Itumọ kikuro ninu ẹsin Islam (Ar-Rida). Awọn nkan ti ọmọniyan yoo se ti idajọ kikuro ninu ẹsin yoo fi sẹ le lori. Idajọ kikuro ninu ẹsin Islam (kikoomọ) ati awọn diẹ ninu ise ti eniyan le se ti yoo se okunfa kikuro ninu ẹsin Islam. Itẹsiwaju ninu alaye awọn okunfa ti o maa ngbe awọn eniyan kuro ninu
Ninu apa yii ọrọ waye lori awọn ẹri lati inu Alukuraani ti o ntọka si ododo sisẹlẹ ọjọ igbende Alukiyaamọ ati bi o se jẹ dandan ki a ni igbagbọ si ọjọ naa, ti olubanisọrọ si sọ diẹ ninu awọn amin isunmọ ọjọ yii pẹlu awon ẹri ti o gbee nilẹ.
Ọrọ waye ninu apa keji yii lori: (1) Iwọ ti o yẹ ki awa Musulumi maa pe fun awọn saabe Anabi. (2) Awọn ẹri ti o fi ẹsẹ mulẹ lori wipe ko si ede aiyede laarin awọn ara ile Anabi ati awọn Saabe yoku.
Awọn ohun ti o waye ninu apa yii: (1) Itumọ Saabe ninu ede larubawa ati wipe taani awọn Saabe gẹgẹ bi awọn onimimọ se se apejuwe wọn. (2) Ipo ati ọla ti nbẹ fun awọn Saabe pẹlu ẹri rẹ lati inu Sunna.
Itumọ aayah kẹtadinlaadọrun lati inu Suuratul Bakọrah eyi ti o da lori iroyin bi Ọlọhun Allah se se aranse fun Anọbi Isa ati bi awọn Yahuudi se tako igbedide Ojise Olohun Muhammad.
Olubanisọrọ tẹsiwaju ninu alaye awọn nkan ti o maa nse akoba fun Taoheed ninu iran Ẹbọ sise ati okunfa re, gẹgẹ bii Mima se ijọsin nibi saare oku, Gbigbẹ saare si inu mọsalaasi, Tita ẹjẹ silẹ fun nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah, Wiwa idaabobo tabi iranlọwọ lọdọ nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah. Ni akotan, wọn jẹ ki a mọ pe iru awọn nkan bayi le se akoba wiwọ Alujannah Musulumi.