معلومات المواد باللغة العربية

Sharafuddeen Gbadebọ Raji - Fonran ohun

Onka awon ohun amulo: 10

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Oludanileko : Hamid Yusuf Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    2- Alaye lori awon idajo ti o sopo mo irun Jimoh, ninu won ni: (1) Asiko wo ni irun Jimoh maa n wole. (2) Onka wo ni o ye ki o pe ki a to le ki irun Jimoh. (3) Rakah melo ni Musulumi gbodo ba ki o to le gba pe oun ba irun Jimoh. 3- Alaye lori wipe Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a maa n gbe ohun soke ni ti o ba n se khutuba ti o si maa n se khutuba ni iduro, gbogbo awon nkan wonyi ni o si maa n se okunfa ki khutuba ni ilapa lara awon ti won n gbo o. 4- Oro waye ni apa kerin yi lori Pataki yiyara lo si mosalasi ni ojo Jimoh ati Pataki titeti si Imam ni asiko khutuba, bakannaa ojuse eni ti o ba tete de mosalasi ati eni ti o pe de mosalasi nibi nafila ti a n pe ni "Tahiyyatul-masjid". 5- Oro waye ninu apa karun yi lori awon suura ti Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa n ka ninu irun Jimoh ati irun odun mejeeji pelu alaye awon eko ti o wa ninu awon suura naa, oludanileko si tun menu ba awon idajo ti o n be fun awon irun odun mejeeji ti odun ba bo si ojo Jimoh. 6- Alaye wa ninu apa kefa yi lori: (1) Nafila eyin irun Jimoh ati iye onka rakaa re. (2) Iwe fun irun Jimoh, se oranyan ni tabi kiise oranyan. (3) Awon ibeere lori oro Jimoh ati gbogbo ohun ti o ropo mo o pelu idahun lori won.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Alaye lori awọn aburu ti ọti mimu nko ba ilera ọmọniyan, owona ati eto isuna orilẹ ede ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn igun ti ọti mimu nda aburu si.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Alaye ni ẹkunrẹrẹ nipa awọn ojuse Musulumi si awọn ẹlomiran ti kii se musulumi.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    1- Alaye lori Irun Ọdun mejeeji ati awọn ofin ti o rọ mọ aaye ikirun pẹlu awọn imura ti wọn fẹ ki a mu fun Irun ọdun. 3- Idanileko ni apa yi da lori awọn ẹwa khutuba Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- ni ọjọ odun ati tita koko ọrọ lori wipe se o maa ngbe minbari lọ si aaye ikirun ni tabi wọn mọ pa si ibẹ.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Eyi ni ẹkunrẹrẹ alaye lori bi Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- se maa n ki Irun Itọrọ Ojo pẹlu sise afihan awọn orisirisi ọna ti o gba se adua lati tọrọ ojo nigba aye rẹ.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Alaye waye ninu waasi yi nipa bi Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- ti se ki irun bi osan ba di oru ni oju aye re pelu awon idajo irun yii. Oro si tun waye lori wipe oorun ati osupa ninu awon amin agbara Olohun ni won wa, won kii wo okunkun nitori iku eniyan kan tabi wiwa laaye re.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Alaye nipa ola ti o nbe fun irun pipe ati awon idajo esin ti o ro m o o, olubanisoro se alaye wipe Ojise Olohun – ike ati ola Olohun ki o maa ba a- kii pe irun tabi se ikaama fun irun odun mejeeji: odun itunu aawe ati odun ileya.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Alaye nipa awon aaye ti ko leto ki Musulumi ki irun nibe gege bii ite oku ati ile egbin.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Alaye nipa imora oniyagbe (imora ti kosi omi nibe) ati awon idajo esin ti o so mo o.

  • Yoruba

    Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    1- Idanileko yi soro nipa bi arinrin-ajo ati alaare yoo se maa ki irun won laini fi wole tabi lo o lara tayo asiko re. 2- Kiki irun rakah merin ni meji ni ori irinajo ati ki alaare fi aawe sile ninu osu Ramadan ki o si gba a pada nigbati ara re ba ya gbogbo eleyi je irorun ti Olohun se fun awa Musulumi ti O si fe ki a maa je anfaani re nitoripe irorun ni Olohun fe fun wa ninu Esin Islam. 3- Alaye ni ekunrere lori awon idajo irun onirin-ajo, igba ti yoo maa bere si din irun re ku ati asiko ti yoo fi din irun ku, bakannaa oro waye lori awon isesi onirin-ajo nipa awon irun ti yoo maa pe ati eyi ti yoo maa din ku. 4- Oro waye ninu apa kerin yi lori idajo kiki irun meji papo fun onirin-ajo ati awon ohun ti o le se okunfa kiki irun papo bakannaa fun eni ti kii se onirin-ajo. 5- Alaye nipa awon iruju ti o maa n waye lori irun arinrin-ajo ati irun alaare, bakannaa nipa pataki iranti Olohun ni gbogbo igba.