Sise Isẹ Ijọsin Umrah ninu Osu Rajab
Ọ̀rọ̀ ṣókí
Alaye bi o se jẹ wipe adadasilẹ ninu ẹsin ni ki Musulumi ni adisọkan wipe isẹ ijọsin Umrah ninu osu Rajab ni ọla kan ti o yatọ si asiko miran.
- 1
Sise Isẹ Ijọsin Umrah ninu Osu Rajab
PDF 555.7 KB 2019-05-02
- 2
Sise Isẹ Ijọsin Umrah ninu Osu Rajab
DOC 3.4 MB 2019-05-02
Asọkun ọrọ
Sise Isẹ Ijọsin Umrah ninu Osu Rajab
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Oju Ewe Ayelujara
IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM
Labẹ Amojuto:
Sheikh Muhammad Sọọlih Al-munajjid
Itumọ si ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello
Atunyẹwo : Hamid Yusuf
2015 - 1436
العمرة في شهر رجب
« بلغة اليوربا »
موقع الإسلام سؤال وجواب
الشيخ محمد صالح المنجد
ترجمة: رفيع أديسا بلو
مراجعة: حامد يوسف
2015 - 1436
Sise Isẹ Ijọsin Umrah ninu Osu Rajab
Fatwa: [36766]
Ibeere:
Njẹ o wa ni akọsilẹ wipe ọla kan nbẹ fun sise isẹ Umrah ninu osu Rajab bi?
Idahun:
Ọpẹ ni fun Ọlọhun.
Alakọkọ: ko si akọsilẹ kankan ti o fi ẹsẹ mulẹ lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] lori wipe ọla kan nbẹ fun sise isẹ ijọsin Umrah ninu osu Rajab, bẹẹni ko si nkankan ti o wa lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun ti o jẹ iseni ni oju kokoro si iru isẹ bayi. Eyiti o rinlẹ, ti o si ni ẹri ni sise isẹ ijọsin Umrah ninu osu Ramadhan, ati awọn osu Haj, awọn naa si ni: Shawwaal, Dhul-ki’dah ati Dhul-hijjah.
Ko si ẹri ti o fi ẹsẹ mulẹ lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun wipe o se ijọsin Umrah ninu osu Rajab. Ni afikun, Iya wa Aishat [ki Ọlọhun yọnu si i] sọ wipe: “Ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] ko se isẹ ijọsin Umrah ninu osu Rajab ri” [1].
Ẹlẹẹkeji: Ninu adadasilẹ ninu ẹsin ni ohun ti apa kan ninu awọn Musulumi maa nse pẹlu ki wọn maa se adayanri osu Rajab fun isẹ Umrah; nitoripe ko lẹtọ rara fun Musulumi kan ki o se adayanri isẹ kan fun asiko kan ayafi eyiti o rinlẹ ninu Shẹria.
Al-‘atoor ti o jẹ ọmọ akẹkọ fun Imam An-nawawi [Ki Ọlọhun kẹ awọn mejeeji] sọ wipe: “Ninu nkan ti mo gbọ lati ọdọ awọn ara ilu Makkah- ki Ọlọhun tubọ maa se alekun iyi ilu naa - ni wipe wọn maa nse adayanri osu Rajab fun isẹ Umrah ni ọpọlọpọ, emi ko si mọ ipilẹ ati ẹri kankan fun eleyi, bikosepe ohun ti o rinlẹ ninu hadiisi ojisẹ Ọlọhun ni wipe: {Umrah sise ninu osu Ramadhan se deede isẹ ijọsin Haj} ”.
Bakannaa, Sheikh Muhammad bin Ibrọhim [Ki Ọlọhun kẹ ẹ] naa sọ wipe: “…. Sugbọn sise adayanri awọn ọjọ kan ninu osu Rajab fun awọn ijọsin kan, gẹgẹ bii sise abẹwo tabi nkan miran, ko si ẹri kankan fun wọn. Al-imaam Abu Shaama sọ ninu tira rẹ wipe: {Sise adayanri awọn asiko kan fun awọn ijọsin kan eyiti Shẹria ko se adayanri rẹ ko lẹtọ rara; nitoripe ko si ọla kan fun asiko kan lori asiko miran ayafi eyiti Shẹria ba gbe ọla fun pẹlu irufẹ iran ijọsin kan, tabi eyiti Shẹria ba gbe ọla fun gbogbo isẹ oloore ti Musulumi ba se ninu rẹ ju awọn miran lọ; fun idi eyi ni awọn onimimọ ẹsin fi kọ ki Musulumi kan sa ẹsa osu Rajab fun sise isẹ ijọsin Umrah lọpọlọpọ ninu rẹ}” [2].
Sugbọn ti Musulumi kan ba lọ se isẹ ijọsin Umrah ninu osu Rajab laini adisọkan wipe isẹ Umrah ti oun se ni ọla kan ju ki oun se e ni asiko miran lọ, ti o jẹ wipe o se deede inu osu Rajab ni, tabi wipe ninu osu naa ni irin-ajo rọrun fun un, ko si aburu kankan nibi eleyi.
[1] Sohiihul Bukhari: [1776], Sohiihu Muslim: [1255].
[2] Fatawa Sheikh Muhammad bin Ibrohim Al-Sheikh: [6/ 131].
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan:
Àwọn ìsọ̀rí ti ìmọ̀: