Àwọn ìsọ̀rí ti ìmọ̀

معلومات المواد باللغة العربية

Onka awon ohun amulo: 3

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Ibanisoro yi se alaye ni ekunrere awon ola ti o n be fun osu Ramadan, ninu re si ni wipe Olohun daruko osu yi ninu Al-kurani ti ko si daruko osu miran leyin re. Ninu awon ola ti Olohun se fun osu yi ni wipe Olohun yoo pa ase wipe ki won si awon ilekun ogba idera Al-janna sile ti Yoo si pa ase pe ki won ti gbogbo awon ilekun ina ti won yoo si de gbogbo awon esu mole. Olubanisoro tun so ni ekunrere oro nipa ilana ojise Olohun lori bibere aawe.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Dhikrullah Shafihi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Khutba yi so nipa oore ti o po ti Olohun se fun awa Musulumi pelu bi O ti se awon asiko kan ni adayanri fun awon ise oloore ti Musulumi yoo maa gba esan ti o po lori won. Ninu awon asiko naa si ni ojo Jimoh ati idameta oru igbeyin ati osu Ramadan.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Dhikrullah Shafihi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Khutba yi so nipa bi Musulumi yoo se mura sile fun osu Ramadan lati gba aawe nibe ati lati se awon naafila nibe. O so nipa bi awon eni isiwaju ninu esin se maa n pade osu Ramadan pelu idunnu ati ayo, ti won si maa n banuje ti o ba tan. Olubanisoro tun menu ba bi osu Shaaban se je osu imurasile ati yiye ara eni wo fun osu aawe Ramadan. O tun so nipa awon adadasile ti awon eniyan maa nse, o si so pe ki awon Musulumi jinna sii nitoripe esin ti di pipe ki ojise Olohun to fi aye sile.