Àwọn Origun Ẹsin Islãm ()

 

Àwọn Origun Ẹsin Islãm

|

 Àwọn Origun Ẹsin Islãm

أركان الإسلام  بلغة اليوروبا

 Ọrọ Isãju

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, ikẹ ati ọla ki o maa ba igbẹyin awọn annabi, Annabi wa Muhammad ọmọ 'Abdullahi ﷺ‬. Lẹhin na:

Dajudaju titan awọn imọ ẹsin Islam ka o ni ipa kan ti o tobi l'ori sise alaye papa ẹsin Islam, ati fifi idi awọn opo ẹsin rinlẹ, ati mimu ilọsiwaju ba ijọ (Musulumi). Eleyi jẹ ero ngba nla, ohun naa ni ile ẹkọ giga ti Islam (Islamic University) n sapa lati se pẹlu ipepe ati ikọnilẹkọ.

Ni ifọwọsowọpọ l'ori eyi ni ile isẹ ti n se amojuto iwadi imọ-ijinlẹ ni ile ẹkọ yii fi dide lati se ọna ati igbesẹ kalẹ l'ori ọpọlọpọ ninu awọn isẹ adawọle ti o jẹ ti imọ, ninu rẹ ni sise iwadi ti o jinlẹ nipa Islam ati awọn daada ti o gbe wa, ati sise afọnka rẹ, lati le fun awọn ọmọ Musulumi ni imọ ti o peye nipa ẹsin wọn, adisọkan rẹ, pẹlu awon ofin rẹ.

Iwadi yi ti o da le ori (Awọn Origun Islam) jẹ ọkan ninu awọn igbesẹ ile işẹ yi, nitori naa ni o fi pe apakan ara awọn olukọ ni ile ẹkọ giga yi ki wọn kọ nkankan nipa origun Islam, lẹyin naa ni o tun wa gbe awọn ikọ kan dide ni ile işẹ naa lati se ayẹwo nkan ti wọn kọ, ki wọn si se atunse ti o yẹ l'ori rẹ ki wọn si gbee jade, ki wọn si gbiyanju lati maa mu ẹri wa lati inu Al-Qur'an ati Sunna (Ilana Annabi) l'ori gbogbo ọrọ imọ ti wọn ba mu ẹnu ba.

Ile işẹ yi n se ojukokoro – lati bi iwadi yi – lọ si ibi fifun awọn ọmọ Musulumi jakejado aye ni anfaani lati ni imọ ẹsin ti o peye ti o ni anfaani. Nitorinaa l'ofi dide lati maa tumọ awọn iwadi naa si awọn ede ti o pọ l'aye, ki o si maa pin wọn kaakiri, ki o si fi si ori ẹrọ imọ agbaye (Intanẹti).

Nipa bayi, awa n bẹ Ọlọhun (ti Ọla Rẹ ga) ki o san ijọba Ilẹ Saudi Arabia l'ẹsan l'ori awọn igbiyanju ti kò ja ti kò yẹ ni igba kankan nipa sise ẹrusin ẹsin Islam, ati titaan ka, ati didaabo bo, ati l'ori amojuto rẹ fun ile ẹkọ giga yi.

Bakanna ni a tun n bẹ Ọlọhun ki O jẹ ki iwadi yi se anfaani, ki O si fi alubarika si, ki o tun wa fi wa se kongẹ lati gbe eyi ti o sẹku ninu awọn işẹ ile işẹ yi jade. Bakanna atun bẹ Ọlọhun ki o fi gbogbo wa se kongẹ lọ si ibi nkan ti oun Ọlọhun yọnu si, ti o si wu ﷻ‬. Ki o si fi wa sinu awọn olupepe imọna ati oluran ododo lọwọ.

Ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ ati alubarika fun ẹru Rẹ ati ojişẹ Rẹ Annabi wa Muhammad, ati awọn ara ile rẹ, ati awọn saabe rẹ.

Ile Işẹ Iwadi Imọ-Ijinlẹ.

Origun-kinin: Ijẹri pe ko si ẹniti a gbọdọ jọsin fun ni ododo afi Ọlọhun, ati pe (Annabi) Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni:

Awọn ijẹri mejeeji yi ni oju ọna ati wọ inu ẹsin Islam, awọn naa si tun ni origun Islam ti o tobi julọ, a ko lee pe enian ni Musulumi afi ki o wi gboloun mejeeji yi, ki o si tun sişẹ pẹlu itumọ gboloun yi, pẹlu bayi ni Keferi yoo fi di Musulumi.

 1-Itumọ Ijẹri pe ko si ẹniti a le jọsin fun ni ododo afi Ọlọhun:

Ohun ni wiwi gboloun yi pẹlu mimọ itumọ rẹ, ati sişe işẹ pẹlu n kan ti o ko si inu ni ọkankan ati ni kọrọ.

Sugbọn wiwi lasan lai mọ itumọ rẹ, ati lai şe işẹ pẹlu n kan ti o ko sinu, eleyiun ko lee wulo pẹlu apanupọ awọn alufa, koda yoo tun jẹ awi jare le onitọhun l'ori.

Itumọ (LA ILAHA ILA ALLAHU): ni: Ijẹri pe ko si ẹniti a le jọsin fun ni ododo afi Ọlọhun kan soso ti O mọ ti O si ga.

Origun meji ni o wa fun gboloun yi: Lile ijọsin jina si gbogbo nkan ti o yatọ si Ọlọhun, ati fifi ijọsin fun Ọlọhun nikan soso, ko si orogun fun. Bakan naa ni o tun ko kikọ ti èsù (Tọgŭt) sinu, ikoria rẹ ati pipaati patapata. Esu (Tọgŭt) ni ohunkohun gẹgẹ bi: enian, okuta, igi, ìfęę nu, tabi adun ti o yọnu si ki eniyan maa jọsin fun oun lęyin Ọlọhun. Ęnikęni ti o ba wi gbolohun yi, şugbọn ti o si tun ni igbagbọ si èsù (Tọgŭt) yi lęyin Ọlọhun, ko ti i mu gbolun yi wa bi o ti tọ ati bi o ti yę.

Ọlọhun sọ bayi pe:

]وَإِلَهُكُم إِلَهٌ وَاحِدٌ لا إِلَهَ إلاّ هُوَ الرَّحْمَنُ الرَّحيم[، [سورة البقرة، الآية: 163].

[Ọlọhun yin, Ọlọhun kanşoşo ni; ko si Ọlọhun miran ayafi Oun. Ajọkę-aye, Aşakę-ọrun]. [Suratul-Bakọrah 2, ãyat: 163].

Ọlọhun tun sọ bayi pe:

]لاَ إِكْرَاهَ فِي الدِّين قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الغَيِّ فَمَنْ يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِن بِاللهِ فَقَدْ اسْتَمْسَكَ بِالعُرْوَةِ الوُثْقَى لا انْفِصَامَ لَهَا وَاللهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ.[ [سورة البقرة، الآية: 256].

[Kò si ifi agbara mu ni ninu ẹsin. Ọna otitọ ti farahan kuro ninu ọna işina. Nitorina ẹni ti o ba kọ èsù (Tọgŭt) ti o si gba Ọlọhun gbọ, onitọun ti gba okun ti o yi ti kòle e ja mu. Ọlọhun ni Olugbọ, Olumọ]. [Suratul-Bakọrah 2, ãyat: 256].

Itumọ (Al-ilah) ni Ọba ti aa jọsin fun l'ododo. Ẹnikẹni ti o ba ni adisọkan wipe itumọ (Al-ilah) ni: Ọba Adẹda, Oluşearisiki, tabi Ọba ti O l'agbara lati mu nkan ọtun-ọtun jade, ti o si ni igbagbọ wipe eleyi nikan naa tito ni gbibga Ọlọhun gbọ (Imọni) lai şe Ọlọhun l'ọkan pẹlu jijọsin fun, iru ẹni bẹ ẹ gbolohun (LA ILAHA ILA ALLAHU) ko le e şe ni anfaani, ko le e fi wọ inu ẹsin Islam l'aye n bi, ko si lèe gba a la kuro nibi iya gbere ni ọjọ ikẹyin.

Ọlọhun tun sọ bayi pe:

]قُلْ مَنْ يَرْزُقُكُم مِّنَ السَّمَاءِ والأَرْضِ أَمَّنْ يَمْلِكُ السَّمْعَ والأَبْصَارَ وَمَنْ يُخْرِجُ الحَيَّ مِنَ المَيِّتِ وَيُخْرِجُ المَيِّتَ مِنَ الحَيِّ وَمَنْ يُدَبِّرُ الأَمْرَ فَسَيَقُولُونَ اللهُ فَقُلْ أَفَلاَ تَتَّقُونَ[، [سورة يونس، الآية: 31].

[Wipe: Taani nfun yin ni ijẹ ati imu lati sanma ati ilệ, tabi taani ẹniti o kapa igbọran ati iriran, tabi taani nfa alãye jade lati inu oku, tabi ti nfa oku jade lati inu alãye? Tabi taani nfi etò si gbogbo nkan? Nwọn o wipe: Ọlọhun ni. Wipe: Ẹyin kò ha ni paya (Rệ) ni?]. [Suratul-Yũnusa 10, ãyat: 31].

Ọlọhun sọ bayi pe:

]أَمَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ والأَرْضَ وَأَنْزَلَ لَكُم مِّنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنْبَتْنَا بِهِ حَدَائِقَ ذَاتَ بَهْجَةٍ مَّا كَانَ لَكُم أَنْ تُنْبِتُوا شَجَرَهَا أَإِلَهٌ مَعَ الله بَلْ هُمْ قَوْمٌ يَعْدِلُونَ[، [سورة النّمل: الآية: 60].

[Tabi ẹniti O şe ẹda sanma ati ilệ ti O si nsọ omi kalệ lati sanma ti A si nfi omi naa hu awọn ọgba oko ti o dara jade, ko si agbara fun yin lati mu igi rệ hu jade. Njẹ oluwa kan ha mbẹ pẹlu Ọlọhun bi? Bẹẹ tiẹ kọ, awọn ni ijọ kan ti wọn nwa orogun fun (Ọlọhun)]. [Suratul-Namli 27, Ayat 60].

Ọlọhun tun sọ bayi pe:

]وَلَئِنْ سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَهُم لَيَقُولُنَّ الله فَأَنَّى يُؤْفَكُون[، [سورة الزخرف، الآية: 87].

[Atipe bi o ba bi nwọn leere wipe taani ẹniti o da wọn, dajudaju wọn yio sọ wipe: Ọlọhun ni. Nitorina kinişe ti wọn fi nşẹri (kuro nibi ododo)].[Suratul-Zukhruf 43, ãyat: 87].

 2- Awọn Mọjẹmu Gboloun Taoheed (Imọ Ọlọhun l'ọkan):

1-Mimọ itumọ rẹ - ni ile - jinna ni, ati ni fifi rinlẹ - eyi ti o lodi si aimọkan, ti yoo lé ijọsin fun ohun ti o yatọ si Ọlọhun jina, ti yoo si şe ijọsin fun Ọlọhun nikan lai wa orogun fun. Kosi ẹni ti ijọsin tọsi yatọ si Ọlọhun.

2-Amọdaju ti yoo lé Iyemeji jina. Eleyi un nipe ki o wi gboloun yi pẹlu amọdaju, ki ọkan rẹ si balẹ pẹlu rẹ, ni ẹni ti o gba itumọ rẹ gbọ pẹlu amọdaju ti o jinlẹ.

3-Gbigba wọle ti yoo lé aiko gba jina. Eleyi un nipe ki o gba gbogbo n ti gbolohun yi ko si inu gbọ pẹlu ọkan rẹ ati ahan rẹ, ki o si gba awọn ìró (ti Ọlọhun tabi Ojisẹ Rẹ) fun wa ni ododo, ki o mọọ tẹle awọn aşẹ, ki o si mọọ jina si awọn eewọ, ki o si mọ se tako awọn ẹri, tabi yi itumọ won pada.

4-Igbafa ti yoo lé aiko gbafa jina. Eleyi un nipe ki o gbafa fun itumọ gboloun yi ni ọkankan ati ni kọkọ.

5-Ododo ti yoo lé irọ jina. Eleyi un nipe ki enia o wi gboloun yi ni ododo ti o ti ọkan wa, ki ohun ti o wa l'ọkan rẹ o ba eyi ti ahan rẹ n sọ mu, ki ikọkọ rẹ si ba ọkankan rẹ mu.

Ẹnikẹni ti o ba wi gbolun yi pẹlu ahan rẹ şugbọn ti ọkan rẹ ko gba a gbọ, gboloun yi ko lee se iru ẹni bẹẹ ni anfaani, o da gẹgẹ bi awọn Munafiki ti wọn n wi gboloun yi pẹlu ahan wọn lasan ti ko si de ọkan wọn.

6-Afọmọ (Al-ikhlas) ti yoo lé iwa orogun (fun Ọlọhun) jina. Ohun naa ki Ẹru o şe afọmọ işẹ rẹ pẹlu aniyan ti o dara kuro nibi awọn orisi iwa orogun pẹlu Ọlọhun.

Ẹri l'ori elesyi ni ọrọ Ọlọhun ti O sọ bayi:

]وَمَا أُمِرُوا إَلاَّ لِيَعْبُدُوا الله مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّيْنَ حُنَفَاءَ[، [سورة البيّنة، الآية: 5].

[A kò pa wọn laşẹ ju pe ki wọn jọsin fun Ọlọhun lọ, ki wọn o si fọ ẹsin mọ fun ﷻ‬]. [Suratu Bayyinah 98, ãyat: 5].

7-Ifẹ ti yoo lé aiko fẹ jina. Eleyiun ni pẹlu ninifẹ gboloun yi ati gbogbo ohun ti o ko sinu, ati awọn n kan ti o da le l'ori, ati nini ifẹ awọn eniyan rẹ ti wọn dunni mọ awọn mọjẹmu rẹ, ki o si korira gbogbo ohun ti o ba tako eleyiun. Ami eleyin ni ki ifẹ Ọlọhun o gbawa ju lọdọ rẹ, koda bi o yapa ifẹẹ inu tirẹ, ki o si binu si gbogbo oun ti Ọlọhun ba n binusi, koda bi ifẹ inu rẹ ba lọ si ibẹ, ki o si maa şe ti awọn ti wọn se ti Ọlọhun ati ojişẹ Rẹ, awọn ti wọn ba si n tako ti Ọlọhun  ati ojişẹ Rẹ, ki o mu wọn ni ọta.  

Ẹri l'ori eleyi ni ọrọ Ọlọhun ti O sọ bayi:

]قَدْ كَانَتْ لَكُم أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ فِي إِبْرَاهِيمَ والَّذِينَ مَعَهُ إِذْ قَالُوا لِقَوْمِهِمْ إَنَّا بُرَاءُ مِنْكُم وَمِمَّا تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ الله كَفَرْنَا بِكُم وَبَدَا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ العَدَاوَةُ وَالبَغْضَاءُ أَبَداً حَتَّى تُؤْمِنُوا بِاللهِ وَحْدَه[[سورة الممتحنة، الآية :4].

[Dajudau ikọşe rere ti wa fun yin ni ara Ibrahima ati awọn ẹniti o pẹlu rệ, nigbati wọn wi fun awọn enian wọn pe: Dajudaju awa mu ori bọ kuro ni ọdọ yin ati kuro ninu ohun ti ẹ nsin lẹyin Ọlọhun. A ti kọ tiyin, ọta ati ibinu ti han ni aarin wa ati ni aarin yin titi lailai ayafi ti ẹ ba gba Ọlọhun kanşoşo gbọ]. [Suratu Mumtahinah 60, ãyat: 4].

Ẹri l'ori eleyi ni ọrọ Ọlọhun ti O sọ bayi:

]وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يَتَّخِذُ مِنْ دُونِ اللهِ أَنْدَاداً يُحِبُّونَهُم كَحُبِّ اللهِ والَّذِيَن آمَنُوا أَشَدُّ حُبّاً للهِ[ [سورة البقرة، الآية: 165].

[O si mbẹ ninu awọn enian ti won mu awọn nkan miran (ni isin) laijẹ Ọlọhun ni ẹgbẹra (Ọlọhun); wọn nfẹran wọn gẹgẹbi ifẹ ti wọn ni si Ọlọhun, sugbọn awọn ti wọn gba Ọlọhun gbọ l'ododo le-koko ni iferan si Ọlọhun]. [Suratul-Baqarah 2, Ayat 165].

Ẹnikẹni ti o ba wi (LA ILAHA ILA ALLAHU) pẹlu afọmọ ati imọdaju, ti o si jina si ẹbọ nla ati kekere, ati awọn adadasilẹ (bid'an), ati awọn ẹşẹ, dajudaju imọna ti wa fun iru ẹnibẹẹ kuro nibi anu laye, ifọkan-balẹ kuro nibi iya si ti wa fun, ina si şe ewọ fun pẹlu.

Pipe awọn mọjẹmu yi pọn dandan fun enian, itumọ pipe rẹ ni ki gbogbo rẹ kojọ si ara enian, ki o si dunni mọ, sugbọn ko pọn dandan fun ki o ha sori. 

Gboloun apọnle yii (LA ILAHA ILA ALLAHU) ohun gan an ni (Taoheedul Uluiyat), Ise Ọlọhun l'ọkan pẹlu ijọsin, ohun naa ni ẹya Taoheed ti o se pataki ju, ibẹ si ni iyapa ti waye lãrin awọn Anọbi ati lãrin awọn ijọ wọn, nitori Taoheed naa ni Ọlọhun fi ran awọn ojişẹ, gẹgẹbi Ọlọhun ti sọ ninu Al-Qurãn pe:

]وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَسُولاً أَنِ اعْبُدُوا اللهَ وَاجْتَنِبُوا الطَّاغُوتَ[. [سورة النحل، الآية: 36].

[Atipe dajudaju A ti gbe ojişẹ kộkan dide ninu ijọ kộkan (pe): Ki ẹ şin Ọlọhun ki ẹ si jinna si awọn orisa]. [Suratul Nahli 16, ãyat:36].

Ọlọhun tun sọ pe:

]وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلاَّ نْوحِي إِلِيْهِ أَنَّهُ لا إِلَهَ إِلاَّ أَنَا فَاعْبُدُونِ[. [سورة الأنبياء، الآية: 25].

[Atipe Awa kò ran ojişẹ kan nişẹ şiwaju rẹ ayafi ki A ranşẹ si i pe: dajudaju kò si Ọlọhun kan ayafi Emi, nitorina ki ẹ ma sin Mi]. [Suratul-Anbiyãi 21, ãyat: 25].

Ni gbogbo igba ti orukọ "Taoheed" yi bati waye lai ko se adayanri kankan, Taoheedul Uluiyat ti a n sọrọ rẹ yi ni o tun mọ si.

-Itumọ rẹ: Taoheedul Uluiyat, ohun ni: Ifirinlẹ pe: Ọlọhun ni O ni iwari fun ati ijọsin fun l'ori ẹda Rẹ lapapọ, ati sişe ijọsin fun Oun nikan laisi orogun fun Un.

-Awọn orukọ rẹ: Wọn n pe Taoheed yi ni Taoheedul Uluiya tabi Al-ilahiyat, nitoripe o duro l'ori işe afọmọ ijọsin (ohun ni ifẹ gidi) fun Ọlọhun  nikan. O tun ni awọn orukọ miran bii:

a- Taoheedul-ibaadat, tabi Al-'ubudiyat, nitoripe o duro l'ori sişe afọmọ ệsin fun Ọlọhun nikan.

b- Taoheedul-iraadat (sişe ero n gba l'ọkan si Ọlọhun) nitori pe o duro lori wiwa oju rere Ọlọhun pẹlu işẹ.

d- Taoheedul-qọsd (sişe gbigbero l'ọkan si Ọlọhun), nitori pe o duro l'ori isafọmọ gbigbero ti o tulasi sişe ijọsin l'ọkan fun Ọlọhun nikan.

e- Taoheedul-tọlab (sişe bibeere l'ọkan lọsi ọdọ Ọlọhun), nitori pe o duro l'ori isafọmọ bibeere nkan lọ si ọdọ Ọlọhun nikan.

ẹ- Taoheedul-amọl (sişe işẹ l'ọkan), nitori pe o duro l'ori sişe afọmọ işẹ fun Ọlọhun nikan.

-Idajọ rẹ: Taoheedul-uluiyat, Ọranyan ni l'ori awọn ẹnian, ẹnikan ko le wọ inu Islam afi pẹlu rẹ, ẹnikan ko si lee la kuro ni ibi ina afi pẹlu adisọkan rẹ ati sişe e nişẹ. Ohun ni akọkọ ohun ti o se ọranyan l'ori ẹni ti o depo balaga ki o ni adisọkan rẹ ki o si şişee ni isẹ, ohun naa si ni akọkọ ohun ti eniyan (olupepe si oju ọna Ọlọhun) yoo fi bẹrẹ nibi da'wa (ipepe) rẹ, ati nibi idani lẹkọ, yatọ si ti awọn miran ni l'ọkan. Ohun ti o ntọka si ijẹ ọranyan yi ni aşẹ ti o wa l'ori rẹ ninu Tira (Al-Qurãn) ati Sunna (Annabi), atipe nitori rẹ ni Ọlọhun fi da ẹda Rẹ l'osi fi sọ awọn tira kalẹ pẹlu.

Ọlọhun sọ pe:

]قُلْ إِنَّمَا أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ اللهَ وَلاَ أُشْرِكَ بِهِ إِلَيْهِ أَدْعُو وَإِلِيهِ مَآب[. [سورة الرعد، الآية: 36].

[Wipe: Ohun ti a pa mi l'asẹ nikan ni pe ki emi maa sin Ọlọhun atipe ki n ma şe da nkankan pọ mọ On. Emi n pe yin si ọdọ Rệ atipe ọdọ Rệ ni apadasi]. [Suratul Ra'du 13, Ayat 36].

Ọlọhun tun sọ pe:

]وَمَا خَلَقْتُ الجِنَّ والإِنْسَ إِلاَّ لِيَعْبُدُونِ[[سورة الذّاريات، الآية:56].

[Atipe Emi kò şe ẹda alijọnu ati enian lasan ayafi ki nwọn le mã sin Mi]. [Suratu Dhãriyati 51, ãyat: 56].

Annabi ﷺ‬ sọ fun Mu'adh t pe:

((إنّك تأتي قوماً من أهل الكتاب فليكن أوّل ما تدعوهم إليه شهادة أن لا إله إلاّ الله، فإن هم أطاعوك لذلك فأعلمهم أن الله افترض عليهم خمس صلوات في كلّ يوم وليلةٍ؛ فإن هم أطاعوك لذلك فأعلمهم أن الله افترض عليهم صدقة تؤخذ من أغنيائهم فترد على فقرائهم...)[الحديث أخرجه البخاري ومسلم].

 ((Dajudaju iwọ n lọ si ọdọ ijọ kan ninu awọn ti afun ni Tira, ijẹri pe ko si Ọba kan ti o too jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun (LA ILAHA ILA ALLAHU) ni ki o jẹ akọkọ ohun ti o pe wọn si, ti wọn ba tẹleọ l'oriẹ, fi mọwọn pe Ọlọhun şe irun wakati marun l'ọranyan lewọn l'ori ni ọsan ati oru, ti wọn batun tẹleọ l'oriẹ, fimọwọn pe Ọlọhun şe zakat l'ọranyan l'ori wọn, wọn o mọ mu ninu owo awọn olowo wọn fun awọn aliani wọn…)). [Hadith yi Bukahry ati Muslim ni wọn gbaa wa].

Taoheed yi ni işẹ ti o ni ọla julọ, ohun si ni o tobi ju ni pipa ẹsẹ rẹ, Koda Bukhary ati Muslim gbaa wa ninu hadith 'Utban t ti o se afiti rẹ si Annabi pe:

فقد أخرج البخاري ومسلم من حديث عتبان t مرفوعاً: ((فإن الله حرم على النار من قال: لا إله إلاّ الله يبتغي بذلك وجه الله)).

((Dajudau Ọlọhun ti şe ina l'eewọ fun ẹni ti o ba wi (LA ILAHA ILALLAHU) ti o nwa oju rere Ọlọhun pẹlu rẹ)). 

Ipanupọ awọn Ojişẹ l'ori gboloun Taoheed:

Gbogbo awọn ojişẹ l'apapọ ni wọn papọ l'ori pipe awọn ijọ wọn lọ si ibi gboloun (LA ILAHA ILALLAHU) ti wọn si dẹru bawọn fun abruru ti o wa nibi lilodi sii, gẹgẹ bi Al-Qurãn Alapọnle ti şe alaye rẹ ninu ọpọlọpọ Aayat.

Ọlọhun sọ bayi pe:

]وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلاَّ نْوحِي إِلِيْهِ أَنَّهُ لا إِلَهَ إِلاَّ أَنَا فَاعْبُدُونِ[. [سورة الأنبياء، الآية: 25].

[Atipe Awa kò ran ojişẹ kan nişẹ şiwaju rẹ ayafi ki A ranşẹ si i pe: dajudaju kò si Ọlọhun kan ayafi Emi, nitorina ki ẹ ma sin Mi]. [Suratul-Anbiyãi 21, ãyat: 25].

وقد ضرب الرسول ﷺ‬ مثلاً لاتفاق الأنبياء في الدّعوة إليها، حيث بيَّن u أن الأنبياء إخوة لعلات، أمهاتهم شتى ودينهم واحد، فأصل دين الأنبياء واحد وهو التوحيد وإن اختلفت فروع الشرائع كما أن الأولاد قد يختلفون في الأمهات وأبوهم واحد.

Koda Ojişẹ Ọlọhun u se apejuwe pipapọ awọn Annabi l'ori ipepe lọ si ibi (LA ILAHA ILALLAHU) ni igbati o şe alaye u wipe awọn Annabi (da gẹgẹ bi) ọmọ baba kan na, ti iyawọn yatọ, sugbọn ikan soso ni ệsin wọn. Nitorinaa, ipilẹ ẹsin awọn Annabi ikan soso ni, ohun naa ni Taoheed (imọ Ọlọhun l'ọkan), bi o tilẹ jẹ wipe awọn ẹtuntun shari'at wọn yatọ, gẹgẹ bi o ti jẹ wipe iya awọn ọmọ le yatọ sugbọn baba wọn ikan naa ni.

 3- Itumọ ijẹripe (Annabi) Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni:

a- Itumọ ijẹri pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni: titẹle aşẹ ẹ rẹ ati igba nkan ti o ba sọ l'ododo, ati ijinansi nkan ti o kọ fun wa ti o si kilọ fun wa, a ko si gbọdọ sin Ọlọhun afi pẹlu n kan ti o mu wa.

b- Mimu ijẹri pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni sẹ:

Ijẹri pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni yoo mọ sẹlẹ pẹlu Imọni (igbagbọ) ati amọdaju pe Muhammad ﷺ‬ ẹru Ọlọhun ati ojişẹ Rẹ ni, Ọlọhun ran si Alijanu ati eniyan patapata, atipe ohun ni ipẹkun awọn Annabi ati igbẹyin awọn ojişẹ. Atipe ẹru ti osun mọ Ọlọhun ni i se, ko si n kankan l'ara awọn ẹşa ijẹ Ọlọhun l'ara rẹ. Imọ tẹle e ﷺ‬ ati sişe apọnle aşẹ rẹ ati ohun ti o kọ fun wa ati idunimọ oju ọna rẹ l'ọrọ, ni işẹ, ati ni adisọkan. 

Ẹri l'ori eleyi ni ọrọ Ọlọhun ti o sọ pe:

]قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنِّي رَسُولُ الله إِلَيْكُم جَمِيعاً[. [سورة الأعراف، الآية 158].

[Wipe: Ẹyin enian, dajudaju emi ni ojişẹ Ọlọhun si gbogbo yin]. [Suratul A'rãf 7, ãyat: 158].

Ọlọhun tun sọ pe:

]وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلاَّ كَافَّةً لِلنَّاسِ بَشِيراً وَنَذِيراً[. [سورة سبأ، الآية: 28].

[Atipe Awa kò ran ọ nişẹ ayafi si gbogbo enian ni olufunni niro idunnu ati olukilọ]. [Suratul Sabai 34, ãyat: 28].

Ọlọhun tun sọ pe:

]مَا كَانَ مُحَمَّدٌ أَباً أَحَدٍ مِّن رِجَالِكُمْ وَلَكِنْ رَسُولَ الله وَخَاتَمَ النَّبِيِّينَ[. [سورة الأحزاب، الآية: 40].

[Muhammad ki i şe baba ẹnikankan ninu awọn ọkunrin yin, şugbọn (o jẹ) Ojişẹ Ọlọhun ati ipẹkun awọn annabi]. [Suratu Ahsãbu 33, ãyat: 40].

Ọlọhun tun sọ pe:

]قُلْ سُبْحَانَ رَبِّي هَلْ كُنْتُ إِلاَّ بَشَراً رَّسُولاً[. [سورة الإسراء، من الآية: 93].

[Sọpe: Mimọ Oluwa mi, emi kò jẹ nkankan ju abara, ojişẹ lọ]. [Suratl Isrãi 17, ãyat: 93].

Eleyi ko awọn ọpọ ọrọ sinu:

Ẹkinnin: Fifi ijẹ ojişẹ Annabi rinlẹ, pẹlu gbigba pe lootọ ni Ọlọhun ran an nisẹ, ati adisọkan bẹẹ ni ikọkọ ati ọkankan.

Ẹlẹẹkeji: Wiwi bẹ ati ijẹri bẹẹ l'ori ahan.

Ẹkẹẹta: Titẹ le e (Annabi) pẹlu sişẹ işẹ pẹlu ododo ti o mu wa, ati fifi gbogbo ibajẹ ti o kọ silẹ.Ọlọhun sọ bayi pe:

]فَآمِنُوا باللهِ وَرَسُولِهِ النَّبِيِّ الأُمِّيِّ الذَّي يُؤْمِنُ بِاللهِ وَكَلْمَاتِهِ وَاتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ[. [سورة الأعراف، من الآية: 158].

[Nitorina ki ẹ gba Ọlọhun naa gbọ ati Ojişẹ Rẹ, Annabi ti kò mọ ọ kọ, ti kò mọ ọ ka ẹniti o gba Ọlọhun gbọ ati ọrọ Rẹ, ẹ tẹle e ki ẹ le baa mọ ọna]. [Suratu A'rãfi 7, ãyat: 158].

Ẹlẹẹkẹrin: Gbigba a (Annabi ﷺ‬ l'ododo nibi awọn iro ti o mu wa.

Ẹkãrun: Inifẹ rẹ ju ifẹ ara ẹni lọ, ti yoo si ju ifẹ owo, ọmọ, obi, ati gbogbo eniyan lọ, tori wipe ohun ni ojişẹ Ọlọhun, atipe ninifẹ rẹ wa ninu inifẹ Ọlọhun, ati nitori ti Ọlọhun. 

Paapa inifẹ rẹ ni: titẹ le e pẹlu titẹ le awọn aşẹ rẹ, jinjinna si awọn nkan ti o kọ, ati riran an lọwọ ati sişe tirẹ.

Ọlọhun sọ bayi pe:

]قُلْ إِنْ كُنْتُمْ تُحِبُّونَ اللهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ[. [سورة آل عمران، من الآية: 31].

[Wipe: Bi ẹyin ba jẹ ẹniti o fẹran Ọlọhun, ẹ tẹle mi, Ọlọhun yio fẹran yin, yoo si fi ori awọn ẹşẹ yin jin yin]. [Suratu Ãli-Imrana 3, ãyat: 31].

Annabi ﷺ‬ sọ bayi pe:

((لا يؤمن أحدكم حتّى أكون أحب إليه من والده وولده والناس أجمعين)). [متّفق عليه من حديث أنس t].

 ((Ẹnikẹni ko le ti i ni igbagbọ afi ti ki o jẹ wipe emi (Annabi) ni onitọun fẹran ju baba rẹ lọ, ju ọmọ rẹ lọ, ati ju gbogbo eniyan lapapọ lọ)). [Bukhary ati Muslim panupọ lee l'ori lati Adith Anas].

Ọlọhun tun sọ bayi pe:

]فَالَّذِينَ آمَنُوا بِهِ وَعَزَّرُوهُ وَنَصَرُوهُ واتَّبَعُوا النُّورَ الَّذِي أُنْزِلَ مَعَهُ أُولَئِكَ هُمُ المُفْلِحُونَ[. [سورة الأعراف، من الآية: 157].

[Nitorina awọn ti o ba gba a gbọ ti wọn si bu ọwọ fun un, ti nwọn si raan l'ọwọ ti nwọn si tẹle imọlẹ ti a sọ kalẹ pẹlu rẹ, awọn eleyiun ni wọn o jere]. [Suatu A'rãf 7, ãyat: 157].

Ẹkẹẹfa: Ini adisọkan pe sunah (Ilana) rẹ ﷺ‬ jẹ ipilẹ fun ofin Islam (Shariah), atipe o da bi Al-Qurãn Alapọnle, nitorina a o gbọdọ fi laakare tako o.

Ẹkeeje: Işişẹ pẹlu sunna rẹ, fifi ọrọ rẹ siwaju gbogbo ọrọ abara, gbigbafa fun, ati lilo ofin rẹ pẹlu yiyọ nu si.

Ọlọhun sọ bayi:

]فَلاَ وَرَبِّكَ لاَ يُؤْمِنُونَ حَتَّى يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ لا يَجِدُوا فِي أَنْفُسِهِم حَرَجاً مِّمَّا قَضَيْتَ وَيُسَلِّمُوا تَسْلِيماً[. [سورة النّساء، الآية: 65].

[Şugbọn wọn ko şe bẹ, Mo fi Oluwa rẹ bura, wọn ko ni gbagbọ titi wọn yoo fi fi ọ şe onidajọ nipa ohun ti nwọn nşe ariyanjiyan si lãrin wọn, lẹhin naa ti wọn ko ri ohun ti ọkan wọn kọ ninu ohun ti o da l'ẹjọ, wọn yio gba tọwọ-tẹsẹ]. [Suratu-Nisãi 4, ãyat: 65].

 4- Ọla ijẹri mejeeji yi: (Pe ko si Ọba kan ti a gbọdọ jọsin fun l'odo afi Ọlọhun,  atipe Annabi Muhammad ojisẹ Rẹ ni):

Ọla gboloun Taoheed (imọ Ọlọhun l'ọkan) yi tobi pupọ, awọn ọpọ ẹri lati inu Al-Qurãn ati Sunna l'owa fun, niuẹ ni:

a- Ohun ni origun Islam akọkọ, ohun naa sini ipilẹ ẹsin, ati pe ohun ni akọkọ ohun ti eniyan fi n wọ inu Islam, pẹlu rẹ ni sanman ati ilẹ fi duro.

b- Pẹlu ijẹri mejeeji yi ni sişe Ọlọhun - ti O ga ti O gbọngbọn - ni ọkan, ati lilo ofin Annab rẹ ﷺ‬ yoo fi kojọ.

d- Ijẹri mejeeji yi ni okunfa ati sọ ẹjẹ ati dukia di eewọ, gbogbo ẹni ti o ba wi ti sọ ẹjẹ rẹ ati dukia rẹ di eewọ.

e- Gboloun (LA ILAHA ILALLAH) ni işẹ ti o ni ọla julọ, ti o si tobi ju ni pipa ẹşẹ rẹ, ti o si tẹwọn ju ni ọjọ agbende. Ohun ni okunfa wiwọ Aljanna, ati lila kuro nibi ina. Koda ti a ba gbe sanma mejeeje ati ilẹ mejeeje si ori iwọn ti a si gbe LA ILAHA ILALLAH si ori iwọn, LA ILAHA ILALLAH ni yoo tẹ iwọn.

Muslim gba ẹgba wa lati ọdọ 'Ubadat ti ose afiti rẹ si Annabi pe:

((من شهد أن لا إله إلاّ الله وأن محمّداً عبده ورسوله حرَّم الله عليه النار)).

((Ẹnikẹni ti o ba jẹri wipe ko si n kan ti a le jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, ati pe Annabi Muhammad ẹru Ọlọhun ni ojişẹ Rẹ situn ni, Ọlọhun ti sọ ina di ewọ fun iru ẹni bẹẹ)).

ẹ- Atipe dajudau iranti, adua ati ẹyin ko jọ si inu gboloun yi. O si ko adua ijọsin ati adua ibeere sinu. Ohun ni opọju ninu awọn iranti ni riri, ti o si rọrun lati wa. Nitorina, ohun ni gboloun ti o dara, okun ti oyi, ati gboloun Ikhlas (Ise-afọmọ). Ohun naa ni sanma ati ilẹ duro pẹlu rẹ, ni itori rẹ ni Ọlọhun fi da awọn ẹda rẹ, ti O si ran awọn ojişẹ, ti O si sọ awọn tira kalẹ, O si pee pẹlu sişe sunna ati ọranyan l'ofin, nitori rẹ ni afi n yọ ida ijagun si oju ọna Ọlọhun (Jihad). Ẹnikẹni ti o ba wi i, ti o si muu lo l'otitọ pẹlu afọmọ, gbigbagbọ, ati inifẹ sii, Ọlọhun yoo mu wọ Alijanna ti ohun ti bi işẹ ti o ba şe tile  wu ki o ri.


 Origun-keji: Al-Sọlat (Irun)

Ọrọ Irun tobi pupo niun awọn ijọsin, ti ẹri rẹ si han ju, Islam şe akolekan rẹ, o si mun oju too pupọ, nitoribẹ l'ofi şe alaye ọla irun ati ipo rẹ ninu awọn ijọsin, atipe ohun ni asopọ laarin ẹru ati Oluwa rẹ, pẹlu rẹ ni afi nmọ pe ẹru ntẹle aşẹ Oluwa rẹ.

 1- Itumọ rẹ:

'Al-sọlat' jẹ ede larubawa, eyi ti o n tumọ si adua, lati ara eleyi ni gboloun Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga).

]وَصَلِّ عَلَيْهِم إِنَّ صَلاَتَكَ سَكَنٌ لَهُم[ [سورة التوبة، من الآية: 103].

[ki ọ si şe adua fun wọn, Dajudaju adua rẹ ifọkanbalẹ ni o jẹ fun wọn]. [Suratu Taobah 9, Ayat: 103].

Agbekalẹ rẹ ninu shariat: Irun 'Al-sọlat' ni: ijọsin kan ti o ko awọn ọrọ ati awọn işẹ ti aşalẹsa sinu. O mbẹrẹ pẹlu ikabara (Allahu Akbar), o npari pẹlu salama.

Itumọ awọn ọrọ (ti irun ko sinu) ni: Kikabara, kikewu, sişe afọmọ (Ọlọhun), adua, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Itumọ awọn işẹ (ti irun ko sinu) ni: iduro, irukuu, iforikanlẹ, ijoko, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

2- Pataki irun l'ọdọ awọn Annabi ﷺ‬ ati awọn ojişẹ:

Irun-kiki jẹ ijọsin ti Ọlọhun şe l'ofin ninu gbogbo awọn ẹsin ti o sọ kalẹ lati sama siwaju ki Annabi wa ﷺ‬ o to de. Ki a wo Annabi Ibrãhĩm u ti on tọrọ l'ọdọ Oluwa ki oun ati arọmọdọmọ oun maa gbe irun duro:

]رَبِّ اجْعَلْنِي مُقِيمَ الصَّلاَةِ وَمِنْ ذُرِّيَّتِي[. [سورة إبراهيم، من الآية: 40].

[Oluwa mi, şe mi ni olugbe irun duro ati ninu awọn arọmọdọmọ mi]. [Suratu Ibrãhĩm 14, ãyat: 40].

Bakan na ni Annabi Ismaĩl u npa awọn ara ile rẹ l'aşẹ pẹlu rẹ. (Ọlọhun fun wa ni iro eleyi bayi pe):

]وَكَانَ يَأْمُرُ أَهْلَهُ بِالصَّلاةِ وَالزَّكَاةِ[. [سورة مريم، من الآية: 55].

[O si jẹ ẹniti o ma npa  awọn enian rẹ ni aşẹ irum kiki ati zaka yiyọ]. [Suratu Mariyam 19, ãyat: 55].

Ọlọhun tun sọ bayi ni igbati O nba Annabi Musa sọrọ pe:

]إِنِّي أَنَا اللهُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنَا فَاعْبُدْنِي وَأَقِمِ الصَّلاَةَ لِذِكْرِي[. [سورة طَه، الآية: 14].

[Dajudaju Emi ni Ọlọhun, kò si ọlọhun kan ayafi Emi, nitorinaa maa jọsin fun Mi, atipe ki o ma gbe irun duro fun iranti Mi]. [Suratu Tộhã 20, ãyat: 14].

Bakanna ni Ọlọhun sọ asọ silẹ pẹlu rẹ fun Annabi Issa u ninun ọrọ rẹ pe:

]وَجَعَلَنِي مُبَارَكاً أَيْنَ مَا كُنْتُ وَأَوْصَانِي بِالصَّلاَةِ وَالزَّكَاةِ مَا دُمْتُ حَيّاً[. [سورة مريم، الآية: 31].

[O si şe mi ni onibukun ni àyè yowu ti mo le maa bẹ, O si pa irun kiki l'aşẹ fun mi ati zàkãt yiyọ nigba yowu ti nba mbẹ l'aye]. [Suratu Mariyam 19, ãyat: 31].

Ọlọhun şe irun ni ọranyan fun Annabi wa Muhammad ﷺ‬ ni sanma l'oru Al-israi walmi'raj. Adọọta irun ni Ọlọhun kọkọ şe ni ọranyan, ki o to wa diinku si wakati marun, idi niyi ti o fi jẹ wipe irun wakati marun ni a nki, sugbọn aadọta ni lada rẹ.

Awọn irun wakati marãrun na ni: Alfajri, (irun owurọ), Alzuhr (irun ayila), Al'asr (irun Alãsari), Almọgrib (irun mọgaribi), Al'işah (irun işai), ori eleyi ni ọrọ durosi pẹlu apanupọ gbogbo Musulumi. 

 3 -Ęri sişe Irun l'ofin:

Sişe irun l'ofin fi ẹsẹ rinlẹ pẹlu awọn eri ti o pọ, ninu rẹ ni:

Ẹkinni: niun Tira  (Al-Qurãn):

1- Ọrọ Ọlọhun:

1- ]وَأَقِيمُوا الصَّلاَةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ[. [سورة البقرة، من الآية: 43].

[Ẹ mã kirun dede, ki ẹ si mã yọ zaka]. [Suratul-Bakọrah 2, ãyat: 43].

2- Ọrọ Ọlọhun:

2- ]إِنَّ الصَّلاَةَ كَانَتْ عَلَى المُؤْمِنِينَ كِتَاباً مَوْقُوتاً[. [سورة النساء، من الآية: 103].

[dajudaju irun kiki jẹ ọranyan ti o ni akoko lori awọn onigbagbọ ododo]. [Suratu-Nisãi 4, ãyat: 103].

3- Ọrọ Ọlọhun:

3- وَمَا أُمِرُوا إِلاَّ لِيَعْبُدُوا اللهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّيْنَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلاَةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ[. [سورة البيّنة، من الآية: 5].

[A kò pa wọn laşẹ ju pe ki wọn jọsin fun Ọlọhun lọ, ki wọn fọ ẹsin mọ fun ﷻ‬, ki wọn se deede, ki wọn mã gbe irun duro, ki wọn mã yọ zaka]. [Suratu Bayyinah 98, ãyat: 5].

Ẹkeeji: Ninu Sunnat (Annabi):

1- Hadith ọmọ 'Umar t wipe ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ pe:

((بني الإسلام على خمس، شهادة أن لا إله إلاّ الله، وأن محمّداً رسول الله، وإقام الصّلاة، وإيتاء الزّكاة، وحجّ البيت، وصوم رمضان)). [متفق عليه].

 ((Ẹsin Islam duro l'ori (origun) marun: ijẹri pe ko si ẹni ti a le jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, ati pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni, imọ gbe irun duro, imọ yọ zaka, sişe Hajj, ati gbigba awẹ Rọmadan)). [Bukhary ati Muslim ni o gbaa wa].

2- Hadith 'Umar ọmọ khatọbi t wipe ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ pe:

((الإسلام أن تشهد أن لا إله إلاّ الله وأنّ محمّداً رسول الله ﷺ‬، وتقيم الصّلاة، وتؤتي الزّكاة، وتصوم رمضان، وتحجّ البيت إن استطعت إليه سبيلاً...)). [رواه مسلم].

((Ẹsin Islam ni ki o jẹri pe: ko si ẹni ti a le jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, ati pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni, ki o ma gbe irun duro, ki o ma yọ zaka, ki o ma gba awẹ Ramọdan, ati ki o lọsi Hajj ti o ba l'agbara ati lọ)). [Muslim ni o gba wa].

3- Hadith Ọmọ 'Abas (رضي الله عنهما) wipe Annabi ﷺ‬ ran Mu'adh lọ si ilu Yamẹn o si wi fun pe:

((ادعهم إلى شهادة أن لا إله إلاّ الله، وأنّ محمّداً رسول الله، فإن هم أطاعوا لذلك فأعلمهم أن الله افترض عليهم خمس صلوات في كل يوم وليلة...)). [متفق عليه].

 ((Pewọn ki wọn o jẹri pe ko si ẹni ti a le jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, ati pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni, ti wọn ba şe bẹ, ẹ sọ fun wọn pe Ọlọhun şe irun wakati marun l'ọranyan lewọn l'ori ni ojoo-jumọ…)). [Bukhary ati Muslim ni wọn gba wa].

Ẹkẹẹta: Apanuọ: (awọn oni-mimọ)

Gbogbo awọn Musulumi ni wọn panupọ l'ori pe Ọlọhun pawa lasẹ lati maa ki irun, atipe ọranyan kan ninu awọn ọranyan Islam ni.

 4- Ọgbọn ati Ẹkọ ti o wa ninu pipa laasẹ ti Ọlọhun paa l'asẹ:

(Ọlọhun) pawa l'asẹ ki a maa kirun fun awọn ọgbọn ati asiri ti o pọ, a o tọ ka si diẹ ninu rẹ bayi:

1-Işe ẹrunsin fun Ọlọhun, atipe Ọlọhun ni oni ikapa ẹru. Pẹlu irun yi ni eniyan yoo fi ni ifura mọ ijẹ-ẹru fun Ọlọhun, ti yoo si wa pẹlu Ọlọhun ọba rẹ ni gbogbo igba.

2- Irun yoo mu ki asopọ olukirun pẹlu Oluwa rẹ o l'agbara, ti yoo si maa şe iranti Rẹ ni gbogbo igba.

3- Irun yoo maa kọ iwa ibajẹ ati ohun ti ọkan kọ fun olukirun, ọkan l'ara awọn okunfa ti yoo maa fọ ẹda mọ kuro ninu ẹsẹ ati asise si ni.

Ẹri lori eleyi ni Hadith Jãbir ọmọ Abdullah t osọpe: Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọpe:

((مثل الصلوات كمثل نهر جار غمر على باب أحدكم يغتسل منه كل يوم خمس مرات)). [رواه مسلم].

((Irun da gẹgẹ bi odo nla ti o n san ti o munitan, ti o wa l'oju ọna ẹnikan ninu yin, ti o nwẹ ni ibẹ l'ẹmaarun l'ojumọ)). [Muslim ni o gb wa].

4- Irun jẹ ibalẹ ọkan, ati isinmi ẹmi, o si tun n mu musiba (ewu) kuro, itori eyi ni irun fi jẹ alẹ-oju fun Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬, ti O si maa n yara lọ si ibi irun ni igbati n kan ba şẹlẹ sii, koda asi tun maa wipe:

((يا بلال أرحنا بالصلاة)). [أخرجه أحمد].

((Iwọ Bilal, fiwa lara balẹ, fun wa ni isimin pẹlu irun)). [Ahmad ni o gba wa].

 5- Awọn Ti Irun Jẹ Ọranyan Fun.

Irun şe ọranyan l'ori gbogbo Musulumi ti o de ipo balaga ti o ni lakae yala ọkunrin ni tabi obinrin. Sugbọn ko jẹ ọranyan l'ori keferi, itumọ eyi nipe: a o ni pee ki o wa ki irun l'aye, to ri pe irun ti keferi ba ki asan ni. Bẹẹ eyiun ko si ni ki o ma jẹ iya l'ori aikirun ni ọjọ ikẹyin, to ri pe o rọrn fun ki o gba Islam l'aye ki o si kirun, sugbọn ti ko şe bẹẹ. Ẹri eleyi ni ọrọ Ọlọhun  (ti ọla Rẹ ga):

]مَا سَلَكَكُمْ فِي سَقَرَ & قَالُوا لَمْ نَكْ مِنَ المُصَلِّينَ & وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ المِسْكِينَ & وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ الخَائضِينَ & وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ الدِّينِ & حَتَّى أَتَانَا اليَقِينُ[. [سورة المدثّر، الآيات: 42-47].

[Ki ni o gbe yin wọ (ina) Sakọrà? & Wọn a sọ pe: Awa kò si ninu awọn ti nkirun ni: & Atipe awa kò si ninu awọn ti mbọ awọn talaka ni: & Atipe awa jẹ awọn ti nsọ isọkusọ pẹlu awọn onisọkusọ ni: & Atipe awa jẹ ẹniti o npe ọjọ ẹsan ni irọ. & Titi ti aridaju (iku) fi wa ba wa]. [Suratu Muddassiru 74, ãyat: 42-47].

Bakanna ni irun ko pan dandan fun ọmọ kekere, nitori kii se ẹni ti a le pa l'asẹ ọrọ ẹsin, ko si pan dandan fun were, ko si pan dandan fun obinrin ti o wa ninu eela (nkan-osu) ati ẹjẹ ibimọ, nitoripe shariah samoju kuro fun awọn mejeeji nitori ẹgbin ti ko nijẹ ki wọn o ki irun.

Şugbọn o, o şe dandan fun alaşẹ ọmọ kekere yala ọkunrin ni o tabi obinrin, ki o maa paa l'aşẹ irun ni igbati ọmọ naa bati wa ni ọmọ ọdun meje, ki o si ma a lu ti ko ba kii, ni igbati o ba di ọmọ ọdun mẹwa. Bayi ni o şe wa ninu ọrọ Annabi ﷺ‬, ki irun leba a mọ ọ lara ki o si şe amoju to rẹ.

 6- Idajọ Ẹni Ti O Fi Irun Silẹ:

Ẹnikẹni ti o ba fi irun silẹ, onitọun ti şe keferi, ti osi ti jade kuro ninu oju ọna ẹsin (Islam), o si ti wa ninu awọn ti o bọ ẹsẹ sẹyin kuro ninu Islam, toripe o ti şẹ Ọlọhun pẹlu fifi ohun ti O şe ni dandan silẹ. Iru ẹnibẹẹ a o paa l'aşẹ ki o tuba, ti o ba tuba ti o si pada si gbe irun duro (o tun di Muslim), ti ko ba tuba o bọ ẹsẹ sẹyin kuro ninu Islam nu u, nitorina a ko ni wẹẹ ti o ba ku bẹẹ, a ko ni fi asọ sii lara, a ko ni kirun si, a ko ni sin si itẹ Musulumi, tori kii şe ọkan lara awọn Musulumi.

 7- Awọn Mọjẹmu Irun:

1- Islam (Ki eniyan jẹ Musulumi).

2- Lakae.

3- Òye.

4-Ki asiko irun to.

5- Aniyan.

6- Idaju-kọ Gabasi (Qibla).

7- Bibo ihoho. Ihoho ọkunrin bẹrẹ l'ati idodo titi de orukun.([1]). Sugbọn obinrin niti rẹ, gbogbo ara rẹ ni ihoho ti o se ọranyan fun ki o boo, afi iwaju rẹ ati atẹlẹwọ rẹ mejeeji ni yoo yọ silẹ ninu irun.

8- Imu ẹgbin kuro ni ibi aşọ olukirun ati ara rẹ ati aiye ti o ti fẹ ki irun.

9-Imu eeri kuro, eleyi ko: Aluwala, ati iwẹ-janaba sinu.

 8- Awọn Asiko Irun:

1- Alzuhr (Irun ayila): asiko rẹ bẹrẹ lati igbati òrún bayẹri – nigbati o ba yẹ ba kuro laarin saman lọ si agbegbe iwọ òrún - titi ti ogigi ohunkohun yoo fi şe deede araa rẹ.

2- Al-'asr (Irun alãsari): asiko rẹ bẹrẹ lati igbati asiko Ayila bati pari titi di igbati ogigi nkan yoo fi gun ni ilọpomeji rẹ, ohun naa ni igbati òrún o bẹrẹ si ma pupa.

3- Al-mọgrib (Irun mọgari): asiko rẹ bẹrẹ lati igbati òrún bati wọ titi ti awo-npapa yoo fi wọ, ohun naa ni pupa ti o ma ngbẹyin wiwọ òrún.

4-Al-'işai (Irun işai): asiko rẹ bẹrẹ lati igbati asiko Mọgari bati jade titi di idaji oru.

5- Al-fajir (Irun alfajri): asiko rẹ bẹrẹ lati igbati alfajri keji ba ti yọ titi di ki òrún o to yọ.

Ẹri l'ori eleyi ni Hadith 'Abdullahi ọmọ 'Amru (رضي الله عنهما) wipe Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ bayi pe:

((وقت الظهر إذا زالت الشمس وكان ظلّ الرجل كطوله ما لم يحضر العصر، ووقت العصر ما لم تصفرّ الشمس، ووقت صلاة المغرب ما لم يغب الشفق، ووقت صلاة العشاء إلى نصف الليل الأوسط، ووقت صلاة الصبح من طلوع الفجر ما لم تطلع الشمس، فإذا طلعت الشمس فأمسك عن الصلاة...)). الحديث. [رواه مسلم].

 ((Asiko irun Ayila ni igbati õrun ba yẹri ti ogigi ọkunrin si gun se deede rẹ, ki asiko Al-'asr o to de. Asiko Al-'asr ni ki õrun to pupa, asiko Mọgari ni ki awonpapa to wọkun, asiko Ishai titi di idaji oru, asiko Asuba bẹrẹ lati igbati Alfajri bayọ tiiti di ki õrun to yọ, ti õrun ba ti yọ a ko gbọdọ kirun ma…)). [Muslim ni o gba hadith naa wa].

 9- Onka awọn (Ọpa) raka'at Irun:

Iye (Ọpa) raka'at awọn irun ọranyan lapapọ jẹ raka'at mẹtadilogun, gẹgẹ bi alaye ti mbọ yi:

1- Ayila: Raka'at (Ọpa) mẹrin.

2-Alasari: Raka'at (Ọpa) mẹrin.

3- Mọgari: Raka'at (Ọpa) mẹta.

4- Ishai: Raka'at (Ọpa) mẹrin.

5-Alfajir (irun Asubaa) Raka'at (Ọpa) meji.

Ẹnikẹni ti o ba şe alekun awọn Raka'at (Ọpa) irun yi, tabi ti o dinku nibẹ, irun iru ẹnibẹẹ ti bajẹ ti o ba şe wipe o fi oju silẹ se e ni, sugbọn ti o ba şe wipe pẹlu igbagbe ni, yoo tun şe pẹlu iforikanlẹ.

Eyi ti a sọ yi ki i şe fun irun onirin-ajo, tori on ti afẹ fun onirin ajo ni ki o maa din irun olopo mẹrin ku si opo-meji. O wa şe ọranyan l'ori gbogbo Musulumi ki o ma kii awọn irun wakati marun yi ni asiko ti a bu fun ọkọọkan wọn, ayafi pẹlu idi kan ti o jẹti shariat gẹgẹ bi oorun, Igbagbe, ati Irin-ajo. Bakanna ẹnikẹni ti o ba sun tabi ti o gbagbe lati ki irun kan, ki ẹni bẹẹ ki irun naa ni igbati o barnti rẹ lẹsẹ-kẹsẹ.

 10- Awọn origun Irun:

1- Iduro fun ẹniti o ba lagbara.

2-Kabara (akọkọ) ti iwọrun.

3-Kike Fãtia.

4- Iruku'u.

5- Igbori si oke lati ruku'u.

6- Iforikanlẹ l'ori awọn orike meje.

7- Ijoko lẹyin iforikanlẹ.

8- Kike Ataaya igbẹyin.

9- Ijoko şe Ataya igbẹyin.

10- Ifarabalẹ nibi awọn origun yi.

11- Tito awọn origun yi lerawọn.

12- Sisalama.


 11- Awọn ọranyan Irun:

 Awọn ọranyan irun jẹ mẹjọ:

Ẹkini: Gbogbo kabara ti a fi n kuro ni ibi origun kan bọ si omiran, yatọ si kabara alakọkọ.

Ẹkeeji: Wiwi gboloun: (SẸMI'AL LAU LIMAN HAMIDAU), itumọ rẹ: Ọlọhun gbọ ọpẹ oludupẹ fun Un. Ọranyan ni fun Imamu ati ẹniti o n da irun ki, sugbọn ero ẹyin imamu koni wii nitiẹ.

Ẹkẹẹta: Wiwi gboloun: (RỌBBANA WALAKAL HAMD), itunmọ rẹ: (Oluwa wa, ti Ẹ ni ọpẹ se). Eleyi şe dandan fun Imamu, ero ẹyin Imamu ati oluda irun ki.

Ẹkẹẹrin: Wiwi gbolun: (SUBUHANA RỌBIYAL 'AZIM), itumọ rẹ: (Mimọ Rẹ Oluwa mi ti O ni apọnle), nibi Ruku'u.

Ẹkãrun: Wiwi gbolun: (SUBUHANA RỌBIYAL A'ALA), itumọ rẹ: (Mimọ Rẹ Oluwa mi ti O ga), nibi Iforikanlẹ.

Ẹkẹẹfa: Wiwi gbolun: (RỌBI IGFIR LI), itumọ rẹ: (Oluwa mi se aforiji fun mi), lãrin ijoko mejeeji.

Ẹkeeje: Kike (Ataayat) akọkọ, on naa ni wiwi gbolun:

((التحيّات لله والصلوات والطيبات، السلام عليك أيّها النبي ورحمة الله وبركاته، السلام علينا وعلى عباد الله الصالحين، أشهد أن لا إله إلاّ الله، وأشهد أن محمّداً عبده ورسوله)). [أو نحو ذلك مما ورد].

((ATTAHIYATU LILLAI WASSỌLAWATU WATTỌYIBÃTU, ASSALÃMU 'ALAEKA AYUA ANNABIYI WARAHMATU LLAHI WABARAKÃTU ﷻ‬, ASSALÃMU 'ALAENA WA 'ALA 'IBADI LLAHI SSỌLIHINA. ASHADU  AN LA ILAHA ILA ALLAHU, WA ASHADU ANA MUHAMMADAN 'ABDU ﷻ‬ WARỌSULU ﷻ‬)).

Itumọ: ((Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo ikẹ ati gbogbo dãda, ikẹ ati ọla Ọlọhun ati õre ajẹnjẹtan rẹ ki o mã ba irẹ Annabi. Ọla Ọlọhun ki o maa ba awa naa, ati gbogbo ẹrusin Ọlọhun ti o duro deede. Mo jẹri pe ko si ẹniti a gbọdọ ma jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, mo si tun jẹri pe (Annabi) Muhammad ẹru Ọlọhun ni ojisẹ Rẹ situn ni)). Tabi Ataayat miran ti o tun wa l'ati ọdọ Annabi.([2])

Ẹkẹẹjọ: Ijoko fun Atayat akọkọ.

Ẹnikẹni ti o ba fi oju silẹ fi ọkan l'ara awọn ọranyan wọnyi silẹ, irun rẹ bajẹ, sugbọn ẹniti o ba gbagbe tabi ti o se aimọ, iru ẹnibẹ yoo fi ori kanlẹ ti igbagbe.

 12- Irun Janmọ:

Kiki irun wakati maraarun ni janmọ ni Mọşalasi kanpa fun ọkunrin Musulumi, ki o le e bã ri iyọnu Ọlọhun ati laada lati ọdọ Rẹ.

Toripe irun janmọ l'ọla ju irun adaki lọ ni igba mẹtadilọgbọn. O wa ninu hadith ọmọ 'Umar (رضي الله عنهما) wipe ojşẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ pe:

((صلاة الجماعة أفضل من صلاة الفذّ بسبع وعشرين درجة)). [متفّق عليه].

((Irun janmọ l'ọla ju irun adaki lọ ni igba mẹtadilọgbọn)). [Bukharyi ati Muslim panupọ l'ori rẹ].

Şugbọn ki Obinrin Muslimat o ki irun rẹ ni ile rẹ l'ọla ju ki o ki pẹlu janmọ ọ lọ.

 13- Awọn nkan ti o n ba irun jẹ:

 Irun amã bajẹ pẹlu ọkan lara awọn nkan ti o mbọyi:

1- Jijẹ ati mimu l'ori irun pẹlu afi oju silẹ. Tori apanupọ awọn Alufa l'ori wipe ẹnikẹni ti o ba fi oju silẹ jẹ kinikan, tabi mu kinikan l'ori irun yoo tun irun na ki.

2- Ifi oju silẹ sọrọ l'ori irun, yatọ si ọrọ ti o tun irun şe. Nitori ẹgbawa Zaed ọmọ Arqọm t ti o sọ wipe:

((كنا نتكلّم في الصلاة، يكلّم الرجل منا صاحبه وهو إلى جنبه في الصلاة حتى نزلت ]وَقُومُوا للهِ قَانِتِيْنَ[، [سورة البقرة، من الآية: 238]. فأُمِرْنَا بالسكوت ونُهِينَا عن الكلام)). [رواه البخاري ومسلم].

((A ma nsọrọ ninu irun tẹlẹ, ikan ninu wa  a maa ba ẹnikeji ti o wa l'ẹgbẹ rẹ ninu irun sọrọ, titi ti ọrọ Ọlọhun fi sọ kalẹ pe: [Ki ẹ si dide duro fun Ọlọhun ninu irun, ki ẹ si tẹ ori yin ba fun ﷻ‬]. [Suratul-Baqọrah 2, ãyat: 238]. Nitorina ni wọn fi pa wa l'asẹ ki a maa dakẹ, ti wọn si kọ ọrọ sisọ fun wa. [Bukharyi ati Muslim ni o gbaa wa].

Ati nitori Apanupọ awọn oni-mimọ l'ori wipe ẹnikẹni ti o ba fi oju silẹ sọrọ l'ori irun ti ki i şe wipe o gbero ati tun irun şe ni, irun iru ẹnibẹẹ ti bajẹ.

3- Ifi oju silẹ şe işẹ ti o pọ. Işẹ ti o pọ naa ni eyi ti ẹlomiran ba ri, ti yoo ro wipe onitọhun ko si l'ori irun ni.

4- Fifi oju silẹ fi ọkan lara awọn origun, tabi mọjẹmu irun silẹ laisi idi fun. Gẹgẹ bi kikirun laini aluwala, tabi ki o dajukọ ibomiran kirun yatọ si Gabasi (Qibla). Nitori ẹgbawa Bukharyi ati Muslim wipe Annabi ﷺ‬ pe:

أن النبي ﷺ‬ قال للأعرابي الذي لم يحسن صلاته: ((ارجع فصلِّ فإنّك لم تصلّ)).

((Annabi ﷺ‬ sọ fun Larubawa-oko ti ko ki irun rẹ bi o ti yẹ pe: ((Pada, ki o tun irun rẹ ki, nitori wipe eyi ti o ki un kii se irun gidi)).

5- Ẹrín lori irun. Ẹri l'ori eleyi ni apanupọ awọn oni-mimọ ti o wa ye l'ori pe ẹrin a maa ba irun jẹ.

 14- Awọn akoko ti irun ko tọ ninu wọn:

1- L'ẹyin irun Alfajir (Asuba) titi ti Òrùn yoo fi ga.

2- Nigbati Òrùn başe deede. (lọsan gangan).

3- L'ẹyin irun Alasari titi di Òrùn wọ.

Ẹri ti o kọ ki akirun ni awọn asiko yi ni hadith 'Uqbat ọmọ 'Ãmir t ti o sọ wipe:

((ثلاث ساعات كان رسول الله ﷺ‬ ينهانا أن نصلي فيهن وأن نقبر فيهن موتانا: حين تطلع الشمس بازغة حتى ترتفع، وحين يقوم قائم الظهيرة حتى تميل الشمس، وحين تضيّف الشمس للغروب حتى تغرب)). [رواه مسلم].

((Igba mẹta kan wa ti Ojişẹ Ọlọhun maa nkọ fun wa lati ki irun, ati lati sin awọn oku wa ninu rẹ: Nigbati Òrùn ba sẹsẹ yọ titi ti yoo fi ga, ati ni ọsan gangan titi ti Òrùn yoo fi yẹba, ati ni aboorunwọ titi ti Òrùn yoo fi wọ)). [Muslim ni o gbaa wa].

Ẹri miran tun ni hadith Abi Sai'id t wipe Annabi ﷺ‬ sọ bayi:

((لا صلاة بعد صلاة العصر حتى تغرب الشمس، ولا صلاة بعد صلاة الفجر حتى تطلع الشمس)). [متفق عليه].

 ((Irun kiki ko tọ l'ẹyin Alasari titi Òrùn yoo fi wọ, bẹ ẹ irun kiki ko tọ l'ẹyin irun Asuba titti Òrùn yoo fi yọ)). [Bukharyi ati Muslim panupọ loriẹ].

 15- Alaye Bi a ti se n kirun ni şoki:

O şe dandan fun Musulumi ki o ma kọşe Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬, ninu rẹ naa ni ọna ti an gba ki irun, nitori ọrọ Annabi ﷺ‬.ti o wipe:

((صلّوا كما رأيتموني أصلّي)). [رواه البخاري].

((Ẹ ki irun yin gẹgẹ bi ẹ ba se rimi ti mo kirun)). [Bukharyi ni o gbaa wa].

وكان ﷺ‬ إذا قام إلى الصلاة ووقف بين يدي الله تبارك وتعالى عقد نيّة الصلاة بقلبه، ولم يؤثر عنه أنه نطق بها، وكبّر قائلاً: ((الله أكبر))، ورفع يديه مع هذا التكبير حذو منكبيه، وأحياناً كان يرفعهما حتى يبلغ بهما شحمة أذنيه، ووضع يمناه على يسراه فوق صدره، واستفتح بدعاء من أدعية الاستفتاح ومنها: ((سبحانك اللهم وبحمدك، تبارك اسمك، وتعالى جَدُّك، ولا إله غيرك)). ثم قرأ سورة الفاتحة وسورة، ثم كبّر رافعاً يديه، وركع، ومدّ ظهره في ركوعه حتى لو وضع قدح ماء فوق ظهره ﷺ‬ ما انسكب، قائلاً: ((سبحان ربّي العظيم))، ثلاثاً، ثم رفع رأسه قائلاً: ((سمع الله لمن حمده، ربّنا ولك الحمد)).رافعاً يديه أيضاً، حتى يستوي قائماً، ثم كبّر وسجد، فإذا سجد جافى ـ أي: باعد ـ ما بين يديه وجنبيه حتى يبدو بياض إبطيه، ومكّن جبهته وأنفه وكفيه وركبتيه وأطراف قدميه حتى تصيب الأرض، قائلاً: ((سبحان ربّي الأعلى))، ثلاثاً، ثم كبّر وجلس مفترشاً، أي: جالساً على القدم اليسرى، ناصباً القدم اليمنى، موجهاً أطراف أصابعها تجاه القبلة قائلاً في هذا الجلوس: ((ربّ اغفر لي وارحمني واجبرني وارفعني واهدني وعافني وارزقني))، ثم كبّر وسجد، ثم قام للركعة الثانية.

Bi Annabi ﷺ‬ se ma nkirun naa wa niyi: Ti o ba dide lati lọ ki irun, ti o si duro ni iwaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, yoo da aniyan irun ti o ba fẹ ki pẹlu ọkan rẹ, ko si ninu ẹgbawa pe Annabi maa n wi aniyan l'ẹnu. L'ẹyin na yoo kabara bayi:

(Allahu akbar), Itumọ: Ọlọhun ni O tobi ju.

Yoo si gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke de ọkankan ejika rẹ mejeeji ni igbati o ba nkabara naa, tabi ni igbamiran yoo gbe wọn si oke titi de ọgangan eti rẹ. Yoo si gbe ọwọ ọtun rẹ le ọwọ alaafia rẹ lori igba-aya rẹ. Yoo bẹrẹ irun pẹlu ọkan niun awọn adua ibẹrẹ irun, niun rẹ ni:

(Subuhanaka Allaumọ wabi hamdika, tabãraka smuka, wata'ala jadduka, walailaha gaeruka). Itumọ: Mimọ rẹ Oluwa mi ati ọpẹ fun Ọ, giga orukọ Rẹ, giga apọnle Rẹ, kosi Ọlọhun miran lẹyin rẹ.

L'ẹyin nan yoo wa ke suratul-fãtia, ati surat mi i le. Lẹyin naa yoo kabara ni ẹniti o gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke, yoo si ruku'u, yoo si tẹ ẹyin rẹ ba ni ibi ruku'u yi debi wipe ti wọn ba gbe aha omi le ẹyin re ﷺ‬ ko ni yi danu. Ni ẹni ti o n wi bayi pe: (Subuhana rabbi Al'azim). Itumọ: Mimọ Rẹ Oluwa mi ti o tobi ju, ni ẹmẹẹta.

Lẹyin naa ni yoo si ori rẹ si oke ni ẹniti o nwi pe: (sẹmiallahu limani hamidau, rọbbanã walakal hamdu). Itumọ: Ọlọhun gbọ ọpẹ oludupẹ fun, Oluwa mi ti Ẹ ni ọpẹ se, ti yoo si gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke titi ti yoo fi naro tanyanyan.

L'ẹyin naa yoo kabara yoo si fi ori kanlẹ. Ni igbati o ba fi orikan lẹ yoo jẹki ọwọ rẹ mejeeji jinan si iha rẹ, koda ti funfun abiya rẹ yoo fi han. Yoo si jẹki iwaju rẹ ati imu rẹ ati atẹlẹwọ rẹ mejeeji ati orukun rẹ mejeeji ati igori ẹsẹ rẹ, yoo jẹ ki wọn lelẹ daradara, ti yoo si wi pe:

(Subuhana rabi al-'aala). Itumọ: Mimọ Rẹ Oluwa mi ti O ga ju. Ni ẹmẹẹta.

L'ẹyin naa yoo tun kabara yoo si joko l'ori ẹsẹ rẹ ti alaafia ti yoo naa ti ọtun, ni ẹniti o daju awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ kọ gabasi (qiblat) ti yoo si wi bayi nibi ijokoyi:

(rabigfr li warhamuni wajburni warfa'ani wa adini wa 'ãfi ni warzuqni). Itumọ: Oluwa mi se aforijin fun mi, kẹ mi, kun mi, se agbega fun mi, fi ọna mọmi, ki O fun mi ni alaafia, ki O si se arisiki rẹ fun mi.

L'ẹyin naa ni yoo kabara ti yoo tun fi ori kanlẹ, l'ẹyin naa ni yoo wa dide lati ki opo (rak'at) keji.

وهكذا فعل ﷺ‬ في كلّ ركعةٍ، فإذا جلس بعد ركعتين للتّشهّد الأوّل قال: ((التّحيّات لله والصّلوات والطّيّبات، السلام عليك أيّها النبيّ ورحمة الله وبركاته، السلام علينا وعلى عباد الله الصالحين، أشهد أن لا إله إلاّ الله وأشهد أنّ محمّداً عبده ورسوله)). ثم يقوم مكبِّراً رافعاً يديه إذا استوى قائماً، وهو الموضع الرابع في الصلاة الذي كان يرفع فيها يديه، فإذا جلس للتّشهّد الأخير وهو في الثالثة من صلاة المغرب أو الرابعة من الظهر والعصر والعشاء جلس متوركاً، أي: جلس على مقعدته اليسرى، وأخرج قدمه اليسرى من تحت ساقه اليمنى، ونصب القدم اليمنى مستقبلاً بها القبلة، وجمع أصابع كفّه تاركاً السّبّابة للإشارة أو التّحريك ملقياً ببصره إليها، قائلاً: ((التّحيّات لله والصّلوات والطّيّبات، السلام عليك أيّها النبيّ ورحمة الله وبركاته، السلام علينا وعلى عباد الله الصالحين، أشهد أن لا إله إلاّ الله وأشهد أنّ محمّداً عبده ورسوله، اللهم صلّ على محمّدٍ وعلى آل محمّدٍ، كما صلّيت على آل إبراهيم إنّك حميدٌ مجيدٌ، وبارك على محمّدٍ وعلى آل محمّدٍ، كما باركت على آل إبراهيم إنّك حميدٌ مجيدٌ)). فإذا فرغ من تشهّده سلّم عن يمينه وعن شماله قائلاً: ((السلام عليكم ورحمة الله، السلام عليكم ورحمة الله))، حتى يبدو بياض خديه ﷺ‬.

Bi a se şe alaye yi ni Annabi ﷺ‬ şe ma n şe ni ibi gbogbo raka'at, ti o ba si joko l'ẹyin raka'at keji fun Ataya ti alakọkọ yoo sọ pe: (Attahiyatu lillah wassọlawaatu wattọyibaatu, Assalaamu alaeka ayua nabiyu warahmatulai wabarakãtu u, Assalaamu 'alaena wa 'ala 'ibadilahi ssọlihina. Aşhadu an la ilaha ilallau, wa aşhadu ana Mummadan 'abudu u warọsulu u)([3]).

Itumọ: ((Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo ikẹ ati gbogbo dãda. Ikẹ ati ọla Ọlọhun ati õre ajẹnjẹtan rẹ ki o mã ba irẹ Annabi, ikẹ Ọlọhun ki o ma ba awa naa, ati gbogbo ẹrusin Ọlọhun ti o duro deede. Mo jẹri pe ko si ẹniti agbọdọ ma jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, mo tun jẹri pe Annabi Muhammad ẹru Ọlọhun ni ojisẹ rẹ situn ni)).

L'ẹyin naa yoo tun wa dide ni ẹniti o kabara ti o si gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke l'ẹyin ti o ba naro tan. Eleyi ni aye ẹlẹẹkẹrin ti o ti ma n gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke ninu irun. Ni igbati o ba joko fun atayat igbẹyin ni ibi raka'at ẹlẹẹkẹta nibi irun Mọgari tabi ẹlẹẹkẹrin nibi irun Ayila ati Alasari ati Işai, yoo fi aye idi alaafia rẹ lelẹ, ti yoo si yọ atẹlẹsẹ alaafia rẹ labẹ ojugun rẹ ti ọtun, yoo si naa ẹsẹ ọtun ni ẹniti o da oju ẹsẹ naa kọ gabasi (qibla). Yoo si ka awọn ọmọnika ọwọ rẹ ọtun kò ni ẹniti o na ika ifabẹla rẹ, tabi ti o n mi ti o si n wo o. Ti yoo sọ abyi:

(Attahiyatu lillah wassọlawaatu wattọyibaatu, Assalaamu alaeka ayua nabiyu warahmatulai wabarakãtu u, Assalaamu 'alaena wa 'ala 'ibadilahi ssọlihina. Aşhadu an la ilaha ilallau, wa aşhadu ana Mummadan 'abdu u warọsulu u. Allaumọ sọlli 'ala Muhammadi wa 'ala ãli Muhammadi, kama sọllaeta 'ala ãli Ibrahima inaka Hamidun Mọjidun, wabaark 'ala Muhammadi wa 'ala ãli Muhammdai, kama baarakta 'ala ãli Ibrahima inaka Hamidun Mọjidun).

Itumọ: ((Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo ikẹ ati gbogbo dãda, ikẹ ati ọla Ọlọhun ati õre ajẹnjẹtan rẹ ki o mã ba irẹ Annabi, ikẹ Ọlọhun ki o maa ba awa naa, ati gbogbo ẹrusin Ọlọhun ti oduro deede. Mo jẹri pe ko si ẹniti a gbọdọ jọsin fun l'ododo afi Ọlọhun, mo tun jẹri pe Annabi Muhammad ẹru Ọlọhun ni ojisẹ rẹ situn ni. Ọlọhun O, se ikẹ ati igẹ Rẹ fun Annabi Muhammad ati awọn ara ile Annabi Muhammad, gẹgẹ bi iwọ Ọlọhun ti se ikẹ ati igẹ fun Annabi Ibrahim ati ara ile Annabi Ibrahim, dajudaju iwọ ni Ọba ti O tobi ti ọpẹ tọsi. Ki O tun se alubarika fun Annabi Muhammad ati ara ile Annabi Muhammad, gẹgẹ bi O ti se alubarika fun Annabi Ibrahim ati ara ile Annabi Ibrahim, dajudaju iwọ ni Ọba ti o tobi ti ọpẹ tọsi)).

L'ẹyin ti o ba pari ataya yi ni yoo salama si ọtun rẹ ati si alaafia rẹ bayi pe:

(Assalaamu 'alaekun warahmọtuhllah, Assalaamu 'alaekun warahmọtuhllah). Itumọ: Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma ba yin.

Titi ti funfun ẹrẹkẹ rẹ mejeeji yoo fi an. (si awọn ti wọn wa ni ẹyin rẹ).

Alaye irun yi wa ninu ọpọlọpọ awọn ọrọ (ahãdith) ti o wa lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬.

Eleyi ni diẹ ninu awọn idajọ irun, ti o se wipe oriẹ naa ni daada işẹ enian duro l'ori, ti irun bati dara gbogbo işẹ ti o sẹ ku naa dara, ti irun ba si bajẹ gbogbo işẹ ti o sẹ ku naa ti bajẹ. Irun yii naa ni akọkọ ohun ti a o siro ninu isẹ ẹda ni ọjọ al-qiyamọ, ti enian ba ki irun rẹ daradara o ti jere pẹlu iyọnu Ọlọhun, ti o ba si ku diẹ kaato onitọun ti se ofo. Irun yii naa ni o ma nkọ iwa-ẹsẹ ati iwa ti ko dara fun eniyan. Ohun naa ni Ògùn ti o nmu gbogbo aburu kuro l'ọkan ọmọniyan ti yoo si fọ ọ mọ.


Origun Ẹlẹẹkẹta: Zakat yiyọ:

 1-Itumọ rẹ:

Zakat ninu ede larubawa tumọ si: alekun ati idagba soke. Wọn si tun fi n pe ẹyìn, ati afọmọ ati iduro dede. Wọn n pe owo ti ayọ ni zakat tori wipe yoo se alekun alubarika fun owo, yoo si tun se afọma ẹni ti o ba ni owo pẹlu aforijin.

Itumọ rẹ ninu ofin Islam: Zakat ni: Ẹtọ kan ti ojẹ ọranyan ninu owo kan, fun awọn eniyan kan, ni asiko kan.

 2- Ipo Zakat Ninu Ẹsin, Ati Ọgbọn Ti O Wa Ni Ibi Sisee Ni Ọranyan:

Zakat jẹ ọkan ninu awọn origun ẹsin Islam marãrun, ti o si papọ mọ irun ni ọpọlọpọ ãye ninu tira Ọlọhun (Al-Qurãn) ninu rẹ ni ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَأَقِيمُوا الصَّلاَةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ[، [سورة البقرة، من الآية: 43].

[Ẹ mã ki irun deede, ki ẹ si mã yọ zaka]. [suratul-Baqọrah 2, 43]. Ati ọrọ Ọlọhun:

]وَيُقِيمُوا الصَّلاَةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ[، [سورة البيّنة، من الآية: 5].

[ki wọn mã gbe irun duro, ki wọn mã yọ zakat]. [suratu Bayyinah 98, ãyat: 5].

Annabi ﷺ‬ sọ bayi pe:

((بني الإسلام على خمس...) وذكر منها: ((إيتاء الزكاة)). [متفق عليه من حديث ابن عمر ـ رضي الله عنهما ـ].

((Ẹsin Islam duro l'ori (origun) marun…)) ninu rẹ l'o darukọ: ((yiyọ zakat)). [Bukhari ati Musulumi panu pọ lee lori  ninu hadith ọmọ 'Umar t.

Ọlọhun se Zakah ni ọran yan lati se afọmọ ọkan ẹdamọniyan kuro ni ibi ahun ati ojukokoro, ati l'ati le jẹ iduro ti fun awọn alaini, ati awọn ti wọn ni bukata, bakan na ni l'ati se afọmọ owo, ati sise alekun rẹ, ki alubarika si wọ owo naa, ati l'ati sọ owo na nibi aburu, ati sise amojuto anfaani ti yoo mu ki aye dẹrun fun onikaluku. Ọlọhun ti sọ ẹkọ ti o wa nibi yiyọ zaka ninu ọrọ Rẹ pe:

]خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِم صَدَقَةً تُطَهِّرُهُم وَتُزَكِّيْهِم بِهَا[، [سورة التوبة، من الآية: 103].

[Gba itọrẹ anu (Zakat) ninu ọrọ wọn ki o fọ wọn mọ ati ki o fi sọ wọn di mimọ]. [suratu Taobah 9, ãyat: 103].

 3-Idajọ rẹ:

Zaka jẹ ọranyan ti o pa dandan lori gbogbo Musulumi ti o ba ni ondiwọn zakat (nisọb) pẹlu awọn majẹmu rẹ, koda ati ọmọ-de ati were ni awọn alamojuto wọn yoo bawọn yọ zaka ninu owo wọn. Ẹnikẹni ti o ba mọọmọ ti o fi oju silẹ sọ pe zaka ko jẹ ọranyan, onitọun ti se keferi; aigbagbọ. Sugbọn ẹni ti ijẹ ahun tabi aikobikita ko ba jẹ ki o yọ, ti o si gba pe ọranyan ni, a o ka onitọhun kun ahun, ti o da ẹsẹ ti o tobi ninu awọn ẹsẹ nla, iru ẹni bẹ ti oba kú bẹẹ ọrọ rẹ wa l'ọwọ Ọlọhun, nitori ọrọ Ọlọhun ti O sọ wipe:

]إِنَّ اللهَ لاَ يَغْفِرُ أَنْ يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُوْنَ لِمَنْ يَشَاءُ[،[سورة النساء،من الآية:48].

[Dajudaju Ọlọhun koni fi ori jin ẹniti o ba da nkan pọ mọ Ọ, şugbọn yoo şe aforijin ẹşẹ miran yatọ si eyi fun ẹnikẹni ti O ba fẹ]. [suratu-Nisãi 4, ãyat: 48]. Iru ẹni bẹ a o gba zaka l'ọwọ rẹ ni tulasi, a o si bãwi ni toripe o da ẹşẹ.

Dajudaju Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) ti se adeun iya fun awọn ti wọn kọ ti wọn ko yọ zaka, ninu ọrọ rẹ:

]وَالَّذِيْنَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالفِضَّةَ وَلاَ يُنْفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللهِ فَبَشِّرْهُم بِّعَذَابٍ أَلِيمٍ & يَوْمَ يُحْمَى عَلَيْهَا فِي نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَى بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنُوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ هَذَا مَا كَنَزْتُمْ لأَنْفُسِكُمْ فَذُوقُوا مَا كُنْتُمْ تَكْنِزُونَ[، [سورة التوبة، من الآية: 34-35].

[Awọn ti wọn n ko wura ati fadaka jọ, ti wọn kii naa si oju ọna ti Ọlọhun, nitorinaa fun wọn ni iro ìyà ẹlẹta elero & Ni ọjọ ti a o ma yộ ninu ina Jahannama, a o mã fi (ina na) jo wọn ni iwaju wọn, ẹgbẹ wọn ati ẹhin wọn; (A o wipe): Eyi ni ohun ti ẹ kojọ fun ara nyin nitorinaa ẹ tọọ wò ohun ti ẹyin kojọ]. [suratu Taobah 9, aayat: 34-35].

Abu Huraera t gba ẹgbawa lati ọdọ Annabi ﷺ‬ o sọ pe:

((ما من صاحب كنْزٍ لا يؤدّي زكاته إلاّ أحمي عليه في نار جهنّم، فيجعل صفائح، فيكوى بها جنباه وجبينه حتى يحكم الله بين عباده في يوم كان مقداره خمسين ألف سنة ثم يرى سبيله إما إلى الجنة وإما النار...)). [الحديث متفق عليه. وهذا لفظ مسلم].

((Ko si ẹnikan ti o ni ọrọ ti ki i si yọ zakat rẹ, afi ki wọn o yọ ina Jahannama le l'ori, ti yoo rọ kiri ka rẹ, ti ina yoo ma jo ni ẹgbẹ rẹ mejeeji ati iwaju rẹ, bayi ni yoo si wa titi Ọlọhun yoo fi se idajọ l'aarin awọn ẹru rẹ, ni ọjọ kan ti o se deede ẹgbẹrun l'ọna aadọta ọdun, l'ẹhin naa ni yoo mọ ibi ti ọrọ rẹ yoo jasi, bọya Alijanna tabi ina…)). [Wọn panu pọ l'ori hadith yi, sugbọn Muslim l'oni gboloun yi].

 3-Awọn mọjẹmu ijẹ ọranyan rẹ:

 Mọjẹmu ijẹ ọranyan zaka marun ni:

Alakọkọ: Islam, zaka ko jẹ ọranyan l'ori keferi.

Ẹkeeji: Ijẹ ọmọluabi, zaka ko jẹ ọranyan ninu owo ẹru l'ọdọ ọpọ ninu awọn oni-mimọ, bakanna naa ni ẹru ti a kọ iwe (ominira) fun, toripe ẹru ni ohun naa l'opin igba ti o ba ku iye owo kan ti yoo san.

Ẹkẹẹta: Ki einyan ni ondiwọn owo (nisọb) ti zaka se ọranyan ni ibẹ, ti owo naa ba din ku diẹ zaka ko jẹ ọranyan l'oriẹ.

Ẹkẹẹrin: Ko ma ni gbese l'ọrun, gẹgẹ bi ẹni ti akọ iwe (ominira) fun, zaka ko si jẹ ọranyan l'ori ere òwò l'arin eyan meji ti wọn o ti pin, bakan na zaka kojẹ ọranyan l'ori gbese ti a ya eniyan, titi ti a o fi gba owo naa. Zaka ko si jẹ ọrayan l'ori awọn owo ti agbe kalẹ si oju ọna daada, ati itọrẹ aanu ni tori Ọlọhun (waqfu), gẹgẹ bi olujagun soju ọna Ọlọhun, ati fun masalasi, ati fun awọn alaini, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ẹkãrun: Iyipo ọdun (Al-haol), zaka ko jẹ ọranyan l'ori owo kan afi bi ọdun ba yipo l'ori rẹ, yatọ si awọn nkan ọgbin, gẹgẹ bi awọn eso ati nkan woro ti o jẹ eyi ti zaka wọ. Toripe a o maa yọ zaka awọn eleyi ni ọjọ kika wọn, ati ọjọ ikore. Ọrọ Ọlọhun sọ bayi pe:

]وَآتُوا حَقَّهُ يَومَ حَصَادِهِ[، [سورة الأنعام، من الآية: 141].

[Ki ẹ si san ẹtọ (pẹlu yiyọ Zakat) rẹ ni ọjọ kika rẹ]. [suratu An'ãm 6, aayat: 141].

Gbogbo awọn alumọni ati awọn nkan ti a ri ninu ilẹ, idajọ wọn gẹgẹ bi idajọ nkan ti njade l'ati inu ilẹ naa ni yiyọ zaka rẹ, tori owo ti ari lati inu ilẹ ni gbogbo wọn.

Awọn nkan ti o ba jade l'ati ara ẹran ti on jẹ koriko funrarẹ, ati ti ere ọja, iyipo ọdun tiwọn ni ki ọdun o kọja l'ori ipilẹ won (oju owo), a o da wọn pọ mọ nkan ti  a ni tẹlẹ, a o si yọ zaka wọn ni igbati wọn bati too yọ zaka nibẹ.

Ko si idepo balaga ninu mọjẹmu zaka, bakan naa ko si ini lakae ninu mọjẹmu rẹ pẹlu, nitorina o jẹ ọranyan ninu owo ọmọde ati were l'ọdọ ọpọlọpọ awọn oni mimọ.

 5- Awọn owo ti ama n yọ zaka nibẹ:

 Zaka jẹ ọranyan ninu iran marun ninu iran owo:

Akọkọ: Awọn golu ati fadaka, ati gbogbo nkan ti o ba se deede wọn ninu awọn owo beba ti o wa l'awujọ.

Ondiwọn zakat ti o jẹ ọranyan ni idaarin idakan ninu idamẹwa ti o n se deede: (2.5%). Zaka ko si jẹ ọranyan titi ti ọdun yoo fi yipo l'ori rẹ, ti yoo si to (nisọb) ondiwọn zakat.

Ondiwọn goolu ti zakat jẹ ọranyan ninu rẹ ni ogun osuwọn. Osunwọn kọọkan se deede: (4.25 gram), Nitorina ondiwọn goolu ti a o ma yọ zakat nibẹ je: (85 gram).

Ondiwọn fadaka ti zakat jẹ ọranyan ninu rẹ ni ọgọrun meji (dirham).  Ọkọọkan nibẹ se deede: (2.975 gram), ti ondiwọn ti a o maa yọ zakat nibẹ yoo si je: (595 gram).

Sugbọn awọn owo beba ti an na nisin, ondiwọn nti zakat jẹ ọranyan ninu ẹ ni ki iye rẹ (ni igbati ọdun bayi po l'ori rẹ ni asiko yiyọ) se deede iye (85 gram) ninu goolu, tabi (595 gram) ninu fadaka. Idi niyi ti o fi maa nyatọ sirawọn nitori bi owo ilu kọọkan base lagbara si l'ati fi ra goolu tabi fadaka. Ni igbati o ba ti ni owo ti o to ra ọkan ninu awọn osuwọn mejeeji yi, yala ti goolu ni tabi ti fadaka, tabi ti o tun le, zakat ti jẹ ọranyan, l'aiwo orukọ wo ni n jẹ, Riyal ni tabi Dinar, tabi Frank, tabi Dollar, tabi Naira, ati bẹẹbẹẹ lọ. Ati l'aisi wo boya owo ẹyọ ni tabi beba tabi nkan miran. Ninu nkan ti atun gbọdọ mọ nipe iye owo a maa yatọ ni asiko kan si omiran, nitorinaa o pa dandan fun oluyọ zakat ki o kiye si iye ti yoo yọ ni asiko ti zakat jẹ ọranyan, ohun naa ni asiko ti ọdun yipo l'ori owo rẹ.

Eyi ti o ba wa le l'ori ondiwọn zakat (nisọb) ninu awọn owo, a o ma yọ zakat rẹ pẹlu isiro ondiwọn iye ti o ba le. Ẹri eleyi ni hadith 'Aliy t o sọ pe, Annabi ﷺ‬ sọ bayi pe:

((إذا كانت لك مائتا درهم وحال عليها الحول ففيها خمسة دراهم، وليس عليك شيء حتّى يكون لك عشرون ديناراً وحال عليها الحول ففيها نصف دينار، فما زاد فبحساب ذلك، وليس في  مال زكاة حتّى يحول عليه الحول)). [رواه أبو داود وهو حديث حسن].

((Ti o ba ni ogọrun meji diriamu, ti ọdun si yipo l'oriẹ, diriamu marun ni o se ọranyan nibẹ. Zakat ko jẹ ọranyan l'ori rẹ titi ti wa fi ni ogun goolu, ti ọdun yoo si yipo l'oriẹ, nigbanaa idaji goolu ni o jẹ ọranyan nibẹ. Eyi ti o ba le l'ori rẹ a o ma yọ zakat rẹ pẹlu isiro iye ti o ba jẹ. Zaka ko jẹ ọranyan ninu owo kan ti ti ọdun yoo fi yipo le l'ori)). [Abu-Daauda ni o gbaa wa, hadith ti o si dara ni].

Eyi ti o ba jẹ nkan ẹşọ goolu ti a pese fun kiko pamọ, tabi eyi ti a pese fun yiyá, zakat jẹ ọranyan l'ori rẹ, l'aisi aroye.

Eyi ti a pese fun lilo fun obinrin, ọrọ meji ni awọn alufa sọ nibẹ, eyi ti o rinlẹ nipe zakat jẹ ọranyan l'oriẹ. Nitori awọn ẹri ti o wa l'ori wipe zakat jẹ ọranyan l'ori goolu ati fadaka l'aiko se adayanri ọkan yatọ si omiran. Ati nitori hadith ti Abu-Daauda ati Al-Nasaai ati Tirmidhy gba wa l'ati ọdọ 'Amru ọmọ Shuaib l'ati ọdọ baba rẹ l'ati ọdọ baba-baba rẹ (رضي الله عنهما) wipe:

((أن امرأة أتت النبي ﷺ‬ ومعها ابنة لها وفي يد ابنتها مسكتان غليظتان من ذهبٍ، فقال لها: أتعطين زكاة هذا؟ قالت: لا. قال: ((أيسرك أن يسورك الله بهما يوم القيامة سوارين من نار؟))، فخلعتهما فألقتهما إلى النبي ﷺ‬، وقالت: هما لله ولرسوله)).

((Obirin kan wa si ọdọ Annabi ﷺ‬ ọmọ rẹ obinrin kan wa l'ọwọ rẹ, ẹgba ọwọ goolu meji ti o nipan wa l'ọwọ ọmọ obinrin yi. Annabi wa bii lere bayi wipe: ((N jẹ o n yọ zakat rẹ bi?)). Obirin naa dahun pe: rara. Annabi ba tun bi lere pe: ((N jẹ yoo dun maọ ninu ki Ọlọhun o fi ẹgba ina meji parọ fun ọ ti o ba di ọjọ ikẹhin?)). Ni obinrin naa ba bọ ẹgba ọwọ goolu mejeeji naa, ti o si ju wọn si Annabi, ti o si wipe: Oun fi ẹgba mejeeji naa kalẹ nitori Ọlọhun ati Ojisẹ rẹ.

Ati pẹlu nkan ti Abu-Dãud ati awọn miran gba wa l'ati ọdọ 'Aishat (رضي الله عنها) o sọ pe:

((دخل عليَّ رسول الله ﷺ‬ فرأى في يدي فتخات من ورق فقال: ((ما هذا يا عائشة؟) فقلت: صنعتهن أتزيَّن لك يا رسول الله، قال: ((أتؤدّين زكاتهن؟) قلت: لا، أو ما شاء الله، قال: ((هو حسبك من النار)).

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ wọ ile tọmi o si ri awọn oruka fadaka l'ọwọ mi, o si wipe: Kin ni eyi iwọ 'Aishat? Mo daun pe: Mo se wọn kin le ba maa fi se ọşọ fun Ọ ni iwọ ojisẹ Ọlọhun. Annabi bi pe: Njẹ o n yọ zakat rẹ bi? Mo daun pe: "rara" tabi "eyi ti Ọlọhun ba fẹ". Annabi dahun pe: O to fun ọ nibi ina)).

Awọn ohun alumọni ilẹ ati awọn nkan miran ti o yatọ si goolu, gẹgẹ bii aluulu, zakat ko jẹ ọranyan l'ori rẹ l'ọdọ gbogbo awọn alufa, ayafi ti o ba se wipe eyi ti a pese fun òwò ni, ni igbana a o mọ yọ zakat rẹ gẹgẹ bi zakat awọn nkan ti a fi nse òwò.

Ẹkeeji: Awọn ẹran ọsin:

Awọn naa ni: Rankumi maalu, ati ewurẹ, agunta, Zakat jẹ ọranyan l'ori eyi ti o njẹ koriko fun rara rẹ ni ọpọlọpọ asiko ninu ọdunkan, tori pe nkan ti o pọ yoo ma gba idajọ odidi. Ẹri eleyi ni ọrọ Annabi ﷺ‬:

((في كلّ إبل سائمة صدقة)). [رواه أحمد وأبو داود والنسائي].

((Zakat se ọranyan nibi gbogbo rankunmi ti o n jẹko fun rara rẹ)). [Ahmad ati Abu-Daauda ati Al-Nasãi ni wọn gbaa wa].

((في صدقة الغنم في سائمتها)). [رواه البخاري].

((Zakat se ọranyan nibi gbogbo ẹran ọsin gẹgẹ bii: ewurẹ, aguntan ati bẹẹbẹẹ lọ, eyi ti o n jẹ koriko fun rara rẹ)). [Bukhariy ni o gbaa wa].

Pẹlu mọjẹmu ki o pe ondiwọn (nisọb) zakat, ki ọdun si yipo l'oriẹ.


  

 Alaye ondiwọn zakat (nisọb) ninu awọn ẹran ọsin lọ bayi:

Ẹya

Ondiwọn Zakat

Iye ti a o yọ

Bẹrẹ lati

Titi de

5

9

Ewurẹ kan

10

14

Ewurẹ meji

15

19

Ewurẹ mẹta

20

24

Ewurẹ mẹrin

25

35

Ọmọ rankumi (abo) ti iya rẹ loyum, ti o ti pe ọdun kan (ti o ti n wọn ọdun keeji)

Rankunmi

36

45

Ọmọ rankumi (abo) ti o ti pe ọdun meji (ti o nwọ ọdun kẹta)

46

60

Hiqat, Eyi ti o ti pe ọdun mẹta (ti o nwọ ọdun kẹẹrin).

61

75

Ọmọ ọdun mẹrin (ti o nwọ ọdun kaarun) ninu rankumi.

76

90

Ọmọ rankumi (abo) meji ti wọn ti pe ọdun meji (ti wọn nwọ ọdun kẹẹta)

91

120

Hiqat (ọlọdun mẹta) meji.

Nti o bale l'ori 120

A o yọ ọmọ rankumi (abo) ti o ti pe ọdun meji ti o nwọ ọdun kẹẹta ninu ogoji, ti a o si ma yo Hiqat (ọlọdun mẹta) ninu aadọta, eleyi ni ọpọ awọn alufa sọ.


30

39

(Tẹbi'iu) ọmọ malu kan ti o pe ọdun kan

40

59

(Musina) ọmọ malu kan (abọ) ti o ti pe ọdun meji.

Mãlu

60

69

Tẹbi'iu meji

70

79

Tẹbi'iu kan ati  Musinat kan

Nti o ba le l'ori 79

A o ma yọ Tẹbi'iu ninu ọgbọn, a o si maa yọ Musinat kan ninu ogoji

Ewurẹ,

40

120

Ewurẹ kan

Aguntan ati

121

200

Ewurẹ meji

Agbò

201

300

Ewurẹ mẹta

Gbogbo nt i o ba le l'ori 300

Ao ma yọ ewurẹ kan ninu ọgọrun

Ẹri ni ori eleyi ni hadith Anas t wipe Abubakr kọ tira yi fun oun ni igbati o ran oun lọ si ilu Bahrein wipe:

((بسم الرحمن الرحيم، هذه فريضة الصّدقة التي فرض رسول الله ﷺ‬ على المسلمين والتي أمر الله بها رسوله، فمن سئلها من المسلمين على وجهها فليعطها ومن سئل فوقها فلا يعط، في أربع وعشرين من الإبل فما دونها من الغنم من كلّ خمسٍ شاة، فإذا بلغت خمساً وعشرين إلى خمسٍ وثلاثين ففيها بنت مخاض أنثى، فإذا ستّاً وثلاثين إلى خمس وأربعين ففيها بنت لبون أنثى، فإذا بلغت ستّاً وأربعين إلى ستّين ففيها حقّة، طروقة الجمل، فإذا بلغت واحدة وستّين إلى خمس سبعين ففيها جذعة، فإذا بلغت ـ يعني ستّاً وسبعين ـ إلى تسعين ففيها بنتا لبون، فإذا بلغت إحدى وتسعين إلى عشرين ومائة ففيها حقّتان، طروقتا الجمل، فإذا زادت على عشرين ومائة ففي كلّ أربعين بنت لبون، وفي كلّ خمسين حقّة، ومن لم يكن معه إلاّ أربع من الإبل فليس فيها صدقة إلاّ أن يشاء ربّها، فإذا بلغت خمساً من الإبل ففيها شاة، وفي صدقة الغنم في سائمتها إذا كانت أربعين إلى عشرين ومائة شاة، فإذا زادت على عشرين ومائة إلى مائتين شاتان، فإذا زادات على مائتين إلى ثلاثمائة ففيها ثلاث، فإذا دزات على ثلاثمائة ففي كلّ مائة شاة، فإذا كانت سائمة الرجل ناقصة من أرعين شاةً شاةٌ واحدة، فليس فيها صدقة إلاّ أن يشاء ربّها.)). [الحديث رواه البخاري].

((L'orukọ Ọlọhun Ajọkẹ aye Aşakẹ ọrun, eleyi ni Zakat ọraayan, eyi ti ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ şe ni ọranyan l'ori gbogbo awọn Musulumi, ti Ọlọhun si pa ojisẹ rẹ l'asẹ pẹluẹ. Ẹnikẹnin ti wọn ba bere deede zakat l'ọwọ rẹ ninu awọn musulumi, o di dandan ki o yọ, ẹni ti wọn ba beere ju iye zakat lọ l'ọwọ rẹ ko ni fun wọn. L'ori rankumi merinlelogun tabi n ti koto ninu ewurẹ, aguntan ati bẹẹbẹẹ, a o maa yọ ewurẹ kan ni ori marun marun. Ti o ba ti pe mẹẹdọgbọn titi de ọgbọn o le marun ọmọ (abo) ọdunkan (ti owọ ọdunkeji) ni a o yọ. Lati ọgbọn ati mẹfa titi de ogoji o le marun, a o maa yọ ọmọ ọdun meji (abo) (ti o nwọ ọdun kẹẹta). Lati ogoji ati mẹfa titi de ọgọta a o maa yọ Hiqat; ọmọ ọdun mẹta (abo) eyi ti o ti too gun, (ti o n wọ ọdun kẹẹrin). Ti o ba pe ọgọta o le ẹyọkan titi de ãdọrin ati marun, ao maa yọ Jaz'an ọmọ ọdun mẹrin (ti onwọ ọdun kaarun). Ti o ba pe ãdọrin ati mẹfa titi de ãdọrun, a o maa yọ ọmọ ọlọdun meji (abo) (ti o nwọ ọdun kẹẹta), a o yọ meji rẹ. Ti o ba pe ãdọrun o le ẹyọkan titi de ọgọfa (120) a o maa yọ Hiqọt; ọmọ ọdun mẹta, (abo) eyi ti o ti too gun, a o yọ meji rẹ. Ti o ba le lori ọgọfa (120) ninu gbogbo ogoogoji a o maa yọ ọmọ rankumi (abo) ọlọdun meji, ti a o si ma yọ Hiqọt; ọmọ ọdun mẹta ninu gbogbo ãdọta. Ẹni ti o ba se wipe rankumi mẹrin pere l'oni, zakat ko jẹ ọranyan l'ori rẹ, afi ti o ba fẹ. Sugbọn ti o ba ni rankumi marun, ewurẹ kan pere ni yoo yọ.

Sugbọn zakat ewurẹ, agunta agbo ati bẹẹbẹẹ lọ, ti a nda jẹko, ti o ba pe ogoji titi de ọgọfa (120) ewurẹ kan ni yoo yọ. Ti o ba ti le l'ori ọgọfa (120) titi de ọgọrun meji, ewurẹ meji ni o jẹ ọranyan. Ti o ba le l'ori ọgọnrun meji titi de ọgọrum mẹta ewurẹ mẹta ni o jẹ ọranyan. Ti o ba le l'ori ọgọrun mẹta, ewurẹ kan ni o jẹ ọranyan ninu gbogbo ọgọrun kan. Ti ẹran ti eniyan ndaa jẹko ba di ni ẹyọkan ti yoo fi pe ogoji, zakat ko jẹ ọranyan l'ori rẹ afi ti o ba fẹ)). [Bukhariy ni o gbaa wa].

Bakanna ni hadith Mu'adh ọmọ Jabal t wipe:

((أن النبي ﷺ‬ بعثه إلى اليمن فأمره أن يأخذ من كلّ ثلاثين بقرة تبيعاً أو تبيعةً، وفي كلّ أربعين مسنة)). [رواه أحمد وأصحاب السنن].

Annabi ﷺ‬ ran oun lọ si ilu Yamani ti o si paa l'asẹ pe ki o maa gba ọmọ malu kan ti o pe ọdunkan akọ tabi abo ninu gbogbo ọgbọọgbọn, ki o si maa mu ọmọ malu ti o ti pe ọdun meji ninu gbogbo ogoogoji)). [Ahmad ati awọn miran wọn gbaa wa].

Nkan ti o ba jade l'ati ara awọn ẹran ti andajẹ, a o ma da wọn pọ mọ ti ilẹ ti o ba tito ondiwọn zakat (nisọb). Sugbọn ti ti ilẹ ko ba to ondiwọn zakat (nisọb) afi pẹlu eleyi ti a dapọ mọọ yi, a o ka pọ mọọ, a o si gba wipe iyipo ọdun ti de baa bẹrẹ lati igbati o ti pe (nisọb) ondiwọn zakat.

Ti a ba pese awọn ẹran ọsin yi fun òwò, a o maa yọ zakat rẹ gẹgẹ bi a ti se nyọ zakat awọn nkan òwò ni. Ti a ba pese wọn fun lilo, tabi ki o le ma pọ si, zakat ko jẹ ọranyan. Ẹri lori eleyi ni hadith Abi-Huraera t.

((ليس على المسلم في عبده ولا فرسه صدقة)). [أخرجه البخاري ومسلم].

((Ko jẹ ọranyan lori Musulumi ki o yọ zakat ẹru rẹ, ati ẹsin rẹ)). [Bukhariy ati Muslim ni o gbaa wa].

Ẹkẹẹta: Awọn nkan-ọgbin ati awọn eeso:

Ti wọn bati to (nisọb) ondiwọn zakat, a o ma yọ zakat wọn l'ọdọ ọpọ awọn alufa. Ondiwọn zakat (Nisọb) l'ọdọ wọn ni apo (wasaq) marun. Nitori ọrọ Annabi t.

((ليس فيما دون خمسة أوسق صدقة)). [متفق عليه].

((Zakat ko jẹ ọranyan l'ori nkan ti ko bato apo (wasaq) marun)). [Bukhariy ati Muslim panupọ l'ori rẹ]. Apo (wasaq) kan jẹ ọgọta igba (Sa'i).

Ondiwọn (nisob) naa si jẹ ọgọrun mẹta igba (Sa'i). Ondiwọn ọkaa-baba  ti o ba dara yoo maa sumọ (652.800 kg).

Ko si mọjẹmu iyipo ọdun l'ori awọn nkan ọgbin ati eso. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَآتُوا حَقَّهُ يَوْمَ حَصَادِهِ[. [سورة الأنعام، من الآية: 141].

[Ki ẹ si san ẹtọ (pẹlu yiyọ Zakat) rẹ ni ọjọ kika rẹ]. [suratu An'ãm 6, ãyat: 141].

Iye ti o jẹ ọranyan ti a o yọ ninu nkan ọgbin tabi eso ni idakan ninu idamẹwa, ti o ba se eyi ti ojo nrọ si ni. Sugbọn ti o ba se eyi ti anwọn omi si fun rarawa ni, idaji idakan ninu idamẹwa ni o jẹ ọranyan nibẹ. Nitori ọrọ Annabi ﷺ‬:

((فيما سقت السماء والأنهار والعيون أو كان عثرياً العشر، وفيما سُقي بالسواني أو النضح نصف العشر)). [أخرجه البخاري].

((Irugbin ti o ba dagba soke pẹlu omi òjò, tabi omi odò, tabi omi isẹlẹru, tabi omi adagun, idakan ninu idamẹwa ni o jẹ ọranyan nibẹ, sugbọn irugbin ti o ba dagba pẹlu wiwọn omi si, pẹlu ọwọ tabi pẹlu ẹrọ (enjini), idaji idakan ninu idamẹwa ni o jẹ ọranyan nibẹ)). [Bukhariy ni o gba wa].

Ẹkẹẹrin: Awọn nkan òwò:

Ohun naa ni eyikeyi nkan ti Musulumi pese fun tita, rira, ti o si jẹ eyi ti o fẹju julọ ninu awọn owo Zakat. Zakat jẹ ọranyan nibẹ nigbati o ba pe (nisọb) ondiwọn zakat. Itumọ rẹ ni ki iye nkan naa o se deede (nisọb) ondiwọn golu ati fadaka. Ogun goolu ti o se deede (85 gram) goolu, tabi ọgọrun meji diram ti o se deede (595 gram) fadaka. A o ma wo elo l'oto ninu goolu tabi fadaka ni igbati ọdun ba yipo le l'ori, eyi ti awọn alaini yoo ba se anfaani nibẹ julọ. Iye ti a o siwo ni iye ti o to nigbati afẹ yọ zakat rẹ l'ẹyin ti ọdun ti yipo l'ori rẹ, ki i se iye ti araa.

Iye ti o jẹ ọranyan ti a o yọ ninu ẹ ni idaarin idankan ninu idamẹwa gbogbo iye ọjà naa. Ao ma da ere pọ mọ oju-owo, ti oju-owo ba ti to (nisọb) ondiwọn zakat, l'alai reti iyipo ọdun tuntun miran mọ fun ere. Sugbọn ti oju-owo ko ba to (nisọb) ondiwọn zakat afi pẹlu ere yi, iyipo ọdun yoo bẹrẹ nigbati oju-owo naa pe (nisọb) ondiwọn zakat.

Ẹkaarun: Awọn alumọni ilẹ, ati awọn nkan ti a ri he ninu ilẹ:

 a- Awọn alumọni ilẹ:

Awọn naa ni gbogbo nkan ti o ja de l'ati inu ilẹ ninu nkan ti Ọlọhun da sinu ilẹ ti o jẹ n ti o niye l'ori, ti kii se irugbin. Gẹgẹ bi: goolu, (fadaka), irin, oje, aluulu ati epo-bẹtiro ati awọn nkan miran ti o yatọ siwọn. Zakat jẹ ọranyan l'ori wọn nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]يَا أَيُهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَنْفِقُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا كَسَبْتُمْ وَمِمَّا أَخْرَجْنَا لَكُم مِّنَ الأَرْضِ[. [سورة البقرة، من الآية: 267].

[Ẹyin ti ẹ gbagbọ Ẹ mã ná ninu ohun ti o dara ninu eyiti ẹ şe ni işẹ ati ninu ohun ti Awa mu jade fun yin l'ati inu ilẹ]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 267]. Ko si iye meji wipe awọn alumọni ilẹ wa ninu nkan ti Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) mu jade fun wa lati inu ilẹ.

Awọn ọpọ ninu awọn alufa ri wipe zakat ko jẹ ọranyan ninu rẹ titi ti yoo fi to (nisọb) ondiwọn zakat. Atipe idaarin idakan ninu idamẹwa ni o jẹ ọranyan, gẹgẹ bi ti zakat goolu ati fadaka.

Zakat rẹ jẹ ọranyan ni igbati aba tiri. Ko si majẹmu iyipo ọdun fun.

 b- Awọn nkan ti a ri ninu ilẹ (Al-rrikãz):

Awọn nkan ti a ri ninu ilẹ (al-rrkaz), awọn naa ni eyi ti awọn eniyan asiko aimọkan ti ri mọ ilẹ, tabi ti awọn keferi ri mọ ilẹ, koda ko ma jẹ asiko aimọkan, l'ori ilẹ Islam ni, tabi l'ori ilẹ awọn keferi, tabi l'ori ilẹ awọn ti adeun n bẹ l'aarin awa pẹlu wọn. Ti ami keferi si wa l'oriẹ tabi l'ori apakan rẹ, gẹgẹ bi awọn orukọ wọn, tabi orukọ awọn ọba wọn, tabi awọn aworan wọn, tabi aworan awọn agbelebu tabi ooşa wọn.

Sugbọn ti o ba se wipe ami ti o wa l'oriẹ jẹ ti awọn musulumi gẹgẹ bi orukọ Annabi ﷺ‬, tabi ọkan l'ara awọn arole (olori) awọn musulumi, tabi aayat kan ninu Al-Qurãn Karim. Nkan ti a ri he ni eyi, ki i se rikãz. Ti ko basi ni ami, gẹgẹ bi awọn paanun ati nkan ẹşọ, nkan ti ari he ni ohun naa, ko le jẹ tiwa afi l'ẹyin igabti aba fi wẹlọ (fun ọdun kan), tori wipe owo musulumi ni.

Idakan ninu ida marun ni o jẹ ọranyan ninu rikãz. Nitori hadit Abi-Huraera t wipe:

أن رسول الله ﷺ‬ قال ((وفي الركاز الخمس)).

Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọpe: ((Idakan ninu ida marun ni o jẹ ọranyan ninu rikãz)).

Idakan ninu ida marun ni o jẹ ọranyan ninu kekere rikãz ati eyi ti o pọ rẹ, l'ọdọ ọpọ awọn oni mimọ. Ibi ti a o si mọ yọ si ni ibi ti a n yọ nkan ti awọn olujagun ẹsin ri logun laijagun (al-faeu). Eyi ti o sẹ ku ninu rikaz jẹ ti ẹni ti o ri i l'ọdọ apapọ awọn oni mimọ. Nitori wipe 'Umaru t ko eyi ti o sẹ ku ninu rikãz fun ẹni ti o rii ni.

 6-Awọn ti a o ma yọ zakat fun:

 Awọn mẹjọ ni o tọ ki a yọ zakat fun, awọn ni:

Akọkọ: Awọn alaini atẹwọ gba ọrẹ; awọn ni awọn ti wọn ko ri nti wọn o jẹ, tabi wọn ri diẹ. Awọn wọn yi a o fun wọn ni nkan ti yoo to wọn di ọdunkan ninu zakat.

Ẹkeeji: Awọn talaka; Awọn wọn yi ni ohun ti wọn ni ko kaju bukaata wọn, nipa bayi awọn tun san ju awọn alaini lọ. Awọn eleyi naa ao ma fun wọn ni nkan ti yoo to wọn di ọdunkan.

Ẹkẹẹta: Awọn osişẹ zakat; awọn ti wọn ngba zakat jọ l'ọwọ awọn olowo, ti wọn o si şe amojuto rẹ, ti wọn o si pin fun awọn ti o tọ si pẹlu aşẹ l'ati ọdọ alaşẹ. A o ma fun awọn eyan wọnyi ni zakat ni deede owo işẹ wọn.

Ẹkẹẹrin: Awọn ti anfa ọkan wọn mọra; wọn pin si orisi meji: a- awọn keferi (awọn alaigbagbọ) ati b- awọn musulumi.

a- Awọn keferi (awọn alaigbagbọ), a o ma fun wọn ninu zakat nigbati a ba ni ireti wipe wọn o gba Islam, tabi wọn o dawọ aburu wọn si awọn musulumi duro, ati bẹẹbẹ lọ.

b- Awọn mususlumi, a o ma fun wọn ni zakat lati fun igbagbọ wọn lagbara, tabi ki ẹlomiran bii tiẹ le gba Islam, ati bẹẹbẹ lọ.

Ẹkaarun: Rira awọn ẹru, awọn ti a kọ iwe ominira fun ti wọn ko ri nkan ti wọn o fi sọ arawọn di ọmọluabi. A o fun ẹniti wọn kọ iwe ominira fun ni iye ti yoo to l'ati bọ l'oko ẹru. Awọn alufa si tun se rira ẹru l'ati inu owo zakat l'ẹtọ, l'ati le baa bọ okun ẹru kuro l'ọrun wọn.

Ẹkẹẹfa: Awọn onigbese; wọn pin si meji: a- ẹniti o jẹ gbese funrarẹ, tabi b- ẹniti o fẹ bayan san gbese.

a- Ẹniti o jẹ gbese funrarẹ ti ko si l'agbara ati san gbese naa, a o fun ninu zakat deede iye ti yoo san gbese rẹ.

b- Ẹniti o fẹ ba eyan san gbese nitori ati şe atunşe l'arin eniyan meji, a o fun ni iye ti yoo to san gbese naa, koda boluwarẹ jẹ ọlọrọ.

Ẹkẹẹje: Si oju ọna ti Ọlọhun; itumọ rẹ ni awọn ti wọn n jagun si oju ọna Ọlọhun, lai gba owó osù.

Ẹkẹẹjọ: Awọn ọmọ ojuọna; Eyiun ni onirin-ajo ti esenpa rẹ tan, ti ko ni owo ti yoo gbe pada si ilu rẹ. A o fun ninu zakat iye ti yoo to l'ati pada si ilu rẹ.

Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) darukọ awọn iran wọnyi ninu ọrọ rẹ pe:

]إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقُرَاءِ وَالمَسَاكِينِ وَالعَامِلِينَ عَلَيهَا وَالمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيْضَةً مِّنَ اللهِ وَاللهُ عَلِيْمٌ حَكِيمٌ[. [سورة التوبة الآية: 60].

[Ọrẹ (zakat) wà fun awọn alaini ati awọn talaka ati awọn ti nşişẹ rẹ ati awọn ti ọkàn wọn fẹ gba (Islam) ati fun irapada awọn ẹru ati awọn ti o jẹ gbese ati si oju ọna ti Ọlọhun ati ọmọ ojuọna, ọranyan ni lati ọdọ Ọlọhun, Ọlọhun ni Olumọ, Ọlọgbọn]. [suratu Taobah 9, aayat: 60].

 7-Zakat (fitr) Itunu ãwẹ (Jákà):

 a- Ọgbọn ati ẹkọ ti o wa nibi sise e ni ọranyan:

Zakat (fitr) itunu ãwẹ jẹ ọranyan l'ati lee fọ alawẹ mọ kuro ni ibi eeri ọrọ ti ko tọ ati ọrọ isọkusọ, ti o si tun jẹ onjẹ fun awọn alaini ati irọwọn l'ọrọ kuro nibi agbe sise ni ọjọ ọdun. Nitori hadith ọmọ 'Abbas t ti o sọ wipe:

((فرض رسول الله ﷺ‬ زكاة الفطر طهرة للصائم من اللغو والرفث وطعمة للمساكين)).

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ şe zakat (fitr) itunu awẹ ni ọranyan l'ati le fọ alawẹ mọ kuro ni ibi eeri ọrọ ti ko tọ ati ọrọ isọkusọ, ti o si tun jẹ onjẹ fun awọn alaini)). [Abu-daauda ati Ibn Mọjah wọn gbaa wa].

 b- Idajọ Re:

Ọranyan l'ojẹ l'ori gbogbo musulumi l'ọkunrin ati l'obinrin, l'ọmọde ati l'agba, ọmọluabi ati ẹru. Nitori hadith ọmọ 'Umaru (رضي الله عنهما) ti o sọ pe:

((فرض رسول الله ﷺ‬ زكاة الفطر من رمضان صاعاً من تمرٍ أو صاعاً من شعيرٍ على العبد والحرّ، والذكر والأنثى، والصغير والكبير، من المسلمين، وأمر بها أن تؤدّى قبل خروج الناس إلى الصلاة)).

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ şe zakat (fitr) itunu ãwẹ ni ọranyan, (igba) sọ'in labidun kan, tabi (igba) sọ'in ọka-baba kan, l'ori gbogbo ọmọluabi ati ẹru, ọkunrin ati obinrin, ọmọde ati agba, ninu awọn Musulumi, o si paşẹ yiyọ rẹ siwaju jijade awọn eniyan lọsi ibi irun)).

Bakanna ni afẹ ki a yọ ti oyun inu naa.

O pan dandan l'ori Musulumi ki o yọ Jaka ti ararẹ, ati awọn ti inawo wọn jẹ ọranyan l'ori rẹ gẹgẹ bi: iyawo, ati ẹbi. Ko si pa dandan afi l'ori ẹniti o ni onjẹ ti yoo to oun ati awọn rẹ, ti yoo tun sẹku l'ọjọ ọdun ati oru rẹ.

 e- Ondiwọn rẹ:

Ondiwọn ti o jẹ ọranyan ni (igba) sọ'in kan ninu onjẹ ti o pọ ju ninu ilu, gẹgẹ bi buru tabi ọka-baba tabi labidun, tabi irẹsi, tabi igbado. Igba (sọ'in) (Mudu mẹta) n se deede nkan ti o sumọ (2.176 kg).

Yiyọ iye owo ti o se deede rẹ dipo rẹ ko lẹtọ l'ọdọ ọpọ awọn alufa. Toripe eleyi un yapa si nkan ti Annabi ﷺ‬ pa wa l'aşẹ rẹ. Atipe o tun yapa si isẹ awọn saabe. رضي الله عنهم.

 ẹ- Asiko yiyọ rẹ:

O ni asiko meji: a- akọkọ asiko ti o tọ: a le yọ ni ọdun ku ọla tabi ọdun ku ọjọ meji. b- Ẹkeeji: asiko ti o ni ọla, ohun naa ni l'ati igbati alifajiri bati yọ ni ọjọ ọdun titi di ki a to kirun ọdun. Nitori Annabi ﷺ‬ paşẹ yiyọ rẹ siwaju ki awọn eniyan to lọ kirun. Lilọ yiyọ rẹ l'ara di ẹyin irun ọdun ko tọ. Ti enian ba lọọ l'ara di ẹyin irun ọdun o ti di sara, ti yoo si l'ẹşẹ pẹlu ilọ lara rẹ.

 5- Ibi ti ao ma yọ ọ si:

Ao ma yọ zakat itunu awẹ fun awọn talaka ati alaini, toripe awọn ni wọn tọsi ju awọn miran lọ.

 Origun Kẹẹrin: Gbigba Ãwẹ Osu Rọmadan:

 1- Itumọ rẹ:

 Ãwẹ ninu ede larubawa ni: Ikoduro.

Itumọ rẹ ninu Shariat (Islam) ni: iko ẹnu duro kruo nibi gbogbo n ti o mba ãwẹ jẹ, lati igbati alifajri keji bati yọ titi di igbati òrún ba wọ.

 2- Idajọ rẹ:

Gbigba ãwẹ osù Rọmadan jẹ ọkan ninu awọn opo Islam ati awọn origun rẹ ti o tobi. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُم تَتَّقُونَ[. [سورة البقرة الآية: 183].

[Ẹyin ti ẹ gbagbọ! A şe ãwẹ ni ọranyan le yin l'ori gẹgẹbi A ti şe e ni ọranyan le awọn ẹniti o şiwaju nyin l'ori ki ẹyin le bẹru (Ọlọhun)]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 183].

Ati nitori ohun ti ọmọ 'Umar t gba wa wipe: Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọpe:

((بني الإسلام على خمس: شهادة أن لا إله إلاّ الله، وأنّ محمّداً رسول الله، وإقام الصّلاة، وإيتاء الزّكاة، وصوم رمضان، وحجّ بيت الله)). [متفق عليه].

((Islam duro l'ori origun marun: ijẹri pe ijọsin ko tọ fun ẹnikankan afi Ọlọhun, ati pe Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni, imaa gbe irun duro, imaa yọ Zakat, ima gba ãwẹ Rọmadan, ima lọ si hajj)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ l'ori rẹ].

Ọlọhun se gbigba ãwẹ Rọmadan l'ọranyan l'ori ijọ Musulumi ninu ọdunkeji l'ẹyin Hijira.

 3-Ọlá ati ọgbọn ti o wa nibi sise e ni ọranyan:

Osu Rọmadan jẹ asiko kan ti o se pataki fun itẹle ti Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga), ki o su yi ba eniyan l'aye õre nla ati ãnu ni l'ati ọdọ Ọlọhun, ti Ọlọhun manse fun ẹniti o ba wu ﷻ‬ ninu awọn ẹru Rẹ, ki daradara rẹ le baa lekun, ki ipo rẹ sile ga si, ki o si le pa ẹsẹ rẹ, rẹ, ki asepọ wọn ati Olusẹda wọn o tun bọ l'agbara si, l'ati le kọ ẹsan ti o pọ fun wọn, ki iyọnu Ọlọhun silee bawọn, ki ọkan wọn si kun fun ibẹru Ọlọhun ati ipaya Rẹ.


 Ninu awọn ẹri ti o wa l'ori ọla rẹ ni:

a- Ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنْزِلَ فِيهِ القُرْآنُ هُدىً لِلنَّاسِ وَبَيِّنَاتٌ مِّنَ الهُدَى وَالفُرْقَانِ فَمَنْ شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ وَمَنْ كَانَ مَرِيضاً أَوْ عَلَى سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِّنْ أَيَّامٍ أُخَرَ يُرِيدُ اللهُ بِكُمُ اليُسْرَ وَلاَ يُرِيدُ بِكُمُ العُسْرَ وَلِتُكْمِلُوا العِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللهَ عَلَى مَا هَدَاكُم وَلَعَلَّكُم تَشْكُرُون[. [سورة البقرة، الآية: 185].

[Oşu Rọmadan eyiti à sọ Al-Qurãn kalẹ ninu rẹ, ilana ni o jẹ fun awọn enian ati ẹri ododo ti ilana-otitọ naa ati ipinya laarin (ododo pẹlu irọ); nitorina ẹnikẹni ti oşù na ba se oju rẹ ninu yin, njẹ ki o gba ãwẹ ninu rẹ; ẹniti o ba nşe aisan tabi ti o mbẹ l'ori irin-àjò (yio san ãwẹ na pada ninu) onka awọn ọjọ miran. Ọlọhun nfẹ irọrun pẹlu yin kò si fẹ inira fun nyin, ki ẹ si şe aşepe onka naa, ki ẹ ba le şe agbega fun (orukọ) Ọlọhun nitori ọna ti O fi mọ yin ati ki ẹnyin le mã se ọpẹ]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 185].

b- Ẹgbawa Abu Huraerah t ti o sọ wipe: Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ pe:

((من صام رمضان إيماناً واحتساباً غفر له ما تقدم من ذنبه)).

((Ẹnikẹni ti o ba gba ãwẹ Rọmadan ni ẹniti o gba Ọlọhun gbọ ti o si nwa oju rere Ọlọhun, yoo di ẹni afori jin nibi gbogbo ẹşẹ rẹ ti o ti sẹ siwaju)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ le l'ori].

d- Ẹgbawa tun wa lati ọdọ rẹ (Abu-huraera) t ti o sọ wipe: Ojisẹ Ọlọhun sọpe:

((يضاعف الحسن عشر أمثالها إلى سبعمائة ضعف، قال الله ﷻ‬: إلاّ الصوم، فإنه لي وأجزي به، يدع شهوته وطعامه من أجلي، للصائم فرحتان، فرحة عند فطره وفرحة عند لقاء ربه، ولخلوف فيه أطيب عند الله من ريح المسلك)).

((Dãda kan yoo mọ di ilọpo mẹwa titi ti yoo fi di ilọpo lọna ọgọrun meje. Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) sọ ba yi pe: afi ãwẹ, emi (Ọlọhun) ni moni emi si ni ma san ẹsan l'ori rẹ, alãwẹ yoo mafi adun ati onjẹ rẹ kalẹ nitori ti temi (Ọlọhun). Inu alãwẹ yoo ma dun ni igba meji: ni igbati o ba nsinu, ati igbati o ba npade Ọlọhun rẹ, òrún ẹnu alãwẹ o dara lọdọ Ọlọhun ju òrún turare alimisiki lọ)). [Bukhariy ati Muslim ni o gbaa wa, gbolohun ti Muslim ni eyi].

e- Adua ti Ọlọhun gba ni adua alãwẹ. Annabi ﷺ‬ sọ wipe:

((للصائم عند فطره دعوة لا تردّ)).

((Adua ti Ọlọhun gba ni adua ti alãwẹ başe ni igba ti o ba fẹ sinu)).

Nitori idi eyi o dara ki alãwẹ maa se ojukokoro ati lo anfãni asiko nla yi pẹlu ki o ma pe Oluwa rẹ ki o si maa tọrọ adua, ki Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) le ba fi se kongẹ rẹ, ki o le baa se orire aye ati ti ọrun.

ẹ- Ọlọhun şa oju ọna kan l'ẹsa ni ọgba idẹra (Alijanna) fun awọn olugbãwẹ, ẹnikankan ko ni gba ibẹ wọ ile afi awọn olugbãwẹ ki o le baa mọ jẹ apọnle fun wọn, ati l'ati se idayanri si ẹlomiran. Sahalu ọmọ Sa'ad t sọ wipe: ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬  sọ wipe:

((إن في الجنة باباً يقال له: "الريان" فإذا كان يوم القيامة قيل: أين الصائمون؟ فإذا دخلوا أغلق عليهم فلم يدخل منه أحد)).

((Dajudaju ilẹkun kan wa ninu ọgba idẹra (Alijanna) orukọ rẹ ni: "Al-rrọyãn". Ti o ba di ọjọ alikiyamọ wọn a beere wipe: awọn olugbãwẹ da? (Ki wọn wa wọle). Ni igbati wọn ba wọle tan wọn o ti ilẹkun yi, ki ẹnikankan malee gba ibẹ kọja l'ẹyin wọn)).

f- Ãwẹ yoo sipẹ fun olugbãwẹ ni ọjọ alikiyamọ. Ẹgbawa wa lati ọdọ 'Abdullahi ọmọ 'Amuru ọmọ Al-'Ãs t o sọ wipe: ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ pe:

((الصيام والقرآن يشفعان للعبد يوم القيامة، يقول الصيام أي ربّ منعته من الطعام والشهوة فشفّعني فيه، ويقول القرآن: منعته النوم بالليل فشفّعني فيه. قال: فيشفعان)).

((Ãwẹ ati Al-Qurãn yoo sipẹ fun enian ni ọjọ alikiyamọ, ãwẹ yoo sọ pe: Iwọ Oluwa mi, mo gba onjẹ ati adun l'ọwọ rẹ, nitorinaa gba ipẹ mi fun, ti Al-Qurãn naa yoo sọ pe: mo gba orun l'ọwọ rẹ l'oru, mio jẹ ki o sun, nitotrinaa gba ipẹ mi fun. O sọ pe: nitorina wọn o gba ipẹ wọn)). [Ahmadu ni o gbaa wa].

g- Ãwẹ yoo mu ki alãwẹ ba suru ati ifarada rẹ, toripe o nkọ awọn nkan adun ati nkan ti o wuu fun, bakannaa ni lati le korarẹ ni ijanu.


 4-Awọn Mọjẹmu Ijẹ Ọranyan Ãwẹ:

Awọn alufa panupọ l'ori pe ãwẹ jẹ ọranyan l'ori Musulumi ti o ti de ipo balaga, ti o si ni lakae, ti o sini alãfia, ti o jẹ olugbele ti ko si l'ori irin ajo, o si jẹ ọranyan l'ori obinrin ti ko si lasiko ẹjẹ nkan osu ati ẹjẹ ibimọ.

 5- Awọn Ẹkọ Gbigba Ãwẹ:

a- Ki alãwẹ jinna si ọrọ ẹyin ati ofofo ati awọn nkan miran ti Ọlọhun şe ni eewọ. Nitorina; o se ọranyan fun Musulumi ki o ko ahan rẹ ni ijanu kuro nibi nkan ti Ọlọhun şe l'ewọ, ki o si sọọ ki o ma fi sọ ọrọ ẹyin, ọrọ-ọlọrọ. Annabi ﷺ‬  sọ wipe:

((من لم يدع قول الزور والعمل به فليس لله حاجة في أن يدع طعامه وشرابه)). [رواه البخاري].

((Ẹnikẹni ti ko ba fi ọrọ irọ ati işẹ irọ silẹ, Ọlọhun koni bukata si ki onitọun fi jijẹ ati mimu rẹ silẹ)). [Bukhariy ni o gbaa wa].

b- Ki o maa jẹ sãri, toripe o ma nran alãwẹ l'ọwọ l'ati gba ãwẹ, ti yoo lo ọsan rẹ pẹlu irọrun, ti yoo sile se işẹ rẹ dãda. Dajudaju Annabi ﷺ‬ se wa l'oju kokoro l'oriẹ pẹlu ọrọ rẹ:

((السحور أكلة بركة، فلا تدعوه، ولو أن يجرع أحدكم جرعة من ماء فإن الله ﷻ‬ وملائكته يصلون على المتسحرين)). [رواه أحمد].

((Sãri onjẹ alubarika ni, ẹ ma se fisilẹ o, koda bi o se wipe ki ẹmu gẹẹ kan omi ni, toripe Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) ati awọn mọlaikat rẹ wọn n se ikẹ fun awọn olujẹ sãri)). [Ahmad ni o gbaa wa].

e- Ki alãwẹ ma yara sinu lẹyin ti o ba ti daju pe õrùn ti wọ. Annabi  ﷺ‬ sọ pe:

((لا يزال الناس بالخير ما عجلوا الفطر)). [متّفق عليه].

((Awọn eniyan wọn o ni yẹ wọn o ni gbo ninu õre l'opin igbati wọn ba n yara sinu)). [Bukhariy ati Musulumi ni o gbaa wa].

ẹ- Ki o maa se ojukokoro ati ma sinu pẹlu rutọb tabi labidun (tamuru). Nitori sunna ni. Anas t sọ wipe:

((كان رسول ﷺ‬ يفطر قبل أن يصلي على رطبات، فإن لم تكن رطبات فتمرات، فإن لم تكن حسا حسوات من ماء)). [رواه أبو داود].

Annabi ﷺ‬ ama sinu siwaju ki o to ki irun mọgari pẹlu awọn rutọb, ti ko ba ri rutọb yoo fi labidum (tamuru) sinu, ti ko ba ri labidun (tamuru) yoo mu awọn gẹẹ omi bi melo kan)). [Abu Daaud ni o gbaa wa].

f- Ki o ma ka Al-Qurãn ni ọpọlọpọ igba, ati iranti Ọlọhun, ati sise ẹyin fun, ati itọrẹ-ãnu, ati ise dãda, ki o si ma yan nafila l'ọpọlọpọ, ati işẹ dãda miran. Nitori ẹgbawa ọmọ 'Abas(رضي الله عنهما)  o sọ wipe:

((كان رسول الله ﷺ‬ أجود الناس بالخير، وكان أجود ما يكون في رمضان حين يلقاه جبريل، وكان جبريل يلقاه في كلّ ليلة من رمضان، فيدارسه القرآن، فلرسول الله ﷺ‬ حين يلقاه جبريل أجود بالخير من الريح المرسلة)). [رواه البخاري ومسلم].

((Annabi ni ẹni ti o ma n ta ọọrẹ ju, sugbọn o tun mọ wa n ta ọrẹ pupọ ninu ãwẹ Ramadan ni igbati o ba n pade Jibril. Jibril a si maa pade rẹ ni gbogbo òru rọmadan, ti wọn o si jọ ka Al-Qurãn, ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ a maa ta ọrẹ pupọ ni igbati o ba n pade Jibril, ju atẹgun yaagbo yaaju lọ)). [Bukhariy ati Musulumi ni wọn gaa wa].

 6- Awọn nkan ti o mba ãwẹ jẹ:

a- Jijẹ ati mimu l'ọsan ãwẹ ni ẹniti o fi oju silẹ. Bakanna ni gbogbo awọn nkan miran ti o le ja ãwẹ, gẹgẹ bi abẹrẹ tabi õgun lilo l'ati ẹnu, idajọ wọn bi idajọ jijẹ ati mimu ni. Sugbọn fifa ẹjẹ diẹ l'ara olugbãwẹ fun yiyẹ ẹjẹ wo l'apejuwe ko ba ãwẹ jẹ.

b- Ilopọ pẹlu obinrin l'ọsan ãwẹ, o ba ãwẹ jẹ, o si pa dandan ki o wa ituba lọsi ọdọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) nitoripe o tapa si apọnle osu yi, yoo si san ãwẹ ọjọ yi pada, yoo si tun san itanran, pẹlu: ki obọkun l'ọrun ẹru, ti ko bari ẹru yoo gba ãwẹ osu meji lerawọn, ti ko ba lagbara; yoo bọ ọgọta alaini, yoo fun ẹnikọọkan wọn ni igba (sọin) meji ọka-baba (buru) tabi onjẹ miran ti awọn ara ilu banjẹ. Nitori hadith Abi Huraerah t o sọ pe:

((بينما نحن جلوس عند النبي ﷺ‬ إذ جاءه رجل، فقال: يا رسول الله هلكت، قال: ما لك؟ قال: وقعت على امرأتي وأنا صائم، فقال رسول الله ﷺ‬: هل تجد رقبة تعتقها؟ قال: لا. قال: فهل تستطيع أن تصوم شهرين متتابعين؟ قال: لا. قال: فهل تجد إطعام ستين مسكيناً؟ قال: لا. قال: فمكث النبي ﷺ‬ فبينما نحن على ذلك أُتِيَ النبي ﷺ‬ بعَرَق فيه تمر ـ والعَرَق المكتل ـ، قال: أين السائل؟ فقال: أنا. قال: خذ هذا فتصدق به. فقال الرجل: على أفقر مني يا رسول الله، فوالله ما بين لابتيها ـ يريد الحرتين ـ أهل بيت أفقر من أهل بيتي. فضحك النبي ﷺ‬ حتى بدت أنيابه. ثم قال: أطعمه أهلك)). [رواه البخاري ومسلم].

((Ni igbati awa l'ọdọ Annabi ﷺ‬ ni ọkunrin kan ba wa si ọdọ rẹ ti o si wi pe: iwọ ojisẹ Ọlọhun mo ti ko iparun ba ara mi!. Annabi wipe: ki ni o şẹlẹ? O dahun pe: mo l'asepọ pẹlu iyawo mi l'asiko ti mo n gba ãwẹ. Ojişẹ Ọlọhun wipe: Njẹ ọl'agbara ati bọkun l'ọrun ẹru? O wipe: rara. Annabi tun bi pe: Njẹ ọl'agbara ati gba ãwẹ osu meji le arawọn? O wipe: rara. Annabi tun bi pe: Njẹ ọl'agbara ati bọ ọgọta alaini? O wipe: rara. Lẹyin igba diẹ ti awa l'ori eleyi pẹlu Annabi ﷺ‬ ni wọn ba gbe apo labidun kan wa fun Annabi ﷺ‬ l'oba beere wipe: olubere naa da? Odahun pe: emi ni i. Owifun pe: gba, ki o lọ fi se saara. Ni ọkunrin naa badahun pe: Kin n fi se sara fun ẹniti o tun ta osi jumilọ iwọ ojisẹ Ọlọhun! Mofi Ọlọhun bura ko si agbo ile kan ni ilu Mọdinat yi ti o ta osi ju agbo ile mi lọ. Ni Annabi ﷺ‬ ba rẹrin ti a si fi ri eyin ọkankan rẹ, ti o si wi fun arakunrin naa pe: fun awọn ara ile rẹ naa jẹ)). [Bukhariy ati Muslim ni wọn gbaa wa].

e- Ki àtọ ọmọkunrin jade l'atara ifẹnu ko obinrin l'ẹnu tabi ifara ro obinrin, tabi mimọ wo obinrin leralera, tabi ọna miran ti ole mu ki àtọ o jade. Bi àtọ ba jade lati ara alãwẹ pẹlu ọkan ninu awọn ọna wọn yi ãwẹ rẹ ti bajẹ, o si pan dandan ki o san gbese, yoo si ko ẹnu duro fun asiko ti o sẹku ninu ọjọ naa, sugbọn itanran ko jẹ ọranyan l'oriẹ. Osi di dandan ki o tuba l'ọdọ Ọlọhun ki o si se abamọ l'ori nkan ti o se, ki o si wa aforijin, ki o si jinna si gbogbo ohun ti o le mu ki àtọ jade l'ara rẹ.

Sugbọn ti o ba se wipe o sun ni, l'owa l'ala ti atọ si jade ni ara rẹ, ti o si ngba ãwẹ, eleyiun ko ba ãwẹ rẹ jẹ rara, nkankan ko si jẹ ọranyan l'oriẹ tayọ ki o wẹ.

ẹ- Ifi ojusilẹ bì. Ki o mọmọ pọ nkan ti o wa nikun rẹ l'ati ẹnu. Sugbọn ti èbì ba gbe laijẹ pe ohun ni o wa, eleyiun ko ba ãwẹ rẹ jẹ. Annabi sọ bayi pe:

((من ذرعه القيء فليس عليه قضاء، ومن استقاء عمداً فليقض)). [رواه أبو داود والترمذي].

((Ẹnikẹni ti èbì ba gbe ko ni gbese ãwẹ l'ọrun, sugbọn ẹni ti o mọọmọ wa èbì o di dandan ki o san ãwẹ naa pada)). [Abu-Dãud ati Tirmithy ni wọn gbaa wa].

f- Ijade ẹjẹ nkan osu tabi ẹjẹ ibimọ, ki baa jade l'arọ ni tabi l'ọsan, koda bi o ku kinkini ki òrún wọ.

O dara fun alãwẹ ki o fi ìdégò silẹ tori ki o ma baa ba ãwẹ rẹ jẹ. O si dara fun bakanna ki o ma fi ẹjẹ silẹ ayafi ti o ba jẹ wipe laluri tulasi lati gba alaisan la tabi n ti o jọ bẹẹ. Sugbọn ẹjẹ ti o jade lati bi amurun, tabi ọfinkin tabi egbò tabi eyín ti a yọ, ati bẹẹbẹ lọ, awọn eleyi ko ba ãwẹ jẹ.

 7- Awọn idajọ apapọ l’ori gbigba ãwẹ:

a- Ãwẹ Ramadan yoo maa jẹ ọranyan pẹlu riri Osú. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]فَمَن شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ[، [سورة البقرة، من الآية: 185].

[Nitorina ẹnikẹni ti oşú na ba şe oju rẹ ninu yin, o di dandan ki o gba ãwẹ ninu rẹ]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 185].

Bi Musulumi kan ti o jẹ o ni deede bati jẹri pe ohun ri osú o ti to. Nitori ẹgbawa ọmọ 'Umar t wipe:

((تراءى الناس الهلال فأخبرت رسول الله ﷺ‬ أني رأيته فصام وأمر الناس بصيامه)). [رواه أبو داود والدارمي وغيرهما].

((Awọn eniyan n wa osú, ni mo ba sọ fun ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬  wipe emi ri i, o si gba ãwẹ o si tun pa awọn eniyan l’asẹ ki wọn gba ãwẹ pẹlu)). [Abu-Dãud ati Darimiy ati awọn miran ni wọn gbaa wa].

Sharia (Islam) se afiti aşẹ ibẹrẹ ãwẹ ni gbogbo orilẹ ede kọọkan si ọdọ olori orilẹ ede naa. Ti o ba ti pasẹ gbigba ãwẹ tabi pe ko si ãwẹ o di dandan ki a tẹlee. Ti olori orilẹ ede ko ba jẹ Musulumi awọn ti o ba jẹ asiwaju ninu ẹsin gẹgẹ bi Ẽmir tabi ọba Musulumi ati bẹẹbẹẹ lọ, ni a o ma gba ọrọ wọn l’ati le jẹ ki ọrọ awọn Musulumi jẹ ọkan.

Lilo awọn irinsẹ iwa nkan, o ni ẹtọ, l’ati le jẹ iranlọwọ l’ati ri osú. Sugbọn isiro awọn onisabi ati awọn aworawọ ko tọ rara l’ati fi bẹrẹ ãwẹ tabi l’ati fi tunu. Eyi ti a o gbe ara le nikan ni fifi oju ri osu, gẹgẹ bi o ti wa ninu ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]فَمَن شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ[، [سورة البقرة، من الآية: 185].

[Nitorina ẹnikẹni ti oşu na ba şe oju rẹ ninu nyin, o di dandan ki o gba ãwẹ ninu rẹ]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 185]. Ẹnikẹni ti osú ãwẹ Ramadan ba se oju rẹ ninu awọn ti ãwẹ jẹ ọranyan fun o di dandan fun ki o gba ãwẹ, ọsan gun ni o tabi okuru.

Ãwẹ yoo maa bẹrẹ ni ilu kọkan pẹlu riri osú l’ati ibuyọ rẹ. Eleyi ni eyi ti o rinlẹ ju ninu ọrọ awọn oni mimọ. Nitori apanupọ awọn alufa pe ibuyọ osú a ma yatọ si arawọn gẹgẹ bi gbogbo eyan naa ti ma. Nitori ọrọ (Annabi) ﷺ‬ pe:

((صوموا لرؤيته وأفطروا لرؤيته فإن غُمَّ عليكم فأكملوا شعبان ثلاثين يوماً)). [أخرجه البخاري ومسلم].

((Ẹ bẹrẹ ãwẹ pẹlu riri osu, ki ẹ si tunu pẹlu riri osu. Ti ẹyin ko ba wa ri osu ki ẹka osu Sha'ban pe ọgbọn)). [Bukhariy ati Muslim ni o gbaa wa].

b- O jẹ ọranyan fun alãwẹ ki o da aniyan lati oru. Nitori ọrọ Rẹ (Annabi) ﷺ‬ pe:

((إنما الأعمال بالنيّات، وإنما لكل امرئ ما نوى)). [متّفق عليه].

((Dajudaju gbogbo işẹ pẹlu aniyan ni, ẹnikọkan yoo si ma gba ẹsan işẹ rẹ gẹgẹ bi aniyan rẹ)). [Bukhariy ati Musulumi ni wọn gbaa wa].

Ati ọrọ Rẹ (Annabi) ﷺ‬ pe:

((من لم يجمع الصيام قبل الفجر فلا صيام له)). [أخرجه أحمد وأبو دواد والترمذي والنسائي من حديث حفصة رضي الله عنها].

 ((Ẹnikẹni ti ko ba pinu aniyan ãwẹ siwaju ki alifajri to yọ onitọhun ko ni ãwẹ)). [Ahmad ati Abu-Dãud ati Tirmidhy ati Al-Nasãiy ni wọn gbaa wa lati ọdọ Afsọt].

e- Ko tọ fun ẹnikẹni l’ati fi ãwẹ silẹ l’aigba ninu osu ãwẹ afi pẹlu idi pataki gẹgẹ bi alaisan, tabi onirinajo, tabi obinrin ti o wa l’asiko nkan osú rẹ tabi ti o wa ninu ẹjẹ ibimọ, tabi aboyun tabi alabiyamọ ti o n fun ọmọ l’ọmu. Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) sọ bayi pe:

]فَمَنْ كَانَ مِنْكُمْ مَرِيضاً أَوْ عَلَى سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِّنْ أَيَّامٍ أُخَر[، [سورة البقرة، من الآية: 184].

[Sugbọn ẹniti o ba nşe aisan tabi ti mbẹ l’ori irin-ajo ninu yin (yio san ãwẹ na pada ninu) onka awọn ọjọ miran]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 184].

Alaisan ti ãwẹ nira fun, ti ati fi jijẹ ati mimu silẹ fun nira o l’ẹtọ fun ki o tunu ninu Rọmadan ki o si san iye ọjọ ti o fi tunu pada.

Aboyun ati alabiyamọ ti o n fun ọmọ l’ọmu ti awọn mejeji ba mbẹru alãfia wọn nikan, o l’ẹtọ fun wọn l’ati sinu, ki wọn si san ãwẹ pada pẹlu apanupọ awọn alufa. Nitoripe awọn naa da gẹgẹ bi alaisan ti o mbẹru alãfia rẹ.

Sugbọn ti wọn ba mbẹru alãfia ara wọn ati ti ọmọ wọn naa, tabi alãfia ọmọ wọn nikan, o tun lẹtọ fun wọn bakanna ki wọn sinu, ki wọn o si san ãwẹ naa pada. Ẹri eleyi ni hadith Anas t l’ati ọdọ ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ wipe:

((إن الله وضع عن المسافر نصف الصلاة والصوم، وعن الحبلى والمرضع)).

((Dajudaju Ọlọhun yọnda idaji irun fun onirinajo, O si yọnda ãwẹ fun, bakanna ni o yọnda ãwẹ fun alaboyun ati alabiyamọ ti o n fun ọmọ l’ọmu)). [Al-Nasãi ati ọmọ Khuzaemat ni wọn gbaa wa. Hadith ti o dara (Hassan) ni].

Sugbọn Baba agbalagba ati arugbo obinrin ti wọn ko l’agbara l’ati gba ãwẹ nitori pe wọn nri inira ti o le, o l'ẹtọ fun wọn ki wọn tunu, ki wọn si maa fun alaini kọọkan l’onjẹ l’ojoojuma dipo ãwẹ ti wọn fisilẹ. Ẹri eleyi ni hadith ti Bukhariy gba wa l’ati ọdọ 'Atã o ni oun gbọ ti ọmọ 'Abbas (رضي الله عنهما) n ka ãyat yi:

]وَعَلَى الَّذِينَ يُطِيقُونَهُ فِدْيَةٌ طَعَامُ مِسْكِينٍ[، [سورة البقرة، من الآية: 184].

[Ati fun awọn ẹniti o ba ni l’ara ki wọn şe irapada nipa bibọ alaini yo]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 184]. Ọmọ 'Abbas sọ pe: ((Ãyat yi fi ẹsẹ rinlẹ ti lilo rẹ si fi ẹsẹ rinlẹ fun awọn Arugbo l’ọkunrin ati l’obinrin, ti wọn ko l’agbara l’ati gba ãwẹ, wọn o ma fun alaini kọọkan l’onjẹ l’ojoojuma dipo ãwẹ ti wọn fisilẹ)).

ẹ- Irin-ajo jẹ ọkan ninu awọn idi ti o sọ itunu di ẹtọ fun alãwẹ. Nitori hadith Anas t pe:

كنا نسافر مع النبي ﷺ‬ فلم يعب الصائم على المفطر ولا المفطر على الصائم. [متفق عليه].

((Ama n se irin-ajo pẹlu Annabi ﷺ‬, a kii maa bu ẹni ti o gba ãwẹ fun ẹni ti ko gbaa, bakanna a kii bu ẹniti ko gba ãwẹ fun ẹni ti o gba ãwẹ)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ le l’ori].


Origun kãrun: Hajj.

 1- Itumọ rẹ:

Itumọ Hajji ninu ede larubawa ni: gbigbero. Gẹgẹ bi: l’amọin se hajj wa si ọdọ wa, itumọrẹ ni pe: o gbero wa o si wa si ọdọ wa.

Itumọ rẹ ninu sharia (Islam): Gbigbero l’ati lọ si Mọkkah nitori ẹsìn, pẹlu işẹ kan ti a sa l’ẹsa, ni asiko kan ti a sa l’ẹsa, ati pẹlu awọn mọjẹmu ti a sa l’ẹsa.

 2- Idajọ rẹ:

Gbogbo Musulumi ni o panupọ l'ori pe hajji jẹ ọranyan l’ẹkan soso ninu isẹmi l’ori gbogbo ẹniti o ba l’agbara. Wọn situn panupọ pe ọkan ninu awọn origun Islam marãrun ni o jẹ pẹlu. Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga) sọ bayi pe:

]وَلِلَهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ البَيتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلاً وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ اللهَ غَنِيٌّ عَنِ العَالَمِينَ[. [سورة آل عمران، من الآية: 97].

[Irin-ajo lọ si ile naa (Ka’abat) nitori ti Ọlọhun jẹ iwọ fun gbogbo enia, ẹnikẹni ti o ba ni agbara irin-ajo lọ si ibẹ, ẹnikẹni ti o ba si şe aigbagbọ, dajudaju Ọlọhun ti rọ ọrọ ju gbogbo ẹda]. [suratu Ãli-Imrana 3, ãyat: 97].

Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọpe:

((بني الإسلام على خمس: شهادة أن لا إله إلاّ الله، وأنّ محمّداً رسول الله، وإقام الصّلاة، وإيتاء الزّكاة، وصوم رمضان، وحجّ بيت الله)). [متفق عليه].

 ((Islam duro l’ori origun marun: ijẹri pe ijọsin ko tọ fun ẹnikan afi Ọlọhun, ati pe (Annabi) Muhammad ojişẹ Ọlọhun ni, ima gbe irun duro, ima yọ zakat, ima gba ãwẹ Rọmadan, ima lọ si hajj)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ loriẹ].

((Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ tun sọ ninu hajji idagbere ti o se wipe:

((يا أيها الناس إن الله فرض عليكم حجّ البيت فحجّوا)). [رواه مسلم].

((Ẹyin eniyan dajudaju Ọlọhun se hajji ni ọranyan l’oriyin, nitorina ki ẹ se hajj)). [Muslim ni o gbaa wa].

 3- Ọla ati Ọgbọn pẹlu Ẹkọ ti o wa nibi ijẹ ọranyan Hajji:

Awọn ẹri ti o pọ l’owa l’ori ọla ti o wa fun hajji, ninu rẹ ni ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَأَذِّنْ فِي النَّاسِ بِالحَجِّ يَأْتُوكَ رِجَالاً وَعَلَى كُلِّ ضَامِرٍ يَأْتِينَ مِنْ كُلِّ فَجٍّ عَمِيْقٍ & لِيَشْهَدُوا مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا اسْمَ اللهِ فِي أَيَّامٍ مَعْلُومَاتٍ عَلَى مَا رَزَقَهُمْ مِنْ بَهِيمَةِ الأَنْعَامِ[. [سورة الحجّ، الآيتان: 27-28].

[Ki o si pe ipe lãrin awọn enian fun isin Hajji, wọn yio maa wa ba ọ ni irin ẹsẹ, ati l'ori gbogbo ohun gigun, wọn o maa wa l’ati ọna ti o jin réré & Ki wọn le ri rere awọn anfãni ti o wà fun wọn, ati ki wọn le ma pe orukọ Ọlọhun ninu awọn ọjọ ti a mọ, lori awọn nkan ti O pa l'ese fun wọn ninu ẹran ọsin]. [suratu Hajji 22, ãyat: 27-28].

Hajji si tun ko awọn anfãni ti o pọ sinu fun awọn Musulumi l’apapọ, anfãni taye ni, tabi ti ọrun, ninu hajji ni gbogbo awọn oniranran ijọsin ko jọ pọ si, gẹgẹ bi: irọkiri ka ile Ọlọhun, ati ipọsẹsẹ lãrin Sọfa ati Marwa ati diduro ni 'Arafat ati Mina ati Muzdalifat, ati juju òkò (asetani) ati sunsun Mina ati pipa ẹran hadayat, ati fifa irun, ati ọpọlọpọ iranti Ọlọhun l’ati maa fi wa oju rere Ọlọhun, ati l’ati rẹ ara ẹni nilẹ fun Un, ati l’ati sẹri lọ si ọdọ Rẹ. Nitori idi eyi ni hajji fi jẹ ọna kan ninu awọn ọna, ati sababi l’ati pa gbogbo ẹsẹ rẹ, ati l’ati wọ Alijanna.

Abu Huraerah t gba ẹgbawa o sọ pe: Mo gbọ ti Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ n sọ bayi pe:

((من حجّ هذا البيت فلم يرفث ولم يفسق رجع من ذنوبه كيوم ولدته أمه)). [رواه البخاري ومسلم].

 ((Ẹnikẹni ti o ba se hajji ti ko sọ ọrọ tabi se isẹ alufansa, ti ko si se pooki, onitọhun yoo pada si ile rẹ l’ẹni ti ko ni ẹsẹ kankan l’ọrun gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ bi i)). [Bukhariy ati Muslim ni wọn gbaa wa].

Ẹgbawa tun wa l’ati ọdọ Abu Huraerah pe Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ bayi pe:

((العمرة إلى العمرة كفارة لما بينهما والحج المبرور ليس له جزاء إلاّ الجنة)). [رواه البخاري ومسلم].

(('Umurah kan de ekeji a maa pa ẹsẹ ti o wa larin wọn rẹ, hajji ti Ọlọhun gba ẹsan rẹ ni alijanna)). [Bukhariy ati Muslim ni wọn gbaa wa].

Ẹgbawa tun wa lati ọdọ Abu Huraerah t pe:

سئل رسول الله ﷺ‬ أيّ الأعمال أفضل؟ قال: ((إيمان بالله ورسوله)). قيل: ثم ماذا؟ قال: ((جهاد في سبيل الله)). قيل: ثم ماذا؟ قال: ((حجّ مبرور)). [متفق عليه].

Wọn bi Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ l’ere bayi pe: Isẹ wo l’oni oore ju? Odahun pe: inigbagbọ si Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ. Wọn tun bi pe: l’ẹyin rẹ nkọ? Odahun pe: Jijagun si oju ọna Ọlọhun. Wọn tun bi pe: l’ẹyin rẹ nkọ? Odahun pe: Hajji ti Ọlọhun gba)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ l'ori rẹ].

Ẹgbawa tun wa lati ọdọ 'Abdullahi ọmọ Mọs'ud t o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ pe:

((تابعوا بين الحجّ والعمرة فإنهما ينفيان الفقر والذنوب كما ينفي الكير خبث الحديد والذهب الفضة، وليس للحجة المبرورة ثواب إلاّ الجنة)). [رواه الترمذي وقال: حديث حسن صحيح].

 ((Ẹ ma se hajji ati 'Umurah lerawọn, nitoripe awọn mejeji yi maa n le osi ati ẹsẹ jina gẹgẹ bi ẹwiri ina-alagbẹdẹ se maa n fẹ eyi ti ko dara kuro lara irin ati golu ati fadaka, hajji ti Ọlọhun gba ẹsan rẹ ni alijanna)). [Tirmidhiy ni o gbaa wa. O si sọ pe: hadith ti o dara ti o fi ẹsẹ rinlẹ ni (hasan sọhihu)].

Ninu anfãni Hajji tun ni ipade gbogbo Musulumi l’ati orisirisi ilu ni ãye ti Ọlọhun yọnu si ju, ti wọn o si maa mọ arawọn, ti wọn o maa ran ara wọn l’ọwọ l’ori ibẹru Ọlọhun ati l’ori dãda, ti gbogbo wọn o jẹ ọkan na nibi ọrọ wọn, isẹ wọn ati iranti wọn. Ẹkọ nla ni eleyi jẹ fun wọn l’ori pataki ijọkan ati ikojọpọ l’ori adisọkan ati ijọsin ati erongba ati akasọ-isẹ. Pẹlu ikojọpọ wọn yi, wọn o mọ arawọn, wọn o si sun mọ arawọn, onikaluku yoo maa beere nipa ẹnikeji (l’ati le mọ ara wọn), l’ati se amusẹ ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوباً وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُم عِنْدَ الله أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ[.[سورة الحجرات، الآية: 13].

[Ẹyin enian, dajudaju A da yin l’ati ara ọkunrin ati obinrin, A si şe yin ni orilẹ ede ati iran-iran ki ẹ le bã mã mọ ara yin. Dajudaju ẹniti o ni ọla ju l’ọdọ Ọlọhun ninu yin ni ẹniti o paya (Rẹ) ju, Dajudaju Ọlọhun ni Oni-mimọ Alamọtan]. [suratu Hujurãti 49, ãyat: 13].

 4- Awọn mọjẹmu ijẹ ọranyan rẹ:

a- ko si iyapa lãrin awọn oni mimọ wipe hajji jẹ ọranyan pẹlu mọjẹmu marun: Islam, lãkae, idepo balaga, ijẹ ọmọluabi ati ilagbara.

Ninu mọjẹmu ijẹ ọranyan hajji l’ori obirnrin ni ki eleewọ rẹ (gẹgẹ ọkọ rẹ, baba, ẹgbọn ati bẹẹbẹ lọ) wa pẹlu rẹ nibi irin-ajo rẹ lọ si hajji. Ẹri l’ori eleyi ni ẹgbawa Abu Huraerah t lati ọdọ Annabi ﷺ‬ ti o sọ pe:

((لا يحلّ لامرأة تؤمن بالله واليوم الآخر تسافر مسيرة يوم إلاّ ومعها ذو محرم)). [متفق عليها].

((Ko tọ fun obinrin kan ti o gba Ọlọhun ati ọjọ ikẹyin gbọ ki o se irin-ajo ti o to ọjọ kan afi pẹlu elewọ rẹ)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ lori ẹ].

Awọn alufa onimọ furua wa pin awọn mọjẹmu yi si ipin mẹta:

Ipin akọkọ: Ninu rẹ, eyi ti o jẹ mọjẹmu ijẹ ọranyan ati ilalãfia, ohun na ni: Islam ati lakae. Nitorinan hajji ko jẹ ọranyan l’ori keferi alaigbagbọ ati were, bẹ ẹ hajji wọn ko le dara. Toripe wọn o si ninu ẹni ti o le jọsin.

Ipin ẹkeeji: Ninu rẹ, eyi ti o jẹ mọjẹmu ijẹ ọranyan ati tito, ohun naa ni idepo balaga ati ijọmọluabi, awọn ki i se mọjẹmu ilalãfia, nitorina bi ọmọ kekere ati eru ba se hajji, hajji wọn dara o si l’alãfia. Sugbọn ko duro fun wọn ni hajji ọranyan ti Islam. (Ti ọmọ kekere ba da gba yoo tun hajji miran se, bakanna ni ti ẹru ba di ọmọluabi).

Ipin ẹkẹẹta: Ninu rẹ ni eyi ti o jẹ mọjẹmu ijẹ ọranyan lasan, ohun na ni ilagbara, sugbọn ti ẹniti ko l’agbara ba se hajji pẹlu inira, ti o fi ẹsẹ rẹ rin pẹlu ebi, dajudaju hajji rẹ dara o si ni alãfia.

 b- Idajọ bi ba eniyan se hajj:

Ko si iyapa ẹnu l’arin awọn oni mimọ wipe ẹnikẹni ti o ba kú ti ko si fi igbakan l'agbara ati se hajji, ko jẹ ọranyan l’oriẹ. Sugbọn ẹni ti o ba kú lẹyin igbati ti o l’agbara ati lọ si hajji sugbọn ti ko lọ, n jẹ hajji bọ fun iru ẹnibẹ tabi ko bọ fun?

Eyi ti o fẹsẹ rinlẹ pẹlu ogo Ọlọhun nipe: hajji ko bọ fun iru ẹnibẹ. O si di ọranyan l’ori awọn ẹbi rẹ ki wọn ba se hajji ninu owo rẹ, o sọ asọlẹ rẹ ni tabi ko sọ asọlẹ. Ọranyan ni ti o ti wa ni ọrun rẹ gẹgẹ bi gbese ti o jẹ. Ẹri l’ori eleyi ni:

((حديث ابن عباس ـ رضي الله عنهما ـ أن امرأة نذرت أن تحج فماتت، فأتى أخوها النبي ﷺ‬ فسأله عن ذلك فقال: ((أرأيت لو كان على أختك دين أكنت قاضيه؟)) قال: نعم. قال: ((فاقضوا الله فهو أحق بالوفاء)). [رواه النسائي].

Hadith ọmọ 'Abbas t wipe obinrin kan se ileri hajji fun Ọlọhun sugbọn o kú ki o to mu ileri rẹ naa sẹ, ni aburo rẹ tabi ẹgbọn rẹ, l’ọkurin ba lọ ba Annabi ﷺ‬ ti o si bi i nipa rẹ, ti Annabi si dahun wipe: ((Njẹ ti ọmọ iya rẹ naa rẹ ba jẹ gbese, wa baa san bi? O daun pe: bẹẹ ni. Annabi sọfun pe: san gbese Ọlọhun, Ọlọhun ni o tọ ki a san gbese rẹ ju ẹlomiran lọ)). [Al-Nasãi ni o gbaa wa].

d- Ẹniti koi ti se hajii ọranyan fun ara rẹ, njẹ ole ba ẹlomiran se hajji?

Eyi ti o fi ẹsẹ rinlẹ nipe ẹniti koi ti se hajii ọranyan fun ara rẹ, ko lee ba ẹlomiran se hajji.

للحديث المشهور أن النبي ﷺ‬ سمع رجلاً يقول: لبيك عن شبرمة، قال: من شبرمة؟ قال: أخ لي أو قريب لي، فقال عليه الصلاة والسلام: حججت عن نفسك؟ قال: لا. قال: ((حجّ عن نفسك ثم حجّ عن شبرمة)).

Nitori hadith ti ogbajumọ un wipe Annabi ﷺ‬ gbọ ti ọkunrin kan sọ pe: (LABAIKA ‘AN SHUBURUMA); itumọ: Iwọ Oluwa mi, mo jẹ ipe Rẹ l’ati se hajji fun Shuburuma. Annabi si bi pe: Tani Shuburuma? O dahun pe: ẹgbọn mi, tabi ẹbi mi kan ni. Ni Annabi ﷺ‬  ba bii pe: Njẹ ọ ti se hajji fun ara rẹ bi? O dahun pe: Rara. Annabi wi fun un pe: Se hajji fun ara rẹ naa, l’ẹhin naa ki o wa se hajji fun Shuburuma)). [Ahmad ati Abu-Dãud ati Ibn Mọjah ni wọn gbaa wa ati Al-baehaqy ti o si sọ pe: o dara (sọhihu)].

Eyi ti o fẹsẹ rinlẹ nipe iba alãye ti o lagbara owo sugbọn ti ko ni alãfia, oni ẹtọ l’ati baa se hajji. Nitori:

لحديث الفضل بن عباس ـ رضي الله عنهما ـ وفيه أن امرأة من خثعم قالت: يا رسول الله إن فريضة الله على عباده في الحجّ أدكرت أبي شيخاً كبيراً لا يثبت على الراحلة أفأحجّ عنه؟قال:نعم.وذلك في حجّة الوداع.[متفّق عليه واللفظ للبخاري].

Hadith Alfọdil ibn 'Abbas (رضي الله عنهما) o wa ninu rẹ pe obinrin kan l’ati iran khath'am sọ ba yi pe: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun dajudaju ọranyan Ọlọhun l’ori awọn ẹru Rẹ ti o jẹ hajji, o ba babaa mi l’aye l'agbalagba ti ko le gun nkaangun, njẹ kin se hajji fun bi? O (Annabi) ba sọ pe: bẹẹni, se hajji fun u. Eleyi sẹlẹ ninu hajji idagbere. [Bukhariy ati Muslim panu pọ le l’ori, sugbọn gbolohun ti Bukhariy ni eyi].

ẹ- Njẹ hajji jẹ ọranyan kiakia nigbati eniyan bati l’agbara ni, abi o le lọ lara?

Eyi ti o fi ẹsẹ rinlẹ pẹlu ogo Ọlọhun nipe hajji jẹ ọranyan kiakia nigbati awọn mọjẹmu ijẹ ọranyan rẹ bati pe, nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَلِلَهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ البَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيْلاً[. [سورة آل عمران، من الآية: 97].

[Irin-àjò lọ si Ile na nitori ti Ọlọhun jẹ iwọ fun gbogbo enian, ẹnikẹni ti o ba ni agbara irin-àjò lọ si ibẹ]. [suratu Ãli-Imrana 3, ãyat: 97].

Ati nitori ọrọ Ọlọhun:

]وَأَتِمُّوا الحَجَّ والعُمْرَةَ لِلَهِ[. [سورة البقرة، من الآية: 196].

[Ki ẹ si şe aşepe (işẹ) Hajji ati 'Umura fun Ọlọhun]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 196].

O si tun wa ninu hadith Ibn 'Abbas (رضي الله عنهما) ọrọ Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬  pe:

((تعجلوا إلى الحجّ، يعني الفريضة، فإن أحدكم لا يدري ما يعرض له)). [رواه أبو داود وأحمد والحاكم وصحّحه].

((Ẹyara lọ si hajji ti o jẹ ọranyan, tori ẹnikan yin ko mọ nkan ti o le sẹlẹ si)). [Abu-Dãud ati Ahmad ni wọn gbaa wa ati Al-hãkim o si sọ pe: o fi ẹsẹ rinlẹ].

 5-Awọn origun Hajji:

 Origun Hajji jẹ mẹrin:

a- Aniyan (Al-ihram, gbigbe harami).

b- Iduro  ni 'Arafat.

d- Tawafu Ziyarat tabi tawafu Hajji.

e- Irin larin Sọfat ati Mọrwat.

 Awọn yi ni awọn origun ko se ma ni fun Hajji.

 a- Origun akọkọ: Aniyan (Al-ihram, gbigbe harami):

1- Itumọ rẹ: ohun naa ni aniyan wiwọ inu ẹsin hajji.

2- Awọn (miqọt) ãye rẹ: Awọn ãye ihram fun hajji pin si meji: a- ti asiko ati b- ti ãye.

a- Awọn (miqọt) asiko ti a ti le gbe ihram nibẹ ni awọn osu hajji ti Ọlọhun sọ nipa rẹ pe:

]الحَجُّ أَشْهَرٌ مَّعْلُومَاتٌ[. [سورة البقرة، من الآية: 197].

[Hajji şişe ninu awọn oşu ti a mọ ni]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 197]. Awọn osu ti a mọ naa ni: Shawal, Dhul-Qa'dat ati Dhul-Hijjat.

-Awọn (mọwaqeet) ãye ti ati le gbe ihram ni eyi ti ẹni ti o ba fẹ se Hajji tabi 'Umurah ko gbọdọ ta yọ rẹ lọ si Mọkkah lai gbe aniyan (ihram), awọn aaye yi jẹ marun:

Alakọkọ: (Dhul-hulaefat) nisin wọn n pe ni: ((Ãbar 'Aliy)), ohun naa ni ãye aniyan awọn ara Mọdinat. O fi (336 km) (224 miles) jina si Mọkkah.

Ẹlẹẹkeji: (Al-juhfat), ohun naa ni oko kan ti o ku (10 km) ti yoo fi de okun pupa, ofi (180 km) (120 miles) jina si Mọkkah, ohun naa ni ãye aniyan awọn ara Misirat (Egypt) ati Syria (Shamu) ati Morocco ati awọn ti wọn tun wa l'ẹyin wọn gẹgẹ bi awọn ara Andalus (Spain) ati Romu ati Tukruru. Awọn eniyan n gbe ihram nisin ni (Rọbig) nitori pe o fẹẹ se deede ọkankan aaye ohun.

Ẹkẹẹta: (Yalamu-lamu) nisin  wọn n pe ni: (Al-ssa'adiyat) o jẹ ọkan l'ara awọn oke Tuhamat. O fi (72 km) (48 miles) jina si Mọkkah, ohun naa ni ãye aniyan awọn ara Yamen, ati awọn ara Jawah, India ati China.

Ẹkẹẹrin: (Qọrnul-mọnazil) nisin wọn n pe ni: (Al-ssaelul kabeer) o fi (72 km) (48 miles) jina si Mọkkah, ohun naa ni ãye aniyan awọn ara Najid ati Al-tọif.

Ẹkãrun: (Dhatu 'inrqi) nisin wọn n pe ni: (Al-dọribat), wọn n pe bẹẹ nitori oke kekere ti o wa ni ibẹ. O fi (72 km) (48 miles) jina si Mọkkah, ohun na ni ãye aniyan awọn ara Ibuyọ òrún (Al-mọshriq) ati Iraq ati Iran.

Awọn ãye wọn yi ni ãla ti alalãji tabi oni-'umurah ko gbọdọ tayọ rẹ lọ si Mọkkah lai gbe ihram (aniyan).

Dajudau Annabi ﷺ‬ ti se alaye eleyi gẹgẹ bi o ti se wa ninu hadith Ibn 'Abbas t ti o sọ pe:

((وقّت رسول الله ﷺ‬ لأهل المدينة ذا الحليفة، ولأهل الشام الجحفة، ولأهل نجد قرن المنازل، ولأهل اليمن يليملم، هن لهن ولمن أتى عليهن من غير أهلهن ممن أراد الحجّ أو العمرة، ومن كان دون ذلك فمن حيث أنشأ، حتى أهل مكّة من مكّة)). [متفق عليه].

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ se Dhul-hulaefat ni ãye ihram fun awọn ara Mọdinat, o si se Al-juhfat fun awọn ara Shamu (Syria), o si se Qọrnul-mọnazil fun awọn ara Najidi, o si se Yalamu-lamu fun awọn ara Yamen, awọn ãye kọọkan yi l'owa fun awọn ara ilu wọnyi, ati fun ẹnikẹni ti o ba wa si awọn ilu yi ti ki i se ara ilu naa, ti o gbero ati se hajji tabi 'umurah. Ẹnikẹni ti o ba ngbe ibi ti kode awọn ãye wọnyi, ibi ti o ngbe naa ni yo ti maa gbe ihram rẹ, koda, awọn ara Mọkkah wọn yoo maa gbe ihramu ti wọn ninu Mọkkah naa)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ l'ori rẹ].

ولمسلم من حديث جابر t: ((مهل أهل العراق ذات عرق)).

Ẹgbawa Jãbir t tun wa l'ati ọdọ Muslim pe: ((Ibu gbe ihramu awọn ara Iraq ni Dhatu 'inrqi)).

Sugbọn ẹniti ko ba kan ọkankan l'ara awọn ãye wọn yi l'oju ọna ti ẹ, yo gbe ihram rẹ ni igbati o ba mọ wipe ohun ti de ọkankan eyi ti o sumọ ohun ju. Bakan naa ni ẹni ti o ba gun bãlu yoo maa gbe ihramu rẹ l'oke nigbati o ba de ọkankan ọkan l'ara awọn ãye wọnyi. Ko tọ fun rara ki o lọ ihramu rẹ l'ara titi bãlu yoo fi ba ni ilu Jeddah gẹgẹ bi awọn alalãji miran ti ma n se. Dajudaju Jeddah ki i se ãye ihramu afi fun awọn ti o ngbe ibẹ, tabi fun ẹniti o se wipe ibẹ l'oti ni aniyan pe ohun fẹ se hajji tabi 'umurah. Lẹyin awọn wọnyi ẹnikẹni ti o ba gbe ihramu (aniyan) l'ati ibẹ o ti fi ọkan ninu awọn ọranyan hajji silẹ, ti se ihramu lati miqọt, ntorina yoo pa ẹran itanran (fidiyat).

Bakannaa ẹniti o ba tayọ miqọt lai gbe ihram (aniyan) o di dandan fun ki o pada si miqọt ti ko ba pada ti o gbe ihramu ni ibomiran o di dandan ki o san itanran, ki o pa ewurẹ tabi idakan ninu ida meje rankumi tabi mãlu, ti yoo pin fun awọn talaka Haram (Makkah), ko si gbọdọ jẹ nkankan nibẹ.

 3- Alaye bi a ti n gbe harami (Aniyan):

O dara fun ẹniti o ba fẹ gbe ihram ki o wẹ, ki o si se imọtoto, ki o si fa nkan ti o batọ fun l'ati fa ninu irun rẹ tabi ki o gee. [Sugbọn eewọ ni ki o fa irungbọn rẹ tabi ki o gee]. Ki o lo lọfinda si ara rẹ, ki ọkunrin si bọ gbogbo n kan ti wọn ran fun wiwọ silẹ, sugbọn ko lo asọ funfun meji ti o ba mọ, yoo ro ọkan si isalẹ yoo da ọkan yoku bo ara.

Eyi ti o fi ẹsẹ rinlẹ nipe ko si ìrun kan pato fun ihramu, sugbọn ti o ba se deede asiko ìrun ọranyan yoo ki l'ẹyin naa yoo da aniyan. Nitori pe Annabi ﷺ‬ da aniyan rẹ l'ẹyin igba ti o ki irun ọranyan tan ni. L'ẹyin naa ki o da aniyan eyi ti o ba wuu ninu awọn orisi hajji mẹtẹẹta: Al-tamatu'u, ati Al-qĩran, ati Ifrọd.

Al-tamat'u: Ohun ni ki eniyan da aniyan 'umurah ninu awọn osu hajji (Shawal, Dhul-qi'dat, ati Dhul-hijjat), l'ẹyin naa ki o tun wa da aniyan hajji ni inu ọdun kan na. (Itumọ rẹ nipe: ki o kọkọ se 'umurah ki o tun wa se hajji, ninu awọn osu hajji ni ọdun kan naa).

Al-qĩran: Ohun ni ki o da aniyan hajji ati 'umurah pọ l'ẹkan naa, tabi ki o da aniyan 'umurah l'ẹyin naa ki o tun wa da aniyan hajji l'ori aniyan ti akọkọ siwaju ki o to se tọwafu. O se deede ki o da aniyan wọn pọ l'ati miqọt, tabi ki o tun da aniyan hajji l'ẹyin ti 'umurah siwaju ki o to se tọwafu, ti yoo wa se tọwafu kan ati s'ayu kan fun mejeeji.

Al-Ifrad: Ohun ni ki o da aniyan hajji nikan soso ni miqọt. Ti yoo si wa ninu ihramu rẹ titi yoo fi pari gbogbo isẹ hajji.

O jẹ ọranyan fun ẹni ti o ba se hajji Tamatu'u ati Al-qiran ti ki i se ọkan l'ara awọn ti o n gbe Haram (Makkah), ki o pa ẹran hadayat.

Wọn wa se iyapa ẹnu l'ori ewo ninu awọn mẹtẹẹta yi ni o l'ọla julọ?

Sugbọn eyi ti apakan awọn Agba onimimọ wi nipe Tamatu'u ni o l'ọla ju.

L'ẹyin ti o ba daniyan tan pẹlu ọkan ninu awọn orisi hajji yi, yoo se LABAEKA ti yoo wi bayi pe:

((لبّيك اللهم لبّيك، لبّيك لا شريك لك لبّيك، إن الحمد والنعمة لك والملك لا شريك لك)).

((LABAEKA ALAHUMỌ LABAEKA, LABAEKA LÃ SHẸRIKA LAKA LABAEKA, INAL HAMDA WA NI'IMỌTA LAKA WAL MULK LÃ SHẸRIKA LAKA)).

Itumọ: ((Mo jẹ ipe Rẹ Oluwami mo jẹ ipe Rẹ, mo jẹ ipe Rẹ ko si orogun fun Ọ mo jẹ ipe Rẹ, dajudaju gbogbo ọpẹ gbogbo idera tiẸ ni ati gbogbo ọla, ko si orogun fun Ọ)).

Yoo ma wi talibiyat (Labaeka…) yi ni ọpọlọpọ, ọkunrin nikan ni yoo ma wi jake (Obinrin yoo maa wi jẹlẹjẹlẹ).

  4- Awọn Ẽwọ Ihram:

Ohun naa ni nkan ti sise rẹ jẹ ẽwọ fun ẹnikẹni ti o ba gbe ihramu nitori ihramu, wọn jẹ mẹsan:

Akọkọ: Fifa eyikeyi irun ara tabi ki o gee, l'ẹyin igbati ti o ti gbe haram. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَلاَ تَحْلِقُوا رُؤُوسَكُم حَتَّى يَبْلُغَ الهَدْيُ مَحِلَّهُ[. [سورة البقرة، من الآية: 196].

[ki ẹ ma şe fà (irun) ori yin titi ti ọrẹ (ẹran hadayat) naa yoo fi de ãye rẹ]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 196].

Ẹkeeji: Ige ekanna. Toripe ise ọşọ ni gẹgẹ bi gige irun ori. Afi ti o ba jẹ nitori idi kan, ale ge ohun na gẹgẹ bi ati le fari.

Ẹkẹẹta: Bibo Ori fun ọkunrin. Nitori pe Annabi ﷺ‬ kọ fun ẹni ti o wa ninu ihram l'ọkunrin ki o we lawani si ori rẹ. Ati ọrọ ti o sọ ni igbati nkaangun ẹnikan gbe e subu ti o si ku, o sọ pe:

((لا تخمّروا رأسه فإنه يبعث يوم القيامة ملبّياً)). [رواه البخاري ومسلم من حديث ابن عباس رضي الله عنهما].

((Ẹ ma se bo ori rẹ, tori pe yoo dide ni ọjọ agbende l'ẹni ti o n se LABAEKA)). [Bukhariy ati Muslim ni wọn gbaa wa ni ati inu hadith Ọmọ 'Abbas (رضي الله تعالى عنهما)  .

'Abdullahi ọmọ 'Umar a si maa sọpe: ((gbigbe ihram ọkunrin wa ni ibi ki o si ori rẹ silẹ, bẹẹ ihram obinrin si wa nibi oju rẹ)). [Al-baehaqy ni o gbaa wa pẹlu ọna ti o dara].

Ẹkẹẹrin: Ọkunrin ko gbọdọ wọ asọ riran (bi ẹwu, sokoto, ati bẹẹbẹẹ lọ), ati ibọsẹ. Nitori  ẹgbawa 'Abdullahi ọmọ 'Umar (رضي الله عنهما) ti o sọ pe:

سئل رسول الله ﷺ‬: ما يلبس المحرم؟ قال: ((لا يلبس المحرم القميص ولا العمامة ولا البرانس ولا السراويل ولا ثوباً مسّه ورس ولا زعفران، ولا الخفّين إلاّ أن لا يجد نعلين فليقطعهما حتى يكونا أسفل من الكعبين)). [رواه البخاري ومسلم].

((Wọn bi Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ pe kinni ẹniti o gbe ihram le wọ? O si dahun pe: ((Ẹniti o ba gbe ihram ko gbọdọ wọ ẹwu, ko gbọdọ we lawani, ko gbọdọ wọ ẹwu ti o ni fila (barãnis), ko gbọdọ wọ sokoto, ko gbọdọ wọ asọ ti o ni turare tabi lọfinda, ko gbọdọ wọ ibọsẹ afi ti ko bari bata alabọyọ ti yoo wọ, ni igbanaa ki o ge ibọsẹ rẹ titi ti yoo fi sọkalẹ kokosẹ)). [Bukhariy ati Muslim ni wọn gbaa wa].

Ẹkãrun: Ki o jinan si nkan olõrun:

لأن النبي ﷺ‬ أمر رجلاً في حديث صفوان بن يعلى بن أمية بغسل الطيب. [رواه البخاري ومسلم].

 Nitoripe Annabi ﷺ‬ pa ọkunrin kan l'asẹ ninu hadith Sọfwan ọmọ Ya'ala ọmọ Umyọyat pe ki o fọ lọfinda kuro. [Bukhariy ati Muslim ni wọn gbaa wa].

Atipe O tun sọ nigbati rankumi ẹnikan gbe e subu pe:

((لا تحنطوه...)). [رواه البخاري ومسلم من حديث ابن عباس] ولمسلم: ((ولا تمسّوه بطيب)).

((Ẹ ma fi hãnut (nkan olõrun) si lara)). [Bukhariy ati Muslim ni wọn gaa wa lati inu hadith Ọmọ 'Ababs]. O tun wa ninu Sọhihu Muslim pe: ((Ẹ ma se fi nkan olõrun si l'ara)).

Nitori naa o jẹ ẽwọ fun ẹniti o gbe ihram ki o lo nkankan ti olõrun si ara rẹ, tabi si asọ harami rẹ, l'ẹyin ti o ti gbe ihram tan. Nitori hadith ọmọ 'Umar ti a ti mẹnu ba siwaju.

Ẹkẹẹfa: Didẹ ọdẹ ori ọdan. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لا تَقْتُلُوا الصَّيْدَ وَأَنْتُم حُرُمٌ[. [سورة المائدة، من الآية: 95].

[Ẹyin onigbagbọ ododo, ẹ ko gbọdọ pa ẹran igbẹ ni igbati ẹ ba wa ninu ihram (aşọ ẹsin Hajji tabi 'Umurah)]. [suratu Mãidah 5, ãyat: 95]. Didẹ ọdẹ rẹ jẹ ẽwọ fun un, koda bi ko ba ri i pa. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَحُرِّمَ عَلَيكُم صَيْدُ البَرِّ مَا دُمْتُمْ حُرُماً[. [سورة المائدة، من الآية: 96].

[A si şee ni ẽwọ fun yin ọdẹ ori ilẹ ni igbati ẹ ba si wa ninu (ihram) aşọ ẹsin Hajji].[suratu Mãidah 5, ãyat: 96].

Ẹkeeje: Siso yigi (Nikah). Ẹniti o wa ninu ihram ko lee fẹ iyawo ko si le fi iyawo fun ẹlomiran ko si le ba eniyan fẹ iyawo. Nitori hadith 'Uthma t  l'ati ọdọ Annabi ﷺ‬ pe:

((لا يَنكح المحرم ولا يُنكِحُ ولا يخطب)). [رواه مسلم].

((Ẹniti o wa ninu ihram ko gbọdọ fẹ iyawo ko si gbọdọ fi iyawo fun ẹlomiran, ko si gbọdọ ba obinrin sọrọ ifẹ)).[Muslim o gbaa wa].

Ẹkẹẹjọ: Iba obinrin lo pọ. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

لقوله تعالى: ]فَمَنْ فَرَضَ فِيهِنَ الحَجَّ فَلاَ رَفَثَ[. [سورة البقرة، من الآية: 197].

[Nitorina ẹnikẹni ti o ba pinnu lati şe Hajji ninu awọn osu yi, kò gbọdọ sọ ọrọ tabi se are ifẹ]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 197]. Ọmọ 'Abbas t sọ wipe: Itumọ rẹ ni: iba obinrin lo pọ, ẹri rẹ ni ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

قوله تعالى: ]أُحِلَّ لَكُمْ لَيْلَةَ الصِّيَامِ الرَّفَثُ إِلَى نِسَائِكُمْ[. [سورة البقرة، من الآية: 187].

[A şe oru ãwẹ ni ẹtọ fun yin l'ati sunmọ awọn aya yin]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 187]. O sọ wipe itumọ rẹ ni: ibalopọ lãrin ọkọ ati iyawo.

Ẹkẹẹsan: Ere sişe lãrin ọkunrin ati obinrin (ti ko depo bibaa lo pọ), ifi ẹnu ko ẹnu ọkunrin ati obinrin, idimọra ẹni ọkunrin ati obinrin, mi maa wo obinrin, ati bẹẹbẹ lọ. Tori gbogbo eleyi le se sababi asepọ laarin ọkunrin ati obiniri eyi ti Ọlọhun se ni ewọ.

Obinrin ati Ọkunrin bakanna ni awọn mejeeji ni ibi ihram. Sugbọn Obinrin yatọ si Ọkunrin ni ibi awọn nkan ti o pọ, ninu rẹ nipe: Ihram Obinrin oju rẹ l'owa, nitorinaa o jẹ ẽwọ fun ki o fi nkan bo oju rẹ([4]). Bakanna o jẹ ẽwọ fun ki o wọ (glove) ibọwọ. Nitori hadith ọmọ 'Umar t l'ati ọdọ Annabi ﷺ‬ pe:

((ولا تنتقب المرأة المحرمة ولا تلبس القفازين)). [رواه البخاري].

((Obinrin ti o wa ninu asọ ihram ko gbọdọ lo (Niqọb) iboju, ko si gbọdọ wọ ibọwọ)).

Ati ọrọ ibn 'Umar t pe:

((إحرام المرأة في وجهها)). [رواه البيهقي بإسناد جيّد].

((Oju ni ihram obinrin wa)). [Al-Baehaqy ni o gbaa wa pẹlu ọna ti o dara].

Ati ẹgbawa ti o wa l'ati ọdọ 'Ãishat (رضي الله عنها) o sọ pe:

ولما روي عن عائشة رضي الله عنها أنها قالت: ((كان الركبان يمرّون بنا ونحن مع رسول الله ﷺ‬ محرمات، فإذا حاذوا بنا سدلت إحدانا جلبابها من رأسها على وجهها، فإذا جاوزنا كشفناه)). [رواه أبو داود وابن ماجه وأحمد وسنده حسن].

((Awọn ti wọn gun nkan ma n kọja l'ẹgbẹ wa ni igbati aba wa pẹlu Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ ti a wa ninu asọ ihram, ni igbati wọn ba sun mọ wa, ẹnikọọkan wa yoo fa jalibaba rẹ l'ati ori rẹ bo oju rẹ, ni igbati wọn ba si tun lọ tan ao tun si oju wa)). [Abu-Dãud ati Ibn Mọjah ati Ahmad wọn gbaa wa, o si dara (hasan)].

Gbogbo nkan ti o ku ti o jẹ ẽwọ fun ọkunrin ni ojẹ ẽwọ fun obinrin naa, gẹgẹ bii gige irun ati ẽkannan ati ọdẹ didẹ, ati bẹẹbẹ lọ, nitori pe awọn ẹri ti o wa l'oriẹ ko yọ ẹnikẹni silẹ.

Wiwọ asọ riran ati ibọsẹ ati bibo ori, ko kan obirnrin. [Nitorina, ko si asọ ti obinrin ko lee wọ, ko saa ti mọ jẹ asọ ti o fẹlẹ ti o fara silẹ, ko si ma jẹ asọ ti o ni ọsọ l'ara, ko si bo gbogbo ara rẹ l'ati oke de ilẹ, ki o si wọ ibọsẹ ati ibori].

b- Origun Ẹlẹẹkeji: Diduro ni 'Arafat. Niroti ọrọ Annabi ﷺ‬ pe:

((الحجّ عرفة)). [رواه أحمد وأصحاب السنن].

(('Arafa gan an ni Hajji)). [Ahmad ati awọn oni Tira Sunnan ni wọn gbaa wa].

d- Origun Ẹlẹẹkẹta: Tọwafu Ifadọt (tọwafu hajji), nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَلْيَطَّوَّفُوا بِالبَيْتِ العَتِيقِ[. [سورة الحجّ، من الآية: 29].

[Ki wọn si rọ kiri ka Ile Lailai na]. [suratu Hajji 22, ãyat: 29].

e- Origun Ẹlẹẹkẹrin: Al-ssa'ay. Nitori ọrọ Annabi ﷺ‬  pe:

((اسعوا، فإن الله كتب عليكم السعي)). [رواه الإمام أحمد والبيهقي].

((Ẹ rin (lãrin Sọfat ati Mọrwat), nitoripe Ọlọhun se e l'ọranyan l'ori yin)). [Imam Ahmad ati Al-Baehaqy ni wọn gbaa wa].

 6- Awọn ọranyan rẹ: Awọn ọranyan Hajji meje ni:

1- Gbigbe ihram (aniyan) lati miqọt.

2- Diduro ni 'Arafat l'ati ọsan titi ti òrún yoo fi wọ.

3- Sunsun ni Muzdalifat.

4- Sunsun ni Mina ni awọn oru ọjọ Tẹshriq (11, 12, 13) Dhul-hijat.

5- Jiju òkò esu.

6- Fifa irun tabi gige e.

7- Tọwafu idagbere.

 7- Alaye bi a ti nse Hajji:

a- Sunna ni fun ẹni ti o ba fẹ se hajji ki o wẹ gẹgẹ bi o ti se n wẹ iwẹ jannaba, ki o si fi lọfinda si ara, gẹgẹ bi ori rẹ ati irungbọn rẹ, ki o lo asọ iro funfun meji, ọkan l'oke ọkan ni isalẹ, ki Obinrin wọ eyi ti o ba wu ninu asọ ki o saa ti mọ fẹlẹ ti yoo fi ara silẹ, ki o si ma jẹ asọ ti o ni ọsọ l'ara.

b- Ni igbati o ba de Miqọt ki o ki irun ọranyan ti o ba se asiko rẹ ko wa gbe ihram l'ẹyin rẹ, ti ko ba jẹ asiko irun ọranyan o le ki nafilat raka'at meji pẹlu aniyan sunna aluwala, ko gbọdọ daniyan sunna ihram, to ri ko si ẹri l'ati ọdọ Annabi ﷺ‬ wipe ihram ni irun kan pato.

d- Ti o ba kirun tan yoo da aniyan iru ijọsin ti o bafẹ se, ti o ba se wipe Tamatu'u ni yoo sọ pe: ((LABAEKA ALAHUMỌ 'UMURAH)); itumọ rẹ: Iwọ Oluwa mi Mo jẹ ipe rẹ lati se 'Umurah. Ti o ba se wipe Ifrọd ni, yoo sọ pe: ((LABAEKA ALAHUMỌ HAJJAN)); itumọ rẹ: Iwọ Oluwa mi Mo jẹ ipe rẹ l'ati se hajji. Ti o ba se wipe Qiran ni o fẹ se yoo sọ pe: ((LABAEKA ALAHUMỌ HAJJAN FI 'UMURAH)); itumọ rẹ: Iwọ Oluwa mi Mo jẹ ipe rẹ l'ati se hajji ati 'umurah. Ọkunrin yoo wi jake, Obinrin yoo wi ti ẹ jẹjẹ. Wọn o si ma wi gbolohun talibiyat: ((LABAEKA ALAHUMỌ LABAEKA, LABAEKA LÃ SHẸRIKA LAKA LABAEKA, INAL HAMDA WA NI'IMỌTA LAKA WAL MULK LÃ SHẸRIKA LAKA)) ni ọpọlọpọ.

Itumọrẹ: ((Mo jẹ ipe rẹ Oluwa mi mo jẹ ipe rẹ, mo jẹ ipe rẹ ko si orogun fun Ọ mo jẹ ipe rẹ, dajudaju gbogbo ọpẹ gbogbo idẹra tiẸ ni ati gbogbo ọla, ko si orogun fun Ọ)).

e- Ni igbati o bade ilu Mọkkah yoo bẹrẹ isẹ pẹlu Tọwafu, yoo bẹrẹ l'ati okuta-dudu (hajaral-aswad) ti Ile Oluwa yoo wa ni apa alãfia rẹ, yoo fẹnu ko (hajaral-aswad) okuta-dudu ti o ba rọrun fun bẹẹ, ti ko ba rọrun yoo fi ọwọ kan lasan, ti ko ba rọrun yoo naa ọwọ si lasan, ẽwọ ni, ko gbọdọ fun eniyan ko si gbọdọ ti eniyan. Yoo se ALLAU-AKBAR, yoo si wi bayi:

((ALAHUMỌ IMỌNAN BIKA WA TASDIQỌN BI KITABIKA WA WAFÃ AN BI 'AHADIKA WA ITBÃ'AN LI SUNNATI NABIYIKA ﷺ‬.)

Itumọ: ((Oluwa mi Mo nse eleyi ni igbagbọ si Ọ, ati ni igba Tira Rẹ ni ododo, ati ni pipe adeun rẹ, ni ẹniti o ntẹle sunna Annabi Rẹ ﷺ‬.

Yoo tawafu nigba ẹmeeje, ti o ba de origun Yamãniy yoo fi ọwọ kan lai ko fi ẹnu pọn la.

Ninu awọn sunnan tọwafu ni Al-rọmlu, ohun na ni: ipọ sẹsẹ diẹ fun ọkunrin nikan ni ibi iyipo mẹta ti akọkọ, yoo se bẹẹ ni igbati o ba n se tọwafu akọkọ l'ẹyin igbati o de Mọkkah nikan. Nitori hadith Ibn 'Umar ti Bukhariy ati Muslim panupọ le l'ori wipe:

((كان رسول الله ﷺ‬ إذا طاف الطواف الأوّل خَب ثلاثاً ومشى أربعاً)).

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ ni igbati o ba se tọwafu akọkọ a ma pọ sẹsẹ ni ibi mẹta ti akọkọ, a si maa rin ni ibi mẹrin)).

Ninu awọn sunnan tọwafu ni yiyọ ejika apa ọtun sita fun ọkunrin, yoo fi asọ rẹ gba abẹ abiya rẹ ọtun. Nitori hadith Ibn 'Abbas (رضي الله عنهما) pe:

((اضطبع رسول الله ﷺ‬ هو وأصحابه ورملوا ثلاثة أشواط)).

((Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬ ati awọn sãbe rẹ yọ ejika apa ọtun wọn si ita, wọn si pọ sẹsẹ ni ibi iyipo (tawafu) mẹta ti akọkọ)).

Iyọ ejika-apa ọtun silẹ jẹ sunna ni igbati a ba fẹ se tọwafu nikan. Ko dara ki a yọ ọ silẹ siwaju rẹ tabi l'ẹyin ti a ba ti pari rẹ.

Yoo ma se adua ti o ba wu ni ibi tọwafu, pẹlu ibẹru ati idari ọkan si ọdọ Ọlọhun. Yoo ma wi adua yi laarin origun Yamọnyi si Okuta dudu (Hajaral aswadu):

]رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الآخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ[. [سورة البقرة، الآية: 201].

((RỌBANA ÃTINA FI DUNIYA HASANATAN WAFIL ÃKHIRATI HASANATAN WA QINA 'ADHABA NÃRI)). [surtaul-Baqọrah 2, ãyat: 201].

Itumọ: [Oluwa wa fun wa ni rere ni aye yi ati rere l'ọrun, ki o şọ wa ninu iya ina]. [surtaul-Baqọrah 2, ãyat: 201].

Sugbọn sise adayanri adua kan fun iyipo kọọkan [gẹgẹ bi awọn kan ti ma n se], eleyi ko l'ẹsẹ nilẹ rara, ko si ninu sunna Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬, bi ko se wipe bidi'at (adadãlẹ) ni. [Eyi ti o tọna ni ki olukuluku tọrọ nkan ti o ba n fẹ l'ọdọ Ọlọhun ọba, ibere wa ko le papọ, to ri ẹdun ọkan wa ko papọ].

Tawafu pin si orisi mẹta: Ifãdọt; tawafu hajji, ati Al-qudum; tawafu ti a ba wọ Mọkkah, ati Al-wada'at; tawafu idagbere. Alakọkọ jẹ origun, ẹlẹekeji jẹ sunna, ẹkẹẹta jẹ ọranyan l'ọdọ apakan awọn alufa.

ẹ- L'ẹyin ti o ba pari tawafu yoo yan nafilat ọpa meji (rak'at meji) l'ẹyin ibuduro Annabi Ibrahim (Mọqọmat Ibrahim) ti o ba ri ãye ni ibẹ, ti ko ba ri ãye ni ibẹ yoo yan ni gbogbo ibi ti o ba ti ri ãye ninu Mọsalasi. Ni ibi ọpa alakọkọ (rak'at alakọkọ) yoo ke suratul Fãtiat ati suratul Kãfirun:

]قُلْ يَا أَيُّهَا الكَافِرُون[. [سورة الكافرون].

((QUL YÃ AYUAL KÃFIRUN)). [suratl Kãfiruna 109].

Ni ibi ọpa ẹlẹẹkeji (rak'at ẹlẹẹkeji) yoo ke suratul Fatiat ati suratul Ikhlas:

]قُلْ هُوَ الله أَحَدٌ[. [سورة الإخلاص].

((QUL UWA LAHU AHADU)). [suratl Ikhlãsi 112].

Sunna si ni ki o fi ara balẹ ki wọn,ki o si se wọn ni fufu yẹ.

f- L'ẹyin naa yoo se sa'ay lãrin Sọfat ati Mọrwat ni igba meje, yoo bẹrẹ ni Sọfa yoo pari si Mọrwat. Ni igbati o ba gun oge Sọfat sunna ni ki o ke ãyat:

]إِنَّ الصَّفَا وَالمَرْوَةَ مِنْ شَعَائِرِ اللهِ فَمَنْ حَجَّ البَيْتَ أَوِ اعْتَمَرَ فَلاَ جُنَاجَ عَلَيهِ أَنْ يَطَّوَّفَ بِهِمَا وَمَنْ تَطَوَّعَ خَيْراً فَإِنَّ اللهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ[. [سورة البقرة، الآية: 158].

Itumọ: [Dajudaju Safa ati Marwa wa ninu awọn ami Ọlọhun ẹnikẹni ti o ba rin irin ajo lọ si ile na ni asiko Hajji tabi ti o lọ bẹ ẹ wo ni igba miran ('Umura), ko si ẹşẹ fun u, bi o ba rọ kiri ka wọn. Ẹniti o ba si finufẹdọ şe rere nitõtọ, Ẹni ti nsan õre ni Ọlọhun, Olumọ si ni Oluda ọpẹ, Oni-mimọ].[suratul-Baqọrah 2, ãyat: 158].

L'ẹyin eyi ni yoo gun oge Sọfa ti yoo da oju rẹ kọ gabasi (Qiblah) ni ẹniti o gbe ọwọ rẹ si oke, ti yoo si ma se Ọlọhun l'ọkan, ti yoo maa gbe E tobi, ti yoo si maa da ọpẹ fun Un, ti yoo maa wi bayi pe:

((الله أكبر، الله أكبر، الله أكبر، لا إله إلاّ الله وحده لا شريك له، له الملك وله الحمد يحيي ويميت وهو على كلّ شيء قدير، لا إله إلاّ الله وحده أنجز وعده ونصر عبده وهزم الأحزاب وحده)).

((ALAHU AKBAR, ALAHU AKBAR, ALAHU AKBAR, LA ILAHA ILAL LAHU WAHDAU LA SHARIKA LAU, LAUL MULIKU WALAUL HAMDU, YUHYI WA YUMITU WA UWA 'ALA KULI SHEI QỌDIR, LA ILAHA ILAL LAHU WAHDAU ANJAZA WA'DAU WA NASỌRA ABDAU WA HAZAMỌL AHZÃBA WAHDAU)).

Itumọ: ((Ọlọhun ọba l'oga ju, Ọlọhun ọba l'oga ju, Ọlọhun ọba l'oga ju, ko si ẹniti a gbọdọ jọşin fun l'ododo afi Ọlọhun nikan soso, kolorogun, ti Ẹ ni ọla se, ti Ẹ ni ẹyin se, ohun ni O le jini, ti O si lee pani, ohun ni alagbara l'ori gbogbo nkan. Ko si Ọlọhun miran yatọ si Ọlọhun nikan, O pe adeun Rẹ, O si ran ẹru Rẹ l'ọwọ, O si pa awọn ijọ ọta run l'oun nikan)). Yoo wi gboloun yi ni ẹmẹẹta.

L'ẹyin eyi ni yoo wa se adua ti o ba fẹ, yoo tọrọ õre aye ati ti ọrun.

L'ẹyin na ni yoo sọ kalẹ ni ẹniti o da oju rẹ kọ oke Mọrwa. O jẹ sunna fun ọkunrin ki o pọ sẹsẹ lãrin amin ina elewe-oko meji ti o ba rọrun fun bẹ, ti ko ni ni ẹlomiran l'ara. Ti o ba de oke Mọrwa yoo gun un, yoo si daju kọ Gabasi (Qiblat) yoo si gbe ọwọ rẹ si oke, yoo wi gẹgẹ bi o ti wi l'oke Sọfat.

Ni igbati o ba n se sa'ayu l'ọwọ o le maa se adua ti o wa l'ati ọdọ Ibn 'Umar ati Ibn Mọs'ud (رضي الله عنهما) yi:

((ربّ اغفر وارحم إنّك أنت الأعزّ الأكرم)).

((RỌBI IGFIR WAR-HAM INAKA ANTAL A'AZUL AKRAMU)).

Itumọ: ((Oluwa mi se aforijin (fun mi), si se ãnu (mi), dajudaju iwọ ni ẹni-iyi ẹni apọnle julọ)).

O dara ki o se sa'ayu (laarin Sọfa ati Mọrwa) pẹlu imọra, ti o ba si see pẹlu aimọra naa, ko si laifi nibẹ, ko da bi obinrin ti o wa ninu nkan osu rẹ ba see o tọ fun, tori imọra kii se mọjẹmu fun Al-sa'ayu.

g- Ni igbati o ba pari sa'ayu rẹ tan yoo ge gbogbo irun rẹ diẹ, ti o ba jẹ ẹniti o n se hajji tamọtu'u, obinrin yoo ge diẹ bi ori-ika, sugbọn ti o ba jẹ ẹniti on se haji ati 'umurah (qiran), tabi haji aso (ifrad) ni onitọun ko ni ge fa irun tirẹ, yoo wa ninu ihram rẹ titi ti yoo fi bọ ọra silẹ ni ọjọ igunran, ọjọ ọdun lẹyin ti o bati ju òkò tan.

gb- Ti o ba di ọjọ kẹjọ ninu osu dhil-hijjat (Yaomul tarwiyat) ẹniti o n se hajji tamatu'u yoo tun gbe ihram ti hajji ni asiko duha ninu ile rẹ ti o de si ni Mikkah, bakanna ni ara ilu Mọkkah yoo gbe ihram rẹ ninu ile rẹ. Yoo wẹ, yoo si se imọtoto ati nkan miran. Ko si ninu sunna lilọ Ile-Ọlọhun (Al-mọsjidi Al-haram) lati lọ gbe ihram. Tori ko si ẹri fun lati ọdọ Annabi ﷺ‬, bẹẹ ko si pa awọn sãbe rẹ l'asẹ bẹẹ ninu nkan ti amọ.

O wa ninu Sọhihaen (Tira Bukhari ati Muslim) hadith Jãbir ọmọ 'Abdullahi t pe; Annabi ﷺ‬  sọ fun wọn pe:

((أقيموا حلالاً حتى إذا كان يوم التروية فأهلّوا بالحجّ...)).

((Ẹ wa ni ilu Mọkkah pẹlu asọ ile yin, ti o ba di ọjọ (Tẹrwiyat) ọjọ kẹjọ dhul-hijjat ki ẹ gbe ihram yin ki ẹ si da aniyan hajji…)).

O tun wa ninu sọhihu Muslim l'ati ọdọ rẹ (Jãbir ọmọ 'Abdullahi t) o sọ pe:

أمرنا رسول الله ﷺ‬ لما أهللنا أن نحرم إذا توجهنا إلى منى فأهللنا من الأبطح.

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ pa wa l'asẹ ni igbati a de Mọkkah pe ki a gbe ihram wa ni igbati a ba n lọ Minna, a si da aniyan ni ãye ti a npe ni: Al-abtọh)).

Ẹniti o n se hajji tamatu'u yoo da aniyan ni ọjọ kẹjọ, l'ati inu ile rẹ ti o de si ni Makkah bayi pe: ((LABAEKA HAJJAN)). Mo jẹ ipe rẹ iwọ Oluwa mi lati se isẹ Hajji.

i- O dara ki o jade lọ si Mina ki o si ki irun Ayila ati Alãsari ati Mọgari ati 'Ishai ni bẹ ni ọjọ kẹẹjọ yi, yoo ki wọn ni asiko wọn ni ọpa mejimeji. Odara ki o sun bẹ ni oru ọjọ 'Arafat, nitori hadith Jãbir ti Muslim gba wa.

h- Ti òrún bati yọ ni ọjọ 'Arafat (ọjọ kẹsan osu Dhul-hijjat) yoo ma lọ si 'Arafat, o dara ki o kọkọ duro si ãye ti a npe ni Namirat titi di òrún yẹri ti o ba rọrun bẹẹ fun gẹgẹ bi Annabi ﷺ‬ ti se. Sugbọn ti ko ba rọrun bẹ; ko si laifi, ki o maa lọ si 'Arafat taara. Ni 'Arafat yoo ki irun Ayila ati Alasari papọ ni ọpa mejimeji, l'ẹyin ti òrún ba yẹri. L'ẹyin naa ni yoo wa duro. Eyi ti o dara ni ki o jẹ ki Oke 'Arafat (Jabalirahmat) wa lãrin oun ati Gabasi (Qiblat) ti o ba rọrun bẹẹ, ti ko ba rọrun ki o saa ti da oju rẹ kọ Gabasi (Qiblat) ko da bi ko da oju rẹ kọ Oke. O dara pupọ ki o dunni mọ iranti Ọlọhun nikan ki o si gbiyanju l'ọpọlọpọ l'ori ijirẹbẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pẹlu adua ati kike Al-Qurãn ni ẹniti o gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke. Nitori hadith Usãmat t  ti o sọ pe:

((كنت رديف النبي ﷺ‬ بعرفات فرفع يديه يدعو فمالت به ناقته فسقط خطامها فتناول خطامها بإحدى يديه وهو رافع يده الأخرى)). [رواه النسائي].

((Mo wa l'ẹyin Annabi ﷺ‬ ni 'Arafat, o gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke, ni igbati rankumi rẹ tẹriba diẹ ijanu rẹ bọ, o si fi ọwọ kan mu ijanu ti o si gbe ọwọ keji si oke)). [Al-Nasãi o gbaa wa].

O tun wa ninu sọhihu Muslim pe:

((ولم يزل واقفاً يدعو حتى غابت الشمس وذهبت الصفرة)).

((Annabi ko yẹ ko gbo ni ẹni ti o duro ti o n se adua, titi ti òrún fi wọ ti pupa si fi wọ ile)).

Adua ọjọ 'Arafat ni adua ti o l'õre ju. Annabi ﷺ‬ sọ pe:

((خير الدعاء دعاء يوم عرفة، وخير ما قلت أنا والنّبيّون من قبلي: ((لا إله إلاّ الله وحده لا شريك له له الملك وله الحمد وهو على كلّ شيء قدير)). [رواه مسلم].

Adua ti o ni oore ju ni adua ọjọ 'Arafat, Adua ti o ni oore ti emi (Annabi Muhmmad) ati awọn Annabi Ọlọhun ti o siwaju mi wi ni:

((LA ILAHA ILA LAHU WAHDAU LA SHARIKA LAU, LAUL MULIKU WALAUL HAMDU, WA UWA 'ALA KULI SHEI QỌDIR)).

Itumọ: ((Ko si ẹniti a gbọdọ jọşin fun l'ododo afi Ọlọhun nikan, ko ni orogun, ti Ẹ ni ọla se, ti Ẹ ni ẹyin se, oun ni alagbara l'ori gbogbo nkan)). [Muslim ni o gbaa wa].

Nitori idi eyi; o di dandan ki eniyan fi ini bukata si Ọlọhun rẹ han, ki o si fi ara gbolẹ fun Ọlọhun, ki o ma se jẹ ki anfãni nlanla yi bọ mọ ohun l'ọwọ([5]). Annabi ﷺ‬ sọ bayi pe:

((ما من يوم أكثر من أن يعتق الله فيه عبداً من النار من يوم عرفة، وإنه ليدنو ثم يباهي بهم الملائكة، فيقول: ما أراد هؤلاء؟)). [رواه مسلم].

((Ko si ọjọ kan ti Ọlọhun ma n bọkun ina kuro l'ọrun awọn ẹru ti o pọ ju ọjọ 'Arafat lọ, Ọlọhun yoo sunmọ wa, ti yoo si ma fi awọn ti wọn wa  ni 'Arafat se iyanran fun awọn Mọlaikat, ti yoo ma sọ bayi pe: kini awọn wọn yi n fẹ?)). [Muslim gbaa wa].

Origun kan ni diduro ni Arafat jẹ. Eyi ti o jẹ ọranyan ni wiwa nibẹ titi òrún yoo fi wọ. O si tun se ọranyan lo ri alalãji ki o ri daju pe ohun wa ninu ãla 'Arafat, toripe ọpọ ninu alalãji ni wọn maa n duro ni ibi ti kii se 'arafat, ti o si jasipe wọn o ni hajji.

j- Ni igbati òrún bawọ dada, alalaaji yoo kọri si Muzdalifat pẹlu pẹlẹ ati ifarabalẹ. Nitori ọrọ Annabi ﷺ‬ ti o sọ pe:

((أيها الناس السكينة السكينة)). [رواه مسلم].

((Ẹyin eniyan, ẹ ma şe pẹlẹpẹlẹ)). [Muslim ni o gbaa wa].

Ni igbati o ba de Muzdalifat yoo kirun Mọgari ati 'Ishai, Mọgari ọpa mẹta, 'Ishai ọpa meji, yoo ki wọn papọ l'asiko 'Ishai([6]). Sunnan ni pe Muzdalifat ni alalãji o ti ki irun mejeeji l'ati fi kọse Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬, afi ti o ba n bẹru ki asiko 'Ishai ma lọ, nigbana o lee ki wọn ni ibikibi.

Yoo sun Muzdalifat, l'oru yi, ko si irun miran ti yoo ki, bẹẹ ko si adua kan ti yoo se, tori pe Annabi ﷺ‬ ko se nkankan tayọ pe o sun. Nitori ẹgbawa Jãbir ibn 'Abdullahi t ti Muslim gba wa pe:

((أن النبي ﷺ‬ أتى المزدلفة فصلى بها المغرب والعشاء بأذان واحد وإقامتين، ولم يسبّح بينهما شيئاً ثم اضطجع حتى طلع الفجر)).

((Ni igbati Annabi de Muzdalifat, o ki irun Mọgari ati 'Ishai pẹlu Ãdhan (irun-pipe) kan ati iqọmat meji, ko yan naafilat kankan l'aarin wọn, l'ẹyin naa ni o sun titi alufajari fi yọ)).

O tọ fun awọn ti wọn bani idiwọ ati awọn alailagbara ki wọn kuro ni Muzdalifat lọ si Mina l'ẹyin idaji òru, ti osupa bati wọọkun, l'ati lọ ju oko. Sugbọn ẹniti kii ba se alailagbara ti ko si jẹ alamojuto alailagbra, onitọhun yoo wa ni Muzdalifat titi ti Alifajri yoo fi yọ. Sugbọn nkan ti ọpọ awọn eniyan n se l'oni, nipa pe ki wọn ma sãre lọ ju oko ni akọkọ oru nitori ati simi, eleyi tako ilana Ojişẹ Ọlọhun ﷺ‬.

Ni igbati o ba kirun Asuba ni Muzdalifat tan, yoo duro ni Almọsh'arl Harãm (Mọsalasi Muzdalifat), yoo daju kọ gabasi (Qiblat) yoo wa tọrọ adua l'ọpọlọpọ, yoo si gbe ọwọ rẹ si oke, yoo se bẹ titi ilẹ yoo fi mọ dãda. Ti ko ba ri aye ni Mọsalasi yi gbogbo ibi ti o ba duro si ninu Muzdalifat ni o tọ. Nitori ọrọ Annabi ﷺ‬ pe:

((وقفت ها هنا، وجَمْع كلّها موقف)). [رواه مسلم].

((Emi duro ni ibiyi, sugbọn gbogbo Jam'u (Muzdalifat) ni ibuduro)). [Muslim gbaa wa].

k- L'ẹyin naa ni alalãji yoo kọri si Mina l'ẹyin ti ilẹ bamọ siwaju ki òrún to yọ ni ọjọ igunran -ọjọ ọdun- ti yoo si ju òkò Jamratul'aqọbat - ohun naa ni òkò toto bi ju ti o sun mọ Mọkkah – meje, òkò kọọkan gẹgẹ bi ọmọ-agbado. Awọn alufa pa ẹnu pọ l'ori wipe juju rẹ tọ l'ati gbogbo ãye. Sugbọn eyi ti o l'ọla ni ki o jẹki Ka'abat (ile Oluwa ni Mikkah) wa ni ọwọ alãfia oun ki Mina si wa ni ọwọ ọtun rẹ. Nitori hadith Ibn Mọsu'ud t wipe:

أنه انتهى إلى الجمرة الكبرى فجعل البيت عن يساره ومنى عن يمينه ورمى بسبع، وقال: ((هكذا رمى الذي أنزل عليه سورة البقرة)). [متفق عليه].

((Ni igbati o de ibi òkò nla yi, o fi Ile Ọlọhun si ọwọ alãfia o si fi Mina si ọwọ ọtun rẹ, ti o waa ju òkò meje. O si sọ pe: bayi ni mose ri ẹni ti Suratul-Baqọrat sọ kalẹ fun (Annabi) ti o se)). [Bukhariy ati Muslim panu pọ le lori].

Juju òkò ti o to bi ko ni ẹtọ, bẹẹ ni juju ibọsẹ ati bata ati bẹẹbẹ lọ, ko ni ẹtọ. Ni igbati alalãji bati fẹẹ ju òkò yi ni yoo dakẹ sise labaika (Talibiyat).

Sunnah ni ki alalãji kọkọ ju òkò, l'ẹyin naa ki o pa ẹran hadayat ti o ba jẹ ẹni ti o se tamatu'u tabi qiran, l'ẹyin naa ki o fa irun rẹ, tabi ki o ge mọlẹ, sugbọn fifa ni o ni ọla ju fun ọkunrin.

لأن النبي ﷺ‬ دعا بالرحمة والمغفرة للمحلّقين ثلاث مرات، وللمقصرّين مرّة واحدة، كما رواه البخاري ومسلم.

Nitori pe Annabi ﷺ‬ tọrọ adua ãnu Ọlọhun ati aforijin rẹ fun awọn ti wọn fari wọn l'ẹmẹta, o si tọrọ ni ẹkan pere fun awọn ti wọn ge irun wọn. Gẹgẹ bi Bukhariy ati Muslim  ti gba wa. L'ẹyin naa alalãji yoo lọ si Ka'abat (ile Ọlọhun) l'ati lọ se tawafu-ifadọt.

Eleyi ni Sunnat. Nitori hadith Jãbir ọmọ 'Abdullahi t ti Muslim gba wa pe:

((أن النبي ﷺ‬ أتى الجمرة التي عند الشجرة فرماها بسبع حصياتٍ يكبّر مع كلّ حصاةٍ منها، مثل حصى الحذف، رمى من بطن الوادي ثم انصرف إلى المنحر فنحر ثم ركب رسول الله ﷺ‬ فأفاض إلى البيت فصلّى بمكة الظهر)).

((Annabi ﷺ‬ lọ si ibi òkò ti o wa l'ẹba igi, o si juu ni òkò keekeeke meje, ti o n gbe Ọlọhun tobi (kabara) ni ibi gbogbo òkò kọọkan, o ju òkò l'ati inu koto (wãdi) l'ẹyin naa ni o lọ si ibu-gun ẹran ti o si gun ẹran, l'ẹyin naa ni Ojisẹ Ọlọhun gun nkan-igun rẹ ti o lọ si ile Ọlọhun ni Mọkkah ti o si ki irun Ayila ni ibẹ.

Ẹnikẹni ti o ba gbe ọkan ninu awọn nkan mẹrẹẹrin yi siwaju omiran ko si laifi fun. Nitori hadith 'Abdullahi ibn 'Amru t ti Bukhariy ati Muslim gba wa ninu hajji idagbere wipe:

وقف رسول الله ﷺ‬ والناس يسألونه، قال: فما سئل رسول الله ﷺ‬ يومئذٍ عن شيءٍ قُدِّم أو أُخِّر إلاّ قال: ((افعل ولا حرج)).

((Annabi ﷺ‬ duro awọn eniyan si n bi ni awọn ibere, o sọ pe: ko si ibere kan ti wọn bii ni ọjọ yi nipa gbigbe kinikan siwaju tabi gbigbe si ẹyin afi ki Annabi sọ wipe: se bẹẹ, ko si laifi)).

Ni igbati o ba pari tawafu rẹ tan, ti o ba jẹ ẹni ti o nse tamatu'u yoo se Sa'ayu l'aarin Sọfa ati Moriwa ti hajji l'ẹyin tawafu, tori sa'ayu rẹ ti akọkọ duro fun 'umurat ni, o si di dandan ki o se sa'ayu ti hajji. Sugbọn ti o ba jẹ ẹni ti o se hajji ifrọd tabi qiran ti o si ti se sa'ayu tẹlẹ l'ẹyin ti o se tawafu akọkọ, onitọun ko nii se sa'ayu miran mọ. Nitori ọrọ Jãbir t pe:

((لم يطف النبي ﷺ‬ ولا أصحابه بين الصفا والمروة إلاّ طوافاً واحداً طوافه الأوّل)). [رواه مسلم].

((Annabi ﷺ‬ ati awọn Saabe rẹ wọn o se tawafu lãrin Sọfa ati Mọrwa afi ẹẹkan, ohun na ni tawafu akọkọ)). [Muslim ni o gbaa wa].

L- Awọn ọjọ sisa ẹran mẹtẹta (ayãmu tẹshriq) (ọjọ kọkanla ati ọjọ kejila ati ọjọ kẹtala ninu osu Dhil-hijjah) jẹ awọn ọjọ jiju òkò fun awọn ti ko ba kanju kuro ni Mina, sugbọn awọn ti wọn ba kanju wọn o ju ni ọjọ kọkanla ati ọjọ kejila nikan. Nitori ọrọ Ọlọhun (ti ọla Rẹ ga):

]وَاذْكُرُوا اللهَ فِي أَيَّامٍ مَّعْدُودَاتٍ فَمَنْ تَعَجَّلَ فِي يَوْمَيْنِ فَلاَ إِثْمَ عَلَيْهِ وَمَنْ تَأَخَّرَ فَلاَ إِثْمَ عَلَيْهِ لِمَنِ اتَّقَى[. [سورة البقرة، الآية: 203].

[Ẹ se iranti (isọ orukọ) Ọlọhun laarin awọn ọjọ ti o ni onka, l'ẹhinna ẹniti o ba kanju lọ ni ọjọ meji ko si ẹşẹ fun u; ẹniti o ba tẹsẹ duro diẹ ko si ẹşẹ fun u; eyin mbẹ fun ẹniti o bẹru Ọlọhun]. [suratul-Baqọrah 2, ãyat: 203].

Bẹrẹ l'ati ọjọ keji ọdun, okuta (Jamarat) kekere eyi ti o sunmọ mọsalasi Khaef, ni alalãji yoo ti maa bẹrẹ jiju òkò meje, l'ẹyin naa ni okuta Jamarat tãrin yoo ju ni òkò ni meje, l'ẹyin naa ni okuta (Jamarat) nla yoo ju ni meje. Ti yoo si ma kabara ni gbogbo òkò kọọkan. Sunna ni ki o duro l'ẹyin okuta (Jamarat) kekere ni ẹniti o daju kọ gabasi (qiblat), ti okuta (Jamara) yii yoo si wa l'ọwọ alãfia rẹ, ti yoo si se adua. Yoo si tun duro l'ẹyin okuta (Jamarat) keji, ni ẹniti o daju kọ gabasi (qiblat), ti okuta yi yoo si wa l'ọwọ ọtun rẹ, ti yoo si tun se adua okuta. Sugbọn (Jamarat) nla ti igbẹyin ko ni duro nibẹ rara l'ẹyin ti o ba ju oko tan.

Asiko jiju òkò bẹrẹ lati ẹyin igba ti òrún ba yẹri. Nitori hadith Ibn 'Umar t ti o sọpe:

((كنا نتحيّن فإذا زالت الشمس رمينا)). [رواه البخاري].

((A ma n wo asiko, ni igbati òrún ba yẹri a o ju òkò)). [Bukhariy ni o gbaa wa].

Awọn alufa si fi ẹnuko l'ori pe opin asiko ti eniyan le juko da ni igbati õrun bawọ ni ọjọ kẹtala osu Dhil-hijjat. Ẹnikẹni ti òrún ọjọ yi bawọ ba ni Mina ti ko iti ju oko, koni ju òkò naa ma, sugbọn yoo san itanran pẹlu ki o pa ẹran.

m- Alalãji yoo ma sun Mina ni awọn oru ọjọ sisa ẹran (ayãmu tẹshriq) (ọjọ kọkanla ati ọjọ kejila ati ọjọ kẹtala ninu Dhil-hijjah). Ti òrún ba ti wọ ba alalãji ni ọjọ kejila ni Mina ti koi ti jade, o di dandan fun ki o tun sun Mina di ọjọ kẹtala ti yoo si ju òkò ọjọ kẹtala naa.

n- Alalãji  ko gbọdọ jade kuro ni ilu Mọkkah afi l'ẹyin ti o ba se tawafu idagbere tan. Toripe ninu awọn ọranyan hajji ni o wa lọdọ ọpọ awọn alufa. Sugbọn ko se dandan fun obinrin ti o nse nkan osu rẹ lọwọ. Nitori hadith Ibn 'Abbas t ti o sọpe:

((لا ينفرن أحدٌ حتى يكون آخر عهده بالبيت)), وفي رواية: ((إلا أنه خفف عن المرأة الحائض)). [رواه مالك وأصله في صحيح مسلم].

((Ojisẹ Ọlọhun ﷺ‬ sọ wipe: ẹnikẹni ninu yin ko gbọdọ kuro ni Mọkkah afi ki idagbere fun ile Ọlọhun jẹ igbẹyin isẹ rẹ)).

O tun wa ninu ẹgba wa miran pe: ((Sugbọn Annabi se idẹkun fun obinrin ti o n se nkan osu l'ọwọ)). [Imam Mọlik ni o gbaa wa, ipilẹ rẹ si wa ninu sọhihu Muslim].

Ẹniti o ba lọ tawafu Ifadọ tiẹ l'ara titi di igba ti o ba fẹ rin-irin ajo, yoo se tawafu Ifadọ nikan, o si ti gbe tawafu idagbere naa fun, l'ọdọ ọpọ awọn alufa.

o- O dara fun ẹniti o ba dari hajji ki o wi adua ti owa ninu ẹgbawa Ibn 'Umar t ti [Bukhariy gba wa] wipe:

إن النبي ﷺ‬ كان إذا قفل من غزو أو حجّ أو عمرة يكبّر على شرف من الأرض ثم يقول: ((لا إله إلاّ الله وحده لا شريك له، له الملك، وله الحمد، وهو على كلّ شيء قدير، آيبون تائبون عابدون لربنا حامدون، صدق الله وعده، ونصر عبده، وهزم الأحزاب وحده)).

Annabi ﷺ‬ jẹ ẹniti o maa n gbe Ọlọhun tobi ni igbati o ba ndaribọ lati oju-ogun, tabi Hajji, tabi 'Umurah, ni awọn aaye ti o ba ga soke l'ori ilẹ, ti o maa n wi bayi pe:

((LA ILAHA ILAL LAHU WA'DAU LA SHARIKA LAU, LAUL MULIKU, WALAUL HAMDU, WA UWA 'ALA KULI SHEI QỌDIR, ÃYIBUNA TÃIBUNA 'ÃBIDUNA LIRỌBINA HÃMIDUNA, SỌDAQAL LAHU WAHDAU, WA NASỌRA 'ABDAU, WA HAZAMỌL AHZÃBA WAHDAU)).

Itumọ: ((Ko si ẹniti agbọdọ jọşin fun l'ododo afi Ọlọhun nikan soso, ko ni orogun, ti Ẹ ni ọla se, ti Ẹ ni ẹyin se, oun si ni alagbara l'ori gbogbo nkan. A de o, A tuba o, A o ma sin Oluwa wa, Oun si ni a o ma da ọpẹ fun Un, Ọlọhun pe adehun Rẹ o, O si ran ẹru Rẹ lọwọ o, O si pa awọn ijọ ọta run l'oun nikan)).([1])  sugbọn ninu irun o gbọdọ wọ asọ ti yoo bo o lati ejika rẹ titi de isalẹ orukun.

([2](  Gẹgẹ bi: ((ATTAHIYATU LILLAH, AZZAKIYATU LILLAH, ATTỌYYIBAATU SSALAWAATU LILLAH, ASSALAAMU ALAEKA AYUA ANNABIYU WARAHMATU LLAH  WABARAKAATU ﷻ‬ …)).

(1)  Tabi: ((Attahiyatu lillah, Azzakiyatu lillah, Attọyibatu Ssalawatu lillah, Assalaamu alaeka ayua annabiyu warahmatu llahi wabarakãtu u, Assalãmu 'alaena wa 'ala 'ibãdillhai ssọlihina. Ashadu an la ilaha ilallahu, wa aşhadu ana Muhmmadan 'abudu u warọsulu u…)).

(1)  Nigbati ko basi nibi ti awọn ọkunrin wa, sugbọn ti o ba sewipe awọn ọkunrin wa niibi ti o wa, yoo ma fi asọ da gaga oju rẹ, nitori hadith 'Aishat ti o mbọ wa.

([5] )  Pẹlu aroye ẹjọ-wẹwẹ, tabi ijoko adua ti ko tọ pẹlu mimọ se adua lapapọ lati ma gba owo lọwọ awọn alalãji.

(1)  Yoo si ki Shaf'i ati Witiri.