معلومات المواد باللغة العربية

Rafiu Adisa Bello - Fonran ohun

Onka awon ohun amulo: 10

  • Yoruba

    Oludanileko : Rafiu Adisa Bello Oludanileko : Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    1- Oro lori koko ohun ti Olohun fi ran ojise Re Muhammad, iranse ni o je si gbogbo aye patapata. 2- Pelu bi o ti je wipe awon osebo fi inira kan ojise Olohun ni ilu Makka sibe sibe o tun fi aanu bawon lo ti ko si fi ibi san ibi. 3- Apejuwe lori aanu ti ojise Olohun ni fun awon eranko. Ikilo si waye lori fifi iya je awon eranko. 4- Apejuwe nipa aanu re si awon ewe tabi awon omode. 5- Apejuwe nipa aanu ojise Olohun si awon obinrin, oro si waye lori bi awon eniyan se maa nse abosi si won ni igba aimokan. 6- Awon apejuwe nipa iteriba ati iwapele ojise Olohun. Bi o ti se ni aanu awon omoleyin re ti awon naa si ni ife si i.

  • Yoruba

    Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

    Alaye waye ninu ibanisoro yi nipa awon eko ti o nbe nibi ipepe Sheikh Muhammad ibn Abdul-wahab. Oniwaasi so nipa bi o se je wipe soki ohun ti ipepe Sheikh da le lori ni mimo Olohun ni okan soso ati dida oju ko O ni Oun nikan nibi awon ijosin.

  • Yoruba

    Oludanileko : Rafiu Adisa Bello Oludanileko : Abdur-rahman Adunola Abdul-wahab Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Ibanisoro yi da lori oro nipa adiokan Imam Abu Haniifa, biotile je wipe olubanisoro menu ba adiokan awon Imaamu mereerin. Ohun ti o si se okunfa eleyi ni bi apa kan ninu awon alaimokan ni awujo se npe Imaam Abu Haniifa ni keeferi nitori awon iruju kan ti o nbe fun won nipa adiokan re. Eleyi ni oniwaasi yi se alaye re ni ekunrere, ki Olohun fi se awon Musulumi ni anfaani.

  • Yoruba

    Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

    Ibanisoro yi so ni ekunrere nipa itumo adadaale ninu esin pelu awon eri lati inu Al-kurani ati Sunna Ojise. O si se alaye ewu ti o wa nibi ki musulumi maa tele awon ti won ba n da adadaale ninu esin. Ni afikun, o tun se alaye awon majemu ti a fi maa nmo adadaale nitori awon iruju ti o wa fun awon Musulumi kan lori re.

  • Yoruba

    Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

    Ibanisoro yi so nipa itumo sunna, o si je ki a mo igba ti awon Musulumi bere si pe awon kan ni oni sunna. Ni ipari alaye tun waye lori awon apeere ti a fi maa nda awon oni sunna mo; nitoripe opolopo naa ni won maa npe ara won ni oni sunna ti won si jinna si i.

  • Yoruba

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Waasi yi so nipa idajo Islam lori orin kiko ati gbigbo. Oniwaasi mu awon eri ti o po wa lati inu Al-kurani ati hadiisi lori bi orin gbigbo ati kiko se je eewo ninu Islam. Bakannaa ni oro waye ninu waasi yi lori awon aburu repete ti o wa nibi gbigbo orin ati kiko.

  • Yoruba

    Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

    Alaye ni ekunrere wa ninu ibanisoro yi lori awon nkan ti o leto fun Musulumi lati maa lo fun idena arun ati lati wa iwosan nigbati arun ba n se e. Bakannaa ni oro tun waye lori awon oogun ti o leto fun Musulumi lati lo ti o si so awon nkan ti esin se ni eewo fun Musumi.

  • Yoruba

    Oludanileko : Abdur-rosheed Ballo Oluajo Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Awon janmoo Islam ti o wa ni awujo ni anfaani pupo, awon ni won nse itoju awon omo Musulumi ti won ko je ki opolopo won ti sina tabi di keferi, won maa nse alaye esin fun awon omode ati odo ati agbalagba, bibe won ni awujo si je amin isokan fun awa Musulumi. Sugbon apa kan ninu awon janmoo yi ni awon aleebu kookan gege bii ki a gba wipe olori janmoo ko le se asise ati wipe janmoo ti a ba wa ninu re nikan ni ona sunna ti o dara julo, irufe awon nkan yii ni olubanisoro menu ba ninu waasi yi.