Ipo Irun Ninu Islam ()

Rafiu Adisa Bello

Akosile yi so nipa bi irun kiki ti se pataki to ninu esin Islam, ohun ni origun ti o lola julo leyin ijeri mejeeji, ohun naa si ni ise ti erusin maa n se ti o loore julo leyin won.

  |

  IPO IRUN NINU ISLAM

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Rafiu Adisa Bello

  2013 - 1434

  مكانة الصلاة في الإسلام

  « بلغة اليوربا »

  رفيع أديسا بلو

  2013 - 1434

  IPO IRUN NINU ISLAM

  Pataki Irun:

  Awon iko Banu Thaqeef wa si odo ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- lati gba esin Islam ki won si pada si odo awon ijo won ti won yoo maa fi esin Olohun mo won. Leyin ti won gba lati se esin Islam tan won beere awon nkan kookan ni odo ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ninu awon nkan naa ni wipe: Awon fe ki ojise Olohun se amojukuro fun awon nibi irun kiki eyi ti o tumo si pe awon ko fe lati maa ki irun, ojise Olohun si da won lohun wipe: "Kosi oore kankan nibi esin ti ko ni irun ninu" [Zaadul Ma'aad: 3/437].

  Irun je origun ti o se pataki julo ninu awon origun esin Islam leyin awon ijeri mejeeji: Ijeri pe kosi olohun kan ti ijosin to si ni otito ati ni ododo ayafi Olohun Allah atipe anabi Muhammad ojise Olohun ni. Olohun Allah se ni oranyan fun anabi Re ati gbogbo awa ijo anabi ninu oru ojo ti O mu un se irin-ajo lo si sanma, ohun si ni origun eleekeji ninu awon origun esin Islam maraarun.

  Irun maraarun ojumo je dandan fun gbogbo Musulumi l'okunrin ati Musulumi l'obinrin ni aaye-kaaye ti won ba wa: ni ile tabi ni ori irin-ajo, nigbati won ba wa ni alaafia tabi won ba n se aisan, nigbati won wa ninu ifokanbale tabi ifoya, gbogbo isesi kookan ni o si ni bi Musulumi yoo se ki irun nibe.

  Ninu Awon Idi ti yoo Je Ki A Mo Pataki Irun:

  Irun ni opomulero esin Islam, o si je origun ti o se pataki pupo ninu awon origun esin Islam, die ninu awon ohun ti yoo je ki a mo amodaju bi o ti se pataki ni wonyi:

  Alakoko: Nitori ipo irun ati pataki re, ohun ni alakoko ohun ti won yoo se isiro ise erusin Olohun le lori ni ojo ajinde. Ojise Olohun so wipe: "Dajudaju ohun ti won yoo koko se ayewo re ninu ise erusin Olohun ni ojo ajinde ni irun kiki, ti o ba ti dara erusin naa ti la o si ti yege, sugbon ti o ba ti baje erusin naa ti pofo o si ti padanu. Ti o ba se wipe irun oranyan re din ku ti ko pe Oluwa yoo so wipe: E wo o, nje erusin mi ni awon irun asegbore? Won yoo si se afikun ohun ti o din ku ninu awon irun oranyan re pelu asegbore yi, bayi ni won yoo si se isiro awon ise re yoku" [Tirmisi: 413, Mishkaatul Masoobih: 1330].

  Eleekeji: Irun ni o je onpinya ti a o fi maa mo iyato laarin Musulumi (eniti o gba fun Olohun re) ati keeferi (eniti o se aimoore ti o ko ti Olohun re). Ojise Olohun so fun wa ninu hadiisi kan pe: "Ohun kan ti o le so Musulumi di osebo tabi keeferi ni ki o gbe irun ju sile" [Muslim: 82]. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- tun so ninu oro re miran pe: "Adehun ti o wa laarin awa Musulumi ati awon olojueji (munaafiki) ni irun, eniti o ba ti gbe e ju sile o ti di keeferi" [Tirmisi: 2621, Nasai: 463, Mishkaatul Masoobih: 574].

  Eleeketa: Irun je ise ti Olohun feran julo ki erusin Re maa se. Saabe alaponle Abdullahi omo Mas'uud- ki Olohun yonu si i- so wipe: Mo beere lowo ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- wipe: Ise wo ni Olohun feran julo? O wa fun mi ni esi pe: "Ki eniyan maa ki irun ni asiko re", o tun beere wipe: Leyinnaa ewo ni? O so wipe: "Sise daradara si awon obi mejeeji", o tun beere wipe: Leyinnaa ewo ni? O so wipe: "Jija'gun si oju ona Olohun" [Bukhari: 527, Muslim: 85].

  Eleekerin: Ipo irun ninu awon ise ijosin yoku da gege bi ipo ori si ara, Olohun Allah gbe e tobi O si royin awon erusin Re ti won maa n ki i ninu Al-kurani ni ona ti o ju ipanna ogorin lo. Olohun- ti ola Re ga- so wipe: (Papaa awon onigbagbo ododo ti jere # Awon eniti won n paya Olohun ninu irun kiki won) [Suuratu Muuminuuna: 1, 2]. Olohun tun royin awon olukirun nigbati O n so ni aaye miran: (Dajudaju A da eniyan ni eniti o maa n kanju # Nigbati aburu ba sele si i yoo maa kanra # Nigbati oore ba si kan an a maa se ahun # Ayafi awon ti won maa n kirun # Awon eniti won maa n te'ra mo irun won {ti won n ki}) [Suuratu Ma'aariji: 19- 23].

  Eleekarun: Nitori ipo irun ti o se pataki ojise Olohun kii fi sere rara, o maa n ki irun ni oru titi ti ese re yoo fi wu fun pipe lori iduro, awon omoleyin re (saabe) yoo maa so wipe: Kinni o de ti iwo n se eleyi nigbati o je wipe Olohun re ti se aforijin fun o awon ese ti o ti da ati awon eyi ti iwo ko tii da, ojise Olohun yoo si maa da won lohun wipe: "Se emi ko ni je eru ti yoo maa dupe gidigidi ni?" [Bukhari: 4836, Muslim: 2819]. Ni afikun lori bi ojise Olohun se pataki irun to, saabe alaponle Ali omo Abi Toolib- ki Olohun yonu si i- so wipe: Oro ti ojise Olohun so keyin ki o to ku ni wipe: "Irun di owo yin o, irun di owo yin o, ki e si beru Olohun lori awon ti won ba wa ni abe ikapa yin" [Abu Daud: 5156, Sohihul Adabil Mufrad: 158]. Bakannaa ni saabe alaponle Umar omo Khatab- ki Olohun yonu si i- so nigbati o seku asiko die ti yoo pa ipo da wipe: {Kosi ipin erenje kankan ninu esin Islam fun eniti o ba gbe irun ju sile} [Sherhu Ssunna: 347].

  Eleekefa: Irun ni opomulero esin Islam ti o je wipe esin ko le duro ko si le dara ayafi pelu re. Ojise Olohun so ninu hadiisi kan fun Ma'aadh omo Jabal- ki Olohun yonu si i- wipe: "Je ki n fun o ni iro nipa ohun ti o je ori fun gbogbo nkan, ati opomulero re, ati ohun ti o ga julo nibe". O so wipe: Fun mi ire ojise Olohun. Ojise Olohun wa so wipe: "Ohun ti o je ori fun gbogbo nkan ni Islam, opomulero re si ni irun kiki, ohun ti o si ga julo nibe ni jija'gun si oju ona Olohun" [Tirmidhi: 2616, Ibn Maajah: 3973, Sohih Tergeeb Wa Ter'iib: 2866].

  Eleekeje: Ojise Olohun so fun awon obi omo wipe ki won maa pa awon omo won ni ase lati maa ki irun ti won ba ti pe omo odun meje, ki won si maa je won ni iya ti won ko ba ki i ti won ba ti pe omo odun mewa, gege bi o ti wa ninu hadiisi [Abu Daud: 495, Sohih Abi Daud: 509].