Siso Ahan Ati Awon Ohun Ti O Le Ran Musulumi Lowo Lori Re ()

Abdur Rasheed Adeniyi Abdur Rahuf

Pataki ahon ninu awon eya ara eniyan, siso ahan nibi awon ohun ti ko ye ki Musulumi maa fi se ati awon ohun ti o le se iranlowo fun Musulumi lati so ahan re, gbogbo awon nkan wonyi ni akosile yi gbe yewo.

  |

  SISO AHON ATI AWON OHUN TI O LE RAN MUSULUMI LOWO LORI RE

  [ Yorùbá - يوربا ]

  ABDUR RASHEED ADENIYI ABDUR RAHUF

  2013 - 1434

  حفظ اللسان والوسائل المعينة عليه

  « بلغة اليوربا »

  عبد الرشيد أدينيي عبد الرؤوف

  2013 - 1434

  SISO AHON ATI AWON OHUN TI O LE RAN MUSULUMI LOWO LORI RE

  Ope ni fun Olohun Oba Alagbara ti O fi ogo Re ati agbara Re da aye ati orun, ti O si fi omo eda eniyan se oludari ati arole lori ile aye, ti O si da awon eda eniyan dara ju gbogbo ohun miran ti O da lo, O da aworan won ti o dun n wo pelu opolo pipe ti O tun fi ke won, O si fun won ni ofin ati ilana ti won yoo maa fi lo eya ara won, ni ona ti yoo ba iyonu Oun Olohun Allah mu, O si fi awon Malaaika ti won lati maa so isesi ati isoro si won. Olohun so ni aaye kan ninu awon ese wura Al-qur'an bayi pe: ([Enikan] ko ni so gbolohun oro kan ayafi ki oluso kan ti wa pelu re) [Suuratu Koof: 18].

  Ike Olohun ati Ola Re ki o maa ba Ojise Re Anabi wa Muhammad ati awon ara ile re ati gbogbo eni ti o ba gba ise re gbo titi di ojo idajo, eniti o da majemu fun wa pe "Enikeni ti o ba le so ohun ti o wa laarin irun imu ati irun agbon re – AHON- ati ohun ti o wa laarin itan re mejeeji– ABE- emi yoo fun un ni idaniloju pe yoo wo ogba idera (Al-janna)". [Bukhari ati Muslim].

  v PATAKI AHON NINU EYA ARA ENIYAN

  Ahon je orike ti ko see fi owo ro seyin ninu eya ara, idera kan ati ike ti o tobi ni o je fun awa eniyan, lati ara ahon ni a ti nmo adun ounje, ohun naa ni a fi nsoro, awon onimimo ijinle fi ye wa pe ninu eya ara ti ko ni jera ti eda eniyan ba ku tan ni ahon je.

  Orike yi da gege bi ida oloju meji, ti eniyan ko ba ti lo o si aaye anfaani, o di dandan ki o lo o si aaye aburu, eyi ti o le se okunfa ki olowo re lo si inu ina Olohun ni orun.

  v PATAKI SISO AHON ATI ANFAANI RE

  1- Siso Ahon je okunfa iduro deede ni iwaju Olohun Allah, "Igbagbo omo eniyan ko le duro deede ayafi ki okan re duro deede, okan re ko si le duro deede ayafi ki ahon re duro deede". [Ahmad, Silsila Sohiiha]. Bakannaa Sufyaan omo Abdullah nbeere lowo Ojise Olohun -ike Olohun ati Ola Re ki o maa ba a- nipa ohun ti o le je iso fun un ti ko fi ni wo ina Jahnnama, Ojise Olohun wa so fun un pe: "So wipe: mo gba Olohun gbo, lehinnaa ki o si duro deede", o ni oun tun so pe: Iwo Ojise Olohun kinni ohun ti o n pa o laya nipa mi? Ojise Olohun si gba ahon re mu, o wa so bayi pe: "Eleyi". [Tirmidhi].

  Bakannaa ni Hadiisi Abu Uraera ti o so bayi pe: Ojise Olohun so pe: "Dajudaju omo eniyan yoo maa so gbolohun kan, ti ko nii bikita pelu re, ti oro naa yoo se okunfa ki o jin si ofin ina ti o jin ju ohun ti o wa laarin ibuyo oorun ati ibuwo oorun lo". [Muslim].

  2- Siso ahon je okunfa iyege: Atiyya omo Aamir beere lowo Ojise Olohun nipa iyege ati aseyori niwaju Olohun, Ojise Olohun si fun un ni esi pe: "So ahon re, je ki ile re o gba o laaye, ki o si maa sun ekun lori asise re". [Tirmidhi].

  3- Siso ahon yoo la awon eya ara ti o ku ninu ewu: Ojise Olohun so pe: "Ti omo Anabi Aadama ba ji ni owuro, dajudaju gbogbo awon orikerike ara re yio re ara won sile fun ahon ti won yoo si maa so fun un pe: beru Olohun nipa wa o, toripe dajudaju owo re ni gbogbo wa wa o, ti o ba duro deede, awa naa ti duro deede ni yen, ti o ba ti wo ti o te , awa naa ti wo ni yen". [Sahiihu Tirmidhiyy].

  v AWON AAYE TI ENIYAN GBODO TI SO AHON RE

  Awon ona ti eniyan gbodo ti so ahon re po repete, eko esin Islam fi ye wa pe gbogbo aaye ko ni Musulumi ododo ti gbodo maa so oro, ki o si tun maa yiri ohun ti o ba fe so wo ki o to so o, eyi ni o mu imam Nawawiy so bayi pe: O se pataki fun gbogbo eni ti o ba ti balaga, ti o si ni opolo, ti o je Musulumi, ki o maa so ahon re nibi gbogbo oro, ayafi eyi ti o ba wulo, sugbon nigbati oro siso ati didake ba ti se deede, ki a fi ara mo didake ni iru asiko yen tabi aaye yen, eleyi ni Sunna Anabi wa Muhammad -ki ike Olohun ati ola Re maa ba a.

  Ninu awon ona ti o se pataki julo lati so ahon wa niyi:

  1- IBURA PELU OHUN TI O YATO SI OLOHUN ALLAH: Ibura je okan ninu ilana ijosin ninu esin Islam, gbogbo ohun ti a ba si ti pe ni ijosin, Olohun Allah ati Ojise Re nikan lo ni eto lati se ofin ati ilana bi a se gbodo maa se e, pelu eri lati inu oro Anabi wa Muhmmad ti Bukhaari ati Muslim gba wa lati odo Umar omo Khataab- ki Olohun yonu si i- o so bayi pe: Dajudaju Ojise Olohun so pe : "Dajudaju Olohun ko fun yin lati fi awon obi yin bura, eniyowu ti o ba fe bura ki o ya fi Olohun Allah bura, tabi ki o dake". Ati Hadiisi Abu Uraerat- ki Olohun yonu si i- ti o so bayi pe: Dajudaju Ojise Olohun- ike Olohun ati ola Re ki o maa ba a- so pe: "Enikeni ti o ba bura ti o wa so pe: oun fi orisa Laata ati Uzza bura, ki iru enibee yara tun gboloun ijeri pe: ko si Olohun miran ayafi Allah (Laa ilaha illa Allah)". [Bukhari]. Eyi fi ye wa pe irufe eniyen ti di keferi.

  2- IJERI EKE: Eyi je ona kan pataki ti ahon ti maa nse suta fun olowo re ti ko ba sora, jijinna si eri eke je apeere igbagbo ododo, Olohun Allah so bayi pe: (Ati awon ti o se pe won kii jeri eke, atipe nigbati won ba re koja nibi oro buruku, won a re koja pelu aponle). [Suuratu Furkoon: 72]. Bakannaa ni Hadiisi Abu Bakri -ki Olohun yonu si i, o so wipe: Ojise Olohun so bayi pe: "E je ki nse alaye ebo ti o tobi ju fun yin", Ojise paara oro yi ni eemeta, awon omoleyin re (Saabe alaponle) so pe: "O ti ya, a fe gbo iwo Ojise Olohun, Ojise Olohun wa so bayi pe: "Mimu orogun mo Olohun, ati sise awon obi mejeeji", Ojise Olohun wa ni eniti o rogbokun tele, o wa joko daradara, o wa so pe: "E te eti yin ki e gbo o, ati Oro eke naa ati ijeri eke". Ojise Olohun bere si ni paara oro yi titi ti a fi so pe: ki o si dake (nitori a ko fe ohun ti yoo maa ko inira ba a). [Bukhari ati Muslim].

  3- EPE SISE: Epe je ikan ninu awon ese nla ti Musulumi ni lati so ahon re kuro nibe, o si tun le yo Musulumi kuro ninu awon olusipe ni ojo idajo. Hadiisi yi wa lati odo Abu Dardaa- ki Olohun yonu si i- o so wipe: Ojise Olohun so bayi pe: "Gbogbo awon ti won ba nse epe won ko ni wa ninu olusipe, bee ni won ko ni si ninu olujeri ni ojo idajo". [Muslim].

  4- IRO PIPA: Ninu awon ese nla ti ahon maa nda ni iro pipa je, ti o si maa nfa ibinu Olohun Allah. Olohun si ti se ikilo fun wa ni opolopo aaye ninu Al-qur'an, oro Olohun so pe: (Eyin Olugbagbo ododo, e beru Olohun, ki e si maa wa pelu awon olotito). [Taobah :119]. Ni aaye miran Olohun tun so pe: (Egbe ki o maa ba awon opuro ni ojo idajo). Aaya yi waye ni igba mewa ninu Suuratu Mursalaat. Eleyi nfi pataki oro naa rinle fun onilaakare eda. Hadiisi miran lori oro yi wa lati odo Abdullah omo Amru omo Aas- ki Olohun yonu si i- o so pe: Ojise Olohun so wipe: "Iwa merin kan wa, eni ti awon mereerin yi ba wa ni ara re ti di olojueji (Manaafiki) ti o daju, eniti o ba ni eyokan ninu won ti ni iwa olojueji (Manaafiki) titi ti yoo fi fi sile: Ti won ba fi okan tan yoo janba, ti o ba soro yoo paro, ti o ba se adehun yoo yapa, ti o ba ja yoo koja enu aala ododo". [Bukhari ati Muslim].

  5- ORO EYIN: Oro eyin je ohun ti a se ni eewo fun Musulumi pelu eri lati inu Al-qur'an ati Sunnah ati ifenuko awon onimimo esin, oro eyin si je okan ninu awon ese nla, idi eyi ni Olohun Allah se fi we jije eran ara eniyan ti o ti ku, Olohun- ti Ola Re ga- so bayi pe: (Apakan ninu yin ko gbodo so oro apakan leyin, abi enikan kan yin feran lati maa je eran omo iya re ti o ti ku bi? okan yin ko o). [Suuratu Hujuraat: 12].

  Anabi wa- ki ike Olohun ati ola Re maa ba a- so pe: "Mo ri awon eniyan kan nigbati mo rin irin ajo oru, eekana owo won lati ara eha oje, ti won fi n wa oju won ati aya won, mo wa beere pe tani awon wonyi? Won so pe: awon ni awon ti won maa nje eran awon eniyan leyin, ti won si maa n ba omoluabi won je pelu". [Abu Daud].

  6- OFOFO SISE: Musulumi ododo gbodo so ahon re nibi ofofo sise, nitoripe o je okan ninu awon ese nla ti o nda wahala sile ninu awujo, oro Olohun so pe: (Mase tele gbogbo awon ti won maa nbura lopolopo, eniyan yepere, apegan eda, gboyisoyi olofofo eda). [Suuratu Kolam: 10-11]. Anabi wa- ike Olohun ati ola Re ki o maa ba a– so pe: ''Olofofo ko ni wo ogba idera (Al-jannat)".[Muslim]. Bakannaa ni Ojise Olohun nre koja lo ni egbe saare kan ni ojo kan, o si n so fun awon omoleyin re pe: "Awon oku meji kan nje iya lowo bayi ninu saare won, eni akoko nje iya nitoripe kii je ki ito da tan ni ara re ti o ba nto, ti yoo si maa kan si ni ara, enikeji je olofofo". [Bukhari ati Muslim].

  v ONA WO NI A LE GBA LATI BO NINU ABURU AHON WA?

  O je oranyan fun Musulumi ododo ki o maa se ayewo ara re ki o si ni arojinle lori igbese yowu ti o ba fe gbe, ninu awon igbese ti o ye ki o se ayewo ara re nibe naa ni oro siso wa. Ni idahun si ibere ti o siwaju, oro siso ye ki o gba ori awon osunwon kan koja ki o to di siso, lati le la kuro nibi ewu ati aburu ahon. Awon osunwon naa niyi:

  Ki eniyan bi ara re ni ibeere wipe:

  · KINNI IDI TI MO FI FE SORO?

  Lati le bo ninu ewu ahon wa, o dara pupo lati mo idi pataki ti a fi fe soro, oro enu wa ye ki o je anfaani fun wa tabi fun elomiran, ki o si le ti aburu danu fun wa tabi fun elomiran.

  · AKOKO WO NI MO FE SORO?

  Nigba miran oro ti a fe so le ma mu ewu dani sugbon akoko ti a fe so oro naa le mu ewu dani ti yio si ko abuku ba oro ati eniti o so oro, Musulumi ododo gbodo mo akoko ati igba ti o ye lati soro.

  · AAYE WO NI MO TI FE SORO?

  O se pataki fun wa ki a le la kuro nibi aburu ahon wa ki a lo mo iru aaye ti a ti fe soro, nitoripe gbogbo oro ni o ni aaye tire ti o ba a mu.

  · BAWO NI ORO WA SE MAA GUN TO?

  Ninu ohun ti o maa nko olusoro si inu ewu ni opolopo igba ni ki oro re po ju asiko, aaye, tabi koko oro lo. Lati ibi siso oro pupo ju ahon le ko olusoro si inu ese ti o tobi niwaju Olohun Allah, tabi ewu lodo awon eda eniyan.

  · BAWO NI MO SE FE SO ORO NAA?

  Oro ti a fe so, akoko ti a fe so o ati aaye le dara ki akori oro naa sunwon sugbon agbekale le ko abuku ba a nigbati ko ba dara, ti yoo si pada je okunfa buru fun eni ti o soro. O se koko ki a ni agbekale ti o yanju, ki ahon wa ma baa ko wa sinu iyonu laye ati niwaju Olohun.

  v KINI AWON OHUN TI O LE RAN WA LOWO LATI SO AHON WA?

  Ninu awon ohun ti o le je iranlowo fun wa lori aburu ahon wa niyi:

  · Wiwa iso pelu Olohun ni gbogbo igba kuro nibi aburu ahon wa, gege bi isesi Anabi wa Muhammad– ike Olohun ati ola Re ki o maa ba a- se maa nse. Ojise Olohun maa nso pe: "Olohun Allah! Mo nwa iso pelu Re kuro nibi aburu igboran mi (eti mi), ati aburu iriran mi (oju mi), ati aburu ahon mi, ati aburu okan mi, ati aburu ato mi".

  · Riranti oore ati anfaani ti o wa nibi siso ahon eni lopolopo, laye ati ni ojo idajo.

  · Riranti aburu ti o ro mo ahon laarin awujo omoniyan ati niwaju Olohun, nitoripe o le se okunfa ki osunwon aburu eda wuwo ju bi o se lero lo.

  · Didake ni opolopo igba.

  · Ki a gbiyanju lati maa se iranti Olohun (Dhikir) ni gbogbo igba, pataki julo nigbati a ba wa larin awujo, ti won so oro ti ko kan wa, ti a ko si ni agbara lati fi ibe sile.

  · Ki a gbiyanju lati jinna si awon ohun ti o le se okufa ikose ati asiso fun ahon wa, gege bii: ibinu, keeta, ete, igberaga, sekagbomi, etan ati bee bee lo.

  v NI IPARI:

  Idera Olohun ni ahon je, ti o si tun je amaana (ohun ti a fun ni so) pelu, "Gbogbo yin ni adaranje, gbogbo yin ni a o si bi lere bi e ba se da eran yin je si". [Bukhari ati Muslim]. Bakannaa ni Ojise Olohun- ike Olohun ati ola Re ki o maa ba a- so wipe: "Dajudaju ninu awon eniti emi yoo feran ju ninu yin ati awon eniti won yoo sun mo mi julo ni ibujoko ni ojo idajo ni awon eniti iwa won dara julo. Ninu awon eniti emi yoo si korira won ju ninu yin ti won yoo si jinna ju si mi ni ojo idajo ni awon ti won maa nso oro pupo ju ati awon ti won maa nfa oro won gun ti o fi maa nje inira fun awon eniyan". [Tirmidhi].