Olohun se ipari aawe ati ojo kewa osu Dhul-hijja ni odun fun awa Musulumi. Ibani soro yi n so nipa awon eko ti Islam ko wa nipa odun aawe. Ninu re ni ki Musulumi wo aso ti o dara ti o si wuyi ni ojo odun lati gbe ojo yi laruge. Ojise Olohun si pase wipe ki gbogbo Musulumi jade lo si aaye ikirun fun odun yii.
Ibanisọrọ yi se alaye awọn koko wọnyi: (1) Iyatọ laarin ifeto sọmọ bibi ati ifopin sọmọ bibi. (2) Awọn ẹri pe Islam se wa lojukokoro lori ọmọ bibi. (3) Itan igba ti irori fifi opin si ọmọ bibi bẹrẹ.