Ninu idanilẹkọ yii ọrọ waye nipa itumọ Aafa tabi Alufa ninu ede ati ni oniranran ọna ti a fi le gbọ itumọ rẹ ye, pẹlu itọka si awọn amin ti a fi le da Aafa mọ ni awujọ.
Ninu apa kinni yi: (1) Oro nipa awọn orukọ, iroyin ati awọn ẹwa ti Ọlọhun fi se iroyin Alukuraani. (2) Awọn ọla ti nbẹ fun Alukuraani. (3) Awọn ẹkọ ti o wa fun kika Alukuraani ati ọla ti nbẹ fun Olumọ Alukuraani.
Apa keji yi so nipa awon nkan wonyi: (1) Awon eko ti o dara julo ti o wa nibi ibasepo Ojise Olohun pelu awon Saabe re. (2) Sise awon Musulumi ni ojukokoro sibi kikose Ojise Olohun nibi awon iwa re fun oore aye ati orun.
Waasi yi je idahun fun awon ibeere wonyi: (1) Kinni paapaa itumo fiferan Ojise Olohun? (2) Kinni idi ti Olohun fi royin Ojise Re pelu iwa rere nibi ti O ti so wipe: {Dajudaju ire (Anabi) ni o ni iwa ti o dara julo}. (3) Tani eni ti o je dandan ki Musulumi mu ni awokose fun ara re lori gbogbo nkan?
Alaye awon nkan ti awon eniyan fi nwa Alubarika ni ona eewo ati alaye awon nkan ti Alubarika wa nibe. Bakannaa ohun ti o fa asise awon eniyan nibi wiwa Alubarika, alaye si tun waye lori awon nkan eelo ti won so wipe Annabi- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- lo nigba aye re, pelu mimu oro ti awon onimimo so nipa awon nkan wonyi wa.
Alaye lekunrere nipa itumo Alubarika ninu Ede larubawa ati ninu Shari’ah, ati oro nipa pataki Alubarika ati idajo wiwa Alubarika latara nkan tabi nibi nkan.
Olubanisoro tesiwaju pelu sise alaye awon asiko ti adua ma ngba, o si tun menuba awon nkan ti kii je ki adua gba, o wa se akotan ibanisoro re pelu awon nkan ti Yoruba ti ro po mo adua.
Ohun ti ibanisoro yi da le lori ni oro nipa adua, olubanisoro se alaye awon ohun ti a npe ni eko adua ti o tumo si awon nkan ti o maa nse okunfa gbigba adua.
Ibanisọrọ yii da lori sise aseju tabi aseeto ninu ẹsin eyi ti o wọpọ laarin awọn ọdọ, ti olubanisọrọ si jẹ ki a mọ awọn okunfa rẹ gẹgẹ bii: 1-Aini imọ ẹsin ti o kun to, 2-Agbọye odi lori ẹsin, 3-lilero aburu si awọn onimimọ, 4-Igbarata ẹsin, 5- Sisọ gbogbo nkan di Bidi’ah, 6- fifun ilẹ mọni nibiti igbalaye wa ki gbolohun pe meji nibẹ. Ni igbẹyin, olubanisọrọ jẹ ki a mọ wipe gbigba Sunnah mu nikan ni o le yọ wa nibi aseju tabi aseeto.