Yiyapa Ilana Awọn Asiwaju Ninu Ẹsin Nibi Itumọ Alukurani jẹ Okunfa Isina

Oluko : Rafiu Adisa Bello

Sise atunyewo: Hamid Yusuf

Olutẹjade:

Ọ̀rọ̀ ṣókí

Ibanisoro yi da lori bi o ti je dandan fun Musulumi lati maa tele ilana awon asiwaju ninu esin papaajulo awon omoleyin ojise Olohun (Saabe) ati awon ti won tele won (Taabi’un) nigbati o ba fe mo itumo Alukurani Alaponle.

Download
Ko idasọrọ si alamojuto oju ewe yii

Asọkun ọrọ

  Yiyapa Ilana Awọn Asiwaju ninu Ẹsin nibi Itumọ Alukurani jẹ Okunfa Isina

  [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

  Lati ọwọ:

  Rafiu Adisa Bello

  Atunyewo:

  Hamid Yusuf

  2014 - 1436

  مخالفة منهج السلف في تفسير القرآن من أسباب الضلال

  « بلغة اليوربا »

  كتبها:

  رفيع أديسا بلو

  مراجعة:

  حامد يوسف

  2014 - 1436

  Yiyapa Ilana Awọn Asiwaju Ninu Ẹsin Nibi Itumọ Alukurani jẹ Okunfa Isina

  Ninu awọn ohun ti o jẹ ojuse fun Musulumi, ti o si jẹ dandan fun un ni ki o maa tẹle ilana awọn ẹni isaaju ninu ẹsin, ki o maa rin lori ilana wọn, ki o si mase yapa si wọn. Eleyi ri bẹẹ nitoripe awọn ni asiwaju ninu ẹsin Islam papaa julọ awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun (Saabe), awọn ni sisọkale Alukurani soju wọn, awọn ni wọn si mọ bi awọn suura rẹ ati awọn aaya rẹ se sọ kalẹ, ibi ti ọkọọkan ninu wọn sọ kalẹ si, igba ti o sọ kalẹ ati idi ti o fi sọ kalẹ.

  Ni afikun, awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] wọnyi ni imọ wọn pe perepere julọ, ti isẹ ọwọ wọn si dara julọ, papaa julọ awọn ti wọn jẹ agbalagba ninu wọn, ti wọn si jẹ onimimọ.

  Awọn idi Pataki meji kan wa ti o fi jẹ wipe ilana awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun (Saabe) ni a gbọdọ gbe ara le nigbati a ba fẹ maa ka itumọ Alukurani, awọn idi mejeeji naa niyii:

  Alakọkọ: Nitoripe awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun wọnyi ni wọn ni imọ julọ nipa ede Larubaawa eyi ti o jẹ ede ti Ọlọhun Allah fi sọ tira Rẹ Alukurani kalẹ. Nitoripe Larubaawa ti o da nitọ ni wọn jẹ, awọn ni wọn si kun oju osunwọn julọ lati mọ itumọ Alukurani ati Sunna ju awọn miran ti wọn yatọ si wọn lọ. Fun idi eyi, gbogbo ọrọ ti wọn ba sọ ati isẹ ti wọn ba se ti o njẹ alaye fun Alukurani, gbogbo rẹ ni o yẹ ki a gbe ara le.

  Elẹẹkeji: Nitoripe awọn ni gbogbo awọn isẹlẹ ti o sẹlẹ nigbati Alukurani nsọ kalẹ soju wọn, awọn ni wọn si mọ awọn okunfa sisọkalẹ awọn aaya kọọkan ati suura kọọkan. Kosi iye meji nibi wipe ẹniti isẹlẹ kan ba s’oju rẹ yoo mọ nipa isẹlẹ naa ju ẹniti ko s’oju rẹ lọ.

  Ninu awọn ẹri si ohun ti a sọ yi ni ọrọ ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun ti orukọ rẹ njẹ Abdullahi ibn Mas’ud [ki Ọlọhun yọnu si i] ti o sọ wipe: “Mo fi Ọlọhun ti ko si ọlọhun miran bii iru Rẹ bura, ko si Suura Alukurani kan ti o sọ kalẹ, ti emi ko mọ ibi ti o ti sọ kalẹ, kosi si aaya kan ti o sọ kalẹ ninu Alukurani, ti emi ko mọ nitori kinni o fi sọ kalẹ, ti o ba jẹ wipe emi mọ ẹnikan ti o ni imọ nipa Alukurani ju mi lọ, ti mo si le gun rakunmi de ọdọ rẹ, emi ko ba lọ” [1].

  Bakannaa ni awọn ti wọn tẹle awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun (Taabi’un), awọn ni wọn gba Alukurani ati itumọ rẹ lati ẹnu awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun (Saabe), fun idi eyi, awọn ni wọn ni imọ nipa Alukurani naa ati itumọ rẹ julọ lẹyin awọn Saabe. Ninu awọn ti wọn tẹle awọn Saabe yi ni ẹniti orukọ rẹ njẹ Mujaaid, o maa nsọ nipa ara rẹ wipe: “Mo tọ Alukurani pẹlu Ibn Abbas ni ẹẹmẹta, mo si maa nda a duro nibi aaya kọọkan, ti emi yoo beere kinni idi ti o fi sọ kalẹ ati bawo ni o se sọ kalẹ?” [2].

  Koko ọrọ ni wipe gbogbo ẹniti o ba yẹ kuro ni ilana awọn ẹni isaaju ninu awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun (Saabe) ati awọn ti wọn tẹle wọn (Taabi’un), ti o si pa oju ọna wọn ti, ti o yapa si wọn, irufẹ ẹni bẹẹ ti se asise ti o tobi, o si ti se adadasilẹ ninu ẹsin pẹlu. Eleyi ni ọna ti o dara julọ lati fi se alaye imọ ẹsin pẹlu awọn ẹri.

  O yẹ ki o ye wa yekeyeke wipe awon Saabe ati awọn Taabi’un ati awọn ti wọn tẹle wọn, gbogbo wọn ni wọn ka Alukurani, awọn ni wọn si ni imọ nipa itumọ rẹ ati alaye rẹ julọ, bi o se jẹ wipe awọn ni wọn ni imọ julọ nipa ododo ti ojisẹ Ọlọhun [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] mu wa. Fun idi eyi, gbogbo ẹniyowu ti o ba se atako si ọrọ wọn ati ilana wọn ti o wa ntu Alukurani ni ọna ti o yapa si tiwọn, iru ẹni bẹẹ ti se asise ti o fi oju han nibi ẹri ti o ba muwa ati awọn ohun ti o nse ẹri fun.

  Asise ti o fi oju han nibi agbọye Alukurani ni o se okunfa isina fun ọpọlọpọ ninu awọn ti wọn ko sinu adadasilẹ ninu ẹsin, awọn kan ninu wọn maa ntu Alukurani ni itumọ ti o yatọ gedegede si ohun ti Ọlọhun gba ni ero lori rẹ, nitoripe wọn gbe ara le laakaye wọn lati tumọ rẹ. Awọn miran fun Alukurani ni itumọ meji, wọn a maa sọ wipe: o ni itumọ ti o han ati eyi ti o pamọ (inu ati ita), wọn si fi juujuu bo ọgọọrọ awọn eniyan ni oju. Awọn miran gbe ara le irori ati ifẹ inu wọn nibi itumọ Alukurani. Kosi ohun ti o se okunfa isina awọn Khawaarij [3] nigbati wọn kọkọ jade bi kiise aimọkan wọn nipa Alukurani ati aini agbọye itumọ rẹ. Idi niyi ti ojisẹ Ọlọhun [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] fi sọ nipa wọn wipe: “Wọn yoo ma a ka Alukurani sugbọn ko ni kọja gogongo wọn” [4]. Eyi ti o tumọ si wipe wọn ko ni gbọ itumọ rẹ ye, wọn ko si ni mọ ohun ti o je erongba Ọlọhun nibẹ; nitoripe wọn ti kuna lati rin ọna ti o tọ, ti wọn fi le ni agboye rẹ.

  [1] Bukhari: (5002), Muslim: (2463).

  [2] Al-Hilya, Abu Nu’aem: 3/279.

  [3] Awọn Khawaarij ni awọn ti wọn maa npe gbogbo Musulumi ti o ba ti da ẹsẹ kan ni Keferi, bi wọn se wa ni aye atijọ naa ni wọn wa ni asiko yi.

  [4] Bukhari: (1063).

  Àwọn ìsọ̀rí ti ìmọ̀: