Oro Nipa Abosi Ati Awon Aburu Re ()

Rafiu Adisa Bello

Akosile yi se alaye nipa abosi, o so nipa die ninu awon aburu re, bakannaa ni o mu apejuwe wa nipa awon orisi abosi ti o tanka ni awujo ni ode oni.

  |

  ORO NIPA ABOSI ATI AWON ABURU RE

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Rafiu Adisa Bello

  2013 - 1434

  الظلم: حقيقته وأضراره

  « بلغة اليوربا »

  رفيع أديسا بلو

  2013 - 1434

  ORO NIPA ABOSI ATI AWON ABURU RE

  Itumo Abosi:

  Abosi ni ki eniyan fi nkan si ibi ti kii se aaye re tabi ibi ti ko leto si. Abosi ni yiye kuro lori deede ati kikoja enu aala ododo. Bakannaa o tun ntumo si ki eniyan kan gba ohun ti o je eto elomiran ni ona ti ko dun mo eni naa ninu.

  Abosi je iwa ti o buru pupo, ti ko si dara rara, fun idi eyi ni Olohun- ti ola Re ga- fi se e ni eewo fun ara Re gege bi ojise Olohun ti so ninu hadiisi kudsi ti o gba wa lati odo Olohun. Olohun so pe: “Mo pe eyin erusin Mi, dajudaju Emi ti se abosi ni eewo fun ara Mi, Mo si se e ni eewo ni aarin yin, ki e ma se maa se abosi” [Muslim: 2577].

  Olohun wa Oba mimo Oba ti o ga julo ni ikapa ki O se abosi si awa eda Re ti kosi si eda kan ti o le bi I, sugbon ki awa eda Re le mo wipe abosi je iwa buburu ati isesi ti ko dara ti kosi ni oore kankan ninu, eyi ni Olohun fi se abosi ni eewo fun ara Re; nitoripe Olohun Oba wa daradara ni gbogbo ohun ti O ba se, Oun kii se aburu rara, kosi leto ki a fi aburu ti si odo Re.

  Ki a le mo bi aburu abosi ti to Olohun Adeda tun so ninu opolopo aayah Al-kur’ani wipe Oun ko ni se abosi si enikankan ninu awon eda Oun bi o ti wule ki o mo.

  Olohun so pe: (Atipe Emi kii se alabosi fun awon eru), [Suuratu Koof: 29]. O tun so pe: (Olohun ko si gbero lati se abosi si awon eru [Re]) [Suuratu Gaafir: 31]. O tun so ni aaye miran pe: (Olohun ko si gbero abosi kan si gbogbo eda) [Suuratu Aali-Imraana: 108]. Bakannaa ni O so pe: (Atipe Oluwa re kii se alabosi fun awon eru [Re]) [Suuratu Fusilat: 46]. O tun so ni aaye miran pe: (Dajudaju Olohun ko ni se abosi kankan si awon eniyan, sugbon awon eniyan ni won maa nse abosi fun ori ara won) [Suuratu Yuunus: 44]. Oro Olohun tun so pe: (Dajudaju Olohun ko ni se abosi si enikan ni odiwon omo-inagun) [Suuratu Nisaai: 40]. O tun so ninu aaya miran pe: (Eniti o ba se ise rere ti o si je olugbagbo ododo, ki o mase paya abosi tabi ituje) [Suuratu Tooha: 112].

  Ohun idaniloju ni awon aaya Al-kur’ani ti o po yi je ti Olohun fi nse alaye fun awa eda Re bi o ti se korira abosi nitoripe iwa buburu gbaa ni, eleyi si ye ki o je eko fun gbogbo eda eniyan lati jinna si abosi sise laarin ara won.

  Bakannaa o ye ki a mo pe kosi inira tabi aburu kan ti yoo kan Olohun Oba mimo Oba ti o ga nibi abosi ti a ba se si ara wa, bikosepe awa eda ara wa naa ni a maa je irora aburu ti o nbe nibi abosi ti a ba se.

  Awon Iran Abosi:

  Abosi pin si ona meji:

  Ipin Alakoko: Abosi si emi ara eni, eyi ti o ga julo ninu ipin yi si ni wiwa orogun fun Olohun Allah tabi jijosin fun nkan miran ti o yato si I, Olohun so pe: (Dajudaju dida nkan po mo Olohun [ebo sise] je abosi ti o tobi) [Suuratu Lukman: 13]. Ti a ba woye si nitooto a o ri wipe osebo ti gbe eda kan si ipo Olohun Adeda ni o fi njosin fun eda naa, eleyi tumo si pe o ti gbe nkan kan si ibi ti kii se aaye re. Opolopo ninu awon aaya ti Olohun ti so nipa awon alabosi ti O si se ileri iya fun won, awon osebo ni awon alabosi naa, gege bi O ti so pe: (Awon alaigbagbo awon ni alabosi) [Suuratu Bakorah: 254]. Ninu abosi sise si emi ara eni bakannaa ni awon iwa ese, kosi iye meji nibi wipe eniti o nda ese nse abosi si emi ara re nitoripe awon ese re ko le ko inira ba enikan ju oun elese lo, gbogbo aburu iwa ese naa yoo si maa wa ni akosile ninu iwe ise re, yala ese kekere ni tabi eyi ti o tobi.

  Ipin Eleekeji: Abosi sise si elomiran ninu awon eda, eleyi ni ojise Olohun so nipa re ninu oro kan ti o gba wa lati odo Olohun re ti o so wipe: “Mo pe eyin erusin Mi, dajudaju Emi ti se abosi ni eewo fun ara Mi, Mo si se e ni eewo ni aarin yin, ki e ma se maa se abosi”. Iran abosi yi naa ni ojise Olohun so nipa re nibi ibanisoro re nigbati o se ise Haj eyi ti o fi dagbere fun awon ijo re nigbati o so pe: “Dajudaju eje yin ati owo yin ati omoluabi yin, eewo ni gbogbo won je laarin ara yin ki enikan se abosi si elomiran lori won, gege bi o ti je wipe ojo yi ati osu yi ati ilu yi je eewo fun yin ki e ja’gun ninu won” [Bukhari: 7078, Muslim: 1679].

  Ninu hadiisi miran, ojise Olohun so wipe: “Dajudaju Olohun yoo maa de alabosi leke, yoo fi i l’ara bale titi ti o fi je wipe nigbati O ba gba a mu ko ni fi i sile titi ti yoo fi je iya re tan, leyinnaa ojise Olohun ka aaya Al-kurani ti o so wipe: (Gege bayi ni ije-ni niya Oluwa re, nigbati yoo ba je awon ilu kan niya nitori abosi won. Dajudaju mimu ni Re je ohun ti o nira ti o si le koko) [Suuratu Huudu: 102] [Bukhari: 4686].

  Ojise Olohun tun so ninu hadiisi kan ti a gba wa lati odo Abu Huraerah wipe: “Eniti o ba ni nkan kan l’orun ti o fi se abosi si omo iya re kan ki o yara lati da a pada nisisiyi ki o to di wipe ko ni je owo diinaari ati dir’ami mo, bikosepe ohun ti yoo je ni wipe won yoo maa yo ninu ise rere re fun omo iya re, nigbati ko ba si ni ise rere kankan mo won yoo maa yo ninu ere ise aburu omo iya re ti won yoo maa fi kun ise aburu tire” [Bukhari: 6534].

  Awon Aburu Ti O Wa Nibi Abosi:

  Alakoko: Abosi maa nse okunfa ibinu Olohun, o si maa n fa iya ni oniran iran fun alabosi. Olohun so wipe: (Gege bayi ni ije-ni niya Oluwa re, nigbati yoo ba je awon ilu kan niya nitori abosi won. Dajudaju mimu ni Re je ohun ti o nira ti o si le koko) [Suuratu Huudu: 102].

  Eleekeji:Abosi maa n fa ki eniti won se abosi si se epe le eniti o se abosi si i. Ojise Olohun so fun saabe eni aponle n ni, Maadh omo Jabal nigbati o n se ikilo fun un pe: “Ki o si beru epe eniti won ba se abosi si, nitoripe kosi gaga kan laarin re ati Olohun” (eyi ti o tumo si pe taara ni epe ti o ba se yoo maa lo si odo Olohun, ti Olohun yoo si fi iya je eniti o ba se abosi si i) [Bukhari: 1496, Muslim: 19].

  Ojise Olohun tun so ninu hadiisi miran wipe: “E beru epe eniti won ba se abosi si, nitoripe bi o ba ti n se epe naa ni yoo maa lo si oke ni odo Olohun, yoo wa ninu kurukuru Olohun yoo si maa so wipe: (Mo fi Iyi Mi ati Titobi mi bura, Emi yoo ran o lowo b’ope b’oya) [Sohihul Jaami’ Sogiir Wasiyaadatuhu: 117].

  Eleeketa: Abosi maa n se okunfa ki awon eniyan rere jinna si eniti o ba n se abosi nitoripe won yoo maa beru aburu owo re.

  Eleekerin: Ese ni abosi, aburu re kosi mo lori eniti o n se e nikan bikosepe o maa n ran elomiran gege bii awon ti alabosi ba se ise buburu owo re si.

  Eleekarun: Abosi sise je eri kan ti o fi oju han lori pe alabosi eniti okan re baje ni, ti okan re si le, bakannaa ti o je eniyan buburu.

  Eleekefa: Eniyan yepere ni alabosi je ni odo Olohun Oba ti ola Re ga.

  Eleekeje: Abosi maa n se okufa ki alabosi wa ninu okunkun ni ojo ajinde nigbati awon ti won beru Olohun ni ile aye ba wa ninu imole, alabosi yoo maa wa ninu okunkun ti ko si ni ri ona lo, eleyi je die ninu iya abosi re si awon eniyan nigbati o wa ni aye. Ojise Olohun so wipe: “Abosi sise okukun ni o je fun alabosi ni ojo ajinde” [Bukhari: 2447, Muslim: 2579].

  Die Ninu Abosi Ti O Gbajumo Ni Awujo:

  Abosi ti awon eniyan maa nse ni asiko ti a wa yi pe orisirisi, die ninu re ni yi:

  (1) Ninu ile: Abosi ni ki baba ni ife si ikan ninu awon omo re ju elomiran lo, tabi ki o maa se itoju enikan ninu won ju enikeji lo. Abosi ni ki okunrin ma se eto ti o ye lori iyawo re, gege bii ki o pese ounje fun un tabi ki o ra aso fun un. Abosi ni ki obinrin maa je ki eniyan kan wo ile oko re lai gba iyonda ni odo oko re tabi ki obinrin lo si ibi ti oko re ko fe nigbati oko re ko mo si i.

  (2) Ni ile-eko: Abosi ni ki oluko ma se ojuse re bi o ti ye nibi ise. Abosi ni ki oluko maa se ojusaaju nibi idanwo fun apakan ninu awon akeko re. Abosi ni ki oluko ti o je okunrin maa se agbere pelu omo akeko re l’obinrin.

  (3) Laarin oja: Abosi ni ki onisowo kan maa din osunwon ku, Olohun si ti se ibi le awon ti won maa n se bee. Olohun so wipe: (Egbe ni fun awon ti won n din osunwon ku # Awon eniti o se pe nigbati won ba maa gba osunwon [ti won] ni odo awon eniyan won a gba [osunwon naa] ni kikun # Sugbon nigbati awon ba fe won fun [awon eniyan] won o din in ku [won ko ni won on pe]) [Suuratu Mutoffifiina: 1-3]. Abosi si ni ki onisowo maa ta oja ti kii se ojulowo ki o pe e ni ojulowo fun eniti o fera a.

  (4) Nibi ise: Abosi ni ki onise-owo lo nkan aloku si ise ti awon eniyan gbe fun un sugbon ki o so wipe nkan titun ni oun lo si i. Abosi ni bakannaa ki onise-owo ra nkan ni iye owo kan sugbon ki o pe e ni iye kan ti o ju iye ti o ra a lo. Ojise Olohun je ki a mo amodaju pe eniti o ba n se abosi iru eleyi kii se Musulumi ododo, “Eniti o ba se abosi si wa, kosi ninu awa olugbagbo ododo” [Muslim: 101].

  (5) Ninu ilu: Abosi ni ki eniyan maa ko owo ilu si apo ara re tabi ki o maa fi owo ilu se nkan fun ara re tabi ki o maa ko oro jo ninu owo ilu ni eyi ti ko ni eto si, iru oro bee kii ba eniti o ba ko o jo kale.

  (6) Ni ile-ijoba: Abosi ni ki osise ijoba ma de ibi ise re ni asiko ti o si je wipe yoo gba owo re pe ni ipari osu. Abosi ni ki enikan ti o je oga ni ibi ise maa di ona agbega fun elomiran ninu awon osise abe re.

  Ni ipari, ojuse ni fun Musulumi lati maa ranti hadiisi kan ti ojise Olohun ti so wipe: “Gbogbo yin ni adaranje, gbogbo yin ni a o si bi yin leere bi e ti se da eran yin je si” [Bukhari: 893, Muslim: 1829]. Eleyi yoo maa mu wa mo wipe gbogbo ibi ti a ba wa o ye ki a maa se daradara ki a si maa tele ofin Olohun, ki a maa hu iwa daradara pelu awon eniyan ki a si jinna si abosi; nitoripe ti a ba lero wipe ohun ti a ba n se pamo fun awon eniyan ki a mo wipe nkan kan ko pamo fun Olohun Allah, Oba ti O mo koko ti O si n ri koko gege bi O ti n ri gbangba. A be Olohun ninu aanu Re ki O fi ododo oro Re ye wa, ki o ma se wa ni alabosi.