Sise atunse awọn asise ti awọn Musulumi kan maa n se nipa Iranti Ọlọhun ()

Akọsilẹ yii sọ diẹ ninu awọn asise ti apa kan ninu awọn Musulumi maa n se nibi iranti Ọlọhun, gẹgẹ bii kikojọ se iranti Ọlọhun, fifi asiko tabi onka si iranti Ọlọhun eyi ti kosi ninu Shẹria Islam.

  |

  Sise atunse awọn asise ti awọn Musulumi kan maa n se nipa Iranti Ọlọhun.

  [Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Lati ọwọ:

  Dr.Mubarak Zakariya Al imam

  Atunyẹwo:

  Rafiu Adisa Bello

  Hamid Yusuf

  2015 - 1436

  تصحيح بعض المفاهيم الخاطئة

  حول ذكر الله تعالى

  « بلغة اليوربا »

  كتبها:

  د. مبارك زكريا الإمام

  مراجعة:

  رفيع أديسا بلو

  حامد يوسف

  2015 - 1436

  Sise atunse awọn asise ti awọn Musulumi maa n se nipa

  Iranti Ọlọhun.

  Ninu awọn atẹjade ti o ti siwaju, a ti se alaye ni ẹkunrere nipa iranti Ọlọhun, ti a si mu ẹnu ba itumọ rẹ, pataki ati ọla ti o wa fun un, ati anfaani iranti Ọlọhun, ati awọn ohun ti Anabi n fẹ ki a maa fi ranti Ọlọhun, ni ojoojumọ ati ni awọn asiko, aaye, ati orisirisi isẹlẹ.

  Sugbọn, ninu atẹjade yi, alaye yoo waye nipa awọn aisedeede ti awọn eniyan kan maa nse nipa iranti Ọlọhun, eleyi ti o jẹ pe o le ma jẹ ki iranti Ọlọhun ti wọn n se, ki o ni abajade ati anfaani ti o yẹ, ti o tun le sọ wọn di ẹni ẹsẹ ni ọdọ Ọlọhun.

  Ninu awọn aise-deede ti o maa n sẹlẹ ni :

  1- Iranti Ọlọhun (adhikir) ni ọna ti o wu wa: Iranti Ọlọhun kii se ohun ti a le se ni ọna ti o wu wa, gẹgẹ bi Ọlọhun ati ojisẹ rẹ se fun wa ni ilana ti a fi n kirun, ti a fi n gba aawẹ, ati bẹẹbẹẹlọ, gẹgẹ bẹẹ ni wọn se fun wa ni ilana ti a o fi maa se iranti Ọlọhun. Wọn se alaye awọn ohun ti a o maa se lati fi ranti Ọlọhun, wọn se alaye iye onka ti a o maa se -nibi eyiti o ni onka-, wọn se alaye awọn eyi ti a o maa se ni awọn orisirisi asiko ati orisirisi isẹlẹ, gẹgẹ bi a ti se alaye ninu awọn akọsilẹ ti o ti siwaju. Lati le baa mu itẹle asẹ Ọlọhun de ogongo nipa iranti Ọlọhun, a gbọdọ maa see ni ibamu si ọna ti Ọlọhun ati ojisẹ rẹ la silẹ fun wa, yala nipa asiko rẹ, abi aaye, abi ọna ti wọn fẹ ki a fi see. Eleyi ni yoo jẹ ki ẹsan wa o jẹ ọna meji ninu ijọsin: ẹsan iranti Ọlọhun, ati ẹsan ikọse Anabi ati ilana rẹ nibi iranti Ọlọhun.

  2- Ẹmi gbigbe tabi sise bii ẹniti oti n pa: Eleyi kii se ara ẹsin Islam ti Ọlọhun fi ran Anabi Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] si araye, ki a sọ ara wa, ki esu o ma gba ibi ijọsin wọle si ara wa, ti o ba yẹ ki ẹmi o gbe ẹnikan nitoripe o n se iranti pupọ, Anabi Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] ati awọn agba saabe bii Abubakar, Umar, Uthman, Alliy, ati bẹẹbẹẹlọ, awọn ni o yẹ ki ẹmi o gbe, sugbọn titi di asiko yii, kosi akọsilẹ kankan wipe ẹmi gbe ẹnikankan ninu wọn. Ibo ni awa ti ri ẹmi ti o n gbewa? Abi awa n ranti Ọlọhun ju wọn lọ ni? Abi awa sun mọ Ọlọhun ju wọn lọ ni? Kosi ki ẹmi gbe eniyan ninu iranti Ọlọhun ni ilana Islam.

  3- Kikojọ fun iranti Ọlọhun ni apapọ (jammah), ni awọn asiko ti awọn eniyan kan ti fi ẹnuko le lori, ni ọjọ jimọh lẹyin asri abi ẹyin magrib, tabi ọjọ Sunday ni aarọ abi ni irọlẹ, ati bẹẹbẹẹ lọ. Ni ododo, Islam fẹ ki a maa se iranti Ọlọhun, bakannaa ni Islam si tun gbe ọla fun nkan asepapọ ju nkan adase lọ, Sugbọn pẹlu alaye ati ondiwọn rẹ. Islam ko gba wa laaye lati se ijọsin kan ni ajọsepọ, ti ko ba jẹ wipe Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ fẹ bẹẹ, ti o si ni akọsilẹ, gẹgẹ bii Irun, Jihad, ati bẹẹbẹẹlọ. Awọn ijọsin miran n bẹ ti o jẹ ọkọọkan ni wọn fẹ ki a see, gẹgẹ bii iranti Ọlọhun. Sugbọn ko buru ki eniyan bii mẹwa o wa ninu mọsalasi, ki onikaluku o maa se iranti Ọlọhun ni aaye ti ẹnikọọkan wa, eleyi yatọ si ki gbogbo wa korajọ, ki a joko yi ara wa ka, ko si akọsilẹ fun eleyi lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun.

  4- Sise iranti Ọlọhun ni iye onka kan, ti kii se wipe Ọlọhun ati Anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) ni wọn pawa lasẹ bẹẹ: gẹgẹ bii ki Ọlọhun ati ojisẹ rẹ sọ pe ki a se iranti kan ni ẹẹmẹta, tabi ẹẹmeje, ki ẹnikan o wa maa ka ọgọrun, tabi ju bẹẹ lọ.

  5- Sise awọn nkan ni asiko ti a n se iranti Ọlọhun, ti a si gba wipe ọranyan ni ki a se bẹẹ, ti o si jẹ wipe kii se ara iranti Ọlọhun rara, gẹgẹ bii ki a tẹ asọ funfun si ilẹ, ki a lo tẹsubaa, lilo turari oloorun dundun, ati bẹẹbẹẹlọ.

  6- Gbigbe ohun s’oke fun iranti Ọlọhun, gẹgẹ bii apa kan ninu awọn Musulumi se maa n se, ti o ba ti yatọ si awọn aaye ti Ọlọhun ati ojisẹ rẹ ti fẹ ki a gbe ohun soke fun iranti Ọlọhun, gẹgẹ bii gbolohun labaika ni asiko Hajj, ati gbolohun iranti Ọlọhun ni ọjọ mẹta lẹyin ọdun ileya, irun pipe, kike Alukuraani - ti kiise ti sekarimi - ati bẹẹbẹẹlọ.

  7- Sise awọn gboloun iranti Ọlọhun atọwọda, ni awọn aaye ati asiko kan, ni eyi ti o yatọ si ohun ti Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ gbe kalẹ fun wa, gẹgẹ bii o se wa ninu awọn iwe adua orisirisi ti o n bẹ ni awujọ wa, gẹgẹ bii tira “dalailu”, “faosul-asiim” ati bẹẹbẹẹlọ.

  8- Ki a ni igbagbọ wipe ati se nkan pataki fun Ọlọhun, pẹlu iranti Ọlọhun ti a n se: Asise nla ni eleyi jẹ, Ọlọhun ko ni anfaani Kankan ti yoo gba ninu ijọsin ti a ba se, bi kose pe awa ẹda ni a ni anfaani ti o wa nibẹ. Ọlọhun sọpe :

  {Ẹnikẹni ti o ba se isẹ rere, o se e fun ara rẹ ni, bẹẹni ẹniti o ba se aburu, o see fun ara rẹ ni} [suuratu fussilat: 46].

  Kosi nkan kan ti agbara Ọlọhun Ọba wa ko ka, nitoripe alagbara ni, Oun ni o ngbọ bukaata awọn ẹda ti O da, idi niyi ti o fi jẹ wipe asise ni ki ẹda o maa ro wipe oun se anfaani fun Ọlọhun nitoripe oun se ijọsin kan tabi omiran ti Ọlọhun pa a lasẹ rẹ. Awa Musulumi si gbọdọ mọ wipe iranti ti a ba nse, a n se e lati fi jọsin fun Ọlọhun ni, kii se wipe a fi se aanu abi itọrẹ fun Ọlọhun, abi a fi se iranlọwọ fun Un.

  9- Ninu asise nla ti awọn kan ninu Musulumi maa nse ni ki a fi awọn adhikiri eyiti Anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) muwa fun wa, ki a fi silẹ, ki a wa fi omiran paarọ rẹ. Idi eleyi ni pe adhikri -iranti Ọlọhun - ọkan ninu ijọsin ni, kii se ẹtọ fun wa lati se ijọsin fun Ọlọhun ni ọna ti o wu wa. Gẹgẹ bi o se jẹ wipe a ko gbọdọ ki irun ni ọna ti o wuwa, ti a ko gbọdọ gba aawẹ tabi se Hajj ni ọna ti o wuwa, ayafi ki a se e ni ọna ti Anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) fi kọwa, toripe oun ni Ọlọhun fi ẹsin rẹ ran si araye.

  10- Ki eniyan o maa sọ awọn ede ajoji ni asiko ti o nse adhikir –iranti Ọlọhun - tabi ki o gba wipe Ọlọhun ran oun si awọn eniyan, eyi ti o maa n sẹlẹ lọdọ apakan ninu awọn Musulumi. Eleyi ni awọn Yoruba n pe ni (ẹmi).

  11- Ninu aise-deede lori agboye awọn kan ni wipe ki a gba wipe ti a ba ti n se adhikiri deede, ko si aburu kankan ti yoo sẹlẹ si wa. Ododo ni wipe -adhikiri- iranti Ọlọhun maa n jẹ okunfa isọ ati aabo Ọlọhun, gẹgẹ bi a ti sọ ninu awọn alaye ti o re kọja, sugbọn eleyi ko tumọ si wipe awọn aburu ti Ọlọhun ti kọ silẹ wipe yoo sẹlẹ siwa ko nii sẹlẹ nitoripe a n se iranti Ọlọhun deede, eleyi ko ri bẹẹ rara, ki a ma gbagbe wipe Anabi Muhammad ni ọga ninu iranti Ọlọhun, sibẹsibẹ, aburu ti Ọlọhun kọ silẹ wipe yoo sẹlẹ sii, gbogbo rẹ ni o sẹlẹ sii, ọmọ rẹ ku ni ọjọ ọdun, gbogbo awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni wọn ku ni oju aye rẹ, iyawo rẹ ku, awọn ọta se oogun asasi sii, wọn fi aburu kan ni oju ogun, ati bẹẹbẹẹlọ, sugbọn sibẹsibẹ, ojisẹ Ọlọhun ko dawọ iranti Ọlọhun duro, idi niyi ti o fi di ẹni aayo Ọlọhun, ati ẹni giga ti o yẹ ki a wo kọse.

  Awọn wọnyi ni diẹ ninu aise-deede ti awọn apa kan ninu awa Musulumi maa nse nipa iranti Ọlọhun.

  Wal-hamdu lillahi Rọbbil a’lamiin.