Alaye Lori Hadiisi Eleekesan Ninu Tira Arbaiina Nawawiyya Ati Awon Anfaani Inu Re ()

Rafiu Adisa Bello

Akosile yi se alaye ni ekunrere lori hadiisi eleekesan ninu tira Arbaiina Nawawiyya, o si so opolopo ninu awon anfaani ti o ye ki Musulumi ni imo nipa re ninu hadiisi naa.

  |

  Alaye Lori Hadiisi Eleekesan Ninu Tira Arbaiina Nawawiyya Ati Awon Anfaani Inu Re

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Rafiu Adisa Bello

  2013 - 1434

  شرح الحديث التاسع من كتاب

  الأربعين النووية

  « بلغة اليوربا »

  رفيع أديسا بلو

  2013 - 1434

  Alaye Lori Hadiisi Eleekesan Ninu Tira Arbaiina Nawawiyya Ati Awon Anfaani Inu Re

  Hadiisi Naa:

  عن أبي هريرة عبد الرحمن بن صخر- رضي الله تعالى عنه- قال: سمعت رسول الله- صلى الله عليه وسلم- يقول: (ما نهيتكم عنه فاجتنبوه وما أمرتكم به فأتوا منه ما استطعتم؛ فإنما أهلك الذين من قبلكم كثرة مسائلهم واختلافهم على أنبيائهم) [رواه البخاري ومسلم].

  Itumo:

  Hadiisi yi wa lati odo Abu Huraera Abdur-rahman bin Sokhar- ki Olohun yonu si i- o so wipe: Mo maa n gbo ti Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa n so wipe: (Ohun ti mo ba ko fun yin ki e jinna si i, ohun ti mo ba si pase re fun yin ki e maa se e bi e ba se ni agbara mo; dajudaju ohun ti o ko iparun ba awon ijo ti won ti siwaju yin naa ni opolopo ibeere ati yiyapa awon Anabi won).

  Alaye Lori Hadiisi Yi:

  Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- n so fun wa ninu oro re yi wipe: Eyin ijo mi, ohun ti mo ba ko fun yin pe ki e ma se ki e jinna si i, ki e ma sun mo o rara. Ohun ti mo ba si so wipe ki e maa se ki e maa se e bi e ba ti se ni agbara mo.

  A o se akiyesi ni ibiyi pe Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- so nibi ohun ti o ko fun awa ijo re pe: Ki a jinna si i, lai se afikun wipe: (bi e ba ti se ni agbara mo), idi eyi si ni pe ohun ti Ojise ba pase wipe ki a fi sile o rorun lati fi sile. Sugbon ohun ti o ba pase sise re, a o ri wipe Ojise so pe: Ki a maa se e bi a ba ti ni abgara mo, ti o n tumo si wipe sise awon nkan naa le rorun fun awon eniyan kan ti ko si ni rorun fun awon eniyan miran.

  Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- tun so wipe: Dajudaju ohun ti o ko iparun ba awon ijo Yahuudi ati Nasaara ti won ti siwaju yin ohun naa ni opolopo ibeere, eyi ti o je wipe die ninu awon itan Al-kurani fi han wa bi awon ijo Yahuudi se je onibeere lopolopo, nigbati Anabi Musa- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- so fun won wipe: {Dajudaju Olohun n pa yin ni ase wipe ki e pa abo-maalu kan} [Suuratu Bakora: 67], won beere opolopo ibeere ni owo Anabi Musa: iru maalu wo? Iru awo wo ni yoo ni? Bawo ni yoo se ri?.

  Bakannaa, ninu awon ohun ti o ko iparun ba awon ijo Yahuudi ati Nasaara ti won ti siwaju ni yiyapa ati sise atako si ohun ti Anabi won ba so. Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- si n so eleyi lati kilo fun awa ijo re wipe ki a jinna si awon nkan ti o maa n se okunfa iparun.

  Awon Anfaani Ti O Wa Ninu Hadiisi Yi:

  Alakoko: O je dandan, o si je oranyan ki Musulumi jinna si ohun ti Ojise Olohun ba ko fun wa wipe ki a mase; nitori oro re ti o so wipe: (Ohun ti mo ba ko fun yin, ki e jinna si i).

  Eleekeji: Ohunkohun ti Ojise Olohun ba ko fun wa wipe ki a mase, eyi ti o kere ninu re ati eyi ti o tobi a ko gbodo se e; nitoripe itumo ki eniyan jinna si nkan kan ohun naa ni ki o jinna si kekere re bi o ti jinna si titobi re. Ni apejuwe, Olohun ati Ojise Re ko fun wa wipe a ko gbodo je owo ele "riba", eyi tumo si wipe a ko gbodo gba eyi ti o kere nibe bi o ti se je wipe a ko gbodo gba eyi ti o tobi.

  Eleeketa: Ohun ti Olohun ati Ojise Re ba pase wipe ki a fi sile o rorun lati fi sile ju ohun ti won ba pase wipe ki a se lo, idi niyi ti Ojise Olohun fi pase wipe ohun ti oun ba ko fun wa ki a jinna si i ni odidi ati ni tefetefe; nitoripe ki eniyan fi nkan kan sile o rorun.

  Eleekerin: Kosi nkan kan ti Olohun se ni dandan ayafi ohun ti omo eniyan ba ni ikapa re; eleyi ni Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- fi so wipe: Ohun ti mo ba pase re fun yin ki e se e bi e ba ti se ni agbara mo. Olohun- mimo Re- naa si so wipe: {Olohun ko la nkan kan bo enikan lorun ayafi ohun ti o ni agbara re} [Suuratu Bakora: 286].

  Eleekarun: Omo eniyan ni agbara, o si ni ikapa lori awon nkan kan ti Olohun fun ni ikapa lori won, pelu eri lati inu oro Ojise Olohun ti o so wipe: (Bi e ba ti se ni agbara mo). Eleyi yoo maa je esi oro fun awon ijo kan ti a n pe ni "Jabriyya" awon ti won n so wipe kosi agbara tabi ikapa kankan fun omo eniyan; nitoripe eni ti a je nipa lori gbogbo ohun ti o ba fe se ni.

  Eleekefa: Ti eniyan ko ba ni agbara tabi ikapa lati se ohun ti Olohun se ni dandan fun un ni odidi, o le se iwon ti abgara re ba ka. Apejuwe eleyi ni wipe: Dandan ni fun Musulumi lati dide duro nigbati o ba fe ki irun oranyan, sugbon ti ko ba ni agbara to lati ki irun naa ni iduro o le ki i ni ori ijoko.

  Eleekeje: Ko leto fun Musulumi kan nigbati o ba gbo ase kan lati odo Ojise Olohun ki o maa beere wipe: Se oranyan ni eleyi ni tabi nkan ti a fe? Nitoripe Ojise Olohun ti so wipe: (Ti mo ba pase nkan kan fun yin, ki e se e bi e ba se ni agbara mo), eyi ti o tumo si wipe gbogbo ohun ti Ojise Olohun ba ti pase re Musulumi kan ko gbodo wo eyin wo mo ki o to se e; nitoripe erusin Olohun ni a je, a si gbodo teriba fun gbogbo ase ti o ba wa lati odo Olohun ati Ojise Re.

  Eleekejo: Gbogbo ohun ti Ojise Olohun ba ti pase pe ki a se tabi o ko fun wa wipe ki a ma se o ti di ohun ti a n pe ni ofin esin "Sheria", yala iru nkan naa wa ninu Al-kurani tabi ko si nibe; nitoripe ojuse Musulumi ni ki o lo gbogbo ohun ti o ba wa lati inu sunna Ojise Olohun; ki o se ohun ti Ojise Olohun pase re ki o si jinna si ohun ti o ko fun wa.

  Eleekesan: Opolopo ibeere maa n se okunfa iparun papaa-julo awon ibeere nipa ohun ti laakaye eniyan ko le ni agboye won gege bii awon imo koko, ninu re si ni: Imo nipa awon oruko Olohun ati iroyin Re, bakannaa oro nipa awon isele ojo ajinde, oro Olohun ati ti Ojise Re nikan ni o le fun wa ni iro nipa awon nkan wonyi. Nitorinaa Musulumi ko gbodo maa beere ibeere pupo nipa re ki o ma baa je okunfa iparun fun un, ki o si mase di alaseju ninu esin.

  Eleekewa: Ibeere ni opolopo [lori awon nkan ti ko si idi fun] ni o se okunfa iparun fun awon ijo ti won ti siwaju wa. Bakannaa, sise atako tabi yiyapa awon Ojise ti Olohun ran si won naa si tun je okunfa miran fun iparun won.

  Eleekokanla: Ikilo fun Musulumi lori yiyapa tabi titako Ojise Olohun. Ohun ti o je ojuse Musulumi ni ki o maa tele ilana awon Ojise Olohun, ki o si gba wipe asiwaju ni won je fun oun, atipe erusin kan ninu awon erusin Olohun ni won je, sugbon Olohun se aponle fun won pelu pe O ran won ni ise si awon eniyan, eni ti o si je opin ati ikeyin fun gbogbo awon Ojise naa ni Anabi wa Muhammad, eni ti Olohun ran si gbogbo agbaye patapata, awon ofin ti Anabi naa si mu wa ni esin Islam, eyi ti Olohun yonu si fun awon erusin Re, ti ko si ni gba esin miran lowo won yato si i. {Dajudaju esin kan soso ti n be ni odo Olohun ni Islam} [Suura Al-imran: 19].