Fatwa yi je idahun si ibeere ti awon Musulumi maa n beere nipa lilo awon aaya Al-kurani lati fi se iwosan, yala ki eniyan ka a ni tabi ki o han si ori nkan ti o mo ki o si fo o, leyinnaa ki o mu u.
Ibeere ti o waye ni aaye yi lo bayi pe: iko kan nso wipe: Ko leto ki a maa wa iranlowo ni odo awon anabi Olohun ati awon ore Olohun, iko miran nso wipe: o leto nitoripe ore Olohun ati aayo Re ni awon eniyan yi, ewo ninu iko mejeeji ni o wa lori ododo?
Idahun si ibeere nipa wipe irun ti won n pe ni "solaatur-rogaaibi" ati sise adayanri ojo ketadinlogbon ninu osu Rajab fun awon ijosin kan, se awon nkan wonyi ni ipile ninu esin, idahun si waye wipe adadaale ni gbogbo re je.
Idajo gbigba aawe ninu osu Rajab bi apa kan ninu awon eniyan se maa n se pelu ero wipe osu naa da yato, awon onimimo si ti se alaye wipe adadaale ni gbogbo awon nkan wonyi.