Olubanisọrọ bẹrẹ pẹlu alaye orisirisi awọn alajẹ ede ti awọn eniyan fun Ọlọhun Allah, o si tun se alaye nipa Eni ti o tọ ki a maa jọsin fun laiwa orogun pẹlu Rẹ Ohun naa ni Ọlọhun .O si tun tẹsiwaju ninu sise alaye ohun ti wọn npe ni At-Taoheed (mimọ Ọlọhun lọkan soso) ati ẹka mẹtẹẹta ti o pin si.
Olubanisoro se ni alaye lekunrere nkan ti won npe ni Sunna, o so pelu akori wipe odidi esin Islam ni Sunna atipe Sunna gan an ni esin Islam. O tesiwaju ninu alaye re wipe agboye Alkurani ko rorun fun Musulumi bikose latari Sunna, bee si ni Sunna je aayan ongbifo fun Alkurani Alaponle.