Idanilẹkọ yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Sise alaye ipo ti awujọ gbe obinrin si pẹlu afiwe rẹ si ipo ti Islam gbe obinrin si. (ii) Sise ni alaye abala diẹ ninu awọn ojuse obinrin musulumi si gbogbo awọn agbegbe ti o nii se pẹlu igbesi aye won.
Abala yii sọ nipa awọn ọna mẹrin ti ede-aiyede ma ngba wa laarin lọkọ-laya, oludanilẹkọ si tun se alaye awọn igbesẹ ti Islam fẹ ki a gbe nigbati ede-aiyede ba waye laarin lọkọ-laya.
Alaye ni abala akọkọ Idanilẹkọ yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Sisọ nipa pataki ati anfaani ti o wa nibi igbeyawo, (ii) Sise alaye awọn ojuse lati ọdọ ọkọ si iyawo rẹ, bẹẹ naa ni awọn ojuse lati ọdọ iyawo si ọkọ rẹ, (iii) Sise apejuwe oniranran ede-aiyede laarin lọkọ-laya.