Oniwaasi se afihan re wipe iyipada ko le waye laisi awon nkan wonyi: Alakoko: Agboye imo ijinle nipa esin Islam. Eleekeji: Wiwa awon imo ijinle ti awujo ni bukaata si. Eleeketa: Sise igbiyanju lati fi imo naa kede esin Islam.
Olubanisoro se alaye wipe imo nipa Olohun Allah ni eniyan maa fi n mo iyato laarin ohun ti o dara ati eyi ti ko dara, o si so wipe eniti o ba mo ohun ti o dara yato si eyi ti ko dara ni yoo le gbero ayipada ni awujo.
Ibanisọrọ yi se alaye awọn koko wọnyi: (1) Iyatọ laarin ifeto sọmọ bibi ati ifopin sọmọ bibi. (2) Awọn ẹri pe Islam se wa lojukokoro lori ọmọ bibi. (3) Itan igba ti irori fifi opin si ọmọ bibi bẹrẹ.