Idanilẹkọ yii da lori itumọ lọkọ-laya ati alaye awọn ohun ti o maa njẹ ki igbesi aye lọkọ-laye ni itumọ gẹgẹ bii: Ibẹru Ọlọhun Allah, Sise akiyesi adehun ti ọkunrin maa nse fun obirin nigba ti wọn ko tii gbe ara wọn wọ ile.
Itẹsiwaju ẹkunrẹrẹ alaye lori orisirisi awọn ọna ti tẹtẹ pin si, ti olubanisọrọ si jẹ ki a mọ awọn isesi ti tẹtẹ wọ ati eyi ti tẹtẹ ko wọ, pelu diẹ ninu abala ibeere ati idahun.
Ibanisọrọ ni abala yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Kinni Itumọ Tẹtẹ tita, (ii) Awọn ẹri ti o se Tẹtẹ Tita ni eewọ lati inu Alukuraani mimọ ati awọn Haadisi pẹlu apanupọ ọrọ awọn onimimọ, (iii) Awọn ewu ti nbẹ nibi tẹtẹ tita.
Olubanisọrọ se alaye awọn idajọ ẹsin ti o rọ mọ mima jẹ orukọ ẹlomiran ti o yatọ si baba ẹni, ati pipe apemọra nkan ti kii se ti ẹni (gẹgẹ bii imọ, dukia ati bẹẹ bẹẹ lọ). O si tun sọ nipa ewu ti o nbẹ nibi pipe musulumi kan ni keferi, ti wọn si kadi ibanisọrọ yii nilẹ pẹlu idahun ati ibeere.
Oniwaasi so nipa awon eto ti Islam la kale fun awon ti oku fi sile, gege bii baba, iya, oko, iyawo, omokunrin, omobinrin ati beebeelo. O si tun menu ba awon asise ti o maa nwaye lori awon eto wonyi.