[1] Asọtẹlẹ lati ọdọ Ọlọhun Allah ni sise daada si obi ẹni. [2] Alukuraani ati ẹgbawa hadisi sọ nipa pataki daada sise si awọn obi mejeeji. [3] Apẹẹrẹ oniran-nran daada ti eniyan le maa se si awọn obi rẹ. [4] Awọn ojuse ọmọ si obi pẹlu awọn apejuwe ifisisẹse rẹ lati ọdọ awọn sahabe Anọbi. [5] Awọn anfaani ti o wa nibi daada sise si awọn obi ẹni. Alaye nipa sise daada si awọn obi ẹni lẹyin ti wọn ti jade laye.
Akori ibanisọrọ da lori wipe iduro sinsin jẹ ẹmi gbogbo awọn isẹ ijọsin patapata. Idahun si awọn ibeere olowo-iye-biye nipa ibanisọrọ ti o waye lori Iduro sinsin.
Oludanilẹkọ sọ ni apa yii ọrọ awọn aafa ti wọn sọ wipe adadasilẹ sise ni ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki maa ba a) pẹlu awọn ẹri ti wọn fi rinlẹ lori awọn ọrọ wọn.