Oniwaasi so wipe awon nkan itoju arun ti Olohun se fun awa Musulumi po pupo ju ki a maa wa iranlowo nibi ohun ti o wa lodo awon keeferi ati elebo lo. O si so die ninu awon nkan iwosan naa, gege bi o ti so nipa awon eyi ti o je eewo fun Musulumi bii awon nkan ebo.
Itẹsiwaju ninu alaye nipa idajọ Sharia lori owo sise, awọn ẹkọ ti o yẹ ki onisowo se amulo rẹ. Lẹyin eyi akiyesi waye lori awọn irori kan ti o pepe si atunse nipa owo sise.
Alaye lori itumọ owo sise pẹlu apejuwe rẹ ninu igbesi aye awọn Sahabe Anọbi [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a], lẹyin eyi ni ọrọ waye nipa idajọ Sharia lori owo sise.
Itẹsiwaju ẹkunrẹrẹ alaye lori orisirisi awọn ọna ti tẹtẹ pin si, ti olubanisọrọ si jẹ ki a mọ awọn isesi ti tẹtẹ wọ ati eyi ti tẹtẹ ko wọ, pelu diẹ ninu abala ibeere ati idahun.
Ibanisọrọ ni abala yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Kinni Itumọ Tẹtẹ tita, (ii) Awọn ẹri ti o se Tẹtẹ Tita ni eewọ lati inu Alukuraani mimọ ati awọn Haadisi pẹlu apanupọ ọrọ awọn onimimọ, (iii) Awọn ewu ti nbẹ nibi tẹtẹ tita.
Apa keta ibanisoro naa so nipa idajo kiko masalaasi, bakannaa ni oro waye lori ohun ti o leto ki a se ninu mosalaasi ati awon ohun ti ko leto, leyinnaa ni idahun waye si awon ibeere.
Apa keji ibanisoro naa, olubanisoro menu ba idajo wiwo masalaasi, alaye bi onirin-ajo yoo se maa ki irun re leyin onile ati idakeji, bakannaa idajo gbigba iwaju irun koja.
Ibanisoro ti o so nipa awon majemu ti o gbodo pe si ara eni ti yoo ba wa ni ipo Imaam, yala Imaam ti inu irun ni tabi Imaam ti yoo je olori fun gbogbo Musulumi.