Awọn ohun ti o yẹ ki musulumi o mọ, ki o si maa se ni Ọjọ jimoh. ()

Akọsilẹ ti o sọ nipa pataki ọjọ jimọh ati awọn ohun ti ye ki Musulumi se nibẹ gẹgẹ bii iwẹ, lilo lọfinda oloorun didun ati bẹẹbẹẹ lọ.

  |

  Awọn ohun ti o yẹ ki musulumi o mọ, ki o si maa se ni Ọjọ jimoh.

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Lati ọwọ:

  Dr.Mubarak Zakariya Al imam

  Atunyewo:

  Hamid Yusuf

  2015 - 1436

  أمور ينبغي أن يعلمها المسلم ويعمل بها يوم الجمعة

  « بلغة اليوربا »

  كتبها:

  د.مبارك زكريا الإمام

  مراجعة:

  حامد يوسف

  2015 - 1436

  OHUN TI O YẸ KI MUSULUMI O MỌ NIPA ỌJỌ JIMỌH.

  Ninu iwe yi, a o sọ ọrọ nipa ọla ati ajulọ ti o wa fun ọjọ jimọh ati pataki ọjọ naa ati awọn isẹ ti o yẹ ki a se ninu rẹ.

  ALAKỌKỌ: PATAKI ỌJỌ JIMOH.

  Ọjọ jimọh jẹ ọkan pataki ninu ọjọ meje ti Ọlọhun da si inu ọsẹ, fun lilo awa ẹda, ọjọ yii si pataki pupọ fun ijọ musulumi nitori awọn idi ti o nbọ yii:

  1- Nitoripe awa ijọ Anabi Muhammad (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) nikan ni a ni ọjọ jimọh.

  2- Ati wipe ọjọ naa ni Ọlọhun se ẹda Anabi Adam.

  3- Ọjọ naa ni Ọlọhun mu u wọ inu ọgba idẹra (alujanna).

  4- Ọjọ jimọh naa ni Ọlọhun mu u kuro ni inu ọgba idẹra (alujanna).

  5- Ọjọ jimọh naa ni Ọlọhun yoo mu ki aye wa si opin.

  6- Ati wipe ọjọ jimọh yii naa ni ọjọ ipade ọsẹ-ọsẹ fun awa musulumu ilu kọọkan, ti a maa n ko jọ lati se ijọsin pataki kan, ti o jẹ pe ọjọ jimọh ni a le see, gẹgẹ bi irun jimọh.

  Eleyi ni diẹ ninu ọna ti a fi le mọ pataki ọjọ Jimọh.

  ẸLẸẸKEJI: ỌLA ATI AJULỌ TI O WA FUN ỌJỌ JIMỌH.

  Ọjọ jimọh jẹ ọjọ kan ti Ọlọhun fun ni ajulọ ati ọla ti o yatọ ninu awọn ọjọ meje ti o wa ninu ọsẹ, nitori awọn ijọsin pataki ti Ọlọhun fẹ ki a se ni ọjọ naa, ati gbigba adua ti o wa ninu ọjọ naa.

  Ni bayi, a o se alaye awọn ọla ti o wa fun ọjọ jimọh ni ọkọọkan.

  1- Ojisẹ Ọlọhun se adehun fun wa pe Ọlọhun yoo pa ẹsẹ ti musulumi ba se laarin jimọh kan si jimọh keji rẹ.

  2- Ọjọ jimọh ni ọjọ ti o ni oore ju awọn ọjọ ọsẹ yoku, gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) se sọ.

  3- Awọn asiko gbigba adua kan nbẹ ninu ọjọ jimọh, t’ojẹ wipe ko si nkan ti eniyan le beere lọdọ Ọlọhun ni asiko naa, ti Ọlọhun ko ni se.

  4- Ọjọ jimọh nikan ni a ti maa n ki irun jimọh, ti a o si gbọ ibanisọrọ Ọlọhun (khutbah), eyiti yoo tun aye ati ọrun wa se.

  Lẹyin awọn ohun ti a ti sọ yi, awa naa ti ni idaniloju, ati imọ nipa ọla ti o wa fun ọjọ jimọh.

  ẸLẸẸKẸTA: AWỌN NKAN TI O YẸ KI MUSULUMI O MAA SE NI ỌJỌ JIMỌH.

  Ẹsin Islam fẹ ki musulumi lo gbogbo ọjọ aye rẹ fun ohun ti yoo jẹ ki Ọlọhun yọnu sii, ti yoo si tun jẹ anfaani fun awọn ẹda Ọlọhun, nitorinaa, ko si igbati musulumi ni ominira lati d’awọ ijọsin ati isẹ rere duro.

  Sugbọn Islam ya ọjọ jimọh si ọtọ, pẹlu awọn ijọsin kan ti o tun yatọ si ti ọjọ yoku, gẹgẹbii:

  1- IMOTOTO ARA:

  Iwẹ fun irun ọjọ jimọh. Islam fẹ ki a wẹ ki a to lọ ki irun jimọh, a o wẹ iwẹ yii gẹgẹ bii eyiti a maa n wẹ lẹyin ti a ba sun pẹlu iyawo wa. Kosi aniyan kan ti a gbọdọ fi ẹnu sọ ti a ba fẹ wẹ, bikosepe a o fi aniyan wa si inu ọkan wa.

  Eleyi fi nyewa wipe, ẹsin Islam kii se ẹsin ọbun rara, ko si fi aaye gba iwa idọti, Ojisẹ Ọlọhun (ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma aba a) sọ pe : (Ọba mimọ ni Ọlọhun, ko si nii gba nkankan lọwọ ẹda ayaafi ohun ti o ba jẹ mimọ). Imọtoto se pataki ninu Islam, papaajulọ ti a ba fẹ ki irun ti o jẹ ibanisọrọ laarin awa ẹda ati Ọlọhun Ọba wa, ati ni ọjọ jimoh ti o jẹ wipe gbogbo musulumi yoo ko jọ si masalasi n la (jimọh) lati gbọ ibanisọrọ ati lati ki irun jimọh.

  2- SISE ARA L`OGE:

  Ninu ohun ti o yẹ ki Musulumi se ni ọjọ jimọh ni ki o wọ eyi ti o dara julọ ninu asọ rẹ, gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun (ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma aba a) se sọ. Eleyi kii se wipe ki eniyan sọpe oun ko nii lọ si jimoh t’oripe oun ko ni asọ tuntun, eleyi ko dara, ẹniti o ba ni asọ tuntun ki o wọ tuntun, ẹniti ko ba ni tuntun, ki o fọ eyi ti o ni, ki o si tun se daradara, ki o wọ ọ lọ si mọsalasi.

  3- LILO TURARI OLOORUN DIDUN (FUN ỌKUNRIN NIKAN):

  Ninu ohun ti Islam fẹ ki musulumi se ni ọjọ jimọh ni ki o lo turari oloorun didun, sugbọn, ẹniti ko ba ni turaari yi, ko si ọranyan fun, bẹẹni ko si si ẹsẹ fun un.

  Awa naa yoo rii wipe o dara pupọ ti a ba tẹle ọrọ Anabi yi, pataki julọ ni aaye ti eniyan pọ nibẹ gẹgẹ bii mọsalasi jimọh, eleyi ko ni jẹ ki oorun ti ko ba ẹmi mu kọ di awọn musulumi lọwọ lati gbọ ibanisọrọ Ọlọhun (khutbah) ninu mọsalasi.

  4- KIKA SURAT KAHF:

  Ninu awọn ohun ti Anabi wa fẹ ki musulumi se ni ọjọ jimọh ni ki o ka suratul kahf ni ale alamisi mọjumọ jimọh. Ojisẹ Ọlọhun (ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma aba a) sọ pe: (Ẹnikẹni ti o ba n ka suratul kahf ni ọjọ jimọh, Ọlọhun yoo fun ni imọlẹ, titi di ọjọ jimọh miran, bakanna Ọlọhun yoo la ẹniti o ba nke aaya mẹwa ti o wa ni ibẹrẹ suratul kahf, Ọlọhun yoo gba kalẹ lọwọ dajjal. [Mustadrakul hakim, hadiisi 3317, 3318].

  5- SISE ỌPỌLỌPỌ ASALATU FUN ANABI MUHAMMAD:

  Sise asalatu fun Anabi wa Muhammad (ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) jẹ ọkan ninu ojuse musulumi si Anabi rẹ, o si jẹ ijọsin ti o yẹ ki a maa se ni gbogbo igba, gẹgẹ bi Ọlọhun se pasẹ fun wa ninu Alukurani.

  Sugbọn asalaatu fun Anabi ni ọjọ jimọh, o yatọ si ti gbogbo ọjọ yoku, toripe Anabi Muhammad gan an ni o pa awa musulumi l’asẹ wipe ki a maa se ọpọlọpọ asalatu fun oun ni ọjọ jimoh.

  Sugbọn, o yẹ ki a pe akiyesi ara wa si awọn nkan mẹta:

  Alakọkọ: a gbọdọ se asalatu fun Anabi Muhammad ni ọna ti Anabi fi kọ wa, ohun naa ni eyi ti o njẹ (solaatul ibrahimiyah), ki a jina si awọn asalatu atọwọda yoku.

  Elẹẹkeji: A ko gbọdọ ko ara wa jọ ni ọjọ jimọh nitori pe a fẹ se asalatu fun Anabi, gẹgẹ bi awọn kan ti n se ni asikoyi. Eyi ti o ba ilana Anabi wa mu ni ki ẹnikọọkan o ma da Asalatu ti rẹ se.

  Elẹẹkẹta: ko si gbedeke onka kankan fun asalatu sise fun anabi ni ọjọ jimọh, Islam fi aye gba wa ki a se iye ti o ba rọrun fun wa lati se.

  6- GIGE EEKANNA ỌWỌ ATI ẸSẸ:

  Gige eekanna ọwọ ati ẹsẹ jẹ amin imọtoto ara, idi niyi ti Sharia Islam fi se e ni ẹtọ fun musulumi lati maa ge eekanna ọwọ ati ẹsẹ rẹ, ki o to lọ si jimọh.

  Eleyi jẹ ki a mọ wipe kii se asa Islam ni lati jẹ ki eekanna ọwọ ati ẹsẹ o gun kọja bi o se yẹ.

  7- IRUN JIMỌH ATI IBANISỌRỌ (KHUTBAH).

  Itumọ “Jimoh” ninu ede abinibi, ohun ni: “Akojọ”, tabi “Iparapọ”. Idi pataki ti o fi n jẹ bẹẹ ni wipe Ọlọhun pa awa musulumi l’asẹ ki a ma ko jọ, lati ki irun jimọh ni ọjọ naa.

  Irun jimọh yi jẹ ọkan pataki ninu ohun ti o yẹ ki Musulumi se ni ọjọ jimoh, nitoripe Ọlọhun ti pa asẹ ninu Alukurani wipe ti wọn ba ti pe irun jimọh, musulumi gbọdọ tete dahun, ki o si lọ ki irun naa, ki o si fi ohun ti o ba n se silẹ ni asiko naa, titi irun yo fi pari.

  Ninu ohun ti o se pataki fun musulumi lati se ni ọjọ jimọh ni ki o fi ẹti ati ara balẹ si ibanisọrọ Ọlọhun (khutbah), nitoripe khubah yi jẹ ọkan pataki ninu ohun ti islam fi p’awa lasẹ lati lọ ki irun jimọh, ki o le baa jẹ iwosan ọlọsẹ ọsẹ fun ẹmi wa, ati iran ni leti, ki a si le baa sun mọ Ọlọhun, pẹlu ki a le jina si ohun ti Ọlọhun ko fẹ.

  Ki Ọlọhun o ran wa lọwọ lati le se awọn n kan wọnyi, ki O si se e ni atẹwọgba ni ọdọ Rẹ. Amin.