Olubanisoro se alaye lekunrere ohun ti a npe ni Ojo Ikehin ati awon orisirisi oruko ti Olohun Allah fun un ninu Alukuraani, Olubanisoro si tun se alaye awon nkan ti Ojo Igbehin ko sinu.
1- Ibanisoro yii se afihan orisi ona meta ti Okan pin si, bee si ni Olubanisoro je ki a mo awon orisi arun ti o ma nse Okan. 2- Alaye ni afikun lori okan ti o nse aare ati ohun ti o je iwosan fun un. Iwosan ti o si dara julo ni nini igbagbo ti o peye ninu Olohun Allah ati mima ka Alukurani Alaponle ni gbogbo igba.
Alaye ohun ti o se okunfa ogun yii ati awon isele ti o waye nibi sise ipalemo fun ogun naa eyi ti o je eri ododo lori wipe Annabi Muhammad ojise Olohun ni. Alaye si tun waye lori aranse ti Olohun se fun ojise Re ninu ogun naa.
Waasi yi so nipa idajo Islam lori orin kiko ati gbigbo. Oniwaasi mu awon eri ti o po wa lati inu Al-kurani ati hadiisi lori bi orin gbigbo ati kiko se je eewo ninu Islam. Bakannaa ni oro waye ninu waasi yi lori awon aburu repete ti o wa nibi gbigbo orin ati kiko.