Ise Ijosin Afokanse Ni Ipile Esin ()

Rafiu Adisa Bello

Ise ijosin afokanse ni o se pataki ju lo, eyi ti o je wipe Olohun ko ni gba ise miran ti ko ba si nibe. Itumo ise ijosin afokanse ni akosile yi da le lori.

  |

  ISE IJOSIN AFOKANSE NI IPILE ESIN

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Rafiu Adisa Bello

  2013 - 1434

  العبادات القلبية أساس الدين

  « بلغة اليوربا »

  رفيع أديسا بلو

  2013 - 1434

  ISE IJOSIN AFOKANSE NI IPILE ESIN

  Kinni Itumo Ijosin?

  Ijosin a maa tumo si nkan meji:

  Alakoko: Ijosin tumo si ki eniyan re ara re sile fun Olohun- Oba Abiyi, Oba ti O ga- pelu ki o maa tele awon ase Re ki o si maa jinna si awon nkan ti O ba ko, ki o maa se awon nkan wonyi ni eniti o n feran Olohun naa ti o si n gbe E tobi.

  Eleekeji: Ijosin tun maa n tumo si awon ise ti eniyan n se gan-an lati wa asunmo si odo Olohun. Pelu bayi, ijosin je oruko kan ti o ko gbogbo ohun ti Olohun feran ti O si yonu si sinu, yala awon ohun ti Olohun feran ninu oro siso ni tabi ise sise, eyi ti o han tabi eyi ti o pamo.

  Ijosin ni erongba ti o ga julo ti Olohun Allah da gbogbo awa eda nitori re, Olohun so wipe: (Atipe Emi ko se eda alijonu ati eniyan lasan ayafi ki won le maa sin Mi) [Suuratu Saariyaati: 56].

  Nitori idi eyi ni o se je wipe alakoko ase ti Olohun pa awa eda Re ninu Al-kurani naa ni ase pe ki a maa josin fun Un ni Oun nikan soso, ki a si jinna si sise ebo pelu Re tabi wiwa orogun fun Un, Olohun so wipe: (Eyin eniyan, e maa josin fun Oluwa yin, Eniti O da yin ati awon ti won siwaju yin, ki e le maa beru Olohun) [Suuratu Bakorah: 21].

  Kinni A Gba Lero Pelu Awon Ise Ijosin Afokanse?

  Ise ijosin afokanse ni awon ise ijosin kan ti o je wipe okan ni eniyan fi maa n se won ki i se awon eya ara yoku. Apejuwe awon ise bee ni: Iferan (ki eniyan feran Olohun), sise agbiyele, biberu (ki eniyan beru Olohun), sise afomo ise fun Olohun (Ikhlaas), wiwa iranwo ni odo Olohun, wiwa aranse ni odo Olohun, wiwa iso pelu Olohun, nini amodaju nipa Olohun, gbigbafa fun Olohun, gbigbe ara le Olohun, rironu piwada lo si odo Olohun, ati bee bee lo.

  Gbogbo awon apeere ise afokanse wonyi ninu ojulowo igbagbo ni won wa, ise afokanse si loore ju ise afi ara se lo; nitoripe ohun ni o je ipile.

  Ibn Qoyyim- ki Olohun ke e- so wipe: "Orisi ijosin meji ni erusin maa n se fun Olohun re: Ijosin ti inu ati ijosin ti ode, erusin Olohun ni ijosin ti o n fi okan re se, o si ni ijosin ti o n fi ahan re ati awon orikerike ara re yoku se, sise ijosin ti ode lai si paapaa ijosin ti inu nibe ko le mu erusin Olohun naa sun mo Olohun re, ko si le se okunfa ki ise re je atewogba ki o si ni esan. Olohun maa n lo ise ijosin afokanse yi lati se ayewo ati idanwo fun koko erusin re, ise afokanse si ni emi gbogbo awon ise ijosin, nigbakiigba ti ise ijosin afi ara se ko ba ti ni ise ijosin afokanse ninu yoo maa da gege bii oku ara ti ko ni emi mo" [Badai'ul Fawaidi: 3/710].

  Ohun ti akosile yi fi n ye wa ni wipe:

  (1) Ise ijosin afokanse ni o se pataki julo ti Olohun Allah si feran julo.

  (2) Ise koko tabi ise afokanse gan-an ni paapaa esin, awon ise ode ko si le se anfaani kanakn ayafi pelu re.

  (3) Bi ise afokanse ba se tobi to ni okan erusin Olohun ni yoo se sun mo Olohun re to bee si ni esan re yoo se po to.