wọn origun igbagbọ-ododo“Al-Iimaan” ()

 

|

 wọn origun igbagbọ-ododo“Al-Iimaan”

Mo bẹrẹ ni orukọ Ọlọhun Alaanujulọ Aladipele-ẹsan-rere

Gbogbo ọpẹ ti Ọlọhun ni i se, ikẹ ati ọla Ọlọhun k’o maa ba ẹni ti kò si anabi kan mọ lẹyin rẹ, Anabi wa, Muhammad ọmọ Abdullaah, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”; lẹyin naa:

Dajudaju titan imọ Islam ka ni oripa nla nipa sise alaye paapaa Islam, ati fifi awọn opo ẹsin naa rinlẹ, ati tita awọn ijọ yii ji.

Ohun afojusi alapọnle yii si ni ohun ti ilé-ẹkọ giga ti Islam [ni ilu Madina] n gbiyanju lati fi rinlẹ gba ọna ipepe, ati ikọnilẹkọ.

Ati pe nitori atikopa ninu fifi eleyii rinlẹ ni aaye iwadii-ijinlẹ ni ilé-ẹkọ giga yii se se eto, ti o si se ipalẹmọ fun ọpọlọpọ ninu awọn adawọle ti imọ, eyi ti o ni itumọ, ninu rẹ si ni awọn iwadii ti o rinlẹ nipa Islam, ati awọn ẹwa rẹ, ati titan an ka, nitori ojukokoro rẹ lori atise ipese fun awọn ọmọ ijọ Musulumi, pẹlu eyi ti o rinlẹ ju, ti o si lagbara ju ninu awọn ẹkọ nipa Islam, ati adisọkan rẹ, ati awọn ofin rẹ.

Eleyii si ni iwadii nipa « Awọn origun igbagbọ-ododo “Iimaan”» ti i se ọkan ninu awọn èto aaye iwadii-ijinlẹ yii, nigba o dari apa kan ninu ikọ awọn olukọ ni ilé-ẹkọ giga yii, lati kọwe nipa koko ọrọ yii, lẹyin naa l’o pa igbimọ imọ-ijinlẹ ni aaye iwadii yii lasẹ pẹlu sise ayẹwo ohun ti wọn kọ, ki wọn o si pe ohun ti o din [ninu rẹ], ki wọn si gbe e jade pẹlu aworan ti o tọ si i, pẹlu gbigbiyanju lati so awọn ohun ayẹwo ti imọ naa pọ pẹlu awọn ẹri-ọrọ wọn, [ti wọn wa] ninu Al-Qur’aan, ati Sunna.

Aaye iwadii-ijinlẹ yii si n se ojukokoro -gba ara iwadii yii- lọ sidi mimu ki awọn ọmọ Musulumi o le ni awọn imọ ẹsin alanfaani, nitori eleyii l’o se tumọ rẹ si awọn ede agbaye, ti o si tan an ka, ti o si gbe e wọ inu internet.

A n bẹ Ọlọhun, ti O gbọn-un-gbọn, ti O si ga, pe ki O san ijọba ilẹ Saudi Arabia ni ẹsan rere, ati eyi ti o pe ju [ninu] rẹ, lori ohun ti o fi n sọwọ ninu awọn iyanju nla, nitori atise isẹ sin Islam, ati titan an ka, ati sisọ awọn aalà rẹ, ati lori ohun ti ilé-ẹkọ giga yii n ri gba ninu iranlọwọ, ati amojuto, lati ọdọ ijọba naa.

A si n bẹ Ọlọhun -ibukun ati giga ni fun Un- pe ki o jẹ ki iwadii yii o sanfaani, ki O si fi wa se kongẹ pẹlu idẹra Rẹ, ati apọnle Rẹ, lati gbe awọn ti o sẹku ninu awọn adawọle aaye iwadii yii jade, gẹgẹ bi a ti se n bẹ Ẹ -giga ni fun Un- pe ki o fi gbogbo wa se kongẹ lọ sidi ohun ti O fẹran, ti O si yọnu si, ki O si se wa [ni ọkan] ninu awọn olupepe [lọ sidi] imọna, ati awọn alaranse [fun] otitọ.

Ikẹ ati ọla Ọlọhun, ati oore Rẹ, k’o maa ẹru Rẹ, ati ojisẹ Rẹ, Anabi wa, Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn Sahaabe rẹ.

 Aaye Iwadii-Ijinlẹ

 AWỌN ORIGUN IGBAGBỌ-ODODO

Awọn ni nini igbagbọ-ododo si Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati akọsilẹ -kadara- rere rẹ, ati aburu rẹ.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ولكن البر من آمن بالله واليوم الآخر والملائكة والكتاب والنبيين { [سورة البقرة: 177].

« Sugbọn oluse-daadaa ni ẹni ti o gba Ọlọhun gbọ, ati ọjọ ikẹyin, ati awọn Malaika, ati awọn tira, ati awọn anabi » [Suuratul-Baqarah: 177].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} آمن الرسول بما أنزل إليه من ربه والمؤمنون كل آمن بالله وملائكته وكتبه ورسله لا نفرق بين أحد من رسله { [سورة البقرة: 285].

« Ojisẹ naa gba ohun ti a sọ kalẹ fun un lati ọdọ Oluwa rẹ gbọ, ati awọn olugbagbọ-ododo, onikaluku wọn gba Ọlọhun gbọ, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, a kò ni i se iyatọ laarin ọkan ninu awọn ojisẹ Rẹ » [Suuratul-Baqarah: 285].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} إنا كل شيء خلقناه بقدر { [سورة القمر: 49].

« Dajudaju awa sẹda gbogbo nnkan pẹlu ebubu -kadara- » [Suuratul-Qamar: 49].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” si sọ pe:

(( الإيمان أن تؤمن بالله، وملائكته، وكتبه، ورسله، واليوم الآخر، وتؤمن بالقدر: خيره وشره )). [رواه مسلم].

« Igbagbo-ododọ ni ki o gba Ọlọhun gbọ, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati akọsilẹ -kadara-: rere rẹ ati aburu ». [Muslim l’o gbe e jade].

Igbagbo-ododo -Iimaani- ni ọrọ kan [ti a n sọ] pẹlu ahọn, ati adisọkan, ati sisisẹ pẹlu awọn orike, a maa lekun pẹlu titẹle ti Ọlọhun, a si maa dinku pẹlu dida ẹsẹ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إنما المؤمنون الذين إذا ذكر الله وجلت قلوبهم وإذا تليت عليهم آياته زادتهم إيماناً وعلى ربهم يتوكلون. الذين يقيمون الصلاة ومما رزقناهم ينفقون. أولئك هم المؤمنون حقا { [سورة الأنفال: 2-4].

« Awọn olugbagbọ-ododo ni awọn t’o se pe nigba ti a ba darukọ Ọlọhun, ẹwariri a maa mu awọn ọkan wọn, nigba ti a ba si ka awọn aayah Rẹ [Al-Qur’aan] fun wọn, a maa se alekun igbagbọ fun wọn, bẹẹ ni Oluwa wọn ni wọn maa n gbẹkẹle. Awọn ti wọn maa n gbe irun duro, ti wọn si maa n na ninu ohun ti A fi rọ wọn lọrọ. Awọn wọnyi ni awọn olugbagbọ ni ododo » [Suuratu l-Anfaal: 2-4].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} ومن يكفر بالله وملائكته وكتبه ورسله واليوم الآخر فقد ضل ضلالا بعيداً { [سورة النساء: 136].

« Ati pe ẹni t’o ba se aigbagbọ si Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, dajudaju o ti sọnu ni sisọnu ti o jinna » [Suuratu -n-Nisaa’i: 136].

Nitori naa igbagbọ-ododo a maa sẹlẹ pẹlu ahọn: Gẹgẹ bi sise iranti Ọlọhun, ati adua, ati ifooro ẹni si daadaa sise, ati kikọ fun eniyan lati se aidaa, ati kike Al-Qur’aan, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ati pe a tun maa sẹlẹ pẹlu ọkan: Gẹgẹ bi nini adisọkan nipa jijẹ ọkan soso Ọlọhun ninu awọn isẹ Rẹ, ati ninu jijẹ ẹni-ajọsin fun, ati ninu awọn orukọ ati awọn iroyin Rẹ, ati ninu jijẹ ọranyan pe ki a jọsin fun Ọlọhun nikan soso, kò si orogun kan fun Un, ati awọn ohun ti yoo wọ inu eleyii, ninu awọn aniyan, ati awọn akolekan. Ati gẹgẹ bi awọn isẹ ọkan: Ipaya Ọlọhun, iseripada si ọdọ Ọlọhun, igbẹkẹle E, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu ohun ti maa n wọ inu ohun ti a n pe ni igbagbọ-ododo -Iimaani-. Bakan naa awọn isẹ ti a maa n fi orike ara se, gẹgẹ bi irun kiki, aawẹ gbigba, ati awọn origun ẹsin Islam yoku, ati ogun jija si oju-ọna Ọlọhun, imọ wiwa, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu ohun ti maa n wọ inu ohun ti a n pe ni igbagbo-ododo -Iimaani-.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وإذا تليت عليهم آياته زادتهم إيماناً { [سورة الأنفال: 2].

« Ati pe nigba ti a ba ka awọn aayah Rẹ [Al-Qur’aan] fun wọn, a maa se alekun igbagbọ fun wọn » [Suuratu l-Anfaal: 2].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} هو الذي أنزل السكينة في قلوب المؤمنين ليزدادوا إيمانا مع إيمانهم { [سورة الفتح: 4].

« Oun l’O sọ ifayabalẹ kalẹ sinu ọkan awọn olugbagbọ-ododo, ki wọn o le baa ni alekun igbagbọ kun igbagbọ wọn » [Suuratu l-Fat’h: 4].

Igbagbo eniyan a si maa lekun ni gbogbo igba ti titẹle ti Ọlọhun, ati awọn ohun t’o n fi n wa oju-rere Rẹ, ba n lekun, bẹẹ ni a maa dinku ni gbogbo igba ti titẹle ti Ọlọhun, ati awọn ohun t’o fi n wa oju-rere rẹ ba dinku, gẹgẹ bi awọn ẹsẹ naa ti se maa n lapa lara rẹ. Nitori naa ti ẹsẹ naa ba jẹ ẹbọ ninla, tabi aigbagbọ ninla, yoo tu gbongbo igbagbo-ododo ti Sharia ka, yoo si ba a jẹ. Sugbọn ti o ba kere si eleyii, yoo kan tu pipe rẹ ti o jẹ ọranyan ka ni, tabi ki o gbọn panti si mimọ kedere rẹ, ki o si ko ọlẹ ba a.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إن الله لا يغفر أن يشرك به ويغفر ما دون ذلك لمن يشاء { [سورة النساء: 116].

« Dajudaju Ọlọhun kò ni I se aforijin [fun ẹnikan] lori wiwa orogun fun Un, sugbọn yoo se aforijin ohun ti kò to eleyii fun ẹni ti O ba fẹ » [Suuratu n-Nisaa’i :116]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} يحلفون بالله ما قالوا ولقد قالوا كلمة الكفر وكفر بعد إسلامهم { [سورة التوبة: 74].

« Wọn n fi Ọlọhun bura pe awọn kò wi [i], ati pe dajudaju wọn ti wi gbolohun aigbagbọ, bẹẹ ni wọn ti se aigbagbọ lẹyin igbafa fun Ọlọhun [Islam] wọn » [Suuratu -t-Tawbah: 74].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” si sọ pe:

(( لا يزني الزاني حين يزني وهو مؤمن، ولا يسرق السارق حين يسرق وهو مؤمن ولا يشرب الخمر حين يشربها وهو مؤمن )). [متفق عليه].

« Alagbere kan kò ni i se agbere ki o jẹ olugbagbọ-ododo ni asiko ti n se agbere, ati pe ole kan kò ni i jale ki o jẹ olugbagbọ-ododo ni asiko ti n jale, bẹẹ ni ọmuti kan kò ni i muti ki o jẹ olugbagbọ-ododo ni asiko ti n muti » Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade.

___

 ORIGUN KINNI: GBIGBA ỌLỌHUN ỌBA T’O GA T’O SI GBỌN-UN-GBỌN GBỌ LODODO

 [1] Fifi i rinlẹ:

Nini igbagbọ si Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn, a maa rinlẹ pẹlu awọn ohun ti n bọ wọnyi:

Alakọkọ ni: Nini adisọkan pe dajudaju ile-aye yii ni Oluwa kan soso, ti O da sẹda rẹ, ti O si da ni ijọba rẹ, ati akoso rẹ, ati tito eto rẹ, ni ti irọnilọrọ, ikapa, ati sise isẹ, ati mimuni maa bẹ laaye, ati pipani, ati siseni lanfaani, ati ininilara, kò si oluwa kan yatọ si I, Oun nikan ni si maa n se ohun ti O ba fẹ, A si maa da ohun ti O gba lero lẹjọ, A maa gbe ẹni ti O fẹ ga, A si maa rẹ ẹni ti O ba fẹ silẹ, ọwọ Rẹ ni akoso awọn sanma ati ilẹ wa, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan, Oun si ni Olumọ nipa gbogbo nnkan, O rọrọ kuro ni ọdọ gbogbo ohun ti o yatọ si I, tiẸ ni gbogbo ọrọ, bẹẹ ni ọwọ Rẹ ni gbogbo oore wa, kò ni orogun kan ninu awọn isẹ Rẹ, kò si si ẹnikan ti o le bori Rẹ lori ọrọ Rẹ, koda ẹru Rẹ ni awọn ẹda lapapọ, ti o fi de ori awọn malaika, ati awọn eniyan, ati awọn alujannu, wọn kò le jade kuro labẹ ijọba Rẹ, tabi ikapa Rẹ, tabi awọn erongba Rẹ -mimọ ni fun Un-. Ati pe awọn isẹ Rẹ kò se e ka, kò tilẹ si onka kankan fun wọn rara. Ẹtọ Ọlọhun nikan ni gbogbo awọn iroyin wọnyi, kò si orogun kan fun Un, ẹnikan kò si ni ẹtọ si wọn [rara] lẹyin Rẹ, ati pe kò tọ wi pe ki a fi wọn ti [si ọdọ ẹnikan], tabi ki a fi wọn rinlẹ fun ẹlomiran, t’o yatọ si Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يا أيها الناس اعبدوا ربكم الذي خلقكم والذين من قبلكم لعلكم تتقون. الذي جعل لكم الأرض فراشا والسماء بناء وأنزل من السماء ماء فأخرج به من الثمرات رزقا لكم { [سورة البقرة: 20-21].

« Ẹyin eniyan, ẹ maa sin Oluwa yin, Ẹni ti O da yin ati awọn ẹni ti wọn siwaju yin, ki ẹ le baa maa paya [Rẹ]. Ẹni ti O se ilẹ fun yin ni itẹ, ti O si se sanma fun yin ni mimọ, ti O si N sọ omi [ojo] kalẹ fun yin lati sanma, ti O si fi n mu awọn irugbin jade, ni ti ipese fun yin » [Suuratul-Baqarah: 20-21]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} قل اللهم مالك الملك تؤتي الملك من تشاء وتنـزع الملك ممن تشاء وتعز من تشاء وتذل من تشاء بيدك الخير إنك على كل شيء قدير { [سورة آل عمران: 26].

« Sọ pe: Iwọ Ọlọhun! Olukapa ijọba, O maa N fun ẹni ti O ba fẹ ni ijọba, O si maa N gba ijọba kuro lọwọ ẹni ti O ba fẹ, O si maa N fun ẹni ti O ba fẹ niyi, O si maa N yẹpẹrẹ ẹni ti O ba fẹ. Ọwọ Rẹ ni gbogbo rere wa, dajudaju Iwọ ni Alagbara lori gbogbo nnkan » [Suuratu Aala Imraan: 26]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وما من دابة في الأرض إلا على الله رزقها ويعلم مستقرها ومستودعها كل في كتاب مبين { [سورة هود: 6].

« Kò si ẹda kan ti n rin ni ori ilẹ afi ki ọrọ -arziki- rẹ o maa bẹ lọdọ Ọlọhun, ati pe O mọ ibugbe rẹ ati ibupamọ rẹ, gbogbo [eleyii] n bẹ ninu tira ti o han » [Suuratu Huud: 6]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} ألا له الخلق والأمر تبارك الله رب العالمين { [سورة الأعراف: 54].

« Tẹti ki o gbọ, tiẸ ni dida ẹda ati asẹ i se, ibukun ni fun Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda » [Suuratul-A’araaf: 54].

Ẹlẹẹkeji ni: Nini adisọkan nipa jijẹ ọkan soso Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn, pẹlu awọn orukọ ti o dara ju, ati awọn iroyin ti o pe ju, eyi ti O fi ara Rẹ mọ awọn ẹda Rẹ lati ara apa kan wọn, ti o wa ninu Tira Rẹ, tabi ninu Sunna -ilana- ipẹkun awọn anabi Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- sọ pe:

} ولله الأسماء الحسنى فادعوه بها وذروا الذين يلحدون في أسمائه سيجزون ما كانوا يعملون { [سورة الأعراف: 180].

« Ti Ọlọhun ni awọn orukọ ti o dara ju. Nitori naa ẹ maa fi wọn pe E, ki ẹ si fi awọn ẹni ti wọn n yẹ awọn orukọ Rẹ kuro lori ododo silẹ, a o san wọn ni ẹsan ohun ti wọn n se ni isẹ » [Suuratu l-A’araaf: 180].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” si sọ pe:

(( إن لله تسعة وتسعين اسماً، من أحصاها دخل الجنة، وهو وتر يحب الوتر )) متفق عليه.

« Dajudaju Ọlọhun ni awọn orukọ mọkandinlọgọrun, ẹnikẹni ti o ba sọ wọn yoo wọ ọgba-idẹra -Al-Janna-  ati pe àáso ni Ọlọhun, O si fẹran àáso » Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade.

Ori ipilẹ meji ninla kan ni adisọkan yii duro le lori:

Alakọkọ ni: Wi pe dajudaju Ọlọhun ni awọn orukọ ti o dara ju, ati awọn iroyin ti o ga ju, eyi ti n tọka si awọn iroyin ti o pe, ti kò si si abuku kan bi o ti wu ki o ri ninu rẹ. Nitori naa nnkan kan ninu awọn ẹda kò jọ ọ, bẹẹ ni ẹnikan ki i ba a se orogun ninu rẹ.

Ninu awọn orukọ Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- ni:  (الحي  ) « Alaaye », o si ni iroyin ( الحياة ) « Isẹmi », eyi ti o jẹ ọranyan pe ki a fi rinlẹ fun Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn Naa, ni ọna ti o pe, ti o si tọ si I, ati pe isẹmi yii isẹmi ti o pe, ti kò ni opin ni i, awọn orisirisi pipe l’o wa ninu rẹ, bii imọ, agbara, ati bẹẹ bẹẹ lọ, aisi kò siwaju rẹ, piparẹ kò si ni i ba a. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الله لا إله إلا هو الحي القيوم لا تأخذه سنة ولا نوم { [سورة البقرة: 255].

« Allahu [Ọlọhun], kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si I, Alaaye, Oludawa, ki I toogbé, bẹẹ ni ki I sun rara » [Suuratul-Baqarah: 255].

Ẹlẹẹkeji ni: Wi pe Ọlọhun t’O ga mọ kuro nibi awọn iroyin aipe, ati nibi gbogbo abuku lapapọ, gẹgẹ bi oorun ati ikagara, aimọ, abosi, ati bẹẹ bẹẹ lọ, gẹgẹ bi Ọba t’O ga Naa ti tun mọ kuro ninu jijọ awọn ẹda Rẹ. Nitori naa dandan ni pe ki a le ohun ti Ọlọhun le jinna kuro ni ọdọ ara Rẹ, ati eyi ti Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” le jinna kuro ni ọdọ Oluwa Rẹ, pẹlu nini adisọkan wi pe dajudaju iroyin Rẹ ni eyi ti o pe ninu atodijẹ eyi ti O le jinna kuro ni ọdọ ara Re. Nitori naa ti a ba le oogbé ati oorun jinna si I, [ki a mọ pe] fifi pipe idaduro rinlẹ n bẹ ninu lile oogbé jinna si I. Bẹẹ ni fifi pipe isẹmi rinlẹ -fun Un- wa ninu lile oorun jinna si I. Ati pe bayii ni gbogbo ohun ti a ba le jinna kuro ni ọdọ Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbon-un-gbon, ri, lile jinna naa se akojọpọ fifi pipe atodijẹ rẹ rinlẹ. Nitori naa Oun ni O pe, ohun ti o ni abuku lara si ni gbogbo ohun ti o yatọ si I. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ليس كمثله شيء وهو السميع البصير { [سورة الشورى: 11].

« Kò si nnkan kan ti o da gẹgẹ bi Rẹ [Ọlọhun], Oun ni Olugbọrọ Oluriran » [Suuratush-Shuuraa’: 11].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وما ربك بظلام للعبيد { [سورة فصلت: 46].

« Oluwa Rẹ ki I se alabosi rara si awọn ẹda Rẹ » [Suuratu Fusilat: 46].

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وما كان الله ليعجزه من شيء في السموات ولا في الأرض { [سورة فاطر: 44].

« Ọlọhun kò jẹ [Ẹni ti] nnkan kan le da ni agara ninu awọn sanma tabi ni ilẹ » [Suuratu Faatir: 44].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وما كان ربك نسياً { [سورة مريم، الآية: 64].

« Oluwa rẹ kò jẹ Olugbagbe [rara] » [Suuratu Maryam: 64].

Ati pe nini igbagbọ si awọn orukọ Ọlọhun, ati si awọn iroyin Rẹ, ati awọn isẹ Rẹ ni: Ọna kan pere lati mọ Ọlọhun, ati ijọsin fun Un. Eleyii jẹ bẹẹ nitori pe dajudaju Ọlọhun gbe riri I ni ojukoroju ninu isẹmi ile-aye pamọ si awọn ẹda Rẹ, O si si ilẹkun imọ yii fun wọn, eyi ti o se pe wọn yoo maa ti ara rẹ mọ Oluwa wọn, ati Ọlọhun wọn, ati Ẹni-Ajọsin-fun wọn, ti wọn yoo si maa jọsin fun Un ni ibamu pẹlu imọ ti o se deedee, ti o si dara naa. Olusẹsin kò sin ẹnikan yatọ si Ẹni ti n royin; nitori naa asan ni ẹni ti o fi ẹyin awọn iroyin Ọlọhun ti n sin, ère si ni olufi Ọlọhun we ẹda Rẹ n sin, sugbọn Ọlọhun, Ọba kan soso, Ọba ti a n ronu kan, Ẹni ti kò bimọ, ti ẹnikan kò si bi I, ti kò si ni alafijọ kankan, ni Musulumi n sin.

 O yẹ ki a maa se akiyesi awọn ohun ti n bọ wọnyi nigba ti a ba n fi awọn orukọ Ọlọhun ti o dara ju rinlẹ:

1- Nini igbagbọ si rinrinlẹ gbogbo awọn orukọ ti o dara ju naa, eyi ti o wa ninu Al-Qur’aan ati ninu Sunna, lai kò se afikun lori wọn, lai kò si dinku ninu wọn.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} هو الله الذي لا إله إلا هو الملك القدوس السلام المؤمن المهيمن العزيز الجبّار المتكبر سبحان الله عما يشركون { [سورة الحشر، الآية: 32].

« Oun ni Ọlọhun Ẹni ti kò si ọba kan ti o tọ lati sin ni ododo yatọ si I, Ọba “Alakoso”, Ẹni-mimọ, Olumọ kuro ninu gbogbo alebu, Ẹlẹri-ododo [fun awọn ojisẹ Rẹ], Oluri gbogbo nnkan, Alagbara, Olujẹni-n-pa, Oni-Moto-Moto, mimọ ni fun Ọlọhun kuro nibi ohun ti wọn fi n se orogun fun Un » [Suuratul-Hashr: 32].

O si rinlẹ ninu Sunna pe Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, gbọ ti ọkunrin kan n sọ pe:

اللهم إني أسألك بأن لك الحمد لا إله إلا أنت المنان بديع السموات والأرض يا ذا الجلال والإكرام يا حي يا قيوم. فقال النبي ﷺ‬ : (( تدرون بما دعا الله؟ قالوا: الله ورسوله أعلم، قال: والذي نفسي بيده لقد دعا الله باسمه الأعظم الذي إذا دعي به أجاب، وإذا سئل به أعطى )). [رواه أبو داود وأحمد].

Iwọ Ọlọhun, dajudaju emi n tọrọ lọdọ Rẹ pe: Dajudaju tiẸ ni gbogbo ọpẹ, kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọ, Olufunni-ni-idẹra, Olupilẹda awọn sanma ati ilẹ, Iwọ Oni-titobi ati ipọnnile, Iwọ Alaaye, Iwọ Oludaduro. N ni Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ba sọ pe: « Njẹ ẹ wa mọ ki l’o fi pe Ọlọhun bi? » Wọn ni: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ l’o ni mimọ ju; Anabi ni: Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju o ti pe Ọlọhun pẹlu orukọ Rẹ ti o tobi ju, eyi ti o se pe ti a ba fi i pe E, yoo dahun, ti a ba si fi i tọrọ [nnkan] lọdọ Rẹ, yoo fun’ni » [Abu Daa’uud, ati Ahmad, l’o gbe e jade].

2- Nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun ni Ẹni ti O sọ ara Rẹ lorukọ, ẹnikan ninu awọn ẹda Rẹ kò si gbọdọ sọ Ọ lorukọ, bẹẹ ni Ọba ti O ga, t’O si gbon-un-gbon Naa, ni Ẹni ti O yin ara Rẹ pẹlu awọn orukọ wọnyi, wọn ki i se ohun titun ti a da rara.

3- Gbigbagbọ pe dajudaju awọn orukọ Ọlọhun ti o dara ju naa n tọka si awọn itumọ ti o jẹ opin pipe, eyi ti o se pe abuku kan kò gba ọna kan bẹ ninu wọn. Nitori naa ọranyan ni ki a gba awọn itumọ naa gbọ, gẹgẹ bi o ti se jẹ ọranyan pe ki a gba awọn orukọ wọnyi gbọ.

4- Wi pe ọranyan ni sise apọnle awọn itumọ awọn orukọ wọnyi, ati sisọra fun sise atako wọn, nipa yiyi itumọ wọn pada, tabi pẹlu fifi ẹyin wọn ti.

5- Nini igbagbọ si ohun ti orukọ kọọkan ninu awọn orukọ wọnyi n tọka si ninu awọn idajọ, ati ohun ti o rọ mọ ọn ninu awọn isẹ, ati awọn oripa.

A o fi orukọ Ọlọhun As-Samii’u: -Ọba Olugbọ- se apejuwe, ki awọn nnkan marun-un wọnyi o le baa han. Nitori naa ọranyan ni ki a se akiyesi ohun ti n bọ yii ni ara rẹ:

(a) Nini igbagbọ pe As-Samii’u “Olugbọ” orukọ kan ni i ninu awọn orukọ Ọlọhun ti o dara ju, nitori wiwa ti o wa ninu Al-Qur’aan ati Sunna.

(b) Gbigbagbọ pe Ọlọhun l’O fi i sọ ara Rẹ, Oun l’O si sọ ọ lọrọ, ti O si sọ ọ kalẹ si inu tira Rẹ t’o bori.

(d) Gbigbagbọ pe As-Samii’u naa se akojọpọ itumọ gbigbọ, eyi ti i se iroyin kan ninu awọn iroyin Ọlọhun.

(e) Wi pe ọranyan ni sise apọnle iroyin gbigbọ, eyi ti orukọ As-Samii’u n tọka si, ati àìkò yi itumọ rẹ pada, tabi fifi ẹyin rẹ ti.

(ẹ) Gbigbagbọ wi pe Ọlọhun n gbọ gbogbo nnkan, ati pe gbigbọrọ Rẹ kari gbogbo awọn ohùn, ati nini igbagbọ si awọn ipa ti o rọ mọ igbagbọ yii, ti i se ọranyan sise akiyesi Ọlọhun, ati ipaya Rẹ, ati ibẹru Rẹ, ati nini amọdaju ti o pe nipa pe nnkan ti o pamọ kan kò le e pamọ si Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn.

 O si tun yẹ ki a maa se akiyesi awọn ohun t’o n bọ wọnyi nibi fifi awọn iroyin Ọlọhun rinlẹ:

1- Fifi gbogbo awọn iroyin ti o wa ninu Al-Qur’aan ati Sunna rinlẹ fun Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbon-un-gbon, ni paapaa fifi wọn rinlẹ, lai kò yi itumọ wọn pada, lai kò si fi ẹyin wọn ti.

2- Nini adisọkan ti o gbopọn pe Ọlọhun -giga ni fun Un- Ẹni ti a maa n royin pẹlu awọn iroyin ti o pe ni I, O si mọ kuro nibi awọn iroyin aipe, ati ti abuku.

3- Pe awọn iroyin Ọlọhun kò jọ awọn iroyin awọn ẹda, nitori pe dajudaju kò si nnkan kan ti o jọ Ọlọhun -mimọ ni fun Un- rara ninu awọn iroyin Rẹ, tabi ninu awọn isẹ Rẹ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ليس كمثله شيء وهو السميع البصير { [سورة الشورى: 11].

« Kò si nnkan kan ti o da gẹgẹ bi Rẹ [Ọlọhun], Oun ni Olugbọrọ Oluriran » [Suuratu Ash-Shuuraa: 11].

4- Jijakan kuro nibi mimọ bi awọn iroyin wọnyi ti ri ni ajatan, tori pe ẹnikan kò mọ bi iroyin Ọlọhun ti ri yatọ si I, kò si ọna ti ẹda kan le gba mọ nipa eleyii.

5- Nini igbagbọ si awọn ohun ti o rọ mọ awọn iroyin wọnyi, ni awọn idajọ, ati ohun ti wọn n tọka si ninu awọn oripa. Nitori naa gbogbo iroyin l’o ni ijọsin.

A o fi iroyin Al-Istiwaa’ -Gigunwa Ọlọhun lori aga ọla Rẹ- se apejuwe. Nitori naa ọranyan ni ki a se akiyesi ohun ti n bọ yii ninu rẹ:

1- Fifi iroyin Al-Istiwaa’ -Gigunwa Ọlọhun lori aga ọla Rẹ- rinlẹ, ki a si gba a gbọ, nitori wiwa ti o wa ninu awọn ọrọ ofin Sharia; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} الرحمن على العرش استوى { [سورة طه: 5].

« Ar-Rahmaan -Ọba Alaanujulọ- gunwa lori aga-ọla Rẹ » [Suuratu Taahaa: 5].

2- Fifi iroyin Al-Istiwaa’ -Gigunwa Ọlọhun lori aga ọla Rẹ- rinlẹ fun Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn, ni ọna ti o pe, ti o si tọ si I -giga ni fun Un-. Ati pe itumọ rẹ ni giga Ọlọhun, ati wiwa Rẹ ni oke aga-ọla Rẹ ni paapaa, ni ọna ti o tọ si gbigbọn-un-gbọn Rẹ, ati rirọrọ Rẹ.

3- Aifi gigunwa Ẹlẹda si ori aga-ọla Rẹ we gigunwa awọn ẹda. Nitori naa Ọlọhun rọrọ kuro nibi aga-ọla Rẹ, kò ni bukaata si i, sugbọn ohun ti o bi gigunwa ti awọn ẹda ni aini, ati nini bukaata; fun ọrọ Ọlọhun -giga ni fun Un- t’o sọ pe:

} ليس كمثله شيء وهو السميع البصير { [سورة الشورى: 11].

« Kò si nnkan kan ti o da gẹgẹ bi Rẹ [Ọlọhun], Oun ni Olugbọrọ Oluriran » [Suuratu Ash-Shuuraa: 11].

4- Àìkò ti ẹnu bọ sisọ nipa bawo l’O ti se gunwa lori aga-ọla Rẹ, nitori pe ohun ti o pamọ ni eleyii i se, ẹnikan kò si mọ ọn yatọ si Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn.

5- Nini igbagbọ si idajọ ati oripa ti o rọ mọ ọn, bii fifi titobi Ọlọhun, ati gbigbọn-un-gbọn Rẹ, rinlẹ, ati motómotó Rẹ, ti o tọ si I, eyi ti giga ainilopin Rẹ -mimọ ni fun Un- lori gbogbo awọn ẹda lapapọ tọka si, ati dida oju awọn ọkan kọ ọdọ Rẹ ni aaye t’o ga naa, gẹgẹ bi ẹni ti o fi ori kanlẹ ti i maa n sọ pe:

( سبحان ربي الأعلى )

« Mimọ ni fun Oluwa mi, Ọba t’O ga ju ».

Ẹlẹẹkẹta: Adisọkan eniyan pe Ọlọhun ni Ọba Ododo ti àá jọsin fun, Ọba àáso nipa nini ẹtọ si gbogbo awọn ijọsin, eyi ti o han, ati eyi ti o pamọ, l’Oun nikan, kò si orogun kan fun Un.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولقد بعثنا في كل أمة رسولاً أن اعبدوا الله واجتنبوا الطاغوت { [سورة النحل: 36].

« Ati pe dajudaju A ti gbe ojisẹ kan dide ninu gbogbo ijọ kọọkan; pe: Ẹ maa jọsin fun Ọlọhun, ki ẹ si jinna si awọn oosa » [Suuratu n-Nah’l :36].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وما أمروا إلا ليعبدوا الله مخلصين له الدين حنفاء { [سورة البينة: 5].

« Ati pe A kò pa wọn lasẹ [pẹlu nnkan kan] yatọ si ki wọn o maa sin Ọlọhun, l’ẹni ti n se afọmọ ijọsin fun Un, ti o fi ọna ti kò tọ silẹ » [Suuratul-Bayyinah: 5].

O si wa ninu awọn Sahiih mejeeji, pe: Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ fun Mu’aadz pe:

(( أتدري ما حق الله على العباد، وما حق العباد على الله. قلت: الله ورسوله أعلم. قال: حق الله على العباد أن يعبدوه ولا يشركوا به شيئاً، وحق العباد على الله ألا يعذب من لا يشرك به شيئاً )).

« Njẹ o wa mọ ki ni iwọ Ọlọhun lori awọn ẹda Rẹ, ki si ni iwọ awọn ẹda lori Ọlọhun bi? ». Mo ni: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn ni mimọ ju. Anabi ni: « Iwọ Ọlọhun lori awọn ẹda Rẹ ni: Ki wọn o maa jọsin fun Un, ki wọn o si ma se fi nnkan kan se orogun fun Un; sugbọn iwọ awọn ẹda lori Ọlọhun ni: Ki O ma se fi iya jẹ ẹni ti kò ba fi nnkan kan se orogun pẹlu Rẹ ».

Ọba Ododo ti àá jọsin fun ni: Ẹni ti awọn ọkan maa n jọsin fun, ti wọn si maa n kun pẹlu ifẹ Rẹ kuro nibi ifẹ ohun ti o yatọ si I, irankan si I a si maa to wọn kuro nibi rirankan si ohun ti o yatọ si I, wọn a si maa rọrọ pẹlu titọrọ [nnkan] lọdọ Rẹ, ati wiwa iranlọwọ lọdọ Rẹ, ati bibẹru Rẹ, ati pipaya Rẹ, kuro ni ọdọ ohun ti o yatọ si I.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ذلك بأن الله هو الحق وأن ما يدعون من دونه هو الباطل وأن الله هو العلي الكبير { [سورة الحج، الآية 62].

« Eleyii [ri bẹẹ] tori pe dajadaju Ọlọhun ni Ododo, ati pe dajudaju ohun ti wọn n pe lẹyin Rẹ ni irọ, dajudaju Ọlọhun si ni Ọba giga, Ọba titobi » [Suuratul-Hajj: 62].

Eleyii ni sise Ọlọhun ni ọkan soso pẹlu awọn isẹ awọn ẹru.

 PIPATAKI AT-TAWHIID -SISE ỌLỌHUN NI ỌKAN NINU IJỌSIN-

Pipataki At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan ninu ijosin- yii yoo maa han ni ara ohun ti n bọ yii:-

1- Wi pe oun ni akọkọ ẹsin yii, ati opin rẹ, ati ipari rẹ, ode rẹ ati inu rẹ, oun si ni ipepe awọn ojisẹ Ọlọhun, “ki ọla Ọlọhun o maa ba  wọn”.

2- Nitori At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin- yii ni Ọlọhun se da awọn ẹda, ti O si ran awọn ojisẹ, ti O si sọ awọn tira kalẹ, nitori rẹ si ni awọn ẹda se yapa sira wọn, ti wọn si pin si olugbagbọ-ododo, ati alaigbagbọ, oloriire ati oloriibu.

3- Wi pe oun ni akọkọ ohun ti o jẹ ọranyan lori ẹni ti a la iwọ ijọsin bọ lọrun, oun si ni akọkọ ohun ti eniyan yoo fi wọ inu Islam, bẹẹ ni oun ni opin ohun ti yoo mu jade kuro laye.

 Fifi At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan ninu ijọsin- rinlẹ:-

Fifi At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan- naa rinlẹ ni: Fifọ ọ mọ, ati jijọ ọ kuro ninu awọn idọti isẹbọ si Ọlọhun, ati adadaalẹ, ati awọn ẹsẹ.

Ọna meji l’o si pin si: Oranyan, ati ohun ti a seni lojukokoro lati se.

Eyi ti o jẹ ọranyan yoo maa sẹlẹ pẹlu nnkan mẹta:

1-      Fifọ ọ mọ kuro ninu As-Shirk -isẹbọ si Ọlọhun- eyi ti o tako ipilẹ At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan ninu ijọsin-.

2-      Fifọ ọ mọ kuro ninu Bid’a -adadaalẹ- eyi ti o tako pipe rẹ ti o jẹ ọranyan, tabi ti o tako ipilẹ rẹ; iyẹn ti o ba jẹ ọkan ninu awọn adadaalẹ ti maa n sọ eniyan di alaigbagbọ.

3-      Fifọ ọ mọ kuro ninu awọn ẹsẹ ti i maa dinku ninu awọn ẹsan rẹ, ti i si maa n lapa ni ara rẹ.

Sugbọn eyi ti o jẹ ohun ti a seni lojukokoro lati se: Oun ni ohun ti a fi pa’ni l’asẹ ni ipanilasẹ ti a nifẹ si, ninu awọn apejuwe rẹ ni ohun ti n bọ yii:

(a) Fifi pipe ipele daadaa sise rinlẹ.

(b) Fifi pipe ipele amọdaju rinlẹ.

(e) Fifi pipe suuru ti o dara rinlẹ, latari àìkò fi ẹjọ sun ẹlomiran ti o yatọ si Ọlọhun -giga ni fun Un.

(ẹ) Fifi pipe irọrọ tayọ awọn ẹda Ọlọhun rinlẹ, pẹlu titọrọ [nnkan] lọdọ Ọlọhun.

(f) Fifi ipele igbẹkẹle Ọlọhun rinlẹ pẹlu fifi apa kan ninu awọn ohun t’o tọ silẹ ninu awọn okunfa -sababi- gẹgẹ bi titọrọ Ar-Ruqyaa -adua isọ- ati jijo egbo, ni ti gbigbẹkẹle Ọlọhun, Ọba t’O ga.

(g) Fifi pipe ipele ifẹ ti ijọsin rinlẹ, pẹlu wiwa sisunmọ Ọlọhun pẹlu awọn Naafila.

Nitori naa ẹnikẹni ti o ba fi At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin- rinlẹ, ni ọna ti alaye rẹ siwaju yii, ti o si mọ kuro ninu isẹbọ si Ọlọhun, ni ẹbọ ti o tobi, ifayabalẹ yoo bẹ fun un nipa pe kò ni i bẹ ninu ina gbere-kese. Ati pe ẹnikẹni ti o ba mọ kuro ninu isẹbọ si Ọlọhun, ni ẹbọ ti o tobi, ati eyi ti o kere, ti o si jinna si awọn ẹsẹ nlanla, ati awọn ẹsẹ kékéké, ibalẹ-ọkan ti o pe n bẹ fun un ni ile-aye, ati ni ọrun.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إن الله لا يغفر أن يشرك به ويغفر ما دون ذلك لمن يشاء { [النساء: 116].

« Dajudaju Ọlọhun kò ni I se aforijin [fun ẹnikan] lori wiwa orogun fun Un, sugbọn yoo se aforijin ohun ti kò to eleyii fun ẹni ti O ba fẹ » [Suuratu n-Nisaa’i :116]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} الذين آمنوا ولم يلبسوا إيمانهم بظلم أولئك لهم الأمن وهم مهتدون {. [سورة الأنعام: 82].

« Awọn ti wọn gba Ọlọhun gbọ lododo, ti wọn kò si lu igbagbọ wọn pọ mọ abosi -ẹbọ sise- awọn wọnyi ni ibalẹ-ọkan n bẹ fun, awọn naa si ni awọn olumọna » [Suuratu l-An’aam :82].

 Atodijẹ At-Tawhiid ni As-Shirk -isẹbọ si Ọlọhun-

Ipin mẹta l’o pin si:

1- Isẹbọ si Ọlọhun ni ẹbọ ninla ti o tako ipilẹ At-Tawhiid; Ọlọhun kò ni I se aforijin lori rẹ, afi pẹlu ironupiwada kuro nidi rẹ. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba ku si ori rẹ, yoo jẹ ẹni ti yoo maa bẹ ninu ina laelae. Oun ni ki eniyan o wa orogun fun Ọlọhun ninu ijọsin Rẹ, ki o maa pe e gẹgẹ bi o ti se n pe Ọlọhun, ki o si maa ronu kan an, ki o si gbẹkẹle e, ki o si maa ni irankan lọ si ọdọ rẹ, ki o si nifẹ rẹ, ki o si maa bẹru rẹ, gẹgẹ bi o ti se nifẹ Ọlọhun, ti i si n bẹru Rẹ.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} إنه من يشرك بالله فقد حرم الله عليه الجنة ومأواه النار وما للظالمين من أنصار { [سورة المائدة: 72].

« Dajudaju ẹnikẹni ti o ba se ẹbọ si Ọlọhun, dajuadaju Ọlọhun ti se ọgba-idẹra -Al-Janna- ni eewọ fun un, ibupadasi rẹ si ni ina, ati pe kò si oluranlọwọ kan fun awọn alabosi » [Suuratul-Maa’idah: 72].

2- Isẹbọ si Ọlọhun ni ẹbọ kekere ti o tako pipe rẹ: Oun ni gbogbo ọna kan, tabi okunfa kan ti a le gba lọ sibi ẹbọ ninla; gẹgẹ bi fifi ohun ti o yatọ si Ọlọhun bura, ati sise karimi diẹ.

3- Ẹbọ ti o pamọ: Oun ni eyi ti o rọ mọ adisọkan ati erongba, ati pe o le jẹ [ẹbọ] ninla tabi [ẹbọ] kekere, gẹgẹ bi afihan rẹ ti siwaju ninu alakọkọ ati ẹlẹẹkeji.

O wa lati ọdọ Mahmuud ọmọ Labiid, “ki Ọlọhun O yọnu si i”, pe Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( إن أخوف ما أخاف عليكم الشرك الأصغر. قالوا: وما الشرك الأصغر يا رسول الله؟، قال: الرياء )) [رواه أحمد].

« Dajudaju ohun ti mo n bẹru ju lori yin ni ẹbọ kekere. Wọn ni: ki ni ẹbọ kekere? Anabi ni: Karimi ». [Ahmad l’o gbe e jade].

 [2] Alaye Ijọsin:

Ijọsin: Orukọ kan ni i ti o se akojọpọ gbogbo ohun ti Ọlọhun nifẹ si, ti o si yọnu si, ninu awọn adisọkan, ati awọn isẹ ọkan, ati awọn isẹ awọn orike ara, ati gbogbo ohun ti maa n sun eniyan mọ Ọlọhun, ninu awọn isẹ, ati awọn ohun ti a maa n fi silẹ.

Bakan naa gbogbo ohun ti Ọlọhun se ni ofin ninu Tira Rẹ, tabi ninu Sunna Ojisẹ Rẹ, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, l’o wọ inu orukọ ijọsin naa. Ati pe awọn orisirisi ijọsin ni wọn. Nitori naa awọn ijọsin ti ọkan n bẹ ninu wọn, gẹgẹ bi awọn origun igbagbọ-ododo -Iimaan- ati ibẹru, ati irankan, ati igbẹkẹle Ọlọhun, ati sise ojukokoro idẹra Rẹ, ati ibẹru iya Rẹ, ati awọn mìíran ninu awọn ijọsin naa. Ninu wọn si tun ni awọn ijọsin ti o han, gẹgẹ bi irun, ati Zaka, aawẹ, ati Haji.

 Ijọsin naa kò si le e dara titi ti yoo fi jẹ ohun ti a mọ sori ipilẹ meji:

Alakọkọ ni: Sise afọmọ ijọsin naa fun Ọlọhun, ati àìkò fi nnkan kan se orogun fun Un. Eleyii ni itumọ Laa Ilaaha Illal Laah -kò si ọba ti o tọ lati jọsin fun lododo yatọ si Ọlọhun Ọba-.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} إنا أنزلنا إليك الكتاب بالحق فاعبد الله مخلصا له الدين. ألا لله الدين الخالص والذين اتخذوا من دونه أولياء ما نعبدهم إلا ليقربونا إلى الله زلفى إن الله يحكم بينهم في ما هم فيه يختلفون إن الله لا يهدي من هو كاذب كَفَّار { [سورة الزمر: 3].

« Dajudaju Awa ti sọ Tira naa kalẹ fun ọ pẹlu ododo. Nitori naa maa sin Ọlọhun l’ẹni ti n se afọmọ ijọsin naa fun Un. Tẹti ki o gbọ, ti Ọlọhun nikan ni ẹsin ti o mọ i se, ati pe awọn ẹni ti wọn mu awọn mìíran ni alagbakaya lẹyin Ọlọhun [ti wọn si n sọ wi pe] : A kò maa jọsin fun wọn nitori nnkan kan, ayafi ki wọn o le baa mu wa sun mọ Ọlọhun ni pẹkipẹki. Dajudaju Ọlọhun yoo se idajọ laarin wọn nipa ohun ti wọn n se iyapa-ẹnu si, dajudaju Ọlọhun ki I fi ọna mọ ẹni ti o jẹ opurọ, alaigbagbọ » [Suuratuz-Zumar: 3].

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وما أمروا إلا ليعبدوا الله مخلصين له الدين حنفاء { [سورة البينة: 5].

« Ati pe A kò pa wọn lasẹ [pẹlu nnkan kan] yatọ si ki wọn o maa sin Ọlọhun, l’ẹni ti o fi ọna ti kò tọ silẹ » [Suuratul-Bayyinah: 5].

Ẹlẹẹkeji ni: Titẹle ohun ti Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, mu wa; nipa pe ki eniyan o maa se iru ohun ti Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” se, ni ọna ti o fi se e, laisi afikun kan, tabi adinku kan. Eleyii si ni itumọ jijẹri pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i.

Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- sọ pe:

} قل إن كنتم تحبون الله فاتبعوني يحببكم الله ويغفر لكم ذنوبكم { [سورة آل عمران: 31].

« Sọ pe: Ti ẹyin ba jẹ ẹni ti o fẹran Ọlọhun, ẹ tẹle mi, Ọlọhun yoo fẹran yin, yoo si se aforijin awọn ẹsẹ yin fun yin » [Suuratu Aala Imraan: 31].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وما آتاكم الرسول فخذوه وما نهاكم عنه فانتهوا { [سورة الحشر: 7].

« Ohun ti Ojisẹ Ọlọhun ba mu wa fun yin, ẹ gba a, ohun ti o ba si kọ fun yin, ẹ jinna si i » [Suuratul-Hashr: 7].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} فلا وربك لا يؤمنون حتى يحكموك فيما شجر بينهم ثم لا يجدوا في أنفسهم حرجاً مما قضيت ويسلموا تسليماً { [سورة النساء: 65].

« Sugbọn kò ri bẹẹ, Mo fi Oluwa rẹ bura, wọn kò ni i gbagbọ titi wọn o fi fi ọ se onidajọ nipa ohun ti wọn n se ariyanjiyan si laarin wọn, lẹyin naa ti wọn kò si ri ohun ti ọkan wọn kọ ninu ẹmi wọn nipa ohun ti o da lẹjọ, ti wọn si gbafa ni tọwọ-tẹsẹ ». [Suuratun-Nisaa’i: 65].

 Isẹrusin ti o pe kò le e rinlẹ afi pẹlu nnkan meji:

Alakọkọ ni: Nini ifẹ ti o pe si Ọlọhun, ti eniyan yoo fi jẹ pe o n ti ifẹ Ọlọhun ati ifẹ ohun ti Ọlọhun fẹran siwaju ifẹ ohun mìíran.

Ẹlẹẹkeji ni: Sise itẹriba, ati irẹra-ẹni-silẹ, ti o pe fun Ọlọhun, ti eniyan yoo fi jẹ pe o n tẹriba fun Ọlọhun, pẹlu fifi awọn asẹ Rẹ sisẹ, ati jijinna si awọn ohun ti O kọ.

Nitori naa isẹrusin ni ohun ti o se akojọpọ pipe ifẹ, pẹlu pipe irẹra-ẹni-silẹ, ati itẹriba, irankan, ati ibẹru, pẹlu eleyii si ni isẹrusin eniyan fun Oluwa Rẹ, ati Ẹlẹda Rẹ, yoo se rinlẹ, ati pe pẹlu didide pẹlu isẹrusin fun Ọlọhun ni eniyan yoo fi de ibi ifẹ Ọlọhun, ati iyọnu Rẹ. Nitori naa Ọlọhun nifẹ si pe ki eniyan o maa wa atisun mọ Oun pẹlu ohun ti O se ni ọranyan le e lori ninu awọn ọranyan; ati pe bi eniyan ba ti n lekun ninu sise awọn aselọla -Naafila- ijọsin ni yoo maa lekun ni sisunmọ Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbon-un-gbon, bẹẹ naa si ni ipo rẹ yoo maa ga ni ọdọ Ọlọhun, eleyii yoo si jẹ ọkan ninu awọn okunfa atiwọ ọgba-idẹra -Al-Janna- fun un, pẹlu ọla Ọlọhun, ati aanu Rẹ. Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- sọ pe:

} ادعوا ربكم تضرعاً وخفية إنه لا يحب المعتدين { [سورة الأعراف: 55].

« Ẹ maa pe Oluwa yin tirẹlẹ-tirẹlẹ, ati ni ikọkọ, dajudaju Oun kò fẹran awọn olutayọ-aala » [Suuratul-Aaraaf: 55].

 [3] Awọn ẹri ati awijare At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan ninu ijọsin-:

Dajudaju awọn ohun t’o n jẹri si jijẹ ọkan soso Ọlọhun t’O ga, ati awọn ẹri rẹ pọ jọjọ, ẹni ti o ba se akiyesi wọn, ti o si lo irori rẹ nipa iwoye si wọn, imọ rẹ yoo gbopọn, amodaju rẹ yoo si lekun nipa jijẹ ọkan soso Oluwa -mimọ ati giga ni fun Un- ati nipa jijẹ àáso rẹ ninu awọn isẹ Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ, ati jijẹ ọlọhun ti àá jọsin fun lododo.

Ninu awọn ẹri, ati awọn idi-ọrọ, ati awọn awijare naa -ni apejuwe lai jẹ akatan- ni ohun ti n bọ wọnyi:

(a) Titobi isẹda aye yii, ati wiwẹ dida rẹ, ati jijẹ orisirisi awọn ẹda -inu- rẹ, ati eto ti o wẹ, eyi ti n yi lori rẹ. Ẹnikẹni ti o ba se akiyesi eleyii, ti o si fi ọpọlọ rẹ ronu nipa rẹ, yoo ni amọdaju nipa jijẹ ọkan soso Ọlọhun. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba woye si dida awọn sanma ati ilẹ, ati dida oorun ati osupa, ati dida eniyan ati ẹranko, ati dida irugbin, ati awọn nnkan bọrọgidi, yoo mọ amọdaju pe wọn ni Ẹlẹda, ti O pe ninu awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ, ati ninu jijẹ ọlọhun ti àá jọsin fun. Nitori naa eleyii n tọka si pe Oun nikan ni O ni ẹtọ si ijọsin.

Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- sọ pe:

} وجعلنا في الأرض رواسي أن تميد بهم وجعلنا فيها فجاجاً سبلاً لعلهم يهتدون. وجعلنا السماء سقفاً محفوظاً وهم عن آياتنا معرضون. وهو الذي خلق الليل والنهار والشمس والقمر كل في فلك يسبحون { [سورة الأنبياء: 32-33].

« Ati pe A se awọn oke si ori ilẹ, ki o ma baa mi mọ wọn, A si tun se awọn oju-ọna ti o fẹ si inu rẹ, ki wọn o le maa mọna. A si se sanma ni àjà ti a sọ, sibẹsibẹ awọn n sẹri kuro nibi awọn ami Wa. Oun ni O da oru ati ọsan, oorun ati osupa, onikaluku wọn n luwẹ ninu awowo » [Suuratul-Anbiyaa’: 32-33].

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} ومن آياته خلق السموات والأرض واختلاف ألسنتكم وألوانكم إن في ذلك لآيات للعالمين {. [سورة الروم: 22].

« Ninu awọn ami Rẹ si ni sisẹda awọn sanma ati ilẹ, ati yiyatọ si ara wọn awọn ede yin, ati awọn àwọ yin, dajudaju awọn ami n bẹ ninu eleyii fun awọn oni-mimọ » [Suuratur-Ruum: 22].

(b) Ohun ti Ọlọhun fi ran awọn ojisẹ ninu awọn ofin -Sharia- ati ohun ti O fi ti wọn lẹyin ninu awọn ami ati awijare, eyi ti n tọka si jijẹ àáso ati ọkan soso Rẹ -giga ati gbigbọn-un-gbọn ni fun Un- pẹlu ijọsin. Nitori naa ẹri ti o han ni ohun ti Ọlọhun se ni ofin fun awọn ẹda Rẹ ninu awọn idajọ lori wi pe nnkan wọnyi kò le e wa lati ọdọ ẹnikan yatọ si Oluwa, Ọlọgbọn, Oni-mimọ nipa ohun ti O da, ati ohun ti yoo tun awọn ẹda naa se.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} لقد أرسلنا رسلنا بالبينات وأنزلنا معهم الكتاب والميزان ليقوم الناس بالقسط { [سورة الحديد، الآية: 25].

« Dajudaju Awa ti ran awọn ojisẹ wa pẹlu awọn alaye, A si sọ Tira ati osunwọn kalẹ pẹlu wọn, nitori ki awọn eniyan o le baa duro pẹlu sise dọgba » [Suuratul-Hadiid: 25]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} قل لئن اجتمعت الإنس والجن على أن يأتوا بمثل هذا القرآن لا يأتون بمثله ولو كان بعضهم لبعض ظهيراً { [سورة الإسراء: 88].

« Sọ pe: Ti awọn eniyan ati alujannu ba papọ lati mu iru Al-Qur’aan yii wa, wọn kò ni le mu iru rẹ wa, koda ki o se pe apa kan wọn jẹ oluse-iranlọwọ fun apa keji [lori rẹ] » [Suuratul-Israa’i: 88].

(d) Adamọ eyi ti Ọlọhun da ọkan awọn ẹda Rẹ le lori, nipa gbigba jijẹ ọkan soso Ọlọhun, ohun ti o si fi idi mulẹ si inu awọn ẹmi ni i. Ati pe nigbakigba ti inira ba ba eniyan yoo ri eleyii, yoo si pada si ọdọ Ọlọhun, ti eniyan ba si bọ lọwọ awọn iruju ati ifẹkufẹ-ọkan, eyi ti maa n yi adamọ rẹ pada, dajudaju ki ba ti si nnkan kan ninu ọkan rẹ ju jijẹwọ ati gbigbafa fun jijẹ ọkan soso Ọlọhun nipa jijẹ ọba ti àá jọsin fun, ati nipa awọn orukọ Rẹ, ati awọn isẹ Rẹ, ati jijuwọ-jusẹ silẹ fun ofin Rẹ, eyi ti O fi ran awọn ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} فأقم وجهك للدين حنيفاً فطرت الله التي فطر الناس عليها لا تبديل لخلق الله ذلك الدين القيم ولكن أكثر الناس لا يعلمون. منيبين إليه واتقوه وأقيموا الصلاة ولا تكونوا من المشركين { [سورة الروم: 30-31].

« Nitori naa da oju rẹ kọ ẹsin ododo, l’ẹni ti o fi ọna ti kò tọ silẹ, adamọ Ọlọhun eyi ti O pilẹ da awọn eniyan le lori, kò si ayipada fun ẹda Ọlọhun. Eyi ni ẹsin ti o duro deedee, sugbọn ọpọlọpọ awọn eniyan ni kò mọ. Ni ẹni ti o sẹri pada si ọdọ Rẹ, ki ẹ si maa paya Rẹ, ki ẹ si maa gbe irun duro, ki ẹ ma si se jẹ ọkan ninu awọn ọsẹbọ » [Suuratur-Ruum: 30-31].

Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( كل مولود يولد على الفطرة، فأبواه يهودانه أو ينصرانه أو يمجسانه، كما تنتج البهيمة بهيمة جمعاء هل تحسون فيها من جدعاء، ثم قرأ: "فطرت الله الذي فطر الناس عليها" )). [رواه البخاري].

« Gbogbo ọmọ ni a bi si ori adamọ -Islam-. Nitori naa awọn obi rẹ mejeeji ni wọn yoo sọ ọ di Yahuudi -Ju- tabi alagbelebu -kiriyo- tabi olubọ-ina, gẹgẹ bi ẹran ti maa n bi ọmọ, ti kò ni alebu kan lara, njẹ ẹ wa ri ọkan ti o ge ni orike ninu wọn bi? Lẹyin naa ni o wa ka: [ọrọ Ọlọhun t’o ni] : [Adamọ Ọlọhun eyi ti O pilẹ da awọn eniyan le lori, kò si ayipada fun ẹda Ọlọhun] » [Bukhari l’o gbe e jade].

###

 ORIGUN KEJI: NINI IGBAGBỌ-ODODO SI AWỌN MALAIKA

 [1] Alaye rẹ:

Nini igbagbọ si awọn Malaika: Oun ni nini adisọkan ti o gbopọn pe Ọlọhun ni awọn Malaika, O da wọn lati ara imọlẹ, a da wọn mọ titẹle tiẸ, wọn ki i sẹ Ọlọhun lori ohun ti O ba fi pa wọn lasẹ, wọn a si maa se ohun ti a ba fi pa wọn lasẹ, wọn a maa se afọmọ fun Ọlọhun ni oru ati ọsan, wọn ki i ko aarẹ, ẹnikan kò mọ onka wọn yatọ si Ọlọhun, Ọlọhun pa wọn lasẹ pẹlu awọn isẹ kan ati awọn orisirisi isẹ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولكن البر من آمن بالله واليوم الآخر والملائكة { [سورة البقرة، الآية: 177].

« Sugbọn daadaa sise ni ẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ, ati ọjọ ikẹyin, ati awọn Malaika » [Suuratul-Baqarah: 177].

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} آمن الرسول بما أنزل إليه من ربه والمؤمنون كل آمن بالله وملائكته وكتبه ورسله { [سورة البقرة، الآية: 185].

« Ojisẹ naa gba ohun ti a sọ kalẹ fun un gbọ ati awọn olugbagbọ-ododo, onikaluku wọn l’o gba Ọlọhun gbọ, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ » [Suuratul-Baqarah: 185].

O si wa ninu ẹgbawa-ọrọ Jibriil ti o gbajumọ, nigba ti o bi Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, leere nipa igbagbọ-ododo -Iimaan- ati igbafa fun Ọlọhun -Islam- ati daadaa sise -Ihsaan-. O sọ pe -iyẹn Jibriil-:

(( أخبرني عن الإيمان؟ قال: أن تؤمن بالله، وملائكته، وكتبه، ورسله، واليوم الآخر، وتؤمن بالقدر خيره وشره )).

« Fun mi niro nipa igbagbọ-ododo. O dahun -iyẹn Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”- pe: « Ki o gba Ọlọhun gbọ, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ki o si gba akọsilẹ gbọ; daadaa rẹ ati aburu rẹ ».

 Ipo nini igbagbọ-ododo si awọn Malaika ninu ẹsin ati idajọ rẹ:

Nini igbagbọ si awọn Malaika ni origun keji ninu awọn origun mẹfa ti igbagbọ-ododo ni, eyi ti o se pe igbagbọ ẹru kan kò le e dara, kò si le e jẹ gbigba afi pẹlu wọn.

Ati pe ẹnu awọn Musulumi ti ko lori pe ọranyan ni ki a ni igbagbọ si awọn Malaika alapọnle. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba tako bibẹ wọn, tabi [o tako] bibẹ apa kan wọn, ninu awọn ti Ọlọhun t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn, darukọ wọn, o ti se aigbagbọ [si Ọlọhun], o si ti tako Al-Qur’aan, ati Sunna, ati ohun ti ẹnu awọn Musulumi ko le lori.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ومن يكفر بالله وملائكته وكتبه ورسله واليوم الآخر فقد ضل ضلالا بعيداً { [سورة النساء، الآية: 136].

« Ati pe ẹnikẹni ti o ba se aigbagbọ si Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, dajudaju o ti sina ni isina ti o jinna» [Suuratun-Nisaa’i: 136].

 [2] Bi a o ti ni igbagbọ si awọn Malaika

Nini igbagbọ si awọn Malaika a maa jẹ akopọ ati ni ẹfọsiwẹwẹ:

Nini igbagbọ si wọn ni akopọ se akojọpọ awọn nnkan ti o se pe ninu wọn ni:

Alakọkọ: Gbigba pe wọn n bẹ, ati pe ẹda kan ninu awọn ẹda Ọlọhun ni wọn, Ọlọhun da wọn nitori ijọsin fun Un, bẹẹ ni otitọ ni bibẹ wọn, àìkò si ri wọn wa kò tọka si pe wọn kò si, meloo-meloo ninu awọn ẹda ti o wẹ ninu aye ni a kò le ri, sugbọn ti o se pe wọn n bẹ ni otitọ.

Ati pe dajudaju Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ri Jibriil ninu paapaa aworan rẹ ni ẹẹmeji, bẹẹ ni apa kan ninu awọn Sahaabe “ki Ọlọhun O yọnu si wọn”, ri apa kan ninu awọn Malaika, nigba ti wọn wa ninu aworan eniyan.

Imam Ahmad gbe ẹgbawa-ọrọ jade ninu Musnad [rẹ], lati ọdọ Abdullaah ọmọ Mas’uud, “ki Ọlọhun O yọnu si i”, o sọ pe:

(( رأى رسول الله ﷺ‬ جبريل في صورته وله ستمائة جناح، وكل جناح منها قد سد الأفق )).

« Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ri Jibriil ninu aworan rẹ, ni ẹni ti o ni iyẹ ọgọrun mẹfa, ti gbogbo iyẹ kọọkan ninu wọn si bo oferefe ».

Ati pe dajudaju o rinlẹ ninu ẹgbawa-ọrọ Jibriil t’o gbajumọ, eyi ti Muslim gbe jade, pe: Jibriil “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, wa pẹlu aworan ọkunrin kan, ti asọ rẹ funfun gboo, ti irun ori rẹ si dudu kirikiri, a kò si ri ami oni-irin-ajo ni ara rẹ, ẹnikan ninu awọn Sahaabe ko tilẹ mọ ọn.

Elẹẹkeji: Gbigbe wọn si ipo wọn ti Ọlọhun gbe wọn si. Nitori naa ẹda Ọlọhun ti a n pa lasẹ ni wọn, Ọlọhun pọn wọn le, O si se agbega ipo wọn, O si sun wọn mọ ọdọ ara Rẹ, ati pe awọn ojisẹ Ọlọhun ti O maa n fi isẹ ati nnkan mìíran ran n bẹ ninu wọn, bẹẹ ni wọn kò ni agbara lori nnkan kan, afi ohun ti Ọlọhun ba fun wọn ni agbara lori rẹ, sibẹsibẹ wọn kò tilẹ ni ikapa atise ara wọn, tabi ẹlomiran ni anfaani kan, tabi aburu kan, lẹyin Ọlọhun, eleyii l’o fa a ti kò fi yẹ pe ki a sẹri nnkan kan si ọdọ wọn ninu awọn orisirisi ijọsin, depo pe a o maa royin wọn pẹlu awọn iroyin Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn alagbelebu -kiriyo- ti se purọ rẹ nipa ẹmi mimọ [Malaika Jibriil], “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وقالوا اتخذ الرحمن ولداً سبحانه بل عباد مكرمون. لا يسبقونه بالقول وهم بأمره يعملون { [سورة الأنبياء، الآية: 26-27].

« Wọn sọ pe: Ọba Alaanujulọ -Ar-Rahmaan- mu [ẹnikan] lọmọ, mimọ ni fun Un, kò ri bẹẹ rara, ẹru alapọnle ni wọn. Wọn ki i gba iwaju Rẹ nibi ọrọ, ati pe asẹ Rẹ ni wọn fi n sisẹ ». [Suuratul-Anbiyaa’: 27-28].

} لا يعصون الله ما أمرهم ويفعلون ما يؤمرون { [سورة التحريم، الآية: 6].

« Wọn ki i sẹ Ọlọhun nipa ohun ti O fi pa wọn lasẹ, ati pe ohun ti a fi pa wọn lasẹ ni wọn maa n se ». [Suuratut-Tahriim: 6].

Ọranyan ni odiwọn igbagbọ yii i se lori gbogbo Musulumi ni ọkunrin ati lobinrin, ọranyan ni ki wọn o kọ nipa rẹ, ki wọn o si ni adisọkan rẹ, ati pe a kò ni i gba awawi ẹnikan latari aimọ nipa rẹ.

Sugbọn ẹfọsiwẹwẹ igbagbọ nipa awọn Malaika: Oun se akojọpọ awọn nnkan kan, ti o se pe ninu wọn ni:

Alakọkọ: Ohun ti a fi sẹda wọn:

Ọlọhun Ọba da awọn Malaika lati ara imọlẹ, gẹgẹ bi Ọba-mimọ Naa ti se ẹda awon alujannu lati ara ina, ti O si se ẹda awọn ọmọ Aadama lati ara ẹrọfọ, isẹda wọn si siwaju dida Anabi Aadama, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”.

O wa ninu ọrọ Ojisẹ Ọlọhun pe:

(( خلقت الملائكة من نور، وخلق الجان من مارج من نار، وخلق آدم مما وصف لكم )). [رواه مسلم].

« A sẹda awọn Malaika lati ara imọlẹ, a si sẹda awọn alujannu lati ara ahọn ina, a si sẹda Aadama lati ara ohun ti a royin fun yin ». [Muslim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkeji: Onka awọn Malaika:

Ẹda ti ẹnikan kò mọ onka wọn yatọ si Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn, ni awọn Malaika, fun pupọ wọn. Ati pe kò si aaye ọmọ-ika mẹrin ni sanma afi ki o jẹ pe Malaika kan n bẹ lori rẹ, l’ẹni ti o fi ori kanlẹ, tabi l’ẹni ti o duro, gẹgẹ bi o ti se jẹ pe ẹgbẹrun-lọna-aadọrin Malaika ni wọn maa n wọ inu [ile ti a n pe ni] Baitul-Ma’amuur ni sanma keje lojoojumọ, ti wọn kò si ni i pada wọ inu rẹ mọ, latari pupọ ti wọn pọ; ati pe a o mu ina -Jahanma- wa ni ọjọ igbende, ni ohun ti o ni ẹgbẹrun-lọna-aadọrin ijanu, ẹgbẹrun-lọna-aadọrin Malaika yoo si maa bẹ pẹlu ijanu kọọkan, ti wọn yoo maa fa a.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وما يعلم جنود ربك إلا هو { [سورة المدثر، الآية: 31].

« Ati pe ẹnikan kò mọ -onka- awọn ọmọ-ogun Oluwa Rẹ yatọ si I » [Suuratul-Muddathir: 31].

O si wa ninu ẹgbawa-ọrọ pe Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( أطت السماء وحق لها أن تئط، ما فيها موضع قدم إلا وفيه ملك ساجـد وراكـع )). [رواه البخاري ومسلم].

« Sanma rọ kẹkẹ, ati pe o tọ fun un pe ki o rọ kẹkẹ, kò si aaye ẹsẹ kan ninu rẹ, afi ki o jẹ pe Malaika kan ti o fi ori kanlẹ, ati eyi ti o tẹ, ni n bẹ nibẹ ».

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ nipa Baitul-Ma’amuur, pe:

(( يدخله في كل يوم سبعون ألف ملك لا يعودون إليه )). [رواه البخاري ومسلم].

« Ẹgbẹrun-lọna-aadọrin Malaika ni wọn maa n wọ inu rẹ lojoojumọ, ti wọn kò si ni i pada wọ inu rẹ mọ ». [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( يؤتى بجهنم يومئذ لها سبعون ألف زمام، مع كل زمام سبعون ألف ملك )). [رواه مسلم].

« A o mu [ina] Jahannama wa ni ọjọ naa, ni ohun ti o ni ẹgbẹrun-lọna-aadọrin ijanu, ẹgbẹrun-lọna-aadọrin Malaika yoo si maa bẹ pẹlu ijanu kọọkan ». [Muslim l’o gbe e jade].

Bibuyaari onka awọn Malaika yoo han si wa nibi, nitori pe awọn wọnyi ni apejuwe, onka wọn to aadọta ọkẹ lọna ẹgbẹrun mẹrin ati ọgọrun-mẹsan [4, 900, 000000] Malaika, njẹ bawo ni awọn Malaika yoku ti to! Mimọ ni fun Ọba ti O sẹda wọn, ti O si N dari wọn, ti O si mọ iye onka wọn.

Ẹlẹẹkẹta: Orukọ awọn Malaika:

Ọranyan ni pe ki a ni igbagbọ si awọn ti Ọlọhun darukọ wọn fun wa ninu Al-Qur’aan, tabi awọn ti Ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, da orukọ wọn fun wa ninu Sunna rẹ, ninu awọn Malaika, ati pe mẹta ni awọn ti wọn tobi ju ninu won:

Ekinni ni: Jibriil, ati pe o see se ki a pe e ni Jibraa’i’iil. Oun ni Ẹmi mimọ ti i maa n sọ isẹ, ti o se pe oun ni maa n mu isẹmi ba awọn ọkan, kalẹ le awọn ojisẹ Ọlọhun “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn” lori.

Ekeji ni: Miikaa’i’iil, ati pe o see se ki a pe e ni Miikaal. Oun ni a fi sọ rirọ ojo, eyi ti o se pe oun ni maa n mu isẹmi ba ilẹ, o maa n dari rẹ lọ si ibi ti Ọlọhun ba pa a lasẹ.

Ẹkẹta ni: Israafiil. Oun ni a fi sọ fifẹ atẹgun si iwo, ni ikede pe ile-aye ti de opin, ati pe isẹmi-igbẹyin, eyi ti o se pe oun ni yoo mu isẹmi ba awọn ara, ti bẹrẹ.

Ẹlẹẹkẹrin: Awọn iroyin awọn Malaika:

Ẹda gidi ni awọn Malaika, wọn ni ara tootọ, eyi ti a maa n royin pẹlu awọn iroyin adamọ, ati ti iwa, ninu wọn ni:

(a) Titobi ẹda wọn, ati kikarabata awọn ara wọn: Ọlọhun Ọba t’O mọ, t’O si ga, sẹda awọn Malaika lori awọn aworan ti o ga, ti o si lagbara, ni ibamu pẹlu awọn isẹ nlanla wọn ti Ọlọhun fi wọn sọ ninu awọn sanma ati ilẹ.

(b) Wi pe wọn ni awọn iyẹ: Ọlọhun Ọba t’O mọ, t’O si ga, da awọn iyẹ meji-meji, tabi mẹta-mẹta, tabi mẹrin-mẹrin fun awọn Malaika, ati pe o see se ki o ju bẹẹ lọ, gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ti ri Jibriil ninu aworan rẹ, l’ẹni ti o ni iyẹ ọgọrun mẹfa, ti o bo gbogbo oferefe. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الحمد لله فاطر السماوات والأرض جاعل الملائكة رسلاً أولي أجنحة مثنى وثلاث ورباع يزيد في الخلق ما يشاء { [سورة فاطر، الآية: 1].

« Ọpẹ ni fun Ọlọhun, Olupilẹ sẹda awọn sanma ati ilẹ, ti O si se awọn Malaika ni awọn ojisẹ oni-iyẹ meji-meji, tabi mẹta-mẹta, tabi mẹrin-mẹrin, A si maa se alekun ohun ti O ba fẹ ninu ẹda naa ». [Suuratu Faatir: 1].

(d) Àìkò ni bukaata wọn si ounjẹ ati ohun mimu: Ọlọhun t’O mọ, t’O si ga, da awọn Malaika pe ki wọn o ma ni bukaata si ounjẹ tabi ohun mimu, ki wọn o si ma maa fẹ iyawo, ki wọn o si ma maa bi ọmọ.

(e) Oni-laakaye, ọlọkan, ni awọn Malaika: Wọn ba Ọlọhun sọrọ, Oun Naa si ba wọn sọrọ, wọn ba Anabi Aadama sọrọ ati awọn mìíran ti wọn yatọ si i ninu awọn anabi Ọlọhun.

(ẹ) Agbara wọn lati yi ara wọn pada si aworan mìíran yatọ si paapaa aworan wọn: Ọlọhun fun awọn Malaika ni agbara lori atiya aworan wọn lori aworan awọn ọkunrin ninu awọn eniyan, esi-ọrọ n bẹ ninu eleyii lori awọn alaigbagbọ ti wọn parọ pe awọn ọmọ-binrin Ọlọhun ni awọn Malaika.

A kò si mọ nipa bi wọn ti se maa n ya aworan ara wọn naa, sugbọn wọn a maa ya ara wọn ni aworan kan ti o wẹ, ti o se pe yoo soro lati mọ iyatọ laarin wọn ati awọn eniyan.

(f) Iku awọn Malaika: Gbogbo awọn Malaika ni yoo ku ni ọjọ igbende, titi ti o fi de ori Malaika iku, lẹyin naa ni a o wa gbe wọn dide lati se awọn isẹ wọn ti Ọlọhun fi wọn sọ.

(g) Ijọsin awọn Malaika: Awọn Malaika n sin Ọlọhun, Ọba t’O mọ, t’O si ga, pẹlu awọn ijọsin ti o se pe ninu wọn ni: Irun kiki, adua, sise afọmọ, titẹ, ati fifi ori kanlẹ, ati ibẹru, ipaya, ifẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ati pe ohun ti n bọ wọnyi n bẹ ninu awọn iroyin awọn ijọsin wọn:

1- Titẹ ara mọ, ati aiduro, pẹlu àìkò aarẹ.

2- Sise afọmọ fun Ọlọhun t’O mọ, t’O si ga.

3- Titẹra mọ titẹle ti Ọlọhun, ati pipa ẹsẹ ti, nitori sisọ wọn kuro nibi awọn ẹsẹ nlanla ati kékéké.

4- Itẹriba fun Ọlọhun pẹlu ọpọlọpọ ijọsin.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يسبحون الليل والنهار لا يفترون { [سورة الأنبياء، الآية: 20].

« Wọn a maa fi oru ati ọsan se afọmọ, wọn ki i ko aarẹ » [Suuratul-Anbiyaa’: 20].

Ẹlẹẹkarun-un: Awọn isẹ awọn Malaika:

Awọn Malaika a maa se awọn isẹ ribiribi ti Ọlọhun fi wọn sọ, ninu wọn ni:

1- Awọn ti wọn gbe aga-ọla Ọlọhun -Al-Arsh- ru.

2- Malaika ti a fi sọ sisọ isẹ Ọlọhun ti maa N fi i ransẹ si awọn ojisẹ.

3- Awọn olusọ ọgba-idẹra -Al-Janna- ati ina.

4- Awọn ti a fi sọ ẹsu-ojo ati ojo, ati irugbin.

5- Awọn ti a fi sọ awọn apata.

6- Malaika ti a fi sọ fifẹ atẹgun si iwo.

7- Awọn ti a fi sọ kikọ isẹ awọn ọmọ Aadama silẹ.

8- Awọn ti a fi sọ sisọ awọn ọmọ Aadama. Nitori naa nigba ti Ọlọhun ba kọ akọsilẹ nnkan kan le e lori, wọn yoo fi i silẹ, ohun ti O kọsilẹ yoo si sẹlẹ si i.

9- Awọn ti a fi sọ bibẹ pẹlu eniyan, ati pipe e lọ sidi rere.

10- Awọn ti a fi sọ omi gbọlọgbọlọ ninu apo-ibi, ati fifẹ ẹmi si eniyan lara, ati kikọ akọsilẹ ọrọ -arziki- rẹ, ati isẹ rẹ, ati pe sé oloriibu ni i, tabi oloriire.

11- Awọn ti a fi sọ gbigba ẹmi awọn ọmọ Aadama ni asiko iku.

12- Awọn ti a fi sọ bibi awọn eniyan leere ninu awọn saare wọn, ati ohun ti yoo ti ẹyin rẹ jade, ninu idẹra tabi iya.

13- Awọn ti a fi sọ jijisẹ fun Anabi wa, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, nipa kiki ọla -salama- ti awọn ijọ rẹ n ki i.

Ati pe eleyii l’o fa a ti Musulumi kò fi bukaata lati rin irin-ajo lọ si ọdọ rẹ nitori atiki i, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ni kiki ọla, kaka bẹẹ, o to o pe ki o se asalaatu fun un, ki o si ki i ni kiki ọla ni ibikibi; tori pe awọn Malaika yoo gbe kiki rẹ, wọn yoo si fi jisẹ fun Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati pe a ki i rin irin-ajo lọ si masalasi Anabi afi nitori atiki irun ninu rẹ.

Ati pe wọn tun ni awọn isẹ pupọ gan-an, sugbọn eleyii l’o gbajumọ ju ninu wọn, ninu awọn ẹri-ọrọ lori eleyii ni:

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الذين يحملون العرش ومن حوله يسبحون بحمد ربهم ويؤمنون به ويستغفرون للذين آمنوا { [سورة غافر: 7].

« Awọn ẹni ti wọn gbe aga-ọla Ọlọhun -Al-Arsh- ru, ati awọn ti o wa ni agbegbe rẹ, wọn n se afọmọ pẹlu fifi ọpẹ fun Oluwa wọn, wọn si ni igbagbọ si I, wọn si n tọrọ aforijin fun awọn ẹni ti wọn gbagbọ ni ododo » [Suuratu Gaafir: 7]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} من كان عدوا لجبريل فإنه نزله على قلبك بإذن الله { [سورة البقرة: 97].

« Sọ pe: Ẹnikẹni ti o ba jẹ ọta Jibriil, dajudaju oun l’o sọ ọ kalẹ si ọkan rẹ pẹlu iyọnda Ọlọhun » [Suuratul-Baqarah: 97]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} ولو ترى إذ الظالِمون في غمرات الموت والملائكة باسطوا أيديهم أخرجوا أنفسكم { [سورة الأنعام: 93].

« Iba se pe iwọ ri awọn alabosi ninu ipọka iku ni, ti awọn Malaika si tẹ ọwọ wọn [pe]: Ẹ yọ awọn ẹmi yin jade » [Suuratul-An’aam: 93].

 Ẹlẹẹkẹfa: Iwọ awọn Malaika lori awọn ọmọ Aadama

1- gbigba wọn gbọ lododo.

2- Nini ifẹ wọn, ati sise agbega wọn, ati sisọ nipa awọn ọla wọn.

3- Sise bibu wọn leewọ, tabi fifi abuku kan wọn, tabi fifi wọn se yẹyẹ.

4- Jijinna si ohun ti awọn Malaika korira, nitori pe ohun ti maa n ni awọn ọmọ Aadama lara a maa ni wọn lara.

 Eso nini igbagbọ-ododo si awọn Malaika:

(a) Fifi igbagbọ-ododo rinlẹ, nitori pe igbagbọ-ododo ki i dara afi pẹlu gbigba wọn gbọ.

(b) Mimọ nipa titobi Ẹlẹda wọn -ibukun ati giga ni fun Un- ati agbara Rẹ, ati ijọba Rẹ; nitori pe titobi ẹda n bẹ ninu titobi Ẹlẹda.

(d) Lilekun igbagbọ-ododo ni ọkan Musulumi latari mimọ awọn iroyin wọn, ati awọn ipo wọn, ati awọn isẹ wọn.

(e) Ibalẹ-ọkan ati ifayabalẹ fun awọn olugbagbọ-ododo nigba ti Ọlọhun ba N fi awọn Malaika fi wọn rinlẹ.

(ẹ) Nini ifẹ awọn Malaika lori ohun ti wọn n se ninu awọn ijọsin, ni ọna ti o pe ju, ati titọrọ aforijin wọn fun awọn olugbagbọ-ododo.

(f) Kikorira awọn isẹ ti kò dara ati awọn ẹsẹ.

(g) Didupẹ fun Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- lori amojuto Rẹ lori awọn ẹda Rẹ, nigba ti O fi sọ wọn ninu awọn Malaika wọnyi ẹni ti yoo maa se isọ wọn, ati kikọ awọn isẹ wọn silẹ, ati ohun ti o yatọ si eleyii ninu awọn anfaani wọn.

###

 ORIGUN KẸTA: NINI IGBAGBỌ-ODODO SI AWỌN TIRA

Nini igbagbọ-ododo si awọn tira Ọlọhun, ti a sọ kalẹ fun awọn ojisẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, ni origun kẹta ninu awọn origun igbagbọ-ododo, tori pe dajudaju Ọlọhun ti ran awọn ojisẹ Rẹ pẹlu awọn ẹri-ọrọ, O si sọ awọn tira kalẹ fun wọn, ki wọn o maa jẹ ikẹ fun awọn ẹda, ati ifinimọna fun wọn, nitori ki oriire wọn o le baa rinlẹ ni aye ati ni ọrun; ati nitori ki o le baa jẹ ilana kan ti wọn yoo maa tọ, ati oluse-idajọ laarin awọn eniyan nipa ohun ti wọn se iyapa-ẹnu si.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} لقد أرسلنا رسلنا بالبينات وأنزلنا معهم الكتاب والميزان ليقوم الناس بالقسط { [سورة الحديد، الآية: 25].

« Dajudaju A ti ran awọn ojisẹ wa pẹlu awọn alaye, A si sọ Tira ati osunwọn kalẹ pẹlu wọn, ki awọn eniyan o le baa duro pẹlu sise deedee» [Suuratul-Hadiid: 25], Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} كان الناس أمة واحدة فبعث الله النبيين مبشرين ومنذرين وأنزل معهم الكتاب بالحق ليحكم بين الناس فيما اختلفوا فيه { [سورة البقرة: 213].

« Awọn eniyan jẹ ijọ kan soso, n ni Ọlọhun ba gbe awọn anabi dide ni olufunni ni iro idunnu, ati olukilọ, ati pe O sọ Tira kalẹ fun wọn pẹlu ododo, ki O le baa se idajọ laarin awọn eniyan nipa ohun ti wọn n se iyapa-ẹnu si » [Suuratul-Baqarah: 213].

 [1] Paapaa nini igbagbọ-ododo si awọn Tira:

Nini igbagbọ si awọn Tira ni: Gbigba ni ododo ti o gbopọn pe dajudaju Ọlọhun ni awọn tira kan, ti O sọ wọn kalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, ati pe ara ọrọ Rẹ ni paapaa ni wọn, imọlẹ ati imọna si ni wọn, bẹẹ ni ododo, otitọ, ati ise-deedee ni ohun ti wọn se akojọpọ rẹ [sinu]. Ọranyan ni titẹle e ati sisisẹ pẹlu rẹ; ẹnikan kò si mọ onka wọn yatọ si Ọlọhun.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وكلَّم الله موسى تكليماً { [سورة النساء: 164].

« Ati pe Ọlọhun ba Muusa sọrọ ni ibasọrọ gan-an » [Suuratun-Nisaa’i: 164]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وإن أحد من المشركين استجارك فأجره حتى يسمع كلام الله { [سورة التوبة: 6].

« Ati pe ti ọkan ninu awọn olusẹbọ si Ọlọhun ba tọrọ idaabo lọdọ rẹ, ki o daabo bo o titi ti yoo fi gbọ ọrọ Ọlọhun » [Suuratut-Tawbah: 6].

 [2] Idajọ gbigba awọn Tira naa gbọ:

Ọranyan ni nini igbagbọ-ododo si gbogbo awọn tira ti Ọlọhun sọ kalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, ati pe Ọlọhun -ibukun ati giga ni fun Un- ti sọ wọn ni ọrọ ni paapaa, bẹẹ ni ohun ti a sọ kalẹ ni wọn, wọn ki i se ohun ti a da, ẹnikẹni ti o ba si tako wọn, tabi o tako nnkan kan ninu wọn ti se aigbagbọ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يا أيها الذين آمَنوا آمِنوا بالله ورسوله والكتاب الذي نزل على رسوله والكتاب الذي أنزل من قبل ومن يكفر بالله وملائكته وكتبه ورسله واليوم الآخر فقد ضل ضلالاً بعيداً { [سورة النساء: 136].

« Ẹyin olugbagbo-ododo, ẹ gba Ọlọhun gbọ ati awọn ojisẹ Rẹ, ati Tira ti o sọ kalẹ fun Ojisẹ Rẹ, ati Tira eyi ti o sọ kalẹ siwaju [rẹ], ẹni ti o ba se aigbagbọ si Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn Tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ-ikẹyin, dajudaju o ti sina ni isina ti o jinna » [Suuratun-Nisaa’i: 136]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وهذا كتاب أنزلناه مبارك فاتبعوه واتقوا لعلكم ترحمون {. [سورة الأنعام: 155].

« Eleyii si ni Tira kan ti Awa sọ ọ kalẹ ni oni-ibukun. Nitori naa ẹ maa tẹle e, ki ẹ si maa bẹru [Ọlọhun], ki ẹ le baa jẹ ẹni ti a o kẹ » [Suuratul-An’aam: 155].

 [3] Bukaata awọn eniyan si awọn Tira naa, ati Hikmah -ọgbọn- ti n bẹ ninu sisọ wọn kalẹ:

Alakọkọ: Ki Tira ti a sọ kalẹ fun ojisẹ naa o le baa jẹ pe oun ni ibupadasi fun awọn ijọ rẹ, ki wọn o maa pada si idi rẹ lati mọ nipa ẹsin wọn.

Ẹlẹẹkeji: Ki Tira ti a sọ kalẹ fun ojisẹ naa o le baa jẹ adajọ, oluse-dọgba fun awọn ijọ rẹ, nipa gbogbo ohun ti wọn ba se iyapa-ẹnu si.

Ẹlẹẹkẹta: Ki Tira ti a sọ kalẹ naa o le baa maa sọ ẹsin naa lẹyin iku ojisẹ naa, gbogbo bi o ti le wu ki awọn aaye ati asiko o jinna sira wọn si, gẹgẹ bi ohun ti o jẹ ise ipepe Anabi wa Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Ẹlẹẹkẹrin: Ki awọn Tira wọnyi o le baa jẹ awijare Ọlọhun lori awọn ẹda Rẹ, ki aaye o ma gba wọn lati tapa si wọn, tabi lati jade kuro ninu wọn.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} كان الناس أمة واحدة فبعث الله النبيين مبشرين ومنذرين وأنزل معهم الكتاب بالحق ليحكم بين الناس فيما اختلفوا فيه { [سورة البقرة: 213].

« Awọn eniyan jẹ ijọ kan soso, Ọlọhun gbe awọn anabi dide ni olufunni ni iro idunnu, ati olukilọ, ati pe O sọ tira kalẹ fun wọn pẹlu ododo, ki O le baa se idajọ laarin awọn eniyan nipa ohun ti wọn n se iyapa-ẹnu si » [Suuratul-Baqarah: 213].

 [4] Bi a o ti gba awọn Tira naa gbọ:

Nini igbagbo si awọn Malaika a maa jẹ akopọ ati ni ẹfọsiwẹwẹ:

Ti akopọ ni: Ki o gbagbọ pe dajudaju Ọlọhun sọ awọn tira kan kalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”.

Ti ẹfọsiwẹwẹ si ni: Ki o ni igbagbọ si ohun ti Ọlọhun darukọ ninu awọn tira Rẹ ninu Al-Qur’aan alapọnle. A si ti mọ ninu eleyii: Al-Qur’aan, ati At-Tawraata -Majẹmu Laelae- ati Zabuurah, ati Injiila -Bibeli, Majẹmu Titun- ati Suhuf -iwe- Anabi Ibraahiim ati Muusa. A si tun gbagbọ pe dajudaju yatọ si eleyii Ọlọhun ni awọn tira kan ti O sọ kalẹ fun awọn anabi Rẹ, ti ẹnikan kò mọ orukọ wọn, ati onka wọn, yatọ si Ẹni ti O sọ wọn kalẹ -mimọ ati giga ni fun Un-.

Ati pe gbogbo awọn Tira wọnyi wa lati wa fi At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan- ati sise E ni àáso pẹlu ijọsin rinlẹ, ati sise awọn isẹ rere, ati kikọ Ash-Shirk -isẹbọ si Ọlọhun- ati ibajẹ lori ilẹ. Nitori naa ọkan naa ni ipilẹ ipepe awọn anabi, bi o tilẹ jẹ pe iyapa wa laarin wọn ninu awọn ofin ati awọn idajọ.

Nini igbagbọ si awọn Tira naa ni gbigba sisọkalẹ wọn fun awọn ojisẹ ti o ti siwaju, ati pe nini igbagbọ si Al-Qur’aan ni gbigba a gbọ, ati titẹle ohun ti o wa ninu rẹ.

} آمن الرسول بـما أنزل إليه من ربه والمؤمنون كل آمن بالله وملائكته وكتبه ورسله { [سورة البقرة: 285].

« Ojisẹ naa gba ohun ti a sọ kalẹ fun un lati ọdọ Oluwa rẹ gbọ, ati awọn olugbagbọ-ododo, onikaluku wọn gba Ọlọhun gbọ ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ » [Qur’aani, Baqarah: 285]. Ọlọhun ti O ga tun sọ pe:

} اتبعوا ما أنزل إليكم من ربكم ولا تتبعوا من دونه أولياء { [سورة الأعراف: 3].

« Ẹ tẹle ohun ti a sọ kalẹ fun yin lati ọdọ Oluwa yin, ki ẹ ma si se tẹle awọn alafẹyinti kan lẹyin Rẹ » [Suuratul-A’araaf: 3].

Ati pe dajudaju Al-Qur’aan da yatọ si awọn tira ti o siwaju pẹlu awọn nnkan kan; eyi ti o pataki ju ninu wọn ni:

1- Wi pe Mu’ujizah -akonilagara- ni i pẹlu gbolohun rẹ, ati itumọ rẹ, ati ohun ti n bẹ ninu rẹ ninu awọn nnkan ti o daju gan-an nipa ile-aye ati imọ.

2- Wi pe oun ni ipari awọn tira sanma, dajudaju a fi i se opin awọn tira naa, gẹgẹ bi a ti se fi anabi wa Muhammad, se ipẹkun fun awọn ojisẹ.

3- Wi pe Ọlọhun ti se Olugbọwọ sisọ ọ, nibi gbogbo ayipada, tabi atọwọbọ, yatọ si awọn tira yoku ti o se pe ayipada ati atọwọbọ ti wọnu wọn.

4- Wi pe olujẹri ododo ni i fun ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn tira, olusọ si ni i lori wọn pẹlu.

5- Wi pe oluparẹ ni i fun gbogbo awọn tira ti o siwaju.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ما كان حديثا يفترى ولكن تصديق الذي بين يديه وتفصيل كل شيء وهدى ورحمة لقوم يؤمنون { [سورة يوسف: 111].

« Kò jẹ ọrọ kan ti wọn da adapa irọ rẹ, sugbọn o jẹ ki a mọ ododo eyi ti o ti siwaju rẹ, o si n se alaye gbogbo nnkan, ati pe imọna ati aanu ni fun awọn ijọ ti wọn jẹ onigbagbọ-ododo » [Suuratu Yuusuf: 111].

 [5] Gbigba awọn iroyin awọn tira ti o siwaju naa:

A mọ amọdaju pe ododo ti kò si iyemeji ninu rẹ ni ohun ti o wa ninu awọn tira wọnyun un, ninu awọn iroyin ti Ọlọhun fi ransẹ si awọn ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”.

Sugbọn eyi kò tumọ si pe ki a ni igbagbọ si ohun ti o wa ninu awọn tira ti n bẹ lọwọ awọn onitira -Ahlul-Kitaab- nisinyi, nitori pe ayipada ati atọwọbọ ti ba wọn, wọn kò si sẹku lori ipilẹ wọn, eyi ti Ọlọhun sọ kalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Ati pe ninu ohun ti a mọ amọdaju rẹ ninu awọn tira wọnyi ni ohun ti Ọlọhun fun wa ni iroyin nipa rẹ ninu Tira Rẹ, nipa pe: Aru-ẹru-ẹsẹ kan kò ni i ru ẹru ẹsẹ ẹlomiran, ati pe kò si ohun ti o wa fun eniyan ju ohun ti o se ni isẹ lọ, ati pe a o fi isẹ rẹ han an nigba ti o ba ya, lẹyin naa a o san an ni ẹsan rẹ ni ẹsan ti o kun rẹrẹ.

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} أم لم ينبأ بما في صحف موسى. وإبراهيم الذي وفـى. ألا تزر وازرة وزر أخرى. وأن ليس للإنسان إلا ما سعى. وأن سعيه سوف يرى. ثم يجزاه الجزاء الأوفـى { [سورة النجم: 36-41].

« Tabi wọn kò fun un niro ni nipa ohun ti o wa ninu Tira Muusa. Ati Ibraahiim ẹni ti o mu ofin Ọlọhun sẹ. Pe ẹmi-ẹlẹsẹ kan kò ni i ru ẹru ẹsẹ omiran. Ati pe kò si ohun ti o wa fun eniyan ju ohun ti o se ni isẹ lọ. Ati pe isẹ rẹ a o fi i han an nigba ti o ba ya. Lẹyin naa a o san an ni ẹsan rẹ ni ẹsan ti o kun rẹrẹ » [Suuratun-Najm: 36-41]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} بل تؤثرون الحياة الدنيا والآخرة خير وأبقى. إن هذا لفي الصحف الأولى. صحف إبراهيم وموسى { [سورة الأعلى: 16-19].

« Sugbọn isẹmi ile-aye ni ẹ wa maya. Bẹẹ si ni [isẹmi] ọrun l’o dara julọ, ti yoo si maa bẹ titi. Dajudaju eyi n bẹ ninu awọn tira ti akọkọ. Tira Ibraahiim ati ti Muusa » [Suuratul-A’alaa: 16-19].

Sugbọn awọn idajọ wọn: Ọranyan l’o jẹ lori wa pe ki a maa fi ohun ti o wa ninu Al-Qur’aan sisẹ, yatọ si ohun ti o wa ninu awọn tira ti o siwaju, a o wo o, ti o ba jẹ ohun ti o tako ofin wa, a kò ni i sisẹ pẹlu rẹ, ki i se nitori pe o jẹ irọ, bẹẹ kọ, otitọ ni i ni asiko rẹ, sugbọn ki i se ọranyan lori wa pe ki a sisẹ pẹlu rẹ, nitori pe a ti pa sise isẹ pẹlu ofin rẹ rẹ pẹlu ofin ti wa. Nitori naa ti o ba dọgba pẹlu ofin wa; a jẹ pe otitọ ti ofin wa tọka si jijẹ otitọ rẹ ni i.

 [6] Awọn Tira ti o ti sanma wa, eyi ti orukọ wọn wa ninu Al-Qur’aan ati Sunna, ni:

1- Al-Qur’aan Alapọnle:

Oun ni ọrọ Ọlọhun eyi ti O sọ kalẹ fun Muhammad, opin awọn ojisẹ ati awọn anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”. Nitori naa o jẹ opin awọn tira ti a sọ kalẹ, Ọlọhun si ti se Olugbọwọ sisọ ọ nibi ayipada ati atọwọbọ, O si se e ni oluparẹ fun awọn tira yoku.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إنا نحن نزلنا الذكر وإنا له لحافظون { [سورة الحجر: 9].

« Dajudaju Awa ni a sọ iranti naa kalẹ, ati pe dajudaju Awa ni Olusọ rẹ » [Suuratul-Hijr: 9], Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وأنزلنا إليك الكتاب بالحق مصدقاً لما بين يديه من الكتاب ومهيمنا عليه فاحكم بينهم بما أنزل الله { [سورة المائدة: 48].

« A si ti sọ Tira naa kalẹ fun ọ pẹlu ododo, o jẹ olumunimọ ohun ti o jẹ ododo ninu ohun ti o siwaju rẹ ninu tira, ati olusọ lori rẹ. Nitori naa maa se idajọ laarin wọn pẹlu ohun ti Ọlọhun sọ kalẹ » [Suuratul-Maa’idah: 48].

2- At-Tawraata -Majẹmu Laelae-:

Oun ni Tira ti Ọlọhun sọ kalẹ fun Anabi Muusa, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, O si se e ni imọna ati imọlẹ, ti awọn anabi awọn ọmọ Isrẹli ati awọn olumọ wọn maa n fi n se idajọ.

Sugbọn At-Tawraata ti o jẹ ọranyan pe ki a ni igbagbọ si ni eyi ti Ọlọhun sọ kalẹ fun Anabi Muusa, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, ki i se At-Tawraata ti wọn ti ti ọwọ bọ, ti o wa lọwọ awọn oni-tira ni oni yii.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إنا أنزلنا التوراة فيها هدى ونور يحكم بها النبيون الذين أسلموا للذين هادوا والربانيون والأحبار بما استحفظوا من كتاب الله { [سورة المائدة: 44].

« Dajudaju Awa ti sọ At-Tawraata -Majẹmu Laelae- kalẹ, imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ. Awọn anabi ti wọn gbafa fun Ọlọhun a maa dajọ pẹlu rẹ fun awọn Yahuudi -Ju- ati pe awọn alufa wọn agba ati awọn amofin wọn naa [a maa dajọ pẹlu rẹ], nitori ohun ti a fun wọn sọ ninu tira Ọlọhun » [Suuratul-Maa’idah: 44].

3- Injiila -Bibeli, Majẹmu Titun-:

Oun ni Tira ti Ọlọhun sọ kalẹ pẹlu ododo fun Anabi Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, ajẹri ododo ni i fun ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn tira ti o ti sanma wa.

Sugbọn Bibeli -Majẹmu Titun- ti o jẹ ọranyan pe ki a gbagbọ ni Tira eyi ti Ọlọhun sọ kalẹ fun Anabi Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, pẹlu ipilẹ rẹ ti o se deedee, ki i se awọn Bibeli ti wọn ti ti ọwọ bọ, ti n bẹ lọwọ awọn oni-tira ni oni yii.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وقفينا على آثارهم بعيسى ابن مريم مصدقا لما بين يديه من التوراة وآتيناه الإنجيل فيه هدى ونور ومصدقا لما بين يديه من التوراة وهدى وموعظة للمتقين { [سورة المائدة: 46].

« Ati pe Awa fi Anabi Isa ọmọ Maryam tẹle ipasẹ wọn, ni olujẹri ododo si ohun ti o siwaju rẹ ninu At-Tawraata, A si fun un ni Injiila -Bibeli- imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ, o si jẹ olumunimọ ododo nipa ohun ti o ti siwaju rẹ ninu At-Tawraata, o si tun jẹ imọna ati isiti fun awọn olubẹru Ọlọhun » [Suuratul-Maa’idah: 46].

Ninu ohun ti At-Tawraata ati Bibeli se akojọpọ rẹ ni ifunni ni iro-idunnu pẹlu isẹ [ti a fi ran] Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الذين يتبعون الرسول النبي الأمي الذي يجدونه مكتوباً عندهم في التوراة والإنجيل يأمرهم بالمعروف وينهاهم عن المنكر ويحل لهم الطيبات ويحرم عليهم الخبائث ويضع عنهم إصرهم والأغلال التي كانت عليهم {. [سورة الأعراف: 157].

« Awọn ti wọn n tẹle ti Ojisẹ naa, Anabi naa, ẹni ti kò mọ ọ kọ ti kò mọ ọ ka, ẹni ti wọn ba akọsilẹ nipa rẹ lọdọ wọn ninu At-Tawraata ati ninu Injiila, yoo maa fooro wọn si iwa rere, yoo si maa kọ aburu fun wọn, yoo si maa se awọn ohun ti o dara ni ẹtọ fun wọn, yoo si maa se awọn ohun ti kò dara ni eewọ fun wọn, yoo si maa gbe awọn ẹru ti o wuwo kuro fun wọn, ati ajaga ti n bẹ fun wọn » [Suuratul-A’araaf: 157].

4- Zabuura

Oun ni Tira eyi ti Ọlọhun sọ kalẹ fun Anabi Daa’uud, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”. Zabuura eyi ti o si jẹ ọranyan pe ki a gbagbọ ni ohun ti Ọlọhun sọ kalẹ fun Anabi Daa’uud, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, ki i se eyi ti atọwọbọ ti wọ inu rẹ ninu isẹ awọn Yahuudi -Ju-. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وآتينا داود زبوراً { [سورة النساء: 63].

« Ati pe Awa fun Daa’uud ni Zabuura » [Suuratun-Nisaa’i: 63].

[5] Tira Anabi Ibraahiim ati ti Anabi Muusa:

Oun ni Tira ti Ọlọhun fun Anabi Ibraahiim ati Anabi Muusa, “ki ọla Ọlọhun o maa ba awọn mejeeji”, awọn tira wọnyi si ti sọnu, a kò si mọ nnkan kan nipa wọn yatọ si ohun ti ọrọ nipa rẹ wa ninu Al-Qur’aan alapọnle ati Sunna.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} أم لم ينبأ بما في صحف موسى. وإبراهيم الذي وفـى. ألا تزر وازرة وزر أخرى. وأن ليس للإنسان إلا ما سعى. وأن سعيه سوف يرى. ثم يجزاه الجزاء الأوفـى { [سورة النجم: 36-41].

« Tabi wọn kò fun un niro ni nipa ohun ti o wa ninu Tira Muusa. Ati Ibraahiim ẹni ti o mu ofin Ọlọhun sẹ. Pe ẹmi-ẹlẹsẹ kan kò ni i ru ẹru ẹsẹ omiran. Ati pe kò si ohun ti o wa fun eniyan ju ohun ti o se nisẹ lọ. Ati pe isẹ rẹ a o fi i han an nigab ti o ba ya. Lẹyin naa a o san an ni ẹsan rẹ ni ẹsan ti o kun rẹrẹ » [Suuratun-Najm: 36-41]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} قد أفلح من تزكى. وذكر اسم ربه فصلى. بل تؤثرون الحياة الدنيا والآخرة خير وأبقى. إن هذا لفي الصحف الأولى. صحف إبراهيم وموسى { [سورة الأعلى: 14-19].

« Dajudaju ẹni ti o se mimọ ti jere. Ti o si n ranti orukọ Oluwa rẹ, ti o si n kirun. Sugbọn isẹmi ile-aye ni ẹ n wa maya. Bẹẹ si ni [isẹmi] ọrun l’o dara ju, ti yoo si maa bẹ titi. Dajudaju eyi n bẹ ninu awọn tira ti akọkọ. Tira Ibraahiim ati ti Muusa » [Suuratul-A’alaa: 14-19].

 ORIGUN KẸRIN: NINI IGBAGBỌ-ODODO SI AWỌN OJISẸ

 [1] Nini igbagbọ-ododo si awọn ojisẹ, ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn:

Ọkan ni i ninu awọn origun igbagbọ-ododo, awọn ti o se pe igbagbọ ẹniyan kò le e rinlẹ afi pẹlu wọn.

Nini igbagbọ-ododo si awọn ojisẹ si ni: Nini adisọkan ti o gbopọn pe dajudaju Ọlọhun ni awọn ojisẹ kan, ti O sa lẹsa, nitori jijẹ awọn isẹ Rẹ dopin. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba tẹle wọn ti mọna, ẹnikẹni ti o ba si kọ ti wọn ti sina, ati pe wọn ti jisẹ ohun ti Ọlọhun sọ kalẹ fun wọn ni jijisẹ ti o han gbangbá, wọn si jisẹ ohun ifọkantan naa, wọn si se isiti fun ijọ wọn, wọn si jagun nitori Ọlọhun ni paapaa jijagun, wọn si mu awọn awijare wa, ati pe wọn kò yi nnkan kan pada, bẹẹ wọn kò pa nnkan kan da, wọn kò si gbe nnkan kan pamọ ninu ohun ti a fi ran wọn nisẹ, a si tun ni igbagbọ si awọn ti Ọlọhun darukọ wọn fun wa ati awọn ti kò darukọ, ati pe gbogbo ojisẹ a maa funni iro-idunnu nipa ẹni ti n bọ lẹyin rẹ, bẹẹ ni ẹni ti o gbẹyin ninu wọn a maa se ijẹri ododo fun ẹni ti o siwaju rẹ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} قولوا آمنا بالله وما أنزل إلينا وما أنزل إلى إبراهيم وإسماعيل وإسحاق ويعقوب والأسباط وما أوتي موسى وعيسى وما أوتي النبيون من ربهم لا نفرق بين أحد منهم ونحن له مسلمون { [سورة البقرة: 136].

« Ẹ wi pe: Awa gba Ọlọhun gbọ, ati ohun ti a sọ kalẹ fun wa ati ohun ti a sọ kalẹ fun Ibraahiim, ati Ismaai’iil, ati Ishaaq, ati Ya’aquub, ati awọn arọmọdọmọ, ati ohun ti a fun Muusa ati Isa ati ohun ti a fun awọn anabi lati ọdọ Oluwa wọn, awa kò ya ẹnikan si ọtọ ninu wọn, awa si jẹ ẹni ti o juwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun -Musulumi- » [Suuratul-Baqarah: 136].

Nitori naa ẹnikẹni ti o ba pe ojisẹ kan ni irọ, dajudaju o ti pe ẹni ti o gba lododo [ninu wọn] ni irọ, ati pe ẹnikẹni ti o ba kọ ọrọ si i lẹnu, ti kọ ọrọ si ẹni ti a pa a lasẹ pe ki o tẹle tiẹ lẹnu. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إن الذين يكفرون بالله ورسله ويريدون أن يفرقوا بين الله ورسله ويقولون نؤمن ببعض ونكفر ببعض ويريدون أن يتخذوا بين ذلك سبيلاً. أولئك هم الكافرون حقا وأعتدنا للكافرين عذابا مهيناً { [سورة النساء: 150، 151].

« Dajudaju awọn ti wọn n se aigbagbọ si Ọlọhun, ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si n fẹ lati fi ipinya si aarin Ọlọhun, ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si n sọ pe: Awa gba apa kan gbọ [ninu awọn ojisẹ] a si se aigbagbọ si omiran; ti wọn si n fẹ lati mu oju-ọna kan laarin eleyii. Awọn wọnyi ni alaigbagbọ ni ododo, a si ti pese iya ẹlẹtẹ fun awọn alaigbagbọ » [Suuratun-Nisaa’i: 150, 151].

 [2] Paapaa Jijẹ anabi:

Jijẹ anabi ni: Wiwa laarin Ẹlẹda ati ẹda nipa jijisẹ ofin Rẹ, Ọlọhun A maa se e ni idẹra fun ẹni ti O ba fẹ ninu awọn ẹda Rẹ, A si maa se ẹsa ẹni ti o ba fẹ fun un ninu awọn ẹda Rẹ. Nitori naa sise ẹsa kò jẹ ti ẹnikan yatọ si I -mimọ ni fun Un-. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الله يصطفي من الملائكة رسلاً ومن الناس إن الله سميع بصير { [سورة الحج: 75].

« Ọlọhun A maa sẹsa awọn ojisẹ ninu awọn malaika ati ninu awọn eniyan; dajudaju Olugbọrọ, Oluriran ni Ọlọhun » [Suuratul-Hajj: 75].

Ati pe ohun ti a maa n fi i ta eniyan lọrẹ ni jijẹ anabi, ki i se ohun ti a maa n sisẹ ri, a ki i ri i pẹlu ọpọlọpọ titẹle ti Ọlọhun, tabi ijọsin, bẹẹ ni ki i wa pẹlu ẹsa anabi naa tabi titọrọ rẹ, ati pe kò tilẹ jẹ nnkan kan bi kò se yiyan ati ẹsa lati ọdọ Ọlọhun, Ọba t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الله يجتبي إليه من يشاء ويهدي إليه من ينيب { [سورة الشورى: 13].

« Ọlọhun A maa yan ẹni ti O ba fẹ funra Rẹ, A si maa tọ ẹni ti n sẹri [si ọdọ Rẹ] si ọna ọdọ ara Rẹ » [Suuratush-Shuuraa: 13].

 [3] Hikmah -ọgbọn- ti o wa ninu riran awọn ojisẹ:

Hikmah -ọgbọn- ti o wa ninu riran awọn ojisẹ, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, n bẹ lara awọn nnkan kan, ti o se pe ninu wọn ni:

Alakọkọ: Yiyọ awọn eniyan kuro ninu jijọsin fun awọn eniyan lọ sibi jijọsin fun Oluwa awọn eniyan, ati nibi imunisin jijẹ ẹru fun ẹda lọ sibi ominira jijọsin fun Oluwa awọn ẹda. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وما أرسلناك إلا رحمة للعالمين { [سورة الأنبياء: 107].

« Ati pe Awa kò ran ọ nisẹ afi ki o le jẹ aanu fun gbogbo aye » [Suuratul-Anbiyaa’: 107].

Ẹlẹẹkeji: Mimọ idi ti Ọlọhun titori rẹ sẹda awọn ẹda, oun ni jijọsin fun Un, ati sise E ni àáso, eyi ti a kò le e mọ afi ni ọna awọn ojisẹ, awọn ẹni ti Ọlọhun sẹsa wọn ninu awọn ẹda Rẹ, ti O si fun wọn ni ajulọ lori gbogbo ẹda. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولقد بعثنا في كل أمة رسولاً أن اعبدوا الله واجتنبوا الطاغوت { [سورة النحل: 36].

« Ati pe dajudaju A ti gbe ojisẹ kan dide ninu gbogbo ijọ kọọkan; pe: Ẹ maa jọsin fun Ọlọhun, ki ẹ si jinna si awọn oosa » [Suuratu n-Nah’l :36].

Ẹlẹẹkẹta: Gbigbe awijare duro lori awọn eniyan pẹlu riran awọn ojisẹ naa. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} رسلا مبشرين ومنذرين لئلا يكون للناس على الله حجة بعد الرسل وكان الله عزيزاً حكيماً { [سورة النساء: 165].

« Awọn ojisẹ ti wọn jẹ olufunni ni iro-idunnu ati olukilọ, ki awijare kan o ma baa si fun awọn eniyan lọdọ Ọlọhun lẹyin -t’O ti ran- awọn ojisẹ wọnyi, Ọlọhun si jẹ Alagbara, Ọlọgbọn » [Suuratul-Nisaa’i: 165].

Ẹlẹẹkẹrin: Alaye apa kan ninu awọn ohun ti o pamọ, eyi ti awọn eniyan kò le mọ pẹlu laakaye wọn, gẹgẹ bi awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ, ati mimọ awọn Malaika, ati ọjọ ikẹyin, ati ohun ti o yatọ si eleyii.

Ẹlẹẹkarun-un: Jijẹ ti awọn ojisẹ naa jẹ awokọse rere, Ọlọhun pe wọn pẹlu awọn iwa alapọnle, O si sọ wọn nibi awọn iruju ati ifẹkufẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} أولئك الذين هدى الله فبهداهم اقتده { [سورة الأنعام: 90].

« Awọn wọnyi ni ẹni ti Ọlọhun ti tọ sọna, nitori naa imọna wọn ni ki o kọse » [Suuratul-An-aam: 90]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} لقد كان لكم في رسول الله أسوة حسنة { [سورة الأحزاب: 21].

« Dajudaju ohun awokọse rere n bẹ fun yin lara Ojisẹ Ọlọhun » [Suuratul Ahzaab: 21].

Ẹlẹẹkẹfa: Sise atunse awọn ẹmi, ati mimu aburu kuro ninu wọn, ati fifọ wọn mọ, ati mimọ wọn, ati sise ikilọ fun wọn nibi gbogbo ohun ti i maa n ko iparun ba wọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} هو الذي بعث في الأميين رسولاً منهم يتلو عليهم آياته ويزكيهم ويعلمهم الكتاب والحكمة { [سورة الجمعة: 2].

« Oun ni Ẹni ti O gbe ojisẹ kan dide laarin awọn alaimọọkọ-mọọka lati inu wọn, ti n ka awọn aayah Rẹ fun wọn, ti o si n fọ wọn mọ, ti o si n kọ wọn ni Tira ati ọgbọn » [Suuratul-Jum’at: 2]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

 (( إنما بعثت لأتمم مكارم الأخلاق )) [رواه أحمد، والحاكم].

« A kò gbe mi dide afi ki n le baa pe awọn iwa alapọnle » [Ahmad ati Haakim l’o gbe e jade].

 [4] Isẹ awọn ojisẹ “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”:

Awọn ojisẹ “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, ni awọn isẹ ribiribi, ti o se pe ninu wọn ni:

a- Jijẹ isẹ ofin Sharia de opin, ati pipe awọn eniyan lọ sidi ijọsin fun Ọlọhun nikan, ati bibọ ijọsin fun ohun ti o yatọ si I danu. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} الذين يبلغون رسالات الله ويَخشونه ولا يَخشون أحداً إلا الله وكفى بالله حسيبـاً { [سورة الأحزاب: 39].

« Awọn ẹni ti wọn jẹ isẹ Ọlọhun de opin, ti wọn si n bẹru Rẹ, ti wọn kò si bẹru ẹnikan yatọ si Ọlọhun, Ọlọhun si to ni Olusiro » [Suuratul-Ahzaab: 39].

b- Sise alaye ohun ti Ọlọhun sọ kalẹ ni ẹsin. Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} وأنزلنا إليك الذكر لتبين للناس ما نزِّل إليهم ولعلهم يتفكرون { [سورة النحل: 44].

« Ati pe A sọ iranti naa kalẹ fun ọ, ki o le maa se alaye fun awọn eniyan ohun ti a sọ kalẹ fun wọn, ati ki wọn o le baa maa ronu » [Suuratun-Nahl: 44].

d- Fifi awọn ijọ mọna lọ sidi rere, ati sise ikilọ fun wọn nibi aburu, ati fifun wọn ni iro-idunnu pẹlu ẹsan, ati sise ikilọ fun wọn pẹlu iya ẹsẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} رسلا مبشرين ومنذرين { [سورة النساء: 165].

« Ni awọn ojisẹ, ti wọn jẹ olufunni ni iro-idunnu ati olukilọ » [Suuratun-Nisaa’i: 165].

e- Sise atunse awọn eniyan pẹlu apejuwe daadaa, ati awokọse rere ninu awọn ọrọ ati awọn ise.

ẹ- Gbigbe ofin Ọlọhun duro laarin awọn eniyan ati mimu un lo.

f- Ijẹri awọn ojisẹ lori awọn ijọ wọn ni ọjọ igbende, pe awọn ti jẹ isẹ fun wọn ni jijẹ ti o de opin, ti o han gbangbá. Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} فكيف إذا جئنا من كل أمة بشهيد وجئنا بك على هؤلاء شهيداً { [سورة النساء: 41].

« Njẹ bawo ni [ọrọ] yoo ti jẹ nigba ti A ba mu ẹlẹri kan wa ninu ijọ kọọkan, ti A si mu iwọ jade ni ẹlẹri lori awọn wọnyi » [Suuratun-Nisaa’i: 41].

 [5] Ẹsin gbogbo awọn anabi ni Islam:

Ẹsin gbogbo awọn anabi ati awọn ojisẹ ni Islam. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} إن الدين عند الله الإسلام { [سورة آل عمران: 19].

« Dajudaju ẹsin ni ọdọ Ọlọhun ni Islam » [Suuratu Aal-Imraan: 19]. Gbogbo wọn ni wọn n pepe lọ sidi ijọsin fun Ọlọhun nikan, ati pipa ijọsin fun ohun ti o yatọ si I ti, bi o tilẹ jẹ pe awọn ofin wọn ati awọn idajọ wọn yatọ sira wọn, sugbọn ẹnu wọn ko lori ipilẹ, ti i se At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan ninu ijọsin-. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( الأنبياء إخوة لعلات )) [رواه البخاري].

« Ọmọ ọbàkan ni awọn anabi » Bukhari l’o gbe e jade.

 [6] Eniyan abara ni awọn ojisẹ, wọn kò mọ ikọkọ:

Imọ ikọkọ wa ninu awọn iroyin jijẹ ọlọhun, ati pe kò si ninu awọn iroyin awọn anabi; nitori pe eniyan abara ni wọn, gẹgẹ bi awọn mìíran ti wọn yatọ si wọn ninu awọn eniyan, wọn a maa jẹ, wọn si maa mu, wọn a si maa fẹ iyawo, wọn a si maa sun, wọn a si maa se amodi, bẹẹ ni a maa rẹ wọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وما أرسلنا قبلك من المرسلين إلا إنهم ليأكلون الطعام ويمشون في الأسواق { [سورة الفرقان 20].

« Awa kò ran ojisẹ kan ninu awọn ojisẹ nisẹ siwaju rẹ, afi ki wọn o maa jẹ ounjẹ, ki wọn o si maa rin ni aarin awọn ọja » [Suuratul-Furqaan: 20]. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولقد أرسلنا رسلا من قبلك وجعلنا لهم أزواجاً وذرية { [سورة الرعد: 38].

« Dajudaju Awa ti ran awọn ojisẹ kan nisẹ siwaju rẹ, A si se awọn iyawo ati awọn ọmọ fun wọn » [Suuratur-Ra’ad: 38]. Ati pe ohun ti i maa n se eniyan ninu ibanujẹ, ati idunnu, idaamu, ati idasansan a maa se wọn; bẹẹ ni Ọlọhun kò sa wọn lẹsa afi nitori jijisẹ ẹsin Rẹ de opin, wọn kò si mọ ikọkọ, afi ohun ti Ọlọhun ba fi han wọn. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} عالم الغيب فلا يظهر على غيبه أحداً. إلا من ارتضى من رسول فإنه يسلك من بين يديه ومن خلفه رصداً { [سورة الجن: 26-27].

« Oni-imọ ikọkọ, nitori naa ki I fi imọ ikọkọ Rẹ han ẹni kankan. Afi ẹni ti O ba yọnu si ni ojisẹ kan, sibẹsibẹ yoo jẹ ki olusọ kan o maa bẹ ni iwaju rẹ ati ni ẹyin rẹ » [Suuratul-Jinn: 26-27].

 [7] Isọ awọn ojisẹ:

Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- se ẹsa awọn ẹni-ajulọ ju ninu awọn ẹda Rẹ, ati awọn ti wọn pe ju ni dida ati ni iwa fun jijẹ isẹ Rẹ, O si se isọ fun wọn kuro nibi awọn ẹsẹ nlanla, O si fọ wọn mọ nibi gbogbo alebu titi wọn yoo fi jẹ isẹ Ọlọhun fun awọn ijọ wọn. Nitori naa ẹnu awọn ijọ ko lori pe ẹni ti a sọ ni wọn ninu ohun ti wọn n funni niroyin rẹ nipa Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- nipa jijẹ isẹ Rẹ de opin. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يا أيها الرسول بلغ ما أنزل إليك من ربك وإن لم تفعل فما بلغت رسالته والله يعصمك من الناس { [سورة المائدة: 67].

« Irẹ Ojisẹ, jisẹ ohun ti a sọ kalẹ fun ọ lati ọdọ Oluwa rẹ de opin, bi o kò ba se bẹẹ, a jẹ pe iwọ kò jẹ isẹ Rẹ de opin, Ọlọhun yoo si maa daabo bo ọ kuro lọdọ awọn eniyan » [Suuratul-Maa’idah: 67].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} الذين يبلغون رسالات الله ويخشونه ولا يخشون أحداً إلا الله { [سورة الأحزاب: 39].

« Awọn ẹni ti wọn jẹ isẹ Ọlọhun de opin, ti wọn si n bẹru Rẹ, ti wọn kò si bẹru ẹnikan yatọ si Ọlọhun » [Suuratul-Ahzaab: 39]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} ليعلم أن قد أبلغوا رسالات ربهم وأحاط بما لديهم وأحصى كل شيء عدداً { [سورة الجن: 28].

« Ki O ba le mọ pe wọn ti jisẹ Oluwa wọn de opin, ati pe O yipo ohun ti n bẹ lọdọ wọn, O si se isiro gbogbo nnkan ni onka » [Suuratul-Jinn: 28].

Ati pe ti ẹsẹ kekere kan ba ti ọwọ ẹnikan wọn sẹlẹ, eyi ti o se pe kò jẹmọ jijẹ isẹ dopin; a o se afihan rẹ fun wọn, wọn yoo si ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun ni kia, wọn yoo si sẹri pada lọ si ọdọ Rẹ. Nitori naa yoo dabi ẹni pe kò sẹlẹ ri, wọn yoo si ti ara rẹ ni ipo ti o ga ju awọn ipo wọn ti o siwaju lọ. Eleyii ri bẹẹ, nitori pe dajudaju Ọlọhun ti se adayanri awọn anabi Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, pẹlu pipe awọn iwa, ati awọn iroyin rere, O si fọ wọn mọ kuro nibi gbogbo ohun ti yoo mu ki iyi wọn ati awọn ipo wọn o subu.

 [8] Onka awọn anabi ati awọn ojisẹ ati ẹni-ajulọ ju ninu wọn:

O rinlẹ pe onka awọn anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, ni ọgọrun mẹta ati nnkan kan le ni mẹwa, fun ọrọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, nigba ti wọn bi i leere nipa onka awọn ojisẹ [pe]:

(( ثلاثمائة وخمس عشرة جما وغفيراً )) [رواه الحاكم].

« Ọgọrun mẹta ati mẹẹdogun, wọn jọ, wọn si pọ » [Haakim l’o gbe e jade]. Ati pe awọn anabi pọ ju eleyii lọ. O n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun sọ fun wa nipa rẹ ninu Tira Rẹ, o si wa ninu wọn ẹni ti kò sọ fun wa nipa rẹ, ati pe Ọlọhun ti darukọ mẹẹdọgbọn ninu wọn ninu Tira Rẹ, ni anabi ati ojisẹ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ورسلاً قد قصصناهم عليك من قبل ورسلاً لم نقصصهم عليك { [سورة النساء: 164].

« Awọn ojisẹ kan n bẹ ti A ti sọ itan wọn fun ọ tẹlẹ, bẹẹ ni awọn ojisẹ kan n bẹ ti A kò sọ itan wọn fun ọ » [Suuratun-Nisaa’i: 164].

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وتلك حجتنا آتيناها إبراهيم على قومه نرفع درجات من نشاء إن ربك حكيم عليم. ووهبنا له إسحاق ويعقوب كلا هدينا ونوحا هدينا من قبل ومن ذريته داود وسليمان وأيوب ويوسف وموسى وهارون وكذلك نجزي المحسنين. وزكريا ويحيى وعيسى وإلياس كل من الصالحين. وإسماعيل واليسع ويونس ولوطاً وكلاً فضلنا على العالمين. ومن آبائهم وذرياتهم وإخوانهم واجتبيناهم وهديناهم إلى صراط مستقيم { [سورة الأنعام: 83-87].

« Eyi ni idi-ọrọ Wa ti A fun Ibraahiim lori awọn eniyan rẹ, A maa N gbe ẹni ti o ba wu Wa ga ni ipo, dajudaju Ọlọgbọn, Oni-Mimọ ni Oluwa rẹ. Awa si fun un ni Ishaaq ati Ya’aquub, Awa si tọ onikaluku wọn si ọna, Awa si tọ Nuuhu si ọna siwaju. Ninu awọn arọmọdọmọ rẹ ni Daa’uud, ati Sulaiman, ati Ayyuub, ati Yuusuf, ati Muusa, ati Haaruun. Bayii ni A se maa N san ẹsan fun awọn oniwa-rere. Ati Zakariyyaa, ati Yahyaa, ati Isa, ati Ilyaas; gbogbo wọn l’o n bẹ ninu awọn ẹni-rere. Ati Ismaai’iil, ati Alyasa’a, ati Yuunus, ati Luut, gbogbo wọn ni A se ajulọ fun lori awọn ẹda. Ati ninu awọn baba wọn ati awọn arọmọdọmọ wọn, ati awọn ọmọ iya wọn lọkunrin, Awa si sa wọn lẹsa; A si tọ wọn si ọna kan ti o tọ » [Suuratul-An’aam: 83-87].

Ati pe Ọlọhun se ajulọ fun apa kan ninu awọn anabi lori omíran. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولقد فضلنا بعض النبيين على بعض { [سورة الإسراء: 55].

« Ati pe dajudaju A ti fun apa kan ninu awọn anabi ni ajulọ lori apa kan » [Suuratul-Israa’: 55]. Bẹẹ ni Ọlọhun se ajulọ fun apa kan ninu awọn ojisẹ lori omiran. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} تلك الرسل فضلنا بعضهم على بعض { [سورة البقرة: 253].

« Awọn ojisẹ ni wọnyun un, A se agbega fun apa kan wọn lori apa kan» [Suuratul-Baqarah: 253].

Awọn ti wọn si ni ajulọ ju ninu wọn ni awọn oni-ipinnu [ọkan] ninu awọn ojisẹ; awọn ni Anabi Nuuhu, Ibraahiim, Muusa, Isa, ati Anabi wa Muhammad, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn”. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} فاصبر كما صبر أولو العزم من الرسل { [سورة الأحقاف: 35].

« Nitori naa se suuru, gẹgẹ bi awọn oni-ipinnu [ọkan] ninu awọn ojisẹ ti se suuru » [Suuratul Ahqaaf: 35]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وإذ أخذنا من النبيين ميثاقهم ومنك ومن نوح وإبراهيم وموسى وعيسى بن مريم وأخذنا منهم ميثاقا غليظاً {. [سورة الأحزاب: 7].

« Nigba ti A gba adehun ni ọdọ awọn anabi ati ni ọdọ rẹ ati ni ọdọ Nuuhu ati Ibrahiim ati Musa ati Isa ọmọ Maryam, ati pe Awa gba adehun ti o nipọn ni ọdọ wọn » [Suuratul-Ahzaab: 7].

Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si ni ẹni-ajulọ ju ninu awọn ojisẹ, ipẹkun awọn anabi, ọga awọn ọmọ Aadama, asiwaju awọn anabi nigba ti wọn ba pejọ, agbẹnusọ wọn nigba ti wọn ba wa, oni-ibuduro ti ẹyin, eyi ti awọn ẹni-akọkọ ati awọn ẹni-igbẹyin yoo titori rẹ jowu rẹ, alasia ọpẹ ati àbatà alọreemu, olusipẹ fun awọn ẹda ni ọjọ igbende, oni-Al-Wasiilah -aye ọla nla kan ninu ọgba-idẹra- ati Fadhiilah -ajulọ-. Ọlọhun ran an pẹlu eyi ti o lọla ju ninu awọn ofin ẹsin Rẹ, O si se ijọ rẹ ni ijọ ti o l’oore ju, ti a gbe jade fun awọn eniyan, ati pe O kojọ fun oun ati ijọ rẹ ninu awọn ajulọ ati awọn daadaa ohun ti o pin laarin awọn ti wọn siwaju wọn, awọn si ni igbẹyin awọn ijọ ni dida, sugbọn awọn ni akọkọ wọn ni gbigbe dide.

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( فضلت على الأنبياء بست )) [رواه مسلم].

« A fun mi ni ajulọ lori awọn anabi pẹlu ohun mẹfa » [Muslim l’o gbe e jade]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( أنا سيد ولد آدم يوم القيامة، وبيدي لواء الحمد، ولا فخر. وما من نبي يومئذ آدم فمن سواه إلا تحت لوائي يوم القيامة )) [رواه أحمد، والترمذي].

« Emi ni asiwaju awọn ọmọ Aadama ni ọjọ igbende, ọwọ mi si ni asia ọpẹ yoo wa, ki i se ti irera. Ati pe kò si anabi kan, Aadama ti o fi de ori awọn ti wọn yatọ si i, ayaafi ki wọn o wa ni abẹ asia mi ni ọjọ igbende » [Ahmad ati At-Tirmidzi ni wọn gbe e jade].

Ẹni ti o si pọwọ le Ojisẹ Ọlọhun, [Muhammad], “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, pẹlu ajulọ ninu wọn ni Ibraahiim, Al-Khaliil -aayò Ọlọhun- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”. Nitori naa awọn Khaliil mejeeji ni ẹni-ajulọ ju ninu awọn oni-ipinnu [ọkan] ninu awọn ojisẹ, lẹyin naa ni awọn mẹta yoku lẹyin awọn mejeeji.

 [9] Awọn Mu’ujizah [awọn ohun ti i ko’ni lagara ti o jẹ arisami] fun awọn anabi, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn”

Ọlọhun se iranlọwọ fun awọn ojisẹ Rẹ, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, pẹlu awọn ami ti o ga, ati awọn ohun ti i ko’ni lagara ti iyanu, ki o le baa jẹ awijare tabi ẹri, gẹgẹ bi Al-Qur’aan alapọnle, ati lila osupa [sis meji], ati yiyipada ọpa si ejo, ati dida ẹyẹ lati ara amọ, ati ohun ti o yatọ si i.

Nitori naa ẹri ni ohun ti i ko’ni lagara ti o yapa si ohun ti a ba saaba lori jijẹ anabi ti ododo, ẹri si ni ami apọnle jẹ lori ododo ẹni ti o jẹri pẹlu jijẹ anabi ti ododo.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} لقد أرسلنا رسلنا بالبينات { [سورة الحديد، الآية: 25].

« Dajudaju Awa ti ran awọn ojisẹ wa pẹlu awọn alaye » [Suuratul-Hadiid: 25]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

(( ما من نبي من الأنبياء إلا وقد أوتي من الآيات ما آمن على مثله البشر، وإنما كان الذي أوتيته وحياً أوحاه إلـيَّ، فأرجو أن أكون أكثرهم تابعاً يوم القيامة )) [متفق عليه].

« Kò si anabi kan ninu awọn anabi afi ki o jẹ pe a fun un ninu awọn ami, ohun ti awọn ẹniyan gbagbọ lori iru rẹ, sugbọn eyi ti a fun emi kò jẹ nnkan kan yatọ si Wahy -isẹ ti Ọlọhun maa N fi i ransẹ- O fi ransẹ si mi, nitori naa mo n rankan pe ki n jẹ ẹni ti o pọju ninu wọn ni ọmọlẹyin ni ọjọ igbende » [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

 [10] Nini igbagbọ si jijẹ anabi Anabi wa, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”:

Ipilẹ nla kan ninu awọn ipilẹ igbagbọ-ododo ni nini igbagbọ si jijẹ anabi Anabi wa, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati pe igbagbọ-ododo kò le e rinlẹ afi pẹlu rẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ومن لم يؤمن بالله ورسوله فإنا اعتدنا للكافرين سعيراً { [سورة الفتح: 13].

« Ati pe ẹnikẹni ti kò ba gba Ọlọhun gbọ ati Ojisẹ Rẹ, dajudaju Awa pese ina elejo fofo silẹ fun awọn alaigbagbọ » [Suuratul-Fath: 13].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( أمرت أن أقاتل الناس حتى يشهدوا أن لا إله إلا الله، وأن محمداً رسول الله )) [رواه مسلم].

« A pa mi ni asẹ pe ki n maa ja awọn eniyan logun, titi ti wọn yoo fi jẹri pe: Kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ati pe Muhammad, ojisẹ Ọlọhun ni i se » [Muslim l’o gbe e jade]. Nini igbagbọ si i “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, kò si le e pe afi pẹlu awọn nnkan kan ti o se pe ninu wọn ni:

Ekinni: Mimọ Anabi wa Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”. Oun ni: Muhammad ọmọ Abdullah, ọmọ Abdul Muttalib, ọmọ Haashim, ninu iran Quraish ni Haashim ti jade, ọkan ninu awọn Larubawa si ni awọn Quraish i se, bẹẹ ni awọn Larubawa jẹ apa kan ninu awọn arọmọdọmọ Anabi Ismaai’iil ọmọ Anabi Ibraahiim, Al- Khaliil -aayò Ọlọhun- eyi ti o lọla ju ninu ikẹ ati igẹ Ọlọhun k’o maa ba oun ati Anabi wa. Ọdun mẹtalelọgọta ni Anabi wa lo laye, o lo ogoji ọdun ninu rẹ siwaju ki Ọlọhun O to se e ni anabi, o si fi ọdun mẹtalelogun ninu rẹ jẹ ojisẹ Ọlọhun, ati anabi Rẹ.

Ekeji ni: Gbigba a lododo lori ohun ti o funni niro, ati titẹle tiẹ ninu ohun ti o pa lasẹ, ati jijinna si ohun ti o kọ, ti o si jagbe [mọ ni lori rẹ], ki a si ma se jọsin fun Ọlọhun afi pẹlu ohun ti o se lofin.

Ẹẹkẹta ni: Nini adisọkan pe ojisẹ Ọlọhun ni i si gbogbo awọn ẹda nla meji; alujannu ati eniyan. Nitori naa aaye kò gba ẹnikan ninu wọn afi ki o tẹle e. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} قل يا أيها الناس إني رسول الله إليكم جميعاً { [سورة الأعراف: 158].

« Sọ pe ẹyin eniyan, dajudaju emi ni ojisẹ Ọlọhun si gbogbo yin » [Suuratul-Aaraaf: 158].

Ẹẹkẹrin ni: Nini igbagbọ si jijẹ ojisẹ rẹ, ati pe oun l’o ni ajulọ ju ninu awọn anabi ati opin wọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولكن رسول الله وخاتم النبيين {. [سورة الأحزاب: 40].

« Sugbọn ojisẹ Ọlọhun ni i, opin awọn anabi si ni i pẹlu » [Suuratul Ahzaab: 40]. Ati pe Khaliil -aayò- Ọba Alaanujulọ ni i, ati asiwaju awọn ọmọ Aadama, oni-ipẹ nla, ẹni ti a se adayanri pẹlu Al-Wasiilah -aye ọla nla kan ninu ọgba-idẹra- eyi ti i se agbega ti o ga ju ninu ọgba-idẹra, ati alabatà alọreemu, ati pe ijọ rẹ ni ijọ ti o ni oore ju ninu awọn ijọ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} كنتم خير أمة أخرجت للناس { [سورة آل عمران: 110].

« Ẹyin ni ijọ ti o ni oore julọ ti a gbe jade fun awọn eniyan » [Suuratu Aal-Imraan: 110]. Awọn si ni wọn pọ ju ninu awọn ara ọgba-idẹra -Al-Janna- ati pe isẹ rẹ [ti a fi ran an] ni oluparẹ fun gbogbo awọn isẹ ti o siwaju.

Ẹẹkarun-un ni pe: Dajudaju Ọlọhun ti i lẹyin pẹlu Mu’ujizah -ami akonilagara- ti o tobi ju, ati arisami ti o han ju, oun ni Al-Qur’aan alapọnle, ọrọ Ọlọhun ti a sọ nibi ayipada ati atọwọbọ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} قل لئن اجتمعت الإنس والجن على أن يأتوا بمثل هذا القرآن لا يأتون بمثله ولو كان بعضهم لبعض ظهيراً { [سورة الإسراء: 88].

« Sọ pe: Ti awọn eniyan ati alujannu ba papọ lori atimu iru Al-Qur’aan yii wa, wọn kò ni le mu iru rẹ wa, bi o fẹ ki o jẹ pe apa kan wọn n ran apa kan wọn lọwọ » [Suuratul-Israa’: 88]. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إنا نحن نزلنا الذكر وإنا له لحافظون { [سورة الحجر: 9].

« Dajudaju Awa ni a sọ iranti naa [Al-Qur’aan] kalẹ, ati pe dajudaju Awa ni Olusọ rẹ » [Suuratul-Hijr: 9].

Ẹkẹfa ni: Nini igbagbọ pe dajudaju Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ti jẹ isẹ de opin, o si jisẹ ohun ifọkantan naa, o si se isiti fun ijọ rẹ. Nitori naa kò si rere kan afi ki o ti tọka rẹ fun awọn ijọ rẹ, ki o si ti gba wọn ni iyanju nipa rẹ, bẹẹ ni kò si aburu kan afi ki o ti kọ ọ fun awọn ijọ rẹ, ki o si ti se ikilọ fun wọn nipa rẹ. Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} لقد جاءكم رسول من أنفسكم عزيز عليه ما عنتم حريص عليكم بالمؤمنين رءوف رحيم { [سورة التوبة: 128].

« Dajudaju ojisẹ kan ti wa ba yin lati inu yin, ohun ti yoo ni yin lara a maa le koko lara rẹ, o jẹ olusojukokoro lori yin [lati fi yin mọna], alaanu onikẹ si ni fun awọn olugbagbọ-ododo » [Al-Qur’aan, Suuratu t-Tawbah: 128].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

(( ما من نبي بعثه الله في أمة قبلي إلا حقا عليه أن يدل أمته على خير ما يعلمه لهم، ويحذر أمته من شر ما يعلمه لهم )) [رواه مسلم ].

« Kò si anabi kan ti Ọlọhun ran si ijọ kan siwaju mi, afi ki o jẹ ọranyan lori rẹ pe ki o fi ọna mọ awọn ijọ rẹ lọ sidi rere ohun ti o mọ fun wọn, ki o si kilọ fun ijọ rẹ nibi aburu ohun ti o mọ fun wọn » [Muslim l’o gbe e jade].

Ekeje ni: Ninifẹ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati titi ifẹ rẹ siwaju [fifẹran] ẹmi [ẹni], ati awọn ẹda yoku, ati gbigbe e ga, ati kika a kun, ati bibu iyi fun un, ati sise apọnle rẹ, ati titẹle tiẹ, tori pe dajudaju eleyii n bẹ ninu awọn iwọ rẹ, eyi ti Ọlọhun se ni ọranyan ninu Tira Rẹ fun Anabi Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tori pe dajudaju ninifẹ rẹ wa ninu ninifẹ Ọlọhun, bẹẹ ni titẹle tiẹ n bẹ ninu titẹle ti Ọlọhun:

} قل إن كنتم تحبون الله فاتبعون يحببكم الله ويغفر لكم ذنوبكم والله غفور رحيم { [سورة آل عمران: 31].

« Sọ pe: Ti ẹyin ba jẹ ẹni ti o fẹran Ọlọhun, ẹ tẹle mi, Ọlọhun yoo fẹran yin, yoo si dari awọn ẹsẹ yin jin yin, Ọlọhun si ni Alaforijin, Alaanu » [Suuratu Aal-Imraan: 31]. Ati ọrọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” [t’o ni]:

(( لا يؤمن أحدكم حتى أكون أحب إليه من ولده ووالده والناس أجمعين )) [متفق عليه].

« Ẹnikan ninu yin kò ni i jẹ ẹni ti o gbagbọ lododo [ni igbagbọ t’o pe], titi ti n o fi jẹ pe emi l’o fẹran ju ọmọ rẹ, ati baba rẹ, ati gbogbo awọn eniyan lapapọ lọ » [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

Ẹkẹjọ ni: Titọrọ ikẹ ati ọla -Asalaatu ati Salama- fun Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati sise e lọpọlọpọ. Nitori naa dajudaju ahun ni ẹni ti a darukọ rẹ lọdọ rẹ ti kò se asalaatu fun un. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إن الله وملائكته يصلون على النبي يا أيها الذين آمنوا صلوا عليه وسلمـوا تسليماً { [سورة الأحزاب: 56].

« Dajudaju Ọlọhun ati awọn Malaika Rẹ ni wọn n fi ibukun fun Anabi. Ẹyin ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ maa tọrọ ibukun fun un, ki ẹ si maa ki i ni kiki ọla » [Suuratul-Ahzaab: 56]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( من صلى علي صلاَة صلى الله عليه بها عشراً )) [رواه مسلم].

« Ẹnikẹni ti o ba se asalaatu kan fun mi, Ọlọhun O tori rẹ se asalaatu mẹwa fun un » Muslim l’o gbe e jade.

Ati pe sise asalaatu -itọrọ ibukun- fun un naa a maa kanpa ni awọn aaye kan, ninu wọn ni: Ninu Ataaya ninu irun, ati ninu adua Qunuut, ati irun ti a n ki si oku lara, ati Khutuba Jima, ati lẹyin pipe irun, ati nigba ti a ba n wọ masalasi, ati jijade kuro ninu rẹ, ati ninu adua, ati nigba ti a ba darukọ Anabi naa, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati awọn mìíran ninu awọn aaye.

Ẹẹkẹsan ni pe: Dajudaju Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati awọn anabi yoku, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn”, abẹmi ni wọn ni ọdọ Oluwa wọn, ni isẹmi ti Barzakh -saare- ni isẹmi kan ti o pe ju, ti o si ga ju isẹmi awọn Shuhadaa’ -awọn ti wọn ku si ogun atigbe ẹsin ga- lọ, sugbọn ki i se bi isẹmi wọn lori ilẹ, isẹmi kan ti a kò mọ bawo l’o ti se ri ni, ti kò si le e mu orukọ iku kuro fun wọn. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” sọ pe:

(( إن الله حرم على الأرض أن تأكل أجساد الأنبياء )) [رواه أبو داود، والنسائي].

« Dajudaju Ọlọhun se e ni eewọ lori ilẹ pe ki o jẹ ara awọn anabi » [Abu Daa’uud l’o gbe e jade]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” tun sọ pe:

(( ما من أحد يسلم عليَّ إِلاَّ ردَّ الله عليَّ روحي حتى أردَّ عليه السلاَم )) [رواه أبو داود].

« Ẹnikan kò ni i salama si mi afi ki Ọlọhun O da ẹmi mi pada fun mi titi ti n o fi salama naa pada si i » [Abu-Daa’uud l’o gbe e jade].

Ẹẹkẹwa: Ninu ninifẹ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ni ki a ma se gbe ohùn soke ni ọdọ rẹ ni oju-aye rẹ, bakan naa nigba ti a ba n salama si i ninu saare rẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يا أيها الذين آمنوا لا ترفعوا أصواتكم فوق صوت النبي ولا تجهروا له بالقول كجهر بعضكم لبعض أن تحبط أعمالكم وأنتم لا تشعرون { [سورة الحجرات: 2].

« Ẹyin ẹni ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ ma se maa gbe ohùn yin ga bori ohùn Anabi mọlẹ, ẹ kò si gbọdọ maa kigbe ba a sọrọ gẹgẹ bi ikigbe sọrọ apa kan yin si apa keji, ki isẹ yin o ma baa bajẹ nigba ti ẹyin kò ni i fura » [Suuratul-Hujraat: 2,3].

Nitori naa apọnle Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, lẹyin ti a ti sin in da gẹgẹ bi apọnle rẹ ninu ọjọ aye rẹ, tori naa ọranyan ni ki a maa se apọnle rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, gẹgẹ bi awọn ẹni-akọkọ “ki Ọlọhun O yọnu si wọn” ti se, nigba ti wọn jẹ ẹni ti o lagbara ju ni didọgba pẹlu Anabi, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, ti wọn si jẹ ẹni ti o jinna ju ninu awọn eniyan si yiyapa si i, ati si sise adadaalẹ ohun ti kò si ninu ẹsin Ọlọhun.

Ẹkọkanla: Fifẹran awọn Sahaabe rẹ, ati awọn ara ile rẹ, ati awọn iyawo rẹ, ati sise ti wọn lapapọ, ati sisọra fun fifi abuku kan wọn, tabi bibu wọn, tabi bibu ẹnu-atẹ lu wọn pẹlu nnkan kan, tori pe dajudaju Ọlọhun ti yọnu si wọn, O si sa wọn lẹsa fun jijẹ ẹni Anabi Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati pe O se e ni ọranyan lori ijọ yii pe ki wọn o maa se ti wọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} والسابقون الأولون من المهاجرين والأنصار والذين اتبعوهم بإحسان رضي الله عنهم ورضوا عنه { [سورة التوبة: 100].

« Awọn ẹni ti o gba iwaju, awọn ẹni-akọkọ, ninu awọn ti o si kuro ni ilu -Makkah lọ si Madina- ati awọn alatilẹyin -awọn ara Madina- ati awọn ẹni ti o tẹle wọn pẹlu daadaa, Ọlọhun yọnu si wọn, awọn naa si yọnu si I » [Suuratut-Tawbah: 100].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( لا تسبوا أصحابي، فوالذي نفسي بيده، لو أنفق أحدكم مثل أحد ذهباً ما بلغ مد أحدهم ولا نصيفه )) [رواه البخاري].

« Ẹ ma bu awọn Sahaabe mi, mo fi Ẹni ti ẹmi mi wa lọwọ Rẹ bura pe: Ti o ba se pe ẹnikan yin na iru oke Uhud ni wura, ki ba ti de opin Mudù -abọ iwọnka- ẹnikan wọn, tabi idaji rẹ » [Bukhari l’o gbe e jade].

A si tọrọ pe ki awọn ti o de lẹyin wọn o maa tọrọ aforijin fun wọn, ki wọn o si maa bẹ Ọlọhun pe ki O ma fi keeta sinu awọn ọkan awọn lori wọn:

} والذين جاءوا من بعدهم يقولون ربنا اغفر لنا ولإخواننا الذين سبقونا بالإيمان ولا تجعل في قلوبنا غلاً للذين آمنوا ربنا إنك رءوف رحيم { [سورة الحشر: 10].

« Ati pe awọn ti wọn de lẹyin wọn, wọn a maa sọ pe: Oluwa wa, dari jin wa ati awọn ọmọ-iya wa ti wọn siwaju wa ninu igbagbọ-ododo, ma se jẹ ki adisọkan buburu wa ninu ọkan wa si awọn olugbagbọ-ododo, Oluwa wa, dajudaju Iwọ ni Alaanu, Onikẹ » [Suuratul-Hashr: 10].

Ekejila: Jijinna si itayọ-aalà nipa Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tori pe dajudaju eleyii wa ninu ininilara ti o tobi ju fun un “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, nigba ti o se pe Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” kilọ fun awọn ijọ rẹ nibi itayọ-aalà nipa rẹ, ati asereke ninu riroyin rẹ ati yiyin in, ati gbigbe e tayọ ipo rẹ, eyi ti Ọlọhun gbe e si, ninu ohun ti o jẹ adayanri fun Oluwa, t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn.

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( إنما أنا عبد، فقولوا عبد الله ورسوله، لا أحب أن ترفعوني فوق منـزلتي )).

« Ẹru nikan ni mo jẹ, nitori naa ẹ maa wi pe: Ẹru Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ, n kò fẹ pe ki ẹ gbe mi tayọ aaye mi ». O tun sọ pe:

(( لا تطروني كما أطرت النصارى ابن مريم )) أخرجاه.

« Ẹ ma se maa royin mi ni arofọ, gẹgẹ bi awọn alagbelebu -kiriyo- ti royin ọmọ Maryam -Jesu- larofọ » Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade. Kò si tọ pe ki a maa pe e, tabi ki a ke gbajare lọ si ọdọ rẹ, tabi ki a se irọkirika saare rẹ, tabi ki a se ileri tabi ki a duran fun un, isẹbọ si Ọlọhun ni gbogbo eleyii, Ọlọhun si ti kọ pe ki a sẹri ijọsin si ọdọ ẹlomiran yatọ si Oun.

Bakan naa ni ida keji, dajudaju ijade kuro ninu Islam, ati aigbagbọ ni aise apọnle Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, eyi ti n mu’ni mọ titabuku rẹ lara ẹni, tabi yiyọ alebu rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tabi mimu un ni bintin, tabi fifi i se yẹyẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} قل أبالله وآياته ورسوله كنتم تستهزءون. لا تعتذروا قد كفرتم بعد إيمانكم { [سورة التوبة: 65-66].

« Sọ pe: Sé Ọlọhun, ati awọn aayah Rẹ, ati Ojise Rẹ, ni ẹ fi n se yẹyẹ? Ẹ ma se wa awawi mọ, dajudaju ẹ ti se aigbagbọ lẹyin igbagbọ yin » [Suuratu t-Tawbah: 65-66].

Nitori naa ninifẹ ododo si Ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ni yoo mu’ni maa kọse imọna rẹ, ati titẹle ilana rẹ, ati fifi ohun ti o yapa si oju-ọna rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” silẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} قل إن كنتم تحبون الله فاتبعون يحببكم الله ويغفر لكم ذنوبكم والله غفور رحيم { [سورة آل عمران: 31].

« Sọ pe: Ti ẹyin ba jẹ ẹni ti o fẹran Ọlọhun, ẹ tẹle mi, Ọlọhun yoo fẹran yin, yoo si dari awọn ẹsẹ yin jin yin, Ọlọhun si ni Alaforijin, Alaanu » [Suuratu Aal-Imraan: 31].

Tori idi eleyii ọranyan ni aitayọ-aalà ati aififalẹ ninu sise agbega Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”. Nitori naa a kò gbọdọ fun un ni iroyin jijẹ ọlọhun, tabi ki a tabuku iyi rẹ ati iwọ rẹ ninu apọnle ati ifẹ, eyi ti o se pe ninu eyi ti o han ju ninu rẹ ni titẹle ofin rẹ, ati rinrin lori imọna rẹ, ati wiwo awokọse rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Ẹkẹtala: Nini igbagbọ si Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, kò le e rinlẹ afi pẹlu gbigba a lododo, ati sisisẹ pẹlu ohun ti o mu wa, ati pe eleyii ni itumọ igbafa fun un, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, nitori naa titẹle tiẹ ni titẹle ti Ọlọhun, bẹẹ ni sisẹ ẹ ni sisẹ Ọlọhun.

Ati pe pẹlu rinrinlẹ gbigba a lododo, ati titẹle e, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ni nini igbagbọ si i “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, yoo se rinlẹ.

###

 ORIGUN KARUN-UN: NINI IGBAGBỌ-ODODO SI ỌJỌ IKẸYIN

  

 [1] Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin:

Oun ni: Nini adisọkan pipari isẹmi ile-aye, ati wiwọ inu ile mìíran lẹyin rẹ, ti yoo bẹrẹ pẹlu iku, ati isẹmi Barzakh -saare- ti yoo si kọja gba ara dide akoko igbende, lẹyin naa gbigbe ẹda dide, ati akojọ, ati ẹsan, titi de ori ki awọn eniyan o wọ ọgba-idẹra -Al-Janna- tabi ina.

Ọkan ninu awọn origun igbagbọ-ododo ti o se pe igbagbọ eniyan kò le e pe afi pẹlu wọn ni nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba tako o, dajudaju o ti se aigbagbọ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولكن البر من آمن بالله واليوم الآخر { [سورة البقرة: 177].

« Sugbọn oluse-daadaa ni ẹni ti o gba Ọlọhun gbọ, ati ọjọ ikẹyin » [Qur’aani: 177].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( فأخبرني عن الإيمان؟ قال: أن تؤمن بالله، وملائكته، وكتبه، ورسله، واليوم الآخر، وتؤمن بالقدر خيره وشره )) [رواه مسلم].

« Nitori naa Fun mi ni iroyin nipa igbagbọ-ododo? Anabi dahun pe: Ki o gba Ọlọhun gbọ, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ki o si gba akọsilẹ -Kadara- gbọ, rere rẹ ati aburu rẹ » [Muslim l’o gbe e jade].

Ninu ohun ti o si jẹ ọranyan pe ki a ni igbagbọ-ododo si ni awọn ohun ti yoo siwaju ọjọ ikẹyin naa, ninu ohun ti Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, funni niro nipa rẹ, ninu ohun ti yoo sẹlẹ ninu awọn ami igbende ati awọn apẹẹrẹ rẹ.

Awọn oni-mimọ si ti pin awọn ami wọnyi si ọna meji:

(a) Kekere: Oun ni eyi ti n tọka si sisunmọ igbende, oun si pọ jọjọ, ati pe pupọ ninu rẹ, tabi eyi ti o pọju ninu rẹ l’o ti sẹlẹ.

Ninu rẹ si ni: Gbigbe Anabi wa, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” dide, ati sisọnu ifọkantanni, ati sise awọn masalasi lọsọ, ati sise fukẹ pẹlu rẹ, ati ki awọn darandaran o maa se idije kikọ ile giga, ati jija awọn Yahuudi -Ju- logun, ati pipa wọn, ati kikuru asiko, ati didinku isẹ, ati yiyọju awọn amiwo, ati pipọ pipa eniyan, ati pupọ agbere -Zina- ati iwa pokii.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} اقترب الساعة وانشق القمر { [سورة القمر: 1].

« Asiko naa ti sunmọ tan, osupa si ti la [si meji] » [Suuratul-Qamar: 1].

(b) Ninla: Oun ni eyi ti yoo sẹlẹ siwaju ki igbende o too de, ti yoo si maa se itaniji nipa bibẹrẹ sisẹlẹ rẹ, awọn ami mẹwa si ni i, ati pe nnkan kan ninu wọn kò i ti sẹlẹ.

Ati pe ninu wọn ni: Jijade Mahdii, ati jijade Dajjaal -opurọ- ati sisọkalẹ Anabi Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, lati sanma ni adajọ, oluse-deedee, tori naa yoo fọ agbelebu, yoo si pa Dajjaal -opurọ- ati ẹlẹdẹ, yoo si fi owo-ori ti keferi maa n san lọlẹ, yoo si maa se idajọ pẹlu ofin Sharia Islam, Ya’ajuuj ati Ma’ajuuj yoo si yọju, yoo si bẹ Ọlọhun le wọn lori, wọn yoo si ku, ati riri ilẹ mẹta, riri ilẹ kan ni ibula oorun, ati riri ilẹ kan ni erekusu Larubawa, ati eefin, oun ni jijade eefin nla kan lati sanma, ti yoo bo awọn eniyan, ti yoo si yi wọn po, ati gbigbe Al-Qur’aan kuro nilẹ lọ si sanma, ati yiyọ oorun lati ibuwọ rẹ, ati jijade ẹranko [kan lati inu ilẹ], ati jijade ina nla kan lati ilu Adan [ni Yamen], ti yoo maa da awọn eniyan lọ si ilẹ Shaam [Syria ati agbegbe rẹ], oun si ni opin awọn ami nla naa.

Muslim gbe ẹgbawa-ọrọ jade lati ọdọ Hudzaifah ọmọ Usaid Al-Gifaari, “ki Ọlọhun O yọnu si i”, o ni:

(( اطلع النبي ﷺ‬، ونحن نتذاكر فقال: (( ما تذكرون؟ قالوا: نذكر الساعة. قال: إنها لن تقوم حتى تروا قبلها عشر آيات. فذكر: الدخان، والدجال، والدابة، وطلوع الشمس من مغربها، ونزول عيسى بن مريم، ويأجوج، وثلاثة خسوف: خسف بالمشرق، وخسف بالمغرب، وخسف بجزيرة العرب، وآخر ذلك نار تخرج من اليمن، تطرد الناس إلى محشرهم )) [رواه مسلم].

« Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” yọ -si wa- nigba ti awa n se iranra-ẹni leti, n l’o ba sọ pe: « Ki ni ohun ti ẹ n se iranti? Wọn ni: A n se iranti igbende. Anabi sọ pe: Dajudaju kò ni i dide titi ti ẹ o fi ri awọn ami mẹwa siwaju rẹ. N l’o ba darukọ: Eefin, ati Dajjaal -opurọ- ati ẹranko, ati yiyọ oorun lati ibuwọ rẹ, ati sisọkalẹ Isa -Jesu- ọmọ Maryam, ati Ya’ajuuj, ati riri ilẹ mẹta: Riri ilẹ kan ni ibuyọ oorun, ati riri ilẹ kan ni ibuwọ rẹ, ati riri ilẹ kan ni erekusu Larubawa, opin eleyii si ni ina kan ti yoo jade lati Yaman, ti yoo maa le awọn eniyan lọ si ibupejọ wọn » [Muslim l’o gbe e jade].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( يخرج في آخر أمتي المهدي، يسقيه الله الغيث، وتخرج الأرض نباتها، ويعطي المال صحاحاً، وتكثر الماشية، وتعظم الأمة، ويعيش سبعاً، أو ثمانياً، يعني حججاً )) [رواه الحاكم في المستدرك].

« Al-Mahdii yoo jade laarin opin awọn ijọ mi, Ọlọhun yoo fun un ni omi ojo mu, ilẹ yoo si mu irugbin rẹ jade, yoo si maa fi owo gidi tọrẹ, awọn nnkan-ọsin yoo si pọ, ijọ naa yoo si ga, yoo sẹmi fun meje, tabi fun mẹjọ, itumọ ni pe: Fun ọdun » [Al-Haakim l’o gbe e jade ninu Al-Mustadrak].

Ati pe ẹri ti wa lori pe dajudaju ohun ti yoo tẹlera wọn ni awọn ami wọnyi, gẹgẹ bi sinsin jọ ilẹkẹ ninu okun rẹ. Nitori naa ti ọkan ninu wọn ba ti yọju ni omiran yoo tẹle e, ti awọn ami wọnyi ba si ti tan ni opin aye yoo de, pẹlu iyọnda Ọlọhun t’O ga.

Ohun ti a si gba lero pẹlu akoko naa ni: Ọjọ kan ti awọn eniyan yoo jade lati inu awọn saare wọn, pẹlu asẹ Oluwa wọn, ki a le baa se isiro fun wọn, ki a wa se idẹra fun oluse-daadaa ninu wọn, ki a si jẹ alaidaa wọn niya. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يوم يخرجون من الأجداث سراعاً كأنهم إلى نصب يوفضون { [سورة المعارج: 43].

« Ọjọ ti wọn yoo jade lati inu awọn saare ni were-were, wọn yoo dabi ẹni pe wọn n yara lọ sidi asia kan ti a kan mọlẹ » [Suuratul-Ma’aarij: 43]. A si sọ nipa ọjọ yii ninu Al-Qur’aan pẹlu orukọ ti o pọ ju ẹyọ kan lọ.

Ninu wọn ni: Yawmul-Qiyaamah: Ọjọ igbende, Al-Qaari’ah: Ẹru akan-ni-laya, Yawmul-Hisaab: Ọjọ isiro, Yawmud-Diin: Ọjọ ẹsan, At-Taammaah: Iparun, Al-Waaqi’ah: Isẹlẹ, Al-Haaqqah: Ododo ti o daju, As-Saakh-khah: Ijagbe, Al-Gaashiyah: Ohun ti i maa n bo ni mọlẹ, ati ohun ti o yatọ si eleyii.

Yawmul-Qiyaamah: Ọjọ igbende: Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} لا أقسم بيوم القيامة { [سورة القيامة: 1].

« Mo fi ọjọ igbende bura » [Suuratul-Qiyaamah: 1].

Al-Qaari’ah: Ẹru akan-ni-laya: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} القارعة. ما القارعة { [سورة القارعة: 1-2].

« Ẹru akan-ni-laya. Ki ni ẹru akan-ni-laya naa? » [Suuratul-Qaari’ah: 1-2].

Yawmul-Hisaab: Ọjọ isiro: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} إن الذين يضلون عن سبيل الله لهم عذاب شديد بما نسوا يوم الحساب { [سورة ص: 26].

« Dajudaju awọn ti wọn sọnu kuro ni oju-ọna Ọlọhun, iya ti o le wa fun wọn, nitori gbigbagbe ti wọn gbagbe ọjọ isiro » [Suuratu: Saad: 26].

Yawmud-Diin: Ọjọ ẹsan: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} وإن الفجار لفي جحيم. يصلونها يوم الدين { [سورة الانفطار: 14-15].

« Dajudaju awọn oniwa-buburu, dajudaju wọn yoo wa ninu ina ti n jo. Wọn yoo wọ inu rẹ ni ọjọ ẹsan » [Suuratul-Infitaar: 14-15].

At-Taammaah: Iparun: Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} فإذا جاءت الطامة الكبرى { [سورة النازعات: 34].

« Nigba ti iparun ti o ninla ju naa ba de » [Suuratun-Naazi’aat: 34].

Al-Waaqi’ah: Isẹlẹ: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} إذا وقعت الواقعة { [سورة الواقعة: 1].

« Nigba ti isẹlẹ naa ba sẹlẹ » [Suuratul-Waaqi’ah: 1].

Al-Haaqqaah: Ododo ti o daju: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} الحاقة. ما الحاقة { [سورة الحاقة: 1-2].

« Ododo ti o daju naa. Ki tilẹ ni ododo ti o daju naa? » [Suuratul-Haaqqah: 1-2].

As-Saakh-khah: Ijagbe: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} فإذا جاءت الصاخة { [سورة عبس: 33].

« Nigba ti ijagbe naa ba de » [Suuratu Abasa: 33].

Al-Gaashiyah: Ohun ti i maa n bo ni mọlẹ: Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} هل أتاك حديث الغاشية { [سورة الغاشية: 1].

« Njẹ ọrọ nipa ohun ti i bo eniyan mọlẹ daru ti wa ba ọ bi? » [Suuratul-Gaashiyah: 1].

 [2] Bi a o ti ni igbagbọ si ọjọ ikẹyin:

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin jẹ akopọ ati ẹfọsiwẹwẹ:

Ti akopọ ni: Ki a gbagbọ pe dajudaju ọjọ kan n bẹ ti Ọlọhun yoo ko awọn ẹni-akọkọ ati awọn ẹni-ikẹyin jọ ninu rẹ, ti yoo si san onikaluku ni ẹsan pẹlu isẹ rẹ, apa kan yoo wa ninu ọgba-idẹra -Al-Janna- apa kan yoo si wa ninu ina elejo. Ọlọhun t’O ga, sọ pe:

} قل إن الأولين والآخرين. لمجموعون إلى ميقات يوم معلوم { [سورة الواقعة: 49-50].

« Sọ pe: Dajudaju awọn ẹni-akọkọ ati ero-ikẹyin. Dajudaju ẹni ti a o kojọ ni wọn fun asiko ọjọ ti a mọ » [Suuratul-Waaqi’ah: 49-50].

Ti ẹfọsiwẹwẹ si ni: Nini igbagbọ si ẹfọsiwẹwẹ ohun ti yoo sẹlẹ lẹyin iku, eleyii si kari awọn nnkan kan, [ti o se pe] ninu wọn ni:

Alakọkọ: Idanwo saare:

Oun ni bibi oku leere lẹyin ti a ti sin in nipa Oluwa rẹ, ati ẹsin rẹ, ati anabi rẹ Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”. Nitori naa Ọlọhun yoo maa fi awọn ẹni ti wọn gbagbọ lododo rinlẹ pẹlu ọrọ ti o rinlẹ; gẹgẹ bi o ti se wa ninu ẹgbawa-ọrọ, pe nigba ti wọn ba bi i leere yoo maa dahun pe:

(( ربي الله، وديني الإسلام، ونبي محمد ﷺ‬ )) [متفق عليه].

« Ọlọhun ni Oluwa mi, Islam ni ẹsin mi, Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ni anabi mi » [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

Nitori naa ọranyan ni nini igbagbọ si ohun ti awọn ẹgbawa-ọrọ tọka si ninu ibeere awọn Malaika meji naa, ati bi wọn yoo ti se eleyii, ati ohun ti olugbagbọ-ododo yoo fi fọ esi, ati ohun ti olujodijẹsọ yoo fi dahun.

Ẹlẹẹkeji: Iya saare ati idẹra rẹ:

Ọranyan ni nini igbagbọ si iya saare ati idẹra rẹ, dajudaju o le jẹ koto kan ninu awọn koto ina, tabi abata tútù kan ninu awọn abata tútù ọgba-idẹra, saare naa si ni akọkọ awọn ibusọ ọrun. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba la ninu rẹ, ohun ti o wa lẹyin rẹ yoo rọrun ju u lọ [fun un], sugbọn ẹni ti kò ba la, ohun ti yoo wa lẹyin rẹ yoo le ju u lọ [fun un], ati pe gbogbo ẹni ti o ba ti ku, igbende tiẹ ti bẹrẹ.

Nitori naa idẹra ati iya yoo maa sẹlẹ si ẹmi ati ara lapapọ ninu saare, o si see se ki ẹmi o da ri eleyii nigba kan, ati pe awọn alabosi ni iya rẹ wa fun, idẹra rẹ si wa fun awọn olugbagbọ-ododo, awọn olotitọ.

A o si maa fi iya jẹ oku lẹyin iku, tabi ki a maa se idẹra fun un, yala a sin in, tabi a kò sin in. Tori naa a o baa sun un nina, tabi ki o tẹri [si odo], tabi ki awọn ẹranko, tabi awọn ẹyẹ o jẹ ẹ, dandan ni ki ipin rẹ ninu iya tabi idẹra naa o ba a.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} النار يعرضون عليها غدوا وعشيا ويوم تقوم الساعة أدخلوا آل فرعون أشد العذاب { [سورة غافر: 46].

« Ina naa ni a o maa sẹ wọn lori lọ si ọdọ rẹ ni owurọ ati ni asaalẹ, ati pe ọjọ ti akoko -igbende- naa yoo ba de, [wọn o sọ pe]: Ẹ fi awọn eniyan Fir’auna sinu eyi ti o le ju ni iya » [Suuratu Gaafir: 46].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

(( فلولا أن لا تدافنوا لدعوت الله أن يسمعكم من عذاب القبر )) [رواه مسلم].

« Ti ki i ba se ki ẹ ma fi sinsin ara yin silẹ ni, dajudaju n o ba bẹ Ọlọhun pe ki O mu yin gbọ ninu iya saare » [Muslim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkẹta: Fifẹ atẹgun si inu As-Suur -iwo-:

As-Suur ni iwo kan ti Israafiil “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”, yoo fẹ atẹgun si, tori naa yoo fọn fifọn alakọkọ, n ni gbogbo awọn ẹda yoo ba ku afi ẹni ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ni yoo fọn fifọn keji, n ni a o ba gbe awọn ẹda dide lapapọ, lati igba ti Ọlọhun ti da ile-aye titi di igbende.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ونفخ في الصور فصعق من في السماوات ومن في الأرض إلا من شاء الله ثم نفخ فيه أخرى فإذا هم قيام ينظرون { [سورة الزمر: 68].

« Ati pe a o fọn iwo, awọn ti wọn wa ninu awọn sanma ati awọn ti wọn wa ni ori ilẹ yoo si daku, afi ẹni ti Ọlọhun ba fẹ. Lẹyin naa ni a o tun fọn ọn ni ida mìíran, n ni wọn yoo ba dide ti wọn o si maa wo sun un » [Suuratuz-Zumar: 68].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

(( ثم ينفخ في الصور فلا يسمعه أحد إلا أصغى ليتاً ورفع ليتاً، ثم لا يبقى أحد إلا صعق، ثم ينـزل الله مطراً كأنه الطل، فتنبت منه أجساد الناس، ثم ينفخ فيه أخرى فإذا هم قيام ينظرون )) [رواه مسلم].

« Lẹyin naa ni a o fẹ atẹgun sinu iwo naa, ẹnikan kò si ni i gbọ afi ki o tẹ abala ọrun kan, ki o si gbe abala ọrun kan soke, lẹyin naa kò ni i sẹku ẹnikan afi ki o daku, lẹyin naa ni Ọlọhun O sọ ojo kan kalẹ, ti yoo dabi ọwiniwini, nitori naa ara awọn eniyan yoo ti ara rẹ hu, lẹyin naa ni a o tun fẹ atẹgun mìíran si i, n ni wọn yoo ba dide ti wọn o si maa wo sun un » [Muslim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkẹrin: Igbende:

Oun ni jiji ti Ọlọhun yoo ji awọn oku nigba ti a o fọn iwo ni fifọn keji, n ni awọn eniyan yoo ba dide fun Oluwa gbogbo ẹda, tori naa nigba ti Ọlọhun ba yọnda fifọn keji, ati pipada awọn ẹmi si awọn ara wọn, nigba yii ni awọn eniyan yoo dide lati inu awọn saare wọn, ti wọn yoo si maa rin ni were-were lọ si ibuduro ni ẹsẹ-fifo, lai kò bọ bata, ni ihoho, lai kò wọ ẹwu, pẹlu atọtọ, lai kò kọla, ti ara wọn da, lai kò si nnkan kan -ninu alebu ara- pẹlu wọn, ati pe iduro naa yoo gun, oorun yoo si sun mọ wọn, a o si se alekun igbona rẹ, oogun yoo si bo wọn de ẹnu, fun lile iduro naa, tori naa o n bẹ ninu wọn ẹni ti oogun yoo de kokosẹ rẹ mejeeji, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti oogun yoo de orukun rẹ mejeeji, ati pe o n bẹ ninu wọn ẹni ti oogun yoo de bèbèré idi rẹ mejeeji, bẹẹ ni o wa ninu wọn ẹni ti yoo de omu rẹ mejeeji, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti yoo de ejika rẹ mejeeji, ati pe o wa ninu wọn ẹni ti oogun naa yoo mu un de ẹnu ni mimu tan, bẹẹ ni gbogbo eleyii yoo wa ni ibamu pẹlu awọn isẹ wọn.

Otitọ ti o rinlẹ ni igbende, ofin -Sharia- ati ifuramọ ati laakaye tọka si i:

Ofin Sharia: Awọn aayah pọ ninu Tira Ọlọhun, ati awọn ọrọ ti o gun rege ninu Sunna -ilana- Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ti wọn n tọka si rinrinlẹ rẹ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} قل بلى وربي لتبعثنّ { [سورة التغابن الآية: 7].

« Sọ pe: Bẹẹ ni, Oluwa mi ni mo fi bura, dajudaju a o gbe yin dide » [Suuratut-Tagaabun: 7]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} كما بدأنا أول خلق نعيده { [سورة الأنبياء: 104].

« Gẹgẹ bi A ti se bẹrẹ ẹda ni akọkọ ni A O da a pa si » [Suuratul-Anbiyaa’: 104].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( ثم ينفخ في الصور فلا يسمعه أحد إلا أصغى ليتاً ورفع ليتاً، ثم لا يبقى أحد إلا صعق، ثم ينـزل الله مطراً كأنه الطل، فتنبت منه أجساد الناس، ثم ينفخ فيه أخرى فإذا هم قيام ينظرون )) [رواه مسلم].

« Lẹyin naa ni a o fẹ atẹgun sinu iho naa, ẹnikan kò si ni i gbọ afi ki o tẹ abala ọrun kan, ki o si gbe abala ọrun kan soke, lẹyin naa kò ni i sẹku ẹnikan afi ki o daku, lẹyin naa ni Ọlọhun O sọ ojo kan kalẹ, ti yoo dabi ọwiniwini, nitori naa ara awọn eniyan yoo ti ara rẹ hu, lẹyin naa ni a o tun fẹ atẹgun mìíran si i, n ni wọn yoo ba dide ti wọn o si maa wo sun un » [Muslim l’o gbe e jade].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} قال من يحيي العظام وهي رميم. قل يحييها الذي أنشأها أول مرة وهو بكل خلق عليم { [سورة يس: 78، 79].

« O sọ pe: Ta ni yoo ji egungun ti o ti kẹfun? Sọ pe: Ẹni ti O se ẹda rẹ ni igba akọkọ ni yoo ji i, Oun si ni Oni-mimọ nipa gbogbo ẹda » [Suuratu Yaasin: 78, 79].

Ohun ifuramọ: Dajudaju Ọlọhun ti fi jiji awọn oku ni ile-aye han awọn ẹru Rẹ, apejuwe marun-un wa ninu Suuratul-Baqarah lori eleyii, awọn ni ti awọn eniyan Muusa, awọn ẹni ti Ọlọhun ji wọn lẹyin mimu wọn ku, ati ẹni ti awọn Isrẹli pa, ati awọn eniyan ti wọn jade ni ile wọn, ni sisa fun iku, ati ẹni ti o gba ilu kan kọja, ati ẹyẹ Anabi Ibraahiim, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a”.

Sugbọn laakaye: Ọna meji ni a o gba fi i se ẹri:

(a) Wi pe dajudaju Ọlọhun t’O ga se ipilẹ sẹda awọn sanma ati ilẹ, ati ohun ti o wa ninu mejeeji, O da mejeeji ni ibẹrẹ, bẹẹ ni Alagbara lori ibẹrẹ sise ẹda kò ni i kagara lati da a pada.

(b) Wi pe ilẹ a maa jẹ oku ti o gbẹ, ti kò si ẹmi kankan ni ara rẹ, n ni Ọlọhun O ba rọ ojo le e lori, n ni yoo ba ruwe ni abẹmi, ti gbogbo awọn orisirisi irugbin ti o dara yoo wa ninu rẹ, tori naa Alagbara lori atimu un sẹmi lẹyin iku rẹ ni Alagbara lori atiji awọn oku.

Ẹlẹẹkarun-un: Akojọ ati isiro ati ẹsan:

A ni igbagbọ si kiko awọn ara jọ, ati sise ibeere lọdọ wọn, ati gbigbe sise deedee dide laarin wọn, ati sisan awọn ẹda ni ẹsan lori awọn isẹ wọn. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وحشرناهم فلم نغادر منهم أحداً { [سورة الكهف: 47].

« Awa yoo si ko wọn jọ, A kò si ni fi ẹnikan silẹ ninu wọn » [Suuratul-Kahf: 47].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} فأما من أوتي كتابه بيمينه فيقول هاؤم اقرأوا كتابيه. إني ظننت أني ملاق حسابيه. فهو في عيشة راضية { [سورة الحاقة: 19-21].

« Nitori naa ẹni ti a ba fun ni iwe tiẹ ni ọwọ-ọtun rẹ, yoo sọ pe: Ẹ gba, ẹ ka tira mi. Dajudaju emi ti mọ amọdaju pe emi o se abapade isiro [isẹ] mi. Nitori naa oun yoo wa ninu isẹmi ti a yọnu si » [Suuratul-Haaqqaah: 19-21]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} وأما من أوتي كتابه بشماله فيقول يا ليتني لم أوت كتابيه. ولم أدر ما حسابيه { [سورة الحاقة: 25-26].

« Sugbọn ẹni ti a ba fun ni iwe tiẹ ni ọwọ-osi rẹ, yoo sọ pe: Ègbé mi o, iba se pe a kò fun mi ni iwe mi [rara]!. Ki n si ma mọ ohun ti isiro isẹ mi jẹ » [Suuratul-Haaqqaah: 25-26].

Akojọ naa ni dida awọn eniyan lọ, ati kiko wọn jọ si ibuduro fun isiro [isẹ] wọn, iyatọ ti i si n bẹ laarin rẹ ati igbende ni pe: igbende ni dida awọn ẹmi pada si awọn ara, akojọ si ni dida awọn ti a gbe dide wọnyi lọ, ati kiko wọn jọ si ibuduro.

Ati isiro ati ẹsan: Oun ni Ki Ọba Otitọ -ibukun ati giga ni fun Un- O da awọn ẹru Rẹ duro ni iwaju Rẹ, ki O si fi awọn isẹ wọn ti wọn se mọ wọn, isiro awọn olugbagbọ-ododo, awọn olupaya Ọlọhun yoo si jẹ pẹlu sise afihan awọn isẹ wọn fun wọn, titi ti wọn yoo fi mọ idẹra Ọlọhun lori wọn, nipa bibo o ti O bo o fun wọn ni ile-aye, ati nipa amojukuro Rẹ fun wọn ni ọrun, a o si ko wọn jọ lori odiwọn igbagbọ wọn, awọn Malaika yoo maa pade wọn, wọn yoo si maa fun wọn ni iro idunnu pẹlu ọgba-idẹra -Al-Janna- wọn yoo si maa fun wọn ni ibalẹ-ọkan nipa ibẹru ati ifoya ọjọ ti o soro yii, nitori naa oju wọn yoo funfun, yoo si mọlẹ ni ọjọ naa, yoo si maa rẹrin-in pẹlu idunnu.

Sugbọn awọn olupe ọrọ Ọlọhun nirọ, awọn olutapa [si i], a o se isiro ti o le, ti o si wẹ fun wọn lori gbogbo ẹsẹ kekere ati titobi, ati pe a o wọ wọn gba oju wọn, ni ti yiyẹpẹrẹ wọn, o si jẹ ẹsan ohun ti ọwọ wọn ti ti siwaju, ati nitori ohun ti wọn n pa niro.

Akọkọ ẹni ti a o si se isiro fun ni ọjọ igbende ni ijọ Anabi wa, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, awọn eniyan ẹgbẹrun lọna aadọrin [70,000] kan yoo si n bẹ pẹlu wọn, ti wọn yoo wọ ọgba-idẹra -Al-Janna- lai kò se isiro kan [fun wọn], lai kò si jẹ iya kan pẹlu, nitori pipe At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni àáso ninu ijọsin- wọn; awọn si ni awọn ẹni ti Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, royin wọn pẹlu ọrọ rẹ [t’o ni]:

(( لا يسترقون، ولا يكتوون، ولا يتطيرون، وعلى ربهم يتوكلون )).

« Wọn ki i tọrọ pe ki a se Ar-Ruqyah -adua iwa-isọ- fun awọn, bẹẹ ni wọn ki i tọrọ pe ki a ba awọn jo apa tabi egbo awọn, wọn kò si ni igbagbọ si wi pe riri ẹyẹ kan [tabi nnkan mìíran] a maa ko ibi bayan, ati pe Oluwa wọn nikan ni wọn ba duro », ninu wọn si ni Sahaabe ẹni-ọwọ, Ukkaashah ọmọ Mihsan, “ki Ọlọhun O yọnu si i”.

Akọkọ ohun ti a o si se isiro fun eniyan lori rẹ ninu awọn iwọ Ọlọhun t’O ga ni irun, bẹẹ ni akọkọ ohun ti a o se isiro nipa rẹ laarin awọn eniyan ninu awọn ẹtọ ni awọn ẹjẹ.

Ẹlẹẹkẹfa: Àbatà:

A ni igbagbọ si àbatà Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati pe àbatà nla kan ni i, bẹẹ ibumu alapọnle ni i, orisun rẹ ni awọn ohun mimu ọgba-idẹra -Al-Janna- lati ara odo Al-Kawthar ni gbagede igbende, awọn olugbagbọ-ododo ninu ijọ Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, yoo mu ninu rẹ.

Ninu iroyin rẹ si ni pe: O funfun ju wara lọ, o si tutu ju yinyin lọ, ati pe o dun ju oyin lọ, bẹẹ ni o dara ni oorun ju Al-Misk lọ, oun si wa ninu fifẹ de opin, ibu ati ooro rẹ dọgba, ati pe irin osu kan ni gbogbo origun kọọkan ninu awọn origun rẹ, bẹẹ ni ọsọọrọ meji l’o wa lara rẹ, mejeeji n fun un ni omi lati ọgba-idẹra, ati pe awọn igba rẹ pọ ju awọn irawọ oju sanma lọ, ẹnikẹni ti o ba si mu nnkan kan ninu rẹ, ongbẹ kò ni i gbẹ ẹ lẹyin rẹ laelae.

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( حوضي مسيرة شهر، ماؤه أبيض من اللبن، وريحه أطيب من المسك، وكيزانه كنجوم السماء، من شرب منه فلا يظمأ أبداً )) [رواه البخاري].

« Irin osun kan ni àbatà mi, omi rẹ funfun ju wara lọ, oorun rẹ si dara ju Al-Misk lọ, ati pe awọn ife rẹ [ni onka] da gẹgẹ bi [onka] awọn irawọ oju sanma, ẹnikẹni ti o ba mu ninu rẹ, ongbẹ kò ni i gbẹ ẹ laelae» [Bukhari l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkeje: Ipẹ:

Nigba ti adanwo ba le koko fun awọn eniyan ni ibuduro nla, ti iduro wọn si gun, wọn yoo gbiyanju fun atisipẹ fun wọn ni ọdọ Oluwa wọn, lati gba wọn la ninu ipọnju ibuduro naa ati ifoya rẹ, nitori naa awọn oni-ipinnu-ọkan ninu awọn ojisẹ yoo yago fun un, titi ti ọrọ naa yoo fi de ọdọ opin awọn ojisẹ naa, Anabi wa, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ẹni ti Ọlọhun ti se aforijin ohun ti o siwaju ninu ẹsẹ rẹ fun un ati ohun ti o gbẹyin, n ni yoo ba duro ni ibuduro kan, ti awọn ẹni-akọkọ ati awọn ẹni-ikẹyin yoo maa yin in lori rẹ, aaye rẹ ninla ati ipo rẹ giga yoo si han pẹlu rẹ, n ni yoo ba fi ori kanlẹ ni abẹ aga-ọla Ọlọhun, n ni Ọlọhun yoo ba nu un ni awọn ohun ise-ẹyin ti yoo fi se ẹyin fun Un, ti yoo si fi se agbega fun Un, yoo si tọrọ iyọnda lọdọ Oluwa rẹ, n ni yoo ba yọnda fun un pe ki o sipẹ fun awọn ẹda, ki a le se isiro laarin awọn ẹda lẹyin ohun ti o ti se wọn ninu idaamu ati ipọnju ohun ti wọn kò lagbara [rẹ].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( إن الشمس تدنو يوم القيامة، حتى يبلغ العرق نصف الأذن، فبينما هم كذلك، استغاثوا بآدم، ثم بإبراهيم، ثم بموسى، ثم بعيسى، ثم بمحمد ﷺ‬، فيشفع ليقضى بين الخلق، فيمشي حتى يأخذ بحلقة الباب، فيومئذ يبعثه الله مقاماً محموداً يحمده أهل الجمع كلهم )) [رواه البخاري].

« Dajudaju oorun yoo sunmọ ni ọjọ igbende, titi ti oogun yoo fi [muyan] de opin idaji eti. Laarin igba ti awọn eniyan wa bayii, wọn yoo fi Anabi Aadama wa iranlọwọ, lẹyin naa Anabi Ibraahiim, lẹyin naa Anabi Muusa, lẹyin naa Anabi Isa, lẹyin naa Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, n ni yoo ba sipẹ ki a le baa se idajọ laarin awọn ẹda, n ni yoo ba rin lọ titi ti yoo fi di oruka ilẹkun naa mu. Nitori naa, ni ọjọ yii Ọlọhun yoo gbe e dide ni aaye ẹyin kan ti awọn ara ibuduro naa ni apapọ wọn yoo ti maa yin in » [Bukhari l’o gbe e jade].

Ọlọhun si se isipẹ ti o tobi ju yii ni adayanrin fun Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ati pe awọn isipẹ mìíran tun rinlẹ fun un, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”. Awọn ni:

1- Isipẹ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, fun awọn ọmọ ọgba-idẹra -Al-Janna- pe ki a yọnda fun wọn lati wọ ọgba-idẹra naa. Ẹri rẹ ni ọrọ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, [t’o ni]:

(( آتي باب الجنة يوم القيامة، فأستفتح، فيقول الخازن: من أنت؟ قال: فأقول: محمد، فيقول: بك أمرت، لا أفتح لأحد قبلك )) [رواه مسلم].

« N o wa si [ibi] ilẹkun ọgba-idẹra -Al-Janna- ni ọjọ igbende, n o si tọrọ sisi [rẹ], n ni Al-Khaazin -Malaika ti n sọ ọ- yoo ba sọ pe: Ta ni ọ? O sọ pe: N ni n o ba wi pe: Muhammad, n ni yoo ba sọ pe: Iwọ ni a fi pa mi lasẹ, n kò gbọdọ si i fun ẹnikan siwaju rẹ » [Muslim l’o gbe e jade].

2- Isipẹ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, fun awọn eniyan kan ti daadaa wọn ati aidaa wọn dọgba, yoo sipẹ fun wọn lati wọ ọgba-idẹra -Al-Janna- apa kan ninu awọn oni-mimọ l’o wi eleyii, sugbọn kò si ẹgbawa-ọrọ ti o gun rege kan nipa rẹ lati ọdọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tabi lati ọdọ ẹlomiran.

3- Isipẹ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, fun awọn eniyan kan ti wọn lẹtọ si ina pe ki wọn o ma wọ ọ, ẹri rẹ ni apapọ ọrọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, [t’o ni]:

(( شفاعتي لأهل الكبائر من أمتي )) [رواه أبو داود].

« Isipẹ mi jẹ ti awọn ẹlẹsẹ-nlanla ninu awọn ijọ mi » [Abu Daa’uud l’o gbe e jade].

4- Isipẹ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, nipa sise agbega ipo awọn ọmọ ọgba-idẹra -Al-Janna- ninu ọgba-idẹra naa. Ẹri rẹ ni ọrọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, [t’o ni]:

(( اللهم اغفر لأبي سلمة، وارفع درجته في المهديين )) [رواه مسلم].

« Iwọ Ọlọhun, dari jin Baba Salamah, si se agbega ipo rẹ ninu awọn ẹni ti a fi mọna » [Muslim l’o gbe e jade].

5- Isipẹ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, fun awọn eniyan kan ti wọn yoo wọ ọgba-idẹra -Al-Janna- lai kò se isiro kan, lai kò si jẹ iya kan. Ẹri rẹ ni: Ẹgbawa-ọrọ Ukkaashah ọmọ Mihsan nipa awọn ẹgbẹrun lọna aadọrin, awọn ẹni ti wọn yoo wọ ọgba-idẹra -Al-Janna- lai kò si isiro kan, lai kò si jẹ iya kan; n ni Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ba tọrọ fun un pẹlu ọrọ rẹ pe:

(( اللهم اجعله منهم )) [متفق عليه].

« Iwọ Ọlọhun, se e [ni ọkan] ninu wọn » [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

6- Isipẹ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, fun awọn ẹlẹsẹ-nlanla ninu awọn ijọ rẹ, ninu awọn ti wọn wọ ina, pe ki wọn o jade kuro ninu rẹ. Ẹri rẹ ni ọrọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”:

(( شفاعتي لأهل الكبائر من أمتي )) [رواه أبو داود].

« Isipẹ mi jẹ ti awọn ẹlẹsẹ-nlanla ninu awọn ijọ mi » [Abu Daa’uud l’o gbe e jade]. Ati ọrọ rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, [t’o ni]:

(( يخرج قوم من النار بشفاعة محمد ﷺ‬، فيدخلون الجنة، يسمون الجهنميين )) [رواه البخاري].

« Awọn eniyan kan yoo jade kuro ninu ina pẹlu isipẹ Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, nitori naa wọn yoo wọ ọgba-idẹra -Al-Janna- a o si maa pe wọn ni awọn ero [ina] Jahannama » [Bukhari l’o gbe e jade].

7- Isipẹ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, fun fifuyẹ iya lori ẹni ti o lẹtọ si i, gẹgẹ bi isipẹ rẹ fun ọmọ-iya baba rẹ lọkunrin: Abu Taalib. Ẹri rẹ ni ọrọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” [t’o ni]:

(( لعله تنفعه شفاعتي يوم القيامة، فيجعل في ضحضاح من النار، يبلغ كعبيه، يغلي منه دماغه )) [متفق عليه].

« Bọya isipẹ mi yoo se e ni anfaani ni ọjọ igbende, ki a wa fi i si inu eyi ti o relẹ ninu ina, ti yoo de opin kokosẹ rẹ mejeeji, ti ọpọlọ rẹ yoo maa ho latari rẹ » [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

Ati pe isipẹ kò le e dara ni ọdọ Ọlọhun afi pẹlu awọn mẹjẹmu meji kan:

a- Iyọnu Ọlọhun si olusipẹ ati ẹni ti a n sipẹ fun.

b- Iyọnda Ọlọhun t’O ga fun olusipẹ pe ki o sipẹ.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ولا يشفعون إلا لمن ارتضى { [سورة الأنبياء: 28].

« Ati pe wọn kò le e sipẹ afi fun ẹni ti O ba yọnu si » [Suuratul-Anbiyaa’: 28].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} من ذا الذي يشفع عنده إلا بإذنه { [سورة البقرة: 255].

« Ẹnikan kò ni i le sipẹ ni ọdọ Rẹ, afi pẹlu iyọnda Rẹ » [Suuratul-Baqarah: 255].

Ẹlẹẹkẹjọ: Osunwọn:

Ododo ni osunwọn, ọranyan ni ki a gba a gbọ, oun si ni ohun ti Ọlọhun yoo fi lelẹ ni ọjọ igbende fun wiwọn awọn isẹ awọn ẹda, ati ki O le san wọn lẹsan lori awọn isẹ wọn, osunwọn kan ti o si se fi oju ri ni i, o ni ọwọ meji ati ahọn, a o fi wọn awọn isẹ, tabi awọn iwe isẹ, tabi ẹni ti o sisẹ gan-an alara, nitori naa o see se ki a wọn gbogbo wọn, sugbọn eyi ti a ni i lo ninu wiwuwo ati fifuyẹ yoo jẹ pẹlu isẹ naa gan-an alara, ki i se pẹlu ara ẹni ti o sisẹ tabi iwe isẹ naa.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ونضع الموازين القسط ليوم القيامة فلا تظلم نفس شيئا وإن كان مثقال حبة من خردل أتينا بها وكفى بنا حاسبين { [سورة الأنبياء: 47].

« Ati pe A o fi awọn osunwọn ti o se deedee lelẹ ni ọjọ igbende, nitori naa a kò ni i se abosi kankan fun ẹmi kan; ti o ba si se pe iwọn isẹ jẹ koro kekere kan, A o mu un jade; Awa si ti to ni Olusiro » [Suuratul-Anbiyaa’: 47].

Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} فمن ثقلت موازينه فأولئك هم المفلحون. ومن خفت موازينه فأولئك الذين خسروا أنفسهم بما كانوا بآياتنا يظلمون { [سورة الأعراف: 8 ، 9].

« Ẹnikẹni ti awọn osunwọn rẹ ba tẹwọn; awọn wọnyi ni awọn oloriire. Ati pe ẹnikẹni ti awọn osunwọn rẹ ba fuyẹ; awọn wọnyi ni awọn ti wọn pofo ẹmi wọn, nitori ohun ti wọn n se ni abosi nipa awọn ami Wa» [Suuratul-A’araaf: 8, 9].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

(( الطهور شطر الإيمان، والحمد لله تملأ الميزان )) [رواه مسلم].

« Idaji igbagbọ-ododo -Imaani- ni imọtoto i se, ati pe gbolohun: AL-HAMDU LI-L-LAH -Gbogbo ọpẹ ti Ọlọhun ni i se- a maa kun osunwọn » [Muslim l’o gbe e jade].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( يوضع الميزان يوم القيامة، فلو وزن فيه السماوات والأرض لوسعت )) [رواه الحاكم].

« A o fi osunwọn lelẹ ni ọjọ igbende, nitori naa iba se pe a wọn awọn sanma ati ilẹ ninu rẹ ko ba gba wọn » [Haakim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkẹsan: Afárá:

A si ni igbagbọ si afárá, oun ni afárá kan ti a gbe si ori ina Jahannama, ati oju-ọna abanilẹru akonilayajẹ kan, awọn eniyan yoo gba ori rẹ kọja lọ si ọgba-idẹra Al-Janna, tori naa o n bẹ ninu wọn ẹni ti yoo kọja gẹgẹ bi sisẹju, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti yoo kọja bii kikọyanran mọnamọna, o si wa ninu wọn ẹni ti yoo kọja bii afẹfẹ, ati pe o wa ninu wọn ẹni ti yoo kọja bii ẹyẹ, bẹẹ ni o wa ninu wọn ẹni ti yoo kọja bii awọn eyi ti o dara ju ninu awọn ẹsin, ati pe o wa ninu wọn ẹni ti yoo kọja bii ere sisa ọkunrin, ti yoo yara kamakama ni iyara-kamakama, bẹẹ ni opin ẹni ti yoo kọja ninu wọn ni ẹni ti yoo wọ ni wiwọ, nitori naa wọn yoo kọja ni odiwọn awọn isẹ wọn, titi ti ẹni ti imọlẹ rẹ mọ bi odiwọn atanpanko ẹsẹ rẹ yoo fi kọja, ati pe o n bẹ ninu wọn ẹni ti a o han, ti a o si sọ si inu ina naa, bẹẹ ni ẹnikẹni ti o ba gba ori afárá naa kọja yoo wọ ọgba-idẹra -Al-Janna-.

Akọkọ ẹni ti yoo sọda rẹ ni Anabi wa, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, lẹyin naa ni ijọ rẹ, ati pe ẹnikan kò ni i sọrọ ni ọjọ naa afi awọn ojisẹ, ati pe adua awọn ojisẹ naa ni ọjọ naa ni: Iwọ Ọlọhun se igbala se akola, awọn doje si n bẹ ninu ina Jahannama ni ẹgbẹ mejeeji afárá naa, ẹnikan kò mọ odiwọn wọn afi Ọlọhun t’O ga, t’O si gbọn-un-gbọn, yoo maa han ẹni ti Ọlọhun ba fẹ ninu awọn ẹda Rẹ.

Ninu awọn iroyin rẹ si ni pe: O mu ju ida lọ, o si tẹẹrẹ ju irun lọ, o yọ, ẹsẹ kan kò le e rinlẹ lori rẹ afi ẹni ti Ọlọhun ba fi rinlẹ, ati pe a o fi lelẹ ninu okunkun, a o si fi ifọkantanni ati apo-ibi ransẹ, awọn mejeeji yoo si duro ni ẹgbẹ mejeeji afárá naa, nitori atijẹri lori ẹni ti o ba mojuto mejeeji tabi o fi mejeeji rare.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وإن منكم إلا واردها كان على ربك حتماً مقضيا. ثم ننجي الذين اتقوا ونذر الظالمين فيها جثياً { [سورة مريم: 71-72].

« Kò si ẹnikan ninu yin afi ki o kọja nibẹ, o jẹ ọranyan ti Oluwa rẹ ti se idajọ rẹ, ti kò ni i yẹ. Lẹyin naa A O la awọn ẹni ti wọn paya [Ọlọhun], A O si fi awọn alabosi silẹ ninu rẹ ni ikunlẹ » [Suuratu Maryam: 71-72].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, si sọ pe:

(( يضرب الصراط بين ظهراني جهنم، فأكون أنا وأمتي أول من يجيزه )) [رواه مسلم].

« A o fi afárá naa le ori ina Jahannama, emi ati ijọ mi o si jẹ akọkọ ẹni ti yoo sọda rẹ » [Muslim l’o gbe e jade].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( ويضرب جسر جهنم .. فأكون أول من يجيز، ودعاء الرسل يومئذ: اللهم سلم سلم )) [متفق عليه].

« Ati pe a o fi afárá ina Jahannama le [e lori], emi o si jẹ akọkọ ẹni ti yoo sọda rẹ, ati pe adua awọn ojisẹ ni ọjọ naa ni: Iwọ Ọlọhun se igbala, se akola » [Bukhari ati Muslim l’o gbe e jade].

Baba Sa’id Al-Khudriyyu “ki Ọlọhun O yọnu si i”, sọ pe:

(( بلغني أن الجسر أدق من الشعر، وأحد من السيف )) [رواه مسلم].

« O de etigbọ mi pe: Dajudaju afárá naa tẹẹrẹ ju irun lọ, o si mu un ju ida lọ » [Muslim l’o gbe e jade].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( وترسل الأمانة والرحم، فتقومان على جنبي الصراط يمينا وشمالاً، فيمر أولكم كالبرق ... ثم كمر الريح، ثم كمر الطير، وشد الرجال، تجزي بهم أعمالهم، ونبيكم قائم على الصراط، يقول: رب سلم سلم، حتى تعجز أعمال العباد، حتى يجئ الرجل فلا يستطيع السير إلا زحفاً، قال: وعلى حافتي الصراط كلاليب معلقة مأمورة بأخذ من أمرت به، فمخدوش ناج، ومكدوس في النار )) [رواه مسلم].

« Ati pe a o fi ifọkantanni ati apo-ibi ransẹ, n ni wọn yoo ba duro ni ẹgbẹ mejeeji afárá naa, apa ọtun ati osi, nitori naa ẹni-akọkọ yin yoo kọja gẹgẹ bi mọnamọna … lẹyin naa gẹgẹ bi afẹfẹ, lẹyin naa gẹgẹ bi kikọja ẹyẹ, ati sisare awọn ọkunrin, isẹ wọn yoo maa gbe wọn sọda, nigba ti Anabi yin yoo duro lori afárá naa, ti yoo maa sọ pe: Oluwa mi, se igbala, se akola, titi ti agara yoo fi da isẹ awọn eniyan, titi ti eniyan yoo fi wa ti kò ni i le rin afi fifa; o ni: Ati pe awọn dòjé wa ni ẹgbẹ mejeeji afárá naa ni asorọ, wọn jẹ ohun ti a pa lasẹ lati mu ẹni ti a ba pa a lasẹ pe ki o mu, nitori naa ẹni ti yoo fi ara pa, ti yoo si la wa ninu wọn, ati pe ẹni ti a o we rogodo ju sinu ina wa ninu wọn » [Muslim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkẹwa: Abakọja:

A tun ni igbagbọ si pe dajudaju nigba ti awọn olugbagbọ-ododo ba sọda afárá naa, wọn yoo duro lori abakọja kan, oun ni aaye kan laarin ọgba-idẹra -Al-Janna- ati ina, a o da awọn olugbagbọ-ododo, awọn ẹni ti wọn ti sọda afárá naa, ti wọn si la nibi ina naa duro nibẹ, nitori ki a le baa gbẹsan fun apa kan wọn ni ọdọ apa kan siwaju ki wọn o to wọ ọgba-idẹra -Al-Janna-. Nitori naa nigba ti a ba tun wọn se, ti a si fọ wọn mọ, a o yọnda fun wọn lati wọ inu rẹ.

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( يخلص المؤمنون من النار، فيحبسون على قنطرة بين الجنة والنار، فيقتص لبعضهم من بعض مظالم كانت بينهم في الدنيا، حتى إذا هذبوا، ونقوا، أذن لهم في دخول الجنة، فوالذي نفس محمد بيده، لأحدهم أهدى بمنـزله في الجنة منه بمنـزله كان في الدنيا )) [رواه البخاري].

« Awọn olugbagbọ-ododo yoo la nibi ina, n ni a o ba se wọn mọ ori abakọja kan laarin ọgba-idẹra -Al-Janna- ati ina, n ni a o ba gbẹsan ohun abosi ti n bẹ laarin wọn ni ile-aye fun apa kan wọn ni ọdọ apa kan, nigba ti o ba wa di pe a ti tun wọn se, ti a si ti fọ wọn mọ, a o yọnda fun wọn lati wọ ọgba-idẹra. Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad wa ni ọwọ Rẹ bura: Dajudaju ẹnikan wọn yoo mọna ile rẹ ninu ọgba-idẹra naa ju bi o ti se mọna ile rẹ ni ile-aye lọ » [Bukhari l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkọkanla: Ọgba-idẹra -Al-Janna- ati ina:

A si tun gbagbọ pe dajudaju ododo ni ọgba-idẹra -Al-Janna- ododo naa si ni ina, ati pe dajudaju mejeeji n bẹ, wọn kò si ni i tan, wọn kò si ni i parẹ rara, nse ni wọn yoo maa bẹ ni gbogbo igba. Nitori naa idẹra awọn ọmọ Al-Janna kò ni i tan, kò si ni i yẹ, bẹẹ ni iya awọn ọmọ ina fun awọn ti Ọlọhun ba se idajọ bibẹ ninu rẹ gberekese le lori, kò ni i pin, kò si ni i ja.

Sugbọn Oluse Ọlọhun ni ọkan soso: A o yọ wọn jade kuro ninu rẹ pẹlu isipẹ awọn olusipẹ, ati pẹlu aanu Ẹni ti aanu Rẹ pọ ju ikẹ awọn alaanu lọ.

Al-Janna si ni: Ile apọnle, eyi ti Ọlọhun pese kalẹ fun awọn olupaya Ọlọhun ni ọjọ igbende, awọn odo ti n san wa ninu rẹ, ati awọn yara giga, ati awọn iyawo ti o dara, ati pe ohun ti maa n wu ẹmi wa ninu rẹ, ti si maa n dun mọ oju, ninu ohun ti oju kan kò riri, ti eti kan kò si gbọ ri, ti kò si ru wuyẹ ni ọkan eniyan kan ri, idẹra rẹ kò ni i parẹ, kò si ni i tan, wọn yoo maa bẹ ninu rẹ gberekese lai kò si jija kan. Ati pe idiwọn aaye pasan ninu Al-Janna ni oore ju ile-aye lọ ati ohun ti n bẹ ninu rẹ, a o maa gboorun rẹ lati irin ogoji ọdun si i, ati pe eyi ti o ga ju ninu idẹra rẹ ni riri ti awọn olugbagbọ-ododo yoo ri Oluwa wọn pẹlu awọn oju wọn ni kedere.

Sugbọn awọn alaigbagbọ: Ẹni ti a o di kuro nibi riri Oluwa wọn ni wọn, nitori naa ẹnikẹni ti o ba kọ riri ti awọn olugbagbọ-ododo yoo ri Oluwa wọn, dajudaju o ti fi wọn se dọgba pẹlu awọn alaigbagbọ ninu ainiri yii.

Ati pe ọgọrun agbega l’o wa ninu Al-Janna, ohun ti o wa laarin agbega kan si omiran dabi ohun ti o wa laarin sanma ati ilẹ, bẹẹ ni eyi ti o ga ju ninu Al-Janna ni Al-Firdaws ti o ga ju, ati pe aga-ọla Ọlọhun ni àjà rẹ, bẹẹ ni ilẹkun mẹjọ l’o ni, ohun ti n bẹ laarin ẹgbẹ mejeeji ilẹkun kan dabi ohun ti o wa laarin Makkah ati Hajar, ati pe dajudaju ọjọ kan n bọ wa ba a ti yoo jẹ ohun ti o kun latari ọpọ eniyan, ẹni ti o si kere ju ni ipo ninu awọn ọmọ Al-Janna ni iru ile-aye ati iru rẹ mẹwa.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ nipa Al-Janna naa pe:

} أعدت للمتقين { [سورة آل عمران: 133].

« A pese rẹ kalẹ fun awọn olupaya Ọlọhun » [Suuratu Aal-Imraan: 133]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ nipa bibẹ gberekere awọn ọmọ Al-Janna, ati pe kò ni i parẹ pe:

} جزاؤهم عند ربهم جنات عدن تجري من تحتها الأنهار خالدين فيها أبداً { [سورة البينة: 8].

« Ẹsan wọn ni ọdọ Oluwa wọn ni awọn ọgba-idẹra -Al-Janna- ti yoo maa bẹ gbere, ti awọn odo kékéké n san ni abẹ wọn, ninu wọn ni wọn yoo maa wa gberekese » [Suuratul-Bayyinah: 8].

Sugbọn ina ni: Ile iya ti Ọlọhun pese kalẹ fun awọn alaigbagbọ ati awọn ẹlẹsẹ, eyi ti o le koko ju ninu iya ati orisirisi jijẹni niya wa ninu rẹ, awọn Malaika ti wọn nipọn ti wọn ni agbara l’o si n sọ ọ, ati pe inu rẹ ni awọn alaigbagbọ yoo maa bẹ laelae, ounjẹ wọn ni igi ẹlẹgun, bẹẹ ni ohun mimu wọn ni omi gbigbona, ati pe ida kan ninu aadọrin ipin ninu gbigbona ina Jahannama ni ina ile-aye, nitori naa a se ajulọ fun un lori ina ile-aye pẹlu ipin mọkandinlaadọrin, ti gbogbo ọkọọkan ninu rẹ jẹ iru gbigbona rẹ tabi ohun ti o le ju bẹẹ lọ.

Ati pe sisu kò ni i se ina yii latari awọn ti a n ko si inu rẹ, ati awọn ti a n ju si inu ọgbun rẹ, koda dajudaju nse ni yoo maa sọ pe: Njẹ alekun wa sẹku bi, ilẹkun meje l’o si ni, gbogbo ilẹkun kọọkan ninu wọn l’o ni ipin kan ti a pin.

Ọlọhun t’O ga sọ nipa ina naa pe:

} أعدت للكافرين { [سورة آل عمران: 131].

« A pese rẹ kalẹ fun awọn alaigbagbọ » [Suuratu Aal-Imraan: 131]. Ọlọhun si tun sọ nipa bibẹ ninu ina laelae ti awọn ọmọ ina, ati pe kò ni i parẹ, pe:

} إن الله لعن الكافرين وأعد لهم سعيراً خالدين فيها أبداً { [سورة الأحزاب: 64-65].

« Dajudaju Ọlọhun sẹbi le awọn alaigbagbọ, O si pese ina elejo kalẹ fun wọn, inu rẹ ni wọn yoo maa bẹ laelae » [Suuratul-Ahzaab: 64-65].

Awọn eso nini igbagbọ-ododo si ọjọ ikẹyin:

Awọn eso ti o gbọn-un-gbọn n bẹ fun nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin, ninu wọn ni:

1- Sise ojukokoro nipa sise awọn ohun ti o jẹ titẹle ti Ọlọhun, ati gbigbiyanju lori wọn, ni irankan ẹsan.

2- Sisa fun dida ẹsẹ, ati [sisa fun] yiyọnu si i, ni ibẹru iya ọjọ naa.

3- Pipa ibanujẹ olugbagbọ-ododo rẹ nipa ohun ti o ti bọ mọ ọn lọwọ ni ile-aye nitori ohun ti n rankan ninu idẹra ọrun ati ẹsan rẹ.

4- Wi pe nini igbagbọ-ododo si igbende ni ipilẹ oriire onikaluku, ati ti awujọ. Nitori pe dajudaju nigba ti eniyan ba ni igbagbọ pe Ọlọhun t’O ga yoo gbe ẹda dide laipẹ lẹyin iku wọn, yoo si se isiro fun wọn, yoo si san wọn ni ẹsan lori awọn isẹ wọn, yoo si gbẹsan lọdọ alabosi fun ẹni ti o se abosi si, titi ti o fi de ori awọn ẹranko; yoo duro sinsin lori titẹle ti Ọlọhun, gbongbo aburu yoo si ja, oore yoo si kari awujọ, ati pe iwa rere ati ifayabalẹ yoo kari.

 ORIGUN KẸFA: NINI IGBAGBỌ-ODODO SI AKỌSILẸ -KADARA-

###

  [1] Alaye akọsilẹ -Kadara- ati pipataki nini igbagbọ si i:

Akọsilẹ ni: Ipebubu Ọlọhun fun gbogbo ohun ti yoo sẹlẹ, ni ibamu pẹlu ohun ti o ti siwaju ninu imọ Rẹ, ti Hikamah -ọgbọn- Rẹ si da lẹjọ. Oun si n pada sidi agbara Ọlọhun, ati pe Alagbara ni I lori gbogbo nnkan, Oluse ohun ti O ba gbero ni I.

Nini igbagbọ si i si n bẹ ninu nini igbagbọ si jijẹ oluwa Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- ati pe ọkan ninu awọn origun igbagbọ, eyi ti igbagbọ naa kò le e pe afi pẹlu wọn ni i. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إنا كل شيء خلقناه بقدر { [سورة القمر: 49].

« Dajudaju Awa da gbogbo nnkan pẹlu idiwọn » [Suuratul-Qamar: 49].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( كل شيء بقدر حتى العجز والكيس، أو الكيس والعجز )) [رواه مسلم].

« Gbogbo nnkan ni n bẹ pẹlu akọsilẹ, titi ti o fi de ori lilẹ ati laakaye, tabi lakaye ati lilẹ» [Muslim l’o gbe e jade].

 [2] Awọn ipele akọsilẹ:

Nini igbagbọ si akọsilẹ kò le e rinlẹ afi pẹlu fifi awọn ipele mẹrin kan rinlẹ, awọn ni:

Alakọkọ: Nini igbagbọ si imọ ayeraye ti Ọlọhun si gbogbo nnkan. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ألم تعلم أن الله يعلم ما في السماء والأرض إن ذلك في كتاب إن ذلك على الله يسير { [سورة الحج: 70].

« Njẹ iwọ kò wa mọ pe dajudaju Ọlọhun mọ ohun ti o wa ninu sanma ati ilẹ bi? Dajudaju eleyii n bẹ ninu tira kan, dajudaju irọrun ni eleyii fun Ọlọhun » [Suuratul-Hajj: 70].

Ẹlẹẹkeji: Nini igbagbọ si sise akọsilẹ ohun ti Ọlọhun mọ ninu awọn ebubu si inu wàlaa ti a sọ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ما فرطنا في الكتاب من شيء { [سورة الأنعام: 38].

« Awa kò sẹ nnkan kan ku ninu Tira [lai sọ] » [Suuratul-An’aam: 38].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( كتب الله مقادير الخلائق قبل أن يخلق السماوات والأرض بخمسين ألف سنة )) [رواه مسلم].

« Ọlọhun ti kọ akọsilẹ awọn ẹda siwaju ki O to da awọn sanma ati ilẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta ọdun » [Muslim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkẹta: Nini igbagbọ si erongba Ọlọhun ti i sẹ, ati agbara Rẹ ti o kari. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وما تشاءون إلا أن يشاء الله رب العالمين { [سورة التكوير: 29].

« Ati pe ẹ kò le fẹ [nnkan kan ki o si ri bẹẹ] afi ti Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda ba fẹ » [Suuratut-Takwiir: 29].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ fun ẹni ti o sọ fun un pe: Ohun ti Ọlọhun ati iwọ fẹ -l’o sẹlẹ- pe:

(( أجعلتني لله ندا ؟، بل ما شاء الله وحده )).

« O wa sọ mi di ẹgbẹra fun Ọlọhun ni bi? Rara o, ohun ti Ọlọhun fẹ l’Oun nikan -l’o sẹlẹ- » [Ahmad l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkẹrin: Nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun ni Ẹlẹda gbogbo nnkan. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} الله خالق كل شيء وهو على كل شيء وكيل { [سورة الزمر: 62].

« Ọlọhun ni Ẹlẹda gbogbo nnkan, ati pe Oun ni Olusọ gbogbo nnkan » [Suuratuz- Zumar: 62]. Ọlọhun tun sọ pe:

} والله خلقكم وما تعملون { [سورة الصافات: 96].

« Ati pe Ọlọhun ni O da yin ati awọn ohun ti ẹ n se » [Suuratus-Saaffaat: 96].

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, tun sọ pe:

(( إن الله يصنع كل صانع وصنعته )) [رواه البخاري].

« Dajudaju Ọlọhun l’O da gbogbo ẹni ti n se nnkan ati ohun ti o se » [Bukhari l’o gbe e jade].

 [3] Awọn ipin ipebubu:

a- Ipebubu ti o kari fun gbogbo awọn ẹda: Oun ni eyi ti a kọ sinu wàlaa ti a sọ, siwaju sisẹda awọn sanma ati ilẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta ọdun.

b- Ipebubu ti ọjọ-ori: Oun ni ipebubu gbogbo ohun ti yoo sẹlẹ si eniyan, lati igba ti a ba ti fẹ ẹmi si i lara, titi di igba iku rẹ.

d- Ipebubu ti ọdọọdun: Oun ni pipebubu ohun ti yoo sẹlẹ ni gbogbo ọdun, eleyii ni oru abiyi -Lailatul-Qadr- ti gbogbo ọdun. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} فيها يفرق كل أمر حكيم { [سورة الدخان: 4].

« Ninu [oru] rẹ ni a maa n se alaye gbogbo ọrọ ti o kun fun ọgbọn » [Suuratud-Dukhaan: 4].

e- Ipebubu ti ojoojumọ: Oun ni pipebubu ohun ti n sẹlẹ ni ojoojumọ, ninu iyi ati iyẹpẹrẹ, fifunni ati aifunni, mimuni maa sẹmi ati pipani, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} يسأله من في السماوات والأرض كل يوم هو في شأن { [سورة الرحمن: 29].

« Awọn ẹni ti n bẹ ninu awọn sanma ati ilẹ ni wọn maa n tọrọ [nnkan] ni ọdọ Rẹ. Ni gbogbo ọjọ ni Oun [Ọlọhun] wa ninu isesi kan » [Suuratur-Rahmaan: 29].

 [4] Adisọkan awọn asiwaju [rere] nipa akọsilẹ:

Wi pe Ọlọhun ni Ẹlẹda gbogbo nnkan, Oluwa rẹ ati Ọba rẹ, O ti pebubu awọn akọsilẹ awọn ẹda siwaju ki O to sẹda wọn, O pebubu awọn ọjọ-ori wọn, ati awọn ọrọ -arziki- wọn, ati awọn isẹ wọn, O si kọ ohun ti wọn yoo pada si ọdọ rẹ ninu oriire tabi oriibu, gbogbo nnkan l’O se akojọ rẹ si inu iwe kan ti o han. Nitori naa ohun ti Ọlọhun ba fẹ ni yoo sẹlẹ, ati pe ohun ti kò ba fẹ kò ni i sẹlẹ, bẹẹ ni O mọ ohun ti o ti sẹlẹ, ati ohun ti n sẹlẹ, ati ohun ti kò i ti i sẹlẹ pe ti o ba sẹlẹ bawo ni yoo ti se ri, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan, A maa fi ọna mọ ẹni ti O ba fẹ, A si maa si ẹni ti O ba fẹ lọna, ati pe awọn eniyan ni erongba ati agbara, ti wọn fi i maa n se ohun ti Ọlọhun fun wọn lagbara lori rẹ, pẹlu adisọkan wọn pe dajudaju awọn eniyan kò le e fẹ [nnkan  kan ki o si ri bẹẹ] afi ti Ọlọhun ba fẹ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} والذين جاهدوا فينا لنهدينهم سبلنا { [سورة العنكبوت: 69].

« Ati pe awọn ẹni ti wọn gbiyanju nipa [ẹsin] Wa, dajudaju Awa yoo fi wọn mọ awọn ọna Wa » [Suuratul-Ankabuut: 69].

Ati pe Ọlọhun t’O ga ni Ẹlẹda awọn eniyan ati awọn isẹ wọn, awọn [eniyan] si ni oluse awọn isẹ naa ni paapaa. Nitori naa kò si awijare kan fun ẹnikan lori Ọlọhun nipa ọranyan kan ti o fi silẹ, tabi eewọ kan ti o se, kaka bẹẹ Oun l’O ni awijare ti o dopin lori awọn ẹda Rẹ. O si tọ pe ki a maa fi akọsilẹ -kadara- se ẹri lori awọn adanwo, yatọ si awọn alebu ati awọn ẹsẹ; gẹgẹ bi Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, ti sọ nipa iyan ti Anabi Muusa ja Anabi Aadama, pe:

(( تحاج آدم وموسى، فقال موسى: أنت آدم الذي أخرجتك خطيئتك من الجنة، فقال له آدم: أنت موسى الذي اصطفاك الله برسالاته، وبكلامه، ثم تلومني على أمر قد قُدِّر عليَّ قبل أن أخلق، فحج آدم موسى )) [رواه مسلم].

« Anabi Aadama ati Anabi Muusa jara wọn niyan, n ni Anabi Muusa ba sọ pe: Iwọ Aadama ni ẹni ti asise rẹ yọ ọ kuro ninu ọgba-idẹra -Al-Janna-. N ni Anabi Aadama ba sọ fun un pe: Iwọ ni Muusa ẹni ti Ọlọhun sa lẹsa pẹlu awọn isẹ Rẹ, ati ọrọ Rẹ, lẹyin naa ti o wa n bu mi lori nnkan kan ti a ti pebubu rẹ le mi lori siwaju ki a to se ẹda mi, nitori naa Aadama bori Musa pẹlu awijare » [Muslim l’o gbe e jade].

 [5] Awọn isẹ awọn eniyan:

Awọn isẹ ti Ọlọhun N se ẹda wọn si inu ile-aye pin si ọna meji:

Alakọkọ: Ohun ti Ọlọhun -ibukun ati giga ni fun Un- maa N mu ki o sẹlẹ ninu awọn isẹ Rẹ si awọn ẹda Rẹ, nitori naa ẹnikan kò ni erongba kan tabi ẹsa kan lori rẹ, ati pe erongba kò jẹ ti ẹnikan [nipa rẹ] yatọ si Ọlọhun, gẹgẹ bi mimuni maa sẹmi ati pipani, aisan ati alaafia.

Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} والله خلقكم وما تعلمون { [سورة الصافات: 96].

« Ati pe Ọlọhun ni O da yin ati awọn ohun ti ẹ n se » [Suuratus-Saaffaat: 96]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} الذي خلق الموت والحياة ليبلوكم أيكم أحسن عملاً { [سورة الملك: 2].

« Ẹni ti O da iku ati isẹmi, ki O le baa dan yin wo pe ta ni ninu yin ni yoo se eyi ti o dara ju ni isẹ » [Suuratul-Mulk: 2].

Ẹlẹẹkeji: Ohun ti awọn ẹda n se ni apapọ wọn, ninu awọn ti wọn ni erongba, eleyii a maa sẹlẹ pẹlu ẹsa ẹni ti o se e, ati erongba rẹ, nitori pe Ọlọhun fi eleyii silẹ fun wọn. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} لمن شاء منكم أن يستقيم { [سورة التكوير:28].

« O wa fun ẹni ti o ba fẹ lati duro sinsin ninu yin » [Suuratut-Takwiir: 28]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} فمن شاء فليؤمن ومن شاء فليكفر { [سورة الكهف: 29].

« Nitori naa ẹni ti o ba fẹ ki o gbagbọ, ẹni ti o ba si fẹ ki o se aigbagbọ » [Suurtul-Kahf: 29]. Nitori naa a o maa dupẹ fun wọn lori ohun ọpẹ, a o si maa bu wọn lori ohun eebu, bẹẹ ni Ọlọhun ki i jẹ eniyan niya afi lori ohun ti eniyan ni ẹsa ninu rẹ, gẹgẹ bi Ọlọhun t’O ga ti sọ pe:

} وما أنا بظلام للعبيد { [سورة ق: 29].

« Ati pe Emi ki I se alabosi si awọn ẹru [Mi] » [Suuratu Qaaf: 29]. Eniyan si mọ iyatọ laarin ẹsa ati tulaasi. Nitori naa ni yoo se maa sọ kalẹ lati oke pẹlu àkàbà ni sisọ kan ti o jẹ ti ẹsa, o si see se ki ẹlomiran o ti i subu lati ori oke naa, sise ẹsa ni ti akọkọ, ijẹni-nipa si ni ti ẹẹkeji.

 [6] Asepọ [t’o wa] laarin dida ti Ọlọhun [da awọn isẹ] ati sise ti eniyan n se e:

Ọlọhun da eniyan, O si da awọn isẹ rẹ, O si se erongba ati agbara fun un, nitori naa oluse-isẹ ni paapaa ni eniyan, nitori sise rẹ ti o kan an taara, nitori pe o ni erongba ati agbara. Nitori naa ti o ba gbagbọ nse l’o jẹ pẹlu erongba rẹ ati fifẹ rẹ, bẹẹ ni ti o ba se aigbagbọ nse ni yoo jẹ pẹlu fifẹ ati erongba rẹ ti o pe, gẹgẹ bi igba ti a ba sọ pe: Lati ara igi yii ni eso yii ti jade, lati ara ilẹ yii si ni irugbin yii ti jade. Eyi ti o tumọ si pe: Lati ara rẹ l’o ti sẹlẹ; ati lati ọdọ Ọlọhun, ni itumọ pe lati ọdọ Rẹ ni isẹda rẹ ti wa. Kò si atako laarin mejeeji, pẹlu eleyii ni ofin Ọlọhun ati agbara Rẹ yoo se dọgba.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} والله خلقكم وما تعملون { [سورة الصافات: 96].

« Ati pe Ọlọhun ni O da yin ati awọn ohun ti ẹ n se » [Suuratus-Saaffaat: 96]. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} فأما من أعطى واتقى. وصدق بالحسنى. فسنيسره لليسرى. وأما من بخل واستغنى. وكذب بالحسنى. فسنيسره للعسرى { [سورة الليل: 5-10].

« Sugbọn ẹni ti n tọrẹ, ti o si n paya [Ọlọhun]. Ti o si gba ohun ti o dara ju naa gbọ. A O fi i se kongẹ irọrun naa. Sugbọn ẹni ti o se ahun, ti o si ro pe oun to tan. Ti o si pe ohun ti o daju naa nirọ. A O fi oun se kongẹ inira naa » [Suuratul-Lail: 5-10].

 [7] Ohun ti o jẹ ọranyan lori eniyan nipa akọsilẹ:

Nnkan meji l’o jẹ ọranyan lori eniyan nipa akọsilẹ:

Alakọkọ: Ki o maa fi Ọlọhun wa iranlọwọ nipa sise ohun ti agbara ka, ati jijinna si ohun ti isọra fun, ki o si maa tọrọ lọdọ Rẹ pe ki O fi oun se kongẹ irọrun naa, ki O si gbe oun jinna si inira naa, ki o si gbẹkẹle E, ki o si maa sadi I. Nitori naa ki o jẹ oni-bukaata lọ si ọdọ Rẹ nipa fifa oore, ati fifi aburu silẹ. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( احرص على ما ينفعك، واستعن بالله، ولا تعجز، وإن أصابك شيء فلا تقل: لو أنِّي فعلت كذا لكان كـذا، ولكن قل: قدر اللَّه وما شاء فعل، فإن لو تفتح الشيطان )). رواه مسلم.

« Maa gbiyanju lori ohun ti yoo se ọ lanfaani, ki o si maa wa iranlọwọ lọdọ Ọlọhun, ma si se ko aarẹ rara, ti nnkan kan ba wa se ọ, ma se sọ pe: Iba se pe mo ti se igbá ni, bai bai ni i ba ri; sugbọn nse ni ki o sọ pe: QADDARA -L-LAAHU WA MAA SHAA’A FA’AL “Akọsilẹ Ọlọhun -ni eleyii- ohun t’O si fẹ l’O se”, tori pe nse ni [gbolohun] iba se pe maa n si isẹ esu silẹ » [Muslim l’o gbe e jade].

Ẹlẹẹkeji ni pe: Ọranyan ni ki o se suuru lori ohun ti agbara ka, nitori naa ki o ma bara jẹ, ki o si mọ daju pe lati ọdọ Ọlọhun ni eleyii ti wa, ki o yọnu ki o si sọpa-sọsẹ silẹ, ki o si mọ daju pe ohun ti o se oun, kò jẹ ohun ti yoo tase oun [l’o mu un se e] bẹẹ ni ohun ti o tase rẹ kò jẹ ohun ti yoo se e [ni kò se se e]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( واعلم أن ما أصابك لم يكن ليخطئك، وأن ما أخطأك لم يكن ليصيبك )).

« Mọ daju pe ohun ti o se ọ, kò jẹ ohun ti yoo yẹ ọ silẹ [l’o mu un se ọ], ati pe ohun ti o yẹ ọ silẹ, kò jẹ ohun ti yoo se ọ [l’o mu un ma se ọ]».

 [8] Yiyọnu si idajọ Ọlọhun ati akọsilẹ:

O yẹ ki eniyan o yọnu si akọsilẹ, nitori pe o n bẹ ninu pipe yiyọnu si jijẹ oluwa Ọlọhun. Nitori naa o yẹ ki gbogbo onigbagbọ-ododo o yọnu si akọsilẹ Ọlọhun; nitori pe isẹ Ọlọhun ati akọsilẹ Rẹ oore ni gbogbo rẹ i se, ati sise deedee, ati Hikmah -ọgbọn-. Nitori naa ẹnikẹni ti ẹmi rẹ ba balẹ si pe ohun ti o se oun kò jẹ ohun ti yoo tase oun, ati pe ohun ti o tase oun kò jẹ ohun ti yoo se oun, iparagadi ati hilahilo yoo kuro ninu ọrọ rẹ, ati pe ibẹru ati ifoya yoo kuro ninu igbesi-aye rẹ. Nitori naa kò ni maa bara jẹ lori ohun ti o bọ mọ ọn lọwọ, kò si ni i maa bẹru lori ọjọ-iwaju rẹ, yoo si tipasẹ eleyii di ẹni ti o se oriire ju ni ipo ninu awọn eniyan, ati ẹni ti o dara ju ni ẹmi ninu wọn, ati ẹni ti ọkan rẹ balẹ ju ninu wọn. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba mọ pe ọjọ-ori oun ni opin, ọrọ -arziki- oun si ni onka, ikọlẹ kò le e se alekun ọjọ-ori rẹ, bẹẹ ni ihawọ kò le e lekun ọrọ -arziki- rẹ, tori pe gbogbo rẹ l’o ti wa ni akọsilẹ, yoo se suuru lori ohun ti o se e ninu awọn adanwo, yoo si maa tọrọ idarijin nipa ohun ti o se ninu awọn asẹ ati awọn ohun alebu, yoo si yọnu si ohun ti Ọlọhun kọ silẹ fun un, nitori naa yoo se akojọpọ laarin titẹle asẹ Ọlọhun ati sise suuru lori awọn adanwo.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ما أصاب من مصيبة إلا بإذن الله ومن يؤمن بالله يهـد قلبه والله بكل شيء عليم { [سورة التغابن: 11].

« Adanwo kan kò le e kan [ẹnikan] afi pẹlu iyọnda Ọlọhun, ati pe ẹni t’o ba gba Ọlọhun gbọ, yoo fi ọkan rẹ mọna, Ọlọhun ni Oni-mimọ nipa gbogbo nnkan » [Suuratu t-Tagaabun: 11]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} فاصبر إن وعد الله حق واستغفر لذنبك { [سورة: ].

« Nitori naa se suuru, dajudaju ododo ni adehun Ọlọhun, maa tọrọ aforijin ẹsẹ rẹ » [Suuratu: ].

 [9] Orisi meji ni imọna:

Ekinni ni: Imọna ti itọka si ododo ati ifọnahanni, oun jẹ ti gbogbo ẹda, oun ni eyi ti awọn ojisẹ ati awọn olutẹle wọn ni agbara lori rẹ. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وإنك لتهدي إلى صراط مستقيم { [سورة الشورى: 52].

« Ati pe dajudaju irẹ yoo maa tọ awọn eniyan si ọna ti o tọ » [Suuratush-Shuuraa: 52].

Ekeji ni: Imọna ti kongẹ ati ifinirinlẹ lati ọdọ Ọlọhun, ni idẹra kan lati ọdọ Ọlọhun, ati oore kan fun awọn ẹda Rẹ, awọn olupaya Rẹ, oun ni eyi ti ẹnikan kò lagbara lori rẹ yatọ si Ọlọhun. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} إنك لا تهدي من أحببت ولكن الله يهدي من يشاء { [سورة القصص: 56].

« Dajudaju iwọ [Anabi] kò le e fi ọna mọ ẹni ti o nifẹ si, sugbọn Ọlọhun ni maa N fi ọna mọ ẹni ti O ba fẹ » [Suuratul-Qasas:56].

 [10] Orisi meji ni erongba ninu Tira Ọlọhun:

Ekinni ni: Erongba ti akọsilẹ ti pe ki nnkan o sẹlẹ, oun ni erongba ti o kari gbogbo ohun ti n bẹ. Nitori naa ohun ti Ọlọhun ba fẹ yoo sẹlẹ, ohun ti kò ba si fẹ kò ni i sẹlẹ. O si pa dandan pẹlu rẹ pe ki ohun ti a gba lero o sẹlẹ, sugbọn kò pa dandan pe ki ifẹ ati iyọnu o bẹ pẹlu rẹ, ayafi ti erongba ti ofin -Sharia- ba rọ mọ ọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} فمن يرد الله أن يهده يشرح صدره للإسلام { [سورة الأنعام: 125].

« Ẹnikẹni ti Ọlọhun ba gbero lati fi ọna mọ ọn, yoo se isipaya aya rẹ si Islam » [Suuratul-An-aam: 125].

Ekeji ni: Erongba ti ẹsin, ti ofin Sharia, oun ni ninifẹ si ohun ti a gba lero, ati awọn ẹni-rẹ, ati yiyọnu si wọn, kò si pa dandan pe ki ohun ti a gba lero naa o sẹlẹ, afi ti erongba ti akọsile ti pe ki nnkan o sẹlẹ ba rọ mọ ọn. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} يريد الله بكم اليسر ولا يريد بكم العسر { [سورة البقرة: 185].

« Ọlọhun gbero irọrun fun yin, kò gbero isoro fun yin » [Suuratul-Baqarah: 185].

Erongba pe ki nnkan o sẹlẹ l’o gbooro ju ni gbogbo ọna, nitori pe gbogbo ohun ti a gba lero ti ofin Sharia ti o sẹlẹ ti di ohun ti a gba lero pe ki o sẹlẹ, sugbọn ki i se gbogbo ohun ti a gba lero pe ki o sẹlẹ ni yoo sẹlẹ l’ohun ti a gba lero ninu ofin Sharia. Nitori naa orisi erongba mejeeji naa l’o rinlẹ l’ara igbagbọ Abubakar, “ki Ọlọhun O yọnu si i”, ni apejuwe. Apejuwe ohun ti erongba ti ki nnkan o sẹlẹ nikan si rinlẹ si ara rẹ ni aigbagbọ Abu Jahl. Bẹẹ ni ohun ti erongba pe ki nnkan o sẹlẹ kò rinlẹ ninu rẹ bi o tilẹ jẹ wi pe a fẹ ẹ ninu erongba ti ofin Sharia ni igbagbọ Abu Jahl naa.

Nitori naa bi o tilẹ jẹ pe Ọlọhun fẹ awọn ẹsẹ ni akọsilẹ -kadara- O si fẹ ẹ ni sisẹlẹ, sugbọn kò yọnu si i ni ẹsin, bẹẹ ni kò nifẹ si i,  ati pe kò pa ni lasẹ pẹlu rẹ, kaka bẹẹ, nse l’O N binu rẹ, ti O si N korira rẹ, ti O si kọ ọ fun’ni, ti O si N se ileri-iya si ẹni ti o ba se e, gbogbo eleyii si n bẹ ninu akọsilẹ -kadara- Rẹ.

Sugbọn awọn itẹle asẹ Rẹ, ati igbagbọ-ododo, dajudaju O nifẹ si wọn, O si N pa’ni lasẹ pẹlu wọn, O si N se adehun ẹsan ati ere ti o dara fun ẹni ti n se wọn. Nitori naa a kò le e sẹ Ọlọhun -mimọ ni fun un- yatọ si pẹlu erongba Rẹ, bẹẹ ni nnkan kan kò le e sẹlẹ afi ohun ti o gbero. Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} ولا يرضى لعباده الكفر { [سورة الزمر: 7].

« Ati pe kò ni I yọnu si aigbagbọ fun awọn ẹru Rẹ » [Suuratuz-Zumar: 7]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ pe:

} والله لا يحب الفساد { [سورة البقرة: 205].

« Ọlọhun Ọba kò fẹran ibajẹ » [Suuratul-Baqarah: 205].

 [11] Awọn okunfa ti wọn maa n ti akọsilẹ -kadara- danu:

Ọlọhun se awọn okunfa kan fun awọn akọsilẹ wọnyi, ti wọn maa n ti wọn, ti wọn si maa n gbe wọn kuro, bii adua, ati saraa sise, ati awọn oogun, ati sisọra, ati lilo idurosinsisn. Nitori pe kaluku wọn wa ninu idajọ Ọlọhun, ati akọsilẹ Rẹ, titi ti o fi de ori aarẹ, ati laakaye.

 [12] Asiri Ọlọhun l’ara awọn ẹda Rẹ ni ọrọ akọsilẹ -kadara-:

Ọrọ pe asiri Ọlọhun ni ara awọn ẹda Rẹ ni akọsilẹ, mọ lori agban eyi ti o pamọ ninu akọsilẹ, tori pe ẹnikan kò mọ paapaa awọn nnkan yatọ si Ọlọhun, ati pe eniyan kò le e ri i, gẹgẹ bii wi pe Ọlọhun si eniyan lọna, tabi O fi ọna mọ eniyan, O pa’ni tabi O mu’ni sẹmi, O kọ lati fun’ni, tabi O fun’ni. Gẹgẹ bi Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” ti sọ pe:

(( إذا ذكر القدر فأمسكوا )) [رواه مسلم].

« Nigba ti a wọn ba sọ nipa akọsilẹ -kadara- ẹ yaa pa ẹnu mọ » [Muslim l’o gbe e jade].

Sugbọn awọn agban akọsilẹ yoku, ati ọgbọn rẹ ti o ga, ati awọn ipele rẹ, ati awọn ipo rẹ, ati awọn oripa rẹ, o tọ pe ki a se alaye eleyii ati mimọ rẹ fun awọn eniyan, nitori pe ọkan ninu awọn origun igbagbọ eyi ti o yẹ ki a kọ nipa rẹ, ki a si mọ nipa rẹ ni akọsilẹ -kadara-. Gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” ti sọ nigba ti o wi awọn origun igbagbọ-ododo fun Malaika Jibriil, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a” pe:

(( هذا جبريل، أتاكم يعلمكم دينكم )) [رواه مسلم].

« Jibriil niyi, o wa ba yin lati kọ yin ni ẹsin yin » [Muslim l’o gbe e jade].

 [13] Fifi akọsilẹ -kadara- se awijare:

Ohun ti o pamọ ni imọ Ọlọhun t’O ga ti o ti siwaju nipa ohun ti yoo sẹlẹ, ẹnikan kò mọ ọn yatọ si I, ohun ti a se aimọkan nipa rẹ ni i se fun awọn ti a pa lasẹ jijọsin. Nitori naa kò si awijare kan fun ẹnikan ninu rẹ, ati pe kò tọ pe ki a fi isẹ silẹ ni ẹni ti o fi ẹyin ti ohun ti o ti siwaju ninu akọsilẹ Ọlọhun, tori pe akọsilẹ ki i se awijare fun ẹnikan lori Ọlọhun, tabi lori awọn ẹda Rẹ, iba si se pe o tọ fun ẹnikan pe ki o fi akọsile se awijare lori ohun ti n se ninu awọn aidara ni, a ki ba ti fi iya jẹ alabosi kan, a ki ba si ti pa ọsẹbọ kan, ati pe a kò ba ti gbe ofin ifiyajẹ-ẹlẹsẹ kan dide, bẹẹ ni ẹnikan ki ba ti ko ara ro nibi abosi. Eleyii wa ninu sise ibajẹ ninu ẹsin ati ni ile-aye eyi ti a mọ inira rẹ.

A o sọ fun ẹni ti n fi akọsilẹ se awijare pe: O kò ni imọ amọdaju kan pe o n bẹ ninu awọn ọmọ ọgba-idẹra -Al-Janna- tabi ninu awọn ọmọ ina, ati pe ti o ba se pe o ni amọdaju kan ni, a kò ba ti pa ọ lasẹ, a kò ba si ti kọ -nnkan kan- fun ọ, sugbọn maa sisẹ, Ọlọhun yoo fi ọ se kongẹ pe ki o jẹ ọkan ninu awọn ọmọ Al-Janna.

Apa kan ninu awọn Sahaabe sọ nigba ti wọn gbọ awọn ẹgbawa-ọrọ nipa akọsilẹ pe: N kò ti jẹ ẹni ti o ni igbiyanju to bi mo ti se ni in nisinsinyi ri. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” sọ nigba ti wọn bi i leere nipa sise awijare pẹlu akọsilẹ pe: Ẹ maa sisẹ, onikaluku ni a o se idẹkun fun, nitori ohun ti a da a fun. Nitori naa ẹni ti o ba jẹ ọkan ninu awọn oloriire, a o fi i se kongẹ lati se isẹ awọn oloriire, bẹẹ ni a o fi ẹni ti o jẹ ọkan ninu awọn oloriibu se kongẹ lati se isẹ awọn oloriibu. Lẹyin naa l’o wa ka:

} فأما من أعطى واتقى. وصدق بالحسنى. فسنيسره لليسرى. وأما من بخل واستغنى. وكذب بالحسنى. فسنيسره للعسرى { [سورة الليل: 5-10].

« Sugbọn ẹni ti n tọrẹ, ti o si n paya [Ọlọhun]. Ti o si gba ohun ti o dara ju naa gbọ. A O fi i se kongẹ irọrun naa. Sugbọn ẹni ti o se ahun, ti o si ro pe oun to tan. Ti o si pe ohun ti o daju naa nirọ. A O fi oun se kongẹ inira naa » [Suuratul-Lail: 5-10].

 [14] Sise awọn ohun ti o jẹ okunfa:

Ohun meji ni i maa n se eniyan:

Nnkan ti ọgbọn [wulo] ninu rẹ; ki o ma se ko agara nidi rẹ.

Ati nnkan kan ti kò si ọgbọn kan [ti eniyan le da si i]; ki o ma se bara jẹ nipa rẹ.

Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- mọ nipa awọn adanwo siwaju ki wọn o to sẹlẹ, ki i si i se imọ t’O ni nipa wọn ni ohun ti o mu ki ẹni ti adanwo se naa o bọ si inu adanwo naa, sugbọn nse l’o sẹlẹ pẹlu awọn okunfa ti o rọ mọ sisẹlẹ rẹ, ti sisẹlẹ rẹ ba  jẹ nitori kikọlẹ eniyan, latari pipa awọn okunfa ati awọn ọna ti wọn maa sọ eniyan nibi sisubu sinu rẹ ti, ti ẹsin rẹ si pa a lasẹ pe ki o lo wọn, oun ni ẹni-ibawi lori kikọlẹ rẹ nipa sisọ ara rẹ, ati ailo awọn okunfa ti adamọ eyi ti yoo sọ ọ, sugbọn ti kò ba ni agbara lati ti adanwo yii, yoo jẹ ẹni ti o ni awawi.

Nitori naa didi awọn okunfa mu kò tako akọsilẹ -kadara- ati igbẹkẹle Ọlọhun, koda ipin kan ni i ninu rẹ, sugbọn ti akọsilẹ ba ti sẹlẹ ọranyan ni ki a yọnu si i, ki a si juwọ-jusẹ silẹ fun un, ki a si sẹri si idi ọrọ rẹ t’o ni:

(( قدر الله وما شاء فعل )).

« Akọsilẹ Ọlọhun [ni eyi] ohun ti O si fẹ l’O se ». Sugbọn ki o to di pe o sẹlẹ ọna ẹni ti a pa lasẹ ijọsin ni ki o di awọn okunfa ti o ba ofin -Sharia- mu mu, ati titi awọn akọsilẹ pẹlu awọn akọsilẹ. Awọn anabi di awọn okunfa ati ọna eyi ti yoo sọ wọn lọdọ ọta wọn mu, t’ohun ti pe ẹni ti a se iranlọwọ fun pẹlu isẹ Ọlọhun ati isọ lati ọdọ Ọlọhun ni wọn, Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, asiwaju awọn olugbẹkẹle Ọlọhun naa jẹ ẹni ti i maa n di awọn okunfa mu, t’ohun ti agbara igbẹkẹle rẹ si Oluwa rẹ.

Ọlọhun t’O ga sọ pe:

} وأعدوا لهم ما استطعتم من قوة ومن رباط الخيل ترهبون به عدو الله وعدوكم { [سورة الأنفال: 60].

« Ẹ pese ohun ti ẹ ba ni agbara rẹ silẹ de wọn ninu ohun-ija, ati ninu siso ẹsin mọlẹ, lati dẹruba awọn ọta Ọlọhun ati awọn ọta yin » [Suuratul-Anfaal: 60]. Ọlọhun t’O ga tun sọ pe:

} هو الذي جعل لكم الأرض ذلولا فامشوا في مناكبها وكلوا من رزقه وإليه النشور { [سورة الملك: 15].

« Oun ni Ẹni ti O se ilẹ fun yin ni irọrun, nitori naa ẹ maa rin ni awọn agbegbe rẹ, ki ẹ si maa jẹ ninu èsè rẹ. Ọdọ Rẹ si ni agbedide yin yoo jẹ» [Suuratul-Mulk: 15].

 Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”, sọ pe:

(( المؤمن القوي خير وأحب إلى الله من المؤمن الضعيف، وفي كل خير، احرص على ما ينفعك، واستعن بالله، ولا تعجز، وإن أصابك شيء فلا تقل: لو أنِّي فعلت كذا لكان كـذا، ولكن قل: قدر اللَّه وما شاء فعل، فإن لو تفتح عمل الشيطان )). رواه مسلم.

« Olugbagbọ-ododo [ti o jẹ] alagbara ni oore ju, Ọlọhun si fẹran rẹ ju olugbagbọ-ododo ti o lẹ lọ, sugbọn oore n bẹ ni ara onikaluku wọn. Maa gbiyanju lori ohun ti yoo se ọ lanfaani, ki o si maa wa iranlọwọ lọdọ Ọlọhun, ma si se ko aarẹ rara, ti nnkan kan ba wa se ọ, ma se sọ pe: Iba se pe mo ti se igbá ni, bai bai ni i ba ri; sugbọn nse ni ki o sọ pe: QADDARA -L-LAAHU WA MAA SHAA’A FA’AL “Akọọlẹ Ọlọhun -ni eleyii- ohun t’O si fẹ l’O se”, tori pe nse ni [gbolohun] iba se pe maa n si isẹ esu silẹ » [Muslim l’o gbe e jade].

 [15] Idajọ ẹni ti o tako akọsilẹ:

Ẹnikẹni ti o ba tako akọsilẹ ti tako ipilẹ kan ninu awọn ipilẹ ofin -Sharia- o si ti se aigbagbọ pẹlu eleyii. Apa kan ninu awọn asiwaju rere -ki Ọlọhun o kẹ ẹ- sọ pe: Ẹ maa fi imọ ba awọn ti wọn tako akọsilẹ -Qadariyyah- se agbeyewo, nitori naa ti wọn ba tako o, wọn se aigbagbọ, ti wọn ba si gba a, a da wọn nija ni yun un.

 [16] Awọn eso nini igbagbọ si akọsilẹ:

Nini igbagbọ si idajọ Ọlọhun ati akọsilẹ ni awọn eso daadaa kan, ati awọn oripa ti o dara, eyi ti yoo pada si ọdọ ijọ ati onikaluku pẹlu daadaa, ninu wọn ni:

a- Wi pe a maa so eso orisirisi awọn ijọsin ti o dara ati awọn iroyin ẹyin, gẹgẹ bi sise afọmọ fun Ọlọhun, ati gbigbẹkẹle E, ati bibẹru Rẹ, ati irankan, ati riro ero rere si I, ati sise suuru ati agbara amumara, ati gbigbe ogun ti isọretinu, ati yiyọnu si Ọlọhun, ati sise Ọlọhun ni àáso pẹlu ọpẹ ati didunnu si oore Rẹ ati aanu Rẹ, ati titẹriba fun Ọlọhun, Ọba t’O ga t’O si gbọn-un-gbọn, ati fifi igberaga ati motómotó silẹ. A tun maa so eso ninawo si awọn ọna rere, ni ti ifayabalẹ si Ọlọhun, ati akin ati igboya, ati ayo-ọkan, ati fifun ẹmi ẹni lọwọ, ati akolekan ti o ga, ati idurosinsin, ati igbiyanju ninu awọn nnkan, ati sise deedee ni asiko irọra ati isoro, ati bibọ lọwọ ilara, ati atako, ati gbigba awọn laakaye lọwọ awọn aforihun ati awọn irọ, ati isinmi ẹmi ati bibalẹ ọkan.

b- Wi pe onigbagbọ si akọsilẹ yoo maa lọ ninu igbesi-aye rẹ lori ilana ti o dara, tori naa idẹra kò ni i mu un yọ ayọ pọrọ, bẹẹ ni kò ni i sọ ireti nu pẹlu adanwo, yoo si ni amọdaju pe ohun ti o sẹlẹ si i ninu inira, pẹlu akọsilẹ Ọlọhun l’o se sẹlẹ ni ti adanwo. Nitori naa kò ni i bara jẹ, sugbọn yoo maa se suuru, yoo si maa reti ẹsan lọdọ Ọlọhun.

d- Wi pe a maa se isọ nibi awọn okunfa anu, ati atunbọtan buburu, nigba ti o se pe yoo maa bi iyanju gbogbo igba lori atidurodeedee, ati sise awọn ise rere lọpọlọpọ, ati jijinna si awọn ẹsẹ ati awọn ohun ti i maa n fa iparun.

e- Wi pe a maa so eso idojukọ awọn isoro ati awọn ibẹru pẹlu ọkan ti o rinlẹ fun awọn olugbagbọ-ododo, ati amọdaju pipe, pẹlu sise awọn okunfa.

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a” sọ pe:

(( عجبا لأمر المؤمن، إن أمره كله له خير، وليس ذلك إلا للمؤمن، إن أصابته سراء شكر، فكان خيراً له، وإن أصابته ضراء صبر، فكان خيراً له )). [رواه مسلم].

« Iyalẹnu ni ọrọ olugbagbọ-ododo, dajudaju rere ni gbogbo ọrọ rẹ jẹ fun un, eleyii kò si si fun ẹnikan yatọ si olugbagbọ-ododo, bi idẹra ba ba a, yoo dupẹ, nitori naa yoo jẹ rere fun un, ti inira ba si se e, yoo se suuru, nitori naa yoo jẹ rere fun un » [Muslim l’o gbe e jade].