Okunfa Ifokanbale fun Musulumi Ododo ()

Rafiu Adisa Bello

Oro nipa Iranti Olohun ni o waye ninu akosile yii, nitoripe iranti Olohun ni o maa nje ki okan onigbagbo ododo bale. Akosile yii menu ba ola ti nbe fun iranti Olohun ati itumo re

  |

  Okunfa Ifokanbale fun Musulumi Ododo

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Rafiu Adisa Bello

  2013 - 1434

  من أسباب اطمئنان القلوب

  « بلغة اليوربا »

  رفيع أديسا بلو

  2013 - 1434

  Okunfa Ifokanbale fun Musulumi Ododo

  Ifokanbale je nkan ti gbogbo eniyan ti o wa laye yii nwa, yala eniti o je Musulumi ti o gba fun Olohun, ti o si jupajuse sile fun Un, tabi keeferi ti o ko ti Olohun Oba re, ti o si se aimoore si I. Kosi eniti ko fe ifokanbale, koda ifokanbale ni ohun ti o ga julo ti eniyan maa nwa ni aye yii, bi o tise je wipe ki eniyan jere pelu ogba idera (Al-Janna) ni ohun ti o ga julo ti eniyan maa ngbero ki oun ri ni orun.

  Nigbati oro wa ri bayi, o ye ki a bi ara wa ni ibeere wipe: kinni o nse okunfa ifokanbale fun eniyan?

  Ni idahun si ibeere yii, e je ki a gbo oro Olohun Oba wa ninu Al-Qur'aan. Olohun so wipe: (Je ki nso fun o, pelu iranti Olohun ni awon okan fi nbale) [Q: 13,28].

  Itumo iranti:

  Ohun ti a npe ni iranti ni ki eniyan jinna si igbagbera. Bakannaa o ntumo si itaji pelu okan si eni ti eniyan nranti re.

  Iranti Olohun- ti ola Re ga- je ise kan ti o tobi ti o si ni esan ti o po pupo. Olohun pa awon erun Re lase pe ki won maa ranti Oun, O si se ileri pe Oun yoo maa san won ni esan ti won ba se bee.

  Imam Qurtubi- ki Olohun ke e- nigbati o nse alaye aaya yii (Nitorina, e ranti mi, Emi yoo si ranti yin) [Q: 2, 152], o so pe: "O wa ninu aaya yi pipani ni ase ati erenje mimu ase naa se, itumo sisan esan fun ni si tun wa nibe, nitori idi eyi ni Olohun se kanpa mo o" [Tefseer Qurtubi].

  Pataki iranti Olohun:

  Ninu awon nkan ti yoo maa je ki a mo Pataki iranti Olohun ni awon koko ti a fe so yii:

  Alakoko: Iranti Olohun je emi fun awon ise rere, nigbakiigba ti ko ba si iranti Olohun nibi ise oloore kan, ise naa yoo da gege bii ara ti ko si emi nibe mo. Nitori idi eyi ni Olohun- mimo fun Un- fi se iranti Re ni ohun ti o gbodo wa nibi gbogbo ise oloore, dajudaju kosi ise oloore kan ayafi ki o je wipe iranti Olohun yoo je majemu ti yoo fi dara, ti yoo si fi ni alaafia.

  Eleekeji: Gbogbo ise ti Olohun pase wipe ki Musulumi maa se, nitori iranti Re ni O fi pa a lase. Olohun- Oba ti O gbongbon- so wipe: (Atipe ki o maa gbe irun duro fun iranti Mi) [Q: 20,14]. Ojise Olohun anabi Muhammad naa so wipe: "Olohun se yiyipo ile (kaaba), ati irin laarin oke Safa ati Marwa, ati jiju oko ni Mina (Jamaraat), lati maa gbe iranti Olohun duro" [Abu Daud (1888)].

  Eleeketa: Gbogbo ijosin patapata ni o ni majemu re, asiko re, o dara ki a se e ni awon asiko kan, o si je eewo ki a se e ni awon asiko miran, ayafi iranti Olohun nikan, eyi ti o je wipe gbogbo asiko ni Olohun pase wipe ki Musulumi se e.

  Imam Ibn Ketheer- ki Olohun ke e- se alaye aaya yii: (Awon eniti nranti Olohun ni iduro ati ni ijoko ati ni idubule won) [Q: 3,191], leyinnaa o fi kun un pe: "Itumo eyi ni wipe: won nranti Re ni oru ati osan, ni ori ile ati ni ori omi, ti won ba wa ni irinajo ati ile, nigbati won ba roro ati nigbati won ba je alaini, nigbati aisan nse won ati nigbati won ni alaafia, ni koko ati ni gbangba, ni gbogbo isesi won" [Tefseer ibn Ketheer].

  Eleekerin: Olohun se ni majemu pe ki Musulumi maa se iranti Oun ni opolopo ni gbogbo ibi ti O ti pase iranti, eyi ti o yato si gbogbo awon ise ijosin yoku. [At- Tesheel Li Uluumit Tenzeel].

  Eleekarun: Iranti Olohun je ilekun nla kan ti Olohun si sile laarin Re ati eru Re nigbakiigba ti eru Re ko ba ti ilekun naa pelu igbagbera.

  Eleekefa: Olohun- ti O ga julo- se aponle fun eru Re nigbati O nso wipe: "Emi yoo maa wa nibiti eru Mi ba gbe Mi si nibi ero re, Emi yoo si maa wa pelu re nigbakiigba ti o ba ranti Mi, ti o ba ranti Emi Olohun ninu emi re, Emi naa yoo ranti re ninu emi Mi, ti o ba ranti Emi Olohun ninu awon ijo kan, Emi naa yoo ranti re ninu ijo kan ti o loore ju ijo tire lo" [Hadiisi Qudsi, Bukhari: (7405), Muslim: (2675)].

  Iranti Olohun je ise oloore ti o rorun pupo ni sise, ti kosi fa idiwo fun Musulumi nibi ise oojo re, kosi asiko ti eniyan ko le se e, nitoripe gbogbo asiko ni o ba a mu, esan ti o po pupo ni o si wa fu un bakannaa. Opolopo ninu awon omoleyin ojise Olohun (Saabe) ni won je olusowo nla, ti owo won gbooro, sugbon sibesibe eleyi ko di won lowo lati maa se iranti Olohun won ni gbogbo isesi won, (Awon eniyan ti won ko je ki tita rira di awon lowo iranti Olohun, ati lati ki irun, ati lati yo saka, won nberu ojo kan ti awon okan yoo maa yi sotun-sosi ninu re ati awon oju) [Q: 24,37].

  Awon aaya Al- Qur'an ati Hadiisi ti o nso nipa Pataki iranti Olohun:

  (1) Oro Olohun ti o so pe: (Eyin ti e gbagbo ni ododo, e maa ranti Olohun ni iranti ti o po) [Q: 33,41].

  (2) Oro Olohun ti o so pe: (Maa ranti Oluwa re ninu okan re niti ireranile ati iberu, ati ni ohun ti kii se ariwo ni owuro ati asaale, ki o si mase wa ninu awon olugbagbera) [Q: 7,205].

  (3) Oro Olohun- mimo fun Un- ti o so pe: (Atipe ki e mase da gege bi awon eniti won gbagbe Olohun ti Olohun si mu won gbagbe ara won, irufe awon yen ni obileje) [Q: 59,19].

  (4) Olohun se iroyin awon ti won nranti Re, O si fun won ni iro ohun ti o pa ni ese sile fun won, bakannaa O so nipa awon ise oloore, O to won gege bi won ti se Pataki si, O wa fi iranti Re se eyi ti o ga julo ninu won nigbati O so wipe: (Ati awon ti o nranti Olohun ni opolopo (igba) ni okunrin ati ni obinrin, Olohun ti pese sile fun won aforiji ati esan ti o tobi) [Q: 33,35].

  (5) Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- so wipe: "Apejuwe eniti o nranti Oluwa re ati eniti kii ranti Oluwa re da gege bii apejuwe alaaye ati oku" [Bukahri: (6407), Muslim: (779)].

  (6) Ojise Olohun so fun arakunrin kan ninu hadiisi miran wipe: "Mase je ki ahan re gbe nibi iranti Olohun" [Ahmad, Tobaraani].

  Ki Musulumi se iranti Olohun pelu ahan re ni ipile nibi iranti, sugbon ti o ba se afikun lori iyen pelu okan re itumo iranti yoo pe ju ti alakoko yen lo, esan ti yoo si ri naa yoo po si, bakannaa ti o ba gbe itumo iranti ti o nse ati titobi Olohun si okan re nigbati o nse iranti naa, ti o si se afomo ise oloore naa fun Olohun eleyi ni o fi pe julo, ti esan re yoo si fi tobi julo. A nbe Olohun ki O se wa ni eni ti yoo maa le ranti Re ni gbogbo igba.