Isa Akindele Solahudeen - Fonran aworan
Onka awon ohun amulo: 34
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Waasi yi so nipa awon ona iwosan ninu Islam. Oniwaasi so wipe awon aisan ti o maa nse awon eniyan pin si meji: aisan emin ati aisan ara. O si so wipe iso ti o dara julo nibi gbogbo arun naa ni iberu Olohun ati gbigbe ara le E. Lehinnaa, olubanisoro je ki a mo wipe kosi aisan ti ko ni itoju ayafi aisan ogbo. Bakannaa ni o menu ba die ninu awon nkan ti a fi maa nse itoju arun gege bii oyin, omi samsam ati beebeelo.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Olubanisoro so ninu apa keji waasi yi Pataki ki oko maa na owo le iyawo re lori, o si je ki a mo wipe ojuse ti Olohun se ni dandan fun un ni, Olohun si ti se adehun lati maa fi opolopo ropo ti o ba ti n na fun iyawo re. Bakanna ni oniwaasi so awon aleebu ti o wa lodo enikookan ninu oko ati iyawo ti o si gba won ni imoran lati fi won sile.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Ibanisoro yi da lori Ile Musulumi ati bi o se ye ki o ri. Olubanisoro so wipe ohun ti o se Pataki julo ki Musulumi mojuto ni ki o sa esa eni ti yoo fi se aya, ki obinrin Musulumi naa si sa esa eni ti yoo fi se oko. Ohun ti o si dara julo ki awon mejeeji wo naa ni esin lehinnaa iwa.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Olubanisoro tun se alaye nipa bi awon alujannu se maa nlo awon eniyan ti won ba gbe ara won si ipo eniti won yoo maa ke pe ti won yoo si maa gbe aworan won wo lati fi so awon eniyan nu. Ni ipari, olubanisoro yi so nipa awon ona ti Musulumi yoo fi maa wa iso pelu Olohun ti alujannu ati awon eni esu ti won maa nlo won ko fi le ni agbara lori wa.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Alaye ni ekunrere wa ninu ibanisoro yi nipa awon al-jannu. Bibe awon al-jannu ninu imo ikoko ti Musulumi gbodo ni igbagbo si ni, o nbe ninu awon al-jannu yi onigbagbo ododo o si nbe ninu won eni ti o ko ti Olohun ti o je keferi. Olubanisoro tun toka awon Musulumi si awon aaya ti ojise Olohun so fun wa wipe ki a maa fi wa iso.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Ibanisoro yi se alaye ni ekunrere awon ola ti o n be fun osu Ramadan, ninu re si ni wipe Olohun daruko osu yi ninu Al-kurani ti ko si daruko osu miran leyin re. Ninu awon ola ti Olohun se fun osu yi ni wipe Olohun yoo pa ase wipe ki won si awon ilekun ogba idera Al-janna sile ti Yoo si pa ase pe ki won ti gbogbo awon ilekun ina ti won yoo si de gbogbo awon esu mole. Olubanisoro tun so ni ekunrere oro nipa ilana ojise Olohun lori bibere aawe.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi soro ni ipari waasi yi o si gba awon Musulumi ni iyanju lori ki won maa moju to esin Olohun bi o ti wule ki ibaje po to ni awujo, ki won si maa be Olohun ni opolopo, ki won jinna si ebo ati awon elebo. O si se adua ni ipari waasi naa fun gbogbo Musulumi.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi soro nipa sisokale Anabi Isa omo Maryam, nigbati o ba de yoo pa agbelebu ati elede run, yoo si maa se idajo pelu deede ni ilana Anabi wa Muhammad.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi soro nipa eranko kan ti Olohun yoo mu jade si awon eniyan ti yoo si maa ba awon eniyan soro gege bii okan ninu awon apeere irole aye ti o tobi. Bakannaa ni o so nipa yiyo oorun nibi ibuwo re, o si se afikun wipe ni asiko yi ko si anfaani fun ironupiwada fun enikankan mo.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, gege bii ki awon eniyan maa se aponle okunrin kan nitori iberu aburu ise owo re. Leyinnaa o menu ba die ninu awon apeere irole aye ti o tobi, o si ka hadiisi ti Udhaefa gba wa lati odo ojise Olohun ti o so nipa awon apeere irole aye ti o tobi. Oniwaasi tun so nipa Dajjal gege bii okan ti o se Pataki ninu awon apeere irole aye ti o tobi.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o so nipa wiwa imo nitori oro aye, ati bi okunrin yoo se maa tele ase iyawo re ti yoo si maa se aburu si iya re, bakannaa bi awon eniyan yoo se maa pariwo ninu mosalaasi fun ohun ti kiise iranti Olohun.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o so nipa bi onka awon obinrin yoo se po ni awujo, bakannaa ni ki awon eniyan maa se afiti nkan si odo eni ti kii se eni ti o leto si i.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o si menu ba bi o se je wipe awon ti won je onimimo nipa oro Olohun yoo tan ni ori ile, ti iwa agbere yoo po, bakannaa ni oti mimu ati beebeelo.
- Yoruba Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello
Ibanisoro yi so nipa die ninu awon apeere ti a o fi maa mo nigbati opin aye ba n sunmo. Oniwaasi so ni ibere oro yi wipe gbigbe dide Anabi wa Muhammad je okan ninu awon apeere irole aye. Bakannaa ni oro wa lori sisokale Anabi Isa omo Maryam gege bii okan ninu awon apeere irole aye. Eyi si je akoko ninu ibanisoro yi ti o je sise-ntele.