Akọsilẹ yii sọ diẹ ninu adisọkan awọn Suufi nipa ojisẹ Ọlọhun ati diẹ ninu adisọkan wọn nipa awọn ti a n pe ni waliyyul-lahi (Awọn ọrẹ Ọlọhun). A mu ọrọ naa wa lati inu tira “Almoosu’atul Muyassarah”.
Akosile yi so oro lori ohun ti a npe ni wiwa alubarika bi awon onimimo se se alaye re, leyinnaa o so nipa awon ipin wiwa alubarika eyi ti o pin si meji: eyi ti o leto ati eyi ti ko leto ti oro si tun waye lori awon nkan ti Olohun fi alubarika si ara won ti o si se e leto lati fi won wa alubarika.
Alaye nipa diẹ ninu awọn nkan ti o maa n se okunfa ki adadasilẹ tan kan ni awujọ gẹgẹ bii kikọlẹ awọn onimimọ lati fi ododo ẹsin mọ awọn eniyan, ati bẹẹ bẹẹ lọ
Akọsilẹ yii sọ diẹ ninu awọn asise ti apa kan ninu awọn Musulumi maa n se nibi iranti Ọlọhun, gẹgẹ bii kikojọ se iranti Ọlọhun, fifi asiko tabi onka si iranti Ọlọhun eyi ti kosi ninu Shẹria Islam.
Ibanisoro yi da lori bi o ti je dandan fun Musulumi lati maa tele ilana awon asiwaju ninu esin papaajulo awon omoleyin ojise Olohun (Saabe) ati awon ti won tele won (Taabi’un) nigbati o ba fe mo itumo Alukurani Alaponle.