki awọn olutẹle wọn lérò pe ẹsin ju làákàyè lọ ni, ati pe ko si igbalaaye fun làákàyè lati gbọ ẹsin ye. Àmọ́ Islām ka ẹsin kun imọlẹ ti o maa tan si ojú ọna fun làákàyè, ti àwọn ti wọn n ṣe ẹsin irọ n fẹ ki awọn èèyàn pa làákàyè ti ki wọn si maa tẹle àwọn, ti Islām si n fẹ ki ọmọniyan ta làákàyè rẹ ji lati mọ pàtó bi àwọn ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan.

Àwọn ẹ̀sìn irọ, ti àwọn ti wọn n ṣe e ko ba ni agbọye àwọn àtakò ti o wa ninu ẹ, ati awọn nkan ti o tako làákàyè, àwọn àlùfáà ẹ̀sìn naa yoo jẹ ki awọn olutẹle wọn lérò pe ẹsin ju làákàyè lọ, ati pe ko si igbalaaye fun làákàyè lati gbọ ẹsin ye. Àmọ́ Islām ka ẹsin kun imọlẹ ti o maa tan si ojú ọna fun làákàyè, ti àwọn ti wọn n ṣe ẹsin irọ n fẹ ki awọn èèyàn pa làákàyè ti ki wọn si maa tẹle àwọn, ti Islām si n fẹ ki ọmọniyan ta làákàyè rẹ ji lati ronú jinlẹ, ati lati mọ pàtó bi àwọn ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),1 ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām). As-Shuura: 52 Imisi ti Ọlọhun ko àwọn ẹri sínú, ti àwọn ẹri naa yóò maa tọ làákàyè ti o ni alaafia sọna lọ sibi ododo to n wa lati mọ ati lati gba a gbọ. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ t’ó yanjú kalẹ̀ fun yín. An-Nisaa: 174 Ọlọhun ti ọla Rẹ ga n fẹ ki ọmọniyan maa ṣẹmi nínú imọlẹ imọna ati ìmọ̀ ati òdodo, ti àwọn ẹṣu si n fẹ ki ọmọniyan maa wa nínú okunkun kèfèrí ati aimọkan ati anu, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu ni Alárànṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Al-Baqara: 257

 ·       Islam n babara imọ ti o ba ni alaafia, o si n ṣeni ni ojúkòkòrò lati maa ṣe iwadi ti imọ ti ko nii si ifẹ-inu ninu ẹ, o si tun n pepe si wiwoye ati rí ronú nipa ara wa ati nipa ayé ni àyíká wa, àwọn àbájáde ìwádìí ìmọ̀ ti o ba si ni àlàáfíà ko le tako Islam.

Islam n babara imọ ti o ba ni àlàáfíà, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. (Suratul Mujaadalah :11) Ọlọhun so ijẹri àwọn onimimọ papọ mọ ijẹri Rẹ ati ijẹri àwọn Malaika lori nkan ti a n jẹri si ti o tobi ju Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. Aal Im’raan/18 Eleyii n ṣàlàyé ipò ti àwọn onimimọ wa nínú Islām, Ọlọhun ko si pa Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- láṣẹ lati wa alekun nkankan tayọ imọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Kí o sì sọ pé: “Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi.” Too'haa: 114 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Eniti o ba tọ oju ona kan leniti o n wa imo ni ibe, Olohun a ro ona kan fun un losi AL-Jannah, ati pe awon Malaika yoo maa tẹ awon iyẹ won sile ni eniti n yonu si ẹni ti o n wa imọ, atipe dajudaju ẹni tí ó n wá ìmọ̀, gbogbo nkan ti n be ni sanmo ati ile ni yoo maa toro aforijin fun un titi de ori awon eja ti n be ninu omi, ati pe dajudaju ola ti n be fun onimimo lori olusin Olohun da gegebi ola ti n be fun osupa lori awon irawo yoku. Dajudaju awon onimimọ ni won jogun awon Anọbi, awon Anọbi o si fi diinar pelu dirham sile lati jogún, nkan ti won fi sile naa ni imo, eniti o ba gba a mu, onitoun ti di ipin ti o pe mu”. Abu Da’ud ni o gbe e jade (3641), ati Tirmidhiy (2682), ati Ibn Maajah (223) ati pe gbolohun yii tie ni, ati Ahmad (21715).

Islaam nse wa ni ojukokoro lori sise iwadi ti o je ti mimo eleyi ti o bora kuro nibi ìfẹ́-inu, ti o si n pepe lọ sibi iwoyesi ati rironu nipa emi wa, ati nipa agbaye ti o yi wa ka. Olohun ti ola Re ga so pe: A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan? Suuratu Fussilat: 53. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? Suuratul Ah’roof: 185. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí. Suuratur Ruum: 9.

Atipe awon abajade (esi) ti o je ti mimo ti o si ni alaafia ko le wa ni itako pelu Islaam. Ati pe a maa so apejuwe kan ti Al-Qur’aan ti se awon alaye ijinle nipa re siwaju nkan ti o le ni ẹgbẹ̀rún kan ati ọgọ́rùn-ún meerin odun, ti imo ijinle ode-oni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi idi re mule ni igbehin-gbehin; awon abajade imo wa wa ni ibamu si nkan ti o wa ninu Al-Qur’aa  ti o tobi julo, oun naa ni siseda ọlẹ-inu si inu ikun iya re. Olohun ti ola Re ga so pe: Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú erùpẹ̀ amọ̀. Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ). Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.1 Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).2 Suuratul Muh’minuun: 12-14.

 ·       Ati pe Olohun ko nii gba ise, Ko si ni se esan le e lori ni ojo ikehin ayaafi ti o ba wa lati odo eniti o ni igbagbo pelu Olohun ti o si tun tele ase Re, ti o si tun gba awon ojise Re – ki ike ati ola maa ba won – ni ododo, ati pe Olohun ko nii gba ninu awon ijosin ayaafi èyí ti O ba se e lofin, nitori naa bawo wa ni omoniyan o se maa se aigbagbo pelu Olohun ti yoo wa maa reti ki o san an ni esan? Ati pe Olohun ko nii gba igbagbo enikeni ninu awon eeyan ayaafi ti o ba ni igbagbo si awon Anọbi- ki ola o maa ba gbogbo won lapapo- ti o si tun ni igbagbo si jije ojise Muhammad (ki ike ati ola Olohun maa ba a).

Ati pe Olohun ko nii gba ise, Ko si ni se esan le e lori ni ojo ikehin ayaafi ti o ba wa lati odo eniti o ni igbagbo si Olohun ti o si tun tele ase Re, ti o si tun gba awon ojise Re – ki ike ati ola maa ba won – ni ododo. Olohun ti ola Re ga so pe: Ẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ, ẹni ẹ̀kọ̀. Ẹni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, iṣẹ́ wọn máa jẹ́ àtẹ́wọ́gbà (pẹ̀lú ẹ̀san rere). Suuratul Is’raai: 18-19. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un. Suurtul Anbiyaah: 94. Ati pe Olohun ko nii gba ninu awon ijosin ayaafi eyi ti O ba se e lofin. Olohun ti ola Re ga so pe: Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀.” Al-Kahf 110 O wa salaye wipe dajudaju ise ko nii je ise daadaa ayaafi ki o je lati inu nkan ti Olohun se ni ofin, ti eniti ti o ni i si fi imokanga fun Olohun ninu iṣẹ́ rẹ, ti o si tun ni igbagbo pelu Olohun ti o si gba awon Anọbi Re ni ododo ati awon Ojise Re – ki ola o maa ba won – amo eniti ise re ba yato si iyen, Olohun ti ola Re ga ti so pe: Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku àfẹ́dànù. Suuratul Fur’qaan: 23. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn. Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé). (3) Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run). (4) Suuratul Gooshiyah: 2-4. Awon oju yii yoo walẹ (ni ti iyepere) yoo si se asekudorogbo ise, amo latari wipe o n sise pelu nkan ti o yato si imona lati odo Olohun; Olohun se ina ni ibuseri si re; nitoripe wọn ko se ise pelu nkan ti o yato si nkan ti Olohun se ni ofin nikan, bi ko se wipe won tun josin pelu awon ijosin burúkú, wọn si tun tẹle awon olori anu awon ti won n da adadaale awon esin buruku fun won. Nitori naa, ise daadaa eleyi ti yoo je atewogba ni odo Olohun naa ni eleyi ti o se deede pelu nkan ti Ojise – ki ike ati ola Olohun maa ba a – mu wa. Ati pe bawo ni omoniyan o se maa se aigbagbo si Olohun, ti yoo si maa reti ki O sesan fun un.

Ati pe Olohun ko nii gba igbagbo enikeni ninu awon eeyan ayaafi ti o ba ni igbagbo si awon Anabi – ki ola o maa ba gbogbo won lapapo – ti o si tun ni igbagbo si jije ojise Muhammad – ki ike ati ola Olohun maa ba a - a si ti so awon eri kan síwájú lori iyen ni ipinro ogun (20). Olohun ti ola Re ga tun so pe: Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.” Suuratul Baqara: 285 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà tefétefé. Suuratun-Nisai: 136. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì pé: (Ẹ lo) èyí tí Mo bá fun yín nínú Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) yóò dé ba yín; ó máa fi èyí t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí." Aal Im’raan/81

 ·       Dajudaju afojusun gbogbo ise ti o je titi Olohun ni pe: ki ẹsin ododo o mu omoniyan ga, yóò wa jẹ eru kan ti o mo esin kanga fun Olohun Oba gbogbo agbanla-aye, yoo si tun tu u sile kuro ni jije eru fun omoniyan tabi ohun elo tabi itankitan. Nitori naa, Esin Islaam - gegebi iwo naa se ri i - kii se afomo awon eeyan, ko si ki n gbe won tayo ipo won, ko si ki n so won di oluwa ati olujosin fun.

Dajudaju afojusun gbogbo ìránṣẹ́ ti o je titi Olohun ni pe: ki ẹsin ododo o mu omoniyan ga, yóò wa jẹ eru kan ti o mo esin kanga fun Olohun Oba gbogbo agbanla-aye, yoo si tun tu u sile kuro ni jije eru fun omoniyan tabi ohun elo tabi itankitan. Ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba a- so pe: “Ẹru owo diinar ati owo dirham, ati aso qoteefah pelu aso khomiisọ ti parun, ti won ba fun un yoo yonu, ti won ko ba fun un ko nii yonu” Sohiihu ti Al-Bukhaar 6435 Nitori naa, omoniyan ti o pe ko nii je eniti yoo maa teriba fun nkankan ayaafi Alloohu. Owo ko si nii so o di eru tabi iyi tabi ipo tabi idile. O si n be ninu itan yii ohun ti yoo maa ṣe afihan fun oluka, nkan ti awon eeyan wa lori re siwaju riran ojise, ati bi won se di leyin re (riran ojise niṣẹ).

Nigbati awon Musulumi akoko se Hijira lo si ilu Abasha, ti oba Abasha ni igba naa loun - An-Najaashi - si bi won leere, ti o si so fun won pe: “Esin wo ni yii, ti o se wipe e yapa awon ijo yin ninu re, ti e ko si darapo mo esin mi tabi esin okan ninu awon ijo yii? Jahfar omo Abi Toolib so fun un pe: Ire oba! Awa je ijo kan ti o je alaimokan, a maa n sin awon orisa, a si maa n je okunbete, a maa n se awon ibaje, a si tun maa n ja okun ebi, a si tun maa n se aburu si alabagbe, alagbara inu wa maa n je ole. Ori iyen ni a si wa titi ti Olohun fi ran Ojise kan si wa laarin wa, a mo iran re, ati ododo re, ati afokantan re, ati kiko ara ro kuro nibi nkan ti ko lẹtọ. O wa pe wa lo si odo Olohun ki a le mu Un ni okan soso, ki a si maa josin fun Un, ki a si tun bora kuro nibi nkan ti awa ati awon baba wa n josin fun ninu awon nkan ti o yato si I (Olohun) ninu okuta, ati awon orisa. O si pa wa lase pelu imaa so ododo, ati imaa pe afunnso (Amanah), ati imaa da ebi po, ati imaa se daadaa si alabagbe, ati jijawo kuro nibi awon nkan eewo ati tita awon eje sile, o si ko fun wa kuro nibi awon ibaje, ati oro eke ati imaa je owo omo-orukan ati imaa pa iro agbere mo awon obinrin ti won ko ara won ni ijanu. O si tun pa wa lase ki a maa sin Olohun ni Oun nikan, ki a si ma mu nkankan mo Oun ni orogun. O si tun pa wa lase pelu Irun kiki ati Zakah yiyo ati Aawe gbigba. O so pe: o wa ka awon alamori Esin Islam fun un”. A si gba a ni ododo, a si ni igbagbo pelu re, a si tun tele e pelu nkan ti o mu wa, a si tun sin Olohun ni Oun nikan ti a ko si mu nkankan mo On ni orogun, a si se nkan ti o se ni eewo lewa lori ni eewo, a si gba nkan ti o se leto fun wa ni eto”. Imam Ahmad lo gbe e jade (1740) pelu iyato die, ati Abu Naheem ninu tira re ((IL'YATUL AOLIYAA))(1/115) ni nkan ti o se ni soki. Esin Islaam - gegebi iwo naa se ri i - kII se afomo awon eeyan, ko si ki n gbe won tayo ipo won, ko si ki n so won di oluwa ati ẹni ti a maa jọsin fun. Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlu-l-kitāb, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan t’ó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.” Aal Im’raan/64 Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: (Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni? Suuratu Al-Imraan: 80 Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “E maa se yin mi ni ayinju gegebi awon Nasoorah se yin Omo Maryam ni ayinju, dajudaju emi o eru Re (Olohun) ni mi; nitori naa e so pe: Ẹrú Ọlọhun ati Ojise Re”. Sọhiihu ti Buhari 3445

 ·       Olohun Oba se tituuba ni ofin, oun naa si ni: Pipada omoniyan si odo Oluwa re, ati gbigbe ese ju sile, ati pe Islaam maa n pa nkan ti o ba saaju re re ninu awon ẹṣẹ. Ati pe tituuba naa maa npa nkan ti o ba ti saaju re re ninu awon ẹṣẹ. Nitori naa, omoniyan o bukaata si ki o maa jewo awon asise re ni iwaju awon eeyan abara.

Olohun Oba se tituuba ni ofin, oun naa si ni: Pipada omoniyan si odo Oluwa re, ati gbigbe ese ju sile, Olohun ti ola Re ga so pe: Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè. {suratul Nuur: 31.} Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run? Suuratut Taobah: 104. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Òun ni Ẹni t’Ó ń gba ìronúpìwàdà àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe àmójúkúrò níbi àwọn àṣìṣe. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Suuratush Shuuroh: 25. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Inu Olohun maa n dun gidi gan si tituuba (rironu piwada) ẹru Re ti o je Mu’mini ju didunu arakunrin kan lọ, ti arákùnrin naa wa ni inu asale ti o tun je aaye iparun, ti nkan ọgun re si wa pelu re, ti jije ati mimu re naa tun wa lori re, ni o ba sun lo, o si taji pada, nkan ogun re si ti lo, o wa bare si ni wa a titi ti òùngbẹ fi n gbe e. Leyin naa ni o wa so pe: Maa pada si aaye mi eleyi ti mo wa tele, maa wa sun titi ti maa fi ku, o wa gbe ori re le apa re ki o le ba ku, ni o ba taji, nkan ọgun si ti wa ni odo re, ti ipese, jije ati mimu re si wa lori re. Inu Olohun maa n dun gidi gan si tituuba (rironu piwada) eru Re ti o je Mu’mini ju bi inu eni yii se dun si riri ti o ri nkan ogun ati ipese re lo”. Sohiihu Muslim: 2744

Ati pe Islaam maa n pa nkan ti o ba saaju re re ninu awon ese. Ati pe tituuba naa maa n pa nkan ti o ba ti saaju re re ninu awon ese, Olohun ti ola Re ga so pe: Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun t’ó ti ré kọjá fún wọn. Tí wọ́n bá tún padà (síbẹ̀, àpèjúwe) ìparun àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá (ní ìkìlọ̀ fún wọn). Suuratul Anfaal: 38. Olohun si tun pe awon Nasoorah si tituuba (rironu piwada), Oba ti ipo Re gbongbon so pe: Nítorí náà, ṣé wọn kò níí ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, kí wọ́n sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. Suuratul Maaidah: 74. Olohun si tun se gbogbo awon oluyapa ati awon elese ni ojukokoro si tituuba (rironu piwada), Oba ti ola Re ga so pe: Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. Suuratuz Zumar: 53. Nigbati Amru Bn Al-Aas pinu lati gba Islaam, o paya wipe won o ni fi ori awon ese re ti o ti se siwaju Islaam jin in. Amru so leniti o n gba egbawa nkan ti o ṣẹlẹ̀ yii wa: Nigbati Olohun- Oba ti O biyi ti O gbonngbon- fi Islaam si mi ni okan, o so pe: Mo wa ba Anabi- ki ike ati ola Olohun maa ba a- lati gbe àdéhùn fun un, nigba naa ni o wa tẹ ọwọ́ re si mi, mo wa so pe: Mi o ni se adehun fun o ire ojise Olohun titi ti wa fi fi ori ese mi ti o ti saaju jin mi, o so pe: Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- wa so fun mi pe, ire Am’ru, se oo mo wipe hijira maa n pa awon ese ti o saaju re re ni, ire Am’ru, se oo mo wipe Islaam maa n pa awon ese ti o saaju re re ni?. Muslim lo gbe e jade (121) ni nkan ti o gun bi iru eleyii, ati Ahmad (17827) atipe gbolohun yii ti e ni.

 ·       Nitori naa, ninu Esin Islaam, asopo laarin omoniyan ati Olohun maa n wa taara ni, nitori naa, oo bukaata si enikankan lati je alagata laarin iwo ati Olohun. Esin Islaam si tun wa ko ki a so awon abara di olujosin fun tabi akẹgbẹ fun Olohun nibi jije Oluwa Re ati nibi lileto si ijosin Re.

Ninu Esin Islaam, omoniyan ko bukaata si ki o maa jewo awon ese re ni iwaju awon eeyan, ati pe ninu ẹsin Islaam asopo laarin eeyan ati Olohun maa n wa taara ni, nitori naa, oo bukaata si enikankan lati je alagata laarin iwo ati Olohun, gegebi o se rekoja ni ipinro (36). Dajudaju Olohun ti ola Re ga pe gbogbo eeyan lo sibi tituuba (rironu piwada) ati siseri pada si odo Re, Oun naa bakanna ni O tun ko fun won kuro nibi ki won mu awon Anabi tabi awon Malaaika ni alagata laarin Re ati awon eru Re. Nitori naa, Oba ti ola Re ga so pe: (Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni? Suuratu Al-Imraan: 80 Esin Islaam - gegebi o se ri i - si tun wa kọ ki a so awon abara di olujosin fun tabi akẹgbẹ fun Olohun nibi jije Oluwa Re ati nibi lileto si ijosin Re. Olohun ti ola Re so nipa awon Nasoorah pe: Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasara) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. Suuratut Taobah: 31. Ati pe Olohun tako awon keferi latari wipe won mu awon alagata laarin won ati Oun (Alloohu). Nitori naa, Olohun ti ola Re ga so pe: Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́. Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): "A ò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni." Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́. Suuratuz Zumar: 3. Olohun si tun salaye wipe dajudaju awon oloosa - awon alaimokan - maa n mu awon alagata laarin won ati Olohun, won wa maa n so pe: dajudaju awon (alagata) maa n sun won mo Olohun.

Ati pe ti Olohun ba kọ̀ fun awon eeyan kuro nibi ki won o mu awon Anabi tabi awon Malaaika ni alagata laarin Re ati awon eru Re; nitori naa, eniti o yato si won (awon Anabi ati awon Malaaika) lo fi n leto ju láti ma ṣe mu ni alagata. Bawo wa ni, ti awon Anabi ati awon Ojise - ki ola o maa ba won - na si maa n tara sàsà láti sunmọ Olohun. Olohun ti ola Re ga so ni Eni ti O n fun wa ni iro nipa isesi awon Anabi ati awon Ojise - ki ola o maa ba won- pe: Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa. Suuratul Anbiyaah: 90. Allah ti ọla Rẹ ga julọ tun sọ pe: Àwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn l’ó súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? – Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún. Suuratul Is’raah: 57. Iyen ni wipe: Dajudaju awọn ti e n pe leyin Olohun - ninu awon anabi ati awon eniire - awon naa maa n sunmọ Olohun, won si tun maa n rankan ikẹ Rẹ, won si tun maa n beru iya Rẹ; bawo wa ni won o se maa pe won leyin Olohun.

 ·       Ni ipari tira yii, a maa ranti wipe awon èèyàn, pẹ̀lú bi igba won ati awon eyameya won ati awon ilu won ati àwùjọ wọn ṣe yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe yàtọ̀ síra níbi irori wọn àti erongba wọn, ti àyíká wọn àti iṣẹ́ wọn naa si tun yàtọ̀ síra, èyí ni o jẹ ki o jẹ dandan fun wọn láti ni afinimọna kan ti o maa tọ wọn sọna, ati eto kan ti yoo ko wọn jọ, ati adari kan ti yoo maa dáàbò bo wọn, awon ojise alaponle - ki ike ati ola maa ba won - maa n se iyen pelu imisi lati odo Olohun, won maa n to awon eeyan s’ona losi oju-ona daadaa ati imona, won si maa n ko won jo si ori ofin Olohun, won si tun maa n dajo laarin won pẹ̀lú ododo. Nitori naa,  alamori wọn yoo duro deede ni ibamu si jije ipe won fun awon ojise yii, ati sisunmo igba won si awon iranse ti Olohun. Olohun wa fi opin si awon iranse Re pelu riran Anọbi Muhammad - ki ike ati ola Olohun maa ba a - ni ise, O si ko akosile siseku gbere fun un, O si tun se e ni imona fun awon eeyan ati ike ati imole ati itosona lo si oju-ona ti yoo muni de odo Re - mimo Re.

Ni ipari tira yii, a maa ranti wipe awon èèyàn, pẹ̀lú bi igba won ati awon eyameya won ati awon ilu won ati àwùjọ wọn ṣe yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe yàtọ̀ síra níbi irori wọn àti erongba wọn, ti àyíká wọn àti iṣẹ́ wọn naa si tun yàtọ̀ síra, èyí ni o jẹ ki o jẹ dandan fun wọn láti ni afinimọna kan ti o maa tọ wọn sọna, ati eto kan ti yoo ko wọn jọ, ati adari kan ti yoo maa dáàbò bo wọn, awon ojise alaponle - ki ike ati ola maa ba won - maa n se iyen pelu imisi lati odo Olohun, won maa n to awon eeyan s’ona losi oju-ona daadaa ati imona, won si maa n ko won jo si ori ofin Olohun, won si tun maa n dajo laarin won pẹ̀lú ododo. Nitori naa,  alamori wọn yoo duro deede ni ibamu si jije ipe won fun awon ojise yii, ati sisunmo igba won si awon iranse ti Olohun. Nigba ti anu ti wa po, ti aimokan si ti kari, ti won si ti josin fun awon orisa; Olohun gbe anabi Re Muhammad - ki ike ati ola Olohun maa ba a - dide pelu imona ati esin ododo lati mu awon eeyan kuro nibi awon okunkun ṣíṣe Kèfèrí, aimokan, ati iborisa, lọ si ibi igbagbo ati imona.

 ·       Fun idi eyii, mo n pe o, iwo omoniyan, ki o duro fun Olohun ni iduro ododo eleyi ti yoo bora kuro nibi àṣà ati ìṣe, ki o si tun lo mo wipe waa pada si odo Oluwa re leyin iku re, ki o si tun woye si ara rẹ ati awon agbegbe ti o wa ni ayika re. Nitori naa, gba Islām, ki o le ba se oriire ni aye re ati orun re. Ti o ba wa fe wo inu Islaam, ko si nkankan ti o je dandan fun o ju ki o jeri wipe ko si eniti ijosin to si ni ododo ayaafi Alloohu, ati pe dajudaju Muhammad ojise Re ni, ki o si tun bopa bose kuro nibi gbogbo nkan ti won ba n josin fun yato si Oba Alloohu, waa tun ni igbagbo wipe dajudaju Olohun yoo gbe awon ti won wa ninu saare dide, ati pe dajudaju isiro ati esan ododo ni, ti o ba ti wa jeri pelu ijeri yii, o ti di Musulumi. O wa je dandan fun o leyin iyen ki o maa josin fun Olohun pelu nkan ti O se ni ofin bii Irun, ati zakah, ati Aawe, ati Hajj ti o ba ni ikapa ona ati lo.

Fun idi eyii, mo n pe o iwo omoniyan ki o duro fun Olohun ni iduro ododo eleyi ti yoo bora kuro nibi àṣà ati ìṣe, gegebi Olohun ti ola Re ga se pe o ninu gbolohun Re: Sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo ni mò ń ṣe wáàsí rẹ̀ fun yín pé, ẹ dúró nítorí ti Allāhu ní méjì àti ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú jinlẹ̀. Kò sí àlùjànnú kan lára ẹni yín. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ fun yín ṣíwájú ìyà líle kan.” Suuratu Saba’: 46. ki o si tun lo mo wipe dajudaju ire o pada si odo Oluwa re leyin iku re, Olohun ti ola Re ga so pe: Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun t’ó ṣe níṣẹ́. Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san t’ó kún jùlọ. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá). Suuratun  Najm: 39-42. ki o si tun woye si emi re ati awon agbegbe ti o wa ni ayika re. Olohun ti ola Re ga so pe: Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? Suuratul Ah’roof: 185.

Gba Islām, ki o le ba se oriire ni aye re ati orun re. Ti o ba wa fe wo inu Islaam, ko si nkankan ti o je dandan fun o ju ki o jeri wipe ko si eniti ijosin to si ni ododo ayaafi Alloohu, ati pe dajudaju Muhammad ojise Re ni. Nigbati Ojise - ki ike ati ola Olohun maa ba a - ran Muadh lo si Yemen leniti n pepe lo si inu Esin Islaam, o so fun un pe: “Dadadaju ire o lo ba ijo kan ninu awon ti won fun ni tira, yaa pe won lo si ibi jijeri wipe ko eniti ijosin to si ni ododo ayaafi Olohun Alloohu ati wipe dajudaju emi o ojise Olohun ni mi, ti won ba ti wa tele o nibi iyen, wa fi mo won wipe dajudaju Olohun ti se irun wakati maarun ni oranyan le won lori ni gbogbo ojo ati oru, ti won ba tun tele o nibi iyen, wa fi mo won wipe dajudaju Olohun ti se zakah ni oranyan le won lori, won o maa gba a lati odo awon abọrọ won, won o si maa da a pada fun awon olosi won, ti won ba tun tele e nibi iyen, wa sora kuro nibi imaa gba awon eyi ti o dara julo ninu awon dukia won”. Sohiihu Muslim: 19 ki o si tun bopa bose kuro nibi gbogbo nkan won ba n josin fun yato si Oba Alloohu. Iwa ibopa-bose kuro nibi nkan ti won n josin fun yato si Olohun Alloohu naa ni AL-HANEEFIYYAH tii se ìlànà Anabi Ibroohim - ki ola maa ba a- Olohun ti ola Re ga so pe: Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fun yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. Suuratul Mumtahana: 4. Waa si tun ni igbagbo wipe dajudaju Olohun yoo gbe awon ti won wa ninu saare dide, Olohun ti ola Re ga so pe: Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn t’ó ń bẹ nínú sàréè dìde. Suuratul Hajj: 6-7. Ati pe dajudaju isiro ati esan ododo ni, Olohun ti ola Re ga so pe: Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo àti nítorí kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn. Suuratul Jaathiyah: 22.

Ti o ba ti wa jẹ́rìí pelu ijeri yii, o ti di Musulumi. O wa je dandan fun o leyin iyen ki o maa josin fun Olohun pelu nkan ti O se ni ofin bii Irun, ati Zakah, ati Aawe, ati Hajj ti o ba ni ikapa ona ati lo, ati nkan ti o yato si iyen.

Eda kan nìyí pelu déètì 19-11-1441

Ojogbon Muhammad omo Abdullaah As-Suhaym ni o ko o.

Oluko imo Aqeedah (adisokan) ni ipin awon eko ti o jemo ti Islaam (tele ri).

Kulliyyah Terbiyah ni ile-eko giga Al-Malik Suhuud.

Ilu Riyadh, ni orílẹ̀-èdè Saudi Arabia