Islam Awọn ipilẹ rẹ ati awọn ipilẹsẹ ẹkọ rẹ

Kiko iwe :

Sise ogbifo: Sharafuddeen Gbadebọ Raji

Download
Ko idasọrọ si alamojuto oju ewe yii

Asọkun ọrọ

Ninu awọn iwe ti ile isẹ -Ministiri- ti n se akoso eto ẹsin Islam, ati auqaafu, ati ipepe, ati ifinimọna tẹ jade.

ISLAM Awọn ipilẹ rẹ ati awọn ipilẹsẹ ẹkọ rẹ

Lati ọwọ:

Dr. Muhammad Ibn Abdullaah Ibn Saalih As-Suhaim

Eyi ti a tumọ si ede Yoruba lati ọwọ:

Sharafuddeen Gbadebọ Raji

Ni abẹ amojuto igbimọ t'o n se akoso eto titẹ iwe, ati titan an ka ni Ministiri yii

1427H

بسم الله الرحمن الرحيم

ỌRỌ ÀKỌSỌ

Dajudaju ti Ọlọhun ni ọpẹ i se, a n fi ọpẹ fun Un, a si n tọrọ iranlọwọ lọdọ Rẹ, a si n tọrọ aforijin lọdọ Rẹ, a si n sadi Ọlọhun Naa nibi awọn aburu ẹmi wa, ati nibi awọn aburu isẹ wa, ẹni ti Ọlọhun ba fi mọna, kò si ẹni ti o le si i lọna, ati pe ẹni ti O ba si lọna, kò si ẹni ti o le fi ọna mọ ọn, mo si n jẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun nikan, kò si orogun kan fun Un, mo si tun n jẹri pe Muhammad, ẹru Rẹ ni i, ojisẹ Rẹ si ni i pẹlu, ikẹ ati ọla Ọlọhun k'o maa ba a ni ọla ti o pọ.

Lẹyin naa, dajudaju Ọlọhun ti ran awọn ojisẹ Rẹ si awọn ẹda, nitori ki awọn eniyan o ma baa ni awijare kan lẹyin awọn ojisẹ naa; ati pe O sọ awọn tira kalẹ ni afinimọna, ikẹ, imọlẹ, ati iwosan. Ni asiko ti o ti rekọja, awọn ojisẹ naa jẹ ẹni ti a maa n ran si awọn ijọ wọn nikan, ti a si maa n fi isọ awọn tira wọn le wọn lọwọ, eyi l'o mu ki awọn akọọlẹ wọn o parẹ, o si mu ki ayipada, ati atọwọbọ, o wọ inu awọn ofin wọn, nitori pe nse ni a sọ wọn kalẹ fun ijọ kan pato, ni asiko kan ti o lonka.

Lẹyin naa ni Ọlọhun wa se adayanri Anabi Rẹ, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", nipa sise e ni ipẹkun awọn anabi, ati awọn ojisẹ. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ما كان محمد أبا أحد من رجالكم ولكن رسول الله وخاتم النبيين { [سورة الأحزاب: 40].

« Muhammad ki i se baba ẹni-kankan ninu awọn ọkunrin yin, sugbọn ojisẹ Ọlọhun ni i, ipẹkun awọn anabi si ni i pẹlu » [Suuratul Ahzaab: 40]. Ọlọhun si se apọnle rẹ pẹlu tira ti o loore ju ninu awọn tira ti a sọ kalẹ, oun ni Al-Qur'aani alapọnle, bẹẹ ni Ọlọhun t'O mọ Naa se onigbọwọ sisọ ọ, kò si fi sisọ rẹ le awọn ẹda Rẹ lọwọ rara; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إنا نحن نزلنا الذكر وإنا له لحافظون { [سورة الحجر: 9].

« Dajudaju Awa ni a sọ iranti naa kalẹ, ati pe dajudaju Awa ni Olusọ rẹ » [Suuratul-Hijr: 9]. O si se ofin rẹ ni ohun ti yoo maa bẹ titi di ọjọ igbende, Ọlọhun -mimọ ni fun Un- si se alaye pe ninu ohun ti o jẹ ọranyan sisẹku ofin rẹ ni gbigba ofin naa gbọ lododo, ati ipepe lọ sidi rẹ, ati sise suuru lori rẹ, nitori eleyii ni ilana Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati ti awọn ti n tẹle e lẹyin rẹ, se jẹ ipepe lọ si ọdọ Ọlọhun, pẹlu aridaju. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ l'Ẹni ti N se afihan ilana yii pe:

} قل هذه سبيلي أدعو إلى الله على بصيرة أنا ومن اتبعني وسبحان الله وما أنا من المشركين { [سورة يوسف: 108].

« Sọ pe: Eleyii ni oju-ọna temi, mo n pepe lọ si ọdọ Ọlọhun pẹlu aridaju, emi ati awọn ti wọn tẹle mi, mimọ ni fun Ọlọhun, emi kò si ninu awọn ti wọn pa nnkan mìíran pọ mọ Ọlọhun » [Suuratu Yuusuf :108]. O si pa a lasẹ pẹlu sise suuru lori inira ti o wa ninu ipepe lọ si oju-ọna Ọlọhun. Tori naa Ọba-giga Naa sọ pe:

} فاصبر كما صبر أولوا العزم من الرسل { [سورة الأحقاف: 35].

« Nitori naa se suuru, gẹgẹ bi awọn oni-ipinnu [ọkan] ninu awọn ojisẹ ti se suuru » [Suuratul Ahqaaf: 35], Ọba ti ẹyin Rẹ ga, tun sọ pe:

} يا أيها الذين آمنوا اصبروا وصابروا ورابطوا واتقوا الله لعلكم تفلحون { [سورة آل عمران: 200].

« Ẹyin olugbagbọ-ododo, ẹ se suuru, ẹ si maa fun ara yin ni suuru, ki ẹ si duro sinsin, ki ẹ si bẹru Ọlọhun, ki ẹ le baa se oriire » [Suuratu Aal Imraan: 200].

Mo kọ iwe yii ni lati tẹle ilana ti o jẹ ti Ọlọhun, Ọba Alapọnle yii, ati ni ipepe lọ si oju-ọna Ọlọhun, l'ẹni ti n ti ara Tira Ọlọhun wa iriran, ti i si n ti ara Sunna -ilana- Ojisẹ Rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" wa imọna. Mo si se alaye soki ninu rẹ nipa iroyin isẹda aye, isẹda eniyan, sise apọnle rẹ, ati riran awọn ojisẹ si i, ati ipo awọn ẹsin ti o ti siwaju. Lẹyin naa ni mo se afihan Islam, itumọ rẹ, ati awọn origun rẹ. Nitori naa, ẹnikẹni ti ba n wa imọna, eleyii ni awọn ẹri-ọrọ rẹ ni iwaju rẹ. Ẹnikẹni ti ba n si n wa ọla, mo ti se alaye oju-ọna rẹ fun un. Nitori naa, ẹni ti o ba fẹ lati tọ oripa awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ati awọn oluse-rere, eleyii ni ọna wọn, dajudaju ẹnikẹni ti o ba si kọ ọ ti gọ ẹmi ara rẹ, o si ti gba oju-ọna anu.

Dajudaju gbogbo awọn ẹlẹsin kan ni wọn maa n pe awọn eniyan lọ sidi rẹ, ti wọn si n maa n gbagbọ pe ibẹ ni otitọ wa, yatọ si ohun ti o yatọ si i. Bẹẹ ni gbogbo awọn ti wọn ni igbagbọ kan ni wọn maa n pe awọn eniyan lọ sidi titẹle oludasilẹ igbagbọ wọn, ati sise apọnle olori ọna wọn.

Sugbọn Musulumi, oun ki i pepe lọ sidi titẹle oju-ọna ara rẹ, nitori pe oun kò da oju-ọna kan ni funra rẹ, kò si ni nnkan kan ni ẹsin yatọ si ẹsin Ọlọhun, eyi ti O yọnu si funra Rẹ; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إن الدين عند الله الإسلام { [سورة آل عمران: 19].

« Dajudaju ẹsin ni ọdọ Ọlọhun ni Islam » [Suuratu Aala Imraan: 19]. Ati pe Musulumi ki i pepe lọ sidi sise agbega eniyan kan, tori pe gbogbo eniyan dọgba ninu ẹsin Ọlọhun, kò si iyatọ kan laarin wọn afi pẹlu ibẹru Ọlọhun, kaka bẹẹ nse ni i maa n pe awọn eniyan lọ sidi titẹle oju-ọna Oluwa wọn, ki wọn o si gba awọn ojisẹ Rẹ gbọ lododo, ki wọn o si maa tẹle ofin Rẹ ti O sọ kale fun opin awọn ojisẹ Rẹ, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ti O si pa a lasẹ pe ki o fi jisẹ fun gbogbo eniyan pata.

Nitori eleyii si ni mo se kọ iwe yii, ni ipepe lọ sidi ẹsin Ọlọhun, eyi ti O yọnu si funra Rẹ, eyi ti O si fi ran opin awọn ojisẹ Rẹ, ati ni ifinimọna fun ẹni ti o ba n fẹ imọna, ati afọnahani fun ẹni ti ba n fẹ oriire. Mo fi Ọlọhun bura pe ẹda kan kò le e ri oriire ti otitọ afi ninu ẹsin yii, ati pe ẹnikan kò ni i mọ ibalẹ-ọkan afi ẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ lododo ni oluwa, ti o si gba Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" ni ojisẹ, ti o si gba Islam ni ẹsin. Nitori naa ẹgbẹrun aimọye ninu awọn ti wọn mọna lọ sidi Islam -ni ọjọ ti o ti pẹ ati ni ode-iwoyi- ni wọn jẹri pe awọn kò mọ isẹmi otitọ afi lẹyin igba ti awọn gba Islam, bẹẹ ni awọn kò tọ oriire wo afi ni abẹ boogi Islam… Nigba ti o si jẹ pe gbogbo eniyan ni n fẹ oriire, ti i si n wa ibalẹ-ọkan, ti i si n se iwadi otitọ; ni mo se kọ iwe yii. Mo wa n tọrọ lọdọ Ọlọhun pe ki O se isẹ yii ni ohun ti a se afọmọ rẹ fun atiwa oju-rere Rẹ, ki O se e ni apepe lọ si oju-ọna Rẹ, ki O si jẹ ki o ni atẹwọgba, ki O si se e ninu awọn isẹ rere eyi ti i maa n se ẹni ti o se e ni anfaani ni aye ati lọrun.

Mo si yọnda fun gbogbo ẹni ti o ba fẹ tẹ ẹ ni ede yowu, tabi ti o fẹ tumọ rẹ si ede yowu [lati se bẹẹ], pẹlu majẹmu pe ki o jẹ ẹni ifọkantan ninu yiyi i si ede ti n tumọ rẹ si, ki o si fi ẹda kan ninu eyi ti o yi si ede mìíran sọwọ si mi, nitori atise anfaani lara rẹ, ati nitori ki iyanju naa o ma baa jẹ asetunse.

Mo si tun n tọrọ lọdọ gbogbo ẹni ti o ba ni nnkan kan lati pe akiyesi mi si, tabi atunse kan, yala ninu ipilẹ iwe yii, ti a kọ ni ede Larubawa ni o, tabi ninu eyiyowu ninu awọn ede ti a yi i pada si, ki o fi sọwọ si mi lori adirẹsi ti a se alaye rẹ nibi.

Ọpẹ ni fun Ọlọhun ni ibẹrẹ ati ni ipari, ni eyi ti o han, ati eyi ti o pamọ, ati pe tiẸ ni ọpẹ ni gbangbá, ati ni ikọkọ, bẹẹ ni tiẸ ni ọpẹ ni akọkọ, ati ni igbẹyin, Oun l'O si ni ọpẹ ti o kun awọn sanma, ti o si kun ilẹ, ati eyi ti o kun ohun ti O fẹ ni nnkan kan, Oluwa wa.

Ikẹ ati ọla Ọlọhun k'o maa ba Anabi wa Muhammad, ati awọn Sahaabe rẹ, ati ẹnikẹni ti n tọ ilana rẹ, ti n si n gba oju-ọna rẹ, ki O si se ọla naa ni ọla ti o pọ titi di ọjọ ẹsan.

Ẹni ti o kọ iwe yii

Dr. Muhammad Ibn Abdillaah Ibn Saalih As-Suhaim

Riyadh 13/10/1420H

P.O BOX 1032 Riyadh 1342

Tabi:

P.O BOX 6249 Riyadh 11442

###

NIBO NI ỌNA?

Nigba ti eniyan ba dagba, ti o si se laakaye, ọpọlọpọ awọn ibeere ni yoo maa wa si i lọpọlọ; gẹgẹ bii: Ibo ni mo ti wa? Ki l'o fa a ti mo fi wa? Ibo si ni ibupadasi mi? Ta l'o da mi, ti o si da aaye ti n bẹ ni ayika mi? Ta l'o ni ile-aye yii, ti o si n dari rẹ? Ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn ibeere.

Eniyan kò si le e da mọ idahun awọn ibeere wọnyi, koda imọ igbalode gan-an kò le e ga debi ki o le fesi lori wọn, nitori pe awọn ohun ayẹwo wọnyi wa ninu ohun ti o wọnu ọgba ẹsin, eyi l'o si mu ki iroyin o pọ, bẹẹ ni o mu ki awọn irọ ati aalọ o jẹ orisirisi nipa awọn ibeere wọnyi, eyi si n bẹ ninu ohun ti o mu ki iparagadi, ati ibẹru eniyan o lekun. Kò si le e see se fun eniyan lati ri idahun ti o tẹrun, ti o si pe fun awọn ibeere wọnyi, afi ti Ọlọhun ba fi i mọna lọ sidi ẹsin ti o ododo, eyi ti i maa n mu ọrọ ododo wa nipa awọn ibeere wọnyi ati omiran, tori pe awọn ohun ayẹwo yii wa ninu awọn nnkan ikọkọ, bẹẹ ni ẹsin ododo nikan l'o ni otitọ ati ọrọ ododo, tori pe oun nikan ni o ti ọdọ Ọlọhun wa, Ọlọhun fi i ransẹ si awọn anabi Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, eyi l'o fa a ti o fi jẹ ọranyan lori eniyan pe ki o da oju kọ ẹsin ododo, ki o si kọ nipa rẹ, ki o si gba a gbọ lododo, nitori ki idaako o le baa kuro lọrọ rẹ, ki awọn iyemeji o si le baa fi i silẹ, ki o si le baa mọna lọ si oju-ọna ti o tọ.

Mo n pe ọ ninu awọn oju ewe iwe ti n bọ wọnyi wa sidi titẹle oju-ọna Ọlọhun ti o tọ, bẹẹ ni n o fi apa kan ninu awọn ẹri-ọrọ, awijare, ati idi-ọrọ han ọ, nitori ki o le baa wo o pẹlu aise ojusaju, ati pẹlu wiwo o finnifinni, ati ifarabalẹ.

BIBẸ ỌLỌHUN, ATI JIJẸ OLUWA RẸ, ATI JIJẸ ÀÁSÓ RẸ, ATI JIJẸ ẸNI TI A GBỌDỌ JỌSIN FUN RẸ, MIMỌ NI FUN UN

Ọpọlọpọ ninu awọn eniyan ni wọn n sin awọn ọlọhun kan ti o jẹ ẹda, ohun ti a se, gẹgẹ bi igi, okuta, ati eniyan; eyi l'o mu ki awọn Yahuudi ati awọn ọsẹbọ o bi Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", nipa iroyin Ọlọhun, ati pe lati ara ki l'O ti jade? N ni Ọlọhun t'O ga ba sọ [Suura yii] kalẹ:-

} قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ. اللَّهُ الصَّمَدُ. لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ. وَلَمْ يَكُنْ لَهُ كُفُوًا أَحَدٌ {.

« Sọ pe: Oun ni Ọlọhun, Ọba Ọkan-soso. Ọlọhun ni Ọba ti a maa n ronu kan. Kò bimọ, bẹẹ ni ẹnikan kò bi I. Kò si si ẹnikan ti o jọ Ọ ». O si fi ara Rẹ mọ awọn ẹru Rẹ, O si sọ -gbigbọn-un-gbọn ni fun ẹyin Rẹ- pe:

} إن ربكم الله الذي خلق السماوات والأرض في ستة أيام ثم استوى على العرش يغشي الليل النهار يطلبه حثيثا والشمس والقمر والنجوم مسخرات بأمره ألا له الخلق والأمر تبارك الله رب العالمين { [سورة الأعراف: 54].

« Dajudaju Oluwa yin ni Ọlọhun ti O da awọn sanma ati ilẹ laarin ọjọ mẹfa, lẹyin naa ni O wa gunwa lori aga ọla [Rẹ]. O N fi oru bo ọsan mọlẹ, o si n tẹle e laiduro. O si tẹ oorun ati osupa ati awọn irawọ lori ba pẹlu asẹ Rẹ. Tẹti ki o gbọ, tiẸ ni dida ẹda ati asẹ i se, ibukun ni fun Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda » [Qur'aan, Al-A'araaf: 54]. Ọba ti O ga ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} الله الذي رفع السموات بغير عمد ترونها ثم استوى على العرش وسخر الشمس والقمر كل يجري لأجل مسمى يدبر الأمر يفصل الآيات لعلكم بلقاء ربكم توقنون. وهو الذي مد الأرض وجعل فيها رواسي وأنهاراً ومن كل الثمرات جعل فيها زوجين اثنين يغشي الليل النهار ... { [سورة الرعد: 2، 3].

« Ọlọhun ni Ẹni ti O gbe sanma ga, lai kò si òpo kan ti ẹ le ri, lẹyin naa ni O wa gunwa si ori aga ọla [Rẹ] naa, O si tẹ oorun ati osupa lori ba, onikaluku wọn n rin titi di asiko kan ti a da; O si n to eto awọn ọrọ, O si n se alaye awọn aayah naa, nitori ki ẹ le baa ni amọdaju nipa pipade Oluwa yin. Oun ni Ẹni ti O tẹ ilẹ [ni pẹrẹsẹ], O si se awọn oke sinu rẹ, ati awọn odo sisan, ati pe ninu gbogbo awọn eso O se e ni meji takọ-tabo, O N fi oru bo ọsan … » [Suuratur-Ra'ad: 2,3], titi ti O fi sọ pe:

} الله يعلم ما تحمل كل أنثى وما تغيض الأرحام وما تزداد وكل شيء عنده بمقدار. عالم الغيب والشهادة الكبير المتعال { [سورة الرعد: 8-9].

« Ọlọhun mọ ohun ti gbogbo obinrin ni ni oyun, ati ohun ti awọn apo-ibi fi din [ọjọ] ku, ati eyi ti o fi le [ọjọ] si, ati pe gbogbo nnkan l'o ni odiwọn ni ọdọ Rẹ. Oni-mimọ ikọkọ ati gbangbá, Ọba ti O tobi, Ọba ti O ga » [Suuratur-Ra'ad: 8-9]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} قل من رب السموات والأرض قل الله قل أفاتخذتم من دونه أولياء لا يملكون لأنفسهم نفعاً ولا ضراً قل هل يستوي الأعمى والبصير أم هل تستوي الظلمات والنور أم جعلوا لله شركاء خلقوا كخلقه فتشابه الخلق عليهم قل الله خالق كل شيء وهو الواحد القهار { [سورة الرعد: 16].

« Sọ pe: Ta ni Oluwa awọn sanma ati ilẹ? Sọ pe: Ọlọhun ni I. Sọ pe: Njẹ ẹyin wa le mu awọn alafẹyinti kan lẹyin Rẹ ti wọn kò ni ikapa anfaani kan tabi ipalara kan fun ori ara wọn. Sọ pe: Njẹ afọju wa le dọgba pẹlu ẹni ti o riran bi? Tabi okunkun ati imọlẹ wa le dọgba bi? Tabi wọn wa orogun fun Ọlọhun ti awọn naa sẹda bii ẹda Rẹ debi wi pe awọn ẹda naa jọra wọn ni oju wọn bi? Sọ pe: Ọlọhun ni Ẹlẹda gbogbo nnkan, Oun si ni Ọba Àásó, Olubori » [Suuratur-Ra'ad: 16]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- si se awọn aayah Rẹ ni ẹlẹri, ati arisami fun wọn, O si sọ pe:

} ومن آياته الليل والنهار والشمس والقمر لا تسجدوا للشمس ولا للقمر واسجدوا لله الذي خلقهن إن كنتم إياه تعبدون. فإن استكبروا فالذين عند ربك يسبحون له بالليل والنهار وهم لا يسأمون. ومن آياته أنك ترى الأرض خاشعة فإذا أنزلنا عليها الماء اهتزت وربت إن الذي أحياها لمحيي الموتى إنه على كل شيء قدير { [سورة فصلت: 37-39].

« Ati pe ninu awọn ami Rẹ ni oru ati ọsan, oorun ati osupa, Ẹ ma se fi ori kanlẹ fun oorun tabi osupa, Ọlọhun ti O se ẹda wọn ni ki ẹ maa fi ori kanlẹ fun, ti ẹyin ba jẹ pe Oun nikan ni ẹ n jọsin fun. Nitori naa ti wọn ba se igberaga, awọn ti wọn wa ni ọdọ Oluwa rẹ n se afọmọ fun Un ni oru ati lọsan, ati pe awọn ki i kagara. O si n bẹ ninu awọn ami Rẹ pe dajudaju iwọ yoo ri ilẹ ti o gbẹ haran-un, nigba ti A ba si sọ omi kalẹ le e lori yoo mira, yoo si ru. Dajudaju Ẹni ti O ji i ni Ẹni ti O daju pe yoo ji awọn oku dide. Dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan» [Suuratu Fusilat: 37-39]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ pe:

} ومن آياته خلق السموات والأرض واختلاف ألسنتكم وألوانكم إن في ذلك لآيات للعالمين. ومن آياته منامكم بالليل والنهار { [سورة الروم، الآية: 22، 23].

« Ati pe ninu awọn ami Rẹ ni dida awọn sanma ati ilẹ, ati iyatọ sira wọn awọn ahọn [ede] yin, ati awọn awọ yin, dajudaju awọn ami n bẹ ninu eleyii fun awọn oni-mimọ. Bẹẹ ni o n bẹ ninu awọn ami Rẹ oorun yin ni oru ati lọsan » [Qur'aan, Al-Ruum: 22, 23].

Ati pe O royin ara Rẹ pẹlu awọn iroyin ẹwa ati pipe, O si sọ -giga ni fun Un- pe:

} الله لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لاَ تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلاَ نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي اْلأَرْض مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلاَّ بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيْهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلاَ يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلاَّ بِمَا شَاءَ ... { [سورة البقرة: 255].

« Allaahu -Ọlọhun- kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si I, Alaaye, Oludawa, ki I toogbe, bẹẹ ni ki I sun rara. TiẸ ni gbogbo ohun t'o wa ni sanma ati ohun t'o wa nilẹ. Ẹnikan kò ni i le sipẹ ni ọdọ Rẹ, afi pẹlu iyọnda Rẹ. O mọ ohun ti n bẹ niwaju wọn ati ohun ti o wa lẹyin wọn, ati pe wọn kò ni i le rọkirika nnkan kan ninu imọ Rẹ afi ohun t'O ba fẹ … » [Suuratul-Baqarah: 255]. Ọlọhun ti O ga tun sọ pe:

} غافر الذنب وقابل التوب شديد العقاب ذي الطَّوْل لا إله إلا هو إليه المصير { [سورة غافر: 3].

« Oluse-aforijin ẹsẹ, Olugba ironupiwada, Olule ni iya-ẹsẹ, Ọlọrẹ, kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si I, ọdọ Rẹ ni ibupadasi » [Suuratu Gaafir: 3]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn Naa, tun sọ pe:

} هو الله الذي لا إله إلا هو الملك القدوس السلام المؤمن المهيمن العزيز الجبار المتكبر سبحان الله عما يشركون { [سورة الحشر: 23].

« Oun ni Ọlọhun, Ẹni ti kò si ọba kan ti o tọ lati sin lododo yatọ si I, Ọba -Alakoso-, Ẹni-mimọ, Olumọ kuro ninu gbogbo alebu, Ẹlẹri-ododo [fun awọn ojisẹ Rẹ], Oluri gbogbo nnkan, Alagbara, Olujẹni-n-pa, Oni-Moto-Moto, mimọ ni fun Ọlọhun kuro nibi ohun ti wọn fi n se orogun fun Un » [Suuratul Hashr: 23].

Oluwa, Ọlọhun ti a jọsin fun, Ọba Ọlọgbọn, Alagbara, Ẹni ti O fi ara Rẹ mọ awọn ẹru Rẹ yii, ti O si fi awọn aayah Rẹ se awọn ẹlẹri, ati awọn ami fun wọn, ti O si royin ara Rẹ pẹlu awọn iroyin pipe; awọn ofin Sharia ti awọn anabi, ati ohun ti jẹ dandan fun laakaye lati gba, ati adamọ ẹda [gbogbo wọn] tọka si bibẹ Rẹ, ati jijẹ oluwa Rẹ, ati jijẹ ọba ti a jọsin fun Rẹ; ati pe ẹnu gbogbo ijọ l'o ko lori eleyii. N o si se alaye apa kan ninu eleyii fun ọ ninu ohun ti n bọ yii:

Awọn ẹri bibẹ Rẹ ati jijẹ oluwa Rẹ ni:-

1- Sise ẹda aye yii, ati ohun ti n bẹ ninu rẹ, ninu awọn ẹda ti o ya'ni lẹnu:

Irẹ eniyan, aye nla yii rọkirika rẹ, o si kojọ lati ara awọn sanma, ati awọn irawọ, ati awọn oju-ọna ti awọn irawọ n gba, ati ilẹ ti a tẹ pẹrẹsẹ, eyi ti awọn ilẹ ti o fi ẹgbẹ kora wọn n bẹ ninu rẹ, ti ohun ti kaluku wọn n mu jade ni irugbin yatọ sira wọn ni bi awọn ilẹ naa ti se yatọ sira wọn, ati pe gbogbo irugbin l'o wa ninu rẹ, bẹẹ ni o ri orisi meji ninu gbogbo ẹda: akọ ati abo… tori naa aye yii kọ l'o sẹda ara rẹ, ati pe lai se aniani dandan ni ki o ni ẹlẹda kan, nitori pe kò see se pe ki o da ara rẹ. Tori naa ta l'o da a lori eto iyanu yii? Ti o si pe e ni pipe ti o dara yii? Ti o si se e ni ohun amusami fun awọn ti n wo o? Ta ni -i ba jẹ- yatọ si Ọlọhun, Ọba Àásó, Olubori, Ẹni ti kò si Oluwa kan yatọ si I, ti kò si si ọba kan ti o tọ lati jọsin fun lododo lẹyin Rẹ; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} أم خلقوا من غير شيء أم هم الخالقون. أم خلقوا السموات والأرض بل لا يوقنون { [سورة الطور: 35، 36].

« Abi a da wọn lati ibi asan bi? Tabi awọn ni olusẹda [ara wọn]?. Abi awọn ni wọn da awọn sanma ati ilẹ ni?. Bẹẹ kọ, wọn kò mọ amọdaju ni » [Suuratu Tuur: 35-36]. Nitori naa aayah yii se akojọpọ awọn itisiwaju mẹta ti i se:

1- Njẹ lati ara asan ni a ti se ẹda wọn bi?.

2- Njẹ awọn wa l'o da ara wọn bi?.

3- Njẹ awọn wa l'o da awọn sanma ati ilẹ bi?.

Nitori naa ti ki i ba ti se pe lati ara asan ni a ti da wọn, ti ki i si i se pe awọn ni o da ara wọn, ti wọn kò si se ẹda awọn sanma ati ilẹ; o daju pe o di dandan ki wọn o gba pe Ẹlẹda kan N bẹ, ti O da awọn, ti O si da awọn sanma ati ilẹ, Oun ni Ọlọhun, Ọba Àásó, Olubori.

2- Adamọ:

A se adamọ awọn ẹda lori gbigba pe Ẹlẹda wa, ati lori pe dajudaju Oun l'O gbọn-un-gbọn ju, ti O si tobi ju, ti O si ninla ju, ti O si pe ju gbogbo nnkan lọ. Ohun ti o si fi ẹsẹ rinlẹ gbọn-in-gbọn-in ninu adamọ ni eleyii i se ni rinrinlẹ ti o ni agbara ju ti awọn ipilẹsẹ ẹkọ imọ isiro lọ. Bẹẹ ni eleyii kò bukaata ki a mu ẹri wa fun un rara, afi fun ẹni ti adamọ tiẹ ba ti yipada, ti awọn isẹlẹ kan ti o le mu un sẹri kuro nibi ohun ti o gba -pe n bẹ- ba sẹlẹ si i. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} فطرت الله التي فطر الناس عليها لا تبديل لخلق الله ذلك الدين القيم { [سورة الروم: 30].

« Adamọ Ọlọhun eyi ti O pilẹ da awọn eniyan le lori, kò si ayipada kan fun ẹda Ọlọhun, eyi ni ẹsin ti o duro sinsisn » [Suuratur-Ruum: 30]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" naa sọ pe:

(( ما من مولود إلا يولد على الفطرة، فأبواه يهودانه، أو ينصرانه، أو يمجسانه، كما تنتج البهيمة بهيمة جمعاء، هل تحسون فيها من جدعاء؟ ثم قرأ: } فطرت الله الذي فطر الناس عليها لا تبديل لخلق الله { )). [رواه البخاري، ومسلم].

« Kò si ọmọ kan ti a bi afi ki o se pe ori adamọ [Islam] ni a bi i si, nitori naa awọn obi rẹ mejeeji ni wọn yoo sọ ọ di Yahuudi -Ju- tabi alagbelebu -Christian- tabi olubọ-ina, gẹgẹ bi ẹran ti i maa n bi ọmọ ti kò ni alebu kan lara, njẹ ẹ wa ri ọkan ti o ge ni orike ninu wọn bi? lẹyin naa ni o wa ka: [ọrọ Ọlọhun t'o ni]: “Adamọ Ọlọhun eyi ti O pilẹ da awọn eniyan le lori, kò si ayipada kan fun ẹda Ọlọhun" » [Bukhari ati Muslim ni wọn gbe e jade]. Bakan naa Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", tun sọ pe:

(( ألا إن ربي أمرني أن أعلمكم ما جهلتم مما علمني يومي هذا: كل ما نحلته عبداً حلال، وإني خلقت عبادي حنفاء كلهم، وإنهم أتتهم الشياطين فاجتالتهم عن دينهم، وحرمت عليهم ما أحللت لهم، وأمرتـهم أن يشركوا بـي ما لم أنزل به سلطاناً )). [رواه أحمد، ومسلم واللفظ له].

« Ẹ tẹti ẹ gbọ, dajudaju Oluwa mi pa mi lasẹ pe ki n fi ohun ti ẹ kò mọ ninu ohun ti O fi mọ mi ni ọjọ oni mi yii mọ yin: Ẹtọ ni gbogbo ohun ti mo fi ta ẹru Mi kan lọrẹ, dajudaju Emi si da awọn ẹru Mi nigba ti gbogbo wọn jẹ ẹni ti awọn orike rẹ mọ kuro ninu awọn ẹsẹ, ati pe awọn esu wa ba wọn, n ni wọn ba da wọn kuro nidi ẹsin wọn, wọn si se ohun ti Mo se ni ẹtọ fun wọn leewọ, wọn si pa wọn lasẹ ki wọn o maa se ẹbọ si Mi pẹlu ohun ti N kò sọ awijare kan kalẹ nipa rẹ ». [Ahmad ati Muslim ni wọn gbe e jade].

3- Ipanupọ awọn eniyan:

Ẹnu awọn eniyan ko -tẹlẹtẹlẹ ati nisinyi- pe aye yii ni Ẹlẹda kan, Oun si ni Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda, ati pe dajudaju Oun ni Ẹlẹda awọn sanma ati ilẹ, kò si orogun kan fun Un ninu dida ẹda Rẹ, gẹgẹ bi kò ti se ni orogun kan ninu akoso Rẹ -mimọ ni fun Un-.

A kò si ri i gba wa lati ọdọ ijọ kan ninu awọn ijọ ti o ti rekọja pe wọn ni adisọkan pe awọn ọlọhun awọn pẹlu Ọlọhun Ọba ninu sisẹda awọn sanma ati ilẹ, bẹẹ kọ, nse ni wọn ni adisọkan pe Ọlọhun ni Ẹlẹda wọn, Oun si ni Ẹlẹda awọn ọlọhun wọn, nitori naa kò si ẹlẹda kan tabi olurọnilọrọ kan ti o yato si I, ati pe ọwọ Rẹ ni anfaani ati inira wa -mimọ ni fun Un-. Ọlọhun t'O ga sọ l'Ẹni ti N fun'ni niro nipa gbigba ti awọn ọsẹbọ gba jijẹ oluwa Rẹ, pe:

} ولئن سألتهم من خلق السموات والأرص وسخر الشمس والقمر ليقولن الله فأنى يؤفكون. الله يبسط الرزق لمن يشاء من عباده ويقدر له إن الله بكل شيء عليم. ولئن سألتهم من نزَّل من السماء ماء فأحيا به الأرض من بعد موتها ليقولن الله قل الحمد لله بل أكثرهم لا يعقلون { [سورة العنكبوت: 61-63].

« Ati pe dajudaju ti iwọ ba bi wọn leere pe: Ta l'o da awọn sanma ati ilẹ, ti o si tẹ oorun ati osupa ni ori ba [fun yin]? Dajudaju wọn o sọ pe: Ọlọhun ni I; njẹ ibo ni wọn n sẹri lọ?. Ọlọhun A maa gba ọrọ -arziki- laye fun ẹni ti O ba wu ﷻ‬ ninu awọn ẹru Rẹ, A si maa diwọn rẹ fun un, dajudaju Olumọ ni Ọlọhun nipa gbogbo nnkan. Dajudaju ti iwọ ba tun bi wọn leere pe: Ta ni n sọ ojo kalẹ lati sanma ti n fi n sọ ilẹ ji lẹyin kiku rẹ? Dajudaju wọn o sọ pe: Ọlọhun ni I. Ọpẹ ni fun Ọlọhun, bẹẹ kọ, ọpọlọpọ wọn ni kò ni laakaye » [Suuratul Ankabuut: 61-63].

Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn Naa, tun sọ pe:

} ولئن سألتهم من خلق السموات والأرض ليقولن خلقهن العزيز العليم { [سورة الزخرف: 9].

« Ati pe dajudaju ti o ba bi wọn leere pe: Ta l'o da awọn sanma ati ilẹ? Dajudaju wọn o sọ pe: Ọba Alagbara, Ọba Oni-imọ, l'O da wọn » [Suuratuz-Zukhruf: 9].

4- Ohun ti o pa dandan fun laakaye lati gba:

Kò si aniani kan fun awọn laakaye lati gba pe dajudaju aye yii ni ẹlẹda kan ti o tobi, nitori pe laakaye ri pe ohun ti a da ti n si n bẹ lẹyin aisi tẹlẹ ni aye, ohun kọ l'o si mu ara rẹ maa bẹ, bẹẹ ni dandan ni ki gbogbo ohun ti n bẹ lẹyin aisi o ni ẹni ti o mu un maa bẹ.

Ati pe eniyan mọ daju pe awọn isoro ati adanwo yoo maa sẹlẹ si oun, nigba ti eniyan kò ba si ni agbara lati ti i kuro, dajudaju yoo da oju ọkan rẹ kọ sanma, yoo si maa ke gbajare lọ si ọdọ Oluwa rẹ, lati sipaya idaamu rẹ, ki O si mu ibanujẹ rẹ kuro, koda ki o se pe abọrisa ti o si n kọ bibẹ Oluwa rẹ ni awọn ọjọ rẹ yoku ni i; nnkan tulaasi ti kò see ti danu ni eleyii, ati pe dandan ni gbigba a, bẹẹ tilẹ kọ, dajudaju ti adanwo ba se ẹranko gan-an alara a maa gbe ori rẹ soke, yoo si fẹ oju rẹ si sanma. Dajudaju Ọlọhun si ti fun'ni niro nipa eniyan pe ti inira ba se e, a maa yara lọ si ọdọ Oluwa rẹ, ti yoo si maa tọrọ lọdọ Rẹ pe ki O mu inira oun kuro; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وإذا مس الإنسان ضر دعا ربه منيباً إليه ثم إذا خوَّله نعمة منه نسي ما كان يدعو إليه من قبل وجعل لله أنداداً { [سورة الزمر: 8].

« Ati pe nigba ti inira kan ba fi ọwọ kan eniyan, yoo ke pe Oluwa rẹ ni ẹni ti o sẹri si ọdọ Rẹ, lẹyin naa nigba ti O ba se idẹkun fun un lati ọdọ Rẹ, yoo gbagbe ohun ti n pe tẹlẹ, yoo si wa awọn orogun fun Ọlọhun » [Suuratuz-Zumar: 8]. Ọlọhun t'O ga tun sọ l'Ẹni ti N fun'ni niro nipa ipo awọn ọsẹbọ pe:

} هو الذي يسيركم في البر والبحر حتى إذا كنتم في الفلك وجرين بهم بريح طيبة وفرحوا بها جاءتها ريح عاصف وجاءهم الموج من كل مكان وظنوا أنهم أحيط بهم دعوا الله مخلصين له الدين لئن أنجيتنا من هذه لنكونن من الشاكرين. فلما أنجاهم إذا هم يبغون في الأرض بغير الحق يا أيها الناس إنما بغيكم على أنفسكم متاع الحياة الدنيا ثم إلينا مرجعكم فننبئكم بما كنتم تعملون { [سورة يونس: 22-23].

« Oun ni Ẹni ti N mu yin rin lori ilẹ ati ni ori okun, titi igba ti ẹyin ba n bẹ ninu ọkọ oju-omi, ti o si n gbe wọn sare pẹlu atẹgun ti o dara, ti wọn si n dunnu si i, n ni atẹgun iji ba wa ba ọkọ naa, igbi odo naa si yi wọn ka, wọn si ro pe a ti yi wọn ka, wọn o maa ke pe Ọlọhun, l'ẹni ti n se afọmọ ẹsin fun Un pe: Dajudaju ti O ba la wa ninu eleyii, dajudaju a o maa bẹ ninu awọn oludupẹ. Sugbọn lẹyin ti O la wọn tan, nigba naa ni wọn o maa se afojudi ni ori ilẹ lai jẹ pẹlu ododo. Ẹyin eniyan, dajudaju ori ara yin ni ẹ n wu iwa afojudi yin fun, igbadun igbesi-aye [diẹ ni i], lẹyin naa ọdọ Wa ni ipadasi yin, A o si fun yin niro nipa ohun ti ẹ se nisẹ » [Suuratu Yuunus: 22-23]. Ọba ti O ga ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} وإذا غشيهم موج كالظلل دعوا الله مخلصين له الدين فلما نجاهم إلى البر فمنهم مقتصد وما يجحد بآيتنا إلا كل ختار كفور { [سورة لقمان: 32].

« Ati pe nigba ti igbi [omi] ba bo wọn gẹgẹ bi iji, wọn o maa ke pe Ọlọhun, l'ẹni ti n se afọmọ ẹsin naa fun Un, nigba ti O ba si ko wọ la si ori ilẹ, awọn oluse-dọgba yoo bẹẹ ninu wọn, ati pe ẹnikan ki i tako awọn aayah Wa afi gbogbo oni-jamba, alaigbagbọ » [Suuratu Luqmaan: 32].

Ọlọhun ti O mu ile-aye yii maa bẹ nigba ti kò jẹ nnkan kan, ti O si da eniyan si ori eyi ti o dara ju ninu didọgba, ti O si fun ijọsin fun Un ati igbafa fun Un ni agbara ninu adamọ rẹ; ti awọn laakaye si gba fun jijẹ oluwa Rẹ, ati jijẹ ọlọhun ti a jọsin fun Rẹ, ti ẹnu awọn ijọ si ko lori gbigba fun jijẹ oluwa Rẹ, kò si aniani pe o gbọdọ jẹ ọkan soso ninu jijẹ oluwa, ati jijẹ ọlọhun ti a jọsin fun, ati pe gẹgẹ bi kò ti si orogun kan fun Un ninu dida ẹda, ni kò ti se ni orogun kan ninu jijẹ ọlọhun ti a jọsin fun. Bẹẹ ni awọn ẹri-ọrọ pọ lori eleyii.

Ninu awọn ẹri ailorogun Ọlọhun ninu jijẹ ọlọhun ni pe:-

1- Kò si ọlọhun kan ninu aye yii yatọ si Ọlọhun, Ọba kan soso, Oun ni Ẹlẹda, Olurọnilọrọ, ẹnikan kò si le fa oore wa, kò si le ti inira danu yatọ si I, iba wa se pe ọlọhun mìíran wa ni aye yii ni, oun naa i ba ni isẹ, isẹda, ati asẹ, ati pe ẹnikan ninu awọn mejeeji kò ni i gba pe ki ọlọhun mìíran o ba oun se orogun; bẹẹ ni dandan ni ki ọkan ninu wọn o bori ekeji, ki o si sẹgun rẹ, ẹni ti a bori kò si le jẹ Ọlọhun rara, ati pe ẹni ti o bori ni Ọlọhun Otitọ, ti ọlọhun kan kò le e jẹ orogun fun Un ninu jijẹ ọba ti a jọsin fun, gẹgẹ bi ọlọhun kan kò ti baa se orogun ninu jijẹ oluwa. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ما اتخذ الله من ولد وما كان معه من إله إذاً لذهب كل إله بما خلق ولعلا بعضهم على بعض سبحان الله عما يصفون { [سورة المؤمنون: 91].

« Ọlọhun kò mu ẹnikan ni ọmọ, ati pe kò si ọlọhun kan pẹlu Rẹ, ti o ba jẹ bẹẹ ni i, ọlọhun kọọkan o ba ti mu ẹda rẹ lọ, apa kan wọn o ba si ti bori ekeji. Mimọ Ọlọhun ju ohun ti wọn n royin lọ » [Suuratul Mu'uminuun: 91].

2- Ẹnikan kò ni ẹtọ si ijọsin yatọ si Ọlọhun, Ẹni ti O ni ikapa awọn sanma ati ilẹ, nitori pe eniyan a maa wa atisunmọ Ọlọhun ti yoo maa fa anfaani wa fun un, ti yoo si maa ti inira danu kuro ni ọdọ rẹ, ti yoo si maa sẹri aburu ati adanwo kuro ni ọdọ rẹ, bẹẹ ni ẹnikan kò le e se awọn nnkan wọnyi yatọ si Ẹni ti O ni ikapa awọn sanma ati ilẹ ati ohun ti n bẹ laarin mejeeji, ati pe ti o ba jẹ pe awọn ọlọhun kan n bẹ pẹlu Rẹ ni, bii awọn ọsẹbọ ti se n sọ, dajudaju nse ni awọn ẹrusin Ọlọhun o ba mu ọna ti yoo mu wọn lọ sibi ijọsin fun Ọlọhun, Ọba Ododo pọn, nitori pe gbogbo awọn ohun ti wọn n sin lẹyin Ọlọhun wọnyi kò jọsin fun nnkan kan t'o yatọ si Ọlọhun, wọn si n wa atisunmọ ỌN, nitori naa ohun ti o tọ ju fun ẹni ti o fẹ lati sunmọ Ẹni ti anfaani ati inira wa lọwọ Rẹ ni pe ki o maa jọsin fun Ọba Otitọ, Ẹni ti awọn ti wọn wa ninu sanma ati ori ilẹ -titi ti o fi dori awọn ọlọhun ti wọn n sin lẹyin ọlọhun yii- n jọsin fun. Ọlọhun, Ọba t'O ga, sọ pe:

} قل لو كان معه آلهة كما يقولون إذاً لابتغوا إلى ذي العرش سبيلاً { [سورة الإسراء: 42].

« Sọ pe: Ti o ba se pe awọn ọlọhun kan n bẹ pẹlu Rẹ ni, gẹgẹ bi wọn ti n wi, nigba naa wọn o ba ti wa oju-ọna kan lọ si ọdọ Ọba Alaga-ọla » [Suuratul Israa': 42]. Ki ẹni ti n fẹ ododo o si ka ọrọ Ọlọhun t'O ga, t'o ni:

} قل ادعوا الذين زعمتم من دون الله لا يملكون مثقال ذرة في السموات ولا في الأرض وما لهم فيهما من شرك وما له منهم من ظهير. ولا تنفع الشفاعة عنده إلا لمن أذن له { [سورة سبأ: 22، 23].

« Sọ pe: Ẹ pe awọn ti ẹ n pe [ni awọn ọlọhun] lẹyin Ọlọhun Ọba; wọn kò ni odiwọn ọmọ-inaagun kan [loore tabi aburu] ninu awọn sanma, bẹẹ ni wọn kò ni in nilẹ, ati pe wọn kò ni ipin kankan ninu mejeeji, bẹẹ ni kò si oluranlọwọ kan fun Ọlọhun ninu wọn rara. Ati pe ipẹ sise kò ni i sanfaani lọdọ Rẹ afi ti ẹni t'O ba yọnda fun ... » [Suuratu Saba'i: 22-23]. Nitori naa awọn aayah wọnyi a maa ja rirọ ọkan mọ ẹlomiran ti o yatọ si Ọlọhun pẹlu nnkan mẹrin kan ti o lọ bayii:-

Alakọkọ ni pe: Awọn [ti wọn fi se] orogun [fun Ọlọhun] wọnyi kò ni odiwọn ọmọ-inaagun kan pẹlu Ọlọhun, bẹẹ ni ẹni ti kò ni odiwọn ọmọ-inaagun kan kò le e se'ni lanfaani, kò si le e ni'ni lara, ati pe kò lẹtọ si ki o jẹ ọlọhun, tabi orogun fun Ọlọhun, Ọlọhun si ni Ẹni ti O ni wọn, ti O si n dari wọn ni Oun nikan.

Ẹlẹẹkeji ni pe: Dajudaju wọn kò ni nnkan kan ninu awọn sanma ati ilẹ, ati pe wọn kò ni odiwọn ọmọ-inaagun kan ni ohun ajọni kan ninu mejeeji.

Ẹlẹẹkẹta ni pe: Ọlọhun kò ni oluranlọwọ kan ninu awọn ẹda Rẹ, ati pe Oun ni N se iranlọwọ fun wọn lori ohun ti yoo se wọn lanfaani, Oun ni N si N ti ohun ti yoo ni wọn lara danu, nitori pipe ti rirọrọ Rẹ kuro lọdọ wọn pe, ati bukaata wọn si I.

Ẹlẹẹkẹrin ni pe: Dajudaju awọn [ti wọn fi se] orogun [fun Ọlọhun] wọnyi, wọn kò ni ikapa lati sipẹ ni ọdọ Ọlọhun fun awọn ọmọlẹyin wọn, a kò si ni i yọnda fun wọn lati se bẹẹ; ati pe Ọlọhun -mimọ ni fun Un- kò tilẹ ni I yọnda fun ẹnikan lati sipẹ yatọ si awọn ẹni-Rẹ; bẹẹ ni awọn ẹni-Rẹ kò ni i sipẹ fun ẹnikan yatọ si ẹni ti Ọlọhun ba yọnu si ọrọ rẹ, ati isẹ rẹ, ati adisọkan rẹ.

3- Wiwa lori eto gbogbo ọrọ ile-aye, ati didọgba ọrọ rẹ jẹ ẹri ti n tọka ju pe oludari rẹ Ọlọhun kan soso ni I, ati pe Oluwa kan soso ni I, ti kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si I, bẹẹ ni kò si oluwa kan lẹyin Rẹ. Nitori naa gẹgẹ bi kò ti see se pe ki Ẹlẹda meji o bẹ fun aye yii, bẹẹ naa ni kò ti see se pe ki Ọlọhun meji o bẹ; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} لو كان فيهما آلهة إلا الله لفسدتا { [سورة الأنبياء: 22].

« Iba se pe awọn ọlọhun mìíran n bẹ ninu awọn mejeeji [sanma ati ilẹ] yatọ si Ọlọhun Ọba ni, dajudaju mejeeji ni ko ba bajẹ » [Suuratul-Anbiyaa': 22]. Iba se pe ọlọhun mìíran ti o yatọ si Ọlọhun wa ni sanma ati ilẹ ni, dajudaju mejeeji ni o ba bajẹ. Idi bibajẹ rẹ si ni pe: Dajudaju ti o ba se pe ọlọhun mìíran n bẹ pẹlu Ọlọhun ni, ki ba pa dandan pe ki onikaluku ninu awọn mejeeji o jẹ alagbara lati se ohun ti o fẹ, bi o ba ti fẹ, ati lati se idari, tori naa aawọ, ati iyapa-ẹnu yoo sẹlẹ ti o ba ri bayii, ati pe ibajẹ yoo titori rẹ sẹlẹ. Ti kò ba si see se pe ki o jẹ pe ẹmi meji ti o dọgba ni n dari ara, ati pe dajudaju ti o ba jẹ bẹẹ, yoo bajẹ, yoo si parun, ti eleyii ba jẹ ohun ti kò see se, njẹ bawo ni a ti se wa lero pe eleyii le see se ni ara aye ti o se pe oun l'o tobi ju?.

4- Kiko ẹnu awọn anabi ati awọn ojisẹ lori eleyii: Ẹnu awọn ijọ ko lori pe dajudaju awọn anabi ati awọn ojisẹ ni wọn pe ju ni laakaye ninu awọn eniyan, awọn si ni wọn mọ ju ni ẹmi, awọn si ni wọn lọla ju ni iwa, ati pe awọn ni wọn pọ ju ni isiti fun awọn ẹni ti wọn n dari, bẹẹ ni awọn ni wọn ni mimọ ju ninu awọn eniyan nipa ohun ti Ọlọhun gba lero, awọn si ni wọn mọna ju ninu wọn lọ si oju-ọna ti o se deedee, ati ọna ti o tọ, nitori pe wọn n gba isẹ lati ọdọ Ọlọhun, wọn si n jẹ ẹ fun awọn eniyan, ati pe ẹnu gbogbo awọn anabi ati awọn ojisẹ ko, bẹrẹ lati ori ẹni-akọkọ wọn Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", titi ti o fi de ori opin wọn, Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", lori pipe awọn ijọ wọn lọ sidi nini igbagbọ-ododo si Ọlọhun, ati pipa ijọsin fun ohun ti o yatọ si I ti, ati pe dajudaju Oun ni Ọlọhun, Ọba Otitọ. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وما أرسلنا من قبلك من رسول إلا نوحي إليه أنه لا إله أنا فاعبدون { [سورة الأنبياء: 25].

« Ati pe Awa kò ran ojisẹ kan [nisẹ] siwaju rẹ afi ki A ransẹ si i pe dajudaju kò si ọba kan ti o tọ lati jọsin fun lododo yatọ si Emi, nitori naa ẹ maa sin Mi » [Suuratul-Anbiyaa': 25]. Ọba ti ẹyin rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ nipa Anabi Nuuhu, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", pe o sọ fun awọn ijọ rẹ pe:

} ألا تعبدوا إلا الله إني أخاف عليكم عذاب يوم أليم { [سورة هود: 26].

« Pe ẹ kò gbọdọ sin [nnkan kan] yatọ si Ọlọhun, dajudaju emi n bẹru iya ọjọ kan ti o jẹ ẹlẹta-elero fun yin » [Suuratu Huud: 26]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ nipa opin wọn, Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", pe o sọ fun awọn ijọ rẹ pe:

} قل إنما يوحى إلـيَّ أنما إلهكم إله واحد فهل أنتم مسلمون { [سورة الأنبياء: 108].

« Sọ pe: Dajudaju ohun ti a fi ransẹ si mi ni pe Ọlọhun yin Ọlọhun kan soso ni I; njẹ ẹyin o yoo wa juwọ-jusẹ silẹ [fun Un bi]? » [Suuratul Anbiyaa': 108].

Ọlọhun ti O da aye nigba ti kò jẹ nnkan kan yii, ti O si da ni ọna ti kò ni afijọ, ti O si da eniyan lori didọgba ti o dara ju, ti O si se apọnle rẹ, ti O si fun gbigba jijẹ oluwa Rẹ, ati jijẹ ọba ti a jọsin fun Rẹ, ni agbara ninu adamọ rẹ, ti O si se ọkan rẹ ni ohun ti kò ni i balẹ afi ti o ba gbafa fun Un, ti o si n gba oju-ọna Rẹ, O si se ni ọranyan lori ẹmi rẹ pe kò ma balẹ afi ti o ba ni ifayabalẹ si Olupilẹsẹda rẹ, ti o si pade pẹlu Ẹlẹda rẹ, ati pe kò si ipade kan fun un afi gba ọna Rẹ ti o tọ, eyi ti awọn ojisẹ alapọnle jisẹ rẹ, O si ta a lọrẹ laakaye kan ti o se pe ọrọ rẹ kò le e dara, kò si le e se isẹ rẹ ni ọna ti o pe ju afi ti o ba gba Ọlọhun -mimọ ni fun Un- gbọ lododo.

Nitori naa nigba ti adamọ naa ba ti duro sinsin, ti ọkan naa si balẹ, ti ẹmi naa si balẹ, ti laakaye naa si gbagbọ, oriire, aabo, ati ibalẹ-ọkan yoo sẹlẹ si i ni ile-aye ati ni ile igbẹyin. Sugbọn ti eniyan ba kọ eleyii, yoo sẹmi ni ẹni ti o pin yẹlẹyẹlẹ, ti o si tuka, ti o nu sinu awọn afonufoji ile-aye, yoo si pinra rẹ laarin awọn ọlọhun rẹ, ti kò si ni i mọ ẹni ti yoo mu un ri anfaani, ta ni yoo si ti inira danu fun un, ati pe nitori ki igbagbọ-ododo o le baa jokoo sinu ọkan, ki aburu aigbagbọ o si le baa han, ni Ọlọhun se fi apejuwe kan lelẹ lori eleyii -nitori pe apejuwe n bẹ ninu ohun ti i maa sun itumọ mọ ọpọlọ- o fi okunrin ti ọrọ rẹ ti pin yẹlẹyẹlẹ laarin ọgọọrọ awọn ọlọhun we ọkunrin kan ti n sin Oluwa rẹ ni Oun nikan ninu rẹ, O si sọ pe:

} ضرب الله مثلاً رجلا فيه شركاء متشاكسون ورجلاً سلماً لرجل هل يستويان مثلاً الحمد لله بل أكثر لا يعلمون { [سورة الزمر: 29].

« Oluwa fi apejuwe ọkunrin [ẹru] kan lelẹ, ti o jẹ ajọni fun awọn onifanfa [ti wọn ni iwọ ti o dọgba lori ẹru yii] ati ọkunrin [ẹru] kan ti da gedegbe jẹ ti ọkunrin kan. Njẹ awọn [ẹru] mejeeji wa le dọgba ni apejuwe bi? Ọpẹ ni fun Ọlọhun; bẹẹ kọ, ọpọlọpọ wọn ni kò mọ » [Suuratuz-Zumar: 29]. Ọlọhun N fi apejuwe lelẹ nipa ẹru oluse Ọlọhun ni ọkan soso [ninu ijọsin] ati ẹru ọsẹbọ pẹlu ẹru kan ti o jẹ ajọni fun awọn ti iwọ wọn lori rẹ dọgba, ti apa kan wọn n ba ekeji ja lori rẹ, ti o si jẹ ohun ti a pin laarin wọn, ti o si jẹ pe onikaluku wọn ni n dari rẹ, onikaluku wọn l'o si n fun un ni isẹ se, ti o wa jẹ ẹni ti n paragadi laarin wọn, ti kò fi ẹsẹ rinlẹ si ori ilana kan, ti kò si fi ẹsẹ rinlẹ si oju-ọna kan, ti kò si agbara fun un lati mu awọn ifẹẹnu wọn ti o tako ara wọn, ti o si kọlu ara wọn, ti o si tapa sira wọn, eyi ti o se pe o n ya adojukọ rẹ ati agbara sẹ! Ati ẹru kan ti o se pe ọga kan l'o ni in, ti o si mọ ohun ti n fẹ lọdọ rẹ, ti o si fi pa a lasẹ ni amọdaju; nitori naa ti o jẹ ẹni ti n sinmi, ti ẹsẹ rẹ rinlẹ lori ilana kan ti o jẹ kedere, awọn mejeeji kò le e dọgba, eleyii n bẹ labẹ ọga kan, n si n gbadun pẹlu isinmi idurosinsin ati imọ ati amọdajọ, ekeji si wa ni abẹ awọn ọga olusefanfa, tori naa oun jẹ ẹni ti iya n jẹ, ti ẹru n ba, kò si le e bẹ lori ipo kan, ati pe kò le e tẹ ẹnikan ninu wọn lọrun, depo pe yoo le tẹ gbogbo wọn lọrun.

Lẹyin ti mo ti se alaye awọn ẹri ti n tọka si bibẹ Ọlọhun, ati jijẹ oluwa Rẹ, ati jijẹ ọba ti a jọsin fun Rẹ, o dara pe ki a mọ nipa dida ti O da aye, ati eniyan, ki a si wadi Hikmah -ọgbọn- ti o wa ninu eleyii.

###

SISE ẸDA AYE

Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- l'O da aye yii pẹlu awọn sanma rẹ ati ilẹ rẹ, ati awọn irawọ rẹ ati awọn oju-ọna irawọ rẹ, ati awọn okun rẹ ati awọn igi rẹ, ati gbogbo awọn ẹranko rẹ, nigba ti kò ti jẹ nnkan kan ri. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} قل أئنكم لتكفرون بالذي خلق الأرض في يومين وتجعلون له أنداداً ذلك رب العالمين. وجعل فيها رواسي من فوقها وبارك فيها وقدر فيها أقواتها في أربعة أيام سواء للسائلين. ثم استوى إلى السماء وهي دخان فقال لها وللأرض ائتيا طوعاً أو كرهاً قالتا أتينا طائعين. فقضاهن سبع سموات في يومين وأوحى في كل سماء أمرها وزينا السماء الدنيا بمصابيح وحفظاً ذلك تقدير العزيز العليم { [سورة فصلت: 9-12].

« Sọ pe: Njẹ ni otitọ ni ẹyin n se aigbagbọ si Ẹni ti O da ilẹ ni ọjọ meji, ẹyin si n wa orogun fun Un? Eleyii mọ ni Oluwa gbogbo aye. Ati pe O da awọn oke nlanla si ori rẹ, O si fi ibukun si i, O si pebubu awọn ounjẹ rẹ sibẹ ni awọn ọjọ mẹrin ni dọgba-n-dọgba fun awọn ti n beere. Lẹyin naa ni O gbero [lati da] sanma nigba ti o wa ni eefin, O si sọ fun oun ati ilẹ pe: Ẹ wa, bi ẹ fẹ, bi ẹ kọ, awọn mejeeji si sọ pe: Awa wa, ni ẹni ti o finufẹdọ tẹle asẹ. Nitori naa o pari wọn si sanma meje ni ọjọ meji, O si fi isẹ sanma kọọkan ransẹ si i. Ati pe Awa fi awọn atupa se sanma ile-aye ni ọsọ, ati ki o maa jẹ aabo, eleyii jẹ eto Ọba Alagbara, Oni-mimọ » [Suuratu Fusilat: 9-12].

Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} أو لم ير الذين كفروا أن السموات والأرض كانتا رتقا ففتقناهما وجعلنا من الماء كل شيء حي أفلا يؤمنون. وجعلنا في الأرض رواسي أن تميد بهم وجعلنا فيها فجاجاً سبلا لعلهم يهتدون. وجعلنا السماء سقفا محفوظاً وهم عن آياتها

معرضون { [سورة الأنبياء 30، 32].

« Njẹ awọn ẹni ti wọn se aigbagbọ kò wa ri i ni pe dajudaju awọn sanma ati ilẹ, mejeeji jẹ ohun ti o papọ, sugbọn Awa ya wọn si ọtọọtọ. A si da gbogbo nnkan alaaye lati ara omi, njẹ wọn o yoo wa gbagbọ bi?. Ati pe A se awọn oke nlanla si ori ilẹ ki o ma baa mi mọ wọn, A si tun se oju-ọna ti o fẹ sinu rẹ, ki wọn o le maa mọna. Bẹẹ ni A se sanma ni àjà ti a n sọ, sibẹsibẹ awọn n sẹri kuro nibi awọn ami rẹ » [Suuratul-Anbiyaa': 30-32].

Ọlọhun da aye yii nitori awọn Hikmah -ọgbọn- ti o tobi, ti o tobi tayọ isiro, ati pe ọgbọn nla kan ati awọn ami ti o ya'ni lẹnu wa ni ara gbogbo ipin kọọkan ninu rẹ, ti o ba si se akiyesi ami kan ninu rẹ, o ri nnkan iyalẹnu kan ninu rẹ. Nitori naa wo awọn ohun iyalẹnu ẹda Ọlọhun ninu awọn irugbin, eyi ti o se pe ewe kan, tabi itakun kan, tabi eso kan ninu rẹ fẹrẹ le ma salai ni awọn anfaani kan ti o se pe rirọkirika rẹ ati awọn alaye rẹ yoo maa ko agara ba ọpọlọ awọn eniyan. Wo ibi ti omi n gba ni ara awọn itakun tẹẹrẹ kekere ti o lẹ yii, eyi ti o se pe oju fẹrẹ ma le ri i, afi lẹyin titẹ oju mọ ọn, bawo ni o ti se ni agbara lati fa omi lati isalẹ wa si oke? Lẹyin naa ti yoo si maa lọ ninu awọn ọna yii ni odiwọn bi o ti se gba a, ati bi o ti fẹ, lẹyin naa ti yoo pin, ti yoo si pẹka, ti yoo si bẹrẹ si ni i wẹ debi ti oju kò ti ni i to o mọ, lẹyin naa se akiyesi kikojọ oyun igi, ati isipopada rẹ lati ipo kan lọ si omiran, gẹgẹ bi yiyipada awọn ipo ọmọ poloro ti o pamọ si oju, laarin ki o ri i ni apola kan ti o wa ni ihoho, ti kò si ẹwu lara rẹ, n ni Oluwa Ẹlẹda rẹ yoo ba wọ ọ lẹwu kan ti o dara ju lati ara ewe, lẹyin naa ni O mu oyun rẹ jade ni ara rẹ ni ohun ti o lẹ ti o si kere, lẹyin ti O ti yọ ewe rẹ, ki o maa jẹ isọ fun un, ati ẹwu fun eso ti o lẹ naa; ki o maa fi i bora nibi ooru, otutu, ati awọn ohun ti i maa n ba eso jẹ, lẹyin naa ni O N fi ọrọ eso naa ati ounjẹ rẹ ransẹ si i ninu awọn itakun ati ọna omi yii, yoo si maa fi se ounjẹ, gẹgẹ bi ọmọ oponlo ti se maa n fi ọyan iya rẹ se ounjẹ, lẹyin naa ni O tọju rẹ, O si mu un dagba, o pe, o si pọn daadaa, n ni ere-oko naa ba jade lati ara odi apola naa ni ohun ti o dun.

Bi iwọ ba si wo ilẹ, ati bi a ti da a, o ri i wi pe o n bẹ ninu awọn ami ti o tobi ju ti Olupilẹsẹda rẹ, ati Oludasẹda rẹ ni ọna ti kò ni afijọ, Ọlọhun -mimọ ni fun Un- da ilẹ naa ni itẹ ati ni pẹrẹsẹ, O si tẹ ẹ lori ba fun awọn ẹru Rẹ, ati pe O fi awọn ọrọ -arziki- wọn ati awọn ounjẹ wọn ati awọn ohun isẹmi wọn sinu rẹ, ati pe O se awọn ọna sinu rẹ nitori ki wọn o le maa lọ maa bọ ninu rẹ, fun awọn bukaata wọn ati awọn igbesẹ wọn, ati pe O fi idi rẹ mulẹ pẹlu awọn oke nlanla, O si se wọn ni awọn eekan ti n sọ ọ, nitori ki o ma baa mi, bẹẹ O fẹ awọn ẹgbẹẹgbẹ rẹ, O si se e ni rogodo, O tẹ ẹ, O se e ni pẹrẹsẹ, O si se e ni afanimọra fun awọn alaaye pẹlu kiko wọn si oke rẹ, afanimọra bakan naa fun awọn oku nipa kiko wọn si inu rẹ nigba ti wọn ba ku, nitori naa ibugbe ni oke rẹ jẹ fun awọn alaaye, bẹẹ ni ibugbe awọn oku ni inu rẹ. Lẹyin naa wo awowo ti n yi pẹlu oorun rẹ ati osupa rẹ ati awọn irawọ rẹ ati apapọ awọn irawọ rẹ ti o duro yii, ati bi o ti se n yipo ile-aye yii ni yiyopo gbogbo igba lori ito lẹsẹẹsẹ ati eto yii titi di ipari opin aye, ati ohun ti n bẹ ninu wiwepọ eleyii ninu yiyatọ oru ati ọsan ati awọn igba inu ọdun, ooru ati otutu. Ati ohun ti n bẹ ninu eleyii ninu awọn anfaani fun ohun ti o wa lori ilẹ ninu ọlọkan-ọ-ọjọkan ẹranko ati awọn irugbin.

Lẹyin naa woye si dida sanma, ki o si tun wo o ni igba kan lẹyin omiran, o ri i pe o wa ninu awọn arisami ti o ga ju, nipa giga rẹ, ati fifẹ rẹ, ati iduro-sinsin rẹ, nigba ti o se pe kò si opo ni abẹ rẹ, ti kò si si agbekọ kan ni oke rẹ, bẹẹ kọ, nse ni a gbe e duro pẹlu agbara Ọlọhun ti O di awọn sanma ati ilẹ mu nibi yiyẹ.

Ati pe ti irẹ ba wo aye yii ati akojopọ awọn apa kan rẹ, ati tito eto rẹ lori eyi ti o dara ju ninu eto -ti n tọka si pipe agbara Ẹlẹda rẹ, ati pipe imọ Rẹ, ati pipe Hikmah -ọgbọn- Rẹ, ati pipe aanu Rẹ- o ri wi pe o dabi ile ti a kọ, ti a si pese gbogbo ohun elo rẹ, ati awọn ohun anfaani rẹ, ati gbogbo ohun ti a maa n bukaata sinu rẹ, tori naa sanma ni aja rẹ ti a gbega lori rẹ, ati pe ilẹ ni ibusun ati itẹ ati ẹni ti o rinlẹ-sinsin fun ẹni ti n gbe ori rẹ, bẹẹ ni oorun ati osupa jẹ imọlẹ meji ti n mọlẹ ninu rẹ; ati pe awọn irawọ ni awọn atupa rẹ ati ọsọ rẹ, ti n fi ọna mọ oni-irin-ajo ninu awọn oju-ọna ile-aye yii, bẹẹ ni awọn okuta olowo-iyebiye ati awọn ohun alumaani ilẹ jẹ ohun ti a ko pamọ sinu rẹ, gẹgẹ bi ohun agbepamọ ti o ti setan fun lilo, gbogbo onikaluku ninu rẹ wa fun ohun ti o wulo fun, ati pe ọlọkan-ọ-jọkan awọn eso ti o ti setan fun ohun ti a maa n lo o fun l'o wa nibẹ, bẹẹ ni orisirisi awọn ẹranko ti a sẹri wọn sidi awọn ohun anfaani wọn, ninu wọn ni gigun, ninu wọn si ni fifun wara, ninu wọn si ni jijẹ, ninu wọn tun ni wiwọ ni ẹwu, ninu wọn si ni sise ọdẹ, O si se eniyan gẹgẹ bi ọba ti a fi wọn le e lọwọ, oludari wọn pẹlu isẹ rẹ ati asẹ.

Ati pe iba se pe iwọ se akiyesi aye yii lapapọ, tabi apa kan ninu awọn ipin rẹ, dajudaju o ba ri iyalẹnu ninu rẹ, ati pe ti o ba wo o finnifinni ni paapaa wiwo finnifinni, ti o si se dọgba lori ara rẹ, ti o si bọ lọwọ imunisin ifẹẹnu ati awokọse-kawokọse, dajudaju o mọ amọdaju ni amọdaju ti o pe, pe ohun ti a da ni aye yii, Ọba Ọlọgbọn, Alagbara, Olumọ ni O da a, O si pebubu rẹ ni ipebubu ti o dara ju, O si to eto rẹ ni eto ti o dara ju, ati pe kò le e see se pe ki Ẹlẹda Naa o pe meji rara, bẹẹ kọ, Ọkan soso ni Ọlọhun, kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo sin yatọ si I, ati pe iba se pe ọlọhun kan ti o yatọ si Ọlọhun Ọba ba n bẹ ni sanma tabi ilẹ ni, dajudaju ọrọ mejeeji ni o ba ti bajẹ, bẹẹ ni eto rẹ o ba daru, awọn anfaani rẹ o ba si duro sin.

Sugbọn ti o ba kọ lati gba nnkan kan yatọ si ki o maa fi ẹda ti si ọdọ ẹni ti o yatọ si Ẹlẹda rẹ, njẹ ki ni o fẹ sọ nipa ẹrọ kan ti a fi n fa omi lodo ti o se pe a se ẹrọ rẹ daadaa, ti a si pe tito rẹ, ti a si pebubu awọn eroja rẹ ni ipebubu ti o dara ju ti o si dopin ju, ni ọna ti o se pe ẹni ti n wo o kò le e ri alebu kan ninu ohun ti a fi se e, tabi lara aworan rẹ, ti a si gbe e si inu ọgba nla kan ti gbogbo onirunruu eso wa ninu rẹ, ti n fun un ni ohun ti o fẹ ninu omi mu, ti o si se pe ẹni ti n tọju ọgba naa wa ninu rẹ, ti n pa awọn eteeti rẹ pọ, ti n si n se amojuto ati ayẹwo rẹ, ti i si n se gbogbo ohun ti o jẹ anfaani rẹ daadaa, ti nnkan kan kò si daru ninu rẹ, bẹẹ ni awọn eso rẹ kò bajẹ, lẹyin naa nigba ti o ba di asiko ikore-oko yoo wa pin iye rẹ lori gbogbo ohun ti o jade ni odiwọn bukaata wọn ati ti awọn ohun ti o pa dandan pe ki a se fun wọn, yoo se ohun ti o tọ fun orisi kọọkan; ti yoo si maa pin in lọ bayii ni gbogbo igba.

Njẹ o wa ro pe asan ni o mu ki eleyii o sẹlẹ bẹẹ, lai kò si ẹlẹda kan, lai kò si si olusẹsa kan, lai kò si si oluto-eto kan bi? Bẹẹ kọ, njẹ nse ni asan mu ẹrọ ifami naa ati ọgba naa maa bẹ bi, se asan l'o mu ki gbogbo eleyii o maa bẹ lai kò si ẹni ti o sisẹ kan, lai kò si si oluto-eto kan, njẹ o wa mọ ohun ti ọpọlọ rẹ yoo sọ fun ọ ti o ba jẹ bẹẹ? Ati pe ki ni esi ti yoo fun ọ? Ati pe ki ni yoo dari rẹ lọ sidi rẹ??.

Hikmah -ọgbọn- ti o wa ninu dida aye:

Lẹyin ipaara ati iwoye si sisẹda aye yii, o dara pe ki a wi apa kan ninu awọn Hikmah -ọgbọn- ti o se pe nitori rẹ ni Ọlọhun se da awọn ẹda nla yii, ati awọn ami iyanu yii; ninu eleyii ni:

1- Titẹ ẹ lori ba fun eniyan: Nigba ti Ọlọhun se idajọ atifi arole kan ti yoo maa jọsin fun Un si ori ilẹ yii, ti yoo si maa gbe ori ilẹ yii, O da gbogbo nnkan yii nitori rẹ, ki isẹmi rẹ o le baa dọgba, ati ki ọrọ isẹmi rẹ ti aye ati ti ọrun o le baa dara fun un. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وسخر لكم ما في السموات وما في الأرض جميعاً منه { [سورة الجاثية: 13].

« Ati pe O tẹ ohun ti o wa ni sanma ati ohun ti o wa ni ilẹ patapata lori ba fun yin » [Suuratul Jaathiyah: 13]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} الله الذي خلق السموات والأرض وأنزل من السماء ماءً فأخرج به من الثمرات رزقا لكم وسخر لكم الفلك لتجري في البحر بأمره وسخر لكم الأنهار. وسخر لكم الشمس والقمر دائبين وسخر لكم الليل والنهار. وآتاكم من كل ما سألتموه وإن تعدوا نعمة الله لا تحصوها إن الإنسان لظلوم كفار { [سورة إبراهيم: 32-34].

« Ọlọhun ni Ẹni ti O sẹda awọn sanma ati ilẹ, O si N sọ omi kalẹ lati ara ẹsu-ojo, O si fi N mu awọn eso jade ni ipese fun yin, O si tun tẹ awọn ọkọ oju-omi lori ba fun yin, ki o le maa rin lori okun pẹlu asẹ Rẹ, O si tun tẹ awọn odo sisan kékéké lori ba fun yin. O si tun tẹ oorun ati osupa lori ba fun yin ti awọn mejeeji n lọ ni ọna wọn [laiduro], O si tẹ oru ati ọsan lori ba fun yin. O si fun yin ninu gbogbo ohun ti ẹ n tọrọ lọwọ Rẹ; ati pe ti ẹyin yoo ba ka idẹra Ọlọhun, ẹ kò le ka wọn tan, dajudaju eniyan jẹ alabosi, alaimoore » [Suuratu Ibraahiim: 32-34].

2- Nitori ki awọn sanma ati ilẹ ati gbogbo ohun ti o wa ninu aye o le baa jẹ ẹlẹri lori jijẹ oluwa Ọlọhun, ki wọn o si le baa jẹ awọn ami lori jijẹ ọkan soso Rẹ: Idi ni pe ohun ti o tobi ju ninu bibẹ yii ni gbigba jijẹ oluwa Rẹ ati nini igbagbọ-ododo si jijẹ ọkan soso Rẹ, ati pe nitori pe Oun ni ohun ti o tobi ju; n l'O se gbe awọn ẹlẹri ti o tobi ju dide lori rẹ, ti O si gbe awọn ohun amusami ti o tobi dide fun un, ti O si se ẹri fun un pẹlu awọn ẹri ti o de opin ju, nitori naa Ọlọhun -mimọ ni fun Un- gbe awọn sanma ati ilẹ ati gbogbo awọn nnkan ti n bẹ dide ki wọn o le maa jẹ ẹlẹri lori eleyii; ati pe eleyii l'o mu ki wiwa:

} ومن آياته {.

« Ati pe ninu awọn ami Rẹ ». O pọ ninu Al-Qur'aani; gẹgẹ bi o ti wa ninu ọrọ Ọlọhun t'O ga, pe:

} ومن آياته خلق السموات والأرض {.

« Ati pe ninu awọn ami Rẹ ni dida awọn sanma ati ilẹ ».

} ومن آياته منامكم بالليل والنهار {.

« Bẹẹ ni o wa ninu awọn ami Rẹ oorun yin ni oru ati ni ọsan ».

} ومن آياته يريكم البرق خوفاً وطمعاً {.

« Ninu awọn ami Rẹ si ni ki O fi manamana han yin ni ti ibẹru ati ireti».

} ومن آياته أن تقوم السماء والأرض بأمره { [سورة الروم: 22-25].

« Ati pe o n bẹ ninu ami Rẹ diduro sanma ati ilẹ pẹlu asẹ Rẹ » [Suuratur-Ruum: 22-25].

3- Nitori ki wọn o le baa jẹ ẹlẹri lori igbende: Nigba ti o se pe isẹmi meji ni isẹmi, isẹmi ti ile-aye ati isẹmi ti ile ikẹyin, isẹmi ti ile ikẹyin si ni isẹmi otitọ. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وما هذه الحياة الدنيا إلا لهو ولعب وإن الدار الآخرة لهي الحيوان لو كانوا يعلمون { [سورة العنكبوت: 64].

« Isẹmi ile-aye yii ki i se nnkan kan mìíran yatọ si awada ati ere, ati pe ile ti ikẹyin ni isẹmi [ni ododo] ti o ba se pe wọn mọ » [Suuratul-Ankabuut: 64]. Nitori pe ile ẹsan ati isiro ni i, ati nitori pe bibẹ laelae ti ailopin ninu idẹra wa ninu rẹ fun awọn ẹni-idẹra, bẹẹ ni bibẹ laelae ti ailopin ninu iya wa ninu rẹ pẹlu fun awọn ẹni-iya.

Nigba ti o wa jẹ pe eniyan kò le e de ile yii afi lẹyin ti o ba ku, ti a si gbe e dide lẹyin iku rẹ, n l'o mu ki gbogbo ẹni ti ajọse rẹ pẹlu Oluwa rẹ ti ja, ti adamọ rẹ si ti pada si ẹyin, ti laakaye rẹ si ti bajẹ o tako eleyii, nitori idi eleyii ni Ọlọhun se gbe awọn awijare dide, ti O si naro awọn ẹri-ọrọ; titi ti awọn ẹmi yoo fi gba igbende gbọ, ti awọn ọkan yoo si fi ni amọdaju si i, nitori pe dida ẹda pada fuyẹ ju dida a ni igba akọkọ lọ, bẹẹ tilẹ kọ, sisẹda awọn sanma ati ilẹ tobi ju dida ẹda eniyan pada lọ. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وهو الذي يبدأ الخلق ثم يعيده وهو أهون عليه { [سورة الروم: 27].

« Ati pe Oun ni Ẹni ti N bẹrẹ ẹda dida, lẹyin naa yoo tun da a pada, ati pe eleyii l'o rọrun ju fun Un » [Suuratur-Ruum: 27]. Ọlọhun t'O ga, tun sọ pe:

} لخلق السموات والأرض أكبر من خلق الناس { [سورة غافر: 57].

« Dajudaju dida awọn sanma ati ilẹ tobi ju dida awọn eniyan lọ » [Suuratu Gaafir: 57]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} الله الذي رفع السموات بغير عمد ترونها ثم استوى على العرش وسخر الشمس والقمر كل يجري لأجل مسمى يدبر الأمر يفصل الآيات لعلكم بلقاء ربكم

توقنون { [سورة الرعد: 2].

« Ọlọhun ni Ẹni ti O gbe sanma ga lai kò si òpo kan ti ẹ le ri, lẹyin naa O se dọgba si ori aga ọla [Rẹ] naa, O si tẹ oorun ati osupa lori ba, onikaluku wọn n rin titi di asiko kan ti a da; O si N to eto awọn ọrọ, O si N se alaye awọn aayah naa, nitori ki ẹ le baa ni amọdaju nipa pipade Oluwa yin » [Suuratur-Ra'ad: 2].

Lẹyin naa, irẹ eniyan:

Ti o ba se pe gbogbo ohun ti o wa ninu aye yii ni a tẹ lori ba nitori rẹ, ati pe ti awọn ami rẹ ati awọn asia rẹ ba si dide ni ẹlẹri ni iwaju rẹ, ti wọn n jẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati jọsin fun lododo afi Ọlọhun nikan soso, kò si orogun kan fun Un, ati pe ti o ba mọ daju pe igbende rẹ ati isẹmi rẹ lẹyin iku rẹ fuyẹ ju sise ẹda awọn sanma ati ilẹ lọ, ati pe iwọ yoo pade Oluwa rẹ, yoo si se isiro isẹ rẹ fun ọ, ti o ba si mọ daju pe olujọsin ni gbogbo aye yii jẹ fun Oluwa rẹ, nitori pe gbogbo awọn ẹda inu rẹ ni wọn n se afọmọ pẹlu fifi ẹyin fun Oluwa wọn. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} يسبح لله ما في السموات وما في الأرض الملك القدوس العزيز الحكيم { [سورة الجمعة: 1].

« Gbogbo ohun ti o wa ni sanma ati ohun ti o wa ni ilẹ ni n se afọmọ fun Ọlọhun, Ọba ti O mọ, Alagbara, Ọlọgbọn » [Suuratul-Jum'ah: 1]. Ati pe wọn a maa fi ori balẹ nitori titobi Rẹ, Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, sọ pe:

} ألم تر أن الله يسجد له من في السموات ومن في الأرض والشمس والقمر والنجوم والجبال والشجر والدواب وكثير من الناس وكثير حق عليه العذاب { [سورة الحج: 18].

« Njẹ iwọ kò wa ri pe dajudaju Ọlọhun ni awọn ẹni ti o wa ninu sanma ati awọn ẹni ti n bẹ lori ilẹ ati oorun ati osupa ati awọn irawọ ati awọn apata ati igi ati awọn ẹranko ati ọpọlọpọ ninu awọn eniyan n fi ori balẹ fun bi? Bẹẹ ni ọpọlọpọ ni iya jẹ ẹtọ lori wọn » [Suuratul-Hajj: 18]. Koda awọn ẹda wọnyi n kirun fun Oluwa wọn, ni irun ti o ba wọn mu; Ọba ti orukọ Rẹ ga sọ pe:

} ألم تر أن الله يسبح له من في السموات والأرض والطير صافات كل قد علم صلاته وتسبيحه { [سورة النور: 41].

« Iwọ kò wa ri i ni pe dajudaju Ọlọhun ni gbogbo ẹni ti n bẹ ninu sanma ati ilẹ ati awọn ẹyẹ ti wọn tẹ awọn iyẹ wọn n se afọmọ fun? Kaluku wọn l'o mọ ọna ikirun fun [Ọlọhun] ati fifi ogo fun Un » [Suuratun-Nuur: 41].

Ati pe ti ara rẹ ba kere ninu eto rẹ, ni ibamu pẹlu ebubu Ọlọhun ati eto Rẹ, tori naa ọkan, fufuu mejeeji, ẹdọ, ati gbogbo ara yoku ni wọn juwọ-jusẹ silẹ fun Oluwa wọn, ti wọn si fi didari wọn le Oluwa wọn lọwọ… njẹ ipinnu rẹ ti isẹsa eyi ti a fun ọ ni ẹsa se ninu rẹ laarin pe ki o gba Oluwa rẹ gbọ, ati ki o se aigbagbọ si I, njẹ ipinnu yii wa le jẹ ohun ti o yapa, ti o si tako irin oloore yii ninu aye ni ayika rẹ, tabi ni ara rẹ bi?.

Dajudaju eniyan onilaakaye yoo maa gbera rẹ jinna si ki o jẹ pe oun ni ẹni ti o tapa, ti o si yapa, ninu alagbalugbu aye nla ti o fẹ yii.

###

SISE ẸDA ENIYAN ATI SISE APỌNLE RẸ

Ọlọhun dajọ atida ẹda kan ti o lẹtọ si gbigbe aye yii, nitori naa ẹda naa ni eniyan; ati pe Hikmah -ọgbọn- Rẹ -mimọ ni fun Un- gba pe ki ohun ti yoo fi se ẹda eniyan naa o jẹ ilẹ, O si bẹrẹ si ni i se ẹda rẹ lati ara ẹrọfọ, lẹyin naa ni O wa ya aworan rẹ lori aworan ti o dara, eyi ti eniyan wa lori rẹ yii; nitori naa nigba ti o dọgba ni ẹni ti o pe ninu aworan rẹ, O fẹ si i lara ninu ẹmi Rẹ, n l'o ba di eniyan kan ninu didọgba ti o dara ju, o n gbọrọ, o si n riran, o si n yi ara pada, o si n sọrọ, n ni Oluwa rẹ ba fi i sinu ọgba-idẹra -Al-janna- Rẹ, O si fi ohun ti o n bukaata lati mọ nipa rẹ mọ ọn, O si se gbogbo ohun ti o wa ninu ọgba-idẹra yii ni ẹtọ fun un, O si kọ fun un [lati de idi] igi kan soso -ni adanwo ati amiwo- ati pe O fẹ lati fi ipo rẹ ati aaye rẹ han, n l'O ba pa awọn malaika lasẹ pe ki wọn o fi ori balẹ fun un, n ni gbogbo awọn malaika lapapọ ba fi ori balẹ fun un, yatọ si esu ti o kọ lati fi ori balẹ ni ti igberaga, ati orikunkun, n ni Oluwa ba binu si i, fun yiyapa si asẹ Rẹ, O si le e kuro ninu ikẹ Rẹ, nitori pe o se igberaga si i, n ni esu ba tọrọ ni ọdọ Oluwa rẹ pe ki O jẹ ki ẹmi oun o gun, ki O si lọ oun lara di ọjọ igbende, n ni Oluwa rẹ ba lọ ọ lara, O si mu ki ẹmi rẹ o gun titi di ọjọ igbende, ati pe esu se ilara Aadama, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", nigba ti a fun oun ati awọn arọmọdọmọ rẹ ni ajulọ lori rẹ, o si fi Oluwa rẹ bura pe oun yoo si gbogbo awọn ọmọ Aadama lọna, ati pe oun yoo maa wa ba wọn ni iwaju wọn, ati ni ẹyin wọn, ati ni apa ọtun wọn, ati ni apa osi wọn, afi awọn ẹru Ọlọhun, awọn ti a fọmọ, awọn olododo, awọn olupaya Ọlọhun, dajudaju Ọlọhun sọ wọn nibi ete esu, ati arekunda rẹ, ati pe Ọlọhun kilọ fun Aadama, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", pe ki o sọra fun ete esu, n ni esu ba se iroyiroyi fun Aadama, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", ati iyawo rẹ Hawwaa'u, ki o le baa yọ awọn mejeeji jade kuro ninu ọgba-idẹra naa, ki o si le baa fi ohun ti a gbe pamọ si wọn ninu ihoho awọn mejeeji han wọn, o si bura fun awọn mejeeji pe dajudaju emi jẹ oluse-isiti fun ẹyin mejeeji, ati pe dajudaju Ọlọhun kò kọ fun yin lati jẹ ninu igi yii afi ki ẹyin mejeeji o ma baa di malaika, tabi ki ẹ ma baa jẹ ẹni ti yoo maa bẹ laelae.

Nitori naa awọn mejeeji jẹ ninu igi ti Ọlọhun kọ fun wọn lati jẹ yii, tori naa iya-ẹsẹ ti o kọkọ jẹ wọn latari yiyapa si asẹ Ọlọhun ni pe ihoho awọn mejeeji han si wọn, n ni Oluwa wọn ba ran wọn leti nipa ikilọ Rẹ, ti O se fun wọn nipa ete esu, n ni Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", ba tọrọ aforijin lọdọ Oluwa rẹ, O si dari jin in, O si gba ironupiwada rẹ, O si sa a lẹsa, O si fi ọna mọ ọn, O si pa a lasẹ pe ki o sọ kalẹ kuro ni ọgba-idẹra ti n gbe lọ si ori ilẹ, nigba ti o se pe oun ni ibugbe rẹ, ibẹ naa si ni ohun igbadun rẹ wa di igba kan, O si fun un niro pe lati ara rẹ ni a ti da a, ati pe ori rẹ naa ni yoo ti sẹmi, bẹẹ ni ori rẹ ni yoo ku si, ati pe lati inu rẹ ni a o ti gbe e dide.

Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ba sọ kalẹ lọ si ilẹ, oun ati iyawo rẹ Hawwaa'u, n ni awọn arọmọdọmọ awọn mejeeji ba bẹrẹ si ni i pọ, wọn si n sin Ọlọhun ni ibamu pẹlu ohun ti O fi pa wọn lasẹ, nigba ti o se pe anabi ni Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a".

Dajudaju Ọlọhun si ti fun'ni niro iroyin yii, Ọlọhun -mimọ ni fun Un- sọ pe:

} ولقد خلقناكم ثم صورناكم ثم قلنا للملائكة اسجدوا لآدم فسجدوا إلا إبليس لم يكن من الساجدين. قال ما منعك ألا تسجد إذ أمرتك قال أنا خير منه خلقتني من نار وخلقته من طين. قال فاهبط منها فما يكون لك أن تتكبر فيها فاخرج إنك من الصاغرين. قال أنظرني إلى يوم يبعثون. قال إنك من المنظرين. قال فبما أغويتني لأقعدن لهم صراطك المستقيم. ثم لآتينهم من بين أيديهم ومن خلفهم وعن أيمانهم وعن شمائلهم ولا تجد أكثرهم شاكرين. قال اخرج منها مذءوماً مدحوراً لمن تبعك منهم لأملأن جهنم منكم أجمعين. ويا آدم اسكن أنت وزوجك الجنة فكلا من حيث شئتما ولا تقربا هذه الشجرة فتكونا من الظالمين. فوسوس لهما الشيطان ليبدي لهما ما ووري عنهما من سوءاتهما وقال ما نهاكما ربكما عن هذه الشجرة إلا أن تكونا ملكين أو تكونا من الخالدين. وقاسمهما إني لكما لمن الناصحين. فدلاهما بغرور فلما ذاقا الشجرة بدت لهما سوءاتهما وطفقا يخصفان عليهما من ورق الجنة وناداهما ربهما ألم أنهكما عن تلكما الشجرة وأقل لكما إن الشيطان لكما عدو مبين. قالا ربنا ظلمنا أنفسنا وإن لم تغفر لنا وترحمنا لنكونن من الخاسرين. قال اهبطوا بعضكم لبعض عدو ولكم في الأرض مستقر ومتاع إلى حين. قال فيها تحيون وفيما تموتون ومنها تخرجون { [سورة الأعراف: 11-25].

« Ati pe dajudaju Awa ti da yin, lẹyin naa Awa si ya aworan yin, lẹyin naa A si sọ fun awọn malaika pe: Ẹ fi ori balẹ fun Aadama. Wọn si fi ori balẹ, afi esu ni kò si ninu awọn ti wọn fi ori balẹ naa. Ọlọhun ni ki l'o mu ọ ma fi ori balẹ nigba ti Mo pa ọ lasẹ? O ni: Emi dara ju u lọ, lati ara ina ni O da mi, O si da oun lati ara erupẹ. O ni: Sọ kalẹ kuro ninu rẹ, kò tọ si ọ pe ki o maa se igberaga ninu rẹ, nitori naa jade, dajudaju iwọ n bẹ ninu awọn ẹni-yẹpẹrẹ. Esu ni: Lọ mi lara di ọjọ ti a o gbe wọn dide. Oluwa ni: Dajudaju iwọ n bẹ ninu ẹni ti a o lọ lara. Esu ni: Fun sise ti O se mi ni ẹni-anu, dajudaju n o maa jokoo de wọn ni oju-ọna Rẹ ti o tọ. Lẹyin naa dajudaju emi yoo maa wa ba wọn lati iwaju wọn, ati lati ẹyin wọn, ati lati ọwọ ọtun wọn, ati lati ọwọ osi wọn, O kò si ni i ri ọpọlọpọ wọn ni oluse-ọpẹ. Oluwa sọ pe: Jade kuro ninu rẹ ni ẹni-abuku ati ni ẹni ti a le jinna si ikẹ -Ọlọhun- dajudaju ẹni ti o ba tẹle ọ ninu wọn, dajudaju Emi yoo fi yin kun ina Jahannama patapata. Ati pe iwọ Aadama, iwọ ati iyawo rẹ, ẹ maa gbe inu ọgba-idẹra naa, ki ẹ si maa jẹ nibikibi ti o ba wu yin, sugbọn ẹ kò gbọdọ sun mọ igi yii, ki ẹ ma baa di ara awọn alabosi. Esu si ko iroyiroyi ba awọn mejeeji, ki o le fi ohun ti a bo fun awọn mejeeji ninu ihoho ara wọn han wọn. Esu si sọ -fun awọn mejeeji- pe: Oluwa ẹyin mejeeji kò kọ igi yii fun yin bi ko se pe ki ẹyin o maa baa di malaika meji, tabi ki ẹ maa bẹ ninu awọn ti wọn yoo maa bẹ gberekese -nibẹ-. O si bura fun awọn mejeeji pe: Dajudaju emi jẹ afunni-nimọran-rere fun ẹyin mejeeji. O si mu awọn mejeeji sina pẹlu ẹtanjẹ. Tori naa nigba ti awọn mejeeji tọ igi naa wo, ihoho awọn mejeeji han si wọn, wọn si bẹrẹ si ni i fi -apa kan- ninu ewe ọgba-idẹra naa bo ara wọn, Oluwa awọn mejeeji si pe wọn pe: Njẹ Emi kò wa ti kọ fun yin nipa igi yii, ti Mo si sọ fun yin pe dajudaju ọta ti o han gbangbá ni esu jẹ fun ẹyin mejeeji bi?. Awọn mejeeji sọ pe: Oluwa wa, a ti se abosi fun ori ara wa, ti O kò ba si fi ori jin wa, ki O si se aanu wa, dajudaju a o bẹ ninu awọn ẹni ofo. Oluwa ni: Ẹyin mejeeji ẹ sọ kalẹ, ki apa kan yin o maa jẹ ọta fun apa kan, ati pe ibugbe n bẹ fun yin ni ori ilẹ, ati igbadun titi igba diẹ. O ni: Ori rẹ ni ẹ o ti maa sẹmi, ati pe ibẹ ni ẹ o ku si, bẹẹ ni inu rẹ ni a o ti yọ yin jade » [Suuratul Aa'raaf: 11-25].

Nigba ti a ba si se akiyesi titobi dida ti Ọlọhun da eniyan yii, nigba ti O da a lori didọgba ti o dara ju, ti O si wọ ọ ni gbogbo ẹwu apọnle ninu: Lakaaye, imọ, alaye, ọrọ sisọ, apejuwe, aworan daadaa, awọ alapọnle, ara ti o dọgba, nini imọ pẹlu wiwa ẹri ati irori, ati nini awọn iwa alapọnle ati ajulọ ninu: Daadaa sise, ati igbọrọ, ati igbafa, nitori naa iyatọ melòó l'o wa laarin ipo rẹ nigba ti o wa ni omi gbọlọgbọlọ ninu apo-ibi ti a fi i pamọ sibẹ, ati ipo rẹ nigba ti malaika yoo maa wọle tọ ọ ninu ọgba-idẹra -Al-janna- ti o jẹ ile-n-gbe ti laelae?.

} فتبارك الله أحسن الخالقين { [سورة المؤمنون: 14].

« Ibukun ni fun Ọlọhun ti O da awọn ẹda Rẹ ni ọna ti o dara ju » [Suuratul Mu'uminuun: 14].

Nitori naa ilu kekere kan ni ile-aye, ati pe eniyan ni ẹni ti n gbe inu rẹ, gbogbo onikaluku ni o si ko airoju nipa rẹ, l'ẹni ti n gbiyanju lori anfaani rẹ; bẹẹ ni gbogbo nnkan ni a ti se nitori anfaani eniyan ati bukaata rẹ, tori naa awọn malaika ti a fi sọ ọ, wọn n sọ ọ ni aarin oru ati ni ọsan, awọn ti a si fi sọ ojo ati awọn irugbin n gbiyanju nipa ọrọ rẹ, wọn si n sisẹ tọ ọ, ati pe awọn awowo fi ori ba ni ohun ti o gbafa ti n si n yipo pẹlu ohun ti o ni anfaani rẹ ninu; ati pe oorun ati osupa ati awọn irawọ ohun ti a tẹ ni ori ba ni wọn, ti wọn si n se isiro awọn asiko rẹ ati awọn akoko rẹ, ati sise atunse awọn owo ounjẹ rẹ, bẹẹ ni a tẹri oju-ọrun ba fun un pẹlu afẹfẹ rẹ ati atẹgun rẹ, ati ẹsu-ojo rẹ ati ẹyẹ rẹ, ati ohun ti a ko pamọ sinu rẹ, gbogbo aye isalẹ naa ni a si tẹ lori ba fun un, a da a nitori anfaani rẹ, ilẹ ati oke rẹ, awọn okun rẹ ati awọn odo sisan rẹ kékéké, awọn eso rẹ ati awọn irugbin rẹ, awọn ẹranko rẹ, ati gbogbo ohun ti o wa ninu rẹ; gẹgẹ bi Ọlọhun -giga ni fun Un- ti sọ pe:

} الله الذي خلق السموات والأرض وأنزل من السماء ماء فأخرج به من الثمرات رزقاً لكم وسخر لكم الفلك لتجري في البحر بأمره وسخر لكم الأنهار. وسخر لكم الشمس والقمر دائبين وسخر لكم الليل والنهار. وآتاكم من كل ما سألتموه وإن تعدوا نعمة الله لا تحصوها إن الإنسان لظلوم كفار { [سورة إبراهيم: 32-34].

« Ọlọhun ni Ẹni ti O sẹda awọn sanma ati ilẹ, O si N sọ omi kalẹ lati ara ẹsu-ojo, O si fi N mu awọn eso jade ni ipese fun yin, O si tun tẹ awọn ọkọ oju-omi lori ba fun yin, ki o le maa rin lori okun pẹlu asẹ Rẹ, O si tun tẹ awọn odo sisan kékéké lori ba fun yin. O si tun tẹ oorun ati osupa lori ba fun yin ti awọn mejeeji n lọ ni ọna wọn [laiduro], O si tẹ oru ati ọsan lori ba fun yin. O si fun yin ninu gbogbo ohun ti ẹ n tọrọ lọwọ Rẹ; ati pe ti ẹyin yoo ba ka idẹra Ọlọhun, ẹ kò le ka wọn tan, dajudaju eniyan jẹ alabosi alaimoore » [Suuratu Ibraahiim: 32-34]. Ati pe o n bẹ ninu pipe sise apọnle rẹ pe Ọlọhun da gbogbo ohun ti n bukaata ninu isẹmi rẹ ti ile-aye, ati ohun ti n bukaata ninu awọn nnkan ti yoo gbe e de awọn ipo ti o ga ju ni ile ikẹyin fun un; nitori naa O sọ awọn tira Rẹ kalẹ fun Un, O si ran awọn ojisẹ Rẹ si i, ti wọn n se alaye ofin Sharia Ọlọhun fun un, ti wọn si n pe e lọ sidi rẹ.

Lẹyin naa O da fun un lati ara rẹ -eyi ni pe lati ara Aadama, ki ọla Ọlọhun o maa ba a- iyawo kan ti yoo maa ri ifayabalẹ ni ọdọ rẹ, ti yoo si maa gbọ awọn bukaata adamọ rẹ -ti ẹmi ati ti laakaye ati ti ara- ti yoo fi maa ri isinmi ati ibalẹ-ọkan ati idurosinsin ni ọdọ rẹ, ati pe awọn mejeeji yoo maa ri ifayabalẹ, itẹlọrun, ifẹ, ati aanu ninu pipade wọn; tori pe a se akiyesi gbigbọ bukaata ẹnikọọkan wọn ni ara ẹni keji ninu agbegun ara ati ẹmi ati ọpọlọ awọn mejeeji, ati ipade awọn mejeeji nitori atipilẹ awọn iran tuntun, ati pe a fi awọn aanu ati awọn ifa-ọkan yii sinu ẹmi awọn mejeeji, ati pe a fi ifayabalẹ ẹmi ati ti ọpọlọ sinu ajọsepọ yii, ati isinmi fun ara ati ọkan, ati idurosinsin fun igbesi-aye ati isẹmi, ati fifamọra wọn awọn ẹmi ati awọn ọkan, ati ifayabalẹ fun ọkunrin ati obinrin ni dọgba-n-dọgba.

Ati pe Ọlọhun se adayanri awọn olugbagbọ-ododo laarin awọn ọmọ eniyan, O si se wọn ni ẹni-Rẹ, O lo wọn fun titẹle tiẸ, wọn sisẹ fun Un ni ibamu pẹlu ofin Sharia Rẹ, nitori ki wọn o le baa jẹ ẹni ti o tọ si wiwa ni ẹgbẹ Oluwa wọn ninu ọgba-idẹra -Al-janna- Rẹ. O se ẹsa awọn anabi ati awọn ojisẹ Rẹ ati awọn ẹni-Rẹ ati awọn ti wọn ku si ori atigbe ẹsin Rẹ ga -Shahiidi- ninu wọn, ati pe o ta wọn lọrẹ pẹlu eyi ti o ga ninu idẹra ti ẹmi maa n ri; eyi ti i se: Ijọsin fun Ọlọhun, ati titẹle tiẸ, ati biba A sọrọ ni jẹẹjẹ, O si tun se adayanri wọn pẹlu awọn idẹra nla kan -eyi ti ẹni ti o yatọ si wọn kò le e ri i- ninu rẹ ni aabo, ibalẹ-ọkan, ati oriire, koda eyi ti o tun tobi ju eleyii lọ ni pe wọn mọ otitọ ti awọn ojisẹ mu wa, wọn si gba a gbọ lododo, ati pe O gbe pamọ fun wọn -ni ile ikẹyin- ohun ti o tọ si apọnle Rẹ -mimọ ni fun Un- ninu idẹra ti ki i tan, ati ere nla; yoo fi san wọn lẹsan igbagbọ-ododo ti wọn ni si I, ati afọmọ wọn fun Un, koda yoo tun se alekun fun wọn ninu ajulọ Rẹ.

IPO OBINRIN

Obinrin de aaye kan ti o ga ninu ẹsin Islam, eyi ti o se pe ẹsin kan ti o siwaju kò [mu un] debẹ ri, ti ijọ kan ti n bọ kò si le e ba a, tori pe dajudaju apọnle ti Islam se fun eniyan kari ọkunrin ati obinrin ni odiwọn kan naa, nitori naa wọn dọgba niwaju awọn idajọ Ọlọhun ni ile-aye nibi, gẹgẹ bi o ti se jẹ pe wọn tun dọgba niwaju ẹsan Rẹ ati ere Rẹ ni ile ikẹyin. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ولقد كرمنا بني آدم { [سورة الإسراء: 70].

« Ati pe dajudaju Awa ti pọn awọn ọmọ Aadama le » [Suuratul Israa'i: 70]. Ọba ti O ga ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} للرجال نصيب مما ترك الوالدان والأقربون وللنساء نصيب مما ترك الوالدان والأقربون { [سورة النساء: 7].

« Awọn ọkunrin ni ipin ninu ohun ti awọn obi mejeeji ati awọn ibatan [wọn] fi silẹ [lẹyin iku], awọn obinrin naa si ni ipin ninu ohun ti awọn obi mejeeji ati awọn ibatan [wọn] fi silẹ [lẹyin iku] » [Suuratun-Nisaa'i: 7]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} ولهن مثل الذي عليهن بالمعروف { [سورة البقرة: 228].

« Awọn obinrin ni [lori awọn ọkọ wọn] iru ohun ti o jẹ ọranyan lori wọn [fun awọn ọkọ wọn] pẹlu daadaa » [Suuratul Baqarah: 228]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ pe:

} والمؤمنون والمؤمنات بعضهم أولياء بعض { [سورة التوبة: 71].

« Awọn onigbagbọ-ododo l'ọkunrin ati awọn olugbagbọ-ododo lobinrin, apa kan wọn jẹ ọrẹ apa keji » [Suuratut-Tawbah: 71]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وقضى ربك أن لا تعبدوا إلا إياه وبالوالدين إحساناً إما يبلغن عندك الكبر أحدهما أو كلاهما فلا تقل لهما أف ولا تنهرهما وقل لهما قولاً كريماً. واخفض لهما جناح الذل من الرحمة وقل رب ارحمهما كما ربياني صغيراً { [سورة الإسراء: 23، 24].

« Ati pe Oluwa rẹ pa a lasẹ wi pe: Ẹ kò gbọdọ jọsin fun nnkan mìíran yatọ si Oun nikan, ki ẹ si maa se daadaa si awọn obi [yin] mejeeji. Ti ọkan ninu wọn ba dagba si ọ lọwọ tabi awọn mejeeji, o kò gbọdọ se siọ wọn, o kò si gbọdọ jagbe mọ wọn, sugbọn ki o maa ba wọn sọrọ alapọnle. Ki o si rẹ ara rẹ silẹ fun wọn ni ti aanu, ki o si maa sọ pe: Oluwa kẹ awọn mejeeji gẹgẹ bi wọn ti re mi ni kekere » [Suuratu l-Israa'i :23, 24]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun wi pe:

} فاستجاب لهم ربهم أني لا أضيع عمل عامل منكم من ذكر أو أنثى { [سورة آل عمران: 195].

« Oluwa wọn si jẹ ipe wọn pe: Emi ki yoo fi isẹ ti ẹnikan ninu yin se rare rara, yala ọkunrin tabi obinrin » [Suuratu Aal Imraan: 195]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} من عمل صالحاً من ذكر أو أنثى وهو مؤمن فلنحيينه حياة طيبة ولنجزينهم أجرهم بأحسن ما كانوا يعملون { [سورة النحل: 97].

« Ẹnikẹni ti o ba se daadaa ni ọkunrin tabi obinrin ti o si jẹ olugbagbọ-ododo, dajudaju A O jẹ ki o lo igbesi-aye ti o dara, ati pe dajudaju A O san wọn ni ẹsan wọn pẹlu eyi ti o dara ju ohun ti wọn n se [nisẹ] lọ » [Suuratun-Nahl: 97]. Ọba ti O ga ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} ومن يعمل من الصالحات من ذكر أو أنثى وهو مؤمن فأولئك يدخلون الجنة ولا يظلمون نقيراً { [سورة النساء: 124].

« Ẹnikẹni ti o ba se daadaa ni ọkunrin tabi obinrin ti o si jẹ olugbagbọ-ododo, awọn wọnyi yoo wọ ọgba-idẹra -Al-janna- a ki yoo si se abosi ti o mọ bi eepo fẹlẹfẹlẹ ara koro dẹbinu kan fun wọn » [Suuratun-Nisaa'i: 124].

Ati pe apọnle ti obinrin ri ninu ẹsin Islam yii, kò ni afiwe ninu ẹsin kankan, tabi ilana kan, tabi ofin kan. Ọlaju ti awọn Roomu fi ọwọ si i pe ki obinrin o jẹ ẹru fun ọkunrin, kò si ni ẹtọ kankan bi i ti wu o ri, ati pe igbimọ nla kan se ipade ni Roomu, wọn si se iwadi nipa ọrọ obinrin, wọn si pari si ori pe nnkan kan ti kò ni ẹmi ni obinrin, ati pe eyi l'o mu un ma jogun isẹmi ti ikẹyin [ti ọrun], ati pe dajudaju ẹgbin ni i.

Ati pe ohun ti kò ni laari ni wọn ka obinrin si ni ilu Athens, n l'o mu wọn maa ta a, ti wọn si maa n ra a, ati pe ẹgbin kan ninu isẹ esu ni wọn ka a kun.

Bẹẹ naa ni awọn ofin India laelae gba pe: Arun ajakaye, iku, ina Jahiimi, oroo awọn ejo, ati ina, ni oore ju obinrin lọ; n l'o si mu ki ẹtọ rẹ ninu isẹmi o maa tan pẹlu titan ọjọ aye ọkọ rẹ -ẹni ti i se olowo rẹ- tori naa ti o ba ti ri ti wọn n jo oku ọkọ rẹ ni ina, nse ni yoo sọ ara rẹ si inu ina rẹ, ati pe ti o ba kọ lati se bẹẹ, wọn yoo ko isẹbi ya a.

Sugbọn obinrin ninu ẹsin awọn Yahuudi -Ju- dajudaju idajọ ti o wa nipa rẹ ninu Majẹmu Laelae lọ bayii pe: « Mo fi aiya mi si i lati mọ, on ati wadi, on ati se afẹri ọgbọn ati oye, on ati mọ iwa buburu were, ani ti were ati ti isinwin: Mo si ri ohun ti o koro ju iku lọ, ani obinrin ti aiya rẹ ise idẹkun ati awọn, ati ọwọ rẹ bi ọbara …» [Iwe Oniwasu, Ori: 7, Ẹsẹ: 25,26].

Eleyii ni bi obinrin ti ri ni aye atijọ, sugbọn ipo rẹ ni igba ti o wa ni agbedemeji ti atijọ ati ti iwoyi, ati ni ode-iwoyi, awọn isẹlẹ ti n bọ wọnyi yoo se afihan rẹ:

Olukọwe ọmọ Denmark Weith Kordsten se alaye ero sọọsi catholic si obinrin pẹlu ọrọ rẹ t'o ni: « Amojuto fun obinrin ilu oyinbo -Europe- ni aarin igba ti o wa ni agbedemeji ti atijọ ati ti iwoyi kere gan-an, ni ibamu pẹlu ero ilana ti catholic, eyi ti o ka obinrin kun ẹda ti o wa ni ipele keji ». Ipade kan waye ni France ni ọdun 586 A.D. ti n se iwadi nipa ọrọ obinrin, ati pe njẹ eniyan ni i, tabi ki i se eniyan? Lẹyin ifọrọwerọ awọn oni-ipade naa gba pe eniyan ni obinrin, sugbọn nse ni Ọlọhun da a nitori sisisẹ-sin ọkunrin. Ati pe ofin ti ọgọrun meji ati mẹtadinlogun ninu ofin France se alaye ohun ti n bọ yii:

« Obinrin ti o lọkọ -koda ki o se pe nini ọkọ rẹ duro lori ipilẹ sise ipinya laarin nnkan-ini rẹ ati nnkan-ini ọkọ rẹ- kò tọ fun un pe ki o bun eniyan ni ẹbun, ati pe kò tọ pe ki o si nnkan-ini rẹ nipo pada, tabi ki o dogo [nnkan kan], tabi ki o ni nnkan kan latari fifi nnkan mìíran rọpo rẹ, tabi lai kò fi nnkan kan rọpo rẹ, [kò tọ ki o se gbogbo eleyii] lai kò jẹ pe ọkọ rẹ lọwọ ninu ipinnu naa, tabi ifohunsi rẹ ni ifohunsi ti o jẹ kikọ ».

Ni England Henry kẹjọ se kika Iwe Mimọ ni eewọ fun obinrin England, ati pe awọn obinrin n bẹ titi ọdun 1850 A.D. l'ẹni ti wọn kò ka kun ọmọ orilẹ-ede, bẹẹ ni wọn n bẹ titi ọdun 1882 A.D. l'ẹni ti kò ni ẹtọ ọmọ eniyan kankan.

Sugbọn obinrin ode-iwoyi ni ilu oyinbo -Europe- ati Amẹrika ati ibomiran ti o yatọ si wọn ninu awọn ilu ti o ni imọ ẹrọ, ẹda alainiye lori kan ti a n lo fun itaja ni i, nitori pe ọkan l'o jẹ ninu awọn olupolongo ikede-ọja, koda ọrọ debi pe o bọra rẹ si ihoho, nitori ki wọn o le baa ko ọja naa si i niwaju ni adojukọ ipolongo ọja naa, ati pe wọn sọ ara rẹ, ati iyi rẹ, di ẹtọ pẹlu awọn eto kan ti awọn ọkunrin se lofin, nitori ki o le baa jẹ igbadun fun wọn ni gbogbo aye.

Ati pe wọn a maa ka a kun lopin igba ti o ba ti ni agbara lati fun'ni ati lati na ninu ọwọ rẹ, tabi ero rẹ, tabi ara rẹ, sugbọn nigba ti o ba dagba, ti o si se afẹku gbogbo eroja fifun'ni, awujọ naa pẹlu awọn ti o wa ninu rẹ ati awọn ile-isẹ rẹ yoo pa a ti, yoo si maa sẹmi ni oun nikan ninu ile rẹ tabi ni awọn ile iwosan ti awọn oni-idaamu ọpọlọ.

Fi eleyii we -kò tilẹ le dọgba- ohun ti o wa ninu Al-Qur'aani alapọnle ninu ọrọ Ọlọhun t'O ga, pe:

} والمؤمنون والمؤمنات بعضهم أولياء بعض { [سورة التوبة: 71].

« Awọn onigbagbọ-ododo l'ọkunrin ati awọn olugbagbọ-ododo lobinrin, apa kan wọn jẹ ọrẹ apa keji » [Suuratut-Tawbah: 71]. Ati ọrọ Ọba ti ẹyin Rẹ ga, t'o sọ pe:

} ولهن مثل الذي عليهن بالمعروف { [سورة البقرة: 228].

« Awọn obinrin ni [lori awọn ọkọ wọn] iru ohun ti o jẹ ọranyan lori wọn [fun awọn ọkọ wọn] pẹlu daadaa » [Suuratul Baqarah: 228]. Ọlọhun ti O ga, ti O si gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} وقضى ربك أن لا تعبدوا إلا إياه وبالوالدين إحساناً إما يبلغن عندك الكبر أحدهما أو كلاهما فلا تقل لهما أف ولا تنهرهما وقل لهما قولاً كريماً. واخفض لهما جناح الذل من الرحمة وقل رب ارحمهما كما ربياني صغيراً { [سورة الإسراء: 23، 24].

« Ati pe Oluwa rẹ pa a lasẹ wi pe: Ẹ kò gbọdọ jọsin fun nnkan mìíran yatọ si Oun nikan, ki ẹ si maa se daadaa si awọn obi [yin] mejeeji. Ti ọkan ninu wọn ba dagba si ọ lọwọ tabi awọn mejeeji, o kò gbọdọ se siọ wọn, o kò si gbọdọ jagbe mọ wọn, sugbọn ki o maa ba wọn sọrọ alapọnle. Ki o si rẹ ara rẹ silẹ fun wọn ni ti aanu, ki o si maa sọ pe: Oluwa kẹ awọn mejeeji gẹgẹ bi wọn ti re mi ni kekere » [Suuratu l-Israa'i :23, 24].

Ati pe nigba ti Oluwa rẹ se apọnle yii fun un, O se alaye fun gbogbo awọn eniyan lapapọ pe dajudaju Oun se ẹda rẹ nitori ki o le maa jẹ iya, aya, ati ọmọ-iya lobinrin, O si se awọn ofin Sharia ti o jẹ adayanri fun obinrin yatọ si ọkunrin nitori eleyii.

###

HIKMAH -ỌGBỌN- TI O WA NINU SISE ẸDA ENIYAN

Ọrọ ti siwaju ninu ẹsẹ ọrọ ti o siwaju pe dajudaju Ọlọhun da Aadama, O si da aya rẹ Hawwaa'u fun un, O si mu awọn mejeeji gbe inu ọgba-idẹra -Al-janna- lẹyin naa ni Aadama sẹ Oluwa rẹ, lẹyin eleyii ni o wa aforijin Rẹ, nitori naa O gba ironupiwada rẹ, O si fi ọna mọ ọn, O si pa a lasẹ pe ki o jade kuro ni ọgba-idẹra naa, ki o si sọ si ilẹ; Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- ni awọn Hikmah -ọgbọn- ninu eleyii ni ohun ti awọn laakaye yoo ko agara lati mọ, ti awọn ahọn yoo si ko aarẹ lati royin; ati pe a o se afihan nnkan kan ninu awọn ọgbọn wọnyi ninu awọn iwoye ti n bọ yii:

1- Pe Ọlọhun -mimọ ni fun Un- da ẹda nitori jijọsin fun Un, ati pe oun ni opin ohun ti o titori rẹ da a, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وما خلقت الجن والإنس إلا ليعبدون { [سورة الذاريات: 56].

« Ati pe N kò da awọn alujannu ati awọn eniyan afi nitori ki wọn o le baa maa jọsin fun Mi » [Suuratu z-Zariyaat :56]. Ohun ti a mọ si ni wi pe pipe ijọsin ti a n wa latari sise ẹda naa kò le e waye ni ile idẹra ati ile bibẹ ti kò ni opin, sugbọn nse ni yoo waye ni ile adanwo ati amiwo, sugbọn ile bibẹ ainipẹkun, ile igbadun, ati idẹra ni oun, ki i se ile adanwo ati ipanilasẹ.

2- Wi pe Ọlọhun -mimọ ni fun Un- fẹ lati yọ awọn anabi ati awọn ojisẹ ati awọn ẹni-Rẹ ati awọn Shahiidi kan ti yoo fẹran wọn, ti awọn naa yoo fẹran Rẹ, nitori naa o fi wọn silẹ pẹlu awọn ọta Rẹ, O si fi wọn se adanwo fun wọn, sugbọn nigba ti wọn fun Un lọla [lori ohun-kohun], ti wọn si na awọn ẹmi wọn ati awọn nnkan-ini wọn nitori iyọnu Rẹ ati ifẹ Rẹ, wọn ri ninu ifẹ Rẹ, ati iyọnu Rẹ ati sisunmọ ỌN, ohun ti a kò le e ri rara lai kò se bẹẹ. Tori naa ipo ojisẹ, ati ti anabi, ati ti kiku si oju-ọna atigbe ẹsin Ọlọhun ga, wa ninu awọn ipo ti o lọla ju ni ọdọ Ọlọhun, ati pe eniyan kò le e ri eleyii afi lati ara ọna ti Ọlọhun -mimọ ni fun Un- se ni idajọ yii; nipa sisọ Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ati awọn arọmọdọmọ rẹ kalẹ.

3- Wi pe Ọlọhun ni Ọba Otitọ ti O han; ati pe Ọba l'Ẹni ti I pasẹ, ti I si I kọ fun'ni, ti I si I san ni lẹsan, ti I si I jẹ ni ni iya ẹsa; bẹẹ ni A maa yẹpẹrẹ ẹni, A si maa pọn'ni le, A maa gbe'ni ga A si maa rẹ'ni silẹ, tori naa ijọba Rẹ -mimọ ni fun Un- se e ni idajọ pe ki O sọ Aadama ati awọn arọmọdọmọ rẹ si ile kan ti idajọ Ọba yoo ti maa jẹ lilo lori wọn, lẹyin naa ni yoo wa ko wọn kuro lọ si ile kan, ti yoo ti san wọn ni ẹsan lori awọn isẹ wọn.

4- Wi pe Ọlọhun da Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", lati ara ẹkunwọ kan lati inu gbogbo ilẹ, bẹẹ ni daadaa ati eyi ti kò dara n bẹ ninu ilẹ, lile ati ẹrọ si wa ninu rẹ pẹlu, nitori naa Ọlọhun -mimọ ni fun Un- mọ daju pe o wa ninu awọn arọmọdọmọ Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ẹni ti kò lẹtọ lati ba A gbe ile Rẹ, n ni O se sọ ọ kalẹ si ile kan ti yoo ti yọ ẹni-rere ati ẹni-buburu, lẹyin naa l'O wa ya wọn -mimọ ni fun Un- si ọtọọtọ pẹlu ile meji, nitori naa O se awọn ẹni-rere ni ẹni ẹgbẹ Rẹ ati oluba A gbe, O si se awọn ẹni-buburu ni ẹni-ile-oriibu, ile awọn ẹni-buburu.

5- Wi pe Ọlọhun -mimọ ni fun Un- ni awọn orukọ ti o dara ju, ninu awọn orukọ Rẹ si ni: Al-Gafuur: Alaforijin, Ar-Rahiim: Olukẹni, Al-Afuwwu: Alamojukuro, Al-Haliim: Alamumọra … dandan si ni ki awọn oripa awọn orukọ wọnyi o han, n ni Hikmah -ọgbọn- Rẹ -mimọ ni fun Un- se da a lẹjọ pe ki Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ati awọn arọmọdọmọ rẹ o sọ kalẹ si ile kan ti oripa awọn orukọ Rẹ ti o dara ju yoo ti han si wọn; ki O le maa se aforijin fun ẹni ti O ba fẹ, ki O si maa kẹ ẹni ti O ba fẹ, ki O si maa se amojukuro fun ẹni ti O ba fẹ, ki O si maa se afarada fun ẹni ti O ba fẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu hihan oripa awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.

6- Wi pe Ọlọhun da Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ati awọn arọmọdọmọ rẹ lati ara agbegun kan ti o gba rere ati aburu, ti o si rọ mọ olupepe ifẹkufẹ ọkan ati arito -Fitina- ati olupepe laakaye ati imọ, nitori naa Ọlọhun -mimọ ni fun Un- da laakaye ati ifẹkufẹ ọkan si i lara, O si gbe awọn mejeeji dide ni olupepe lọ sidi ohun ti wọn maa n bi nitori ki erongba Rẹ o le baa sẹ, ati nitori ki ogo Rẹ ninu ọgbọn Rẹ ati motomoto Rẹ o le baa han si awọn ẹru Rẹ, ati ikẹ Rẹ ati daadaa Rẹ ati aanu Rẹ ninu ijọba Rẹ ati akoso Rẹ; n ni ọgbọn Rẹ se da a lẹjọ pe ki O sọ Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ati awọn arọmọdọmọ rẹ kalẹ wa si ilẹ, nitori ki idanwo naa o le baa pe, ki awọn oripa ipalẹmọ eniyan fun awọn olupepe wọnyi ati jijẹ wọn nipe o le baa han, ati sise apọnle rẹ tabi titẹnbẹlu rẹ ni ibamu pẹlu eleyii.

7- Wi pe gbigba ohun ti o pamọ gbọ ni igbagbọ ti o sanfaani, sugbọn gbigba awọn ohun ti a n ri gbọ, gbogbo eniyan ni yoo gba a gbọ ni ọjọ igbende, iba se pe ile idẹra ni a da wọn si ni, wọn ki ba ti ri agbega nini igbagbọ si ohun ti o pamọ, eyi ti adun maa n kẹyin rẹ, ati apọnle ti i maa n sẹlẹ nitori nini igbagbọ si ohun ti o pamọ, eyi l'O mu Un sọ wọn kalẹ si ile kan ti aaye yoo ti wa fun nini igbagbọ wọn si ohun ti o pamọ.

8- Wi pe Ọlọhun -mimọ ni fun Un- fẹ lati ti ara eleyii mọ awọn ẹrusin Rẹ ti O se idẹra Rẹ le lori ni idẹra Rẹ ti o pe, ati odiwọn rẹ, ki wọn o le baa jẹ ẹni ti yoo tobi ju ni ifẹ ati ọpẹ, ati ẹni ti yoo tobi ju ni jijẹgbadun ohun ti O fun wọn ninu awọn idẹra naa, nitori naa Ọlọhun -mimọ ni fun Un- fi ohun ti O fi oju awọn ọta Rẹ ri, ati ohun ti o pese kalẹ fun wọn ninu iya han wọn, O si fi sise adayanri ti wọn pẹlu eyi ti o ga ju ninu awọn orisirisi idẹra han wọn, nitori ki idunnu wọn o le baa lekun, ki ayọ wọn o si le baa pe, ki idunnu wọn o si le baa tobi, n l'o mu ki eleyii o maa bẹ ninu pipe idẹra Rẹ ati ifẹ Rẹ lori wọn, n l'o mu un ma si aniani kan nipa sisọ wọn kalẹ wa si ilẹ, ati sise idanwo fun wọn ati sisa wọn lẹsa, ati fifi ẹni ti O ba fẹ ninu wọn se kongẹ ni ti ikẹ lati ọdọ Rẹ ati ajulọ, ti O si pa ẹni ti O ba fẹ ninu wọn ti ni ti Hikmah -ọgbọn- kan lati ọdọ Rẹ ati isedeedee. Oun ni Ọba Oni-mimọ, Ọlọgbọn.

9- Wi pe Ọlọhun fẹ ki Aadama “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" ati awọn arọmọdọmọ rẹ o pada si inu rẹ, ni igba ti awọn yoo wa ninu awọn ipo ti o dara ju, nitori naa o mu wọn tọ wahala ile-aye wo, ati ibanujẹ rẹ, ati idaamu rẹ, ati awọn isoro rẹ siwaju rẹ, ohun ti yoo mu ki bibabara wiwọ ibẹ wọn ni ile ikẹyin o tobi ni ọdọ wọn, nitori pe dajudaju daadaa atodijẹ ni i fi atodijẹ rẹ han.

Lẹyin ti mo ti se alaye ibẹrẹ eniyan tan, o dara pe ki a se alaye bukaata rẹ si ẹsin ododo.

###

BUKAATA AWỌN ENIYAN SI ẸSIN

Bukaata awọn eniyan si ẹsin tobi ju bukaata wọn si ohun ti o yatọ si i lọ ninu awọn ohun kò see ma ni ti isẹmi, tori pe dajudaju dandan ni ki eniyan o mọ awọn aaye iyọnu Ọlọhun -mimọ ni fun Un- ati awọn aaye ibinu Rẹ, ati pe dandan ni gbigbera-n-lẹ lati fa anfaani rẹ jẹ fun un, ati igbera-n-lẹ lati ti inira rẹ danu, bẹẹ ni ofin Sharia ni i maa n se iyatọ laarin awọn isẹ ti o se anfaani ati eyi ti i maa n ni'ni lara, oun si ni isedeedee Ọlọhun lori awọn ẹda Rẹ, ati imọlẹ Rẹ laarin awọn ẹru Rẹ. Nitori naa kò see se fun awọn eniyan lati sẹmi lai kò si ofin kan ti wọn yoo maa fi se iyatọ laarin ohun ti wọn o maa se ati ohun ti wọn o maa fi silẹ.

Nigba ti eniyan ba si ni erongba kan, dandan ni ki o mọ ohun ti n fẹ, ati pe njẹ alanfaani ni i fun un bi tabi aninilara? Sé yoo tun oun se ni, tabi yoo ba oun jẹ?. Bẹẹ ni apa kan ninu awọn eniyan le mọ eleyii pẹlu adamọ wọn, omiran wọn si le mọ ọn pẹlu wiwa ẹri fun lati ara laakaye wọn, ati pe apa kan wọn si le ma mọ ọn afi pẹlu afihan awọn ojisẹ, ati alaye wọn, ati ifinimọna wọn, fun wọn.

Tori naa gbogbo bi awọn ilana gbigba ohun ti a n ri nikan gbọ eyi ti o jẹ ti aigba Ọlọhun gbọ ba ti le wu ki o kọ to, ati bi o ti le wu ki wọn o se e lọsọ to, ati gbogbo bi awọn ero ati awọn aforihun o pọ to, wọn kò le e rọ onikaluku lọrọ kuro nidi ẹsin ti o dọgba rara, ati pe wọn kò le e gbọ awọn bukaata ẹmi, ati ti ara, koda bi eniyan ba ti n wọ inu ọgbun rẹ ni yoo maa mọ daju pe kò le e fi aabo ta oun lọrẹ, kò si le e tan ongbẹ oun fun oun, ati pe kò si ibusalọ kuro lọdọ rẹ yatọ si ẹsin otitọ. Aransat Riinaan sọ pe: « Dajudaju ohun ti o rọrun ni ki gbogbo ohun ti a fẹran o di ofoo, ki ominira lilo laakaye, ati imọ, ati rirọ nnkan o si bajẹ, sugbọn kò see se ki sise ẹsin o parẹ, koda yoo sẹku ni awijare ti n sọ nipa bibajẹ ilana gbigba ohun ti a ri nikan gbọ, eyi ti n fẹ lati se eniyan mọ inu awọn ihagaga aleebu ti isemi ori ilẹ »[[1]].

Muhammad Fariid Wajdi si sọ pe: « Kò see se ki ero sise ẹsin o parẹ, nitori pe dajudaju oun ni o ga ju ninu ohun ti ẹmi maa n fi lọ si ọdọ rẹ, ati eyi ti o ni apọnle ju ninu awọn aanu rẹ, ki a ma sẹsẹ ti i sọ nipa fifi ẹmi kan ti i maa n gbe eniyan lori soke, koda fifi yii yoo maa lekun, tori naa adamọ sise ẹsin yoo maa wa ba eniyan, lopin igba ti o ba ti jẹ onilaakaye, ti i fi n mọ ẹwa ati ailẹwa, ati pe adamọ yii yoo maa lekun ni ara rẹ ni odiwọn bi òye rẹ ba ti se n ga, ati bi imọ rẹ ba ti se n dagba »[[2]]..

Nitori naa ti eniyan ba jinna si Oluwa rẹ, bi òye rẹ ba ti ga to ati bi oferefe imọ rẹ ba ti fẹ to, ni yoo ti mọ bi aimọkan oun nipa Oluwa oun ti to ati ohun ti o jẹ ọranyan fun Un, ati aimọ nipa ara rẹ ati ohun ti yoo se e lanfaani ati ohun ti yoo ba a jẹ, ti yoo si mu un se oriire, ati eyi ti yoo mu un se oriibu, ati pe aimọkan rẹ nipa awọn eyi ti o wẹ ninu imọ ati awọn eyọkọọkan rẹ, gẹgẹ bi imọ awọn awowo ati ọna awọn irawọ, ati imọ ẹrọ ọlọpọlọ ati ibukorijọsi agbara ati ohun mìíran, igba yii ni awọn ẹda yoo pada kuro lati ipele ẹtanjẹ ati igberaga lọ si idi itẹriba ati igbafa, ti yoo si ni adisọkan pe Oni-mimọ, Ọlọgbọn kan N bẹ lẹyin awọn imọ, ati pe Ẹlẹda, Alagbara kan N bẹ lẹyin ẹda, ati pe ododo yii yoo mu ki oluse iwadi ti o jẹ oluse-dọgba o ni igbagbọ-ododo si ohun ti o pamọ ni dandan, yoo si mu un gbafa fun ẹsin ti o tọ, ati didahun ipe adamọ, ati imọ inu ti o jẹ ti adamọ … ati pe ti eniyan ba pa eleyii ti adamọ rẹ yoo bajẹ, yoo si subu si ipo ẹranko alailesọrọ.

Ati pe a o ri i mu jade ninu eleyii pe sise ẹsin -eyi ti o fi ẹyin ti sise Ọlọhun ni ọkan pẹlu Tawhiid, ati sisin IN ni ibamu pẹlu ohun ti O se lofin- ohun kò se e ma ni ni i fun isẹmi, nitori ki eniyan o le baa ti ara rẹ mu ijọsin rẹ fun Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda sẹ, ati nitori atiri oriire Rẹ, ati lila Rẹ, nibi iparun, wahala, ati oriibu ni ile mejeeji, ati pe ohun kò se e ma ni ni i fun pipe agbara ti ọpọlọ ninu eniyan; tori naa pẹlu rẹ nikan ni yoo fi ni laakaye ti yoo yo kikundun rẹ, ati pe lai kò si i, kò ni i le ri awọn ohun ilepa rẹ ti o ga ju.

Ohun ni ohun kò see ma ni fun sise afọmọ ẹmi, ati sise atunse agbara ọkan, nigba ti o se pe awọn aanu ti o dara a maa ri aaye ti o fẹ ninu ẹsin, ati ibumu ti orisun rẹ ki i gbẹ, eyi ti yoo ti maa ri ohun ti n wa.

Ohun ni ohun kò see ma ni lati pe agbara erongba, latari ohun ti yoo fi se atilẹyin fun un ninu awọn ohun ti i maa n mu ni gbera, ti i si maa n ta eniyan nidi kan; a si maa daabo bo wọn pẹlu awọn ohun ti a fi maa n se atako fun awọn ohun ti i maa n mu'ni sọ ireti nu, ti i si maa n mu'ni jakan.

Nipa bẹẹ, ti ẹnikan ba wa ti n sọ pe: Dajudaju olubániyànse ni eniyan ninu adamọ rẹ, o yẹ ki awa naa o sọ pe: « Dajudaju olusẹsin ni eniyan ninu adamọ rẹ ». Nitori pe agbara meji ni eniyan ni: Agbara imọ irori, ati agbara erongba, bẹẹ ni oriire rẹ ti o pe rọ mọ pipe agbara rẹ mejeeji, ti imọ, ati ti erongba. Ati pe pipe agbara imọ kò ni i sẹlẹ afi pẹlu mimọ ohun ti n bọ yii:

1- Mimọ Ọlọhun, Ẹlẹda, Olurọnilọrọ, Ẹni ti O da eniyan nigba ti kò jẹ nnkan kan, ti O si da idẹra Rẹ bo o.

2- Mimọ awọn orukọ Ọlọhun, ati awọn iroyin Rẹ, ati ohun ti o jẹ ọranyan fun Un -mimọ ni fun Un- ati oripa awọn orukọ wọnyi lori awọn ẹru Rẹ.

3- Mimọ ọna ti i maa n gbe eniyan lọ si ọdọ Rẹ -mimọ ni fun Un-.

4- Mimọ awọn ikuna ati awọn isoro ti i maa n di eniyan lọna atimọ ọna yii, ati ohun ti i maa n gbe eniyan lọ sidi rẹ ninu awọn idẹra nla.

5- Mimọ ẹmi ara rẹ ni paapaa mimọ, ati mimọ ohun ti n bukaata, ati ohun ti yoo tun un se tabi ti yoo ba a jẹ, ati mimọ ohun ti o se akojopọ rẹ ninu awọn daadaa ati awọn abuku.

Nitori naa pẹlu mimọ awọn nnkan marun-un yii ni eniyan yoo pe agbara rẹ ti imọ, ati pe pipe agbara ti imọ ati ti erongba kò le e sẹlẹ afi pẹlu sise amojuto awọn iwọ Ọlọhun -mimọ ni fun Un- lori ẹru, ati sise e ni ti afọmọ, ati ododo, ati isiti, ati titẹle ilana Rẹ, ati ni ti riri idẹra Rẹ ti O se le e lori, bẹẹ ni kò si ọna kan lati pe awọn agbara mejeeji yii afi pẹlu iranlọwọ Rẹ, nitori naa o ni bukaata lọ sidi pe ki O fi ọna mọ ọn lọ si oju-ọna ti o tọ, eyi ti o fi awọn ẹni-Rẹ mọna lọ sidi rẹ.

Lẹyin ti a ti mọ pe dajudaju ẹsin otitọ ni atilẹyin ti Ọlọhun fun ọlọkan-ọ-ọjọkan awọn agbara ti ẹmi, -bakan naa- ẹsin naa tun ni ẹwu irin ti i maa n daabo bo awujọ, idi ni pe isẹmi awọn eniyan kò le e duro afi lori iranra-ẹni-lọwọ laarin awọn ero rẹ, ati pe iranra-ẹni-lọwọ yii kò le e sẹlẹ afi pẹlu eto kan ti yoo maa to ajọsepọ wọn, ti yoo si maa la awọn ọranyan wọn; ti yoo si maa sọ awọn ẹtọ wọn, ati pe eto yii kò le e rọrọ kuro lọdọ ijọba kan ti o jẹ agbeni-nija, adẹrubani, ti yoo maa le ẹmi jinna si titẹ eto naa mọlẹ, ti yoo si maa se e ni ojukokoro nipa sisọ ọ, ti yoo si mu ki bibabara rẹ o bẹ ninu awọn ọkan, ti yoo si maa kọ titẹ awọn iyi rẹ mọlẹ. Njẹ ki ni ijọba yii? Mo fọ ẹsi pe: Kò si agbara kan lori ilẹ ti o fi agagbaga pẹlu agbara sise ẹsin, tabi ti o sunmọ ọn nipa sise onigbọwọ sise apọnle eto naa, ati sise agbatẹru ki awujọ o di mọra wọn, ki eto rẹ o si duro sinsin, ki awọn okunfa isinmi, ati ti ifayabalẹ o si papọ ninu rẹ.

Asiri eleyii ni pe eniyan yatọ si awọn ẹda ti n sẹmi yoku, nipa pe awọn isipopada rẹ ati awọn isesi rẹ eyi ti n se pẹlu ẹsa rẹ, nnkan kan ti kò se e gbọ, ti kò si se e ri ni n se oludari rẹ, nnkan naa kò si jẹ nnkan kan bi ko se adisọkan ti igbagbọ-ododo ti n se atunse ẹmi, ti i si n se afọmọ awọn orike. Nitori naa ẹni ti a n dari titi laelae pẹlu adisọkan ti o dara tabi eyi ti kò dara ni eniyan, tori naa ti adisọkan rẹ ba ti dara gbogbo nnkan ni yoo dara lara rẹ, ti o ba si bajẹ gbogbo nnkan l'o bajẹ.

Adisọkan, ati igbagbọ-ododo, mejeeji ni oluse-akiyesi ti ara ẹni, ati pe awọn mejeeji -gẹgẹ bi a ti n se akiyesi ni ara awọn eniyan lapapọ- orisi meji ni wọn:

- Nini igbagbọ si iyi ajulọ, ati apọnle eniyan, ati ohun ti o jọ bẹẹ ninu awọn itumọ ti o ga, eyi ti oju maa n ti awọn ẹmi ti o ga lati tako awọn ohun ti i maa n pe ni lọ sidi rẹ, koda bi a gba a kuro lọwọ awọn ọranyan ti ode, ati awọn isinmi ti nnkan ile-aye.

- Ati nini igbagbọ si Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- ati pe dajudaju Olufojusi awọn ohun ti o pamọ ni I, O mọ ikọkọ ati ohun ti o pamọ gan-an, ofin Sharia n gba agbara ijọba rẹ lati ara asẹ Rẹ ati kikọ Rẹ, ti awọn ifura si i maa n gbina pẹlu titiju Rẹ, yala ni ti nini ifẹ Rẹ tabi ni ti ibẹru Rẹ, tabi nitori mejeeji lapapọ … kò si si aniani pe iru igbagbọ yii ni o ni agbara ju ninu orisi mejeeji ni ijọba lori ẹmi eniyan, ati pe oun ni o le koko ju ninu mejeeji ni atako fun awọn iji lile ti ifẹkufẹ ọkan ati yiyipada awọn igbọrandun ọkan, bẹẹ ni oun ni o yara wọle ju si awọn ọkan gbogbo eniyan ati ti awọn ẹni-pataki.

Nitori idi eleyii ni ẹsin se jẹ abaya-gbaagbaa ti o loore ju fun dide ibasepọ laarin awọn eniyan lori awọn ofin isedeedee ati ododo, eyi l'o si mu un jẹ ohun ti kò see ma ni fun awujọ; nitori naa kò si iyalẹnu ti ẹsin ba bọ si aaye ọkan ninu ara lara ijọ.

Ati pe ti ẹsin lapapọ ba jẹ ohun ti o ni ipo yii, ti o si jẹ pe ohun ti a n ri ni oni yii ni pipọ awọn ẹsin ati awọn ilana ninu ile-aye yii, ati pe o ri pe gbogbo ijọ kọọkan n dunnu pẹlu ohun ti wọn ni lẹsin, wọn si n di i mu, njẹ ewo ni ẹsin otitọ, eyi ti yoo mu ki ẹmi eniyan o ri ohun ti n wa? Ati pe ki ni awọn ofin ti yoo mu ni mọ ẹsin otitọ?.

###

AWỌN OFIN TI YOO MU ENIYAN MỌ ẸSIN OTITỌ

Gbogbo oni-ilana kan a maa ni adisọkan pe ilana oun ni otitọ, ati pe gbogbo awọn olutẹle ẹsin kan a maa ni adisọkan pe ẹsin awọn ni ẹsin ti o dara ju, ati ọna ti o duro sinsin ju. Ati pe nigba ti o ba bi awọn olutẹle awọn ẹsin eke, tabi awọn olutẹle awọn ilana ti eniyan, ti o jẹ atọwọda leere nipa ẹri lori awọn adisọkan wọn; wọn yoo maa se ẹri pẹlu pe awọn ba awọn baba awọn lori oju-ọna kan, ori awọn oripa wọn si ni awọn n tọ, lẹyin naa wọn a maa sọ awọn itan kan, ati awọn iroyin kan ti ọna ti wọn gba wa kò gun rege; ati pe awọn ohun ti wọn ko sinu kò bọ lọwọ awọn abuku ati alebu, wọn a si maa gbe ara le awọn iwe kan ti wọn jogun, eyi ti a kò mọ ẹni ti o sọ ọ [lọrọ], tabi ẹni ti o kọ ọ, tabi ede wo ni wọn fi kọ ọ ni akọkọ, tabi ilu wo ni a ti ri i; kò tilẹ jẹ nnkan kan bi kò se ohun ti a ropọ mọra wọn, ti a wa kojọ, ti o wa tobi, ti awọn ti wọn de lẹyin si jogun rẹ, lai kò se iwadi-ijinlẹ kan ti yoo mu'ni mọ ọna ti o gba wa, ti yoo si se ayẹwo ohun ti o ko sinu.

Ati pe awọn iwe ti a kò mọ nipa wọn wọnyi, ati awọn iroyin, ati awokọse ti afọju yii, kò tọ ki o jẹ awijare ninu ọrọ awọn ẹsin, ati awọn adisọkan. Tori naa njẹ ohun otitọ ni gbogbo awọn ẹsin eke, ati awọn ilana ti o jẹ ti awọn eniyan wọnyi, tabi ibajẹ?.

Kò see se ki o jẹ pe gbogbo rẹ wa lori otitọ, nitori pe ọkan soso ni otitọ, ki i pọ, bẹẹ ni kò see se pe ki gbogbo awọn ẹsin eke, ati awọn ilana ti o jẹ ti eniyan wọnyi o jẹ pe lati ọdọ Ọlọhun ni wọn ti wa, tabi ki o jẹ ododo; tori naa ti awọn ẹsin ba pọ -ti otitọ si jẹ ọkan- njẹ ewo ninu rẹ ni otitọ? Tori idi eleyii, dandan ni ki a mọ awọn ofin kan ti a o maa fi mọ ẹsin ododo yatọ si ẹsin ibajẹ, nitori naa ti a ba ti ri awọn ofin wọnyi ti o dọgba lori ẹsin kan, a o mọ daju pe oun ni otitọ, ati pe ti awọn ofin wọnyi, tabi ọkan ninu wọn ba ti daru lori ẹsin kan, a o mọ daju pe ibajẹ ni i.

Awọn ofin ti a o maa fi mọ iyatọ laarin ẹsin otitọ ati ẹsin ibajẹ:

Alakọkọ ni pe: Ki ẹsin naa o jẹ pe ọdọ Ọlọhun l'o ti wa, ki O sọ ọ kalẹ gba ọwọ malaika kan ninu awọn malaika Rẹ, fun ojisẹ kan ninu awọn ojisẹ Rẹ, ki o le baa fi jisẹ fun awọn ẹru Rẹ; nitori pe ẹsin otitọ ni ẹsin Ọlọhun, ati pe Ọlọhun -mimọ ni fun Un- ni Ẹni ti I maa N san ni lẹsan, ti yoo si se isiro fun awọn ẹda ni ọjọ igbende lori ẹsin ti O sọ kalẹ fun wọn. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إنا أوحينا إليك كما أوحينا إلى نوح والنبيين من بعده وأوحينا إلى إبراهيم وإسماعيل وإسحاق ويعقوب والأسباط وعيسى وأيوب ويونس وهارون وسليمان وآتينا داوود زبوراً { [سورة النساء: 163].

« Dajudaju Awa ransẹ si ọ gẹgẹ bi a ti se ransẹ si Nuuhu, ati awọn anabi lẹyin rẹ, A si tun ransẹ si Ibraahiim, ati Ismaa'i'iil, ati Ishaaq, ati Ya'aquub, ati awọn arọmọdọmọ [rẹ], ati Isa, ati Ayyuub, ati Yuunus, ati Haaruun, ati Sulaiman, A si fun Daawuuda ni Zabuura » [Suuratun-Nisaa'i: 163]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ pe:

} وما أرسلنا من قبلك من رسول إلا نوحي إليه أنه لا إله إلاَّ أنا فاعبدون { [سورة الأنبياء: 25].

« Ati pe Awa kò ran ojisẹ kan nisẹ siwaju rẹ, afi ki A ransẹ si i pe dajudaju kò si ọba kan ti o tọ lati jọsin fun lododo yatọ si Emi, nitori naa ẹ maa sin Mi » [Suuratul-Anbiyaa': 25]. Lori eleyii, ẹsin yowu ti ẹnikan ba mu wa, ti o si fi i ti si ọdọ ara rẹ yatọ si ọdọ Ọlọhun, kò si ibuyẹsi pe ẹsin ibajẹ ni i.

Ẹlẹẹkeji ni: Ki o maa pepe lọ sidi sise Ọlọhun -mimọ ni fun Un- ni ọkan soso ninu ijọsin, ati sise ẹbọ sise si Ọlọhun ni eewọ, ati sise awọn okunfa ti i maa n fa ni lọ sidi rẹ leewọ, tori pe ipepe lọ sidi sise Ọlọhun ni àásó -Tawhiid- ni ipilẹ ipepe gbogbo awọn anabi ati awọn ojisẹ, ati pe gbogbo anabi kọọkan l'o sọ fun awọn ijọ rẹ pe:

} اعبدوا الله ما لكم من إله غيره { [سورة الأعراف: 73].

« Ẹ maa sin Ọlọhun, ẹ kò ni ọlọhun kan yatọ si I » [Suuratul Aaraaf: 73]. Nitori naa ẹsin yowu ti o se akojọpọ sise ẹbọ si Ọlọhun sinu, ti o si n fi ẹni ti o yatọ si Ọlọhun bi anabi kan, tabi malaika kan, tabi woli kan, se orogun fun Un, ẹsin ibajẹ ni i, koda bi awọn ẹni ti n se e fi ara wọn ti si ọdọ anabi kan ninu awọn anabi.

Ẹlẹẹkẹta ni: Ki o jẹ ohun ti o dọgba pẹlu awọn ipilẹ ti awọn ojisẹ Ọlọhun pepe lọ sidi rẹ; ninu ijọsin fun Ọlọhun ni Oun nikan, ati ipepe lọ si oju-ọna Rẹ, ati sise ẹbọ sise ni eewọ, ati sisẹ awọn obi mejeeji, ati pipa ẹmi lai tọ ọ, ati sise awọn ibajẹ ni eewọ; eyi ti o han ninu rẹ ati eyi ti o pamọ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

}وما أرسلنا من قبلك من رسول إلا نوحي إليه أنه لا إله إلاَّ أنا فاعبدون { [سورة الأنبياء: 25].

« Ati pe Awa kò ran ojisẹ kan nisẹ siwaju rẹ, afi ki A ransẹ si i pe dajudaju kò si ọba kan ti o tọ lati jọsin fun lododo yatọ si Emi, nitori naa ẹ maa sin Mi » [Suuratul-Anbiyaa': 25]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} قل تعالوا أتل ما حرم ربكم عليكم ألاّ تشركوا به شيئاً وبالوالدين إحسانا ولا تقتلوا أولادكم من إملاق نحن نرزقكم وإياهم ولا تقربوا الفواحش ما ظهر منها وما بطن ولا تقتلوا النفس التي حرم الله إلا بالحق ذلكم وصاكم به لعلكم تعقلون{ [سورة الأنعام: 151].

« Sọ pe: Ẹ wa ki n ka ohun ti Oluwa yin se leewọ le yin lori -fun yin- pe: Ẹ kò gbọdọ fi nnkan kan se orogun pẹlu Rẹ, ki ẹ si maa se daadaa si awọn obi [yin] mejeeji, ẹ kò si gbọdọ maa pa awọn ọmọ yin nitori osi, Awa ni A O maa pese fun ẹyin ati awọn, ẹ si ma se maa sun mọ awọn ibajẹ eyi ti o han ninu wọn ati eyi ti o pamọ; ẹ si ma se maa pa ẹmi ti Ọlọhun se pipa rẹ leewọ afi pẹlu ododo, awọn wọnyi ni O fi pa yin lasẹ; ki ẹ le baa se laakaye » [Suuratu l'An'aam :151]. Ọlọhun t'O ga tun sọ pe:

} واسأل من أرسلنا من قبلك من رسلنا أجعلنا من دون الرحمن آلهة يعبدون { [سورة الزخرف: 45].

« Si beere ni ọdọ awọn ti A ti ran nisẹ siwaju rẹ ninu awọn ojisẹ Wa. Njẹ Awa wa se ọlọhun mìíran kan lẹyin Ọba Alaanujulọ ti wọn yoo maa sin bi? » [Suuratuz Zukhruf: 45].

Ẹlẹẹkẹrin ni: Ki o ma jẹ ohun ti o tako ara rẹ, ki apa kan rẹ o si ma se jẹ ohun ti o yapa si omiran, nitori naa ki o ma se pa nnkan kan lasẹ, lẹyin naa ki o tu u ka pẹlu asẹ mìíran, ki o si ma se nnkan kan leewọ, lẹyin naa ki o se ohun ti o jọ ọ ni ẹtọ lai kò nidi, ki o si ma se se nnkan kan ni eewọ, tabi ki o se e ni ẹtọ fun awọn eniyan kan, lẹyin naa ki o se e ni eewọ fun awọn mìíran. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} أفلا يتدبرون القرآن ولو كان من عند غير الله لوجدوا فيه اختلافاً كثيراً { [سورة النساء: 82].

« Wọn kò wa ni ronu nipa Al-Qur'aani ni? Bi o ba jẹ pe lati ọdọ ẹni ti o yatọ si Ọlọhun l'o ti wa ni, dajudaju wọn o ba ri ọpọlọpọ iyapa-ọrọ ninu rẹ » [Suuratun-Nisaa'i: 82].

Ẹlẹẹkarun-un ni: Ki ẹsin naa o se akojọpọ ohun ti yoo maa sọ ẹsin awọn eniyan, iyi wọn, nnkan-ini wọn, awọn ẹmi wọn, ati awọn arọmọdọmọ wọn fun wọn, pẹlu ohun ti n se ni ofin ninu awọn asẹ ati awọn ohun ti n kọ, ati awọn ihanileti [rẹ], ati awọn iwa ti yoo maa sọ awọn ohun akotan marun-un wọnyi.

Ẹlẹẹkẹfa ni: Ki ẹsin naa o jẹ ikẹ fun awọn ẹda nibi abosi awọn ẹmi wọn, ati abosi apa kan wọn si omiran, yala abosi yii jẹ ti titẹ awọn ẹtọ mọlẹ ni o, tabi dida gbe ọwọ le awọn oore, tabi pẹlu ki awọn ẹni-nla o maa si awọn ẹni-yẹpẹrẹ lọna, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ l'Ẹni ti N fun'ni niroyin nipa aanu ti Tawraata -Majẹmu Laelae- ti O sọ kalẹ fun Musa “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" kojọ sinu pe:

} ولما سكت عن موسى الغضب أخذ الألواح وفي نسختها هدى ورحمة للذين هم لربهم يرهبون { [سورة الأعراف: 154].

« Nigba ti ibunu naa si rọlẹ fun Musa, o gbe awọn walaa naa, imọna ati aanu si n bẹ ninu akọsilẹ rẹ fun awọn ẹni ti wọn n bẹru Oluwa wọn» [Suuratul-A'araaf: 154]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ l'Ẹni t'O N fun'ni niroyin nipa riran Anabi Isa “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" nisẹ pe:

} ولنجعله آية للناس ورحمة { [سورة مريم: 21].

« Ati nitori ki A le baa se e ni arisami fun awọn eniyan ati aanu » [Suuratu Maryam: 21]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ nipa Anabi Saalih, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", pe:

} قال يا قوم أرأيتم إن كنت على بينة من ربي وآتاني منه رحمة { [سورة هود: 63].

« O sọ pe: Ẹyin eniyan mi, Ẹ fun mi niroyin, njẹ ti mo ba jẹ ẹni ti o wa lori alaye lati ọdọ Oluwa mi, ti O si fun mi ni ikẹ lati ọdọ Rẹ..? » [Suuratu Huud: 63]. Ọlọhun ti O ga ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} وننـزل من القرآن ما هو شفاء ورحمة للمؤمنين { [سورة الإسراء: 82].

« Awa N sọ ohun ti o jẹ iwosan kalẹ ninu Al-Qur'aani ati ikẹ fun awọn onigbagbọ-ododo » [Suuratul-Israa'i: 82].

Ẹlẹẹkeje ni: Ki o se akojọpọ ifinimọna lọ sidi ofin Ọlọhun, ati fifi eniyan mọna lọ sidi erongba Ọlọhun lori rẹ, ati fifun un ni iroyin nipa ibo l'o ti wa, ati pe ibo ni ibupadasi rẹ? Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ l'Ẹni ti N fun'ni niroyin nipa Tawraata -Majẹmu Laelae- pe:

} إنا أنزلنا التوراة فيها هدى ونور ... { [سورة المائدة: 44].

« Dajudaju Awa ti sọ At-Tawraata kalẹ, imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ » [Suuratul-Maa'idah: 44]. Ọlọhun ti ọrọ Rẹ ga, tun sọ nipa Injiila -Bibeli- pe:

} وآتيناه الإنجيل فيه هدى ونور { [سورة المائدة: 46].

« Awa si fun un ni Injiila -Bibeli- imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ » [Suuratul-Maa'idah: 46]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ nipa Al-Qur'aani alapọnle pe:

} هو الذي أرسل رسوله بالهدى ودين الحق { [سورة التوبة: 33].

« Oun ni Ẹni ti O ran Ojisẹ Rẹ pẹlu imọna, ati ẹsin ododo » [Suuratut-Tawbah: 33]. Ati pe ẹsin otitọ ni eyi ti o se akojọpọ ifinimọna lọ sidi ofin Ọlọhun, ti yoo si maa mu ki ẹmi o ni aabo, ati ifayabalẹ, nigba ti o se pe yoo maa le gbogbo iroyiroyi jinna si i, ti yoo si maa fọ esi gbogbo ibeere, ti yoo si maa se alaye gbogbo ohun ti o ru ti i ru'ni loju.

Ẹlẹẹkẹjọ ni: Ki o maa pepe lọ sidi awọn iwa, ati isẹ alapọnle, gẹgẹ bi otitọ, isedọgba, ifọkantan, ati itiju, ati sisọ abẹ, ati lilawọ, ki o si maa kọ awọn ti kò dara wọn, gẹgẹ bi sisẹ awọn obi mejeeji, ati pipa ẹmi, ati sise awọn ibajẹ ni eewọ, ati irọ, ati abosi, ati agbere, ati ahun, ati ẹsẹ.

Ẹlẹẹkẹsan ni: Ki o mu oriire sẹlẹ si ẹni ti o ba gba a gbọ, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} طه. ما أنزلنا عليك القرآن لتشقى { [سورة طه: 1-2].

« Tọọ Haa. A kò sọ Al-Qur'aani yii kalẹ fun ọ nitori ki o le ba se oriibu » [Suuratu Tọọ Haa: 1-2]. Ki o si jẹ ohun ti o se deedee pẹlu adamọ ti o dara:

} فطرت الله التي فطر الناس عليها { [سورة الروم: 30].

« Adamọ Ọlọhun eyi ti O pilẹ da awọn eniyan le lori » [Suuratur-Ruum: 30]. Ki o si se deedee pẹlu laakaye ti o gbadun, nitori pe ẹsin otitọ ni ofin Ọlọhun, bẹẹ ni laakaye ti o gbadun ni ẹda Ọlọhun, ohun ti kò si see se ni ki ofin Ọlọhun o yapa si ẹda Rẹ.

Ẹlẹẹkẹwa ni: Ki o maa tọka si ododo, ki o si maa se ikilọ nibi ibajẹ, ki o si maa se amọna lọ sidi imọna, ki o si maa le'ni nibi anu, ki o si maa pe awọn eniyan lọ si oju-ọna ti o tọ, ti kò si lilọpọ ninu rẹ, tabi aitọ; Ọlọhun t'O ga sọ l'Ẹni ti N fun'ni niro nipa awọn alujannu, pe nigba ti wọn gbọ Al-Qur'aani, apa kan wọn sọ fun apa kan, pe:

} يا قومنا إنا سمعنا كتاباً أنزل من بعد موسى مصدقاً لما بين يديه يهدي إلى الحق وإلى صراط مستقيم { [سورة الأحقاف: 30].

« Ẹyin eniyan wa, dajudaju awa gbọ tira kan ti a sọ kalẹ lẹyin Musa, ti o n jẹri ododo fun ohun ti o ti siwaju rẹ, o n fi'ni mọna lọ sibi otitọ ati si oju-ọna ti o tọ » [Suuratul-Ahqaaf: 30]. Nitori naa kò ni i maa pe wọn lọ sibi ohun ti oriibu wọn wa ninu rẹ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} طه. ما أنزلنا عليك القرآن لتشقى { [سورة طه: 1-2].

« Tọọ Haa. A kò sọ Al-Qur'aani yii kalẹ fun ọ ki o le ba se oriibu » [Suuratu Tọọ Haa: 1-2]. Kò si gbọdọ maa pa wọn lasẹ pẹlu ohun ti iparun wọn wa ninu rẹ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ولا تقتلوا أنفسكم إن الله كان بكم رحيماً { [سورة النساء: 29].

« Ẹ kò si gbọdọ pa ara yin, dajudaju Ọlọhun jẹ Alaanu si yin » [Suuratun-Nisaa'i: 29]. Kò si gbọdọ maa se iyatọ laarin awọn olutẹle e, latari ẹya, tabi awọ, tabi iran [wọn]. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} يا أيها الناس إنا خلقناكم من ذكر وأنثى وجعلناكم شعوباً وقبائل لتعارفوا إن أكرمكم عند الله أتقاكم إن الله عليم خبير { [سورة الحجرات: 13].

« Ẹyin eniyan dajudaju Awa se ẹda yin lati ara ọkunrin ati obinrin kan, A si se yin ni ẹya ati oniran-ran, ki ẹ le baa maa mọ ara yin. Dajudaju ẹni ti o ni apọnle ju ninu yin lọdọ Ọlọhun ni ẹni ti n paya [Rẹ] ju ninu yin, dajudaju Ọlọhun ni Oni-mimọ, Oni-mimọ nipa gbogbo nnkan » [Suuratul-Hujraat: 13]. Nitori naa osunwọn ti a kakun fun sise ajulọ ninu ẹsin otitọ ni ibẹru Ọlọhun.

Lẹyin ti a ti se afihan awọn ofin ti o maa fi se iyatọ laarin ẹsin otitọ ati ẹsin ibajẹ -ti mo si ti fi ohun ti o wa ninu Al-Qur'aani alapọnle se ẹri-ọrọ fun un ninu ohun ti n tọka si awọn ofin wọnyi lapapọ fun awọn ojisẹ ti wọn jẹ olododo, awọn ti a ran lati ọdọ Ọlọhun- nitori naa ninu ohun ti o dọgba ni ki a se afihan awọn ipin awọn ẹsin.

###

AWỌN IPIN AWỌN ẸSIN

Ọna meji ni awọn eniyan pin si ni ibamu pẹlu awọn ẹsin wọn:

Apa kan ni iwe kan, ti a sọ kalẹ lati ọdọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Yahuudi -Ju- ati awọn alagbelebu -Christians- ati awọn Musulumi, nitori naa latari aisisẹ awọn Yahuudi -Ju- ati awọn alagbelebu -Christian- pẹlu ohun ti o wa ninu awọn iwe wọn, ati nitori mimu ti wọn mu awọn eniyan ni awọn oluwa lẹyin Ọlọhun, ati nitori pipẹ ti igba pẹ … awọn iwe wọn ti Ọlọhun sọ kalẹ fun awọn anabi wọn sọnu, nitori naa awọn olumọ wọn kọ awọn iwe kan fun wọn, ti wọn purọ pe ọdọ Ọlọhun ni wọn ti wa, sugbọn ti o se pe ki i se ọdọ Ọlọhun l'o ti wa, afọpọlọhun awọn asebajẹ, ati yiyi ọrọ pada awọn olutayọ-aala lasan ni i.

Sugbọn iwe awọn Musulumi [Al-Qur'aani alapọnle] oun ni opin awọn tira Ọlọhun nipa dide, oun si ni o nipọn ni tita ni koko, Ọlọhun si se agbatẹru sisọ rẹ, ati pe kò fi eleyii ti si ọdọ awọn eniyan; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} إنا نحن نزلنا الذكر وإنا له لحافظون { [سورة الحجر: 9].

« Dajudaju Awa ni a sọ iranti naa kalẹ, ati pe dajudaju Awa ni Olusọ rẹ » [Suuratul-Hijr: 9]. Nitori naa ohun ti a sọ sinu awọn igbaaya ati si inu awọn iwe ni i se, tori pe oun ni iwe ikẹyin, eyi ti Ọlọhun se akojọpọ imọna fun eniyan si inu rẹ, O si se e ni awijare le wọn lori titi di ọjọ igbende, O si kọ akọọlẹ sisẹku fun un, O si pese awọn ti yoo maa pa awọn ofin rẹ mọ, ti wọn yoo si maa gbe awọn harafi rẹ duro fun un ni gbogbo igba, ti wọn yoo si maa sisẹ pẹlu ofin rẹ, ti wọn yoo si gba a gbọ ni ododo; ati pe alekun alaye nipa iwe alapọnle yii yoo wa laipẹ ninu ẹsẹ ọrọ kan ti n bọ.

Ipin kan kò si ni iwe kan, ti a sọ kalẹ lati ọdọ Ọlọhun, bi o tilẹ jẹ pe wọn ni iwe kan ti wọn n jogun lọwọ ara wọn, ti wọn n fi i ti si ọdọ ẹni ti o ni ẹsin wọn; gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin Hindu, ati awọn Majuusi -olusin-ina- ati awọn ẹlẹsin Budda ati awọn ọmọlẹyin kunfuushisiin, ati gẹgẹ bi awọn Larubaawa siwaju ki a to gbe Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" dide.

Ati pe kò si ijọ kan afi ki o jẹ pe wọn ni imọ kan, ati isẹ kan, ni odiwọn ohun ti yoo mu wọn maa ri awọn anfaani wọn ti ile-aye, bẹẹ ni eyi wa ninu ifinimọna ti gbogbogboo, eyi ti Ọlọhun se fun gbogbo eniyan, koda fun gbogbo ẹranko, gẹgẹ bi I ti I maa N fi ọna mọ ẹranko lọ sibi fifa ohun ti yoo se e ni anfaani ninu ounjẹ, ati ohun mimu, ati titi ohun ti yoo ni i lara danu, ati pe dajudaju Ọlọhun ti se ẹda ifẹ eleyii, ati ikorira t'ọhun si i lara, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} سبح اسم ربك الأعلى. الذي خلق فسوى. والذي قدر فهدى { [سورة الأعلى: 1-3].

« Se afọmọ orukọ Oluwa rẹ, Ọba Olugaju. Ẹni ti O da ẹda ti O si se e ni dọgba. Ẹni ti O si pebubu [ẹda] ti O si fi i mọna » [Suuratul-A'alaa: 1-3]. Anabi Musa “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" si sọ fun Fir'auna, pe:

} ربُّنا الذي أعطى كل شيء خلقه ثم هدى { [سورة طه: 50].

« Oluwa wa ni Ẹni ti O se ẹda gbogbo nnkan, lẹyin naa ti O tọ ọ sọna » [Suuratu Tọọ Haa: 50]. Anabi Ibraahiim, Al-Khaliil, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", sọ pe:

} الذي خلقني فهو يهدين { [سورة الشعراء: 78].

« Ẹni ti O da mi, Oun ni yoo fi ọna mọ mi » [Suuratu Shu'araa': 78]. O si n bẹ ninu ohun ti o ye gbogbo onilaakaye -ti o ni iwoyesi ati akiyesi ti o kere ju- pe dajudaju awọn olorisirisi ẹsin ni wọn pe ninu awọn imọ ti o sanfaani, ati awọn isẹ rere, ju awọn ti wọn ki i se ẹlẹsin lọ, kò si si ohun kan ninu oore ti o wa ni ọdọ awọn ti ki i se Musulumi ninu awọn olorisirisi ẹsin, afi ki o jẹ pe awọn Musulumi ni ohun ti o pe ju u lọ, bẹẹ ni awọn ẹlẹsin ni ohun ti kò si ni ọdọ ẹni ti o yatọ si wọn; idi eleyii ni pe dajudaju orisi meji ni awọn imọ, ati awọn isẹ:

Orisi kinni: A maa sẹlẹ pẹlu laakaye, gẹgẹ bi imọ isiro, ati ti iwosan, ati ti ẹrọ, bi awọn nnkan wọnyi ti ri ni ọdọ awọn ẹlẹsin gbogbo, ni o ri ni ọdọ awọn ti wọn ki i se ẹlẹsin, koda awọn ẹlẹsin pe ju ninu wọn, sugbọn ohun ti kò see fi laakaye lasan mọ, gẹgẹ bi mimọ nipa Ọlọhun, ati mimọ nipa awọn ẹsin, ohun adayanri ni eleyii jẹ fun awọn ẹlẹsin, ati pe ohun ti a le fi laakaye se ẹri fun wa ninu eleyii, bẹẹ ni awọn ojisẹ fi ọna mọ awọn eniyan, wọn si tọka fun wọn lọ sidi bi awọn laakaye ti se se ẹri lori eleyii, nitori naa imọ laakaye ati ti ofin Sharia ni i.

Orisi keji: Ohun ti a kò le e mọ afi pẹlu iroyin awọn ojisẹ, -kò si ọna kan ti a le gba ri eleyii ninu awọn ọna lakaaye- gẹgẹ bi iroyin nipa Ọlọhun, ati awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ, ati ohun ti o wa ni ile ikẹyin ninu awọn idẹra, fun ẹnikẹni ti o ba tẹle tiẸ, ati iya fun ẹnikẹni ti o ba sẹ Ẹ, ati alaye ofin Rẹ, ati iroyin awọn anabi ti wọn siwaju pẹlu awọn ijọ wọn; ati bẹẹ bẹẹ lọ.

IPO AWỌN ẸSIN TI N BẸ

Awọn ẹsin ti o tobi ju, ati awọn iwe wọn laelae, ati awọn ofin wọn ti o ti pẹ, ti di ohun ti a n dẹdẹ rẹ fun awọn onibajẹ, ati awọn alarekare, ati ohun ere fun awọn oluyi-nnkan-pada, ati awọn alagabangebe, o si ti di ohun ti n kọlu awọn isẹlẹ ẹlẹjẹ, ati awọn ewu nla, titi ti wọn fi se afẹku ẹmi, ati awọ wọn, iba se pe a gbe awọn ẹlẹsin naa ti akọkọ dide ni, ati awọn anabi wọn ti a n ran nisẹ, dajudaju wọn o ba tako wọn, wọn o ba si se aimọ nipa wọn.

Ẹsin Yahuudi -ni oni- ti di akojopọ awọn ilana-isin ati awọn asa kan ti kò si ẹmi kan ninu rẹ, tabi isẹmi, ati pe -ti a ba tun mu eyi ti a wi yii kuro nibẹ- ẹsin awọn arọmọdọmọ kan ni i ti o jẹ ohun adayanri fun awọn ijọ kan, ati fun ẹya kan pataki, kò ni isẹ kankan jẹ fun aye, bẹẹ ni kò ni ipepe kankan se fun ijọ awọn eniyan, ati pe kò ni aanu kan fun ọmọ-eniyan.

Ati pe ijamba ti se ẹsin yii ninu adisọkan rẹ ti ipilẹ, eyi ti o jẹ ami rẹ laarin awọn ẹsin ati awọn ijọ; ti o si jẹ asiri agbega rẹ, oun ni adisọkan sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin -Tawhiid- eyi ti Anabi Ibraahiim fi sọ asọtẹlẹ fun awọn ọmọ rẹ, ti Ya'aquub naa “ki ọla Ọlọhun o maa ba awọn mejeeji" si sọ ọ, ati pe awọn Yahuudi ti mu pupọ ninu eyi ti o buru ninu awọn adisọkan awọn ijọ ti wọn ba gbe, tabi ti wọn bọ si abẹ imunisin wọn, ati pupọ ninu awọn asa iborisa wọn ti oju-dudu, ati pe awọn oni-deedee ninu awọn opitan awọn Ju ti jẹwọ eleyii, o wa ninu [iwe ti o se akotan ọrọ Yahuudi] ohun ti itumọ lọ bayii pe:

« Dajudaju ibarajẹ awọn anabi, ati ibinu wọn, lori jijọsin fun awọn oosa n tọka si pe ijọsin fun awọn oosa, ati awọn ọlọhun [mìíran] jẹ ohun ti o yọ wọ inu ẹmi awọn ọmọ Isrẹli, ati pe wọn ti gba awọn adisọkan ti isẹbọ si Ọlọhun Ọba, ati ti palapala, dajudaju Talmud -Mişna- naa n jẹri pe ifanimọra kan pataki wa fun awọn Yahuudi ninu ibọrisa »[[3]].

Talmud -iwe ofin atọwọda, ti awọn Ju n pe ni Mişna- ti Baabil -eyi ti awọn Ju n se afọmọ rẹ de gongo, debi pe o see se ki wọn o fun un lọla lori At-Tawraata -Majẹmu Laelae- o si jẹ ohun ti o tan ka laarin awọn Yahuudi ni ọdun ọgọrun kẹfa ti awọn ẹlẹsin agbelebu, ati ohun ti o kun inu rẹ ninu awọn apejuwe ti o ya ni lẹnu ninu lilẹ laakaye, ati ọrọ ti kò wulo, ati yiyaju si Ọlọhun, ati sise ibajẹ awọn ododo, ati sisere pẹlu ẹsin ati laakaye- n tọka si ohun ti awujọ awọn Yahuudi de idi rẹ ni asiko naa ninu sisubu laakaye ati bibajẹ adun ẹsin.

Sugbọn ẹsin agbelebu -Christianity- a dan an wo pẹlu atọwọbọ awọn olutayọ-aala, ati yiyi ọrọ ni itumọ pada ti awọn alaimọkan, ati ibọrisa awọn Roomu -Roman- ti wọn gba ẹsin agbelebu -Christianity- lati igba ibẹrẹ rẹ, ati pe gbogbo eleyii ni o ti di okiti kan; ti a sin awọn ẹkọ nla Jesu Kristi si abẹ rẹ, ti imọlẹ sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin -Tawhiid- ati sise afọmọ ijọsin fun Ọlọhun si pamọ si ẹyin ẹsu-ojo ti o sokunkun yii.

Olukọwe kan ti o jẹ alagbelebu -Christian- n sọ nipa iru bi adisọkan mẹtalọkan ti se wọ inu awujọ alagbelebu, lati igbẹyin ọdun ọgọrunkẹrin ti bibi Jesu, o si sọ pe: Adisọkan pe Ọlọhun Ọkan soso ohun ti a se agbegun Rẹ lati ara ohun mẹta ni I, yọ wọ inu isẹmi aye ọmọlẹyin Jesu Kristi, ati ero rẹ, lati ida kẹrin ti ikẹyin ti ọdun ọgọrun kẹrin, ati pe o sẹku ni adisọkan kan ti ijọba fi ọwọ si, ti wọn si gba wọle ni gbogbo origun aye ọmọlẹyin Jesu Kristi, bẹẹ ni a kò ka asọ lori idagbasoke adisọkan mẹtalọkan ati asiri rẹ afi ni ida keji ti ọdun ọgọrun mọkandinlogun ti a ti bi Jesu.

Ati pe opitan kan ni ode-oni ti o jẹ ẹlẹsin Nasaara n sọ ninu iwe kan [ti n jẹ]: « Itan ẹsin ọmọlẹyin Jesu ni abẹ òye imọ ode-oni » nipa yiyọju ibọrisa ni awujọ awọn alagbelebu -Christians- ninu orisirisi aworan ati ọlọkan-ọ-jọkan awọ, ati bi awọn ẹlẹsin alagbelebu -Christians- ti se gba orisirisi ọna nipa gbigba awọn ọna sise ẹsin, ati awọn asa, ati awọn ajọdun, ati awọn akin abọrisa lati ọdọ awọn ijọ ati awọn ẹsin ti o jinlẹ ninu ẹbọ sise ni abẹ idajọ awokọse, tabi iyanu, tabi aimọkan. O si n sọ pe: « Dajudaju ibọrisa ti tan, sugbọn kò i ti ri iparun ti o pe, kaka bẹẹ nse l'o yọ wọ inu awọn ẹmi ti gbogbo nnkan si tẹsiwaju ninu rẹ ni orukọ ọmọlẹyin Kristi ati ninu asọ rẹ, tori naa awọn ti wọn bọra kuro ninu awọn ọlọhun wọn ati awọn akin wọn ti wọn si pa wọn ti, wọn ti mu ajẹriku kan ninu awọn ajẹriku wọn, wọn si ki i pẹlu awọn iroyin awọn ọlọhun, lẹyin naa ni wọn wa se ọlọhun ere kan, bayii ni ẹbọ ati ijọsin fun awọn orisa yii ti se bọdi si ọdọ awọn ajẹriku ti inu ile wọnyi, ati pe awọn ero igba naa kò tilẹ fura titi ti sinsin awọn ajẹriku ati awọn woli fi gbode kan laarin wọn, adisọkan tuntun si yọju, oun ni pe awọn woli ni awọn iroyin jijẹ ọlọhun, n ni awọn woli ati awọn ẹni-mimọ wọnyi ba di ẹda kan ti o wa laarin Ọlọhun ati eniyan, wọn si yi awọn orukọ awọn ajọdun ibọrisa pada si awọn orukọ tuntun, titi ti ajọdun oorun ti atijọ fi yipada si ajọdun ọjọ-ibi Jesu “Christmas" ni ọdun 400 lẹyin bibi Jesu »[[4]].

Sugbọn awọn olusin-ina, a ti mọ wọn lati igba ti o ti pẹ pẹlu sinsin iran ẹda ohun-kohun, eyi ti o si tobi ju ninu rẹ ni ina, ati pe ni ikẹyin, wọn ko ara ro si ori sisin in, wọn si n kọ ile isin, ati aaye ijọsin fun un, ati pe awọn ile ina si tan ka ni ooro ilu ati ibuu rẹ, gbogbo adisọkan ati ẹsin si parẹ yatọ si ijọsin fun ina, ati sise afọmọ oorun, ati pe ijọsin ni ọdọ wọn si di ohun ti o tumọ si awọn ọna-isin kan, ati awọn awokọse kan, ti wọn n se ni awọn aaye kan pataki.

Olukọ iwe « Ilẹ Iran ni aye awọn Saasaan » ti o jẹ ọmọ Denmark “Aartahar Kurstin sin" n royin ipo awọn asiwaju ẹsin ati awọn isẹ wọn, o si n sọ pe:

« Ọranyan l'o jẹ lori awọn osisẹ wọnyi lati sin oorun ni ẹẹmẹrin lojumọ, pẹlu afikun jijọsin fun osupa, ina, ati omi, ati pe a pa wọn lasẹ pe wọn kò gbọdọ jẹ ki ina naa o ku, ki omi ati ina o si ma se kan ara wọn, ki wọn o si ma jẹ ki irin o dogun, nitori ohun mimọ ni irin ni ọdọ wọn ».

Ati pe dajudaju wọn gba fun jijẹ meji ni gbogbo igba, eleyii si di ami isin wọn, wọn si gba ọlọhun meji gbọ, ọkan ninu wọn ni imọlẹ, tabi ọlọhun rere, wọn a si maa pe e ni: Ahuur Mizdaa, tabi Yazdaan; ẹlẹẹkeji ni okunkun, tabi ọlọhun aburu, oun si ni Aharman, ati pe ija kò yee maa bẹ laarin awọn mejeeji, bẹẹ ni gbogbo igba ni ogun “laarin wọn".

Sugbọn ẹsin Budda -ẹsin ti o tan ka ni India, ati Asia ti aarin- ẹsin ibọrisa kan ti i maa n gbe orisa lọwọ pẹlu rẹ nibikibi ti o ba lọ ni i, a si maa kọ awọn ile-isin, a si maa gbe awọn ere “Budda" duro nibikibi ti o ba de si, tabi ti o sọ si.

Sugbọn ẹsin Baraahimah -ẹsin India- o gbayi pẹlu ọpọlọpọ ohun ijọsin fun ati awọn ọlọhun, ati pe ibọrisa de gongo ni ọdun ọgọrun kẹfa lẹyin bibi Jesu, onka awọn ọlọhun si to aadọta ọkẹ lọna ọgọrun mẹta ati ọgban, ati pe gbogbo nnkan ti o rẹwa, ati gbogbo nnkan ti o ga, ati gbogbo nnkan ti o sanfaani, ni o di ọlọhun ti wọn n sin, idagbasoke si ba isẹ ere gbigbẹ ni asiko yii, awọn oluse nnkan lọsọ si se wọn ni ọsọ.

C. Y. Wed ti o jẹ ẹlẹsin Hindu sọ ninu iwe rẹ « Itan India ti aarin» nigba ti n sọrọ nipa aye ọba Harsh “606-648 A.D" eleyii ni igba ti o tẹle yiyọju Islam ni erekusu Larubaawa pe:

« Ẹsin Hindu ati ti Budda jẹ ẹsin ibọrisa ni dọgba-n-dọgba, koda o see se ki ẹsin Budda o jẹ pe o tayọ ẹsin Hindu ninu titẹri sinu ibọrisa, ibẹrẹ ẹsin yii -Budda- jẹ pẹlu titako “bibẹ" Ọlọhun, sugbọn o fi diẹdiẹ sọ “Budda" di ọlọhun ti o tobi ju, lẹyin naa ni o wa fi awọn ọlọhun mìíran gẹgẹ bi « Bodhistavas » eyi ti o dọgba pẹlu gbolohun “orisa" tabi “ere" ninu apa kan ninu awọn ede ibula oorun kun un ».

Ati pe ninu ohun ti kò si iyemeji nipa rẹ ni pe ibọrisa jẹ ohun ti o tan ka ninu gbogbo aye ode-oni, dajudaju ile-aye si ti tẹri ni apapọ rẹ sinu ibọrisa, bẹrẹ lati okun nla ti Atlantic titi de okun nla ti Pacific, afi bi igba ti o se pe ẹsin ọmọlẹyin Jesu, ati awọn ẹsin giga naa, ati ẹsin Budda, jẹ ohun ti n se idije lori gbigbe awọn orisa ga, ati sise afọmọ fun wọn, o wa da gẹgẹ bi ẹsin idije pẹlu ijiyan ti n sare ni ibi isure ije kan.

Ẹlẹsin Hindu mìíran tun sọ ninu iwe rẹ ti o sọ ni: « Ẹsin Hindu ti o gbode kan »: « Dajudaju isẹ gbigbẹ awọn ọlọhun kò tan lori eleyii, awọn ọlọhun kékéké ni onka ti o tobi kò si yee maa da ara pọ mọ eleyii “apejọ awọn ọlọhun" ni awọn asiko ọtọọtọ, titi ti onka kan ti o kọja kika ati isiro fi ti ara wọn jade ».

Eyi ni ọrọ awọn ẹsin naa, sugbọn ilu olaju eyi ti awọn ijọba nlanla dide nibẹ, ti awọn imọ pupọ si tan ka nibẹ, ti o si jẹ itẹ fun ọlaju ati imọ-ẹrọ, ati awọn ẹkọ, dajudaju wọn jẹ ilu kan ti wọn ti pa awọn ẹsin rẹ ninu rẹ, ti o si se afẹku ipilẹ rẹ, ati agbara rẹ, ti o si se afẹku awọn alatunse, ti awọn olukọni ni imọ kò si si ninu rẹ, ti wọn si n kede aigbagbọ pe Ọlọhun wa, ti ibajẹ si pọ ninu rẹ, ti awọn osunwọn si ti yipada ninu rẹ, ti eniyan si di ẹni-abuku lọwọ ara rẹ ninu rẹ, eyi l'o si mu ki ipokunso o pọ ninu rẹ, ti awọn okun-ẹbi si ja ninu rẹ, ti awọn ajọsepọ ti awujọ si ti tuka, ti awọn ile-iwosan awọn onisegun arun ọpọlọ si kun fọfọ fun awọn ti n lọ fun ayẹwo, ti ọja awọn opidan si n ta nibẹ, ti eniyan si dan gbogbo adun wo ninu rẹ, ti o si tẹle gbogbo ẹsin adadaalẹ, latari ojukokoro atitan ongbẹ ẹmi rẹ, ati lati mu ayọ ba ẹmi rẹ, ati ibalẹ ọkan rẹ, awọn igbadun yii, ati awọn ilana wọnyi, ati awọn ero wọnyi, kò yege lati ri eleyii mu sẹ, ati pe yoo maa wa ninu wahala ọkan ati iya ẹmi yii titi ti yoo fi pade pẹlu Ẹlẹda rẹ, ti yoo si fi maa sin IN, ni ibamu pẹlu ilana Rẹ, eyi ti O yọnu si fun ara Rẹ, ti O si fi pa awọn ojisẹ Rẹ lasẹ, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ l'Ẹni ti N se alaye ipo ẹni ti o sẹri kuro ni ọdọ Oluwa rẹ, ti si n wa imọna ni ọdọ ẹni ti o yatọ si I pe:

} ومن أعرض عن ذكري فإن له معيشة ضنكاً ونحشره يوم القيامة أعمى { [سورة طه: 124].

« Ẹni ti o ba sẹri kuro nibi iranti Mi, dajudaju igbesi-aye inira ni yoo wa fun un, A o si gbe e dide ni ọjọ igbende ni afọju » [Suuratu Tọọ Haa: 124]. Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun un- tun sọ l'Ẹni ti N fun'ni niroyin nipa ibalẹ-ọkan awọn olugbagbọ-ododo ati oriire wọn ninu igbesi-aye yii pe:

} الذين آمنوا ولم يلبسوا إيمانهم بظلم أولئك لهم الأمن وهم مهتدون { [سورة الأنعام: 82].

« Awọn ti wọn gba Ọlọhun gbọ lododo, ti wọn kò si lu igbagbọ wọn pọ mọ abosi -ẹbọ sise- awọn wọnyi ni ibalẹ-ọkan n bẹ fun, awọn naa si ni awọn olumọna » [Suuratu l-An'aam :82]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} وأما الذين سعدوا ففي الجنة خالدين فيها ما دامت السموات والأرض إلا ما شاء ربك عطاء غير مجذوذ { [سورة هود: 108].

« Sugbọn awọn ti a se ni oloriire, ninu ọgba-idẹra -Al-janna- ni wọn yoo wa, wọn yoo maa wa ninu rẹ gberekese, lopin igba ti awọn sanma ati ilẹ ba n bẹ, afi ohun ti Oluwa rẹ ba fẹ, ni ọrẹ ti ki yoo duro » [Suuratu Huud: 108].

Awọn ẹsin wọnyi -yatọ si Islam- ti a ba lo awọn ofin ẹsin ododo ti o siwaju le wọn lori; dajudaju a o ri pe wọn ti se afẹku eyi ti o pọju ninu awọn iran wọn, gẹgẹ bi o ti se han ni ara afihan soki nipa wọn yii.

Ati pe eyi ti o tobi ju ninu ohun ti awọn ẹsin wọnyi ti mẹhẹ ni sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin -Tawhiid-. Dajudaju awọn ọmọlẹyin wọn ti fi awọn ọlọhun mìíran se orogun fun Ọlọhun Ọba, gẹgẹ bi o ti se jẹ pe awọn ẹsin ti wọn ti ti ọwọ bọ wọnyi kò gbe ofin kan ti o dara fun gbogbo igba, ati fun gbogbo aaye, wa fun awọn eniyan, ti yoo maa sọ ẹsin awọn eniyan, ati awọn iyi wọn, ati awọn arọmọdọmọ wọn, ati awọn nnkan-ini wọn, ati awọn ẹjẹ wọn fun wọn, kò si fi ọna mọ wọn, bẹẹ ni kò tọka si ofin Ọlọhun, eyi ti O fi pa wọn lasẹ fun wọn, kò i si fi ifayabalẹ ati oriire ta awọn ẹni-rẹ lọrẹ, latari ohun ti o se akojọpọ ninu atako, ati iyapa.

Sugbọn Islam, ohun ti yoo se alaye pe ẹsin Ọlọhun ti otitọ ni i, eyi ti yoo sẹku, ti Ọlọhun yọnu si funra Rẹ, ti O si yọnu si i fun awọn ọmọ eniyan, yoo wa ninu awọn ori-ori ọrọ ti n bọ.

Ni ipari ẹsẹ ọrọ yii, o ba a mu pe ki a mọ paapaa jijẹ anabi, ati awọn ami jijẹ anabi, ati bukaata awọn eniyan lọ sidi rẹ, ki a si se alaye awọn ipilẹ ipepe awọn ojisẹ, ati paapaa isẹ ti opin, ti yoo maa bẹ laelae.

###

PAAPAA JIJẸ ANABI

Dajudaju ohun ti o tobi ju, ti o jẹ ọranyan pe ki eniyan o mọ ninu isẹmi yii ni mimọ Oluwa rẹ, Ẹni ti O mu un maa bẹ, nigba ti kò jẹ nnkan kan, ti O si da awọn idẹra bo o, ati pe eyi ti o tobi ju ninu ohun ti Ọlọhun titori rẹ sẹda ẹda ni jijọsin fun Un ni Oun nikan -mimọ ni fun Un-.

Sugbọn bawo ni eniyan yoo ti se mọ Oluwa Rẹ ni paapaa mimọ Ọn? Ati ohun ti o jẹ ọranyan fun Un, ninu awọn iwọ ati awọn ọranyan, ati pe bawo ni yoo ti maa sin Oluwa Rẹ? Dajudaju eniyan a maa ri ẹni ti yoo ran an lọwọ lori awọn adanwo aye rẹ, ti yoo si maa ba a se awọn ohun anfaani rẹ ninu itọju aisan, ati fifun'ni loogun, ati riran'ni lọwọ lori atikọ ile, ati ohun ti o jọ bẹẹ. Sugbọn kò le e ri ẹni ti yoo fi Oluwa rẹ mọ ọn ninu gbogbo eniyan, ti yoo si salaye bawo ni yoo ti maa sin Oluwa rẹ fun un; nitori pe awọn laakaye kò le e da mọ erongba Ọlọhun nipa wọn, tori pe laakaye ọmọ eniyan lẹ ju ki o mọ erongba eniyan ẹgbẹ rẹ siwaju ki o to fun un niro nipa erongba rẹ, njẹ bawo wa ni yoo ti se mọ erongba Ọlọhun, ati nitori pe ohun ti a sẹ mọ si ori awọn ojisẹ ati awọn anabi, awọn ẹni ti Ọlọhun N sa lẹsa nitori jijẹ isẹ, ati lori awọn ti wọn de lẹyin wọn ninu awọn asiwaju imọna, awọn olujogun awọn anabi, awọn ti wọn n gbe awọn ilana wọn, ti wọn si n tẹle oripa wọn, ti wọn si n ba wọn jisẹ wọn, ni ohun ti o pataki yii i se, tori pe kò see se ki awọn eniyan o gba ọrọ lati ọdọ Ọlọhun taara, wọn kò le e se bẹẹ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وما كان لبشر أن يكلمه الله إلا وحياً أو من وراء حجاب أو يرسل رسولا فيوحي بإذنه ما يشاء إنه علي حكيم { [سورة الشورى: 51].

« Ati pe kò tọ fun abara kan pe ki Ọlọhun O ba a sọrọ [ni taara] afi ki O ransẹ [si i], tabi ni ẹyin gaga kan, tabi ki O ran ojisẹ kan [si i], ki o la ohun ti O fẹ ye [e] pẹlu iyọnda Rẹ, Dajudaju Oun ni Ọba giga, Ọlọgbọn » [Suuratu Shuuraa: 51].

Nitori naa dandan ni ki ẹni-aarin kan, ati iransẹ kan, o wa ti yoo maa jisẹ ofin Ọlọhun, lati ọdọ Ọlọhun si awọn ẹru Rẹ, ati pe awọn iransẹ ati awọn ẹni-aarin wọnyi ni awọn ojisẹ ati awọn anabi, tori naa malaika yoo maa mu isẹ Ọlọhun wa si ọdọ anabi, n ni ojisẹ naa yoo ba jẹ ẹ fun awọn eniyan, malaika ki i si i mu awọn isẹ naa lọ si ọdọ awọn eniyan taara, nitori pe aye awọn malaika yatọ si aye awọn eniyan ninu paapaa ẹda rẹ. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} الله يصطفي من الملائكة رسلاً ومن الناس { [سورة الحج: 75].

« Ọlọhun A maa sẹsa awọn ojisẹ ninu awọn malaika ati ninu awọn eniyan » [Suuratul-Hajj: 75].

Ati pe Hikmah -ọgbọn- Ọlọhun -mimọ ni fun Un- da a lẹjọ pe ki ojisẹ o maa jẹ iru awọn ti a ran an si, ki wọn o le baa ni mimọ gba ọwọ rẹ, ki wọn o si le ba a gbọ ọ ye, nitori nini ikapa wọn lati ba a sọrọ, iba se pe lati inu awọn malaika l'O ti gbe ojisẹ naa dide ni, dajudaju wọn kò ba ti ni agbara lati da oju kọ ọ, tabi lati kọ nnkan kan ni ọdọ rẹ; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وقالوا لولا أنزل عليه ملك ولو أنزلنا ملكاً لقضي الأمر ثم لا ينظرون. ولو جعلناه ملكاً لجعناه رجلاً وللبسنا عليهم ما يلبسون { [سورة الأنعام: 8-9].

« Wọn tun sọ pe: O ti jẹ ti a kò sọ malaika kan kalẹ fun un? Ti o ba se pe A sọ malaika kan kalẹ ni, ọran naa i ba ti pari, lẹyin naa a kò ba ti lọ wọn lara. Ati pe ti o ba jẹ pe Awa se e ni malaika ni, dajudaju Awa O ba se e ni ọkunrin, A O ba si se ohun ti wọn se ni iruju ni iruju fun wọn » [Suuratul-An'aam: 8-9]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ pe:

} وما أرسلنا قبلك من المرسلين إلا إنهم ليأكلون الطعام ويمشون في الأسواق ... وقال الذين لا يرجون لقاءنا لولا أنزل علينا الملائكة أو نرى ربنا لقد استكبروا في أنفسهم وعتوا عتواً كبيراً { [سورة الفرقان 20-21].

« Awa kò ran ojisẹ kan ninu awọn ojisẹ nisẹ siwaju rẹ, afi ki wọn o maa jẹ ounjẹ, ki wọn o si maa rin ninu awọn ọja … Awọn ẹni ti wọn kò si ni ireti fun ipade Wa sọ pe: Ki l'o se ti a kò sọ malaika kalẹ fun wa, tabi ki a ri Oluwa wa [ni ojukoroju]? Dajudaju wọn ti se igberaga ninu ẹmi wọn, wọn si se agbere ni agbere ti o tobi » [Suuratul-Furqaan: 20-21].

Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وما أرسلنا من قبلك إلا رجالاً نوحي إليهم { [سورة النحل: 43].

« Ati pe Awa kò ran [ẹnikan] nisẹ siwaju rẹ yatọ si awọn ọkunrin kan ti A N ransẹ si wọn » [Suuratun-Nahl: 43]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} وما أرسلنا من رسول إلا بلسان قومه ليبين لهم { [سورة إبراهيم: 4].

« Kò si si ojisẹ kan ti A ran nisẹ, afi ki o jẹ pẹlu ede awọn eniyan rẹ, ki o le se alaye fun wọn » [Suuratu Ibraahiim: 4]. Ati pe a maa n royin awọn ojisẹ, ati awọn anabi wọnyi pẹlu pipe laakaye, ati alaafia adamọ, ati otitọ ninu ọrọ ati isẹ, ati ifọkantan ninu fifi ohun ti a fi ti si ọdọ wọn jisẹ, ati aabo kuro nibi gbogbo ohun ti o le da itan abara ru, ati alaafia ara nibi ohun ti oju maa n sa fun, ti awọn laakaye ti o gbadun si maa n sa fun, ati pe dajudaju Ọlọhun ti fọ wọn mọ ninu awọn ẹmi wọn ati awọn iwa wọn, tori naa awọn eniyan ti o pe ju ni iwa, ti o si mọ ju ni ẹmi, ti o si ni apọnle ju ni lilawọ ni wọn, Ọlọhun ko awọn iwa alapọnle jọ fun wọn, ati eyi ti o dara ju ninu isesi, gẹgẹ bi O ti se ko afarada, ati imọ jọ fun wọn, ati inu-rere, ati apọnle, ati lilawọ, ati akin ati sise dọgba, titi wọn fi da yatọ ninu awọn iwa wọnyi laarin awọn eniyan wọn; awọn eniyan Anabi Saalih “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" niyi -ti wọn n sọ fun un- gẹgẹ bi Ọlọhun ti se fun'ni niro nipa wọn pe:

} قالوا يا صالح قد كنت فينا مرجوا قبل هذا أتنهانا أن نعبد ما يعبد آباؤنا { [سورة هود: 62].

« Wọn sọ pe: Irẹ Saalih, dajudaju iwọ ti n bẹ laarin wa ni ẹni ti a n fi ọkan tẹ siwaju eleyii. Njẹ irẹ yoo wa kọ fun wa pe ki a ma se sin ohun ti awọn baba wa n sin? » [Suuratu Huud: 62], ati pe awọn eniyan Anabi Shuaib sọ fun Shuaib “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" pe:

} أصلاتك تأمرك أن نترك ما يعبد آباؤنا أو أن نفعل في أموالنا ما نشاء إنك لأنت الحليم الرشيد { [سورة هود: 87].

« Sé irun rẹ ti o n ki ni n pa ọ lasẹ pe ki awa o fi ohun ti awọn baba wa n sin silẹ, tabi ki a fi sise bi a ti se fẹ ninu ọrọ wa silẹ, [sé] dajudaju iwọ gan-an ni alafarada, olumọna? » [Suuratu Huud: 87]. Bẹẹ ni Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" gbayi laarin awọn eniyan pẹlu orukọ atẹpe ti i se « Al-Amiin » ẹni-ifọkantan, siwaju ki a to sọ isẹ ti a fi ran an kalẹ fun un, ati pe Oluwa rẹ -ti O ga, ti O si gbọn-un-gbọn- royin rẹ pẹlu ọrọ Rẹ:

} وإنك لعلى خلق عظيم { [سورة القلم: 4].

« Dajudaju iwọ jẹ ẹni ti o ni iwa ti o dara » [Suuratul-Qalam: 4].

Nitori naa awọn ni asayan Ọlọhun ninu awọn ẹda Rẹ, O sa wọn lẹsa, O si yan wọn fun gbigbe isẹ riran naa, ati fifi ohun ifọkantan naa jisẹ, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} الله أعلم حيث يجعل رسالته { [سورة الأنعام: 124].

« Ọlọhun ni O mọ ju nipa aaye ti O maa N fi isẹ riran Rẹ si » [Suuratul-An'aam: 124]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} إن الله اصطفى آدم ونوحاً وآل إبراهيم وآل عمران على العالمين { [سورة آل عمران: 33].

« Dajudaju Ọlọhun sa Aadama lẹsa, ati Nuuhu, ati awọn ara ile Ibraahiim, ati awọn ara ile Imraan, lori gbogbo ẹda » [Suuratu Aala Imraan: 33].

Awọn ojisẹ ati awọn anabi wọnyi “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn" t'ohun ti ohun ti Ọlọhun fi royin wọn ninu awọn iroyin ti o buaya, ati ohun ti wọn gbayi pẹlu rẹ ninu awọn iroyin giga; sibẹsibẹ eniyan ni wọn, ohun ti i si i maa n se gbogbo abara a maa se wọn, nitori naa ebi a maa pa wọn, wọn a si maa se aarẹ, wọn a si maa sun, wọn a si maa jẹun, wọn si maa n fẹ iyawo, wọn si maa n ku. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} إنك ميت وإنهم ميتون { [سورة الزمر: 30].

« Dajudaju ẹni ti yoo ku ni iwọ i se, ati pe dajudaju ẹni ti yoo ku ni awọn naa » [Qur'aan, Al-Zumar: 30]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} ولقد أرسلنا رسلا من قبلك وجعلنا لهم أزواجاً وذرية { [سورة الرعد: 38].

« Dajudaju Awa ti ran awọn ojisẹ kan nisẹ siwaju rẹ, A si se awọn iyawo ati awọn ọmọ fun wọn » [Suuratur-Ra'ad: 38]. Koda o see se ki wọn o ni wọn lara, tabi ki wọn pa wọn, tabi ki wọn o le wọn jade ni ilu wọn, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وإذ يمكر بك الذين كفروا ليثبوك أو يقتلوك أو يخرجوك ويمكرون ويمكر الله والله خير الماكرين { [سورة الأنفال: 30].

« Nigba ti awọn alaigbagbọ n pete si ọ lati se ọ mọ ibikan, tabi ki wọn o pa ọ, tabi ki wọn o le ọ jade, wọn n dete, Ọlọhun Naa si N pete; ati pe Ọlọhun ni O loore ju ninu awọn elete » [Suuratul-Anfaal: 30]. Sugbọn atubọtan rere, ati aranse, ati igbanilaye, ni yoo jẹ ti wọn ni aye ati ni igbẹyin:

} ولينصر الله من ينصره { [سورة الحج: 40].

« Ati pe dajudaju Ọlọhun yoo maa se iranlọwọ fun ẹni ti i ba n ran AN lọwọ » [Suuratul-Hajj: 40]. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tun sọ pe:

} كتب الله لأغلبن أنا ورسلي إن الله قوي عزيز { [سورة المجادلة: 21].

« Ọlọhun ti kọ ọ silẹ pe: Dajudaju Emi ati awọn ojisẹ Mi ni yoo bori; dajudaju Ọlọhun ni Alagbara, Olubori » [Suuratul-Mujaadalah: 21].

###

AWỌN AMI JIJẸ ANABI

Nigba ti jijẹ anabi jẹ ọna kan lati mọ eyi ti o ga ju ninu imọ, ati gbigbe eyi ti o ga ju ninu isẹ, ati eyi ti o gbọn-un-gbọn ju ninu rẹ dide, o n bẹ ninu aanu Ọlọhun -mimọ ni fun Un- pe O se awọn ami kan fun awọn anabi naa, ti n tọka si wọn, ti awọn eniyan yoo si maa fi sẹri lori wọn, ti wọn yoo si maa ti ara rẹ mọ wọn -bi o tilẹ jẹ pe gbogbo ẹni ti o ba pera rẹ ni nnkan kan ni ohun ti yoo se alaye otitọ rẹ, ti o ba jẹ olotitọ, ti yoo si ja irọ rẹ, ti o ba jẹ opurọ, ninu awọn ami yoo han lara rẹ- awọn ami naa si pọ, ninu awọn eyi ti o pataki ju ninu wọn ni:

1- Ki ojisẹ naa o maa pepe lọ sidi jijọsin fun Ọlọhun nikan soso, ati fifi sinsin ohun ti o yatọ si I silẹ, nitori pe eleyii ni opin ohun ti Ọlọhun titori rẹ da ẹda.

2- Ki o maa pe awọn eniyan lọ sidi nini igbagbọ si i, ki wọn si gba a lotitọ, ki wọn o si maa sisẹ pẹlu isẹ ti a fi ran an, Ọlọhun si ti pa Anabi Rẹ Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" lasẹ pe ki o sọ pe:

} قل يا أيها الناس إني رسول الله إليكم جميعاً { [سورة الأعراف: 158].

« Sọ pe: Ẹyin eniyan, dajudaju emi ni ojisẹ Ọlọhun si gbogbo yin » [Suuratul-Aaraaf: 158].

3- Ki Ọlọhun O ran an lọwọ pẹlu awọn arisami orisirisi, ninu awọn ami jijẹ anabi, ninu awọn arisami yii ni awọn ami ti anabi maa n mu wa, ti awọn eniyan rẹ kò si ni i le kọ ọ, tabi ki wọn o le mu iru rẹ wa, ninu eleyii ni ami Musa “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", nigba ti ọpa rẹ yipada si ejo, ati ami Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", nigba ti n wo awọn afọju ati awọn adẹtẹ san pẹlu iyọnda Ọlọhun, ati ami Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", oun ni Al-Qur'aani alapọnle t'ohun ti bi o ti se jẹ alaimọọkọ-mọọka, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn ami awọn ojisẹ.

Ninu awọn arisami naa tun ni: Ododo ti o han, ti o ye, eyi ti awọn anabi, ati awọn ojisẹ, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn" maa n mu wa, ti awọn alatako wọn kò si ni i le ti i danu tabi ki wọn o tako o, koda dajudaju awọn alatako wọnyi mọ daju pe ododo ti kò se e ti danu ni ohun ti awọn anabi naa mu wa.

Ati pe ninu awọn ami yii ni ohun ti Ọlọhun fi da awọn anabi Rẹ yanri ninu pipe awọn ipo wọn, ati rirẹwa awọn iwa wọn, ati apọnle isesi ati iwa.

Ninu awọn ami yii tun ni aranse Ọlọhun fun wọn lori awọn alatako wọn, ati sise afihan ohun ti wọn n pepe lọ sidi rẹ.

4- Ki ipe rẹ o dọgba ninu ipilẹ rẹ pẹlu awọn ipilẹ ti awọn anabi ati awọn ojisẹ pepe lọ sidi rẹ.

5- Ki o ma se pepe lọ sidi jijọsin fun ara rẹ, tabi sisẹri nnkan kan ninu ijọsin naa lọ si ọdọ rẹ, ki o si ma se maa pepe lọ sidi gbigbe iran rẹ ga, tabi awọn ẹni rẹ. Dajudaju Ọlọhun pa Anabi Rẹ Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" lasẹ, pe ki o sọ fun awọn eniyan pe:

} قل لا أقول لكم عندي خزائن الله ولا أعلم الغيب ولا أقول لكم إني ملك إن أتبع إلا ما يوحى إلـيَّ { [سورة الأنعام: 50].

« Sọ pe: Emi kò sọ fun yin pe pẹpẹ ọrọ Ọlọhun wa lọdọ mi, ati pe emi kò mọ ohun ti o pamọ, bẹẹ ni emi kò sọ fun yin pe dajudaju emi jẹ malaika kan, n kò maa tẹle nnkan kan yatọ si ohun ti a n fi n ransẹ si mi » [Suuratul-An'aam: 50].

6- Ki o ma maa wa nnkan kan ninu awọn ohun ile-aye ni ẹsan fun ipepe rẹ, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ l'Ẹni ti N fun'ni niro nipa awọn anabi Rẹ: Nuuhu, Huud, Saalih, Luut, ati Shuaib, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn" pe wọn sọ fun awọn ijọ wọn pe:

} وما أسألكم عليه من أجر إن أجري إلا على رب العالمين { [سورة الشعراء: 109].

« Emi kò si beere ẹsan kan lọwọ yin lori rẹ, kò si ẹsan mi ni ọdọ ẹnikan afi ni ọdọ Oluwa gbogbo ẹda » [Suuratu Shuaraa': 109]. Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" naa sọ fun awọn eniyan rẹ pe:

} قل ما أسألكم عليه من أجر وما أنا من المتكلفين { [سورة ص: 86].

« Sọ pe: Emi kò bi yin leere ẹsan kan; bẹẹ ni emi kò si ninu awọn ti n pera wọn ni ohun ti wọn kò jẹ » [Suuratu Saad: 86].

Ati pe awọn ojisẹ ati awọn anabi -ti mo sọ nnkan kan fun ọ ninu awọn iroyin wọn ati awọn ami jijẹ anabi wọn- wọnyi pọ, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ولقد بعثنا في كل أمة رسولاً أن اعبدوا الله واجتنبوا الطاغوت { [سورة النحل: 36].

« Ati pe dajudaju A ti gbe ojisẹ kan dide ninu gbogbo ijọ kọọkan; pe: Ẹ maa jọsin fun Ọlọhun, ki ẹ si jinna si awọn oosa » [Suuratu n-Nah'l :36]. Awọn eniyan si ti tara wọn se oriire, ati pe itan kun fun akọọlẹ awọn iroyin wọn, bẹẹ ni lati ọwọ ọgọọrọ eniyan ni gbigba awọn ofin ẹsin wọn wa ti waye, ati pe dajudaju awọn ni ododo ati deedee, -bakan naa- ọgọọrọ eniyan naa l'o tun gba iroyin ohun ti Ọlọhun ni ki o sẹlẹ si wọn ninu aranse Rẹ ati pipa awọn ọta wọn run, gẹgẹ bi “omi" tuufaana awọn eniyan Nuuhu, ati titẹri Fir'auna, ati iya awọn eniyan Luut, ati isẹgun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", lori awọn ọta rẹ, ati titanka ẹsin rẹ.. tori naa ẹnikẹni ti o ba mọ eleyii, yoo mọ amọdaju pe dajudaju oore ati imọna ni wọn mu wa, ati titọ awọn ẹda si ọna lọ sibi ohun ti yoo se wọn lanfaani, ati kiki wọn nilọ nibi ohun ti yoo ni wọn lara, akọkọ wọn si ni Nuuhu, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", bẹẹ ni ikẹyin wọn ni Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a".

###

BUKAATA AWỌN ENIYAN SI AWỌN OJISẸ

Awọn anabi ni awọn ojisẹ Ọlọhun si awọn ẹru Rẹ, wọn n jisẹ awọn asẹ Rẹ fun wọn, wọn si n fun wọn niro idunnu nipa ohun ti Ọlọhun pese kalẹ fun wọn, ninu awọn idẹra, ti wọn ba tẹle awọn asẹ Rẹ, wọn si n kilọ fun wọn nipa iya ti ki i tan [ti O pese silẹ fun wọn], ti wọn ba yapa si kikọ Rẹ, wọn si n sọ itan awọn ijọ ti o ti rekọja fun wọn, ati ohun ti o sẹlẹ si wọn ninu iya, ati ibawi, ni ile-aye, nitori yiyapa wọn si asẹ Oluwa wọn.

Ati pe kò see se fun awọn laakaye pe ki wọn o da mọ nipa awọn asẹ ati kikọ ti Ọlọhun wọnyi, eyi l'o mu ki Ọlọhun O se awọn ofin, ti O si se awọn asẹ, ati awọn kikọ ni ọranyan, ni ti apọnle fun awọn ọmọ eniyan, ati agbega fun wọn, ati isọ fun awọn anfaani wọn, nitori pe o see se ki awọn eniyan o maa da tẹle awọn ifẹkufẹ ọkan wọn, ki wọn o si tipasẹ bẹẹ tẹ awọn ohun ti O se ni eewọ mọlẹ, ki wọn o si maa yaju si awọn eniyan, ki wọn o si fi bẹẹ gba ẹtọ wọn mọ wọn lọwọ. Nitori naa o n bẹ ninu Hikmah -ọgbọn- ti o de opin pe ki Ọlọhun o maa gbe awọn ojisẹ kan dide ninu wọn lati igba kan si omiran, ti wọn yoo maa ran wọn leti awọn asẹ Ọlọhun, ti wọn o si maa se ikilọ fun wọn nibi sisubu sinu sisẹ Ẹ, ti wọn yoo si maa ka awọn isiti fun wọn, ti wọn yoo si maa sọ itan awọn asiwaju fun wọn, tori pe dajudaju nigba ti awọn iroyin iyanu ba wọnu eti, ti awọn itumọ ti o se ajoji ba si ta awọn ọpọlọ ji, laakaye yoo fi i se agbara, nitori naa imọ rẹ yoo lekun, agbọye rẹ o si dọgba, ati pe ẹni ti o pọju ni ọrọ gbigbọ ninu awọn eniyan ni ẹni ti o pọju ninu wọn ni iro ọpọlọ, bẹẹ ni ẹni ti o ba pọju ni iro ọpọlọ ninu wọn ni o pọju ninu wọn ni ironu, ẹni ti o si pọju ni ironu ninu wọn ni o pọju ni imọ, ati pe ẹni ti o pọju ninu wọn ni imọ ni o pọju ninu wọn ni isẹ. Nitori naa kò si ibuyẹsi kan kuro nibi gbigbe awọn ojisẹ dide, kò si si ohun ti a le fi jaarọ wọn nibi tito ododo.

Shaikhul-Islam Ibn Taimiyyah -ki Ọlọhun O kẹ ẹ- sọ pe: Dandan ni isẹ [ti Ọlọhun maa N fi i ransẹ] ninu sise atunse ẹru ninu isẹmi rẹ, ati ibudapadasi rẹ, tori naa bi o ti se jẹ pe kò si rere kan fun un ni igbẹyin rẹ, afi pẹlu titẹle isẹ naa, bẹẹ naa ni kò si rere kan fun un ni isẹmi rẹ, ati ile-aye rẹ, afi pẹlu titẹle isẹ naa. Nitori naa eniyan n bukaata ofin -Sharia- tori pe laarin iyirapada meji l'o wa, iyirapada kan ti yoo maa fi fa ohun ti yoo se e ni anfaani, ati iyirapada kan ti yoo maa ti ohun ti yoo ni in lara danu, ati pe ofin -Sharia- ni imọlẹ, eyi ti yoo maa se alaye ohun ti yoo se e lanfaani, ati ohun ti yoo ni in lara, oun ni imọlẹ Ọlọhun ni ori ilẹ Rẹ, ati sise dọgba Rẹ laarin awọn ẹru Rẹ, ati odi Rẹ, eyi ti o se pe ẹni ti o ba ti wọ ọ di ẹni-ifayabalẹ.

Ati pe ki i se ohun ti a gba lero pẹlu ofin -Sharia- ni sise iyatọ laarin ohun ti o sanfaani, ati eyi ti i ni'ni lara pẹlu òye, nitori pe eleyii a maa sẹlẹ si awọn ẹranko naa, dajudaju kẹtẹkẹtẹ, ati rakunmi, a maa se iyatọ laarin ọka-baba ati erupẹ, sugbọn [ohun ti a gba lero ni] sise iyatọ laarin awọn isẹ ti i maa n ni ẹni ti o se e lara ni aye ati ọrun rẹ, ati awọn isẹ ti yoo se e ni anfaani ni aye, ati ọrun rẹ; gẹgẹ bi anfaani igbagbọ-ododo, ati sise Ọlọhun ni àásó ninu ijọsin, ati sise dọgba, ati sise rere, ati daadaa sise, ati ifọkantanni, ati sisọ abẹ, ati akin, ati imọ, ati suuru, ati fifooro ẹni si rere ati kikọ fun'ni lati se aidaa, ati siso okun ẹbi pọ, ati sise daadaa si awọn obi mejeeji, ati sise daadaa si alamuleti, ati pipe awọn iwọ, ati sise afọmọ isẹ fun Ọlọhun, ati gbigbẹkẹle E, ati wiwa iranlọwọ Rẹ, ati yiyọnu si awọn akọọlẹ Rẹ, ati gbigbafa fun idajọ Rẹ, ati gbigba A lododo, ati gbigba awọn ojisẹ Rẹ lododo ninu gbogbo ohun ti wọn fun'ni niro nipa rẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ninu ohun ti o jẹ anfaani, ati rere fun ẹru, ni ile-aye rẹ, ati ọrun rẹ, ti oriibu ati inira rẹ ni ile-aye rẹ ati ọrun rẹ si wa ninu atodijẹ rẹ.

Ati pe ti kò ba si isẹ riran naa ni, laakaye kò ba ti mọna lọ sidi awọn alaye awọn anfaani ati awọn inira inu isẹmi [ile-aye], tori naa ninu eyi ti o tobi ju ninu awọn idẹra Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ, ati eyi ti o ga ju ninu awọn irọra Rẹ lori wọn, ni riran ti O ran awọn ojisẹ Rẹ si wọn, ti O si sọ awọn tira Rẹ kalẹ fun wọn, ti O si se alaye oju-ọna ti o tọ fun wọn. Ati pe ti kò ba si ti eleyii ni, dajudaju nse ni wọn o ba da gẹgẹ bi awọn ẹranko, ipo wọn o ba si buru ju ti awọn ẹranko naa lọ. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba gba isẹ Ọlọhun ti O fi ransẹ, ti o si duro sinsin lori rẹ, oluwaarẹ n bẹ ninu awọn t'o loore ju ninu awọn ẹda, ati pe ẹnikẹni ti o ba kọ ọ, ti o si jade kuro ninu rẹ, onitọun wa ninu awọn ti o buru ju ninu awọn ẹda, ti o si buru ni ipo ju ajá ati ẹlẹdẹ lọ, ti o si yẹpẹrẹ ju gbogbo ẹni-yẹpẹrẹ lọ. Kò si si sisẹku fun awọn ara ilẹ afi pẹlu awọn oripa isẹ [ti Ọlọhun fi ransẹ] ti n bẹ laarin wọn, tori naa ti oripa awọn ojisẹ naa ba ti parẹ kuro lori ilẹ, ti awọn ami imọna wọn si poora, Ọlọhun yoo fọ aye ti oke ati ti isalẹ, yoo si gbe igbende dide.

Ati pe bukaata awọn ara ilẹ si ojisẹ ki i se bii bukaata wọn si oorun ati osupa ati atẹgun ati ojo, ki i tilẹ se bii bukaata eniyan si isẹmi rẹ, tabi bii bukaata oju si imọlẹ oorun, tabi ti ara si ounjẹ ati ohun mimu, koda o tobi ju eleyii lọ, bukaata rẹ si i si ni agbara ju gbogbo ohun ti a le pebubu ti o si le sọ si ni lọkan lọ, nitori naa ẹni ti o wa laarin Ọlọhun -giga ni fun Un- ati awọn ẹda Rẹ ni awọn ojisẹ nipa asẹ Rẹ ati kikọ Rẹ, ati pe awọn ni iransẹ laarin Rẹ ati awọn ẹru Rẹ, Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba oun ati gbogbo wọn lapapọ" si jẹ opin wọn, ati asiwaju wọn, ati ẹni ti o ni apọnle ju ni ọdọ Oluwa rẹ, Ọlọhun ran an ki o maa jẹ ikẹ fun gbogbo ẹda, awijare fun awọn olutọ-oju-ọna Rẹ, awijare lori gbogbo ẹda lapapọ, O si se titẹle e, ati nini ifẹ rẹ, ati gbigbe e ga, ati sise atilẹyin fun un, ati didide pẹlu sise awọn iwọ rẹ, ni ọranyan lori awọn ẹru Rẹ; ati pe O gba awọn adehun ati awọn majẹmu lori atigba a gbọ lododo, ati titẹle e lọdọ gbogbo awọn anabi, ati awọn ojisẹ, O si pa wọn lasẹ pe ki wọn o gba a lọdọ ẹnikẹni ti o ba tẹle wọn ninu awọn olugbagbọ-ododo, O ran an nisẹ ki igbende o too de, ni olufuni-niro-idunnu, ati olukilọfunni, ati olupepe lọ si ọdọ Ọlọhun pẹlu iyọnda Rẹ, ati atupa ti n mọlẹ. Tori naa O fi i pe isẹ riran naa, O si fi i mọna nibi anu, O si fi i kọ'ni ni imọ nibi aimọkan, O si fi isẹ rẹ ya awọn oju ti o ti fọ, ati awọn eti ti o ti di, ati awọn ọkan ti o ti di, ilẹ si mọlẹ latari isẹ rẹ lẹyin awọn okunkun rẹ, awọn ọkan si di mọra wọn pẹlu rẹ lẹyin fifọnka wọn yẹlẹyẹlẹ. Ọlọhun si fi i gbe ilana ti o wọ dide, O si fi i se alaye oju-ọna ti o funfun, O si sipaya igbaaya rẹ fun un, O si gbe ẹru wiwo rẹ kuro fun un, O si gbe orukọ rẹ ga fun un, O si se iyẹpẹrẹ, ati abuku, ni ti ẹni ti o ba tako asẹ rẹ, O ran Anabi yii “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" nisẹ nigba dida wiwa awọn ojisẹ, ti awọn tira si ti parẹ, nigba ti wọn ti yi ọrọ naa pada, ti wọn si ti pa awọn ofin naa da, ti gbogbo ijọ kọọkan si fi ẹyin ti abosi awọn aba wọn, ti wọn si n dajọ le Ọlọhun lori, ati laarin awọn ẹru Rẹ pẹlu awọn ọrọ buburu ti wọn n sọ, ati awọn ifẹẹnu wọn, tori naa Ọlọhun fi i fi awọn ẹda mọna, O si fi i se alaye oju-ọna, O si fi i mu awọn eniyan jade kuro ninu awọn okunkun lọ sinu imọlẹ, O si fi i se iyatọ laarin awọn ẹni ti o jere ati awọn ẹni-ẹsẹ, tori naa imọna rẹ ni ẹni ti o mọna fi mọna, ati pe ẹni ti o ba yẹra kuro ni ọna rẹ dajudaju o ti sọnu, o si ti tayọ-ala. Ikẹ ati ọla Ọlọhun k'o maa ba oun, ati gbogbo awọn ojisẹ, ati anabi yoku.

A si le ta koko bukaata eniyan si isẹ ti Ọlọhun fi i maa n ransẹ naa si ara ohun ti n bọ yii:

1- Wi pe ẹni ti a da, ti o si ni Oluwa ni eniyan, dandan si ni pe ki o wa mimọ nipa Ẹlẹda rẹ, ki o si mọ ohun ti N fẹ lọdọ rẹ, ati pe ki l'o mu Un se ẹda rẹ, eniyan kò si le e da mọ eleyii, bẹẹ ni kò si ọna kan lati lọ sidi rẹ, afi lati ara mimọ awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ati mimọ ohun ni wọn mu wa, ninu imọna, ati imọlẹ.

2- Wi pe latara ara ati ẹmi ni eniyan ti kojọ, ounjẹ ara si ni ohun ti o ba rọrun ninu ohun jijẹ, ati ohun mimu, ounjẹ ti ẹmi, Ẹni ti O da a ti da a fun un, oun ni ẹsin otitọ, ati isẹ rere, ati pe awọn anabi ati awọn ojisẹ mu ẹsin otitọ wa, wọn si tọka si isẹ rere.

3- Wi pe ẹlẹsin ni eniyan ninu adamọ rẹ; dandan si ni ki o ni ẹsin kan ti yoo maa se; ati pe dandan ni ki ẹsin yii o jẹ otitọ, kò si si ọna kan lati lọ sidi ẹsin otitọ afi lati ara nini igbagbọ-ododo si awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ati gbigba ohun ti wọn mu wa gbọ lododo.

4- Wi pe o n bukaata mimọ ọna, eyi ti yoo mu un lọ sibi iyọnu Ọlọhun ni ile-aye, ati lọ si ọgba-idẹra Rẹ, ati idẹra Rẹ ni ile igbẹyin, ati pe ẹnikan kò le e fi'ni mọna lọ sidi rẹ, ki o si tọka rẹ fun'ni afi awọn anabi, ati awọn ojisẹ.

5- Wi pe ọlẹ ni eniyan funra rẹ, awọn ọpọlọpọ ọta l'o si lugọ de e, ninu esu ti o fẹ si i lọna, ati awọn alabarin buburu ti yoo maa se aidaa ni ọsọ fun un, ati ẹmi kan ti i maa n pa ni lasẹ pẹlu aidaa, idi niyi ti o fi jẹ ẹni ti n bukaata ohun ti yoo maa fi sọ ara rẹ nibi ete awọn ọta rẹ, awọn anabi ati ojisẹ si ti tọka si eleyii, wọn si se alaye rẹ ni opin alaye.

6- Wi pe olubaniyanse ni eniyan ninu adamọ, dandan si ni ki pipade rẹ pẹlu awọn eniyan ati ibasepọ rẹ pẹlu wọn o ni ofin kan, nitori ki awọn eniyan o le baa dide pẹlu sise dọgba ati deedee -lai jẹ bẹẹ, nse ni isẹmi wọn yoo jẹ ohun ti o jọ isẹmi inu-igbẹ- ati pe dandan ni ki ofin yii o maa sọ iwọ fun gbogbo oni-iwọ, lai kò fi i falẹ, tabi gbigbe e tayọ ala, bẹẹ ni ẹnikan kò le mu ofin ti o pe wa yatọ si awọn anabi, ati awọn ojisẹ.

7- Wi pe o n bukaata lati mọ ohun ti yoo mu un ni ifayabalẹ ati isinmi ẹmi, ti yoo si fi i mọna lọ sibi awọn okunfa oriire tootọ, eyi si ni ohun ti awọn anabi ati awọn ojisẹ n tọka si.

Lẹyin ti a ti se alaye bukaata awọn ẹda si awọn anabi, ati awọn ojisẹ, o tọ si wa pe ki a sọ nipa agbende, ki a si se alaye awọn awijare, ati awọn ẹri ti n tọka si i.

###

AGBENDE

Gbogbo eniyan ni o mọ amọdaju pe kò si ibuyẹsi pe oun yoo ku, sugbọn ki ni atunbọtan rẹ lẹyin iku naa? Njẹ oloriire ni i, tabi oloriibu?.

Dajudaju ọpọlọpọ ninu awọn ẹya, ati awọn ijọ, ni wọn ni adisọkan pe a o gbe wọn dide lẹyin iku, a o si se isiro fun wọn lori awọn isẹ wọn, ti o ba jẹ rere, rere ni yoo jẹ ti wọn, ti o ba si jẹ aburu, aburu ni yoo jẹ ti wọn; ọrọ yii -iyẹn igbende ati isiro- awọn laakaye ti wọn gbadun gba a, bẹẹ ni awọn ofin Ọlọhun naa si n ka an nipa, ati pe ori awọn ipilẹ mẹta ni a mọ ọn le:

1- Fifi pipe imọ Oluwa -mimọ ni fun Un- rinlẹ.

2- Fifi pipe agbara Rẹ -mimọ ni fun Un- rinlẹ.

3- Fifi pipe Hikmah -ọgbọn- Rẹ -mimọ ni fun Un- rinlẹ.

Ati pe awọn ẹri ti a gba wa ati ti laakaye pọ lori fifi i rinlẹ, ninu awọn ẹri wọnyi ni ohun ti n bọ yii:

1- Fifi dida awọn sanma ati ilẹ se ẹri lori jiji awọn oku. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} أو لم يروا أن الله الذي خلق السموات والأرض ولم يعي بخلقهن بقادر على أن يحيي الموتى بلى إنه على كل شيء قدير { [سورة الأحقاف: 33].

« Njẹ wọn kò wa mọ ni pe dajudaju Ọlọhun, Ẹni ti O da awọn sanma ati ilẹ, ti kò si ko aarẹ nipa dida wọn, ni Alagbara lori pe ki O ji awọn oku bi? Bẹẹ ni, dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan » [Suuratul-Ahqaaf: 33]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} أو ليس الذي خلق السموات والأرض بقادر على أن يخلق مثلهم بلى وهو الخلاق العليم { [سورة يس: 81].

« Njẹ Ẹni ti O da awọn sanma ati ilẹ kọ ni Alagbara lati da iru wọn bi? Bẹẹ ni, Oun ni Olusẹda Oni-mimọ » [Suuratu Yaasin: 81].

2- Fifi agbara Rẹ lori dida ẹda lai jẹ pe apejuwe kan ti siwaju se ẹri fun agbara Rẹ lori dida a pada ni ida keji, tori pe Alagbara lori pipilẹ mu ẹda maa bẹ, yoo jẹ pe O ni agbara ju lori dida a pada, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وهو الذي يبدأ الخلق ثم يعيده وهو أهون عليه وله المثل الأعلى { [سورة الروم: 27].

« Ati pe Oun ni Ẹni ti N bẹrẹ ẹda dida, lẹyin naa yoo tun tun un da, ati pe eleyii l'o rọrun ju fun Un, tiẸ si ni apejuwe ti o ga ju » [Suuratur-Ruum: 27]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn tun sọ pe:

} وضرب لنا مثلاً ونسي خلقه قال من يحيي العظام وهي رميم. قل يحييها الذي أنشأها أول مرة وهو بكل خلق عليم { [سورة يس: 78، 79].

« Ati pe o se apejuwe fun Wa, o si gbagbe isẹda rẹ. O sọ pe: Ta ni yoo ji egungun ti o ti kẹfun?. Sọ pe: Ẹni ti O se ẹda rẹ ni igba akọkọ ni yoo ji i, Oun si ni Oni-mimọ nipa gbogbo ẹda » [Suuratu Yaasin: 78, 79].

3- Dida eniyan lori didọgba ti o dara ju, pẹlu aworan ti o pe yii, pẹlu awọn orike rẹ, agbara rẹ, awọn iroyin rẹ, ati ohun ti o wa lara rẹ ninu ẹran, egungun, awọn isan, ọpọlọ, ati awọn ọna ti nnkan n gba kọja, ati awọn ẹrọ, ati awọn imọ, ati awọn erongba, ati rirọ awọn nnkan, ẹri ti o tobi ju wa ninu wọn lori agbara Rẹ -mimọ ni fun Un- lori jiji awọn oku.

4- Sise ẹri pẹlu jiji awọn oku ni ile-aye nibi lori agbara Rẹ -mimọ ni fun Un- lati ji awọn oku ni ile ikẹyin, ati pe dajudaju iroyin ti wa nipa eleyii ninu awọn tira Ọlọhun, eyi ti Ọlọhun sọ kalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, ninu awọn iroyin wọnyi si ni jiji awọn oku pẹlu iyọnda Ọlọhun lati ọwọ Anabi Ibraahiim, ati Al-Masiihu -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn", bẹẹ ni eyi ti o yatọ si eleyii pọ.

5- Fifi agbara Rẹ lori awọn ohun ti o jọ akojọ ati agbende se ẹri lori jiji oku; ninu eleyii si ni:

(a) Dida ti Ọlọhun da eniyan lati ara àtọ ninu omi gbọlọgbọlọ, ti o se pe nse l'o wa ni ọtọọtọ ninu ara -eyi l'o fa ti gbogbo awọn orike ara fi i maa n jọ n jẹ igbadun ibalopọ- Ọlọhun yoo si ko àtọ yii jọ lati awọn ayika ara, lẹyin naa ni yoo jade lọ si inu apo-ibi, Ọlọhun O si da eniyan lati ara rẹ, tori naa ti awọn ipin yii ba jẹ ohun ti o wa ni ọtọọtọ ti Ọlọhun si ko o jọ, ti o si ti ara rẹ ko eniyan yii jọ, ti o ba tun wa tuka latari iku ni ida mìíran, njẹ bawo ni kò ti ni i see se fun Un lati ko o jọ ni ida mìíran!. Ọlọhun t'O ga ni Olusọrọ sọ pe:

} أفرأيتم ما تمنون. أأنتم تخلقونه أم نحن الخالقون { [سورة الواقعة: 58، 59].

« Ẹyin kò wa ri ohun ti ẹ n da jade [lara]?. Sé ẹyin ni ẹ n da a ni, tabi Awa ni Oluda a » [Suuratul-Waaqi'ah: 58, 59].

(b) Pe awọn koro irugbin t'ohun ti bi awọ rẹ ti se yatọ sira wọn, ti o ba bọ si ilẹ ẹrọfọ, ti omi ati erupẹ ba si bori rẹ, ohun ti iwoyesi laakaye yoo da lẹjọ ni ki o jẹra, ki o si bajẹ, nitori pe ọkan ninu wọn to lati mu un jẹra, tori naa jijẹra nigba ti mejeeji ba pade l'o sunmọ ju, sugbọn kò ni i bajẹ, nse ni yoo bẹ ni ohun ti a sọ, lẹyin naa nigba ti ririn naa ba lekun, koro naa yoo pin, irugbin yoo si ti inu rẹ jade, njẹ eleyii kò wa maa tọka si agbara ti o pe, ati Hikmah -ọgbọn- ti o kari bi? Nitori naa bawo ni Ọlọhun, Ọlọgbọn, Alagbara yii, yoo ti kagara lati ko awọn ipin ara naa jọ ati lati to awọn orike naa jọ!. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} أفرأيتم ما تحرثون. أأنتم تزرعونه أم نحن الزارعون { [سورة الواقعة: 63، 64].

« Njẹ ẹyin kò wa ri ohun ti ẹ n gbin ni bi?. Sé ẹyin ni ẹ n gbin in ni, tabi Awa ni Olugbin in? » [Suuratul-Waaqi'ah: 63, 64]. Iru eleyii tun ni ọrọ Ọlọhun -giga ni fun Un-:

} وترى الأرض هامدة فإذا أنزلنا عليها الماء اهتزت وربت وأنبتت من كل زوج بهيج { [سورة الحج: 5].

« Irẹ yoo ri ilẹ ti o ti gbẹ, nigba ti A ba sọ omi [ojo] kalẹ le e lori, yoo yirapada, yoo si gberu, yoo si hu jade ninu gbogbo awọn orisirisi irugbin ti o dara » [Suuratul-Hajj: 5].

6- Wi pe Ẹlẹda, Alagbara, Oni-mimọ, Ọlọgbọn, mọ kuro nibi ki O da ẹda lasan, ki O si fi wọn silẹ lasan, Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, sọ pe:

} وما خلقنا السماء والأرض وما بينهما باطلاً ذلك ظن الذين كفروا فويل للذين كفروا من النار { [سورة ص: 27].

« Ati pe Awa kò da sanma ati ilẹ ati ohun ti o wa ni agbedemeji wọn lasan. Ero awọn ti kò gbagbọ niyun un, nitori naa egbe ni fun awọn ti kò gbagbọ ninu ina » [Suuratu Saad: 27]. Bẹẹ kọ, nse l'O da ẹda Rẹ nitori ọgbọn nla, ati ero ti o ga; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وما خلقت الجن والإنس إلا ليعبدون { [سورة الذاريات: 56].

« Ati pe N kò da awọn alujannu ati awọn eniyan afi nitori ki wọn o le baa maa jọsin fun Mi » [Suuratu z-Zariyaat :56]. Nitori naa kò tọ si Ọlọhun, Ọlọgbọn yii, pe ki ẹni ti n tẹle tiẸ o dọgba pẹlu ẹni ti o kọ tiẸ ni ọdọ Rẹ, Ọlọhun ti O ga sọ pe:

} أم نجعل الذين آمنوا وعملوا الصالحات كالمفسدين في الأرض أم نجعل المتقين كالفجار { [سورة ص: 28].

« Njẹ Awa le se awọn ti o gbagbọ ni ododo, ti wọn si sisẹ rere, gẹgẹ bi awọn obilẹjẹ lori ilẹ bi? Abi Awa le se awọn olubẹru Ọlọhun gẹgẹ bi awọn ẹni-buburu bi? » [Suuratu Saad: 28]. Nitori naa ni o se n bẹ ninu pipe ọgbọn Rẹ, ati titobi bibori Rẹ, pe ki O gbe awọn ẹda dide ni ọjọ igbende, ki O le baa san gbogbo eniyan lẹsan isẹ rẹ, yoo san oluse-rere ni ẹsan rere, yoo si jẹ onibajẹ niya; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إليه مرجعكم جميعاً وعد الله حقاً إنه يبدأ الخلق ثم يعيده ليجزي الذين آمنوا وعملوا الصالحات بالقسط والذين كفروا لهم شراب من حميم وعذاب أليم { [سورة يونس: 4].

« Ọdọ Rẹ ni apadasi yin lapapọ, otitọ ni adehun Ọlọhun. Dajudaju Oun ni Olupilẹ dida ẹda, lẹyin naa yoo da a pada, ki O le san awọn ti wọn gbagbọ ni ododo, ti wọn si se isẹ rere, ni ẹsan pẹlu deedee, ati pe awọn ti wọn se alaigbagbọ, ti wọn ni mimu ninu omi gbigbona, ati iya ẹlẹta-elero yoo jẹ » [Suuratu Yuunus: 4].

Gbigba ọjọ igbẹyin -ọjọ igbende ati akojọ- gbọ lododo ni awọn oripa pupọ lori onikaluku ati awujọ; ninu awọn oripa rẹ ni:

1- Wi pe ki eniyan o gbiyanju lori titẹle ti Ọlọhun, ni ti sise ojukokoro ẹsan ọjọ yii, ki o si jinna si sisẹ Ẹ, ni ibẹru iya ẹsẹ ọjọ naa.

2- Iparonurẹ wa ninu gbigba ọjọ ikẹyin gbọ fun olugbagbọ-ododo nibi ohun ti o bọ mọ ọn lọwọ ninu idẹra ile-aye, ati igbadun rẹ, nitori ohun ti n rankan ninu idẹra ti ọjọ ikẹyin, ati ẹsan rẹ.

3- Pẹlu gbigba ọjọ ikẹyin gbọ ni eniyan o fi mọ ibo ni apadasi oun lẹyin iku rẹ, ti yoo si mọ daju pe oun yoo ri ẹsan isẹ oun, bi o ba jẹ rere yoo ri rere, ti o ba si jẹ aburu yoo ri aburu, ati pe a o da a duro fun isiro, a o si gbẹsan fun un lọdọ ẹni ti o se abosi fun un, a o si gba iwọ awọn eniyan ni ọdọ rẹ fun ẹni ti o se abosi fun, ti o si tayọ ala lori rẹ.

4- Wi pe gbigba ọjọ ikẹyin gbọ a maa mu ifayabalẹ ati alaafia wa fun awọn eniyan -ni asiko kan ti ifayabalẹ wọn, ti ogun kò si duro ninu rẹ- ati pe nnkan kan kọ l'o mu ki eleyii o jẹ bẹẹ bi kò se pe gbigba Ọlọhun gbọ, ati ọjọ ikẹyin, a maa se e ni ọranyan lori eniyan lati ko aburu rẹ ro kuro ni ọdọ ẹlomiran ni ikọkọ rẹ ati ni gbangbá, koda a maa wọ inu ohun ti o ba rọrun fun un ninu igbaaya rẹ, yoo si pa awọn aniyan buburu -ti o ba wa nibẹ- yoo si yanju wọn siwaju ki a to bi wọn.

5- Gbigba ọjọ ikẹyin gbọ a maa le eniyan jinna si sise abosi si awọn mìíran, ati nibi gbigbe ẹsẹ le ẹtọ wọn, nitori naa ti awọn eniyan ba gba ọjọ ikẹyin gbọ ni ododo, wọn yoo bọ lọwọ abosi apa kan wọn si omiran, ati pe awọn ẹtọ yoo jẹ ohun ti a sọ.

6- Gbigba ọjọ ikẹyin gbọ ni ododo a maa se eniyan ni ẹni ti n wo ile-aye ni ibusọ kan ninu awọn ibusọ isẹmi, ti ki i si i se gbogbo isẹmi.

Ni ipari ẹsẹ ọrọ yii, yoo dara pe ki a fi ọrọ “Wainbat" ti o jẹ ẹlẹsin agbelebu -Christian- ti o jẹ ọmọ Amẹrika se ẹri; ẹni ti o jẹ pe ni ọkan ninu awọn sọọsi l'o ti n sisẹ tẹlẹ, lẹyin naa ti o gba ẹsin Islam, ti o si ri eso nini igbagbọ-ododo si ọjọ ikẹyin, ni ibi ti o ti n sọ pe:

« Dajudaju emi mọ idahun awọn ibeere mẹrin ti o ko airoju ba isẹmi pupọ ni isinyi. Oun ni: Ta ni mi? Ki ni mo n fẹ? Ki si l'o mu mi wa? Ati pe ibo ni apadasi mi? ».

###

AWỌN IPILẸ IPEPE AWỌN OJISẸ

Ẹnu awọn anabi ati awọn ojisẹ ko lori ipepe lọ sidi awọn ipilẹ ti o kari, gẹgẹ bi gbigba Ọlọhun gbọ ni ododo, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati gbigba akọọle -kadara- gbọ ni ododo, rere rẹ ati aburu rẹ; ati gẹgẹ bi ipanilasẹ pẹlu jijọsin fun Ọlọhun nikan soso, kò si orogun kan fun Un, ati titẹle oju-ọna Rẹ, ati aitẹle awọn ọna ti o yapa si i, ati sise ohun orisi mẹrin ni eewọ, awọn ni: Awọn ibajẹ ohun ti o han ninu rẹ ati ohun ti o pamọ, ati ẹsẹ, ati sise agbere lai jẹ pẹlu otitọ, ati sise ẹbọ si Ọlọhun, ati sisin awọn ere, ati awọn oosa. Ati fifọ Ọ mọ kuro nibi iyawo, ati ọmọ, ati orogun, ati alafijọ, tabi alafiwe, ati nibi ki a sọ nnkan kan nipa rẹ yatọ si otitọ, ati sise pipa awọn ọmọ leewọ, ati sise pipa ẹmi lai jẹ pẹlu otitọ ni eewọ, ati kikọ owo-ele -riba- ati jijẹ owo ọmọ-orukan. Ati ipanilasẹ pẹlu pipe adehun ati osuwọn ati iwọnka, ati sise rere si awọn obi mejeeji, ati sise dọgba laarin awọn eniyan, ati ododo ninu ọrọ, ati isẹ, ati kikọ ina-apa, ati igberaga, ati jijẹ owo awọn eniyan pẹlu ibajẹ fun'ni.

Ibnul Qayyim -ki Ọlọhun O kẹ ẹ- sọ pe: « Awọn ofin -Sharia- lapapọ dọgba ninu awọn ipẹlẹ wọn -wọn o baa tilẹ yatọ sira wọn- daadaa wọn si fidi mulẹ ninu awọn laakaye, ati pe ti o ba se pe ori ohun ti o yatọ si ori ohun ti wọn wa lori rẹ ni wọn wa ni, dajudaju wọn o ba jade kuro ninu Hikmah -ọgbọn- ati anfaani ati ikẹ; koda kò tilẹ see se pe ki wọn mu ohun ti o yapa si ohun ti wọn mu wa wa:

} ولو اتبع الحق أهواءهم لفسدت السموات والأرض ومن فيهن { [سورة المؤمنون: 71].

« Ati pe ti o ba se pe ododo naa tẹle ifẹ-inu wọn ni, dajudaju sanma ati ilẹ o ba ti bajẹ ati awọn ti o wa ninu wọn » [Suuratul-Mu'uminuun: 71]. Ati pe bawo ni onilaakaye yoo ti se gba pe ki ofin Ọlọhun ti O mọ ẹjọ da ju gbogbo oludajọ lọ o wa pẹlu atodijẹ ohun ti o mu wa? »[[5]].

Eyi l'o si mu ki ẹsin awọn anabi o jẹ ọkan, gẹgẹ bi Ọlọhun -giga ni fun Un- ti sọ pe:

} يا أيها الرسل كلوا من الطيبات واعملوا صالحاً إني بما تعملون عليم. وإن هذه أمتكم أمة واحدة وأنا ربكم فاتقون { [سورة المؤمنون: 51-52].

« Ẹyin ojisẹ ẹ maa jẹ ninu ohun ti o dara, ki ẹ si maa se daadaa, dajudaju Emi ni Olumọ nipa ohun ti ẹ n se nisẹ. Ati pe dajudaju eyi ni ijọ yin, ijọ kan soso; Emi si ni Oluwa yin, tori naa ẹ maa bẹru Mi » [Suuratul-Mu'uminuun: 51-52]. Ọba ti O gbọn-un-gbọn ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} شرع لكم من الدين ما وصى به نوحاً والذي أوحينا إليك وما وصينا به إبراهيم وموسى وعيسى أن أقيموا الدين ولا تتفرقوا فيه { [سورة الشورى: 13].

« O se l'ofin fun yin ninu ẹsin ohun ti O fi pa Nuuhu lasẹ, ati eyi ti A fi ransẹ si Ọ, ati eyi ti A sọ asọtẹlẹ rẹ fun Ibraahiim, ati Musa, ati Isa, pe ki ẹ gbe ẹsin naa duro, ati pe ki ẹ ma se pin yẹlẹyẹlẹ nidi rẹ » [Suuratu Shuraa: 13].

Koda ohun ti a gba lero pẹlu ẹsin ni ki awọn ẹru o de ibi ohun ti a da wọn fun, ninu jijọsin fun Oluwa wọn ni Oun nikan soso, kò si orogun kan fun Un, nitori naa yoo se ni ofin fun wọn ninu awọn ẹtọ ohun ti o jẹ ọranyan lori wọn pe ki wọn o gbe duro, yoo si se olugbọwọ fun wọn ninu awọn ọranyan, yoo si maa se atilẹyin fun wọn pẹlu awọn ọna ti yoo gbe wọn de idi ohun afojusi yii, ki iyọnu Ọlọhun o le baa jẹ ti wọn, ati oriire ile mejeeji, ni ibamu pẹlu ilana Ọlọhun, kò ni ya ẹru ni gbogbo yiya, kò si ni i ko aarẹ fifọnka yẹlẹ-yẹlẹ buburu ba a, eyi ti yoo mu un kọlu adamọ rẹ, ati ẹmi rẹ, ati ile-aye ni ayika rẹ.

Nitori naa gbogbo awọn ojisẹ n pepe lọ sidi ẹsin Ọlọhun, eyi ti yoo fun eniyan ni ipilẹ adisọkan ti yoo gbagbọ, ati ofin eyi ti yoo maa rin ni ori rẹ ninu isẹmi rẹ, idi niyi ti At-Tawraata -Majẹmu Laelae- fi jẹ “iwe" adisọkan ati ofin, ti a si pa awọn ẹni rẹ lasẹ pe ki wọn o maa wa idajọ lọ si idi rẹ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إنا أنزلنا التوراة فيها هدى ونور يحكم بها النبيون الذين أسلموا للذين هادوا والربانيون والأحبار { [سورة المائدة: 44].

« Dajudaju Awa ti sọ At-Tawraata kalẹ, imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ. Awọn anabi ti wọn gbafa fun Ọlọhun a maa dajọ pẹlu rẹ fun awọn Yahuudi, ati pe awọn alufa wọn agba ati awọn amofin wọn naa [a maa dajọ pẹlu rẹ] » [Suuratul-Maa'idah: 44]. Lẹyin naa ni Al-Masiihu -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" de ati Injiila -Bibeli- pẹlu rẹ, imọna, ati imọlẹ, n bẹ ninu rẹ, o si n jẹri ododo si ohun ti o siwaju rẹ ninu At-Tawraata; Ọba ti ẹyin Rẹ ga, sọ pe:

} وقفينا على آثارهم بعيسى ابن مريم مصدقا لما بين يديه من التوراة وآتيناه الإنجيل فيه هدى ونور { [سورة المائدة: 46].

« Ati pe Awa fi Anabi Isa ọmọ Maryama tẹle ipasẹ wọn, ni olujẹri ododo si ohun ti o siwaju rẹ ninu At-Tawraata, A si fun un ni Injiila -Bibeli- imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ » [Suuratul-Maa'idah: 46]. Lẹyin eleyii ni Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", wa de pẹlu ofin -Sharia- ti opin, ati ẹsin pipe, ti o si jẹ olusọ lori ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn ofin, ati oluparẹ fun wọn, Ọlọhun si fun un ni Al-Qur'aani, ti o jẹ olumuni-mọ ohun ti o jẹ ododo ninu ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn tira; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وأنزلنا إليك الكتاب بالحق مصدقاً لما بين يديه من الكتاب ومهيمنا عليه فاحكم بينهم بما أنزل الله ولا تتبع أهواءهم عما جاءك من الحق { [سورة المائدة: 48].

« A si ti sọ Tira naa kalẹ fun ọ pẹlu ododo, o jẹ olumuni-mọ ohun ti o jẹ ododo ninu ohun ti o siwaju rẹ ninu tira, ati olusọ lori rẹ, nitori naa maa se idajọ laarin wọn pẹlu ohun ti Ọlọhun sọ kalẹ, ma si se tẹle ifẹ-inu wọn kuro nibi ohun ti o wa ba ọ ninu ododo » [Suuratul-Maa'idah: 48]. Ati pe Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- se alaye pe Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati awọn olugbagbọ-ododo pẹlu rẹ, gba Oun gbọ ni ododo, gẹgẹ bi awọn ti o siwaju wọn ninu awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ti se gba A gbọ lododo; nitori naa Ọba ti ẹyin Rẹ ga Naa, sọ pe:

} آمن الرسول بما أنزل إليه من ربه والمؤمنون كل آمن بالله وملائكته وكتبه ورسله لا نفرق بين أحد من رسله وقالوا سمعنا وأطعنا غفرانك ربنا وإليك المصير { [سورة البقرة: 285].

« Ojisẹ naa gba ohun ti a sọ kalẹ fun un lati ọdọ Oluwa rẹ gbọ, ati awọn olugbagbọ-ododo, onikaluku wọn gba Ọlọhun gbọ lododo, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, a kò ni i se iyatọ laarin ọkan ninu awọn ojisẹ Rẹ, wọn sọ pe: A gbọ, a si tẹle [tiẸ], dari jin wa Oluwa wa, ọdọ Rẹ si ni ibupadasi [wa] » [Qur'aani, Baqarah: 285].

###

ISẸ ỌLỌHUN TI YOO MAA BẸ LỌ GBERE

Ohun ti o siwaju ninu sise afihan ipo awọn ẹsin Yahuudi, ati ti alagbelebu -Christians- ati ti Majuusi -awọn sinna-sinna- ati ti Ziraadishtiyyah, ati ti awọn abọrisa lorisirisi, n se alaye ipo awọn eniyan ni ọdun ọgọrun kẹfa lẹyin bibi Jesu, ti ẹsin ba si ti bajẹ nse ni awọn eto oselu, ati ti ajumọgbe, ati ti ọrọ-aje, yoo bajẹ … tori naa awọn ogun adẹjẹsilẹ yoo kari aye, didari awọn eniyan ni ọna imunisin o si yọju, awọn eniyan yoo si maa sẹmi ninu okunkun biribiri, awọn ọkan o si titori rẹ sokunkun, nitori okunkun aigbagbọ, ati aimọkan, awọn iwa o si dọti, wọn o si fa iyi ya, wọn o si gbe ẹsẹ le awọn ẹtọ, ibajẹ yoo si han ni ori ilẹ ati ninu okun, debi wi pe ti onilaakaye ba woye si i -ni asiko naa- dajudaju ki ba ri i pe awọn eniyan wa ni ipo ipọka-iku, ati pe o n kede atitan ile-aye, ti Ọlọhun kò ba gba a silẹ pẹlu alatunse nla kan ti yoo gbe atupa jijẹ anabi lọwọ, ati òye imọna, ki o le baa mọlẹ oju-ọna awọn eniyan fun wọn, ki o si le baa fi wọn mọna lọ si oju-ọna ti o tọ.

Ni asiko yii ni Ọlọhun yọnda pe ki imọlẹ jijẹ anabi laelae o tan lati [ilu] Makkah alapọnle, eyi ti ile Ọlọhun alapọnle wa ninu rẹ, ati pe ayika rẹ jẹ ohun ti o jọ awọn ayika awọn eniyan yoku, nipa sise ẹbọ si Ọlọhun, ati aimọkan, ati abosi, ati didari ẹni ni ọna ti a fẹ; yatọ si wi pe o yatọ si ibomiran pẹlu awọn iyatọ pupọ; [ti o se pe] ninu wọn ni:

1- Wi pe ayika kan ti o mọ ni i, kò lapa pẹlu eeri irori -filọsọfi- awọn Giriisi “Greece", tabi ti awọn Roomu “Rome", tabi ti awọn India, ati pe awọn ara ibẹ jẹ ẹni ti o ni anfaani alaye amọgbọndani, ati ọpọlọ ti o mọlẹ, ati awọn adamọ ti i maa n fa ohun ti kò ni afijọ yọ.

2- Wi pe ọkan ile-aye l'o bọ si, aaye kan ti o jẹ aarin-gbun-gbun laarin Europe ati Asia ati Africa l'o wa, eyi n bẹ ninu ohun ti yoo jẹ okunfa pataki kan nipa titete tan ka, ati ki isẹ laelae yii o de awọn origun ile-aye wọnyi ninu asiko diẹ.

3- Wi pe ilu ifayabalẹ ni i, nigba ti o se pe Ọlọhun daabo bo o, nigba ti Abrahata gbero lati ja a logun, bẹẹ ni awọn ijọba nlanla ti awọn Furus “Persian" ati Roomu “Rome" ti o wa ni itosi rẹ kò si da ọwọ tẹ ẹ ri, kaka bẹẹ, nse ni o wa ninu ifayabalẹ, titi ti o fi de ori rira-tita [owo] rẹ lọ si arewa ati gusu, ati pe eleyii jẹ ami ipalẹmọ fun gbigbe Anabi alapọnle yii dide; Dajudaju Ọlọhun si ti ran awọn ara ibẹ leti pẹlu idẹra yii, O si sọ pe:

} أو لم نمكن لهم حرماً آمنا يجبى إليه ثمرات كل شيء { [سورة القصص: 57].

« Njẹ A kò ti fun wọn ni aaye ọwọ kan, ti o ni ifọkanbalẹ gbe, ti a n fa awọn [orisirisi] eso gbogbo nnkan wa sibẹ bi? » [Suuratul-Qasas: 57].

4- Wi pe aaye asalẹ kan ni i, o se isọ ọpọlọpọ ninu awọn iwa ẹyin, gẹgẹ bi apọnle, ati sisọ iwọ alabagbe, ati owu jijẹ lori awọn iyi, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn ajulọ ti o gbe e si ipo aaye ti o tọ si isẹ laelae naa.

Lati aaye nla yii, ati ninu iran Quraish ti o gbayi pẹlu idalahọn ati ki a sọrọ yọ komookun rẹ, ati awọn iwa alapọnle, iran ti o se pe oun l'o ni agbega, ati isiwaju, Ọlọhun sẹsa Anabi Rẹ, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ki o le baa jẹ opin awọn anabi ati awọn ojisẹ, nibi ti a ti bi i ni ọdun ọgọrun kẹfa lẹyin bibi Jesu, ni nnkan bii ọdun 570 A.D.

O si dide ni ọmọ-orukan, nigba ti o se pe baba rẹ ti ku, nigba ti oun wa ni inu iya rẹ, lẹyin naa ni iya rẹ ati baba baba rẹ ku, nigba ti o wa ni ọmọ ọdun mẹfa, nitori naa ọmọ-iya baba rẹ Abu Taalib se agbatọ rẹ, ọmọde-kunrin naa wa dide ni ọmọ-orukan, awọn ami mimu samsam si han ni ara rẹ. Iwa rẹ, ati isesi rẹ si yatọ si isesi awọn eniyan rẹ, ki i parọ ninu ọrọ rẹ, ki i si i ni ẹnikan lara, ati pe o gbayi pẹlu ododo sisọ, ati sisọ abẹ, ati ifọkantan, ti o fi debi pe pupọ ninu awọn eniyan rẹ l'o maa n fi ọkan tan an lori eyi ti o wọn ninu nnkan-ini wọn, wọn a si maa ko o pamọ si ọdọ rẹ, a si maa sọ ọ gẹgẹ bi o ti se n sọ ẹmi rẹ ati owo rẹ, eyi si n bẹ ninu ohun ti o mu wọn maa pe e ni Al-Amiin -ẹni ifọkantan- ati pe o jẹ onitiju, ihoho rẹ kò si han si ẹni-kankan lati igba ti o ti balaga, o si jẹ ẹni ti o mọra, olubẹru Ọlọhun, ohun ti o n ri ni ara awọn eniyan rẹ ninu ibọrisa, oti mimu, ati itajẹsilẹ, a maa ba a lọkan jẹ, tori naa a maa ba awọn eniyan rẹ se nibi ohun ti o ba yọnu si ninu awọn isẹ wọn, a si maa yẹra fun wọn nigba ti wọn ba n se palapala, ati iwa poki wọn, a si maa se iranlọwọ fun awọn ọmọ-orukan, ati awọn opó-binrin, a si maa fun awọn ti ebi n pa lounjẹ … titi ti o fi di igba ti o fẹrẹ pe ogoji ọdun, ara rẹ kò gba ohun ti n ri ni ayika rẹ ninu ibajẹ mọ, n l'o ba bẹrẹ si ni i da wa fun sisin Oluwa rẹ, n si n tọrọ lọdọ Rẹ pe ki O fi oun mọna lọ si oju-ọna ti o tọ. Laarin asiko ti o wa lori ipo yii ni malaika kan ninu awọn malaika Ọlọhun ba sọ kalẹ wa ba a pẹlu isẹ lati ọdọ Oluwa rẹ, ati asẹ Rẹ pe ki o maa jisẹ ẹsin yii fun awọn eniyan, ki o si maa pe wọn lọ sidi jijọsin fun Oluwa wọn, ki wọn si pa ijọsin fun ohun ti o yatọ si I ti. Isẹ Ọlọhun naa si tẹsiwaju ni sisọkalẹ wa si ọdọ rẹ, pẹlu awọn ofin, ati awọn idajọ, ni ọjọ kan lẹyin omiran, ati ni ọdun kan lẹyin omiran, titi ti Ọlọhun fi pe ẹsin yii fun awọn ọmọ eniyan, ti O si se idẹra naa le wọn lori pẹlu pipe rẹ, nigba ti isẹ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" pe, Ọlọhun gba ẹmi rẹ, ọjọ ori rẹ si jẹ ọdun mẹtalelọgọta nigba ti o ku, o lo ogoji ọdun ninu rẹ siwaju ki o to di anabi, o si lo mẹtalelogun ninu rẹ ti i fi n jẹ anabi, ati ojisẹ.

Ẹnikẹni ti o ba si woye si ipo awọn anabi, ti o si kọ nipa itan wọn; yoo mọ daju pe kò si ọna kan ti jijẹ anabi anabi kan ninu awọn anabi gba rinlẹ afi ki o jẹ pe jijẹ anabi Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ti gba ọna naa rinlẹ ni ọna ti o tọ ju.

Nitori naa ti o ba wo ọna ti a gba gba jijẹ anabi ti Anabi Musa, ati Anabi Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba awọn mejeeji" wa, o mọ pe a gba a wa ni lati ọna ọgọọrọ eniyan, ati pe ọna ọgọọrọ eniyan ti a si gba gba jijẹ anabi ti Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", wa tobi ju, o si nipọn ju, ati pe o sunmọ ju ni asiko.

Bakan naa ni ọna ọgọọrọ eniyan ti a gba gba awọn ohun akonilaga wọn, ati awọn arisami wọn wa jọra wọn, sugbọn ti Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" tobi ju, tori pe awọn arisami rẹ pọ, koda eyi ti o tobi ju ninu awọn arisami rẹ ni Al-Qur'aani alapọnle, eyi ti o se pe a kò i ti yee maa gba a wa ni gbigbawa gba ọna ọgọọrọ eniyan ni ohùn ati ni kikọsilẹ.

Ati pe ẹnikẹni ti o ba wo ohun ti Anabi Musa, ati Anabi Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba awọn mejeeji" mu wa, ati ohun ti Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" mu wa, ninu adisọkan ti o dara, ati awọn ofin ti o rinlẹ, ati awọn imọ alanfaani, yoo mọ daju pe lati ara opo ifatupakọ kan soso ni wọn ti jade, oun ni opo ifatupakọ ti jijẹ anabi.

Ẹnikẹni ti o ba si wo ipo awọn olutẹle awọn anabi naa si ti awọn olutẹle Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", yoo mọ daju pe awọn ni eniyan ti o loore ju fun awọn eniyan, koda awọn tilẹ l'o tobi ju ninu awọn olutẹle awọn anabi ni lilapa lori awọn ti o wa lẹyin wọn, wọn tan sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin -Tawhiid- ka, wọn si tun tan sise deedee ka, ati pe wọn jẹ aanu fun awọn alailera ati awọn alaini.

Ti o ba si n fẹ alekun alaye ti o maa fi se ẹri lori jijẹ anabi Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a"; n o mu awọn ẹri ati ami ti Ali ọmọ Rabban At-Tabarii ri nigba ti o jẹ ẹlẹsin agbelebu -Christian- ti o si titori rẹ gba ẹsin Islam.

Awọn ẹri wọnyi ni:

1- Wi pe o pepe lọ sidi sisin Ọlọhun nikan soso, ati pipa sisin ohun ti o yatọ si I ti, o fi bẹẹ se dọgba pẹlu gbogbo awọn anabi.

2- Wi pe o se afihan awọn ami ti o han, ti ẹnikan kò le mu un wa yatọ si awọn anabi Ọlọhun.

3- Wi pe o fun'ni niro nipa awọn isẹlẹ [ti yoo sẹlẹ ni] ọjọ-iwaju, o si sẹlẹ gẹgẹ bi o ti fun'ni niro nipa rẹ.

4- Wi pe o fun'ni niro nipa ọpọlọpọ isẹlẹ ninu awọn isẹlẹ ile-aye, ati ti awọn ijọba rẹ, o si sẹlẹ gẹgẹ bi o ti fun'ni niro.

5- Wi pe Tira ti Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" mu wa -ti i se Al-Qur'aani- ami kan ni i ninu awọn ami jijẹ anabi; tori pe oun ni Tira ti o de opin ju, ti Ọlọhun si sọ ọ kalẹ fun ọkunrin alaimọọkọmọọka, ti kò mọ iwe kọ, ti kò si mọ ọn ka, o si fi i pe awọn sọrọsọrọ ti o da lahọn nija pe ki wọn o mu iru rẹ wa, tabi iru Suura -ọgba ọrọ- kan ninu rẹ; ati nitori pe Ọlọhun se olugbọwọ isọ rẹ; O si fi i sọ adisọkan igbagbọ ti o dara, O si se akojọpọ ofin ti o pe ju sinu rẹ, O si fi i gbe ijọ kan ti o lọla ju dide.

6- Wi pe opin awọn anabi ni i, ati pe ti o ba se pe a kò ran an nisẹ ni, jijẹ anabi awọn anabi ti wọn fun'ni niro nipa riran an nisẹ ko ba bajẹ.

7- Wi pe awọn anabi “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn" ti fun'ni niro nipa rẹ, siwaju ki o to yọju pẹlu asiko gigun, wọn si royin riran an nisẹ, ati ilu rẹ, ati bi awọn ijọ ati awọn ọba yoo ti gba fun oun, ati ijọ rẹ, wọn si mu ẹnu ba titanka ẹsin rẹ.

8- Wi pe ami kan ninu awọn ami jijẹ anabi ni sisẹgun rẹ lori awọn ijọ ti o gbogun ti i, tori pe kò see se ki eniyan o pera rẹ ni ojisẹ kan lati ọdọ Ọlọhun -ki o si jẹ opurọ- ki Ọlọhun O maa wa se atilẹyin fun un pẹlu aranse ati igbanilaye, ati ibori awọn ọta, ati titanka ipepe rẹ, ati pupọ awọn ọmọlẹyin rẹ; dajudaju eleyii kò le sẹlẹ afi ni ọwọ anabi olododo kan.

9- Ohun ti o wa lori rẹ ninu ijọsin rẹ, ati sisọ abẹ rẹ, ododo rẹ, ati iroyin ẹyin rẹ, ilana rẹ, ati awọn ofin rẹ; dajudaju eleyii kò le pejọ afi si ara anabi kan.

Ẹni ti o mọna yii wa sọ lẹyin ti o ti ka awọn amusẹri wọnyi tan pe: « Awọn iwa ti o mọlẹ wọnyi, ati awọn ẹri ti o to yii, ẹni ti o ba mu un wa, jijẹ anabi jẹ ọranyan fun un, ọfa rẹ si se jere, ẹtọ rẹ si soriire, gbigba a lododo si jẹ ọranyan, ati pe ẹnikẹni ti o ba kọ ọ, ti o si tako o, iyanju rẹ kuna, o si se ofoo ile-aye rẹ, ati ọrun rẹ ».

Ni ipari ẹsẹ ọrọ yii, n o mu ẹri meji kan wa fun ọ: Ẹri ọba Roomu ti aye-jọhun ti o jẹ ẹni ti o l'o igba pẹlu Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati ẹri olupeni-sẹsin-agbelebu kan ti o jẹ ọmọ England ti o n ba ni logba, iyẹn John Saint.

Ẹri Alakọkọ: Ẹri Hiraql -Hercules-: Bukhari “ki Ọlọhun o kẹ ẹ" sọ iroyin Baba Sufyaan, nigba ti ọba Roomu pe e, ti o si sọ pe: « Baba Al-Yamaan, Al-Hakam ọmọ Naafiu sọ fun wa pe Shuaib fun wa niro, lati ọdọ Az-Zuhri, pe Ubaidu-L-laah ọmọ Abdul-Laah ọmọ Utbah ọmọ Mas'uud, wi pe Abdul-Laah ọmọ Abbaas fun un niro pe Baba Sufyaan ọmọ Harb fun un niro, pe Hiraql “Hercules" ran ẹni si oun laarin awọn onirin-ajo kan ninu Quraish, ti wọn jẹ olusowo ni ilẹ Shaamu, ni asiko ti Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" ba awọn Baba Sufyaan ati awọn alaigbagbọ Quraish se iwawọ-ija-bọlẹ, wọn si wa ba a ni [ilu] Elya, o si pe wọn wa si ibujokoo rẹ, nigba ti awọn ẹni-nla Roomu wa ni ayika rẹ, lẹyin naa ni o wa pe wọn, o si pe ogbefọ rẹ, o si sọ pe: Ta l'o tan mọ ọkunrin ti n pe ara rẹ ni anabi yii ni ẹbi ninu yin? N ni Baba Sufyaan ba sọ pe: Mo ni: Emi ni mo tan mọ ọn ju ni ẹbi. O ni ẹ sun un mọ mi, ki ẹ si sun awọn ẹni rẹ mọ ọn, ki ẹ si ko wọn si ẹyin rẹ; o si sọ fun ogbefọ rẹ pe: Sọ fun wọn pe emi yoo bi eleyii leere nipa ọkunrin naa, ti o ba parọ fun mi, ki ẹ ja a nirọ, o ni: Mo fi Ọlọhun bura pe ti kò ba si ti itiju pe ki wọn o ma mu mi pẹlu irọ kan ni, n o ba purọ mọ ọn, lẹyin naa akọkọ ohun ti o bi mi nipa rẹ ni pe o ni: Bawo ni ẹbi rẹ ti jẹ laarin yin? Mo ni: Ẹlẹbi [nla] ni laarin wa. O ni: Njẹ ẹnikan ninu yin wa ti sọ iru ọrọ yii siwaju rẹ ri bi? Mo ni: rara o. O ni: Njẹ ọba kan wa n bẹ ninu awọn baba-nla rẹ bi? Mo ni rara. O ni: Sé awọn ẹni-nla ninu awọn eniyan ni n tẹle e ni, tabi awọn ẹni-yẹpẹrẹ wọn? Mo ni: Awọn ẹni-yẹpẹrẹ wọn ni. O ni: Sé wọn n lekun ni, tabi wọn n dinku? Mo ni: Nse ni wọn n lekun. O ni: Njẹ ẹnikan ninu wọn a wa maa kọ ẹsin naa silẹ ni ti ibinu si ẹsin rẹ lẹyin ti o ti wọnu rẹ bi? Mo ni: rara. O ni: Njẹ ẹ wa jẹ ẹni ti n fi ẹsun irọ kan an siwaju ki o to sọ ohun ti o sọ bi? Mo ni: rara. O ni: Njẹ a maa dalẹ bi? Mo ni rara. Sugbọn awa pẹlu rẹ wa ni asiko ifijahapara, a kò si mọ ohun ti yoo se ninu rẹ. O ni gbolohun kan kò gba mi laye lati se afikun kan yatọ si gbolohun yii. O ni: Njẹ ẹ wa ja a logun bi? Mo ni: Bẹẹ ni. O ni: Njẹ bawo ni ogun ti ẹ ja a naa ti ri? Mo ni: Bori loni ki n bori lọla ni laarin wa; o n pa wa lara, awa naa si n pa a lara. O ni: Ki ni o fi n pa yin lasẹ? Mo ni: O n sọ pe: Ẹ maa sin Ọlọhun nikan soso, ẹ kò si gbọdọ fi nnkan kan se orogun fun Un, ki ẹ si fi ohun ti awọn baba yin n sọ silẹ, o si n pawa lasẹ pẹlu irun kiki, ati ododo sisọ, ati sisọ abẹ, ati siso okun ẹbi pọ. O si sọ fun ogbefọ naa pe: Sọ fun un pe: Mo bi ọ lere nipa ẹbi rẹ, o si dahun pe ẹlẹbi nla l'o jẹ ninu yin, bẹẹ naa ni awọn ojisẹ ri, a maa n gbe wọn dide lati inu ẹbi nla ninu awọn eniyan wọn. Mo si tun bi ọ leere pe njẹ ẹnikan ninu yin wa ti sọ ọrọ yii ri bi, o si fesi pe rara, mo si sọ pe: Iba se pe ẹnikan ti sọ ọrọ yii ri siwaju rẹ ni, n o ba sọ pe ọkunrin kan [ni i] ti n kọse ọrọ kan ti wọn ti sọ siwaju rẹ. Mo si bi ọ pe njẹ ọba kan wa n bẹ ninu awọn baba rẹ bi, o si dahun pe rara, mo si sọ pe: Ti o ba se pe ọba kan n bẹ ninu awọn baba rẹ ni, n o ba sọ pe ọkunrin kan [ni i] ti n wa ijọba baba rẹ. Mo si bi ọ leere pe njẹ ẹ wa n fi ẹsun irọ kan an siwaju ki o to wi ohun ti o wi bi, o si dahun pe rara, dajudaju mo mọ pe dajudaju kò gbọdọ jẹ ẹni ti yoo fi irọ pipa mọ awọn eniyan silẹ, ti yoo wa maa purọ mọ Ọlọhun. Mo si bi ọ leere pe se awọn eni-nla ninu awọn eniyan ni n tẹle e ni, tabi awọn ẹni-yẹpẹrẹ wọn, o si sọ pe awọn ẹni-yẹpẹrẹ wọn ni wọn n tẹle e, awọn naa ni olutẹle awọn ojisẹ. Mo si bi ọ leere pe njẹ wọn n pọ ni, tabi wọn n dinku, o si dahun pe nse ni wọn n pọ, bẹẹ naa ni ọrọ igbagbọ-ododo ri titi ti yoo fi pe. Mo si bi ọ leere pe njẹ ẹnikan a wa maa kọ ẹsin naa silẹ, ni ti ibinu si ẹsin rẹ, lẹyin ti o ti wọ inu rẹ, o si ni rara, bẹẹ naa ni igbagbọ-ododo ri nigba ti ọyaya rẹ ba ti dara pọ mọ awọn ọkan. Mo si bi ọ leere pe njẹ a wa maa dalẹ bi, o si dahun pe rara, bẹẹ naa ni awọn ojisẹ ri, wọn ki i dalẹ. Mo tun bi ọ leere nipa ohun ti i fi n pa yin lasẹ, o si dahun pe o n pa yin lasẹ lati sin Ọlọhun, ki ẹ si ma fi nnkan kan se orogun fun Un, o si n kọ fun yin lati jọsin fun awọn orisa, o si n pa yin lasẹ pẹlu irun kiki, ododo sisọ, ati sisọ abẹ, ti ohun ti o sọ ba jẹ otitọ, yoo ni ikapa lori aaye ẹsẹ mi mejeeji laipẹ, ati pe dajudaju mo ti mọ daju pe yoo jade, n kò lero pe ninu yin ni yoo ti wa, iba si se pe mo mọ daju pe mo le yọ de ọdọ rẹ ni, n o ba fi ara da isoro pipade rẹ, iba si se pe mo wa ni ọdọ rẹ ni, dajudaju n o ba fọ ẹsẹ rẹ nu, lẹyin naa ni o wa tọrọ iwe Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", eyi ti o fi ran Dihyah si ọlọla Basri, n ni o ba fun Hiraql, o si ka a, o si ba ninu rẹ pe: « Mo bẹrẹ ni orukọ Ọlọhun, Alaanujulọ, Aladipele-ẹsan-rere, lati ọdọ Muhammad, ẹru Ọlọhun, ati ojisẹ Rẹ, si Hiraql ọlọla Roomu, ọlà ki o maa ba ẹni ti o ba tẹle imọna, lẹyin naa emi n pe ọ pẹlu ipe Islam, gba ẹsin Islam ki o la, Ọlọhun O fun ọ ni ẹsan rẹ lẹẹmeji, ti o ba wa kọyin, a jẹ pe ori rẹ ni ẹsẹ awọn mẹkunnu [rẹ] yoo wa. Ẹyin ti a fun ni tira, ẹ wa sidi gbolohun kan ti o se dọgba laarin wa ati aarin yin, pe a kò gbọdọ sin [nnkan kan] yatọ si Ọlọhun, a kò si gbọdọ fi nnkan kan se orogun pẹlu Rẹ, ati pe apa kan wa kò gbọdọ mu apa kan ni awọn oluwa lẹyin Ọlọhun, tori naa ti wọn ba kọyin [si eleyii], ẹ sọ pe: Ẹ jẹri pe dajudaju olugbafa fun Ọlọhun -Musulumi- ni awa ».

Ẹri Ẹlẹẹkeji: Ẹri olupeni-sẹsin-agbelebu ti o jẹ ọmọ England ti o n ba'ni lo igba John Saint; nibi ti o ti n sọ pe: Lẹyin kika ti kò ja nipa awọn ẹfọsiwẹwẹ Islam ati awọn ipilẹsẹ ẹkọ rẹ nipa sisisẹ-sin kaluku ati awujọ, ati sise dọgba rẹ nipa gbigbe awujọ dide lori awọn ipilẹ kan ninu sise deedee, ati sise Ọlọhun ni àásó ninu ijọsin, mo ri ara mi ni ẹni ti n fa lọ sidi Islam pẹlu gbogbo ọpọlọ mi, ati ẹmi mi, mo si se adehun fun Ọlọhun -mimọ ni fun Un- lati ọjọ naa pe n o jẹ olupepe lọ sidi Islam, olufuni niro idunnu pẹlu imọna rẹ ni gbogbo aaye.

Dajudaju o de idi amọdaju yii lẹyin ti o ti kọ nipa ẹsin agbelebu -Christianity- ti o si jindo ninu rẹ; ti o si ri wi pe kò fọ esi pupọ ninu awọn ibeere, eyi ti n yi ninu isẹmi eniyan, n ni iyemeji ba bẹrẹ si ni i wọnu [ọkan] rẹ, lẹyin naa ni o tun kọ nipa ilana pe ẹnikan kò gbọdọ da nnkan kan ni “Communism", ati ti Budda, kò si ri ohun ti n wa ninu mejeeji, lẹyin naa l'o wa kọ nipa Islam, ti o si jindo ninu rẹ, nitori naa o gba a gbọ ni ododo, o si n pepe lọ sidi rẹ.

###

OPIN JIJẸ ANABI

Paapaa jijẹ anabi ti ye ọ lara ohun ti o siwaju, ati awọn apẹrẹ rẹ, ati awọn arisami rẹ, ati awọn ẹri jijẹ anabi ti Anabi wa Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ki a to wa sọrọ nipa opin jijẹ anabi, dandan ni ki o mọ daju pe dajudaju Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- kò ki I ran ojisẹ kan afi nitori ọkan ninu awọn idi ti n bọ yii:

1- Wi pe ki isẹ anabi naa o jẹ adayanri fun awọn eniyan kan, ki a si ma pa ojisẹ yii lasẹ pe ki o jẹ isẹ rẹ fun awọn ijọ ti wọn wa ni itosi, nitori naa Ọlọhun O wa ran ojisẹ kan pẹlu isẹ kan pataki si ijọ mìíran.

2- Ki isẹ anabi ti o siwaju o ti parẹ, ki Ọlọhun O wa ran anabi kan ti yoo sọ ẹsin awọn eniyan di ọtun fun wọn.

3- Ki ofin anabi ti o siwaju o jẹ ohun ti o dara fun asiko rẹ, ki o si ma ba awọn asiko ti o tẹle e mu, nitori naa Ọlọhun yoo gbe ojisẹ kan dide, ti yoo gbe isẹ ati ofin ti o ba asiko naa, ati aaye naa mu wa, ati pe Hikmah -ọgbọn- Ọlọhun -mimọ ni fun Un- dajọ pe ki O gbe Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" dide pẹlu isẹ kan ti o kari fun awọn ara ilẹ, ti yoo si ba gbogbo igba ati aaye mu, O si sọ ọ kuro ni ọwọ yiyipada ati atọwọbọ, ki isẹ rẹ o le baa sẹku laaye, ki awọn eniyan o fi maa bẹ laaye, ki o si jẹ ohun ti o mọ kuro nibi awọn panti yiyi ọrọ pada, ati atọwọbọ, eleyii l'o mu ki Ọlọhun O se e ni opin awọn isẹ riran Rẹ.

Ati pe ninu ohun ti Ọlọhun fi se adayanri fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ni pe oun ni opin awọn anabi, tori naa kò si anabi kan lẹyin rẹ, tori pe dajudaju Ọlọhun ti fi i pe awọn isẹ riran naa, O si fi i pe awọn ofin naa, O si fi i pe ile naa, jijẹ anabi rẹ si mu ki iro-idunnu Anabi Isa -Jesu- o sẹ, nigba ti o sọ pe: « Ẹyin kò ti ka a ninu iwemimọ pe, okuta ti awọn ọmọle kọ silẹ, on na li o si di pataki igun ile » [Matteu 21:42]. Alufa-ijọ -pastor- Ibraahiim Khaliil -ti o gba ẹsin Islam ni ẹyin-ọ-rẹyin- ka ọrọ yii kun ohun ti o dọgba pẹlu ọrọ Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ti o sọ nipa ara rẹ, pe:

(( إن مثلي ومثل الأنبياء من قبلي كمثل رجل بنى بيتا فأحسنه وأجمله إلا موضع لبنة من زاوية، فجعل الناس يطوفون به، ويعجبون له، ويقولون: هلا وضعت هذه اللبنة، قال: فأنا اللبنة، وأنا خاتم النبيين )). [متفق عليه].

« Dajudaju apejuwe mi ati ti awọn anabi ti o siwaju mi da gẹgẹ bi apejuwe ọkunrin kan ti o kọ ile kan, ti o si kọ ọ daadaa, ti o si se e ni ọsọ, yatọ si aaye okuta -amọ sunsun- kan ni ara origun kan, n ni awọn eniyan ba bẹrẹ si ni i rọkirika rẹ, wọn si n se iyanu fun un, wọn si n sọ pe: O yoo wa fi okuta yii si i bi? O ni: Emi ni okuta naa, emi si ni opin awọn anabi » [Bukhari ati Muslim ni wọn gbe e jade].

Nitori eleyii ni Ọlọhun -mimọ ni fun Un- se se Tira ti Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" mu wa ni olusọ lori awọn tira ti o siwaju, ati oluparẹ fun wọn, gẹgẹ bi O ti se ofin rẹ ni oluparẹ fun gbogbo awọn ofin ti o siwaju, ati pe Ọlọhun se onigbọwọ sisọ isẹ rẹ, n ni a se gba a wa ni gbigba wa gba ọwọ ọgọọrọ eniyan, nigba ti a gba Al-Qur'aani alapọnle wa ni gbigbawa gbọwọ ọgọọrọ eniyan ni ohùn ati ni kikọsilẹ, gẹgẹ bi a ti se gba Sunna -ilana- rẹ, ti ọrọ ẹnu, ati ti isẹ, wa gba ọwọ ọgọọrọ eniyan, bẹẹ ni a tun gba lilo awọn ofin ẹsin yii ni ifisisẹ, ati awọn ijọsin rẹ, ati awọn ilana rẹ, ati awọn ofin rẹ, ni gbigbawa gba ọwọ ọgọọrọ eniyan.

Ẹnikẹni ti o ba si wo awọn iwe itan aye Anabi, ati ti Sunna -ilana Anabi- yoo mọ daju pe awọn Sahaabe rẹ “ki Ọlọhun O yọnu si wọn" wọn sọ gbogbo isesi Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati gbogbo awọn ọrọ rẹ, ati awọn isẹ rẹ, fun awọn ọmọ-eniyan, nitori naa wọn gba ijọsin rẹ fun Oluwa rẹ wa, ati ogun atigbẹsinga rẹ, ati iranti Ọlọhun -mimọ ni fun Un- rẹ, ati itọrọ aforijin rẹ, ati lilawọ rẹ, ati akin rẹ, ati ibasepọ rẹ pẹlu awọn ara rẹ, ati pẹlu awọn ti n ba a lalejo, gẹgẹ bi wọn ti se gba idunnu rẹ, ati ibanujẹ rẹ wa, ati irin-ajo rẹ, ati gbigbele rẹ, ati iroyin bi o ti se n jẹ, ati bi o ti se n mu, ati bi o ti se n wọ ẹwu, itaji ati oorun rẹ, tori naa ti o ba mọ eleyii, o mọ daju pe ohun ti a sọ pẹlu isọ Ọlọhun ti O fi sọ ọ ni ẹsin yii, o si mọ daju -ni igba naa- pe Anabi wa ni opin awọn anabi ati awọn ojisẹ; tori pe dajudaju Ọlọhun -mimọ ni fun Un- fun wa niro pe Ojisẹ yii ni opin awọn anabi, Ọlọhun -mimọ ni fun Un- si sọ pe:

} ما كان محمد أبا أحد من رجالكم ولكن رسول الله وخاتم النبيين { [سورة الأحزاب: 40].

« Muhammad ki i se baba ẹni-kankan ninu awọn ọkunrin yin, sugbọn ojisẹ Ọlọhun ni i, ipẹkun awọn anabi si ni i pẹlu » [Suuratul Ahzaab: 40]. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" si sọ nipa ara rẹ pe:

(( وأرسلت إلى الخلق كافة، وختم بي النبيون )). [رواه أحمد، ومسلم، واللفظ له].

« A si ran mi si awọn ẹda ni apapọ, ati pe a fi mi pin awọn anabi » [Ahmad ati Muslim ni wọn gbe e jade].

Eleyii ni asiko sisọ itumọ Islam, ati alaye paapaa rẹ, ati awọn ibi ti a o ti maa mọ nipa rẹ, ati awọn origun rẹ, ati awọn ipele rẹ.

###

ITUMỌ GBOLOHUN ISLAM

Ti o ba yẹ awọn iwe ti n sọ itumọ awọn ọrọ wo, o mọ daju pe itumọ gbolohun Islam ni igbafa, ati itẹriba, ati gbigba, ati isọpa-sọsẹ-silẹ ati isisẹ pẹlu asẹ olupasẹ ati ikọfunni rẹ lai kò se atako kan, ati pe Ọlọhun sọ ẹsin ododo ni Islam, tori pe oun ni itẹle ti Ọlọhun, ati igbafa fun asẹ Rẹ, lai kò se atako, ati sise afọmọ ijọsin naa fun Un -ogo ni fun Un- ati gbigba iroyin Rẹ ni ododo, ati gbigba A gbọ ni ododo, orukọ Islam si ti di orukọ gidi fun ẹsin ti Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" mu wa.

Sisọ itumọ Islam

Ki ni o mu ni pe ẹsin naa ni Islam? Dajudaju gbogbo ohun ti n bẹ ni ori ilẹ ninu ọlọkan-ọ-ọjọkan ẹsin, nse ni a sọ wọn ni awọn orukọ wọn, boya nipa fifi wọn ti si ara orukọ ẹniyan pataki kan, tabi ijọ kan pato. Nitori naa ẹsin Nasaaraa -alagbelebu- mu orukọ rẹ lati ara “Nasaaraa" -awọn ara Nasaret- ẹsin Budda si mu orukọ [tiẹ] lati ara orukọ ẹni ti o mọ ọn “Budda", ati pe ẹsin Zaraadishtiyyah gbayi pẹlu orukọ yii tori pe ẹni ti o da a silẹ, ati olugbe asia rẹ ro n jẹ “Zaraadisht", bẹẹ naa ni ẹsin Yahuudi yọju laarin awọn iran kan ti a mọ si “Yahuudza", n ni a se pe wọn ni ẹlẹsin Yahuudi, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Yatọ si pe Islam, ki i se ohun ti a maa n fi i ti si ara ẹnikan pataki, tabi si ara ijọ kan pato, ati pe n se ni orukọ rẹ n tọka si iroyin kan pataki ti itumọ gbolohun Islam se akojọpọ rẹ, bẹẹ ni ninu ohun ti yoo han ninu orukọ yii ni pe ki i se ẹnikan ninu awọn eniyan ni ohun ti a gba lero pẹlu mimu ẹsin yii maa bẹ, ati mimu un wa, ati pe ki i se ohun ti a se adayanri rẹ fun ijọ kan pato yatọ si awọn ijọ yoku, sugbọn ohun afojusi rẹ ni ki o se awọn ara ori ilẹ lapapọ ni ọsọ pẹlu iroyin Islam, nitori naa gbogbo ẹni ti o ba jẹ ẹni ti a royin pẹlu iroyin yii, ninu awọn ẹni-isaaju ati awọn eniyan isinyi Musulumu ni i, bẹẹ ni Musulumi naa ni gbogbo ẹni ti o ba gba iroyin naa ni ọjọ-iwaju yoo maa jẹ.

###

PAAPAA ISLAM

Ninu ohun ti o ye ni pe gbogbo nnkan ni ile-aye yii ni n tẹle ofin kan pataki, ati ilana kan ti o rinlẹ, tori naa oorun ati osupa, awọn irawọ ati ilẹ, ni a tẹ ni ori ba ni abẹ ofin kan ti n lọ taara, ti kò si agbara fun wọn lati yẹra fun un, tabi lati jade kuro ni abẹ rẹ, bi o fẹ ki o jẹ fun odiwọn gaga irun kan, titi debi wi pe eniyan gan-an alara ti o ba woye si ọrọ rẹ yoo ye ọ pe o gbafa fun awọn ilana Ọlọhun ni igbafa ti o pe, tori naa kò ni i mi, kò si ni i jẹro bukaata rẹ si omi, ati ounjẹ, ati imọlẹ, ati ooruu, afi ni ibamu pẹlu ipebubu ti Ọlọhun ti n to isẹmi rẹ, ati pe gbogbo awọn orike ara rẹ ni n gbafa fun ipebubu yii, tori naa isẹ ti awọn orike wọnyi n se, wọn ki i se e afi ni odiwọn bi Ọlọhun ti se e lofin fun wọn.

Nitori naa ebubu ti o kari yii, eyi ti a gbafa fun, ti nnkan kan ni ile-aye yii kò si le e bọ lọwọ titẹ le e, bẹrẹ lati ori irawọ ti o tobi ju ni sanma titi de ori eyi ti o wẹ ju ninu yanrin ni ilẹ, o wa ninu ipebubu Ọlọhun, Ọba Titobi, Olupebubu. Ti gbogbo nnkan ninu sanma ati ilẹ ati ohun ti n bẹ laarin mejeeji ba jẹ ohun ti o gbafa fun ipebubu yii, a jẹ pe gbogbo aye ni n gbọrọ si Ọba Olupebubu Naa, Ẹni ti O se e lẹnu, ti wọn si n tẹle asẹ Rẹ, ati pe yoo han lati ara adojukọ yii pe ẹsin gbogbo aye ni Islam, tori pe itumọ Islam ni igbafa, ati sisisẹ pẹlu asẹ olupasẹ ati kikọ rẹ, lai kò se atako, gẹgẹ bi o ti se ye ọ siwaju. Nitori naa ati oorun ati osupa ati ilẹ ni olugbafa, bẹẹ ni olugbafa ni atẹgun ati omi, imọlẹ ati okunkun, ooru, ati pe olugbafa ni igi ati okuta, ati awọn ẹranko, koda gan-an ẹni ti kò mọ Oluwa rẹ ti si n tako bibẹ Rẹ, ti o si kọ awọn ohun arisami Rẹ, tabi ti n jọsin fun ẹlomiran, ti si n fi ohun ti o yatọ si I se orogun fun Un, olugbafa ni oun naa nipa adamọ rẹ, eyi ti a da a mọ.

Ti eleyii ba ye ọ, wa ki a woye si ọrọ eniyan, o ri pe ohun meji ni n fa eniyan:

Alakọkọ ni: Adamọ eyi ti Ọlọhun da mọ eniyan, nipa igbafa fun Ọlọhun, ati ninifẹ jijẹ ẹrusin fun Un, ati wiwa atisunmọ Ọn, ati fifẹran ohun ti Ọlọhun fẹran ninu ododo ati rere ati otitọ, ati kikorira ohun ti Ọlọhun korira ninu ibajẹ ati aburu, ojusaju ati abosi, ati ohun ti n tẹle eleyii ninu ohun ti adamọ maa n pe eniyan lọ sidi rẹ ninu inifẹ si owo, ẹbi, ati ọmọ, ati nini ifẹ si ounjẹ ati ohun mumu, ati igbeyawo, ati ohun ti eleyii n tọrọ ninu ki awọn orike ara o maa gbe awọn isẹ wọn ti o jẹ ọranyan fun wọn duro.

Ẹlẹẹkeji ni: Erongba eniyan ati ẹsa rẹ, ati pe dajudaju Ọlọhun ti ran awọn ojisẹ si i, O si sọ awọn Tira kalẹ, ki o le baa se iyatọ laarin otitọ ati ibajẹ, imọna ati anu, rere ati aburu, O si se atilẹyin fun un pẹlu ọpọlọ ati agbọye, ki o le baa wa lori aridaju ninu isẹsa rẹ, tori naa ti o ba fẹ ki o gba ọna oore ki o si dari rẹ lọ sidi otitọ ati imọna; ti o ba si fẹ ki o gba awọn ọna aburu ki wọn o si tu u lọ sidi aburu ati iparun.

Nitori naa ti o ba wo eniyan pẹlu iwoye si ọrọ alakọkọ, o ri pe a se adamọ rẹ lori igbafa, a si da a mọ titẹpẹlẹ mọ ọn, ati pe kò tilẹ si ibuyẹsi kan fun un kuro nibẹ, ọrọ rẹ si dabi ọrọ awọn mìíran ti wọn yatọ si i ninu awọn ẹda.

Ti o ba si wo o pẹlu iwoye si ọrọ keji, o ri i ni olusẹsa, ti i maa n se ẹsa ohun ti o ba fẹ, ninu ki o jẹ Musulumi, tabi ki o jẹ alaigbagbọ:

} إما شاكراً وإما كفوراً {. [سورة الإنسان: 3].

« O le jẹ oluse-ọpẹ, o si le jẹ alaimoore » [Suuratul-Insaan: 3].

Idi niyi ti o fi ri pe orisi meji ni awọn eniyan:

Eniyan ti o mọ Ẹlẹda rẹ, ti o si gba A gbọ ni Oluwa, ati Olukapa, ati Ọlọhun ti a jọsin fun, yoo maa sin IN ni Oun nikan soso, yoo si maa tẹle ofin Rẹ ninu isẹmi rẹ ti o jẹ ti ẹsa. Gẹgẹ bi o tun se jẹ ẹni ti a se adamọ rẹ mọ gbigbafa fun Oluwa rẹ, kò si ibuyẹsi kan fun un kuro nibẹ, olutẹle ipebubu Rẹ, eleyii ni Musulumi pipe ẹni ti n wa pipe Islam rẹ, ati pe dajudaju imọ rẹ ti di ohun ti o dara, tori pe o mọ Ọlọhun Ẹlẹda rẹ, ati Olupilẹsẹda rẹ, Ẹni ti O ran awọn ojisẹ si i, ti O si fun un ni agbara imọ ati kikọ ẹkọ, bẹẹ ni laakaye rẹ ti di ohun ti o dara, aba rẹ si ti di ohun ti tọ, tori pe o lo irori rẹ lẹyin naa ni o wa pinnu lati ma sin nnkan kan yatọ si Ọlọhun, Ẹni ti O se apọnle rẹ pẹlu ọrẹ agbọye ati aba ninu ọrọ naa, ati pe ahọn rẹ ti di ohun ti o dara, olusọrọ pẹlu otitọ, tori pe kò gba ju Oluwa kan lọ nisinyi, Oun ni Ọlọhun -giga ni fun Un- Ẹni ti O rọ ọ lọrọ pẹlu agbara wiwi ati sisọrọ … isẹmi rẹ si dabi ẹni pe nnkan kan kò sẹku ninu rẹ ni isinyi yatọ si ododo; tori pe ẹni ti o gba fun ofin Ọlọhun ni i, ninu ohun ti o ti ni ẹsa ninu rẹ ninu ọrọ rẹ, ati pe okun imọra-ẹni ati ibara-ẹni-se si na ni aarin rẹ ati awọn ẹda yoku ni ile-aye, tori pe o n sin Ọlọhun, Ọlọgbọn, Olumọ, Ẹni ti gbogbo awọn ẹda n sin, ti wọn si n gba fun asẹ Rẹ, ti wọn si n gbafa fun ipebubu Rẹ, ati pe O ti tẹ wọn lori ba nitori iwọ eniyan.

###

PAAPAA AIGBAGBỌ -SISE KEFERI-

Ati pe eniyan mìíran wa ni odikeji rẹ, ti a bi i ni olugbafa, ti o si sẹmi fun gbogbo ọjọ-aye rẹ ni olugbafa, lai kò jẹ pe o mọ nipa igbafa rẹ, tabi ki o se laakaye si i, ati pe kò mọ Oluwa rẹ, bẹẹ ni kò gba ofin Rẹ gbọ, kò si tẹle awọn ojisẹ Rẹ, kò si lo ohun ti Ọlọhun bun un ni ẹbun ninu imọ, ati laakaye, lati mọ Ẹni ti o da a, ti O si la igbọrọ ati iriran rẹ, tori naa o tako bibẹ Rẹ, o si se igberaga kuro nibi jijọsin fun Un, o si kọ lati gbafa fun ofin Ọlọhun ninu ohun ti a ti fun un ni ẹtọ lati se idari ati ẹsa, ninu awọn ọrọ isẹmi rẹ, tabi o fi ẹlomiran se orogun fun Un, o si kọ lati gba awọn ami Rẹ, ti n tọka si jijẹ ọkan soso Rẹ gbọ, eleyii ni alaigbagbọ -keferi-. Eyi jẹ bẹẹ tori pe itumọ Kufr ni gbigbe nnkan pamọ, ati bibo nnkan, ati agbebọsọ, wọn a maa sọ pe: O bo -Kafar- ẹwu ija rẹ pẹlu asọ rẹ, nigba ti o ba bo o pẹlu rẹ, ti o si wọ ọ le e lori. Tori naa a o pe iru ọkunrin yii ni Kaafir -keferi- tori pe o gbe adamọ rẹ pamọ, o si bo o pẹlu ebibo kan ninu aimọkan ati agọ. Ati pe dajudaju o ti mọ daju pe wọn kò bi oun, afi si ori adamọ Islam, bẹẹ ni awọn orike ara rẹ kò maa sisẹ afi ni ibamu pẹlu adamọ Islam; ati pe ile-aye ni apapọ rẹ kò maa lọ ni ẹgbẹ rẹ bi kò se lori awọn ilana igbafa, sugbọn a bo o pẹlu ebibo kan ti i bo'ni ti aimọkan ati agọ, bẹẹ ni adamọ ile-aye ati adamọ ara rẹ si ti parẹ mọ aridaju rẹ lọwọ, nitori naa o maa ri ti kò ni i lo agbara rẹ ti ero-ori ati ti imọ afi si ohun ti o tako adamọ rẹ, kò i si i ri nnkan kan yatọ si ohun ti o tako o, bẹẹ ni kò ni i gbiyanju afi lori ohun ti yoo ba a jẹ.

Ni isinyi iwọ funra rẹ wo ohun ti aigbagbọ kojọ si i lara ninu anu ti o jinna, ati isina ti o han.

Ati pe Islam yii, eyi ti a fẹ ni ọdọ rẹ pe ki o maa mu un lo, ki i se ọrọ ti o soro, kaka bẹẹ nse ni o rọrun fun ẹni ti Ọlọhun ba se e ni irọrun fun, Islam ni ohun ti ile-aye yii lapapọ n tọ lọ:

} وله أسلم من في السموات والأرض طوعاً وكرهاً { [سورة آل عمران: 83].

« Oun si ni ẹnikẹni ti o wa ni awọn sanma ati ilẹ juwọ-jusẹ silẹ fun, yala pẹlu fifẹ tabi kikọ » [Suuratu Aala Imraan: 83]. Oun si ni ẹsin Ọlọhun, gẹgẹ bi Ọlọhun ti O ga ti sọ pe:

} إن الدين عند الله الإسلام { [سورة آل عمران: 19].

« Dajudaju ẹsin ni ọdọ Ọlọhun ni Islam » [Suuratu Aala Imraan: 19]. Ati pe oun ni gbigbafa oju fun Ọlọhun, gẹgẹ bi Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, ti sọ pe:

} فإن حاجوك فقل أسلمت وجهي لله ومن اتبعن { [سورة آل عمران: 20].

« Ti wọn ba si ba ọ jiyan, sọ pe: Mo ti tẹ oju mi ba fun Ọlọhun, ati awọn ti o tẹle mi [awọn naa tẹ oju wọn ba] pẹlu » [Suuratu Aala Imraan: 19]. Dajudaju Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" si ti se alaye itumọ Islam, o si sọ pe:

(( أن تسلم قلبك لله، وأن تولي وجهك لله، وتوتي الزكاة المفروضة )). [رواه الإمام أحمد، وابن ماجة].

« Ki o ju ọkan rẹ silẹ fun Ọlọhun, ki o si da oju rẹ kọ Ọlọhun, ki o si maa yọ zaka ti o jẹ ọranyan » [Imaam Ahmad ati Ibn Maajah ni wọn gbe e jade]. Ọkunrin kan si bi Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" leere pe:

ما الإسلام؟ قال: (( أن يسلم قلبك لله، وأن يسلم المسلمون من لسانك ويدك )). قال: أي الإسلام أفضل؟ قال: (( الإيمان )). قال: وما الإيمان؟ قال: (( أن تؤمن بالله وملائكته وكتبه ورسله والبعث بعد الموت )). [رواه الإمام أحمد].

« Ki ni Islam? O ni: Ki ọkan rẹ o gbafa fun Ọlọhun, ati ki awọn Musulumi o bọ lọwọ [aburu] ahọn rẹ ati ọwọ rẹ. O ni: Islam wo l'o lọla ju? O dahun pe: Igbagbọ-ododo. O ni: Ki ni igbagbọ-ododo? O ni: Ki o gba Ọlọhun gbọ, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati igbende lẹyin iku » [Imaam Ahmad l'o gbe e jade], ati bi Ojisẹ Ọlọhun “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" ti sọ pe:

(( الإسلام أن تشهد أن لا إله إلا الله، وأن محمداً رسول الله، وتقيم الصلاة، وتؤتي الزكاة، وتصوم رمضان، وتحج البيت إن استطعت إليه سبيلاً )). [رواه مسلم].

« Islam ni ki o jẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati sin lododo yatọ si Ọlọhun, ati pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i, ati ki o maa gbe irun duro, ki o si maa yọ zaka, ki o si maa gba aawẹ Ramadaan, ati ki o se Haji -abẹwo- ile Oluwa, ti o ba ni agbara ọna atilọ sibẹ » [Muslim l'o gbe e jade]. Ati ọrọ rẹ ti o sọ pe:

(( المسلم من سلم المسلمون من لسانه ويده )). [متفق عليه].

« Musulumi ni ẹni ti awọn Musulumi bọ nibi [aburu] ahọn rẹ ati [aburu] ọwọ rẹ ». [Bukhari ati Muslim ni wọn gbe e jade].

Ati pe ẹsin yii -ti i se ẹsin Islam- eyi ti Ọlọhun kò ni I gba ẹsin kan ti o yatọ si i, ni ọwọ awọn ẹni-akọkọ tabi lọwọ awọn ẹni-igbẹyin, ori ẹsin Islam naa ni gbogbo awọn anabi wa, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ nipa Anabi Nuuhu “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" pe:

} واتل عليهم نبأ نوح إذ قال لقومه يا قوم إن كان كبر عليكم مقامي وتذكيري بآيات الله فعلى الله توكلت ... وأمرت أن أكون من المسلمين { [سورة يونس: 71-72].

« Ka iroyin Nuuhu fun wọn, nigba ti o sọ fun awọn eniyan rẹ pe: Ẹyin eniyan mi, ti o ba jẹ pe wiwa nibi mi ba jẹ ohun ti o n ni yin lara, ati riran yin leti mi pẹlu awọn aayah Ọlọhun, ti o ba ri bẹẹ emi gbẹkẹle Ọlọhun … » titi debi ọrọ Rẹ -giga ni fun Un- pe: « Ati pe a pa mi lasẹ pe ki n jẹ ọkan ninu awọn ti o gbafa fun Ọlọhun -Musulumi- » [Suuratu Yuunus: 71-72]. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn tun sọ nipa Anabi Ibraahiim, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", pe:

} إذ قال له ربه أسلم قال أسلمت لرب العالمين { [سورة البقرة: 131].

« Nigba ti Oluwa rẹ sọ fun un pe: Gbafa, o si dahun pe: Mo juwọ-jusẹ silẹ fun Oluwa gbogbo ẹda » [Suuratul-Baqarah: 131]. Ọlọhun ti ọrọ Rẹ ga tun sọ nipa Anabi Musa, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", pe:

} وقال موسى يا قوم إن كنتم آمنتم بالله فعليه توكلوا إن كنتم مسلمين { [سورة يونس: 84].

« Musa si wi pe: Ẹyin eniyan mi, ti ẹyin ba jẹ ẹni ti o gba Ọlọhun gbọ lododo, Oun ni ki ẹ gbẹkẹle, ti ẹyin ba jẹ olugbafa -fun Un- -Musulumi- » [Suuratu Yuunus: 84]. Ọlọhun t'O ga tun sọ ninu iroyin Anabi Isa -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", pe:

}وإذ أوحيت إلى الحواريين أن آمنوا بي وبرسولي قالوا آمنا واشهد بأننا مسلمون { [سورة المائدة: 111].

« Ati nigba ti Mo ransẹ si awọn ẹmẹwa -rẹ- pe: Ẹ gba Mi gbọ ati ojisẹ Mi, wọn sọ pe: Awa gbagbọ, ki o si jẹri pe olugbafa -fun Ọlọhun- -Musulumi- ni awa » [Suuratul-Maa'idah: 111].

Ẹsin yii -Islam- si n gba awọn ofin rẹ ati awọn adisọkan rẹ ati awọn idajọ rẹ lati ara isẹ Ọlọhun ti I maa N fi i ransẹ -Al-Qur'aani ati Sunna- n o si se alaye iwọnba soki fun ọ nipa mejeeji.

AWỌN IPILẸ ISLAM ATI IBI TI O TI N MU AWỌN OFIN RẸ

Asa awọn olutẹle awọn ẹsin ti a ti parẹ, ati awọn ilana ti o jẹ atọwọda, ni ki wọn o maa se afọmọ awọn iwe kan ti wọn n jogun laarin wọn, eyi ti wọn kọ ninu awọn asiko kan ti o ti rekọja, ti o si se pe a le ma mọ paapaa ẹni ti o kọ ọ, tabi ẹni ti o yi i pada si ede mìíran, tabi igba wo ni wọn kọ ọ, awọn ti wọn si kọ ọ kò ju awọn eniyan kan ti o se pe ohun ti i maa n se ọmọ eniyan ninu ailera, aipe, ifẹẹnu, ati igbagbe a maa se wọn.

Sugbọn Islam, oun da yatọ si awọn ẹsin ti o yatọ si i, nigba ti o se pe ipilẹ ododo ni o fi ẹyin ti, [Isẹ Ọlọhun ti I maa N fi i ransẹ] Al-Qur'aani ati Sunna; eleyii si ni alaye soki nipa mejeeji:

(a) Al-Qur'aani Alapọnle: O ti ye ọ ninu ohun ti o siwaju pe dajudaju Islam ni ẹsin Ọlọhun, ati pe nitori eleyii ni Ọlọhun se sọ Al-Qur'aani kalẹ fun ojisẹ Rẹ Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ni afinimọna fun awọn olupaya Ọlọhun, ati iwe ofin fun awọn Musulumi, ati iwosan fun igbaaya awọn ti Ọlọhun fẹ iwosan fun, ati atupa fun awọn ti Ọlọhun ba fẹ oriire fun, ati imọlẹ, ati pe o se akojọpọ awọn ipilẹ eyi ti Ọlọhun titori rẹ ran awọn ojisẹ, bẹẹ ni Al-Qur'aani ki i se akọkọ ninu awọn tira, gẹgẹ bi Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ki i ti i se akọkọ ninu awọn ojisẹ; tori pe dajudaju Ọlọhun ti sọ tira kan -Suhuf- kalẹ fun Anabi Ibraahiim, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", O si se apọnle Anabi Musa “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" pẹlu At-Tawraah, ati Anabi Daa'uud “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" pẹlu Zabuura, Al-Masiihu -Jesu- “ki ọla Ọlọhun o maa ba a" si mu Al-Injiila -Bibeli- wa. Isẹ ni awọn tira wọnyi jẹ lati ọdọ Ọlọhun, O fi wọn ransẹ si awọn anabi Rẹ ati awọn ojisẹ Rẹ, sugbọn pupọ ninu awọn tira ti o siwaju yii ni a ti se afẹku wọn, ati pe ọpọlọpọ wọn l'o ti parẹ, bẹẹ ni ayipada ati atọwọbọ si ti wọnu wọn.

Sugbọn Al-Qur'aani alapọnle, dajudaju Ọlọhun ti se agbatẹru nipa sisọ ọ, O si se e ni olusọ, ati oluparẹ, fun ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn tira, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وأنزلنا إليك الكتاب بالحق مصدقاً لما بين يديه من الكتاب ومهيمنا عليه { [سورة المائدة: 48].

« A si ti sọ Tira naa kalẹ fun ọ pẹlu ododo, o jẹ olumuni-mọ ohun ti o jẹ ododo ninu ohun ti o siwaju rẹ ninu tira, ati olusọ lori rẹ » [Suuratul-Maa'idah: 48]. O si royin rẹ pẹlu pe alaye ni o jẹ fun gbogbo nnkan. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọ-un-gbọn, sọ pe:

} ونزلنا عليك الكتاب تبيانا لكل شيء { [سورة النحل: 89].

« Awa si sọ Tira naa kalẹ fun ọ, ti o jẹ alaye fun gbogbo nnkan » [Suuratun-Nahl: 89]. Itọsọna, ati aanu, si ni i, Ọba ti O ga ni Olusọrọ, sọ pe:

} فقد جاءكم بينة من ربكم وهدى ورحمة { [سورة الأنعام: 157].

« Dajudaju alaye lati ọdọ Oluwa yin ti wa ba yin, ati itọsọna, ati aanu » [Suuratul-An'Aam: 157]. Bẹẹ ni a maa fi'ni mọna lọ si ọna ti o tọ ju:

} إن هذا القرآن يهدي للتي هي أقوم { [سورة الإسراء: 9].

« Dajudaju Al-Qur'aani yii a maa tọ'ni si ọna eyi ti o tọ ju » [Suuratul-Israa'i: 9]. Nitori naa a maa fi ọmọ eniyan mọna lọ sidi ọna kan, ti o tọ ju, ninu gbogbo ọrọ kan, ninu awọn ọrọ isẹmi rẹ.

Ati pe ẹnikẹni ti o ba ranti bi a ti se sọ Al-Qur'aani alapọnle naa kalẹ, ati bi a ti se isọ rẹ, yoo mọ iyi Al-Qur'aani fun un, yoo si se afọmọ adojukọ rẹ fun Ọlọhun; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

}وإنه لتنـزيل رب العالمين. نزل به الروح الأمين. على قلبك لتكون من المنذرين{ [سورة الشعراء: 192-194].

« Ati pe oun -Al-Qur'aani- jẹ ohun ti a sọ kalẹ lati ọdọ Oluwa gbogbo ẹda. Ẹmi ododo [Jibriil] l'o sọ ọ kalẹ. Si inu ọkan rẹ, ki o le baa jẹ ọkan ninu awọn olukilọ » [Suuratu-Shu'araa': 192-194].

Nitori naa Ẹni ti O sọ Al-Qur'aani kalẹ ni Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda.

Ati pe ẹni ti o sọ ọ kalẹ pẹlu rẹ ni ẹmi ododo, Jibriil, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a".

Bẹẹ ẹni ti a sọ ọ kalẹ si ọkan rẹ ni Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a".

Ati pe ami ti yoo sẹku ni Al-Qur'aani yii jẹ fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", -ni ara awọn ami ti yoo sẹku titi di ọjọ igbende- awọn ami awọn anabi ti wọn siwaju, ati awọn ohun akonilagara wọn, jẹ ohun ti i maa n pari pẹlu pipari isẹmi wọn, sugbọn Al-Qur'aani yii, dajudaju Ọlọhun se e ni awijare kan ti yoo sẹku.

Oun si ni awijare ti o dopin, ati ami iyanu, Ọlọhun pe awọn ọmọ eniyan nija pe ki wọn o mu iru rẹ wa, tabi Suura -ọgba ọrọ- mẹwa ti o jẹ iru rẹ, tabi ki wọn o mu ọgba ọrọ kan ninu awọn ọgba ọrọ rẹ wa, sugbọn wọn kagara [lati se bẹẹ], t'ohun ti pe lati ara awọn harafi ati awọn gbolohun ni o ti kojọ, ti ijọ ti a sọ ọ kalẹ fun si jẹ ijọ adalahọn, ati asọrọyọkomookun rẹ, Ọlọhun ti O ga sọ pe:

} أم يقولون افتراه قل فأتوا بسورة مثله وادعوا من استطعتم من دون الله إن كنتم صادقين { [سورة يونس: 38].

« Abi wọn n wi pe: O da a pa nirọ ni bi? Sọ pe: Njẹ, ẹ mu Suura iru rẹ kan wa, ki ẹ si pe ẹni ti ẹ ba le pe lẹyin Ọlọhun [lati ran yin lọwọ] ti ẹ ba jẹ olododo » [Suuratu Yuunus: 38].

Ati pe ninu ohun ti yoo jẹri fun Al-Qur'aani yii pe isẹ kan ni lati ọdọ Ọlọhun ni pe: O se akojọpọ awọn iroyin pupọ nipa awọn ijọ ti o siwaju, o si fun'ni niro nipa awọn isẹlẹ ti yoo sẹlẹ ni ọjọ iwaju, o si sẹlẹ gẹgẹ bi o ti royin, bẹẹ ni o sọ ohun pupọ ninu awọn ẹri ti imọ, ninu ohun ti o se pe awọn olumọ kò debi apa kan ninu rẹ afi ni asiko yii.

Ninu ohun ti o tun jẹri fun Al-Qur'aani yii -bakan naa- pe isẹ kan ni lati ọdọ Ọlọhun ni pe: A kò mọ Anabi ti a sọ Al-Qur'aani yii kalẹ fun mọ iru rẹ ri [tẹlẹ], ati pe a kò gba ohun ti o jọ ọ ri wa lati ọdọ rẹ siwaju sisọ Al-Qur'aani kalẹ; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} قل لو شاء الله ما تلوته عليكم ولا أدراكم به فقد لبثت فيكم عمراً من قبله أفلا تعقلون { [سورة يونس: 16].

« Sọ pe: Ti o ba jẹ pe Ọlọhun fẹ ni, emi ki ba ti ka a fun yin, n kò ba si ti fi i mọ yin, dajudaju emi ti gbe aarin yin fun ọdun gbọọrọ siwaju rẹ, ẹ kò wa se laakaye ni » [Suuratu Yuunus: 16]; kaka bẹẹ nse ni o jẹ alaimọọka-mọọkọ, kò le e kọ, bẹẹ ni kò le e ka, ati pe kò lọ si ọdọ olumọ kan ri, kò tilẹ jokoo lọdọ olukọ kan ri, sugbọn t'ohun ti bẹẹ, o n se atako fun awọn sọrọsọrọ ti o da lahọn, ati awọn asọrọyọkomookun rẹ, pe ki wọn o mu iru rẹ wa:

} وما كنت تتلو من قبله من كتاب ولا تخطه بيمينك إذا لارتاب المبطلون { [سورة العنكبوت: 48].

« Ati pe iwọ kò jẹ ẹni ti n ke tira kan siwaju rẹ, bẹẹ ni ọwọ [ọtun] rẹ kọ l'o fi kọ ọ, [iba se pe o ri bẹẹ ni] nigba naa dajudaju awọn asebajẹ o ba se iyemeji » [Suuratul-Ankabuut: 48]. Ọkunrin alaimọọkọ-mọọka ti a royin ninu At-Tawraata -Majẹmu Laelae- ati Injiila -Bibeli- pe alaimọọkọ-mọọka ti kò le kọ ti kò si le ka yii, awọn alufa Yahuudi ati ti awọn alagbelebu -Christians- -awọn ti wọn ni ohun ti o sẹku ninu Majẹmu Laelae, ati Majẹmu Titun- wọn a maa wa ba a, wọn a maa bi i leere nipa ohun ti wọn n se iyapa-ẹnu lori rẹ, wọn a si maa wa idajọ lọ si ọdọ rẹ nipa ohun ti wọn n ja lori rẹ, Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ ni Ẹni ti N se alaye iroyin rẹ ninu At-Tawraata -Majẹmu Laelae- ati Injiila -Bibeli- pe:

} الذين يتبعون الرسول النبي الأمي الذي يجدونه مكتوباً عندهم في التوراة والإنجيل يأمرهم بالمعروف وينهاهم عن المنكر ويحل لهم الطيبات ويحرم عليهم الخبائث { [سورة الأعراف: 157].

« Awọn ti wọn n tẹle ti Ojisẹ naa, Anabi naa, ẹni ti kò mọ ọ kọ ti kò mọ ọ ka, ẹni ti wọn ba akọsilẹ nipa rẹ lọdọ wọn ninu At-Tawraata ati ninu Injiila, yoo maa fooro wọn si iwa rere, yoo si maa kọ aburu fun wọn, yoo si maa se awọn ohun ti o dara ni ẹtọ fun wọn, yoo si maa se awọn ohun ti kò dara ni eewọ fun wọn » [Suuratul-A'araaf: 157]. Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ ni Ẹni ti N se alaye ibeere awọn Yahuudi ati awọn alagbelebu -Christians- fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", pe:

} يسألك أهل الكتاب أن تنـزل عليهم كتاباً من السماء { [سورة النساء: 153].

« Awọn oni-tira yoo bi ọ leere pe ki o sọ tira kan kalẹ fun wọn lati sanma » [Suuratun-Nisaa'i: 153]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn tun sọ pe:

} ويسألونك عن الروح { [سورة الإسراء: 85].

« Ati pe wọn o maa bi ọ leere nipa ẹmi » [Suuratul-Israa'i: 85]. O tun sọ -mimọ ni fun Un- pe:

} ويسألونك عن ذي القرنين { [سورة الكهف: 83].

« Ati pe wọn o maa bi ọ leere nipa Zul-Qarnaini » [Suuratul-Kahf: 83]. O tun sọ -mimọ ni fun Un- pe:

} إن هذا القرآن يقص على بني إسرائيل أكثر الذي هم فيه يختلفون { [سورة النمل: 76].

« Dajudaju Al-Qur'aani yii yoo maa se iroyin fun awọn ọmọ Isrẹli nipa ọpọlọpọ ohun ti wọn n se iyapa-ẹnu nipa rẹ » [Suuratun-Naml: 76].

Dajudaju alufa-ijọ -pastor- Abraham Philips ti gbiyanju ninu iwe rẹ ti o fi gboye iwe ẹri giga -Ph.D- lati se ibajẹ Al-Qur'aani, sugbọn agara da a lati se bẹẹ, ati pe Al-Qur'aani bori rẹ pẹlu awọn awijare rẹ, ati awọn ẹri-ọrọ rẹ, ati awọn afisami rẹ, nitori naa o kede ikagara rẹ; ati pe o juwọ-jusẹ silẹ fun Ẹlẹda rẹ, o si kede gbigba Islam rẹ.

Ati pe nigba ti ọkan ninu awọn Musulumi bun ọmọ Amẹrika Dr. Jefry Lang ni alaye itumọ Al-Qur'aani alapọnle, o ri i pe Al-Qur'aani yii n ba ẹmi oun sọrọ, o si n fesi fun awọn ibeere rẹ, o si n si awọn gaga ti o wa laarin rẹ ati ẹmi rẹ kuro; koda o sọ pe: « Dajudaju o dabi wi pe Ẹni ti O sọ Al-Qur'aani yii kalẹ mọ mi ju bi mo ti se mọ ara mi lọ ». Bawo ni kò ti se ni i ri bẹẹ? Nigba ti o se pe Ẹni ti O sọ Al-Qur'aani kalẹ ni Ẹni ti O sẹda eniyan, Oun si ni Ọlọhun -mimọ ni fun Un-:

} ألا يعلم من خلق وهو اللطيف الخبير { [سورة الملك: 14].

« Njẹ Ẹni ti O da ẹda kò wa mọ bi? Nigba ti o se pe Oun ni Alaanu, Oni-mimọ nipa gbogbo nnkan » [Suuratul-Mulk: 14]; lẹyin naa kika ti o ka alaye itumọ Al-Qur'aani alapọnle jẹ okunfa gbigba Islam rẹ, ati kikọ iwe ti mo ti yọ ọrọ jade fun ọ ninu rẹ yii.

Ati pe Al-Qur'aani alapọnle kari gbogbo ohun ti ọmọ eniyan n bukaata, tori naa o kari ipilẹ awọn ofin, ati awọn adisọkan, ati awọn idajọ, ati awọn ibanise, ati awọn ẹkọ; Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} ما فرطنا في الكتاب من شيء { [سورة الأنعام: 38].

« Awa kò sẹ nnkan kan ku ninu Tira [lai sọ] » [Suuratul-An'aam: 38], tori naa ipepe lọ sidi sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin -Tawhiid- wa ninu rẹ, ati sisọ awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn isẹ Rẹ, o si n pepe lọ sidi didọgba ohun ti awọn anabi ati awọn ojisẹ pepe lọ sidi rẹ, o si fi ẹsẹ igbende ati ẹsan ati isiro rinlẹ, ati pe o n mu awọn ẹri-ọrọ ati awọn awijare wa lori eleyii, bẹẹ ni o n sọ iroyin awọn ijọ ti o ti lọ, ati ohun ti o sẹlẹ si wọn ninu awọn ẹsin ni ile-aye, ati ohun ti n reti wọn ninu iya ati ibawi ni igbẹyin.

Ati pe nnkan pupọ wa ninu rẹ ninu awọn ẹri-ọrọ ati awọn awijare, ninu ohun ti i maa n ya awọn oni-mimọ lẹnu, ti o si ba gbogbo igba mu, ti awọn oni-mimọ ati awọn oluse-iwadi yoo si maa ri ohun ti wọn n wa ninu rẹ, ati pe n o sọ apejuwe mẹta pere fun ọ, ti yoo sipaya nnkan kan fun ọ ninu eleyii, awọn apejuwe naa ni:

1- Ọrọ Ọlọhun ti O ga:

} وهو الذي مرج البحرين هذا عذب فرات وهذا ملح أجاج وجعل بينهما برزخا وحجراً محجوراً { [سورة الفرقان: 53].

« Oun si ni Ẹni ti O mu awọn odo meji san, ọkan dun o tutu, ekeji si ni iyọ o hanyọ, O si fi gaga kan si aarin mejeeji ati edidi ti a fi di wọn -sira wọn- » [Suuratul-Furqaan: 53]. Ọlọhun ti ọrọ Rẹ ga tun sọ pe:

} أو كظلمات في بحر لُجِيٍّ يغشاه موج من فوقه موج من فوقه سحاب ظلمات بعضها فوق بعض إذا أخرج يده لم يكد يراها ومن لم يجعل له نوراً فما له من نور{ [سورة النور: 40].

« Tabi o dabi awọn okunkun kan ninu okun ti o jin, ti igbi kan n bo o ni oke rẹ, ti igbi kan, ti ẹsu ojo n bẹ ni oke rẹ, wa ni oke rẹ, awọn okunkun kan ti apa kan wọn wa lori omiran, nigba ti o ba mu ọwọ rẹ jade yoo fẹrẹ le ma ri i, ati pe ẹni ti Ọlọhun kò ba fun ni imọlẹ, kò le si imọlẹ kan fun un » [Suuratun-Nuur: 40]. Bẹẹ ni ninu ohun ti a mọ daju ni pe Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" kò gun okun, ati pe kò si awọn ohun elo, eyi ti i maa n ran ni lọwọ lati se iwadii awọn ọgbun okun ni asiko rẹ, njẹ ta ni ẹni ti o fun Anabi Muhammad “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" niro nipa awọn imọ wọnyi yatọ si Ọlọhun?.

2- Ọrọ Ọlọhun -giga ni fun Un-:

} ولقد خلقنا الإنسان من سلالة من طين. ثم جلعناه نطفة في قرار مكين. ثم خلقنا النظفة علقة فخلقنا العلقة مضغة فخلقنا المضغة عظاماً فكسونا العظام لحماً ثم أنشأناه خلقاً آخر فتبارك الله أحسن الخالقين { [سورة المؤمنون: 12-14].

« Dajudaju Awa da eniyan lati inu eyi ti a yọ ninu erupẹ amọ. Lẹyin naa A se e ni omi gbọlọgbọlọ sinu aaye irọrun kan. Lẹyin naa Awa sọ omi gbọlọgbọlọ naa di ẹjẹ didi, A si sọ ẹjẹ didi naa di ekiri-ẹran, A si sọ ekiri-ẹran naa di awọn egungun, A si fi ẹran bo awọn egungun naa, lẹyin eyi Awa sọ ọ di ẹda mìíran kan; tori naa ibukun ni fun Ọlọhun ti O da awọn ẹda Rẹ ni ọna ti o dara julọ » [Suuratul-Mu'uminuun: 12-14]. Awọn olumọ kò si mọ awọn alaye ti o wẹ nipa awọn ipele sise ẹda ọmọ wọnyi afi ni ode-oni.

3- Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وعنده مفاتح الغيب لا يعلمها إلا هو ويعلم ما في البر والبحر وما تسقط من ورقة إلا يعلمها ولا حبة في ظلمات الأرض ولا رطب ولا يابس إلا في كتـاب مبين { [سورة الأنعام: 59].

« Ọdọ Rẹ ni awọn kọkọrọ ohun ti o pamọ wa, ẹnikan kò le e mọ ọn yatọ si I, O si tun mọ ohun ti o wa ninu ilẹ ati okun, ati pe kò si ewe kan ti yoo jabọ afi ki O mọ nipa rẹ, bẹẹ ni kò si horo ọka kan ninu okunkun ilẹ, kò tilẹ si ohun tutu kan tabi ohun gbigbẹ kan afi ki o ti wa ninu tira ti o han » [Suuratul-An'aam: 59]. Arojinlẹ ti o kari kò mọ ọmọ eniyan lara, ati pe wọn ki i ronu nipa rẹ, depo pe wọn yoo ni agbara rẹ, koda ti ikọ awọn olumọ kan ba fi oju si irugbin kan, tabi kokoro kan, ti wọn si kọ akọọlẹ ohun ti wọn mọ nipa rẹ, iyalẹnu yoo mu wa fun eleyii, t'ohun ti pe o daju pe ohun ti o pamọ si wọn nipa rẹ pọ ju ohun ti wọn se akiyesi rẹ lọ.

Ati pe olumọ ọmọ Faase, Moris Boukaye, ti wo At-Tawraata ati Injiila ati Al-Qur'aani sira wọn, o si se alaye ohun ti awọn awari ode-iwoyi ti dedi rẹ nipa dida awọn sanma, ati ilẹ, ati dida eniyan, o si ri i pe awọn ohun ti a jagbọn mọ ni ode-oni dọgba pẹlu ohun ti o wa ninu Al-Qur'aani, nigba ti o si ri pe At-Tawraata ati Injiila -Bibeli- ti o wa ni ọwọ awọn eniyan ni oni se akojọpọ awọn imọ pupọ, ti o jẹ asise nipa dida awọn sanma, ati ilẹ, ati dida eniyan, ati ẹranko.

(b) Sunna -Ilana- Anabi:

Ọlọhun sọ Al-Qur'aani alapọnle kalẹ fun Ojisẹ Rẹ, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", O si fi iru rẹ ransẹ si i, eyi ti i se Sunna -ilana- Anabi oluse-alaye ati oluse-afihan fun Al-Qur'aani. Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" sọ pe:

(( ألا إني أوتيت القرآن ومثله معه )). رواه أحمد، وأبو داود.

« Tẹti ki o gbọ, dajudaju a fun mi ni Al-Qur'aani, ati iru rẹ pẹlu rẹ » [Ahmad ati Abu Daa'uud ni wọn gbe e jade]. Dajudaju Ọlọhun yọnda fun un pe ki o maa se alaye ohun ti o wa ninu Al-Qur'aani ni ohun ti o gbooro, tabi adayanri, tabi ohun ti o wa ni sangiliti. Ọlọhun -giga ni fun Un- sọ pe:

} وأنزلنا إليك الذكر لتبين للناس ما نزِّل إليهم ولعلهم يتفكرون { [سورة النحل: 44].

« Ati pe A sọ iranti naa kalẹ fun ọ, ki o le maa se alaye fun awọn eniyan ohun ti a sọ kalẹ fun wọn, ki wọn o si le baa maa ronu » [Suuratun-Nahl: 44].

Ati pe Sunna naa ni ipilẹ keji ninu awọn ipilẹ ofin Islam, oun si ni gbogbo ohun ti a gba wa lati ọdọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", -lati ọna kan ti o gun rege, ti o si sopọ titi de ọdọ Ojisẹ Ọlọhun- ninu ọrọ, tabi isẹ, tabi ohun ti o fi ọwọ si, tabi iroyin.

Isẹ kan si ni lati ọdọ Ọlọhun si ojisẹ Rẹ, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a"; tori pe Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" ki i sọ ifẹẹnu; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وما ينطق عن الهوى. إن هو إلا وحي يوحى. علمه شديد القوى { [سورة النجم: 3-5].

« Ati pe ki i sọ ọrọ ifẹẹnu. Oun [ti n sọ] kò jẹ nnkan kan yatọ si isẹ ti a n fi i ransẹ [si i]. Ale-ni-agbara ni o n kọ ọ » [Suuratun-Najm: 3-5]. Kò jẹ nnkan kan nisẹ fun awọn eniyan bi kò se ohun ti a fi pa a lasẹ; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إن أتبع إلا ما يوحى إلـيَّ وما أنا إلا نذير مبين { [سورة الأحقاف: 9].

« Emi kò maa tẹle nnkan kan afi ohun ti a n fi i ransẹ si mi, bẹẹ ni emi kò jẹ nnkan kan afi olukilọ ti o han » [Suuratul-Ahqaaf: 9].

Sunna ti o mọ naa si ni lilo Islam ni ifisisẹ, ni awọn idajọ, ati awọn adisọkan, ati awọn ijọsin, ati awọn ibasepọ, ati awọn ẹkọ, tori pe dajudaju Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" jẹ ẹni ti i maa n fi ohun ti a fi pa a lasẹ sisẹ, a si maa se alaye rẹ fun awọn eniyan, a si maa pa wọn lasẹ pe ki wọn o se iru isẹ oun; gẹgẹ bi ọrọ rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" pe:

(( صلوا كما رأيتموني أصلي )). [رواه البخاري].

« Ẹ maa kirun gẹgẹ bi ẹ ti se ri mi ti mo n kirun » [Bukhari l'o gbe e jade]; ati pe Ọlọhun ti pa awọn olugbagbọ-ododo lasẹ pe ki wọn o maa kọse rẹ ninu awọn isẹ rẹ, ati awọn ọrọ rẹ, titi ti pipe igbagbọ wọn yoo fi sẹlẹ fun wọn, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} لقد كان لكم في رسول الله أسوة حسنة لمن كان يرجو الله واليوم الآخر وذكر الله كثيراً { [سورة الأحزاب: 21].

« Dajudaju ohun awokọse rere n bẹ fun yin lara Ojisẹ Ọlọhun, fun ẹni ti n rankan Ọlọhun, ati ọjọ ikẹyin, ti o si n ranti Ọlọhun ni ọpọlọpọ » [Suuratul Ahzaab: 21], bẹẹ ni awọn Sahaabe alapọnle -ki Ọlọhun O yọnu si wọn- ti gba awọn ọrọ Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" ati awọn isẹ rẹ wa fun awọn ti wọn de lẹyin wọn, awọn wọnyi naa gba a wa fun awọn ti n bẹ lẹyin wọn, lẹyin naa ni kikọsilẹ rẹ sinu awọn iwe Sunna waye, ati pe dajudaju awọn olugba-Sunna wa a maa le koko nipa ẹni ti wọn n gba ọrọ lọdọ rẹ, wọn a si maa tọrọ pe ki ẹni ti wọn yoo gba ọrọ lọdọ rẹ o jẹ ẹni ti o ba ẹni ti oun naa gba a lọwọ lo igba, ki ọna ti ọrọ naa gba wa o le baa sopọ lati ọdọ ẹni ti o gba ọrọ wa titi de ọdọ Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati ki gbogbo ẹni ti n bẹ ninu ọna ti o ba wa naa o jẹ ẹni ti ọkan balẹ si, olusedọgba, olododo, ẹni-ifọkantan.

Gẹgẹ bi Sunna naa si ti se jẹ lilo Islam ni ifisisẹ, ni o n tun se afihan Al-Qur'aani alapọnle, o si n se alaye awọn aayah rẹ, o si n la eyi ti a wa ni sangiliti ninu awọn idajọ rẹ, nigba ti o se pe Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" a maa se alaye ohun ti a sọ kalẹ fun un nigba kan pẹlu ọrọ, a si maa se e nigba mìíran pẹlu isẹ, o si maa n se e nigba mìíran pẹlu mejeeji, ati pe Sunna a maa da se alaye awọn idajọ ofin kan jinna si Al-Qur'aani.

Ọranyan si ni gbigba Al-Qur'aani ati Sunna gbọ ni ododo, pe ipilẹ meji ti ofin ni wọn, ti mejeeji jẹ itilẹ ninu ẹsin Islam, eyi ti o se pe ọranyan ni ki a tẹle mejeeji, ki a si maa da ọrọ pada sidi mejeeji, ati titẹle asẹ mejeeji, ati jijinna si ohun ti mejeeji kọ, ati gbigba awọn iroyin mejeeji ni ododo, ati gbigba ohun ti o wa ninu mejeeji ninu awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ ati awọn isẹ Rẹ gbọ, ati ohun ti Ọlọhun pa l'ese kalẹ fun awọn ẹni-Rẹ olugbagbọ-ododo, ati ohun ti O se ni ileri-iya fun awọn ọta Rẹ alaigbagbọ; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} فلا وربك لا يؤمنون حتى يحكموك فيما شجر بينهم ثم لا يجدوا في أنفسهم حرجاً مما قضيت ويسلموا تسليماً { [سورة النساء، الآية: 65].

« Sugbọn kò ri bẹẹ, Mo fi Oluwa rẹ bura, wọn kò ni i gbagbọ titi wọn o fi fi ọ se onidajọ nipa ohun ti wọn n se ariyanjiyan si laarin wọn, lẹyin naa ti wọn kò si ri ohun ti ọkan wọn kọ ninu ohun ti o da lẹjọ, ti wọn si gbafa ni tọwọ-tẹsẹ » [Suuratun-Nisaa'i: 65]. Ọlọhun t'O mọ tun sọ pe:

} وما آتاكم الرسول فخذوه وما نهاكم عنه فانتهوا { [سورة الحشر: 7].

« Ohun ti Ojisẹ Ọlọhun ba mu wa fun yin, ẹ gba a, ohun ti o ba si kọ fun yin, ẹ jinna si i » [Suuratul-Hashr: 7].

Lẹyin alaye nipa awọn ipilẹ ti a ti n mu ofin ẹsin yii, o dara pe ki a sọ awọn ipele rẹ, ti i se Islam -igbafa fun Ọlọhun- ati Iimaan -igbagbọ-ododo, ati Ihsaan -daadaa sise- a o si sọ nipa awọn origun awọn ipele wọnyi ni soki:

###

IPELE KINNI: ISLAM

Awọn origun rẹ jẹ marun-un, awọn ni: Ijẹri mejeeji, ati irun, ati Zaka -itọrẹ aanu- ati aawẹ, ati Haji.

Alakọkọ: Ijẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati sin lododo yatọ si Ọlọhun, ati pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a".

Itumọ ijẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati sin lododo yatọ si Ọlọhun ni pe: Kò si ẹni ti a jọsin fun ni ododo ni ori ilẹ, tabi ninu sanma, afi Ọlọhun -Allaahu- nikan, nitori pe Oun ni Ọlọhun Otitọ, irọ si ni gbogbo ọlọhun mìíran ti o yatọ si I; o si mu ki sise afọmọ ijọsin naa fun Ọlọhun nikan, ati lile e jinna si ohun ti o yatọ si I o jẹ ọranyan, ati pe kò ni i se oluwi i ni anfaani titi ohun meji kan yoo fi pe si i lara:

Ekinni ni: Wiwi LAA ILAAHA ILLA -L-LAAH -ti o tumọ si- “kò si ọba kan ti o tọ lati sin lododo afi Ọlọhun" jade lati ara adisọkan, ati imọ, ati amọdaju, ati gbigba a ni otitọ ati ifẹ.

Ekeji ni: Sise aigbagbọ si ohun ti wọn n sin lẹyin Ọlọhun. Tori naa ẹnikẹni ti o ba wi ijẹri yii, ti kò si se aigbagbọ si ohun ti wọn n sin lẹyin Ọlọhun, gbolohun yii kò ni i se e lanfaani.

Ati pe itumọ ijẹri pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i, ni titẹle e nipa ohun ti o pa lasẹ, ati gbigba a lododo nipa ohun ti o fun'ni niro, ati jijinna si ohun ti o kọ, ti o si le'ni nibẹ, ati ki a ma se jọsin fun Ọlọhun afi pẹlu ohun ti o se lofin, ati ki o mọ daju, ki o si ni adisọkan pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i si gbogbo awọn eniyan, ati pe ẹru kan ti a kò gbọdọ jọsin fun ni i, ojisẹ kan ti a kò si gbọdọ pe ni opurọ ni i, sugbọn ti a o maa gbọrọ si i lẹnu, ti a o si maa tẹle e, ẹnikẹni ti o ba tẹle e yoo wọ ọgba-idẹra -Al-janna- bẹẹ ni ẹnikẹni ti o ba kọ ọrọ si i lẹnu, yoo wọ ina; ati ki o mọ daju ki o si ni adisọkan pe gbigba ofin Sharia yala ninu adisọkan, tabi ninu awọn ami ijọsin eyi ti Ọlọhun fi pa'ni lasẹ, tabi ninu eto idajọ ati sise ofin, tabi ninu ohun ti o jẹmọ awọn iwa, tabi ninu ohun ti o jẹmọ mimọ ẹbi, tabi ninu ohun ti o jẹmọ sise ni ẹtọ ati eewọ … kò le e sẹlẹ afi lati ọna Ojisẹ alapọnle yii, Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a"; tori pe oun ni ojisẹ Ọlọhun, olujisẹ ofin Rẹ, lati ọdọ Rẹ.

Ẹlẹẹkeji: Irun:

Oun ni opo keji ninu awọn opo Islam, koda oun ni opomulero Islam, tori pe oun ni asepọ ti n bẹ laarin ẹru ati Oluwa rẹ, yoo maa se e ni asetunse ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, yoo maa se igbagbọ rẹ ni ọtun ninu rẹ, yoo si maa fọ ẹmi rẹ mọ nibi eeri awọn ẹsẹ, yoo si maa doola laarin rẹ ati awọn iwa ibajẹ ati awọn ẹsẹ, tori naa nigba ti ẹru ba ji lati oorun rẹ ni owurọ rẹ -yoo duro ni iwaju Oluwa rẹ, ni ẹni ti o mọra ti o se imọtoto- siwaju ki o to ko airoju pẹlu ẹru ofoo ile-aye- lẹyin naa yoo gbe Oluwa rẹ tobi, yoo si jẹwọ jijẹ ẹru Rẹ, yoo si wa iranlọwọ lọdọ Rẹ, yoo si tọrọ imọna lọdọ Rẹ, yoo si se ohun ti o wa laarin rẹ ati Oluwa rẹ ninu awọn majẹmu titẹle -asẹ Rẹ- ati ijọsin -fun Un- ni ọtun, ni ẹni ti o fi ori kanlẹ, ti o si dide, ti o si tẹ, yoo maa se eleyii ni asetunse ni ojoojumọ ni ẹẹmarun-un; o si pa dandan nitori atiki irun yii pe ki o jẹ ẹni ti o mọra ninu ọkan rẹ, ati ara rẹ, ati ẹwu rẹ, ati aaye ikirun rẹ; ati ki Musulumi o maa ki i ni jama pẹlu awọn ọmọ-iya rẹ Musulumi -ti eyi ba rọrun fun un- ni awọn ti wọn yoo kọ oju awọn ọkan wọn si Oluwa wọn, ti wọn yoo si kọ awọn oju wọn si Ka'abah alapọnle, ile Ọlọhun, tori naa dajudaju a ti gbe irun le ori eyi ti o pe ju ninu awọn ọna, ati eyi ti o dara ju ninu rẹ, eyi ti Ẹlẹda ibukun ati giga ni fun Un ni ki awọn ẹru Oun o maa fi jọsin; nipa kikojọpọ ti o ko sise agbega fun Un pẹlu awọn orisirisi orike pọ, ninu wiwi ni ori ahọn, ati isẹ ọwọ mejeeji, ati ẹsẹ mejeeji, ati ori, ati awọn ohun ijẹro ara rẹ, ati awọn orike ara rẹ yoku; onikaluku ni yoo mu ipin rẹ ninu ijọsin nla yii.

Nitori naa awọn orike ijẹro ati awọn apa ati ẹsẹ yoo mu ipin wọn ninu rẹ, ati pe ọkan naa yoo mu ipin rẹ ninu rẹ, o si tun se akojọpọ ẹyin, ati ọpẹ, ati agbega, ati afọmọ, ati gbigbetobi, ati ijẹri otitọ, ati kike Al-Qur'aani alapọnle, ati diduro niwaju Oluwa ni iduro ẹru yẹpẹrẹ olutẹriba fun Oluwa, Oluto-eto, lẹyin naa itẹriba fun Un ni ibuduro yii, ati irababa, ati wiwa sisunmọ Ọn, lẹyin naa titẹ -ruku- ati iforikanlẹ, ati ijokoo ni itẹriba ati ibẹru ati ifarabalẹ fun titobi ati titẹriba fun titobi Rẹ, ọkan rẹ ti da, ara rẹ si rẹlẹ fun Un, awọn orike rẹ si balẹ fun Un, lẹyin naa yoo pe irun rẹ pẹlu fifi ẹyin fun Ọlọhun, ati titọrọ ikẹ ati igẹ fun Anabi Rẹ Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", lẹyin naa ni yoo tọrọ oore aye ati ti ọrun ni ọdọ Oluwa rẹ.

Ẹlẹẹkẹta: Zaka:

Oun ni origun kẹta ninu awọn origun Islam, ati pe ọranyan l'o jẹ lori Musulumi ọlọrọ pe ki o yọ zaka nnkan-ini rẹ, ipin diẹ gan an si ni i, yoo yọ ọ fun awọn alaini, ati awọn talaka, ati awọn mìíran ninu awọn ti o tọ pe ki a yọ ọ fun.

Ọranyan l'o si jẹ lori Musulumi pe ki o yọ ọ fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i, ni ẹni ti inu rẹ dun si i, kò si gbọdọ fi i se iregun si awọn t'o ni in, bẹẹ ni kò gbọdọ titori rẹ ni wọn lara, ati pe ọranyan ni pe ki Musulumi o yọ ọ ni ẹni ti n wa iyọnu Ọlọhun, ti kò si fi i wa ẹsan kan, tabi ọpẹ kan ni ọdọ eniyan; sugbọn nse ni yoo yọ ọ ni ti sise afọmọ fun oju Ọlọhun, ki i se ti karimi, tabi asegbọni.

Ati pe fifa oore n bẹ ninu yiyọ Zaka, ati didun awọn alaini, ati awọn talaka, ati awọn oni-bukaata ninu, ati rirọ wọn lọrọ kuro nibi abuku ibeere, ati sise aanu wọn nibi iparun, ati bukaata, nigba ti awọn olowo ba pa wọn ti, bẹẹ ni jijẹ ẹni ti a royin pẹlu apọnle, ati lilawọ, ati titi ẹlomiran siwaju ẹni, ati ninawo, ati aanu n bẹ ninu yiyọ Zaka, ati pipa awọn iroyin awọn ahawọ ti, ati ti awọn ahun, ati ti abuku, ati pe awọn Musulumi yoo maa ranra wọn lọwọ ninu rẹ, olowo wọn yoo maa se aanu alaini wọn, tori naa -ti a ba mu ẹsin yii lo- talaka alaini kan kò ni i sẹku ni awujọ, tabi onigbese ti ẹru gbese n pa, tabi oni-irin-ajo ti ọna se mọ.

Ẹlẹẹkẹrin: Aawẹ:

Oun ni gbigba aawẹ osu Ramadaan, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi oorun yoo fi wọ, alaawẹ yoo fi ounjẹ, ati ohun mimu, ati biba obinrin lo, ati ohun ti o ni idajọ rẹ silẹ ninu rẹ, ni ti ijọsin fun Ọlọhun, t'O mọ, t'O si ga, yoo si ko ara rẹ ro kuro nibi awọn ifẹkufẹ rẹ, ati pe dajudaju Ọlọhun ti se aawẹ ni fifuyẹ fun alaarẹ, ati oni-irin-ajo, ati oloyun, ati olure-ọmọ, ati oni-nnkan-osu, ati ẹlẹjẹ-ibimọ; tori naa onikaluku wọn l'o ni idajọ ti o ba a mu.

Musulumi o si ko ara rẹ ro ninu osu yii kuro nibi awọn ifẹẹnu rẹ, tori naa ẹmi rẹ yoo jade pẹlu ijọsin yii nibi jijọ awọn ẹranko lọ sibi jijọ awọn malaika ti wọn sunmọ Ọlọhun, debi pe dajudaju a le ya aworan alaawẹ pẹlu aworan ẹni ti kò ni bukaata kan ninu ile-aye yatọ si ki o ri iyọnu Ọlọhun.

Ati pe aawẹ a maa ye ọkan, a si maa mu'ni ri aye sa, a si maa se'ni ni ojukokoro nipa ohun ti o wa lọdọ Ọlọhun, a si maa ran awọn olowo leti nipa awọn alaini, ati awọn ipo wọn, nitori naa ọkan wọn yoo se aanu wọn, wọn o si mọ ohun ti awọn wa ninu rẹ ninu idẹra Ọlọhun, tori naa wọn o se alekun ọpẹ.

Aawẹ a si maa fọ ẹmi mọ, a si maa gbe e ro lori ibẹru Ọlọhun, a si maa se onikaluku ati awujọ ni ẹni ti yoo maa se akiyesi pe Ọlọhun n wo oun ninu idẹra ati inira, ni ikọkọ ati gbangbá; nigba ti o se pe awujọ yoo se osu kan gbako ni ẹni ti n se amojuto ijọsin yii, ti i si n se akiyesi Oluwa rẹ, ti o se pe ibẹru Ọlọhun t'O ga ati gbigba Ọlọhun gbọ lododo ati ọjọ ikẹyin l'o mu un se bẹẹ, ati amọdaju pe dajudaju Ọlọhun mọ ikọkọ ati ohun ti o pamọ ju, ati pe ọjọ kan n bọ dandan ti eniyan yoo duro ninu rẹ niwaju Oluwa rẹ, ti yoo si bi i leere nipa awọn isẹ rẹ patapata, kekere wọn ati ninla wọn.

Ẹlẹẹkarun-un: Haji:

“Haji" lọ si ile Ọlọhun abiyi ni Makkah alapọnle, ọranyan ni i lori gbogbo Musulumi, ti o ti balaga, onilaakaye, alagbara, ti o ni ikapa lori ohun gigun, tabi owo rẹ lọ si ile Ọlọhun abiyi naa, ti o si ni ohun ti yoo to o ni owo-na ni alọ ati abọ rẹ, pẹlu majẹmu pe ki owo-na yii o jẹ alekun lori ounjẹ awọn ti n tọju, ki o si jẹ ẹni ti o ni ifayabalẹ lori ara rẹ ni oju-ọna rẹ, ti o si ni ifayabalẹ lori awọn ti n tọju nigba ti kò ni i si pẹlu wọn, ati pe ọranyan ni Haji jẹ ni ẹẹkan soso ninu igbesi-aye fun ẹni ti o ba ni agbara ọna atilọ sibẹ.

O si yẹ pe ki ẹni ti o ba fẹ lati se Haji o ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun; ki ẹmi rẹ o le baa mọ kuro nibi idọti awọn ẹsẹ, tori naa nigba ti o ba de Makkah alapọnle ati awọn aaye ijọsin mimọ, yoo se awọn isẹ Haji ni ti ijọsin ati sise agbega fun Ọlọhun, yoo si mọ daju pe a ki i jọsin fun Ka'abah, ati awọn aaye ijọsin yoku, lẹyin Ọlọhun, ati pe wọn ki i se'ni lanfaani, wọn ki i si i ni eniyan lara, ati pe ti Ọlọhun kò ba pa eniyan lasẹ pẹlu sise Haji lọ sibẹ ni, dajudaju ki ba ti tọ fun Musulumi kan lati se Haji lọ sibẹ.

Ninu Haji yii, alalaaji yoo lo ilọdi ati ibora funfun, tori naa awọn Musulumi yoo pejọ lati gbogbo awọn orilẹ-ede agbaye si aaye kan naa, wọn o wọ asọ kan naa, wọn o si maa sin Oluwa kan soso, kò si iyatọ kan laarin olori ati mẹkunu, olowo ati alaini, eniyan funfun ati dudu, ẹda Ọlọhun ati ẹru Rẹ ni onikaluku, kò si ajulọ kan fun Musulumi kan lori Musulumi mìíran afi pẹlu ipaya Ọlọhun, ati isẹ rere.

Nitori naa iranra-ẹni-lọwọ ati imọra-ẹni yoo sẹlẹ fun awọn Musulumi, wọn yoo si maa se iranti ọjọ ti Ọlọhun yoo gbe gbogbo wọn dide; ti yoo si ko wọn jọ si aaye kan fun isiro, tori naa wọn yoo maa se ipalẹmọ pẹlu titẹle ti Ọlọhun t'O ga fun ohun ti n bẹ lẹyin iku.

Ijọsin ninu Islam:

Oun ni sise ẹrusin fun Ọlọhun ni itumọ, ati ni paapaa, tori pe Ọlọhun ni Ẹlẹda, iwọ ni ẹda, ati pe ẹrusin ni ọ, Ọlọhun si ni Ẹni ajọsin fun Rẹ. Ti eleyii ba jẹ bẹẹ, a jẹ pe dandan ni ki eniyan o maa lọ ninu isẹmi yii lori oju-ọna Ọlọhun ti o tọ, ni ẹni ti yoo maa tẹle ofin Rẹ, olutọ oripa awọn ojisẹ Rẹ, ati pe Ọlọhun ti se awọn ofin nla ni ofin fun awọn ẹru Rẹ, gẹgẹ bii fifi At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan ninu ijọsin- rinlẹ fun Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda, ati irun, ati Zaka, ati aawẹ, ati Haji.

Sugbọn ki i se eleyii nikan ni gbogbo awọn ijọsin ninu Islam, ijọsin ninu Islam tilẹ kari ju [bayii lọ], nigba ti o se pe oun ni: Gbogbo ohun ti Ọlọhun nifẹ si, ti O si yọnu si i, ninu awọn isẹ, ati awọn ọrọ, ti o han, ati eyi ti o pamọ. Nitori naa gbogbo isẹ kan, tabi ọrọ kan, ti o se, tabi o sọ, ninu ohun ti Ọlọhun nifẹ si, ti O si yọnu si, ijọsin ni i, koda gbogbo asa kan ti o dara, ti o se pẹlu aniyan atisunmọ Ọlọhun, ijọsin ni i. Nitori naa ibasepọ rẹ ti o dara si baba rẹ, ẹbi rẹ, aya rẹ, awọn ọmọ rẹ, ati awọn alamuleti rẹ, ti o ba ni adisọkan wiwa oju-rere Ọlọhun pẹlu rẹ, ijọsin ni i; bẹẹ ni ibasepọ rẹ ti o dara ninu ile, ati ọja, ati ni ibi-isẹ, nigba ti o ba ni adisọkan wiwa oju-rere Ọlọhun pẹlu rẹ, ijọsin ni i; ati sisọ ohun ifọkantan, ati idunnimọ ododo ati isedọgba ati kiko inira ro, ati riran alailera lọwọ, ati kiko ọrọ jọ lati ara isẹ ti o tọ, ati ninawo lori ẹbi ati awọn ọmọ, ati sise atilẹyin fun awọn alaini, ati sise abẹwo awọn alaarẹ, ati fifun ẹni ti ebi n pa lounjẹ, ati sise iranlọwọ fun ẹni ti a se abosi fun, ijọsin ni gbogbo eleyii, ti a ba se adisọkan wiwa oju-rere Ọlọhun pẹlu wọn. Tori naa gbogbo isẹ ti o ba n se fun ara rẹ, tabi fun ẹbi rẹ, tabi fun awujọ rẹ, tabi fun ilu rẹ, ti o ni adisọkan wiwa oju-rere Ọlọhun pẹlu rẹ, ijọsin ni i.

Koda gan-an jijẹ igbadun ẹmi rẹ ninu aala ohun ti Ọlọhun gba fun ọ, yoo jẹ ijọsin, nigba ti aniyan ti o dara ba pẹlu rẹ; Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", sọ pe:

(( وفي بضع أحدكم صدقة، قالوا: يا رسول الله، أيأتي أحدنا شهوته، ويكون له فيها أجر؟ قال: (( أرأيتم لو وضعها في حرام، أكان عليه وزر؟ فكذلك إذا وضعها في الحلال، كان له أجر )). [رواه مسلم].

« Ati pe ibalopọ ti ẹnikan [ninu] yin ba ba iyawo rẹ lopọ, sara ni i fun un », wọn ni: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, njẹ ẹnikan wa yoo wa se ohun ti ẹmi rẹ n fẹ, ki o si tun ti ara rẹ gba ẹsan bi? O ni « Ẹ sọ fun mi, njẹ ti o ba ti i [iyẹn abẹ rẹ] bọ ibi ti o jẹ eewọ, se yoo ti ara rẹ gbẹsẹ bi? A jẹ pe bẹẹ naa ni ti o ba ti i bọ ibi ti o jẹ ẹtọ fun un, yoo ti ara rẹ gba ẹsan » Muslim l'o gbe e jade.

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", tun sọ pe:

(( على كل مسلم صدقة. قيل: أرأيت إن لم يجد! قال: يعتمل بيديه فينفع نفسه ويتصدق. قال: أرأيت إن لم يستطع؟ قال: يعين ذا الحاجة الملهوف. قال: قيل له: أرأيت إن لم يستطع؟ قال يأمر بالمعروف أو الخير. قال: أرأيت إن لم يفعل؟ قال: يمسك عن الشر، فإنها صدقة )). [متفق عليه].

« Ọranyan ni sara sise lori gbogbo Musulumi. Wọn ni: O dara ti kò ba ri [ohun ti yoo fi se sara n kọ]? O dahun pe: Ki o maa sisẹ pẹlu ọwọ rẹ mejeeji, ki o si maa se ara rẹ ni anfaani, ki o si maa se sara. O ni: Njẹ ti kò ba le se e n kọ? O ni: Ki o maa se iranlọwọ fun oni-bukaata ẹni ti oju-n-pọn. O ni: Wọn sọ fun un pe: Njẹ ti kò ba le se e n kọ? O dahun pe: Ki o maa fooro si daadaa sise tabi rere. O ni: Ti kò ba se bẹẹ n kọ? O dahun pe: Ki o ka ọwọ ro kuro nibi aburu, dajudaju saara ni i » Bukhari ati Muslim ni wọn gbe e jade.

###

IPELE KEJI: IGBAGBỌ-ODODO

Mẹfa si ni awọn origun tiẹ, awọn ni: Nini igbagbọ-ododo si Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati nini igbagbọ-ododo si akọsilẹ -kadara-.

Alakọkọ: Nini igbagbọ si Ọlọhun:

Ni ki o ni igbagbọ si jijẹ oluwa Ọlọhun t'O ga, pe dajudaju Oun ni Oluwa, Ẹlẹda, Oluto-eto gbogbo ọrọ, ki o si gba jijẹ ọlọhun ti a jọsin fun Ọlọhun, Ọba t'O ga gbọ, eyi ni pe dajudaju Oun ni Ọlọhun Ododo, ati pe irọ ni gbogbo ohun ti wọn n sin lẹyin Rẹ, ki o si gba awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ gbọ, pe dajudaju O ni awọn orukọ ti o dara ju, ati awọn iroyin ti o ga ju, ti o pe.

Ki o si ni igbagbọ si jijẹ ọkan soso Ọlọhun ninu eleyii, pe dajudaju kò si orogun kan fun Un ninu jijẹ oluwa Rẹ, tabi ninu jijẹ ọlọhun ti a jọsin fun Rẹ, tabi ninu awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} رب السماوات والأرض وما بينهما فاعبده واصطبر لعبادته هل تعلم له سمياًّ { [سورة مريم: 65].

« Oluwa awọn sanma ati ilẹ ati ohun ti o wa ni aarin mejeeji, nitori naa maa jọsin fun Un, ki o si se suuru fun ijọsin Rẹ, njẹ iwọ wa mọ ẹnikan ni alafijọ Rẹ bi? » [Suuratu Maryam: 65].

Ki o si tun ni igbagbọ pe dajudaju oogbe ki i gbe E tabi oorun, ati pe dajudaju Oun ni Oni-mimọ ikọkọ ati gbangbá, bẹẹ ni dajudaju Oun l'O ni ijọba awọn sanma ati ilẹ:

}وعنده مفاتح الغيب لا يعلمها إلا هو ويعلم ما في البر والبحر وما تسقط من ورقة إلا يعلمها ولا حبة في ظلمات الأرض ولا رطب ولا يابس إلا في كتاب مبين { [سورة الأنعام: 59].

« Ọdọ Rẹ ni awọn kọkọrọ ohun ti o pamọ wa, ẹnikan kò le e mọ ọn afi Oun, O si tun mọ ohun ti n bẹ ninu ilẹ ati okun, ati pe kò si ewe kan ti yoo jabọ afi ki O mọ nipa rẹ, bẹẹ ni kò si horo ọka kan ninu okunkun ilẹ, kò tilẹ si ohun tutu kan tabi ohun gbigbẹ kan afi ki o ti wa ninu tira ti o han » [Suuratul-An'aam: 59].

Ki o si tun gbagbọ lododo pe dajudaju Oun -giga ni fun Un- N bẹ lori aga-ọla Rẹ, O leke lori awọn ẹda Rẹ, ati pe bakan naa Oun tun N bẹ pẹlu awọn ẹda Rẹ, O mọ awọn isesi wọn, O si N gbọ awọn ọrọ wọn, O si N ri awọn aaye wọn, O si N to awọn ọrọ wọn, O N rọ alaini lọrọ, O si tun ẹni ti o ku diẹ kaato se, O si N da ẹni ti O ba fẹ lọla, O si N gba ọla kuro lọdọ ẹni ti O ba fẹ; Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan.

Ninu awọn eso gbigba Ọlọhun gbọ lododo ni ohun ti n bọ yii:

1- Yoo maa so eso nini ifẹ Ọlọhun fun ẹru, ati gbigbe E tobi, mejeeji a si maa se gbigbe asẹ Rẹ dide, ati jijinna si ohun ti O kọ, ni ọranyan, ati pe nigba ti ẹru ba ti se eleyii, yoo ti ara mejeeji se oriire ni aye ati ni ọrun.

2- Wi pe nini igbagbọ-ododo si Ọlọhun, a maa mọ iyi, ati agbega sinu ẹmi ẹni, tori pe o mọ daju pe Ọlọhun ni Olukapa ni ti otitọ fun gbogbo ohun ti o wa ninu aye, ati pe dajudaju kò si oluseni-lanfaani kan tabi oluninilara kan yatọ si I, amọdaju yii yoo si rọ ọ lọrọ kuro ni ọdọ ẹni ti o yatọ si Ọlọhun, yoo si yọ ibẹru ẹni ti o yatọ si I kuro ni ọkan rẹ, nitori naa kò ni i ni irankan lọ si ọdọ ẹnikan lẹyin Ọlọhun, kò si ni i bẹru ẹnikan lẹyin Rẹ.

3- Wi pe nini igbagbọ-ododo si Ọlọhun, yoo maa mọ itẹriba sinu ẹmi rẹ; tori pe o mọ daju pe lati ọdọ Ọlọhun ni ohun ti o wa pẹlu rẹ ninu idẹra ti wa. Nitori naa esu kò ni i ri i tanjẹ, ati pe kò ni i kọ otitọ, kò si ni i se igberaga, kò si ni i maa se fukẹ pẹlu agbara rẹ, ati nnkan-ini rẹ.

4- Wi pe eni ti o gba Ọlọhun gbọ yoo mọ imọ amọdaju pe kò si ọna kan lọ si idi oriire ati ọla afi pẹlu isẹ rere, eyi ti Ọlọhun yọnu si, ni igba ti ẹlomiran ti o yatọ si i ni awọn adisọkan ti kò dara; gẹgẹ bi adisọkan pe Ọlọhun pa asẹ pẹlu kikan ọmọ Rẹ mọ agbelebu, lati fi pa asise ọmọ-eniyan rẹ; tabi ki o gba awọn ọlọhun kan gbọ, ki o si ni adisọkan pe wọn o mu oun ri apa kan ninu ohun ti oun n fẹ, ni ohun ti o se pe ni paapaa rẹ kò le e se'ni ni anfaani kan, bẹẹ ni kò le e ni'ni lara; tabi ki o jẹ alaimọ Ọlọhun rara, ti kò ni igbagbọ si bibẹ Ẹlẹda… ohun inaga si ni gbogbo awọn wọnyi, titi igba ti wọn ba wa si ọdọ Ọlọhun ni ọjọ igbende, ti wọn si ri awọn otitọ, wọn o mọ pe dajudaju ori anu ti o han ni awọn wa.

5- Wi pe gbigba Ọlọhun gbọ lododo a maa re agbara ti o tobi kan ninu ipinnu, itẹsiwaju, suuru, idurosinsin, ati igbẹkẹle Ọlọhun, si ara eniyan, nigba ti i ba n gbe awọn nnkan ti o ga se ni ile-aye, ni ti wiwa iyọnu Ọlọhun, ti o si tun wa lori amọdaju pipe pe olugbẹkẹle Ọba awọn sanma ati ilẹ ni oun, ati pe yoo se iranlọwọ fun oun, yoo si di ọwọ oun mu, nitori naa yoo jẹ ẹni ti o rinlẹ ni rinrinlẹ awọn apata ninu suuru rẹ, irinlẹ rẹ, ati agbẹkẹle rẹ.

Ẹlẹẹkeji: Nini igbagbọ-ododo si awọn Malaika:

Wi Pe dajudaju Ọlọhun da wọn fun titẹle asẹ Rẹ, O si royin wọn pe awọn:

} عباد مكرمون. لا يسبقونه بالقول وهم بأمره يعملون. يعلم ما بين أيديهم وما خلفهم ولا يشفعون إلا لمن ارتضى وهم من خشيته مشفقون { [سورة الأنبياء: 26-28].

« Ẹru alapọnle ni wọn. Wọn ki i gba iwaju Rẹ pẹlu ọrọ, ati pe asẹ Rẹ ni wọn fi n sisẹ. O mọ ohun ti n bẹ niwaju wọn, ati ohun ti n bẹ lẹyin wọn, ati pe wọn kò le e sipẹ afi fun ẹni ti O ba yọnu si, bẹẹ ni awọn a maa paya fun ibẹru Rẹ » [Suuratul-Anbiyaa': 26-28]. Ati pe dajudaju awọn:

} لا يستكبرون عن عبادته ولا يستحسرون. يسبحون الليل والنهار لا يفترون { [سورة الأنبياء: 19، 20].

« Wọn ki i se igberaga tayọ ijọsin fun Un, ati pe wọn ki i ko agara. Wọn a maa se afọmọ ni oru ati ni ọsan, wọn ki i si ja [nibi sise e] » [Suuratul-Anbiyaa': 19 ,20]. Ọlọhun gbe wọn pamọ si wa, tori naa a kò le e ri wọn, ati pe o see se ki Ọlọhun O sipaya apa kan ninu wọn fun apa kan ninu awọn anabi Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ.

Ati pe awọn malaika ni awọn isẹ kan ti a fi pa wọn lasẹ, ninu wọn ni Jibriil ti a fi sọ isẹ -ti Ọlọhun maa N fi i ransẹ- a maa sọ ọ kalẹ lati ọdọ Ọlọhun fun ẹni ti O ba fẹ ninu awọn ẹru Rẹ [ninu] awọn ojisẹ, o si wa ninu wọn ẹni ti a fi sọ gbigba awọn ẹmi, bẹẹ ni o n bẹ ninu wọn awọn malaika ti a fi sọ awọn ọmọ ti o wa ninu apo-ibi, o si n bẹ ninu wọn awọn ti a fi sọ sisọ awọn ọmọ Aadama, o si n bẹ ninu wọn awọn ti a fi sọ kikọ awọn isẹ wọn silẹ, tori naa onikaluku l'o ni malaika meji:

} عن اليمين وعن الشمال قعيد. ما يلفظ من قول إلا لديه رقيب عتيد { [سورة ق: 17-18].

« Wọn o jokoo ni ọwọ ọtun ati ọwọ osi. [Ẹnikan] kò ni i sọ ọrọ kan afi ki olusọ kan ti jokoo ni ọdọ rẹ » [Suuratu Qaaf: 17-18].

Ninu awọn eso nini igbagbọ-ododo si awọn Malaika ni:

1- Ki adisọkan Musulumi o mọ kuro nibi awọn panti ẹbọ, ati awọn eeri rẹ, tori pe dajudaju nigba ti Musulumi ba ni igbagbọ-ododo si bibẹ awọn malaika ti Ọlọhun pa lasẹ pẹlu awọn isẹ nla wọnyi; yoo bọ lọwọ adisọkan bibẹ awọn ẹda irọ kan ti wọn n kopa ninu didari aye.

2- Ki Musulumi o mọ daju pe awọn malaika kò le e se'ni ni anfaani, wọn kò si le e ni'ni lara, ati pe wọn kò jẹ nnkan kan yatọ si awọn ẹru alapọnle kan, wọn ki i sẹ Ọlọhun ninu ohun ti O ba fi pa wọn lasẹ, ati pe wọn a maa se ohun ti O fi pa wọn lasẹ; tori naa kò ni i sin wọn, kò si ni i da oju kọ wọn, kò si ni i rọ mọ wọn.

Ẹlẹẹkẹta: Nini igbagbọ-ododo si awọn Tira:

Nini igbagbọ-ododo pe dajudaju Ọlọhun sọ awọn tira kan kalẹ fun awọn anabi Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ; lati se alaye ododo, ati lati pepe lọ sidi rẹ, gẹgẹ bi Ọlọhun t'O ga ti sọ pe:

} لقد أرسلنا رسلنا بالبينات وأنزلنا معهم الكتاب والميزان ليقوم الناس بالقسط { [سورة الحديد، الآية: 25].

« Dajudaju Awa ti ran awọn ojisẹ wa pẹlu awọn alaye, A si sọ Tira ati osunwọn kalẹ pẹlu wọn, nitori ki awọn eniyan o le baa duro pẹlu sise dọgba » [Suuratul-Hadiid: 25]. Awọn tira wọnyi si pọ, ninu wọn ni: Iwe Anabi Ibraahiim, ati At-Tawraata -Majẹmu Laelae- eyi ti a fun Anabi Musa, ati Zabuura eyi ti a fi ran Anabi Daa'uud, ati Injiila -Bibeli- eyi ti Al-Masiihu -Jesu- mu wa, ki ọla Ọlọhun o maa ba gbogbo wọn.

Nitori naa nini igbagbọ-ododo si awọn tira ti o siwaju wọnyi yoo maa sẹlẹ pẹlu ki o gbagbọ lododo pe: Dajudaju Ọlọhun sọ wọn kalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, ati pe dajudaju wọn se akojọpọ ofin eyi ti Ọlọhun fẹ jisẹ Rẹ fun awọn eniyan ni asiko yun un.

Awọn ti Ọlọhun fun wa niro nipa wọn wọnyi si ti parẹ, tori naa iwe Anabi Ibraahiim kò si ni aye mọ, sugbọn At-Tawraata ati Injiila -Bibeli- ati Zabuura, bi o tilẹ jẹ pe wọn n bẹ pẹlu awọn orukọ wọn, ni ọdọ awọn Yahuudi, ati awọn alagbelebu -Christians- sugbọn wọn ti yi wọn pada, wọn si ti ti ọwọ bọ wọn, bẹẹ ni ọpọlọpọ ninu wọn l'o si ti sọnu, ohun ti ki i si se ara wọn ti wọnu wọn, koda wọn fi wọn ti si ọdọ awọn ti o yatọ si awọn ti o ni wọn, tori naa iwe ti o le ni ogoji l'o wa ninu Majẹmu Laelae, sugbọn ti o se pe marun-un pere ni wọn fi ti si ọdọ Anabi Musa, bẹẹ ni kò si ọkan ninu awọn Injiila -Bibeli: Majẹmu Titun- ti o wa loni yii ti wọn fi ti si ọdọ Al-Masiihu -Jesu-.

Sugbọn opin awọn tira ti a sọ kalẹ lati ọdọ Ọlọhun, oun ni Al-Qur'aani alapọnle, eyi ti O sọ kalẹ fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ti kò si yee jẹ ohun ti a sọ pẹlu isọ Ọlọhun, ti ayipada kan tabi atọwọbọ kan kò si sẹlẹ si i, yala ninu awọn harafi rẹ ni o, tabi awọn gbolohun rẹ, tabi awọn itumọ rẹ.

Ọpọlọpọ ọna si ni iyatọ fi wa laarin Al-Qur'aani alapọnle ati awọn tira ti o ti rekọja naa.

Ninu wọn ni:

1- Wi pe awọn tira ti wọn ti rekọja yii ti sọnu, ati pe ayipada ati atọwọbọ ti sẹlẹ si wọn, wọn si fi wọn ti si ọdọ awọn t'o yatọ si awọn t'o ni wọn, wọn si fi awọn alaye ati afikun ati afihan kun wọn, wọn si se akojọpọ nnkan pupọ ninu awọn ohun ti o tako isẹ ti Ọlọhun maa N fi i ransẹ, ati laakaye, ati adamọ.

Sugbọn Al-Qur'aani alapọnle, oun kò i ti yee jẹ ohun ti a sọ pẹlu isọ Ọlọhun, pẹlu awọn harafi ati awọn gbolohun gan-n-gan eyi ti Ọlọhun fi sọ ọ kalẹ fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ayipada kankan kò sẹlẹ si i, bẹẹ ni afikun kankan kò wọnu rẹ, tori pe awọn Musulumi gbiyanju lori pe ki Al-Qur'aani o sẹku ni ohun ti o mọ kuro ninu gbogbo panti, nitori naa wọn kò lu u pọ mọ ohun ti o yatọ si i ninu itan aye Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", tabi itan aye awọn Sahaabe, “ki Ọlọhun O yọnu si wọn", tabi alaye Al-Qur'aani alapọnle, tabi awọn idajọ ijọsin ati awọn ibasepọ.

2- Wi pe a kò mọ itan ọna ti awọn tira ti tẹlẹ naa gba wa, koda a kò mọ ẹni ti apa kan ninu rẹ sọ kalẹ fun, tabi ede wo ni wọn fi kọ ọ, wọn tilẹ fi apa kan ninu wọn ti si ọdọ ẹni ti o yatọ si ẹni ti o mu un wa.

Sugbọn Al-Qur'aani, awọn Musulumi gba a wa lati ọdọ Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ni gbigbawa gba ọwọ ọgọọrọ eniyan, ni gbigba lati ẹnu ati ni kikọ silẹ, ati pe awọn Musulumi ni ọpọlọpọ ẹgbẹrun ni gbogbo ilu ati asiko ti wọn ha Tira yii -sori- bẹẹ ni ọpọlọpọ ẹgbẹrun ni awọn akọsilẹ rẹ -ti n bẹ- ati pe ti ohun ti a gbọ lẹnu ninu rẹ kò ba ti dọgba pẹlu ohun ti o wa ni akọsilẹ a kò ni i ka ẹdà eyi ti o yatọ kun; tori naa dandan ni ki ohun ti o wa ninu igbaaya o dọgba pẹlu ohun ti o wa ni akọsilẹ.

Ati pe pari-pari rẹ ni pe dajudaju a gba Al-Qur'aani wa ni gbigba lati ẹnu, iru eyi ti iwe kan ninu awọn iwe ile-aye kò ri iru rẹ ri; koda kò tilẹ si aworan iru gbigbawa yii rara afi ni ọdọ ijọ Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a"; ọna gbigba ọrọ wa yii ni: Ki akẹkọ o ha Al-Qur'aani ni ọdọ olukọ rẹ, ni ihaha si ori, nigba ti o se pe olukọ rẹ naa ti ha a lọdọ olukọ tiẹ, lẹyin naa ni olukọ yoo wa fun akẹkọ rẹ ni ẹbun iwe ẹri ti a n pe ni “Ijaazah" -ifọwọsi- olukọ naa yoo jẹri ninu rẹ pe dajudaju oun ka fun akẹkọ oun ohun ti oun ka ni ọdọ awọn olukọ oun, olukọ kan lẹyin omiran, gbogbo olukọ yoo maa darukọ olukọ rẹ titi ọna yii yoo fi de ọdọ Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati pe bayii ni ọna ti a fi gba a lati ẹnu naa yoo maa lọ lati ọdọ akẹkọ titi de ọdọ Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a".

Dajudaju awọn ẹri ti o ni agbara ati awọn arisami ti itan -ti o wa pẹlu alaye awọn ti o gba a wa bakan naa- si pọ jọjọ lori mimọ nipa Suura kọọkan, ati aayah kọọkan ninu Al-Qur'aani alapọnle, nibo l'o ti sọ? Ati nigba wo l'o sọ kalẹ fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a"?.

3- Wi pe awọn ede ti awọn tira ti wọn ti rekọja fi sọ kalẹ ti parẹ lati igba t'o pẹ, nitori naa kò si ẹnikan ti n sọ wọn mọ, ati pe diẹ l'o ku ti o gbọ wọn ye ni ode oni, sugbọn ede ti a fi sọ Al-Qur'aani kalẹ, ede kan ti n sẹmi ni i, ti o se pe ọgọọrọ aadọta ọkẹ eniyan l'o n sọ ọ, wọn n si n kọ'ni nipa rẹ, bẹẹ ni a n kọ ọ ni gbogbo orilẹ-ede ile-aye, ati pe ẹnikẹni ti kò ba kọ nipa rẹ, yoo ri ẹni ti yoo se alaye awọn itumọ Al-Qur'aani alapọnle fun un nibikibi.

4- Wi pe awọn tira tẹlẹtẹlẹ naa wa fun igba kan pato ni, wọn si jẹ ohun ti a da oju rẹ kọ ijọ kan pato yatọ si awọn eniyan yoku; idi niyi ti o fi se akojọpọ awọn idajọ kan pataki fun awọn ijọ yun un ati igba yun un, bẹẹ ni ohun ti o ba ri bẹẹ kò ba a mu pe ki o jẹ ti gbogbo eniyan.

Sugbọn Al-Qur'aani alapọnle, tira kan ti o kari gbogbo igba ni i, ti o ba gbogbo aaye mu, ti o se akojọpọ ninu awọn idajọ, ati awọn ibasepọ, ati awọn iwa, ohun ti o dara fun gbogbo ijọ, ti o si ba gbogbo igba mu; nitori pe ohun ti a da oju rẹ kọ eniyan ni apapọ ni ọrọ inu rẹ.

Ati pe yoo han lati ara eleyii pe dajudaju kò see se pe ki awijare Ọlọhun lori awọn ọmọ eniyan o wa ninu awọn iwe kan ti kò si ipilẹ ẹda rẹ, ti kò si si ẹnikan ni ori ilẹ ti n sọ ede ti wọn fi kọ awọn iwe naa lẹyin ti wọn ti ti ọwọ bọ wọn, ohun ti yoo jẹ awijare Ọlọhun lori awọn ẹda rẹ kò si nibi kan yatọ si inu tira kan ti a sọ, ti o si mọ kuro ninu afikun, adinku, ati ayipada, ti awọn ẹda rẹ tan ka ni gbogbo aye, ti a kọ pẹlu ede kan ti n sẹmi, ti ọkẹ aimoye ninu awọn eniyan fi n ka iwe, ti wọn si n jẹ awọn isẹ Ọlọhun fun awọn eniyan, tira yii si ni [Al-Qur'aani alapọnle], eyi ti Ọlọhun sọ kalẹ fun Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", oun si ni olusọ lori awọn tira ti o siwaju yii, olujẹri ododo fun wọn -siwaju ki wọn o to ti ọwọ bọ wọn- ati ẹlẹri lori wọn, oun l'o si jẹ ọranyan lori gbogbo ọmọ eniyan pe ki wọn o maa tẹle, ki o le baa jẹ imọlẹ, iwosan, imọna, ati ikẹ fun wọn. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وهذا كتاب أنزلناه مبارك فاتبعوه واتقوا لعلكم ترحمون { [سورة الأنعام: 155].

« Eleyii si jẹ Tira kan ti Awa sọ ọ kalẹ ni oni-ibukun, tori naa ẹ maa tẹle e, ki ẹ si maa paya [Ọlọhun], ki ẹ le baa jẹ ẹni ti a o kẹ » [Suuratul-An'aam: 155]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ ga tun sọ pe:

} قل يا أيها الناس إني رسول الله إليكم جميعاً { [سورة الأعراف: 158].

« Sọ pe ẹyin eniyan, dajudaju emi ni ojisẹ Ọlọhun si gbogbo yin » [Suuratul-Aaraaf: 158].

Ẹlẹẹkẹrin: Nini igbagbọ-ododo si awọn Ojisẹ ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba wọn:

Pe dajudaju Ọlọhun ran awọn ojisẹ kan si awọn ẹda Rẹ, ki wọn o maa fun wọn ni iro idunnu pẹlu idẹra, nigba ti wọn ba gba Ọlọhun gbọ, ti wọn si gba awọn ojisẹ lododo, ki wọn o si maa se ikilọ iya fun wọn, nigba ti wọn ba sẹ Ọlọhun. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ولقد بعثنا في كل أمة رسولاً أن اعبدوا الله واجتنبوا الطاغوت { [سورة النحل: 36].

« Ati pe dajudaju A ti gbe ojisẹ kan dide ninu gbogbo ijọ kọọkan; pe: Ẹ maa jọsin fun Ọlọhun, ki ẹ si jinna si awọn oosa » [Suuratu n-Nah'l :36]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ ga tun sọ pe:

} رسلا مبشرين ومنذرين لئلا يكون للناس على الله حجة بعد الرسل { [سورة النساء: 165].

« Awọn ojisẹ ti wọn jẹ olufun-ni ni iro-idunnu ati olukilọ, nitori ki awijare kan o ma baa si fun awọn eniyan lọdọ Ọlọhun lẹyin [t'O ti ran] awọn ojisẹ wọnyi » [Suuratun-Nisaa'i: 165].

Awọn ojisẹ yii si pọ, akọkọ wọn ni Anabi Nuuhu, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", opin wọn si ni Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ati pe o wa ninu wọn ẹni ti Ọlọhun fun wa niro nipa wọn, gẹgẹ bi Anabi Ibraahiim, ati Musa, ati Isa -Jesu- ati Daa'uud, ati Yahyaa, ati Zakariyyaa, ati Saalih, “ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn", bẹẹ ni o wa ninu wọn ẹni ti Ọlọhun kò sọ iroyin rẹ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ورسلاً قد قصصناهم عليك من قبل ورسلاً لم نقصصهم عليك { [سورة النساء: 164].

« Awọn ojisẹ kan n bẹ ti A ti sọ itan wọn fun ọ tẹlẹ, bẹẹ ni awọn ojisẹ kan n bẹ ti A kò sọ itan wọn fun ọ » [Suuratun-Nisaa'i: 164].

Ati pe eniyan abara ti Ọlọhun da ni awọn ojisẹ wọnyi, wọn kò ni ipin kan ninu awọn ohun ti o jẹ adayanri fun jijẹ oluwa, tabi ti jijẹ ọlọhun, nitori naa a kò gbọdọ sẹri nnkan kan si ọdọ wọn ninu ijọsin, ipin yowu o le jẹ, wọn kò si ni ikapa anfaani kan tabi inira kan fun ẹmi ara wọn; Ọlọhun t'O ga sọ nipa Nuuhu, “ki ọla Ọlọhun o maa ba a", -ti i se akọkọ wọn- pe o sọ fun ijọ rẹ pe:

} ولا أقول لكم عندي خزائن الله ولا أعلم الغيب ولا أقول إني ملك { [سورة هود: 31].

« Emi kò si sọ fun yin pe pẹpẹ ọrọ Ọlọhun wa lọdọ mi, ati pe emi kò mọ ohun ti o pamọ, ati pe emi kò sọ pe dajudaju emi jẹ malaika kan» [Suuratu Huud: 31]. Ọlọhun t'O ga si pa Anabi Muhammad -ti i se igbẹyin wọn- lasẹ pe ki o sọ pe:

} لا أقول لكم عندي خزائن الله ولا أعلم الغيب ولا أقول لكم إني ملك { [سورة الأنعام: 50].

« Emi kò sọ fun yin pe pẹpẹ ọrọ Ọlọhun wa lọdọ mi, ati pe emi kò mọ ohun ti o pamọ, ati pe emi kò sọ fun yin pe dajudaju emi jẹ malaika kan » [Suuratul-An'aam: 50]. Ati ki o sọ pe:

} لا أملك لنفسي نفعاً ولا ضراً إلا ما شاء الله { [سورة الأعراف: 188].

« N kò ni agbara anfaani kan funra mi, n kò si ni agbara [atimu] inira kan [kuro], afi ohun ti Ọlọhun ba fẹ » [Suuratul-A'araaf: 188].

Nitori naa ẹrusin alapọnle ni awọn anabi, Ọlọhun sa wọn lẹsa, O si pọn wọn le pẹlu riran wọn nisẹ, O si royin wọn pẹlu jijẹ ẹrusin, Islam ni ẹsin wọn, ati pe Ọlọhun kò ni I gba ẹsin kan yatọ si i, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إن الدين عند الله الإسلام { [سورة آل عمران: 19].

« Dajudaju ẹsin ni ọdọ Ọlọhun ni Islam » [Suuratu Aala Imraan: 19]. Awọn isẹ wọn dọgba ninu awọn ipilẹ wọn, awọn ofin wọn si pe orisirisi; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} لكلٍّ جعلنا منكم شرعة ومنهاجاً { [سورة المائدة: 48].

« Onikaluku yin ni A ti se ofin ati ilana ẹsin fun » [Suuratul-Maa'idah: 48]. Opin awọn ofin yii si ni ofin Anabi Muhammad, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", oun ni olupa gbogbo ofin ti o siwaju rẹ, bẹẹ ni isẹ rẹ ni opin awọn isẹ ti Ọlọhun fi ransẹ, oun si ni ipẹkun awọn ojisẹ.

Nitori naa ẹnikẹni ti o ba gba anabi kan gbọ ọranyan l'o jẹ lori rẹ pe ki o gba gbogbo wọn gbọ, bẹẹ ni ẹnikẹni ti o ba pe ọkan ninu wọn nirọ, dajudaju o ti pe gbogbo wọn nirọ, tori pe gbogbo awọn anabi ati awọn ojisẹ n pepe lọ sidi nini igbagbọ-ododo si Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati nitori pe ọkan naa ni ẹsin wọn, tori naa ẹnikẹni ti o ba se iyatọ laarin wọn, tabi ti o gba apa kan gbọ, ti o si se aigbagbọ si omiran, dajudaju o ti se aigbagbọ si wọn lapapọ; nitori pe onikaluku ninu wọn l'o n pepe lọ sidi nini igbagbọ-ododo si gbogbo awọn anabi ati awọn ojisẹ. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} آمن الرسول بما أنزل إليه من ربه والمؤمنون كل آمن بالله وملائكته وكتبه ورسله لا نفرق بين أحد من رسله { [سورة البقرة: 285].

« Ojisẹ naa gba ohun ti a sọ kalẹ fun un lati ọdọ Oluwa rẹ gbọ, ati awọn olugbagbọ-ododo, onikaluku wọn gba Ọlọhun gbọ ati awọn malaika Rẹ ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, a kò ni i se iyatọ laarin ọkan ninu awọn ojisẹ Rẹ » [Suuratul-Baqarah: 285]. Ọlọhun ti ẹyin Rẹ ga, tun sọ pe:

} إن الذين يكفرون بالله ورسله ويريدون أن يفرقوا بين الله ورسله ويقولون نؤمن ببعض ونكفر ببعض ويريدون أن يتخذوا بين ذلك سبيلاً. أولئك هم الكافرون حقا وأعتدنا للكافرين عذابا مهيناً { [سورة النساء: 150، 151].

« Dajudaju awọn ti wọn n se aigbagbọ si Ọlọhun ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si n fẹ lati se ipinya laarin Ọlọhun ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si n sọ pe: Awa gba apa kan gbọ [ninu awọn ojisẹ] a si se aigbagbọ si omiran; ti wọn si n fẹ lati mu oju-ọna kan laarin eleyii. Awọn wọnyi ni alaigbagbọ ni ododo, a si ti pese iya ẹlẹtẹ fun awọn alaigbagbọ » [Suuratun-Nisaa'i: 150, 151].

Ẹlẹẹkarun-un: Nini igbagbọ-ododo si ọjọ ikẹyin:

Idi ni pe iku ni ipari gbogbo ẹda ni ile-aye! Njẹ ki ni apadasi eniyan lẹyin iku? Ki si ni atunbọtan awọn alabosi ti wọn bọ lọwọ iya ni ile-aye, njẹ wọn o wa bọ nibi iya abosi wọn bi? Ati awọn oluse-daadaa ti ipin wọn fo wọn ru, ati ẹsan daadaa wọn ni ile-aye, njẹ ẹsan wọn yoo wa sọnu bi?

Dajudaju awọn ọmọ eniyan n tẹlera wọn lọ si ọdọ iku, iran kan lẹyin omiran, titi ti o fi di pe Ọlọhun pasẹ pe ki ile-aye o tan, ti gbogbo ẹda o si parẹ lori ilẹ, Ọlọhun O gbe gbogbo ẹda dide ni ọjọ ẹri, Ọlọhun O ko awọn ẹni-akọkọ ati ẹni-ikẹyin jọ ninu rẹ, lẹyin naa ni yoo wa se isiro fun awọn ẹru lori awọn isẹ wọn, rere tabi aburu ti wọn se nisẹ ni ile-aye; tori naa a o da awọn olugbagbọ-ododo lọ si ọgba-idẹra -Al-janna- a o si da awọn alaigbagbọ lọ si ina.

Ọgba-idẹra -Al-janna- si ni: Idẹra ti Ọlọhun pa lese kalẹ fun awọn ẹni-Rẹ, olugbagbọ-ododo, onirunruu idẹra l'o wa ninu rẹ, eyi ti ẹnikan kò le e royin rẹ, awọn ipo ọgọrun ni n bẹ ninu rẹ, gbogbo ipo kọọkan si ni ẹni ti n gbe ibẹ, ni odiwọn igbagbọ wọn si Ọlọhun, ati titẹle ti wọn tẹle asẹ Rẹ, ati pe ẹni ti o kere ju ni ipo ninu awọn ọmọ Al-janna ni ẹni ti a o fun ni idẹra ti o dabi iru ọla ọba kan ninu awọn ọba ile-aye ati ilọpo mẹwa rẹ.

Ina si ni iya ti Ọlọhun pese kalẹ fun ẹni ti o ba se aigbagbọ si I, orisirisi iya ti sisọ nipa rẹ ba'ni lẹru l'o wa ninu rẹ, iba si se pe Ọlọhun yọnda fun ẹnikan lati ku ni ọrun ni, dajudaju gbogbo awọn ọmọ ina ni o ba ku ni kete ti wọn ba ti ri i.

Ọlọhun si ti mọ daju -pẹlu imọ Rẹ ti o siwaju- ohun ti ẹnikọọkan yoo wi, ati ohun ti yoo se, ninu rere tabi aburu, yala ni ikọkọ ni o tabi ni gbangbá, lẹyin naa o fi malaika meji sọ ẹnikọọkan, ọkan ninu wọn o maa kọ awọn rere, nigba ti ekeji o maa kọ awọn aburu, nnkan kan kò si ni i bọ mọ wọn lọwọ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ما يلفظ من قول إلا لديه رقيب عتيد { [سورة ق: 18].

« Kò ni i sọ ọrọ kan afi ki olusọ kan o ti jokoo ni ọdọ rẹ » [Suuratu Qaaf: 17-18]. A o si kọ awọn isẹ wọnyi silẹ sinu tira kan ti a o fun eniyan ni ọjọ igbende, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ووضع الكتاب فترى المجرمين مشفقين مما فيه ويقولون يا ويلتنا ما لهذا الكتاب لا يغادر صغيرة ولا كبيرة إلا أحصاها ووجدوا ما عملوا حاضراً ولا يظلم ربك

أحدا ً{ [سورة الكهف: 49].

« Ati pe a o gbe tira naa kalẹ, iwọ o si ri awọn ẹlẹsẹ ti ohun ti o wa ninu rẹ yoo maa ba wọn lẹru, wọn o si maa sọ pe: Egbe wa o, iru iwe wo niyi, ti kò fi ohun kekere kan tabi ninla kan silẹ afi ki o siro gbogbo rẹ pọ? Wọn o si ri ohun ti wọn se nibẹ perepere, Oluwa rẹ ki I si I se abosi fun ẹnikan » [Suuratul-Kahf: 49]. Yoo si ka iwe rẹ, kò ni i tako nnkan kan ninu rẹ, ati pe ẹnikẹni ti o ba tako nnkan kan ninu awọn isẹ rẹ, Ọlọhun O fun igbọrọ rẹ, ati iriran rẹ, ati ọwọ rẹ mejeeji, ati ẹsẹ rẹ mejeeji, ati awọ rẹ, ni ọrọ sọ pẹlu gbogbo isẹ rẹ; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وقالوا لجلودهم لم شهدتم علينا قالوا أنطقنا الله الذي أنطق كل شيء وهو خلقكم أول مرة وإليه ترجعون. وما كنتم تستترون أن يشهد عليكم سمعكم ولا أبصاركم ولا جلودكم ولكن ظننتم أن الله لا يعلم كثيراً مما تعملون { [سورة فصلت: 21-22].

« Wọn yoo sọ fun awọn awọ wọn pe: Ki l'o se ti ẹ fi jẹri le wa lori? Wọn yoo sọ pe: Ọlọhun ti O fun gbogbo nnkan ni ọrọ sọ l'O fun wa lọrọ sọ, ati pe Oun l'O da yin ni akọkọ, bẹẹ ni ọdọ Rẹ ni a o da yin pada si. Ẹ kò si fi ara yin pamọ, ki awọn igbọrọ yin ati awọn iriran yin ati awọn awọ yin o ma baa jẹri le yin lori, sugbọn ẹ lero pe Ọlọhun kò mọ pupọ ninu isẹ ti ẹ n se » [Suuratu Fusilat: 21-22].

Ati pe gbogbo awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ni wọn mu nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin -ti i se ọjọ igbende, ọjọ ajinde, ati ọjọ fifọnka- wa; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ومن آياته أنك ترى الأرض خاشعة فإذا أنزلنا عليها الماء اهتزت وربت إن الذي أحياها لمحيي الموتى إنه على كل شيء قدير { [سورة فصلت: 39].

« O si n bẹ ninu awọn ami Rẹ pe dajudaju iwọ yoo ri ilẹ ti o gbẹ haran-un, nigba ti A ba si sọ omi kalẹ le e lori a mira, yoo si ru. Dajudaju Ẹni ti O ji i ni Ẹni ti O daju pe yoo ji awọn oku dide. Dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan » [Suuratu Fusilat: 39]. Ọlọhun t'O mọ, t'O si ga, sọ pe:

} أو لم يروا أن الله الذي خلق السموات والأرض ولم يعي بخلقهن بقادر على أن يحيي الموتى { [سورة الأحقاف: 33].

« Njẹ wọn kò wa mọ ni pe dajudaju Ọlọhun, Ẹni ti O da awọn sanma ati ilẹ, ti kò si ko aarẹ nipa dida wọn, ni Alagbara lori pe ki O ji awọn oku bi? » [Suuratul-Ahqaaf: 33], oun ni ohun ti Hikimah -ọgbọn- Ọlọhun se ni ọranyan; tori pe dajudaju Ọlọhun kò da awọn ẹda Rẹ lasan, kò si fi wọn silẹ lasan, tori pe ẹni ti o lẹ ju ni laakaye ninu awọn eniyan kò see se ki o se isẹ kan -ti o pataki- lai jẹ pe idi kan ti o ni mimọ nipa rẹ wa fun un, ati lai kò si ero kan lati ọdọ rẹ, njẹ ti eleyii kò ba jẹ ohun ti o tọ si eniyan, bawo ni eniyan ti wa n daba si Oluwa pe O da awọn ẹda Rẹ nitori asan, ati pe yoo fi wọn silẹ lasan, Ọlọhun ga ju ohun ti wọn n sọ lọ, ni giga ti o tobi; Ọlọhun -giga ni fun Un- tun sọ pe:

} أفحسبتم أنما خلقناكم عبثا وأنكم إلينا لا ترجعون { [سورة المؤمنون: 115].

« Njẹ ẹ wa ro pe asan ni A da yin fun ni, ati pe ẹyin kò ni i pada si ọdọ Wa bi? » [Suuratul-Mu'uminuun: 115]. Ọlọhun ti ọrọ Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

} وما خلقنا السماء والأرض وما بينهما باطلاً ذلك ظن الذين كفروا فويل للذين كفروا من النار { [سورة ص: 27].

« Ati pe Awa kò da sanma ati ilẹ ati ohun ti o wa ni agbedemeji wọn lasan. Ero awọn ti kò gbagbọ niyun un, nitori naa egbe ni fun awọn ti kò gbagbọ ninu ina » [Suuratu Saad: 27].

Ati pe gbogbo awọn onilaakaye l'o jẹri si gbigba a gbọ, bẹẹ ni ohun ni ohun ti laakaye tọka si, ti adamọ ti o tọ si gba fun, tori pe dajudaju ti eniyan ba gba ọjọ igbende gbọ; yoo mọ ki l'o fa ti eniyan fi n fi ohun ti n fi silẹ silẹ, ti i si n fi n se ohun ti n se ni irankan ohun ti n bẹ lọdọ Ọlọhun, lẹyin naa yoo mọ bakan naa pe ẹnikẹni ti n se abosi fun awọn eniyan dandan ni ki o gba ipin rẹ, ki awọn eniyan o si gbẹsan lọdọ rẹ ni ọjọ igbende, ati pe dajudaju dandan ni ki eniyan o gba ẹsan rẹ, ti o ba jẹ rere yoo ri rere, ti o ba si jẹ aburu yoo ri aburu, nitori ki a le baa san gbogbo ẹmi lẹsan pẹlu ohun ti o se, ki sise deedee Ọlọhun o si le baa sẹ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} فمن يعمل مثقال ذرة خيراً يره. ومن يعمل مثقال ذرة شراً يره { [سورة الزلزلة: 7-8].

« Nitori naa ẹnikẹni ti o ba se isẹ rere bi ọmọ-inaagun, yoo ri i. Ati pe ẹnikẹni ti o ba se isẹ buburu bi ọmọ-inaagun, yoo ri i » [Suuratul Zalzalah: 7-8].

Ati pe ẹnikan ninu awọn ẹda kò mọ igba wo ni ọjọ igbende yoo de, tori naa ọjọ kan ni eleyii ti o se pe anabi kan ti a ran nisẹ kò mọ ọn, tabi malaika kan ti o sunmọ Ọlọhun, sugbọn nse ni Ọlọhun da ara Rẹ yanri pẹlu imọ rẹ; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} يسألونك عن الساعة أيان مرساها قل إنما علمها عند ربي لا يجليها لوقتها إلا هو{ [سورة الأعراف: 187].

« Wọn o maa bi ọ leere nipa akoko igbende, nigba wo ni idide rẹ? Wi fun wọn pe: Ọdọ Oluwa mi nikan ni imọ rẹ wa, ẹnikankan kò le e se afihan asiko naa afi Oun » [Suuratul-A'araaf: 187]. Ọlọhun t'O mọ tun sọ pe:

} إن الله عنده علم الساعة { [سورة لقمان: 34].

« Dajudaju Ọlọhun ni imọ akoko igbende lọdọ » [Suuratu Luqmaan: 34].

Ẹlẹẹkẹfa: Nini igbagbọ-ododo si ohun ti Ọlọhun da lẹjọ ati akọsilẹ -Kadara-:

Ki o gbagbọ pe dajudaju Ọlọhun mọ ohun ti o ti sẹlẹ, ati ohun ti yoo sẹlẹ, O si mọ isesi awọn eniyan ati awọn isẹ wọn, ati iye igba ti wọn o lo, ati awọn ọrọ -arziki- wọn; Ọlọhun sọ pe:

} إن الله بكل شيء عليم { [سورة العنكبوت: 62].

« Dajudaju Olumọ ni Ọlọhun nipa gbogbo nnkan » [Suuratul-Ankabuut: 62]. Ọlọhun, ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, tun sọ pe:

}وعنده مفاتح الغيب لا يعلمها إلا هو ويعلم ما في البر والبحر وما تسقط من ورقة إلا يعلمها ولا حبة في ظلمات الأرض ولا رطب ولا يابس إلا في كتاب مبين { [سورة الأنعام: 59].

« Ọdọ Rẹ ni awọn kọkọrọ ohun ti o pamọ wa, ẹnikan kò le e mọ ọn yatọ si I, O si tun mọ ohun ti n bẹ ninu ilẹ ati okun, ati pe kò si ewe kan ti yoo jabọ afi ki O mọ nipa rẹ, bẹẹ ni kò si horo ọka kan ninu okunkun ilẹ, kò tilẹ si ohun tutu kan tabi ohun gbigbẹ kan afi ki o ti wa ninu tira ti o han » [Suuratul-An'aam: 59]. O si kọ gbogbo nnkan sinu tira kan ni ọdọ Rẹ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وكل شيء أحصيناه في إمام مبين { [سورة يس: 12].

« Ati pe Awa ti se isiro gbogbo nnkan sinu tira kan ti o han » [Suuratu-Yaasin: 12]. Ọlọhun t'O mọ sọ pe:

} ألم تعلم أن الله يعلم ما في السماء والأرض إن ذلك في كتاب إن ذلك على الله يسير { [سورة الحج: 70].

« Njẹ iwọ kò wa mọ pe dajudaju Ọlọhun mọ ohun ti o wa ninu sanma ati ilẹ bi?, dajudaju eyi n bẹ ninu tira kan, dajudaju eyi jẹ irọrun fun Ọlọhun » [Suuratul-Hajj: 70]. Nitori naa ti Ọlọhun ba fẹ nnkan kan yoo sọ fun un pe: Ki o jẹ bẹẹ, yoo si jẹ bẹẹ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إنما أمره إذا أراد شيئاً أن يقول له كن فيكون { [سورة يس: 82].

« Ohun ti o jẹ isesi Rẹ nigba ti O ba gbero nnkan kan ni ki O sọ fun un pe: Jẹ bẹẹ, ni yoo ba si jẹ bẹẹ » [Suuratu-Yaasin: 82]; ati pe dajudaju bi o ti se jẹ pe Ọlọhun t'O mọ ti pebubu gbogbo nnkan, Oun Naa ni Ẹlẹda gbogbo nnkan, Ọlọhun ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn sọ pe:

} إنا كل شيء خلقناه بقدر { [سورة القمر: 49].

« Dajudaju Awa da gbogbo nnkan pẹlu akọsilẹ » [Suuratul-Qamar: 49]. Ọlọhun ti O ga ni Olusọrọ, sọ pe:

} الله خالق كل شيء { [سورة الزمر: 62].

« Ọlọhun ni Ẹlẹda gbogbo nnkan » [Suuratuz- Zumar: 62]. Nitori naa O da awọn ẹda Rẹ nitori titẹle ilana Rẹ, O si se alaye rẹ fun wọn, O si pa wọn lasẹ pẹlu rẹ, O si kọ sisẹ Ẹ, O si se alaye rẹ fun wọn, ati pe O fun wọn ni agbara ati erongba eyi ti yoo mu wọn le se awọn asẹ Ọlọhun, ki wọn o le gba láádá, ati jijinna si ohun ti o jẹ sisẹ Ẹ, ki wọn o ma baa di ẹni ti o lẹtọ si iya Rẹ.

Nigba ti eniyan ba ti ni igbagbọ-ododo si idajọ Ọlọhun ati akọsilẹ Rẹ, ohun ti n bọ yii yoo sẹ fun un:

1- Gbigbẹkẹle Ọlọhun nigba ti o ba ti se awọn okunfa; tori pe o mọ daju pe okunfa ati ohun ti i maa n ti ara rẹ jade, gbogbo mejeeji a maa waye pẹlu idajọ Ọlọhun ati akọsilẹ Rẹ.

2- Isinmi ẹmi ati ibalẹ ọkan; tori pe nigba ti o ba ti mọ daju pe pẹlu idajọ Ọlọhun ati akọsilẹ Rẹ ni eleyii wa, ati pe ohun ti yoo sẹlẹ ni ipọnju ti a ti kọ akọsilẹ rẹ, kò si ibuyẹsi kan fun un, ẹmi rẹ yoo sinmi, yoo si yọnu si idajọ Ọlọhun, tori naa kò si ẹnikan ti isẹmi rẹ dun, ti ẹmi rẹ si ni isinmi, ti ifayabalẹ rẹ si lagbara ju ẹni ti o gba akọsilẹ gbọ ni ododo lọ.

3- Lile ijọra-ẹni-loju jinna nigba ti a ba ri ohun ti a n fẹ, tori pe idẹra kan lati ọdọ Ọlọhun ni riri eleyii jẹ, latari ohun ti O kọ akọsilẹ rẹ ninu awọn okunfa rere ati oriire; nitori naa yoo dupẹ fun Ọlọhun lori eleyii.

4- Lile ijaya, ati ibarajẹ jinna nigba ti ohun ti a n fẹ ba bọ mọ'ni lọwọ, tabi ti nnkan ipọnju ba sẹlẹ, tori pe pẹlu idajọ Ọlọhun, eyi ti kò si ẹni ti o le e da ọrọ Rẹ pada l'o fi sẹlẹ, ti kò si si ẹnikan ti o le se atunyẹwo fun idajọ Rẹ, ati pe ohun ti yoo sẹlẹ ni i, kò si ibuyẹsi kan fun un, nitori naa yoo se suuru, yoo si maa reti ẹsan rẹ ni ọdọ Ọlọhun t'O ga:

} ما أصاب من مصيبة في الأرض ولا في أنفسكم إلا في كتاب من قبل أن نبرأها إن ذلك على الله يسير. لكيلا تأسوا على ما فاتكم ولا تفرحوا بما آتاكم والله لا يحب كل مختال فخور { [سورة الحديد: 22، 23].

« Adanwo kan kò ni i sẹlẹ ni ori ilẹ tabi ninu ara yin, afi ki o maa bẹ ninu tira kan siwaju ki A too da a, dajudaju eyi jẹ irọrun fun Ọlọhun. Nitori ki ẹ le baa ma banujẹ lori ohun ti o ti bọ fun yin, ati ki ẹ ma si se maa yọ ayọju nitori ohun ti O fun yin, ati pe Ọlọhun kò nifẹ si gbogbo onigberaga, oniyanran » [Suuratul-Hadiid: 22, 23].

5- Gbigbẹkẹle Ọlọhun t'O mọ ni agbẹkẹle ti o pe, tori pe Musulumi mọ daju pe ọwọ Ọlọhun t'O mọ -nikan- ni anfaani ati inira wa, nitori naa kò ni i bẹru alagbara kan nitori agbara rẹ, ati pe kò ni i lọra lati se isẹ rere nitori ibẹru ẹnikan ninu awọn ọmọ eniyan, Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" sọ pe:

(( واعلم أن الأمة لو اجتمعوا على أن ينفعوك لم ينفعوك إلا بشيء قد كتبه الله لك، ولو اجتمعوا على أن يضروك لم يضروك إلا بشيء قد كتبه الله عليك )). [رواه أحمد، والترمذي].

« Mọ daju pe ti gbogbo awọn ijọ patapata ba pejọpọ lati fi nnkan kan se ọ ni anfaani, wọn kò ni i le se ọ ni anfaani pẹlu nnkan kan yatọ si eyi ti Ọlọhun ti kọ akọsilẹ rẹ lẹ fun ọ, ati pe ti wọn ba pejọpọ lati fi nnkan kan ni ọ lara, wọn ki yoo le ni ọ lara pẹlu nnkan mìíran yatọ si eyi ti Ọlọhun ti kọ akọsilẹ rẹ le ọ lori » [Ahmad ati Tirmidzi ni wọn gbe e jade].

###

IPELE KẸTA: DAADAA SISE

Origun kan ni oun ni: Ki o maa sin Ọlọhun bi ẹni pe o n ri I, ti iwọ kò ba si ri I, dajudaju Oun N ri ọ. Nitori naa eniyan o maa sin Oluwa rẹ lori iroyin yii, oun ni gbigbe sisunmọ Rẹ wa si ọkan, ati pe O wa ni iwaju rẹ, eleyii o si bi ibẹru, ati ipaya, ati fifi ọla fun Un, ati gbigbe E tobi, yoo si bi afọmọ ninu sise ijọsin naa, ati gbigbiyanju nipa atitun un se, ati pipe e.

Nitori naa ẹru yoo maa se akiyesi Oluwa rẹ ninu sise ẹsin naa, yoo si mu sisunmọ Rẹ wa sinu ọkan rẹ, bi ẹni pe o n ri I, ti eleyii ba si soro fun un, ki o wa iranlọwọ lati mu un sẹ pẹlu igbagbọ-ododo rẹ pe Ọlọhun N ri oun, O si N wo ikọkọ ati gbangbá oun, inu ati ode oun, ati pe nnkan kan kò pamọ si I ninu ọrọ oun.

Tori naa ẹru ti o ba de ipo yii, yoo maa jọsin fun Oluwa rẹ l'ẹni ti n se afọmọ, kò ni i yiju si ẹnikan yatọ si I, tori naa kò ni i reti ẹyin awọn eniyan, bẹẹ ni kò ni i bẹru eebu wọn, nitori pe o to o pe ki Oluwa rẹ O yọnu si i, ki Oluwa rẹ O si dupẹ fun un.

Eniyan kan ni ti gbangbá rẹ dọgba pẹlu ikọkọ rẹ, olusin Oluwa rẹ si ni i ni kọlọfin ati ni ojutaye, alamọdaju -ni amọdaju ti o pe- ni i pe Ọlọhun N wo ohun ti ọkan oun n bo, ati ohun ti n se iroyiroyi ni ẹmi rẹ, igbagbọ-ododo gba ọkan rẹ, o si bẹrẹ si ni i gburo akiyesi Oluwa rẹ lori rẹ, tori naa awọn orike rẹ gbafa fun Olupilẹsẹda wọn, ki i si i fi wọn se -nnkan kan- ninu isẹ afi ohun ti Ọlọhun nifẹ si, ti O si yọnu si, olugbafa fun Oluwa rẹ.

Ati pe nigba ti ọkan rẹ ti rọ mọ Oluwa rẹ, kò ni i wa iranlọwọ ẹda kan, nitori rirọrọ rẹ pẹlu Ọlọhun, kò si ni i ke lọ ba eniyan, tori pe o ti gbe bukaata rẹ fun Ọlọhun, Ọba t'O mọ, Ọlọhun si to ni Oluranlọwọ, ati pe ki i wo pe oun nikan l'oun wa ni aaye kan, ki i si bẹru ẹnikan; nitori pe o mọ daju pe Ọlọhun wa pẹlu oun ninu gbogbo isesi oun, ati pe Oun to o, O si dara ju ni Alaranse, bẹẹ ni ki i fi asẹ kan ti Ọlọhun fi pa a lasẹ silẹ, ki i si i sẹ Ọlọhun ni ẹsẹ kan, tori pe o n tiju Ọlọhun, o si n korira ki O fẹ oun ku nibi ti O pa a lasẹ, tabi ki O ri oun nibi ti O kọ fun un, ki i ditẹ, tabi ki o se abosi fun ẹda kan, tabi ki o gba ẹtọ rẹ, tori pe o mọ daju pe Ọlọhun N wo oun, ati pe Ọba t'O mọ Naa yoo se isiro fun oun lori awọn isẹ oun.

Ki i si i se ibajẹ lori ilẹ, tori pe o mọ daju pe gbogbo ohun ti o wa ninu rẹ ni oore nnkan-ini Ọlọhun t'O ga ni wọn, O tẹ ori wọn ba fun awọn ẹda Rẹ, tori naa oun yoo maa mu ninu wọn ni odiwọn bukaata rẹ, yoo si maa dupẹ fun Oluwa rẹ nipa sise wọn ni irọrun fun un.

###

Dajudaju ohun ti mo sọ fun ọ, ti mo si se afihan rẹ niwaju rẹ ninu iwe kekere yii, kò jẹ nnkan kan yatọ si awọn ohun ti o pataki, ati awọn origun nla ninu Islam, ati pe awọn origun wọnyi ni awọn ti o se pe ti eniyan ba gba wọn gbọ, ti o si fi wọn sisẹ, yoo di Musulumi, sugbọn yatọ si eyi, dajudaju Islam -gẹgẹ bi mo ti wi fun ọ- ẹsin ati iselu ni i, ijọsin ati eto igbesi-aye ni i, dajudaju eto kan ti o jẹ ti Ọlọhun ti o kari ti o pe, ti o se akojọpọ gbogbo ohun ti onikaluku ati awujọ n bukaata ni ori ala ti o dọgba ninu gbogbo ojupọna isẹmi ti o jẹ ti adisọkan, ati ti iselu, ati ti eto ọrọ-aje, ati ti ajọgbepọ lawujọ, ati ti aabo ni i.. ati pe eniyan yoo ri awọn ofin, ati awọn ipilẹ, ati awọn idajọ kan ninu rẹ ti n to eto ifayabalẹ ati ogun, ati awọn ẹtọ ti o jẹ ọranyan, ti n si n sọ apọnle eniyan, ẹyẹ, ẹranko, ati ayika, ti yoo si maa se alaye paapaa eniyan, isẹmi, iku, ati igbende lẹyin iku fun un, ati pe yoo ri ninu rẹ -bakan naa- ilana ti o dara ju lati ba awọn eniyan lo ni ayika rẹ, gẹgẹ bi ọrọ Ọlọhun t'O ga:

} وقولوا للناس حسنا { [سورة البقرة: 83].

« Ẹ si maa sọ ọrọ t'o dara fun awọn eniyan » [Suuratul-Baqarah: 83]. Ati ọrọ Ọlọhun t'O ga:

} والعافين عن الناس { [سورة آل عمران: 134].

« Ati awọn oluse-amojukuro fun awọn eniyan » [Suuratu Aala Imraan: 134]. Ati ọrọ Ọlọhun t'O ga:

} ولا يجرمنكم شنئان قوم على ألا تعدلوا اعدلوا هو أقرب للتقوى { [سورة المائدة: 8].

« Ẹ ma si se jẹ ki ibinu awọn ijọ kan o mu yin ma se deedee, ẹ se deedee, oun l'o sunmọ ibẹru Ọlọhun ju » [Suuratul-Maa'idah: 8].

Ati pe o dara lẹyin ti a ti se afihan awọn ipele ẹsin yii, ati awọn origun gbogbo ipele kọọkan ninu awọn ipele rẹ, pe ki a se alaye soki nipa awọn ẹwà rẹ.

###

NINU AWỌN ẸWÀ ISLAM

Gege o kagara nibi atirọkirika awọn ẹwà Islam, bẹẹ ni ọrọ o kọlẹ nibi pipe sisọ nipa awọn ajulọ ẹsin yii; eyi kò si jẹ bẹẹ afi nitori pe dajudaju ẹsin yii ni ẹsin Ọlọhun -mimọ ati giga ni fun Un- tori naa gẹgẹ bi iriran kò ti se le rọkirika Ọlọhun ni òye, ti awọn ọmọ eniyan kò si le e rọkirika Rẹ ni mimọ, bẹẹ naa ni ofin Rẹ -mimọ ni fun Un- ikọwe kò le e rokirika rẹ ni iroyin. Ati pe Ibn Al-Qayyim -ki Ọlọhun O kẹ ẹ- sọ pe: « Ti o ba si se akiyesi ọgbọn iyalẹnu ninu ẹsin ti o duro sinisin yii, ati ilana ti o tọ yii, ati ofin ẹsin Anabi Muhammad, eyi ti ọrọ kò le e ka pipe rẹ, ti iroyin kò si le e ba ẹwa rẹ, ti laakaye awọn onilaakaye -koda bi wọn pejọ, ti wọn si wa lori iru laakaye ẹni ti o pe -ni laakayi- julọ ninu wọn- wọn kò le da imọran ohun ti o ju u lọ, ati pe o to awọn laakaye ti wọn pe, ti wọn ni ajulọ, pe wọn mọ ẹwa rẹ, wọn si jẹri nipa ajulọ rẹ, ofin kan kò si wa si aye yii ti o pe ju, ti o si gbọn-un-gbọn ju, ti o si tobi ju u lọ; bẹẹ ni ti Ojisẹ Ọlọhun kò ba tilẹ mu awijare kan wa lori rẹ oun gan-an ko ba to ni awijare, ati ami, ati ẹlẹri, lori pe lati ọdọ Ọlọhun l'o ti wa; gbogbo wọn n jẹri si pipe imọ, ati pipe ọgbọn, ati fifẹ ikẹ, ati rere, ati daadaa sise, ati rirọkirika ohun ti o pamọ ati ohun ti o han, ati imọ nipa awọn ipilẹsẹ ati awọn atunbọtan, ati pe wọn n bẹ ninu eyi ti o tobi ju ninu awọn idẹra Ọlọhun, eyi ti O se ni idẹra fun awọn ẹru Rẹ, tori naa kò se idẹra kan fun wọn ti o gbọn-un-gbọn ju pe O fi wọn mọna lọ si idi wọn lọ, O si se wọn ni ẹni wọn, ati ninu awọn ti O yọnu wọn si fun, ati pe eleyii l'o fa ti O fi se iregun le awọn ẹru Rẹ lori nipa pe O fi wọn mọna lọ si idi wọn; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} لقد من الله على المؤمنين إذ بعث فيهم رسولاً من أنفسهم يتلو عليهم آياته ويزكيهم ويعلمهم الكتاب والحكمة وإن كانوا من قبل لفي ضلال مبين { [سورة آل عمران: 164].

« Lotitọ Ọlọhun ti se idẹra fun awọn olugbagbọ-ododo nigba ti O gbe ojisẹ kan dide ninu wọn lati inu ara wọn, ti o n ke awọn aayah Rẹ fun wọn, ti o si n fọ wọn mọ, ti o si n kọ wọn ni Tira naa, ati ọgbọn, bi o tilẹ jẹ pe dajudaju ninu anu ti o han ni wọn wa tẹlẹ » [Suuratu Aala Imraan: 164]. O tun sọ l'Ẹni ti N se afihan fun awọn ẹru Rẹ, ti I si N ran wọn leti titobi idẹra Rẹ lori wọn, ti I si N tọrọ ọpẹ rẹ lọdọ wọn, nipa sise ti O se wọn ni ọkan ninu ẹni idẹra naa:

} اليوم أكملت لكم دينكم { [سورة المائدة: 3].

« Loni yii Mo se ẹsin yin ni pipe fun yin » [Suuratul-Maa'idah: 3].

Ninu idupẹ fun Ọlọhun ti o jẹ ọranyan lori wa nipa ẹsin yii ni ki a sọ apa kan ninu awọn ẹwa rẹ, nitori naa ki a sọ pe:

1- Ẹsin Ọlọhun ni i:

Wi pe ẹsin ti Ọlọhun yọnu si funra rẹ, ti O si fi ran awọn ojisẹ Rẹ, ti O si yọnda fun awọn ẹda Rẹ pe ki wọn o maa gba ara rẹ jọsin fun Oun ni i, nitori naa gẹgẹ bi Ẹlẹda kò ti se jọ ẹda ni ẹsin Rẹ -ti i se Islam- kò ti se jọ awọn ofin awọn ẹda, ati awọn ẹsin wọn, ati pe gẹgẹ bi Ọba t'O mọ Naa ti se jẹ Ẹni ti a n royin pẹlu gbogbo pipe, bẹẹ naa ni gbogbo pipe ti se jẹ ti ẹsin Rẹ, nipa pipe awọn ofin ti yoo tun igbesi-aye awọn eniyan se, ati ibupadasi wọn, ati rirọkirika awọn iwọ Ẹlẹda -mimọ ni fun Un- ati awọn ọranyan awọn ẹda lori Rẹ, ati ẹtọ apa kan wọn lori omiran, ati awọn ọranyan apa kan wọn lori omiran.

2- Wi Pe o kari:

Ninu ohun ti o han ju ninu awọn ẹwa ẹsin yii ni kikari ti o kari gbogbo nnkan, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ما فرطنا في الكتاب من شيء { [سورة الأنعام: 38].

« Awa kò sẹ nnkan kan ku ninu Tira [lai sọ] » [Suuratul-An'aam: 38]. Nitori naa ẹsin yii kari gbogbo ohun ti o jẹmọ Ẹlẹda, ninu awọn orukọ Ọlọhun, ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn iwọ Rẹ, ati gbogbo ohun ti o jẹmọ awọn ẹda ninu awọn ofin, ati awọn ipanilasẹ, ati awọn iwa, ati ibasepọ, ati pe ẹsin yii rọkirika iroyin awọn ẹni-akọkọ ati awọn ẹni-igbẹyin, ati awọn malaika, ati awọn anabi, ati awọn ojisẹ, o si tun sọ nipa sanma ati ilẹ, ati awọn awowo, ati awọn irawọ, ati awọn okun, ati awọn igi, ati aye, o si sọ idi dida ẹda, ati ohun ti a gba lero pẹlu rẹ ati opin rẹ, o si sọrọ ọgba-idẹra -Al-janna- ati ibupadasi awọn olugbagbọ-ododo, o si tun sọrọ ina, ati ipari awọn alaigbagbọ.

3- Wi pe a maa so Ẹlẹda pọ pẹlu awọn ẹda:

Gbogbo ẹsin irọ, ati gbogbo ilana, l'o jẹ adayanri pẹlu pe o maa n mu eniyan pade pẹlu eniyan ẹgbẹ rẹ, ti yoo ku, ti ọlẹ, ati agara, ati aarẹ si i maa n se, koda o see se pe ki o so o pọ pẹlu eniyan kan ti o ti ku lati ọgọrun ainiye ọdun, ti o si ti di egungun ati erupẹ … sugbọn ẹsin Islam yii jẹ adayanri pẹlu pe oun a maa so eniyan pọ pẹlu Ẹlẹda rẹ taarata, lai kò si alufa-ijọ kan -pastor- tabi ẹni-mimọ kan, tabi imulẹ kan [laarin wọn], oun kò jẹ nnkan kan yatọ si pipade taarata laarin Ẹlẹda ati ẹda, ipade kan ti yoo so ọpọlọ pọ pẹlu Oluwa rẹ ni i, ti yoo si maa wa imọlẹ, ti yoo si maa wa imọna, ti yoo si maa ga, ti yoo si maa roke, ti yoo si maa wa pipe, ti yoo si maa jinna si awọn rẹdẹrẹdẹ ati awọn ohun yẹpẹrẹ, tori pe gbogbo ọkan ti kò ba ti i sopọ pẹlu Ẹlẹda rẹ, ọkan ti o sina ju awọn ẹranko lọ ni i.

Ati pe oun ni pipade kan laarin Ẹlẹda ati ẹda, ti yoo maa ti ara rẹ mọ erongba Ọlọhun nipa rẹ, n ni yoo ba maa jọsin fun Un pẹlu amọdaju, yoo si maa mọ awọn aaye iyọnu Rẹ, tori naa yoo maa wa a, ati awọn aaye ibunu Rẹ, tori naa yoo maa jinna si i.

Oun si ni pipade kan laarin Ẹlẹda Giga ati ẹda ọlẹ alaini, tori naa yoo maa wa aranse ati iranlọwọ ati kongẹ lọdọ Rẹ, yoo si maa tọrọ lọdọ Rẹ pe ki O sọ oun nibi ete awọn adete, ati ibajẹ awọn esu.

4- Sise akiyesi awọn anfaani ile-aye ati ti ọrun:

A mọ ofin Islam lori sise akiyesi awọn anfaani aye ati ti ọrun, ati pipe awọn iwa alapọnle.

Sugbọn alaye awọn anfaani ọrun: Dajudaju ofin yii ti se alaye awọn ojupọna wọn, ati pe kò gbagbe nnkan kan ninu wọn, kaka bẹẹ nse l'o se alaye wọn, ti o si se afihan wọn, ki a ma baa se aimọ nipa nnkan kan ninu wọn, tori naa o se adehun pẹlu idẹra wọn, o si se ileri-iya pẹlu iya wọn.

Sugbọn alaye awọn anfaani ti ile-aye: Dajudaju Ọlọhun ti se ohun ti yoo maa sọ ẹsin eniyan, ẹmi rẹ, nnkan-ini rẹ, ẹbi rẹ, iyi rẹ, ati laakaye rẹ ni ofin fun un.

Sugbọn alaye awọn iwa alapọnle: Dajudaju o pa a lasẹ pẹlu rẹ ni gbangbá ati ni ikọkọ, ati pe o kọ awọn iwakiwa, ati awọn iwa palapala, nitori naa ninu awọn iwa alapọnle ti o han ni: imọtoto, ati imọra, ati ifọramọ kuro ninu awọn ẹgbin ati idọti, o si se'ni ni ojukokoro lati lo lọfinda, ati titun awọ se, o si se awọn idọti gẹgẹ bi agbere “zina", ọti mimu, okunbete jijẹ, ati ẹjẹ, ati ẹran ẹlẹdẹ ni eewọ; o si pasẹ pẹlu awọn ohun ti o dara, o si kọ itayọ-ala, ati inakuna.

Imọtoto ti inu n pada sidi pipa awọn iwa buburu ti, ati sise ọsọ pẹlu [iwa] ti ẹyin [ninu] wọn, ati awọn ti o dara ninu wọn, tori naa apejuwe awọn iwa buburu ni: Irọ, iwa ẹsẹ, ibinu, ilara, ahun, yiyẹpẹrẹ ara ẹni, ati ninifẹ si iyi, ati ifẹ ile-aye, ati igberaga, ijọra-ẹni-loju, ati karimi; ati pe ninu awọn iwa ẹyin ni: Iwa rere, ibasepọ daadaa pẹlu awọn eniyan, ati sise daadaa si wọn, ati sise dọgba, ati itẹriba, otitọ, ati ẹmi ọrẹ, ati lilawọ, ati gbigbẹleke Ọlọhun, ati sise afọmọ, ati ibẹru Ọlọhun, ati suuru, ati idupẹ.

5- Irọrun:

Ọkan ninu awọn iroyin ti ẹsin yii fi yatọ ni pe irọrun wa ninu gbogbo ọna ijọsin kan ninu awọn ọna ijọsin rẹ, ati pe irọrun ni gbogbo ijọsin kan ninu awọn ijọsin rẹ, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وما جعل عليكم في الدين من حرج { [سورة الحج: 78].

« Ati pe kò di isoro kan le yin lori ninu ẹsin » [Suuratu -l-Hajj: 78]; ati pe akọkọ irọrun yii ni pe: Ẹnikẹni ti o ba fẹ wọ inu ẹsin yii kò ni bukaata lati fi ọmọ eniyan kan se atẹgun rara, tabi ki o jẹwọ ohun ti o ti se saaju, sugbọn gbogbo ohun ti yoo se ko ju pe ki o se imọra, ki o si se imọtoto lọ, ki o si jẹri pe: LAA ILAAHA ILLA -L-LAAH WA ANNA MUHAMMADAN RASUULU -L-LAAH “kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ati pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i, ati ki o ni adisọkan itumọ mejeeji, ki o si maa sisẹ pẹlu ohun ti mejeeji tọka si.

Lẹyin naa dajudaju gbogbo ijọsin ni irọrun ati idẹkun maa n wọnu rẹ, nigba ti eniyan ba rajo, tabi o saarẹ, a o maa kọ akọọlẹ iru isẹ ti i maa n se nigba ti o ni alaafia, ti o wa nile fun un, koda dajudaju isẹmi Musulumi ni yoo di ohun irọrun, ati ifayabalẹ, yatọ si isẹmi alaigbagbọ, ti o se pe ele, ati isoro ni i, bẹẹ naa ni iku olugbagbọ-ododo yoo jẹ irọrun, tori naa ẹmi rẹ yoo jade bi ẹkankan omi ti i se maa n jade ni ẹnu igba, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

}الذين تتوفاهم الملائكة طيبين يقولون سلام عليكم ادخلوا الجنة بما كنتم تعملون { [سورة النحل: 32].

« Awọn ti awọn Malaika yoo pa ni ẹni-daadaa, wọn yoo maa sọ pe: Alaafia ki o maa ba yin, ẹ wọ ọgba-idẹra naa nitori ohun ti ẹ ti se “nisẹ" » [Suuratun-Nahl: 32]. Sugbọn alaigbagbọ, awọn malaika alagbara ti wọn le yoo wa ba a, nigba iku rẹ, wọn o si maa na an ni pasan, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ولو ترى إذ الظالمون في غمرات الموت والملائكة باسطوا أيديهم أخرجوا أنفسكم اليوم تجزون عذاب الهون بما كنتم تقولون على الله غير الحق وكنتم عن آياته تستكبرون { [سورة الأنعام: 93].

« Iba se pe iwọ ri awọn alabosi ninu ipọka-iku ni, ti awọn Malaika si tẹ ọwọ wọn pe: Ẹ mu ẹmi yin wa. Ni oni a o san yin ni ẹsan iya ẹlẹtẹ nitori ohun ti ẹ n sọ nipa Ọlọhun, ti ki i se ododo, ti ẹ si jẹ ẹni ti n se igberaga si awọn amin Rẹ » [Suuratul-An'aam: 93]. Ọba t'O ga, tun sọ pe:

} ولو ترى إذ يتوفى الذين كفروا الملائكة يضربون وجوههم وأدبارهم وذوقوا عذاب الحريق { [سورة الأنفال: 50].

« Iba se pe iwọ ri i ni, nigba ti awọn malaika n gba ẹmi awọn alaigbagbọ, ti wọn n gba oju wọn ati ẹyin wọn; [ti wọn si n sọ pe]: Ẹ tọ iya ina elejo wo » [Suuratul-Anfaal: 50].

6- Sise Dọgba:

Pe Ẹni ti o se awọn ofin Islam ni Ọlọhun nikan, Oun si ni Ẹlẹda awọn ẹda lapapọ, funfun ati dudu, akọ ati abo, ati pe wọn dọgba niwaju idajọ Rẹ, ati isedọgba Rẹ, ati ikẹ Rẹ, O se ni ofin fun onikaluku ni ọkunrin ati obinrin ohun ti o ba a mu, tori naa kò see se pe ki ofin naa o se ojusaju fun ọkunrin lori obinrin, tabi ki o se ajulọ fun obinrin ki o si se abosi fun ọkunrin, tabi ki o da eniyan funfun yanri pẹlu awọn adayanri kan, ki o si se wọn leewọ fun eniyan dudu, onikaluku dọgba niwaju ofin Ọlọhun, kò si iyatọ kan laarin wọn afi pẹlu ibẹru Ọlọhun.

7- Ifooro ẹni si daadaa sise, ati kikọ fun'ni lati se aidaa:

Ẹsin yii se akojọpọ iyatọ ọtọ kan, ati iroyin giga kan, oun ni: Ifooro ẹni si daadaa sise, ati kikọ fun'ni lati se aidaa, tori naa ọranyan ni lori gbogbo Musulumi-kunrin ati Musulumi-binrin, ti o ti balaga, ti o si ni laakaye, ti o si ni ikapa, pe ki o maa fooro, ki o si maa kọ, ni ibamu pẹlu agbara rẹ, ni odiwọn awọn ipele ifooro ati kikọ naa: Eyi ni pe ki o maa fooro, tabi ki o maa kọ, pẹlu ọwọ rẹ, ti kò ba si le se eleyii, njẹ ki o maa se e pẹlu ahọn rẹ, ti kò ba si le se e, ki o maa se e pẹlu ọkan rẹ, pẹlu eleyii ni ijọ yii ni apapọ yoo se di alafojusi lori ara rẹ, ati pe ọranyan l'o jẹ lori onikaluku pe ki o maa fooro lọ sidi daadaa sise, ki o si maa kọ sise aidaa, fun gbogbo ẹni ti o ba kọlẹ nibi daadaa sise kan, tabi o se aidaa kan, yala o jẹ oluse-ijọba ni o, tabi ẹni ti a n se ijọba le lori, ni odiwọn bi agbara rẹ ba ti se mọ, ati ni ibamu pẹlu awọn ilana ofin Sharia ti o de ọrọ yii.

Nitori naa ọrọ naa -gẹgẹ bi o ti se ri i- ọranyan ni lori onikaluku ni odiwọn bi o ti se lagbara mọ, ni asiko ti ọpọlọpọ ninu awọn ijọba oselu ti ode-oni n se irera pe awọn gba awọn ẹgbẹ alatako laye lati maa fi oju si bi isẹ ijọba ti se n lọ, ati ise awọn ohun elo ijọba.

Tori naa eyi jẹ apa kan ninu awọn ẹwa rẹ, ati pe ti o ba se pe mo fẹ lati fa a gun ni, ki ba pa dandan pe ki a duro nibi gbogbo ọna ijọsin kọọkan, ati gbogbo ọranyan, ati gbogbo ifooro, ati gbogbo kikọ, lati se alaye ohun t'o wa ninu rẹ ninu ọgbọn ti o dopin, ati ofin ti o fi ẹsẹ rinlẹ, ati ẹwa ti o de gongo, ati pipe ti kò ni afijọ, bẹẹ ni ẹnikẹni ti o ba se akiyesi awọn ofin ẹsin yii yoo mọ -ni imọ amọdaju- pe lati ọdọ Ọlọhun l'o ti wa, ati pe otitọ ti kò si iyemeji kan ninu rẹ ni i, imọ ti kò si si anu kan ninu rẹ si ni i pẹlu.

Nitori naa ti o ba fẹ lati mu ọna Ọlọhun pọn, ati titẹle ofin Rẹ, ati titọ oripa awọn anabi Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ, ilẹkun ironupiwada ti si silẹ niwaju rẹ, Alaforijin, Alaanu si ni Oluwa rẹ, O N pe ọ ki O le baa se idarijin fun ọ.

IRONUPIWADA

Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a" sọ pe:

(( كل ابن آدم خطاء، وخير الخطائين التوابون )). [رواه أحمد، والترمذي، وابن ماجة].

« Gbogbo ọmọ Aadama ni alasise, ati pe awọn ti o loore ju ninu awọn alasise naa ni awọn oluronupiwada » [Ahmad ati Tirmidzi ati Ibn Maajah ni wọn gbe e jade], ati pe ọlẹ ni eniyan ninu ẹmi rẹ, alailera si ni i ninu akolekan ati ipinnu rẹ, bẹẹ ni kò le e fi ara da adadé ẹsẹ, ati asise rẹ, n ni Ọlọhun se se idẹkun fun eniyan ni ti sisaanu rẹ, n l'O se se ironupiwada ni ofin fun un, paapaa ironupiwada si ni: Pipa ẹsẹ ti fun biburu rẹ -ni ti ibẹru Ọlọhun, ati irankan ohun ti O pa lese kalẹ fun awọn ẹru Rẹ- ati sise abamọ lori ohun ti o ti siwaju gba ọwọ rẹ, ati ipinnu lori atipa pipada sidi rẹ ti, ati sise atunse ohun ti o sẹku ninu ọjọ-ori pẹlu awọn isẹ rere, tori naa -gẹgẹ bi o ti se ri i- isẹ ọkan pọnbele kan ni i, laarin ẹru ati Oluwa rẹ, kò si aarẹ kan, tabi wahala kan lori rẹ, kò tilẹ si idayako isẹ kan ti o soro -ninu rẹ- isẹ ọkan nikan ni i, ati sisa kuro nidi ẹsẹ naa, ati ki o ma se pada sidi rẹ mọ, ati pe ipa-ẹsẹ-ti ati isinmi wa ninu ikoraro.

Tori naa o kò bukaata lati ronupiwada gba ọwọ ẹnikan ti yoo tu ọ fo, ti o si tu asiri rẹ, ti o si maa lo aimókun rẹ; ati pe kò jẹ nnkan kan ju ọrọ jẹẹjẹ kan laarin rẹ ati Oluwa rẹ lọ, ki o tọrọ aforijin Rẹ, ki o si tọrọ ki O fi ọna mọ ọ, yoo si gba ironupiwada rẹ.

Kò si ẹsẹ ajogunba kan ninu Islam, bẹẹ ni kò si olugbala kan ti ọmọ eniyan n reti, bẹẹ tilẹ kọ, nse l'o ri bi ẹlẹsin Ju ọmọ Hungary kan ti o mọna [wọ Islam] Muhammad Asad ti wi nibi ti o ti sọ pe: « Kò see se fun mi lati ri ọrọ kankan nipa nini bukaata lọ si ọdọ “igbala" ni aaye kankan ninu Al-Qur'aani; kò si ẹsẹ ajogunba akọkọ kankan ninu Islam, ti o duro laarin onikaluku ati apadasi rẹ, eyi ri bẹẹ tori pe:

} وأن ليس للإنسان إلا ما سعى { [سورة النجم: 39].

« Ati pe kò si ohun ti o wa fun eniyan ju ohun ti o se nisẹ lọ » [Suuratun-Najm: 39]. Bẹẹ ni kò tọrọ lọdọ eniyan pe ki o se ohun iwa-oju-rere kan, tabi ki o pa ara rẹ, ki a le baa si awọn ilẹkun ironupiwada fun un, ki o si le baa la nibi awọn asise rẹ »; kò ri bẹẹ, n se l'o ri bi Ọlọhun ti wi pe:

} ألا تزر وازرة وزر أخرى { [سورة النجم: 38].

« Pe ẹmi-ẹlẹsẹ kan kò ni i ru ẹru ẹsẹ omiran » [Suuratun-Najm: 38].

Ironupiwada ni awọn oripa ati awọn eso nla kan, ti o se pe ninu wọn ni:

1- Ki ẹru o mọ gbigbooro afarada Ọlọhun, ati apọnle Rẹ ninu bibo o lasiri, ati pe ti o ba se pe O fẹ ni, ki ba kan an loju lori ẹsẹ naa, ki ba si da oju ti i laarin awọn ẹru Rẹ, ki isẹmi kan o si ma dun mọ ọn laarin wọn, sugbọn kaka bẹẹ nse l'O bo o pẹlu asiri rẹ, ti O si da afarada Rẹ bo o, ti O si tun ran an lọwọ pẹlu ọgbọn, ati agbara, ati ọrọ -arziki- ati ounjẹ.

2- Ki o mọ paapaa ẹmi rẹ, ati pe ẹmi kan ni i ti o maa n pa'ni lasẹ lọpọlọpọ pẹlu aidaa, ati pe ẹri kan ni ohun ti o sẹlẹ lati ọwọ ẹmi naa ninu asise, ẹsẹ, ati ikuna, lori lilẹ ẹmi naa, ati ikọlẹ rẹ lori atise suuru kuro nibi ifẹkufẹ ti o jẹ eewọ, ati pe ẹmi naa kò le e rọrọ kuro ni ọdọ Ọlọhun -ni odiwọn isẹju kan- ki O le baa fọ ọ mọ, ki O si fi ọna mọ ọn.

3- Ọba t'O mọ se ironupiwada ni ofin, ki a le baa maa fi fa eyi ti o tobi ju ninu awọn okunfa oriire ẹru, eyi ti i se isẹripada si ọdọ Ọlọhun, ati wiwa isadi pẹlu Rẹ, gẹgẹ bi a tun se maa fi i fa orisirisi adua, ati irababa, ati irawọrasẹ-ẹbẹ, ati [fifi] aini [han], ati ifẹ, ati ibẹru ati irankan, tori naa ẹmi naa yoo sunmọ Ẹlẹda rẹ ni sisunmọ pataki kan ti kò le e sẹlẹ lai kò si ironupiwada, ati isẹripada lọ si ọdọ Ọlọhun.

4- Ki Ọlọhun O fi ori ohun ti o siwaju ninu ẹsẹ rẹ jin in, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} قل للذين كفروا إن ينتهوا يغفر لهم ما قد سلف { [سورة الأنفال: 38].

« Wi fun awọn alaigbagbọ pe ti wọn ba siwọ, a o dari ohun ti wọn ti se rekọja jin wọn » [Suuratul-Anfaal: 38].

5- Ki a yi awọn isẹ buburu eniyan pada si isẹ rere, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إلا من تاب وآمن وعمل صالحاً فأولئك يبدل الله سيئاتهم حسنات وكان الله غفوراً رحيماً { [سورة الفرقان: 70].

« Afi ẹni ti o ba ronupiwada, ti o si gbagbọ ni ododo, ti o si se isẹ rere, awọn wọnyi ni Ọlọhun O fi awọn daadaa jaarọ awọn aidaa wọn, Ọlọhun jẹ Alaforijin, Alaanu » [Suuratul-Furqaan: 70].

6- Ki eniyan o maa ba awọn eniyan ẹgbẹ rẹ lo -nipa awọn isẹ buburu wọn ti wọn se si i, ati asise wọn si i- pẹlu iru ohun ti o fẹ ki Ọlọhun O se fun oun lori awọn isẹ buburu rẹ ati awọn asise rẹ ati awọn ẹsẹ rẹ; dajudaju ẹsan isẹ yoo jẹ iru isẹ, tori naa ti o ba ba awọn eniyan lo pẹlu ibasepọ daadaa yii, yoo gba iru rẹ ni ọdọ Oluwa rẹ t'O ga, ati pe Ọba t'O mọ yoo fi daadaa Rẹ pade isẹ buburu rẹ ati ẹsẹ rẹ, gẹgẹ bi oun naa ti se n pade isẹ buburu awọn eniyan si i.

7- Ki o mọ daju pe ọlọpọlọpọ asise ati abuku ni ẹmi oun, eleyii o si se e ni ọranyan lori rẹ pe ki o ko ara ro nibi awọn abuku awọn eniyan, ki o si ko airoju pẹlu sise atunse ẹmi ara rẹ kuro nibi rironu nipa awọn abuku awọn mìíran.

N o pari ẹsẹ ọrọ yii pẹlu iroyin ọkunrin kan ti o wa si ọdọ Anabi, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ti o si sọ pe:

(( يا رسول الله، ما تركت حاجة ولا داجة إلا قد أتيت، قال: (( أليس تشهد ألا إله إلا الله، وأن محمداً رسول الله؟ )) ثلاث مرات. قال: نعم. قال: (( ذاك يأتـي على ذاك ) وفي رواية: (( فإن هذا يأتي على ذلك كله )). [رواه أبو يعلى في مسنده، وغيره].

« Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, n kò fi nnkan nla kan tabi kekere kan silẹ ninu ohun ti [ẹmi mi] n fẹ afi ki n se e, Anabi ni: « Sé bi o jẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun afi Ọlọhun, ati pe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni i? » lẹẹmẹta. O ni: Bẹẹ ni. Anabi ni: « Eyun un yoo maa pa eleyun un rẹ ». O si wa ninu ẹgbawa-ọrọ mìíran pe: « Dajudaju eleyii yoo maa pa apapọ eleyun un rẹ ». [Abu Ya'ala ati awọn mìíran ni wọn gbe e jade].

O si wa ninu ẹgbawa-ọrọ mìíran pe: O wa si ọdọ Ojisẹ Ọlọhun, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", o si sọ pe:

(( أرأيت رجلاً عمل الذنوب كلها، فلم يشرك بالله تعالى شيئاً، وهو في ذلك لا يترك حاجة أو داجة إلا اقتطعها بيمنه، فهل لذلك من توبة؟ قال: (( هل أسلمت؟ )) قال: أما أنا فأشهد ألا إله إلا الله وحده لا شريك له، وأنك رسول الله ﷺ‬. قـال: (( نعم! تفعل الخيرات، وتترك السيئات؛ فيجعلهن الله عز وجل لك خيرات كلهن)). قال: وغدراتي وفجراتي؟ قال: (( نعم )). قال: الله أكبر. فما زال يكبر حتى تورى. [رواه ابن أبي عاصم في الآحاد والمثاني، وغيره].

« Fun mi niro nipa ọkunrin kan ti o da gbogbo awọn ẹsẹ, ti kò si fi nnkan kan se orogun si Ọlọhun t'O ga, ti o si se pe kò fi ẹsẹ nla tabi kekere kan silẹ afi ki o fi ọwọ rẹ ge e [ki o se e], njẹ ironupiwada wa n bẹ fun eleyii bi? Anabi ni: « Njẹ o wa gba Islam bi? », o ni: Sugbọn emi, mo jẹri pe kò si ọba kan ti o tọ lati sin lododo yatọ si Ọlọhun nikan, kò si orogun kan fun Un, ati pe iwọ ojisẹ Ọlọhun ni ọ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba ọ". Anabi ni: « Bẹẹ ni! Maa se isẹ rere, ki o si fi isẹ buburu silẹ, ki Ọlọhun, Ọba t'O ga, t'O si gbọn-un-gbọn, O wa sọ gbogbo wọn di isẹ rere fun ọ ». O ni: Awọn ijamba mi ati awọn iwa ẹsẹ mi? Anabi ni: « Bẹẹ ni ». O ni: Ọlọhun l'O tobi ju. Kò tilẹ yee gbe Ọlọhun tobi titi ti o fi fara sin. [Ibn Abi Aasim, ati awọn mìíran ni wọn gbe e jade].

Tori naa Islam a maa pa ohun ti o siwaju rẹ [ninu ẹsẹ] rẹ, ironupiwada ododo a si maa pa ohun ti o gbawaju rẹ, gẹgẹ bi ẹgbawa-ọrọ ti se fi ẹsẹ rinlẹ pẹlu eleyii lati ọdọ Anabi; “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a".

###

ATUBỌTAN ẸNIKẸNI TI KÒ BA GBA ISLAM

Gẹgẹ bi o ti se han si ọ ninu iwe yii pe Islam ni ẹsin Ọlọhun, oun si ni ẹsin ododo, oun si ni ẹsin ti gbogbo awọn anabi ati awọn ojisẹ mu wa, ati pe Ọlọhun ti gbe ẹsan nla kalẹ ni ile-aye ati ni ọrun fun ẹni ti o ba gba a gbọ lododo, O si se ileri-iya elero fun ẹnikẹni ti o ba se aigbagbọ si i.

Nigba ti o si se pe Ọlọhun ni Ẹlẹda, Olukapa, Oludari, ninu aye yii, ati pe iwọ eniyan, ẹda kan ninu awọn ẹda Rẹ ni ọ, O da ọ, O si tẹ ori gbogbo ohun ti n bẹ ni aye ba fun ọ, O si se ofin Rẹ fun ọ, O si pa ọ lasẹ pẹlu titẹle e, tori naa ti o ba gbagbọ-lododo, ti o si tẹle ohun ti O fi pa ọ lasẹ, ti o si jinna si ohun ti O kọ fun ọ, o jere ohun ti O se ni adehun fun ọ ni ile ikẹyin, ninu awọn idẹra ti ki i tan; o si se oriire ni ile-aye pẹlu ohun ti yoo maa se ni idẹra fun ọ ninu awọn onirunruu idẹra, o si jẹ ẹni ti o fi ara jọ awọn ti wọn pe ju ninu awọn ẹda ni laakaye, ti wọn si mọ ju ni ẹmi, awọn ni awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ati awọn ẹni-rere, ati awọn malaika ti wọn sunmọ Ọlọhun.

Ti o ba si se aigbagbọ, ti o si tako Oluwa Rẹ, o padanu aye rẹ ati ọrun rẹ, o si ri ibunu Rẹ, ati iya Rẹ, ni ile-aye ati ni ile ikẹyin, ati pe o jẹ ẹni ti o fi ara jọ awọn ti wọn buru ju ninu awọn ẹda, ti wọn si dinku ju ni laakaye, ti wọn si jabọ ju ni ẹmi, ninu awọn esu ati awọn alabosi, ati awọn obilẹjẹ, ati awọn alagbẹrugbanri, eyi jẹ akopọ.

Alaye diẹ ninu awọn atubọtan aigbagbọ ni yekeyeke niyi:

1- Ibẹru ati aisi ibalẹ-ọkan:

Ọlọhun se adehun ibalẹ-ọkan ti o pe ninu igbesi-aye ati ni ile ikẹyin fun awọn ti wọn gba A gbọ ni ododo, ti wọn si n tẹle awọn ojisẹ Rẹ; Ọlọhun sọ pe:

} الذين آمنوا ولم يلبسوا إيمانهم بظلم أولئك لهم الأمن وهم مهتدون { [سورة الأنعام: 82].

« Awọn ti wọn gba Ọlọhun gbọ ni ododo, ti wọn kò si lu igbagbọ wọn pọ mọ abosi -ẹbọ sise- awọn wọnyi ni ibalẹ-ọkan n bẹ fun, awọn naa si ni awọn olumọna » [Suuratu l-An'aam :82]. Ọlọhun ni Olufinilọkanbalẹ, Arinurode, Oun si ni Olukapa lori gbogbo ohun t'o wa laye, ti O ba nifẹ ẹru kan nitori igbagbọ-ododo rẹ, yoo fun un ni aabo, ibalẹ-ọkan, ati ifayabalẹ, ati pe nigba ti eniyan ba se aigbagbọ si I, yoo mu ibalẹ-ọkan rẹ ati aabo rẹ kuro lọdọ rẹ, tori naa o kò ni i ri i afi l'ẹni ti n bẹru nipa apadasi rẹ ni ile-aye ati ni ile ikẹyin, l'ẹni ti yoo maa bẹru arun ati amodi lori ara rẹ, l'ẹni ti yoo maa bẹru ọjọ-iwaju rẹ ni ile-aye, ati pe eleyii l'o mu ki wọn fi ọja ile ifunni ni idaju aabo -insurance- lori ẹmi, ati nnkan-ini lọlẹ; nitori aisi aabo, ati nitori aisi igbẹkẹle Ọlọhun.

2- Isẹmi lile:

Ọlọhun da eniyan, O si tẹ ori gbogbo ohun t'o wa laye ba fun un, O si pin ipin gbogbo ẹda fun un ninu ọrọ -arziki- ati ọjọ-ori, sé bi iwọ n ri ẹyẹ ti o maa n fi afẹjumọ dide kuro lori itẹ rẹ, lati lọ wa ijẹ rẹ, ti yoo si maa fi ẹnu sa a jẹ, ti yoo si maa ti ori ẹtuntun igi kan bọ si ori omiran, ti yoo si maa kọrin pẹlu ohùn ti o dun ju, ati pe ẹda kan ni eniyan jẹ ninu awọn ẹda ti O ti pin ọrọ -arziki- rẹ ati ọjọ-ori rẹ fun wọnyi, nitori naa ti o ba gba Oluwa rẹ gbọ lododo, ti o si duro sinsin lori ofin Rẹ, yoo ta a lọrẹ oriire, ati idurosinsin, yoo si se ọrọ rẹ ni irọrun fun un, koda ki o se pe ohun ti o ni kò ju ohun ti o le fi gbe ẹmi ro lọ.

Sugbọn ti o ba se aigbagbọ si Oluwa rẹ, ti o si se igberaga kuro nibi ijọsin fun Un, yoo se isẹmi rẹ ni lile, yoo si ko idaamu, ati ibanujẹ, jọ le e lori, koda ki o se pe gbogbo ohun ti a fi i ri isinmi, ati onirunruu ohun igbadun l'o ni. Njẹ iwọ kò wa ri i bi awọn olupokunso ti se pọ to ni awọn orilẹ ede ti wọn ti pese gbogbo ohun igbadun fun awọn eniyan wọn bi? Iwọ kò wa ri i bi itayọ-ala ti se pọ to nipa onirunruu ohun itole, ati orisirisi irin-ajo, nitori atigbadun igbesi-aye bi? Dajudaju ohun ti o mu ki itayọ-ala o wọnu eleyii ni gbigbofo ọkan kuro nibi igbagbọ-ododo, ati jijẹro ihagaga ati ele, ati igbiyanju lati pa ibẹru yii rẹ pẹlu awọn ohun ti n yipada ati eyi ti n di ọtun, a! Ododo ni Ọlọhun sọ nibi ti O ti sọ pe:

} ومن أعرض عن ذكري فإن له معيشة ضنكاً ونحشره يوم القيامة أعمى { [سورة طه: 124].

« Ati pe ẹnikẹni ti o ba sẹri kuro nibi iranti Mi, dajudaju igbesi-aye inira ni yoo wa fun un, A o si gbe e dide ni ọjọ igbende ni afọju » [Suuratu Tọọ Haa: 124].

3- Wi pe yoo maa sẹmi ninu iwọya-ija pẹlu ori ara rẹ ati pẹlu ile-aye ni ayika rẹ:

Eyi jẹ bẹẹ, nitori pe a se adamọ ẹmi rẹ lori At-Tawhiid -sise Ọlọhun ni ọkan soso ninu ijọsin-. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} فطرت الله التي فطر الناس عليها { [سورة الروم: 30].

« Adamọ Ọlọhun, eyi ti O pilẹ da awọn eniyan le lori » [Suuratur-Ruum: 30]. Ati pe ara rẹ ti sọwọsọsẹ silẹ fun Ẹlẹda rẹ, o si n lọ lori eto Rẹ, sugbọn alaigbagbọ kọ afi ki o tako adamọ rẹ, ki o si maa sẹmi ninu awọn ohun ti o sa lẹsa funra rẹ ni ẹni ti o tako asẹ Oluwa rẹ, tori naa bi o tilẹ jẹ pe ara rẹ jẹ ohun ti o gbafa, sugbọn ẹsa rẹ jẹ ohun ti o se atako

Oun si wa ninu ijakadi pẹlu ile-aye ni ayika rẹ, eyi ri bẹẹ, nitori pe dajudaju apapọ ile-aye yii, bẹrẹ lati ori eyi ti o tobi ju ninu awọn irawọ rẹ, titi ti o fi de ori eyi ti o kere ju ninu awọn kokoro rẹ, o n lọ lori ebubu ti Oluwa rẹ se ni ofin fun un. Ọlọhun sọ pe:

} ثم استوى إلى السماء وهي دخان فقال لها وللأرض ائتيا طوعاً أو كرهاً قالتا أتينا طائعين { [سورة فصلت: 11].

« Lẹyin naa ni O gbero [lati da] sanma nigba ti o wa ni eefin, O si wa sọ fun oun ati ilẹ pe: Ẹ wa, bi ẹ fẹ, bi ẹ kọ. Awọn mejeeji si sọ pe: Awa wa, ni ẹni ti o finufẹdọ tẹle asẹ » [Suuratu Fusilat: 11]. Koda ile-aye yii fẹran ẹnikẹni ti o ba se dọgba pẹlu rẹ ninu igbafa rẹ fun Ọlọhun, o si korira ẹni ti o ba tapa si i, alaigbagbọ si ni alaigbọran ni ile-aye yii, nigba ti o se ara rẹ ni alatako fun Oluwa rẹ, olukẹyin si I; eyi l'o mu ki o jẹ ẹtọ fun awọn sanma ati ilẹ ati gbogbo awọn ẹda yoku pe ki wọn o korira rẹ, ki wọn o si korira aigbagbọ ati aimọ Ọlọhun rẹ, Ọlọhun sọ pe:

} وقالوا اتخذ الرحمن ولداً. لقد جئتم شيئا إداً. تكاد السموات يتفطرن منه وتنشق الأرض وتخر الجبال هداً. أن دعوا للرحمن ولداً. وما ينبغي للرحمن أن يتخذ ولداً. إن كل من في السموات والأرض إلا آتي الرحمن عبداً { [سورة مريم: 88-93].

« Ati pe wọn sọ pe: Ọba Alaanujulọ mu ẹnikan ni ọmọ. Dajudaju ẹyin ti gbe ọrọ ti o buru wa. Sanma fẹrẹ faya nitori rẹ, ilẹ naa si fẹẹ faya, awọn apata si fẹẹ wo purupupu. Nitori pe wọn pe ọmọ mọ Ọba Alaanujulọ. Ati pe kò tọ fun Ọba Alaanujulọ pe ki O mu ẹnikan ni ọmọ. Kò si ẹnikan ninu sanma ati lori ilẹ afi ki o wa ba Ọba Alaanujulọ ni jijẹ ẹru » [Suuratu Maryam: 88-93]. Ọlọhun t'O mọ, tun sọ nipa Fir'auna, ati awọn ọmọ ogun rẹ, pe:

} فما بكت عليهم السماء والأرض وما كانوا منظرين { [سورة الدخان: 29].

« Sanma ati ilẹ kò sunkun wọn, ati pe wọn kò jẹ ẹni ti a lọ lara » [Suuratud-Dukhaan: 29].

4- Wi pe yoo maa sẹmi ni alaimọkan:

Nigba ti o se pe aigbagbọ ni aimọkan, koda oun ni aimọkan ti o tobi ju, tori pe alaigbagbọ se aimọ Oluwa rẹ, o n wo ile-aye ti Oluwa rẹ da, ti O si da a lai kò ni afijọ yii, o si n ri isẹda nla ninu ara rẹ, ati idẹda ti o gbọn-un-gbọn, lẹyin naa yoo maa se alaimọ Ẹni ti O da ile-iye yii, ati Ẹni ti O da ara rẹ, njẹ ki i wa se eleyii ni aimọkan ti o tobi ju bi??.

5- Ki o maa sẹmi ni ẹni ti o se abosi fun ori ara rẹ, ti o si se abosi fun awọn ti wọn wa ni ayika rẹ:

Nitori pe o tẹ ara rẹ lori ba fun ohun ti o yatọ si ohun ti a da a fun un, kò si sin Oluwa rẹ, kaka bẹẹ, nse l'o n sin ẹlomiran, bẹẹ ni abosi ni fifi nnkan si ibi ti ki i se aaye rẹ, abi abosi wo l'o tobi ju didoju ijọsin kọ ẹlomiran t'o yatọ si Ẹni ti O lẹtọ si i lọ? Luqmaan ọlọgbọn si ti sọ fun ọmọ rẹ, ni ẹni ti n se alaye aidaa sise ẹbọ si Ọlọhun, pe:

} يا بني لا تشرك بالله إن الشرك لظلم عظيم { [سورة لقمان: 13].

« Irẹ ọmọde mi, ma se ẹbọ si Ọlọhun, dajudaju ẹbọ sise ni abosi ti o tobi » [Suuratu-Luqmaan: 13].

Oun si ni abosi fun ẹni ti o wa ni ayika rẹ ninu awọn ọmọ eniyan ati awọn ẹda; tori pe kò mọ ẹtọ fun ẹlẹtọ, nitori naa ti o ba di ni ọjọ igbende gbogbo ẹni ti o se abosi fun ni eniyan, tabi ẹranko, ni yoo duro niwaju rẹ, ti yoo tọrọ ni ọdọ Oluwa rẹ pe ki O ba oun gbẹsan ni ọdọ rẹ.

6- Wi pe o gbera rẹ kọlu ikorira Ọlọhun, ati ibinu Rẹ, ni ile-aye:

Nitori naa yoo bẹ ni ipo ki awọn adanwo o sẹlẹ si i, ki awọn ajalu o si ja lu u, ki o maa jẹ iya kan ti a kan loju. Ọba ti ẹyin Rẹ gbọn-un-gbọn, sọ pe:

} أفأمن الذين مكروا السيئات أن يخسف الله بهم الأرض أو يأتيهم العذاب من حيث لا يشعرون. أو يأخذهم في تقلبهم فما هم بمعجزين. أو يأخذهم على تخوف فإن ربكم لرءوف رحيم { [سورة النحل: 45-47].

« Njẹ awọn ẹni ti wọn da ete buburu wa le fi ayabalẹ si pe ki Ọlọhun O jẹ ki ilẹ o gbe wọn mi bi, tabi ki iya naa o wa ba wọn lati aaye ti wọn kò fura?. Tabi ki O mu wọn lori lilọ-bibọ wọn, nitori naa awọn kò jẹ ẹni ti o le bọ. Tabi ki O mu wọn diẹdiẹ? Nitori naa dajudaju Ọlọpọlọpọ aanu, Onikẹ, ni Oluwa yin » [Suuratun-Nahl: 45-47]. Ọlọhun t'O mọ, tun sọ pe:

} ولا يزال الذين كفروا تصيبهم بما صنعوا قارعة أو تحل قريباً من دارهم حتى يأتي وعد الله إن الله لا يخلف الميعاد { [سورة الرعد: 31].

« Ati pe iya lile koko kò ni i yee maa ba awọn ẹni ti kò gbagbọ, nitori ohun ti wọn se nisẹ, tabi ki o sọ si itosi ile wọn titi ti adehun Ọlọhun yoo fi de, dajudaju Ọlọhun ki I yapa adehun » [Suuratur-Ra'ad: 31]. Ọba t'O gbọn-un-gbọn ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} أو أمن أهل القرى أن يأتيهم بأسنا ضحى وهم يلعبون { [سورة الأعراف: 98].

« Njẹ awọn ilu naa wa le fi ayabalẹ pe ki iya Wa o wa ba wọn ni iyalẹta, nigba ti wọn ba n sere bi? » [Suuratul-Aaraaf: 98], eleyii ni ise gbogbo ẹni ti o ba tako iranti Ọlọhun, Ọlọhun t'O ga sọ l'Ẹni ti N fun'ni niro nipa awọn jijẹ awọn ijọ alaigbagbọ ti o ti rekọja niya pe:

} فكلا أخذنا بذنبه فمنهم من أرسلنا عليه حاصبا ومنهم من أخذته الصيحة ومنهم من خسفنا به الأرض ومنهم من أغرقنا وما كان الله ليظلمهم ولكن كانوا أنفسهم يظلمون { [سورة العنكبوت: 40].

« A si mu onikaluku wọn pẹlu ẹsẹ rẹ; nitori naa o n bẹ ninu wọn ẹni ti A ran atẹgun le lori, o si wa ninu wọn ẹni ti ijagbe mu, bẹẹ ni o wa ninu wọn ẹni ti a tẹri sinu ilẹ, ati pe o n bẹ ninu wọn ẹni ti a tẹri [sinu omi], Ọlọhun kò si se abosi fun wọn, sugbọn awọn jẹ ẹni ti n se abosi fun ori ara wọn » [Suuratul-Ankabuut: 40]. Ati bi o ti se n ri awọn adanwo awọn ẹni ti wọn wa ni ayika rẹ ninu awọn ti iya Ọlọhun ati ibawi Rẹ sẹlẹ si.

7- Ki a kọ ikuna, ati adanu, fun un:

Tori naa latari abosi rẹ, o padanu ohun ti o tobi ju ninu ohun ti ọkan ati awọn ẹmi maa n jẹ igbadun rẹ, oun ni mimọ Ọlọhun, ati ninaju pẹlu biba A sọrọ jẹẹjẹẹ, ati ifayabalẹ si I, o si pofo ile-aye, nitori pe o se isẹmi osi ati anu ninu rẹ, o si padanu ẹmi rẹ ti n se akojọ nitori rẹ, tori pe kò tẹ ori rẹ ba fun ohun ti a sẹda rẹ fun, kò si fi i se oriire ni ile-aye, tori pe o sẹmi ni oloriibu, o si ku ni oloriibu, ati pe a o gbe e dide pẹlu awọn oloriibu, Ọba t'O ga sọ pe:

} ومن خفت موازينه فأولئك الذين خسروا أنفسهم { [سورة الأعراف: 9].

« Ẹnikẹni ti awọn osunwọn isẹ [rere] rẹ ba fuyẹ, awọn wọnyun un ni ẹni ti o pofo ẹmi wọn » [Suuratul-A'araaf: 9]. O si padanu ẹbi rẹ; tori pe o sẹmi pẹlu wọn lori sise aigbagbọ si Ọlọhun, tori naa wọn dọgba pẹlu rẹ ninu oriibu ati isẹmi lile, ati pe ina ni ibupadasi wọn. Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} إن الخاسرين الذين خسروا أنفسهم وأهليهم يوم القيامة { [سورة الزمر: 15].

« Dajudaju awọn ẹni-ofo ni awọn ẹni ti wọn sofo ẹmi wọn, ati awọn eniyan wọn, ni ọjọ igbende » [Suuratuz-Zumar: 15]. Ti o ba si di ni ọjọ igbende, a o gbe wọn dide lọ si inu ina, o buru ni ibugbe, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} احشروا الذين ظلموا وأزواجهم وما كانوا يعبدون. من دون الله فاهدوهم إلى صراط الجحيم { [سورة الصافات: 22-23].

« Ẹ ko awọn alabosi jọ ati awọn iyawo wọn ati ohun ti wọn n jọsin fun. Lẹyin Ọlọhun, nitori naa ẹ mu wọn lọ si oju-ọna ina Jahiim » [Suuratus-Saaffaat: 22-23].

8- Wi pe yoo maa sẹmi ni alaigbagbọ si Oluwa rẹ, alaimoore si awọn idẹra Rẹ:

Dajudaju lati ara aijẹ nnkan kan ni Ọlọhun ti da a, ti O si dasọ gbogbo awọn idẹra bo o, bawo ni yoo ti se maa sin ẹlomiran, ti yoo si maa se ti ẹni t'o yatọ si I, ti yoo si maa dupẹ fun ẹlomiran lẹyin Rẹ … njẹ aimoore wo l'o tobi ju eleyii lọ? Tabi aimọpẹdu wo l'o buru ju eleyii lọ?.

9- Wi pe a kò ni i jẹ ki o ri isẹmi otitọ se:

Eyi jẹ bẹẹ, nitori pe eniyan ti o lẹtọ si isẹmi ni ẹni ti o gba Oluwa rẹ gbọ lododo, ti o si mọ ohun afojusi rẹ, ti ibupadasi rẹ si ye e, ti o si ni amọdaju nipa agbende rẹ, ti o wa mọ iwọ gbogbo oniwọ fun un, ti ki i kọ otitọ kan, ti ki i si i ni ẹda kan lara, ti o si sẹmi ni isẹmi awọn oloriire, ti o si ri isẹmi daadaa ni ile-aye ati ni ikẹyin, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} من عمل صالحاً من ذكر أو أنثى وهو مؤمن فلنحيينه حياة طيبة { [سورة النحل: 97].

« Ẹnikẹni ti o ba se daadaa ni ọkunrin tabi obinrin, ti o si jẹ olugbagbọ-ododo, dajudaju A o jẹ ki o lo igbesi-aye ti o dara » [Suuratun-Nahl: 97]. Ti [o ba si di ni] ile ikẹyin:

} ومساكن طيبة في جنات عدن ذلك الفوز العظيم { [سورة الصف: 12].

« Ati awọn ibugbe ti o dara ninu awọn ọgba-idẹra ti yoo maa gbe titi, eyi jẹ erenjẹ ti o tobi » [Suuratus-Saff: 12].

Sugbọn ẹni ti o ba se isẹmi ni isẹmi kan ti o jọ isẹmi awọn ẹranko, ti kò mọ Oluwa rẹ, ti kò si mọ ki ni ohun afojusi rẹ, ti kò si mọ ibo ni ibupadasi rẹ? Sugbọn ti o se pe afojusi rẹ ni ki o jẹ, ki o si mu, ki o si sun … njẹ iyatọ wo l'o wa laarin rẹ ati awọn ẹran yoku? Koda o nu ju wọn lọ, Ọlọhun t'O gbọn-un-gbọn ni ẹyin, sọ pe:

} ولقد ذرأنا لجهنم كثيراً من الجن والإنس لهم قلوب لا يفقهون بها ولهم أعين لا يبصرون بها ولهم آذان لا يسمعون بها أولئك كالأنعام بل هم أضل أولئك هم الغافلون { [سورة الأعراف: 179].

« Dajudaju A ti da ọpọlọpọ ninu alujannu ati eniyan fun ina Jahannama; wọn ni ọkan ti wọn kò i fi i gbọ agbọye, wọn si ni oju ti wọn kò i fi i riran, bẹẹ ni wọn ni eti ti wọn kò i fi i gbọrọ, awọn wọnyi dabi awọn ẹran; bẹẹ tilẹ kọ, wọn sina [ju ẹran lọ] awọn wọnyi ni olugbagbera » [Suuratul-A'araaf: 179]. Ọba t'O ga ni Olusọrọ, tun sọ pe:

} أم تَحسب أن أكثرهم يسمعون أو يعقلون إن هم إلا كالأنعام بل هم أضل سبيـلاً { [سورة الفرقان: 44].

« Tabi iwọ n ro ni pe dajudaju ọpọlọpọ wọn ni wọn n gbọrọ, tabi ni wọn n se laakaye bi? Kò si ohun ti wọn jẹ bi kò se bii ẹran, bẹẹ tilẹ kọ, wọn sina ju [ẹranko] lọ » [Suuratul-Furqaan: 44].

10- Wi pe yoo maa bẹ ninu iya laelae:

Eyi ri bẹẹ, nitori pe alaigbagbọ yoo maa ti ibi iya kan bọ si ori omiran, nitori naa yoo jade kuro laye -lẹyin ti o tọ awọn isoro ati adanwo rẹ wo- lọ si ile ikẹyin, ati pe ninu igbesẹ akọkọ ninu rẹ malaika iku yoo sọ kalẹ wa ba a, ti awọn malaika iya yoo si siwaju rẹ, lati jẹ ẹ ni iya ti o tọ si i, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ولو ترى إذ يتوفى الذين كفروا الملائكة يضربون وجوههم وأدبارهم { [سورة الأنفال: 50].

« Iba se pe iwọ ri i ni nigba ti awọn malaika n gba ẹmi awọn alaigbagbọ, ti wọn n gba oju wọn ati ẹyin wọn » [Suuratul-Anfaal: 50]. Lẹyin igba ti ẹmi rẹ ba jade, ti o si sọ sinu saare rẹ, yoo ba eyi ti o le ju ninu iya pade, Ọlọhun sọ ni Ẹni t'O N fun'ni niro nipa awọn ẹni Fir'auna, pe:

} النار يعرضون عليها غدوا وعشيا ويوم تقوم الساعة أدخلوا آل فرعون أشد العذاب { [سورة غافر: 46].

« Ina naa ni a o sẹ wọn lori lọ si ọdọ rẹ ni owurọ ati ni asaalẹ, ati pe ọjọ ti igbende naa yoo ba de, [a o sọ pe]: Ẹ fi awọn eniyan Fir'auna sinu eyi ti o le ju ni iya » [Suuratu Gaafir: 46]. Lẹyin naa ti o ba di ni ọjọ igbende, ti a gbe awọn ẹda dide, ti a si se afihan awọn isẹ wọn, ti alaigbagbọ si ri pe dajudaju Ọlọhun ti siro gbogbo isẹ rẹ fun un sinu iwe ti Ọlọhun sọ nipa rẹ yun un, pe:

} ووضع الكتاب فترى المجرمين مشفقين مما فيه ويقولون يا ويلتنا ما لهذا الكتاب لا يغادر صغيرة ولا كبيرة إلا أحصاها { [سورة الكهف: 49].

« Ati pe a o gbe tira naa kalẹ, iwọ o si ri awọn ẹlẹsẹ ti ohun ti o wa ninu rẹ yoo maa ba wọn lẹru, wọn o si maa sọ pe: Egbe wa o, iru iwe wo niyi, ti kò fi ohun kekere kan tabi ninla kan silẹ afi ki o siro gbogbo rẹ pọ? » [Suuratul-Kahf: 49]. Ni ibi yii alaigbagbọ yoo rankan pe ki oun o kuku jẹ erupẹ:

} يوم ينظر المرء ما قدمت يداه ويقول الكافر يا ليتني كنت تراباً { [سورة النبأ: 40].

« Ọjọ ti eniyan yoo maa wo ohun ti ọwọ rẹ ti ti siwaju; alaigbagbọ yoo sọ pe: Ee se ti n kò ti jẹ erupẹ » [Suuratun-Naba'a: 40].

Ati pe dajudaju iba se pe eniyan ni gbogbo ohun ti o wa lori ilẹ ni, ki ba fi se irapada nibi iya ọjọ yii, nitori isoro ijaya ibuduro naa; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ولو أن للذين ظلموا ما في الأرض جميعاً ومثله معه لافتدوا به { [سورة الزمر: 47].

« Iba se pe dajudaju gbogbo ohun ti o wa lori ilẹ patapata jẹ ti awọn alabosi ni, ati iru rẹ pẹlu rẹ, dajudaju wọn o ba fẹ fi se pasipaarọ » [Suuratuz-Zumar: 47]. Ọlọhun t'O ga tun sọ pe:

} يود المجرم لو يفتدي من عذاب يومئذ ببنيه. وصاحبته وأخيه. وفصيلته التي تؤويه. ومن في الأرض جميعاً ثم ينجيه { [سورة المعارج: 11-14].

« Ẹlẹsẹ yoo fẹ pe iba se pe [o le] fi awọn ọmọ rẹ gba ara rẹ silẹ nibi iya ọjọ naa. Ati iyawo rẹ, ati ọmọ iya rẹ. Ati awọn ẹbi rẹ ti wọn maa n daabo bo o. Ati gbogbo ẹni ti o wa lori ilẹ patapata, lẹyin naa ki wọn gba a silẹ » [Suuratul-Ma'aarij: 11-14].

Ati nitori pe ile ẹsan ni ile yun un, ki i se ile irankan, dandan ni ki eniyan o gba ẹsan isẹ rẹ, ti o ba jẹ rere yoo ri rere, ti o ba si jẹ aburu yoo ri aburu. Ati pe ohun ti o buru ju ti alaigbagbọ yoo ri ni ile ikẹyin naa ni iya ina, ati pe orisirisi ni Ọlọhun se onirunru iya rẹ fun awọn ara ibẹ, ki wọn o le baa tọ aburu ọrọ wọn wo; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} هذه جهنم التي يكذب بها المجرمون. يطوفون بينها وبين حميم آن { [سورة الرحمن: 43-44].

« Eyi ni ina Jahannama ti awọn ẹlẹsẹ n pe ni irọ. Wọn yoo rọkirika aarin rẹ ati aarin omi gbigbona ti o gbona janjan » [Suuratur-Rahmaan: 43-44]. O si sọ ni Ẹni ti N fun'ni niro nipa ohun ibumu ati ẹwu wọn pe:

} فالذين كفروا قطعت لهم ثياب من نار يصب من فوق رءوسهم الحميم. يصهر به ما في بطونهم والجلود. ولهم مقامع من حديد { [سورة الحج: 19-21].

« Nitori naa awọn ti wọn jẹ alaigbagbọ a ge asọ ina fun wọn, a o da omi gbigbona le wọn lati oke wọn. A o fi yọ ohun ti n bẹ ninu ikun wọn ati awọ ara wọn. Arọ irin yoo maa bẹ fun wọn » [Suuratul-Hajj: 19-21].

###

ỌRỌ IPARI

Iwọ eniyan:

O ti jẹ alaisi rara ri, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} أو لا يذكر الإنسان أنا خلقناه من قبل ولم يك شيئاً { [سورة مريم: 67].

« Eniyan kò se iranti ni pe Awa ni A se ẹda rẹ ni isiwaju, nigba ti oun kò jẹ nnkan kan » [Suuratu Maryam: 67]. Lẹyin naa ni Ọlọhun da ọ lati ara omi gbọlọgbọlọ kan, O si se ọ ni olugbọrọ, oluriran, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} هل أتى على الإنسان حين من الدهر لم يكن شيئاً مذكوراً. إنا خلقنا الإنسان من نطفة أمشاج نبتليه فجعلنا سميعاً بصيراً { [سورة الإنسان: 1-2].

« Dajudaju igba kan ninu akoko ti rekọja lori eniyan ti kò jẹ nnkan kan ti a le darukọ. Dajudaju Awa ni A da eniyan lati ara omi gbọlọgbọlọ ti a ropọ mọ ara wọn, ki A le baa dan an wo; nitori naa A se e ni olugbọrọ, oluriran » [Suuratul-Insaan: 1-2]. Lẹyin naa ni o bẹrẹ si ni i yi lati ibi ailagbara lọ sibi agbara, ati pe ibi ailera ni adapada rẹ; Ọlọhun t'O ga, sọ pe:

} الله الذي خلقكم من ضعف ثم جعل من بعد ضعف قوة ثم جعل من بعد قوة ضعفاً وشيبة يخلق ما يشاء وهو العليم القدير { [سورة الروم: 54].

« Ọlọhun ni Ẹni ti O da yin lati inu ailagbara, lẹyin naa O fun yin ni agbara lẹyin ailagbara, lẹyin naa O se yin ni alailagbara ati [arugbo] abewu lẹyin agbara; O N sẹda ohun ti O ba fẹ, Oun si ni Olumọ, Alagbara » [Suuratur-Ruum: 54]. Lẹyin naa opin ti kò si iyemeji nipa rẹ ni iku, ati pe iwọ yoo gbera ninu awọn igbesẹ wonyi lati ori ailagbara kan bọ si ori omiran, o kò ni i le ti inira kuro ni ọdọ ara rẹ, o kò si ni i le fa anfaani funra rẹ, afi pẹlu wiwa iranlọwọ rẹ pẹlu awọn idẹra Ọlọhun lori rẹ ninu ọgbọn, agbara, ati ounjẹ, nigba ti iwọ jẹ alaini, olubukaata ninu adamọ, tori naa melòó-melòó ni ohun ti o n bukaata nitori ki o le baa maa bẹ laaye, eyi ti kò si ni arọwọto rẹ, ti o si see se pe ki o ri i ni igba kan, ki o si bọ mọ ọ lọwọ ni igba mìíran, ati pe melòó-melòó ni nnkan ti yoo se ọ lanfaani, ti o si fẹ lati ri i, ti o si see se pe ki ọwọ rẹ o tẹ ẹ lẹẹkan, ki o si ma ri i nigba mìíran, melòó-melòó si ni ohun ti n ni ọ lara, ti i si n ko irẹwẹsi ọkan ba ọ, ti i si n fi iyanju rẹ rare, ti i si n fa adanwo ati awọn aburu fun ọ, ti o si fẹ lati ti i danu kuro ni ọdọ ara rẹ, ti o si maa n ri i ni igba kan, sugbọn ti o maa n da ọ lagara ni igba mìíran … njẹ o wa woye si aini rẹ ati bukaata rẹ si Ọlọhun bi? Ọlọhun si N sọ pe:

} يا أيها الناس أنتم الفقراء إلى الله والله هو الغني الحميد { [سورة فاطر: 15].

« Ẹyin eniyan, ẹyin ni ẹ jẹ oni-bukaata si Ọlọhun; Ọlọhun si ni Ọlọrọ, Ọba-ẹyin » [Suuratu Faatir: 15].

Kokoro lilẹ kekere kan ti kò se e fi oju lasan ri a maa kọlu ọ; ti yoo si da ọ ni idubulẹ aisan, ti o kò si ni i le ti i kuro, sugbọn ti o lọ si ọdọ eniyan alailera kan bi tiẹ lati tọju rẹ, nigba mìíran o le ri oogun t'o dọgba, nigba mìíran ẹwẹ onisegun a maa kagara, tori naa iparagadi yoo bo onisegun ati alaarẹ.

Tẹti ki o gbọ, iwọ ọmọ Aadama, o ma kuku lẹ pupọ o, iba se pe esinsin gbe nnkan kan mọ ọ lọwọ, o kò ni agbara lati gba a pada, ati pe otitọ ni Ọlọhun sọ nibi ti o ti wi pe:

} يا أيها الناس ضرب مثل فاستمعوا له إن الذين تدعون من دون الله لن يخلقوا ذباباً ولو اجتمعوا له وإن يسلبهم الذباب شيئا لا يستنقذوه منه ضعف الطالب والمطلوب { [سورة الحج: 73].

« Ẹyin eniyan, a fi apejuwe kan lelẹ, nitori naa ẹ tẹti si i. Dajudaju awọn ti ẹ n pe lẹyin Ọlọhun kò le da esinsin kan, bi o fẹ bi wọn parapọ lati se e; ti esinsin ba si gbe nnkan kan lọdọ wọn, wọn kò le e gba a lọwọ rẹ, ọlẹ ni ẹni ti n tọrọ nnkan ati ẹni ti wọn n tọrọ lọwọ rẹ » [Suuratul-Hajj: 73]. Njẹ ti o ba jẹ ẹni ti kò le e gba ohun ti esinsin gbe mọ ọ lọwọ pada, ki wa l'o ni ikapa lori rẹ ninu ọrọ rẹ?: « Asoso rẹ wa ni ọwọ Ọlọhun, ẹmi rẹ si wa lọwọ Rẹ, ati pe ọkan rẹ wa laarin meji ninu awọn ọmọ-ika Ọba Alaanujulọ, O N yi i bi O ti fẹ, bẹẹ ni isẹmi rẹ ati iku rẹ wa ni ọwọ Rẹ, oriire rẹ ati oriibu rẹ si wa lọwọ Rẹ, ati pe awọn iyirapada rẹ, ati aimira rẹ, ati awọn ọrọ rẹ pẹlu iyọnda Ọlọhun ati erongba Rẹ ni i, nitori naa o kò ni yirapada afi pẹlu iyọnda Rẹ, o kò si ni sisẹ afi pẹlu erongba Rẹ, ti O ba da ọ dara rẹ O da ọ da ailera, ailagbara, ijafara, ẹsẹ, ati asise; ati pe ti O ba fi ọ le ẹlomiran mìíran lọwọ, O ti fi ọ le ẹni ti kò ni ikapa inira tabi idẹra kan, iku tabi isẹmi kan, tabi igbende kan fun ọ, tori naa kò si irọrọ fun ọ kuro ni ọdọ Rẹ ni odiwọn isẹju kan, kaka bẹẹ, nse ni o ni bukaata lọ si ọdọ Rẹ ninu gbogbo mimi ni ikọkọ ati ni gbangbá, O N da awọn idẹra bo ọ, nigba ti iwọ n bi I ninu pẹlu awọn ẹsẹ ati aigbagbọ, t'ohun ti nini bukaata ti o le koko si I ni gbogbo ọnakọna, o ti sọ Ọ di ohun igbagbe, ti o si se pe ọdọ Rẹ ni adapada, ati apadasi rẹ, ati pe iwaju Rẹ ni ibuduro rẹ »[[6]].

Iwọ eniyan: Iwoye si ailera rẹ, ati ailagbara rẹ, lati fi ara da awọn adadé ẹsẹ rẹ,

} يريد الله أن يخفف عنكم وخلق الإنسان ضعيفاً {. [سورة النساء: 28].

« Ọlọhun fẹ lati se irọrun fun yin, a si se ẹda eniyan ni ọlẹ » [Suuratun-Nisaa'i: 28], ni Ọlọhun se ran awọn ojisẹ, ti O si sọ awọn tira kalẹ, ti O si se awọn ofin, ti O si la ọna ti o tọ si iwaju rẹ, ti O si mu awọn alaye, ati awijare, ati awọn amusẹri, ati awọn ẹri-ọrọ wa, titi O fi se ami kan fun ọ nipa gbogbo nnkan, ti o n tọka si jijẹ ọkan soso Rẹ, ati jijẹ oluwa Rẹ, ati jijẹ ọlọhun ti a sin Rẹ, sugbọn iwọ n ti otitọ pẹlu ibajẹ, o si n mu esu ni ọrẹ timatima lẹyin Ọlọhun, o si n jiyan pẹlu ibajẹ:

} وكان الإنسان أكثر شيء جدلاً { [سورة الكهف: 54].

« Ati pe eniyan jẹ nnkan ti o pọju ni ijiyan » [Suuratul-Kahf: 54], idẹra Ọlọhun ti o n yi ninu rẹ mu ọ gbagbe ibẹrẹ ati ipari rẹ, njẹ o wa ranti pe dajudaju lati ara omi gbọlọgbọlọ ni a ti sẹda rẹ bi? Ati pe ibudapasi rẹ ni iho, agbende rẹ yoo si jẹ lọ si inu ọgba-idẹra tabi ina, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} أو لم ير الإنسان أنا خلقناه من نطفة فإذا هو خصيم مبين. وضرب لنا مثلا ونسي خلقه قال من يحيي العظام وهي رميم. قل يحييها الذي أنشأها أول مرة وهو بكل خلق عليم { [سورة يس: 78، 79].

« Njẹ eniyan kò mọ ni pe dajudaju Awa ni A da oun ni lati inu omi gbọlọgbọlọ? Nigba naa n l'o wa jẹ alatako ti o han gbangbá. Ati pe o se apejuwe fun Wa, o si gbagbe isẹda rẹ. O sọ pe: Ta ni yoo ji egungun ti o ti kẹfun?. Sọ pe: Ẹni ti O se ẹda rẹ ni igba akọkọ ni yoo ji i, Oun si ni Oni-mimọ nipa gbogbo ẹda » [Suuratu Yaasin: 78, 79]. Ọlọhun t'O ga tun sọ pe:

} يا أيها الإنسان ما غرك بربك الكريم. الذي خلقك فسوّاك فعدلك. في أيِّ صورة ما شاء ركبّك { [سورة الإنفطار: 6-8].

« Irẹ eniyan, ki l'o tan ọ jẹ nipa Oluwa rẹ Alapọnle. Ẹni ti O da ọ, ti O si se ọ ni asepe, lẹyin naa O se awọn orike rẹ dọgba. O si to eto aworan rẹ bi O ti fẹ » [Suuratul-Infitaar: 6-8].

Iwọ eniyan! Ki l'o se ọ ti o kọ adun diduro ni iwaju Ọlọhun lati maa ba A sọrọ jẹẹjẹẹ fun ori ara rẹ, ki O le baa rọ ọ lọrọ nibi aini rẹ, ki O si wo ọ san nibi amodi rẹ, ki O si gbe ibanujẹ rẹ kuro, ki O si dari ẹsẹ rẹ jin ọ, ki O si sipaya inira rẹ, ki O si ran ọ lọwọ nigba ti wọn ba se abosi fun ọ, ki O si fi ọ mọna nigba ti o ba n tarara, ti o sọnu, ki O fi ohun ti o se aimọ nipa rẹ mọ ọ, ki O si fun ọ ni ifayabalẹ nigba ti wọn ba sẹru ba ọ, ki O si kẹ ọ nigba ailagbara rẹ, ki O si da awọn ọta rẹ pada kuro lọdọ rẹ, ki O si fa ọrọ -arziki- rẹ wa fun ọ[[7]].

Iwọ eniyan, dajudaju idẹra ti o tobi ju ti Ọlọhun se fun eniyan -lẹyin idẹra ẹsin- ni idẹra laakaye, ki o le maa fi se iyatọ laarin ohun ti yoo se e ni anfaani ati ohun ti yoo ni i lara, ki o si le baa maa se laakaye nipa asẹ Ọlọhun ati kikọ Rẹ, ati ki o le baa fi mọ ohun afojusi ti o ga ju, ti i se ijọsin fun Ọlọhun nikan, kò si orogun kan fun Un, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وما بكم من نعمة فمن الله ثم إذا مسكم الضر فإليه تجأرون. ثم إذا كشف الضر عنكم إذا فريق منكم بربهم يشركون { [سورة النحل: 53-54].

« Ati pe ohunkohun ti n bẹ fun yin ni idẹra lati ọdọ Ọlọhun ni o ti wa, lẹyin naa ti inira ba wa se yin, ọdọ Rẹ ni ẹ o ke lọ fun iranlọwọ. Lẹyin naa ti O ba mu inira naa kuro fun yin, nigba naa apa kan ninu yin yoo maa fi nnkan mìíran se orogun fun Oluwa wọn » [Suuratun-Nahl: 53-54].

Iwọ eniyan! Dajudaju onilaakaye eniyan fẹran awọn ohun ti o ga, o si korira awọn nnkan rẹkurẹku, a si maa fẹ lati kọse gbogbo ẹni-rere, alapọnle, ninu awọn anabi, ati awọn ẹni-rere, ati pe ẹmi rẹ a maa fẹ lati ba wọn bi kò tilẹ ba wọn, bẹẹ ni oju-ọna lati lọ si idi eleyii ni ohun ti Ọlọhun tọka si pẹlu ọrọ Rẹ:

} إن كنتم تحبون الله فاتبعوني يحببكم الله { [سورة آل عمران: 31].

« Bi ẹyin ba jẹ ẹni ti o fẹran Ọlọhun, ẹ tẹle mi, Ọlọhun yoo fẹran yin » [Suuratu Aala Imraan: 31], ti o ba si ti se eleyii, Ọlọhun O pa a pọ pẹlu awọn anabi, ati awọn ojisẹ, ati awọn ti o ku si oju-ogun atigbe ẹsin Ọlọhun ga, ati awọn ẹni-rere; Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} ومن يطع الله والرسول فأولئك مع الذين أنعم الله عليهم من النبيين والصديقين والشهداء والصالحين وحسن أولئك رفيقاً { [سورة النساء: 69].

« Ẹnikẹni ti o ba tẹle Ọlọhun ati Ojisẹ naa, awọn wọnyi n bẹ ninu awọn ẹni ti Ọlọhun se idẹra fun ninu awọn anabi, ati awọn olododo, ati awọn ti wọn ku si ori ogun atigbe ẹsin ga, ati awọn ẹni-rere, awọn wọnyi ni wọn dara ni alabarin » [Suuratun-Nisaa'i: 69].

Iwọ eniyan! Nse ni mo n se isiti fun ọ pe ki o ba ara rẹ jokoo, lẹyin naa ki o wa se akiyesi ohun ti o wa ba ọ ninu ododo, ki o si wo awọn ẹri rẹ, ki o si woye si awọn awijare rẹ, ti o ba ri i pe otitọ ni i, ki o tara sasa lọ sidi titẹle e, ma si se jẹ iwọfa ise tabi asa, si mọ daju pe ẹmi rẹ wọn lọdọ rẹ ju awọn ẹlẹgbẹ rẹ ati awọn irọ rẹ ati ogun awọn baba-nla rẹ lọ, Ọlọhun si ti fi eleyii se isiti fun awọn alaigbagbọ, O si se wọn ni ojukokoro lọ sidi rẹ. Ọba t'O mọ Naa, sọ pe:

} إنما أعظكم بواحدة أن تقوموا لله مثنى وفرادى ثم تتفكروا ما بصاحبكم من جنة إن هو إلا نذير لكم بين يدي عذاب شديد { [سورة سبأ: 46].

« Sọ pe: Ohun kan soso ni emi n se isiti fun yin nipa rẹ, pe ki ẹ duro ti Ọlọhun ni meji-meji ati ni ọkọọkan, lẹyin naa ki ẹ ronu jinlẹ pe were kò si lara ẹni yin; oun kò jẹ nnkan kan afi olukilọ fun yin siwaju iya kan ti o le koko » [Suuratu Saba': 46].

Iwọ eniyan! Dajudaju nigba ti o ba gba Islam o kò ni i padanu nnkan kan, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} وماذا عليهم لو آمنوا بالله واليوم الآخر وأنفقوا مما رزقهم الله وكان الله بهم

عليماً { [سورة النساء: 39].

« Ki ni [ipalara ti] yoo se wọn bi wọn ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ ikẹyin, ti wọn si n na ninu ohun ti Ọlọhun fi rọ lọrọ? Ọlọhun jẹ Olumọ nipa wọn » [Suuratun-Nisaa'i: 39]. Ibn Kathiir “ki Ọlọhun O kẹ ẹ" sọ pe: « Ki ni nnkan ti yoo ni wọn lara ti o ba se pe wọn gba Ọlọhun gbọ lododo, ti wọn si tọ oju-ọna ẹyin, ti wọn si gba Ọlọhun gbọ lododo, ni irankan ohun ti O se ni adehun ni ile ikẹyin fun ẹnikẹni ti o ba se isẹ rere, ti wọn si na ninu ohun ti Ọlọhun fi rọ wọn lọrọ si awọn ọna ti Ọlọhun N fẹ, ti O si yọnu si, Oun si ni Olumọ nipa awọn aniyan wọn daadaa ati aidaa, Olumọ si ni nipa ẹni ti o lẹtọ si kongẹ ninu wọn, yoo si fi i se kongẹ, yoo si fi ọna mọ ọn, yoo si mu un se isẹ rere ti yoo fi yọnu si i, ati nipa ẹni ti o lẹtọ si pipati ati lile kuro ni itosi Rẹ t'o ga ju ti o jẹ ti Ọlọhun, Ẹni ti O se pe gbogbo ẹni ti O ba le kuro nidi ilẹkun Rẹ, dajudaju o ti fi ori sanpọn, o si padanu ni ile-aye ati ni ile ikẹyin »[[8]]. Dajudaju gbigba Islam rẹ kò ni i kọdina ohunkohun ti o ba gbero lati se, tabi lati fi ọwọ ba, ninu ohun ti Ọlọhun se ni ẹtọ fun ọ, kaka bẹẹ, dajudaju Ọlọhun O san ọ lẹsan lori gbogbo isẹ kan ti o ba se, ti o n fi n wa oju-rere Ọlọhun, koda ki o se pe o jẹ ọkan ninu ohun ti yoo tun ile-aye rẹ se, ti yoo si se alekun dukia rẹ, tabi iyi rẹ, tabi agbega rẹ, koda titi de ori ohun ti o ba n se ninu awọn ohun ti o tọ, nigba ti o ba n rankan ẹsan lọdọ Ọlọhun lori atini itẹlọrun pẹlu ẹtọ kuro nibi eewọ; nitori naa ẹsan wa ninu rẹ fun ọ, Anabi “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", sọ pe:

(( وفي بضع أحدكم صدقة، قالوا: يا رسول الله، أيأتي أحدنا شهوته، ويكون له فيها أجر؟ قال: (( أرأيتم لو وضعها في حرام، أكان عليه وزر؟ فكذلك إذا وضعها في الحلال، كان له أجر )). [رواه مسلم].

« Ati pe ibalopọ ti ẹnikan yin ba ba iyawo rẹ lopọ sara ni fun un », wọn ni: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, njẹ ẹnikan wa yoo wa se ohun ti ẹmi rẹ n fẹ, ki o si tun ti ara rẹ gba ẹsan bi? O ni « Ẹ sọ fun mi, njẹ ti o ba ti i [iyẹn abẹ rẹ] bọ ibi ti o jẹ eewọ, se yoo ti ara rẹ gbẹsẹ bi? A jẹ pe bẹẹ naa ni ti o ba ti i bọ ibi ti o jẹ ẹtọ fun un, yoo ti ara rẹ gba ẹsan ». Muslim l'o gbe e jade.

Iwọ eniyan! Dajudaju awọn ojisẹ mu ododo wa, wọn si jisẹ erongba Ọlọhun, olubukaata lọ sidi mimọ ofin Ọlọhun si ni eniyan, nitori ki o le baa maa lọ ninu igbesi-aye yii lori amọdaju, ki o si le baa jẹ ọkan ninu awọn olujere ni ile ikẹyin, Ọlọhun t'O ga sọ pe:

} يا أيها الناس قد جاءكم الرسول بالحق من ربكم فآمنوا خيرا لكم وإن تكفروا فإن لله ما في السماوات والأرض وكان الله عليماً حكيماً { [سورة النساء: 170].

« Ẹyin eniyan, dajudaju Ojisẹ naa ti de wa ba yin pẹlu ododo lati ọdọ Oluwa yin, nitori naa ki ẹ gbagbọ l'o loore fun yin; ti ẹyin ba si se aigbagbọ, dajudaju ti Ọlọhun ni ohun ti n bẹ ninu sanma ati ilẹ; Ọlọhun si jẹ Oni-mimọ, Ọlọgbọn » [Suuratun-Nisaa'i: 170]. Ọba ti ọrọ Rẹ gbọn-un-gbọn, si sọ pe:

} قل يا أيها الناس قد جاءكم الحق من ربكم فمن اهتدى فإنما يهتدي لنفسه ومن ضلَّ فإنما يضل عليها وما أنا عليكم بوكيل { [سورة يونس: 108].

« Sọ pe: Ẹyin eniyan, dajudaju otitọ ti de wa ba yin lati ọdọ Oluwa yin, nitori naa ẹnikẹni ti o ba mọna nse l'o mọna fun ori ara rẹ, ati pe ẹnikẹni ti o ba sina nse l'o sina fun ori ara rẹ. Emi ki i se olusọ lori yin» [Suuratu Yuunus: 108].

Iwọ eniyan! Dajudaju ti o ba gba Islam, o kò se ẹnikan ni anfaani ju ori ara rẹ lọ, bẹẹ ni ti o ba se aigbagbọ, o kò ni ẹni-kankan lara yatọ si ori ara rẹ, dajudaju Ọlọhun rọrọ kuro ni ọdọ awọn ẹda Rẹ, nitori naa ẹsẹ awọn ẹlẹsẹ kò ni I lara, bẹẹ ni igbọrọ awọn olutẹle asẹ Rẹ kò se E lanfaani, ati pe a kò ni i sẹ Ẹ afi pẹlu imọ Rẹ, a kò si ni i tele asẹ Rẹ afi pẹlu iyọnda Rẹ, Ọlọhun si ti sọ gẹgẹ bi Anabi Rẹ “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a", ti fun'ni niro nipa Rẹ pe:

(( يا عبادي، إني حرمت الظلم على نفسي وجعلته بينكم محرماً فلا تظالموا، يا عبادي، كلكم ضال إلا من هديته فاستهدوني أهدكم، يا عبادي كلكم جائع إلا من أطعمته فاستطعموني أطعمكم، يا عبادي كلكم عار إلا من كسوته فاستكسوني أكسكم : يا عبادي، إنكم تخطئون بالليل والنهار وأنا أغفر الذنوب جميعا فاستغفروني أغفر لكم، يا عبادي، إنكم لن تبلغوا ضري فتضروني ولن تبلغوا نفعي فتنفعوني، يا عبادي لو أن أولكم وآخركم وإنسكم وجنكم كانوا على أتقى قلب رجل واحد منكم ما زاد ذلك في ملكي شيئا: يا عبادي، لو أن أولكم وآخركم وإنسكم وجنكم كانوا على أفجر قلب رجل واحد منكم ما نقص ذلك من ملكي شيئا : يا عبادي، لو أن أولكم وآخركم وإنسكم وجنكم قاموا في صعيد واحد فسألوني فأعطيت كل واحد مسألته ما نقص ذلك مما عندي إلا كما ينقص المخيط إذا أدخل البحر، يا عبادي، إنما هي أعمالكم أحصيها لكم ثم أوفيكم إياها فمن وجد خيراً فليحمد الله ومن وجد غير ذلك فلا يلومن إلا نفسه )). [رواه مسلم].

« Ẹyin ẹru Mi, dajudaju Emi se abosi sise ni eewọ le ara Mi lori, Mo si se e ni eewọ laarin yin, nitori naa ẹ kò gbọdọ se abosi funra yin, Ẹyin ẹru Mi, ẹni ti o sina ni gbogbo yin, afi ẹni ti Mo ba fi ọna mọ, tori naa ẹ maa tọrọ imọna lọdọ Mi, N O si maa fi ọna mọ yin, Ẹyin ẹru Mi, ẹni ti ebi n pa ni gbogbo yin, afi ẹni ti mo ba fun ni ounjẹ jẹ, tori naa ẹ tọrọ ounjẹ lọdọ Mi, N O si maa fun yin ni ounjẹ jẹ. Ẹyin ẹru Mi, ẹni ti o wa ni ihoho ni gbogbo yin, afi ẹni ti mo ba wọ lasọ, ẹ tọrọ asọ lọdọ Mi, N O si maa wọ yin lasọ. Ẹyin ẹru Mi, ẹ n se asise ni ọsan ati loru, Emi A si maa se aforijin gbogbo awọn ẹsẹ patapata, tori naa ẹ tọrọ aforijin Mi, N O si maa fi ori jin yin. Ẹyin ẹru Mi, ẹ kò to lati ni Mi lara rara, depo pe ẹ o wa ri Mi ni lara, ati pe ẹ kò to lati se Mi ni anfaani rara, depo pe ẹ o wa ri Mi se lanfaani. Ẹyin ẹru Mi, iba se pe ẹni-akọkọ yin, ati ẹni-ikẹyin yin, eniyan inu yin, ati alujannu yin, ti gbogbo wọn ba jẹ olupaya Ọlọhun [ti ọkan wọn si da] gẹgẹ bi ọkan ẹni ti n paya Ọlọhun ju ninu yin ti ri, eleyii kò le e se alekun nnkan kan ninu ọla Mi. Ẹyin ẹru Mi, iba se pe ẹni-akọkọ yin, ati ẹni-ikẹyin yin, eniyan inu yin, ati alujannu yin, ti gbogbo wọn ba jẹ oludẹsẹ [ti ọkan wọn si da] gẹgẹ bi ọkan ẹni ti o jẹ ẹlẹsẹ ju ninu yin ti ri, eleyii kò le e din nnkan kan ku ninu ọla Mi. Ẹyin ẹru Mi, iba se pe ẹni-akọkọ yin, ati ẹni-ikẹyin yin, eniyan inu yin, ati alujannu yin, ti gbogbo wọn ba duro ni aaye kan naa, ti wọn si tọrọ ohun ti wọn n fẹ lọdọ Mi, ti Mo si fun onikaluku wọn ni ohun ti o tọrọ, eleyii kò le e din nnkan kan ku ninu ohun ti n bẹ lọdọ Mi, afi iru ohun ti abẹrẹ maa n dinku nigba ti a ba ki i bọ inu okun. Ẹyin ẹru Mi, nnkan mìíran kọ ni mo N se isiro rẹ fun yin yatọ si awọn isẹ yin, lẹyin naa N o pe ẹsan wọn fun yin, nitori naa ẹnikẹni ti o ba ri rere, ki o dupẹ fun Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba si ba nnkan mìíran ti o yatọ si eleyii pade, ki o ma se bu ẹlomiran yatọ si ori ara rẹ ». [Muslim l'o gbe e jade].

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, Oluwa gbogbo ẹda, ikẹ ati ọla Ọlọhun k'o maa ba ẹni agbega ju ninu awọn anabi, ati awọn ojisẹ, Anabi wa Muhammad, ati awọn ara ile rẹ, pẹlu awọn Sahaabe rẹ lapapọ.

###[[1]] Wo Al-Diin ti Muhammad Abdullah Daraaz, oju ewe: 87.

[[2]] Wo iwe ti a wi saaju, oju ewe: 88.

[[3]] Wo Jewish Encyclpaedia, Vol. XLL (P.7) XLL . P. 568-69.

[[4]] Wo Rev, James Houstion Baxter in the History of Christionity in the light of Modern Knowledge Glassgow, 1929, oju ewe: 407.

[[5]] Wo Miftaahu Daar As-Sa'aadah 2/383.

[[6]] Pẹlu ayipada diẹ lati inu tira Alfawaa'id ti Ibnul Qayyim, oju ewe: 56.

[[7]] Wo Miftaahu Daar As-Sa'aadah: 1/251.

[[8]] Lati inu Tafsiir Ibn Khathiir pẹlu ayipada diẹ 1/497.