Olubanisoro se alaye bi ojise Olohun anabi Muhammad se je ike fun gbogbo aye, Olohun lo ojise naa lati se agbega fun awon iwa rere O si loo lati pa awon iwa buburu re. Olohun si da ojise re ni eniti o pe ni eda ati ni iwa.
Ibanisoro yi da lori sise Olohun ni okan soso ati awon ipin re meteeta. Olubanisoro si se alaye ni ekunrere eyi ti o se pataki julo ninu awon ipin wonyi ti opolopo Musulumi ni asiko yi si nse asise ti o fi oju han nibe.
Waasi yi so nipa awon nkan pataki, ninu won ni: (1) Awon ona ti esu (shatani) maa ngba lati dari eniyan si ona anu. (2) Awon ohun ti esin Islam toka Musulumi si lati maa fi wa iso Olohun.
Waasi yi so nipa awon nkan kan, ninu won niyi: (1) Musulumi ni eni ti iwa daradara ti Islam pepe si ba han ni ara re. (2) Ninu ohun ti esin Islam pase re ni ki Musulumi maa se aponle gbogbo eniyan, eni ti o je Musulumi ati eni ti kiise Musulumi, ki o si maa dun won ninu.
Oniwaasi so wipe awon nkan itoju arun ti Olohun se fun awa Musulumi po pupo ju ki a maa wa iranlowo nibi ohun ti o wa lodo awon keeferi ati elebo lo. O si so die ninu awon nkan iwosan naa, gege bi o ti so nipa awon eyi ti o je eewo fun Musulumi bii awon nkan ebo.
Ibanisoro yi da lori adua ati pataki re. Adua ni ohun ti o je oranyan fun Musulumi lati maa se nigbakiigba ti o ba nfe nkan, ki o si doju adua naa ko Olohun re, ki o mase pe elomiran ayafi Oun.
Ibanisoro yi so nipa bi esin Islam se je esin ti o dasi igbesi aye eniyan patapata ti kii se nipa ohun ti o nse ninu mosalaasi nikan. Olubanisoro si menu ba itumo Islam, beenaani o so ewu ti o nbe nibi ki eniyan maa tele awon eniyan kan lori oro esin lai si eri.
Waasi yi so nipa pataki sise daradara si awon obi mejeeji ati bi Olohun ti se e ni dandan fun omo eniyan, beeni o tun se alaye esan nla ti o wa nibi ki eniyan maa se itoju won ati aburu ti o wa nibi sise aidaa si won.
Koko ohun ti ibanisoro yi da le lori ni: (1) Eto isejoba aye titun ni aburu ti yoo se fun awon ilu Musulumi, nibi eto oro-aje won ati awujo won. (2) Ohun ti oore aye ati ti orun wa nibe fun awa Musulumi ni ki a maa lo ofin Olohun nibi gbogbo ohun ti a ba n se.
Oro waye ninu waasi yi lori itumo Malaika, ohun ti a gba lero pelu ki Musulumi ni igbagbo si Malaika, awon nkan ti Olohun fi sa won lesa ati wipe orisirisi ni won je.
Waasi yi so nipa awon asigboye esin ni odo awon iran Yoruba ti won da asa won po mo esin ti o si je wipe awon asa naa tako ohun ti esin Islam mu wa. Oniwaasi si menu ba awon asa ati ise kan ti o je wipe ebo sise ni won je sibesibe ti apa kan ninu awon Musulumi si mu won wo inu esin.
Waasi yi so nipa asa ati esin Islam, olubanisoro pin asa si meji: eyi ti o dara ati eyi ti ko dara. Lehinnaa o so wipe esin Islam fi awon eniyan sile lori asa ti won nse ti o dara o si ko fun won nibi eyi ti ko dara wipe ki won fi sile.
Olubanisoro se alaye ohun ti o nje ebi, o si se alaye bakannaa bi o se ye ki eniyan maa da ebi re po. O tun se afikun anfaani ti o wa nibi ki eniyan maa da ebi po ati ijiya ti o wa nibi ki eniyan maa ja okun ibi pelu awon eri lati inu Al-kurani ati hadiisi.