Èyí, nínú ìran rẹ̀, ni àkọ́kọ́ àkànṣe iṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára, tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ, èyí tó ní àkàkún pẹ̀lú ìlànà afaraṣe Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – àti àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí ó máa ń ṣe ní ojoojúmọ́. Ó ń bá gbogbo èdè àgbáyé, èyí tó gbajúmọ̀ jùlọ sọ̀rọ̀ láti ipasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ tí à ń kà, àwọn àwòrán àti àwọn ohùn tí a gbà sílẹ̀, pẹ̀lú ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nínú àwọn nǹkan àrà-ọ̀tọ̀ tó pàtàkì.
Mó ń gbé síwájú rẹ, ìrẹ ọmọ-ìyá mi nínú ẹ̀sìn Islām, tí ó ń ka ìwé yìí; àwọn ìlànà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – tí ó máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ láti ìgbà tí ó bá ti jí, títí di ìgbà tí yóò sùn, èyí tí a tò ní ìbámu sí àsìkò wọn, lẹ́yìn náà máa fi àwọn ìlànà Ànábì mìíràn tí ó máa ń ṣe ní ojoojúmọ́, èyí tí kò ní àsìkò kan pàtó, tẹ̀lé e.
Idanilẹkọ yii da lori awọn ọna ti musulumi fi le wa isọ Ọlọhun ati aabo Rẹ gẹgẹ bii: Jijẹ eso dabidun ‘ajiwa, sise aluwala loore koore, mima ki irun Fajri ni jama’a, mima ki irun oru, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Olubanisoro tesiwaju pelu sise alaye awon asiko ti adua ma ngba, o si tun menuba awon nkan ti kii je ki adua gba, o wa se akotan ibanisoro re pelu awon nkan ti Yoruba ti ro po mo adua.
Ohun ti ibanisoro yi da le lori ni oro nipa adua, olubanisoro se alaye awon ohun ti a npe ni eko adua ti o tumo si awon nkan ti o maa nse okunfa gbigba adua.
Ibanisoro yi da lori adua ati pataki re. Adua ni ohun ti o je oranyan fun Musulumi lati maa se nigbakiigba ti o ba nfe nkan, ki o si doju adua naa ko Olohun re, ki o mase pe elomiran ayafi Oun.
1- Itumọ adua ati asikiri lati inu agbọye Alukuraani ati Sunnah pẹlu alaye lori ẹkọ adua ati asikiri ni sise. 2- Pataki adua, asiko gbigba adua ati gbogbo ohun ti o takọ ilana gbigbaa adua ni sise.
Akọsilẹ yii sọ diẹ ninu awọn asise ti apa kan ninu awọn Musulumi maa n se nibi iranti Ọlọhun, gẹgẹ bii kikojọ se iranti Ọlọhun, fifi asiko tabi onka si iranti Ọlọhun eyi ti kosi ninu Shẹria Islam.