Àwọn ìsọ̀rí ti ìmọ̀

معلومات المواد باللغة العربية

Fonran aworan

Onka awon ohun amulo: 314

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Dhikrullah Shafihi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Khutba yi so nipa bi Musulumi yoo se mura sile fun osu Ramadan lati gba aawe nibe ati lati se awon naafila nibe. O so nipa bi awon eni isiwaju ninu esin se maa n pade osu Ramadan pelu idunnu ati ayo, ti won si maa n banuje ti o ba tan. Olubanisoro tun menu ba bi osu Shaaban se je osu imurasile ati yiye ara eni wo fun osu aawe Ramadan. O tun so nipa awon adadasile ti awon eniyan maa nse, o si so pe ki awon Musulumi jinna sii nitoripe esin ti di pipe ki ojise Olohun to fi aye sile.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Dhikrullah Shafihi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Khutba yi da lori oro nipa awon omode ati bi won ti se Pataki ni awujo. Oniwaasi fi oro yi se khutuba ni ibamu pelu ojo ti orile-ede Nigeria mu gege bii ojo awon ewe (omode). O si se alaye pupo nipa bi esin Islam ti se amojuto awon omode.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi soro ni ipari waasi yi o si gba awon Musulumi ni iyanju lori ki won maa moju to esin Olohun bi o ti wule ki ibaje po to ni awujo, ki won si maa be Olohun ni opolopo, ki won jinna si ebo ati awon elebo. O si se adua ni ipari waasi naa fun gbogbo Musulumi.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi soro nipa sisokale Anabi Isa omo Maryam, nigbati o ba de yoo pa agbelebu ati elede run, yoo si maa se idajo pelu deede ni ilana Anabi wa Muhammad.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi soro nipa eranko kan ti Olohun yoo mu jade si awon eniyan ti yoo si maa ba awon eniyan soro gege bii okan ninu awon apeere irole aye ti o tobi. Bakannaa ni o so nipa yiyo oorun nibi ibuwo re, o si se afikun wipe ni asiko yi ko si anfaani fun ironupiwada fun enikankan mo.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, gege bii ki awon eniyan maa se aponle okunrin kan nitori iberu aburu ise owo re. Leyinnaa o menu ba die ninu awon apeere irole aye ti o tobi, o si ka hadiisi ti Udhaefa gba wa lati odo ojise Olohun ti o so nipa awon apeere irole aye ti o tobi. Oniwaasi tun so nipa Dajjal gege bii okan ti o se Pataki ninu awon apeere irole aye ti o tobi.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o so nipa wiwa imo nitori oro aye, ati bi okunrin yoo se maa tele ase iyawo re ti yoo si maa se aburu si iya re, bakannaa bi awon eniyan yoo se maa pariwo ninu mosalaasi fun ohun ti kiise iranti Olohun.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o so nipa bi onka awon obinrin yoo se po ni awujo, bakannaa ni ki awon eniyan maa se afiti nkan si odo eni ti kii se eni ti o leto si i.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Oniwaasi so ninu ibanisoro yi nipa awon apeere kekere ninu awon apeere irole aye, o si menu ba bi o se je wipe awon ti won je onimimo nipa oro Olohun yoo tan ni ori ile, ti iwa agbere yoo po, bakannaa ni oti mimu ati beebeelo.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

    Ibanisoro yi so nipa die ninu awon apeere ti a o fi maa mo nigbati opin aye ba n sunmo. Oniwaasi so ni ibere oro yi wipe gbigbe dide Anabi wa Muhammad je okan ninu awon apeere irole aye. Bakannaa ni oro wa lori sisokale Anabi Isa omo Maryam gege bii okan ninu awon apeere irole aye. Eyi si je akoko ninu ibanisoro yi ti o je sise-ntele.

  • Yoruba

    MP3

    Olohun se ipari aawe ati ojo kewa osu Dhul-hijja ni odun fun awa Musulumi. Ibani soro yi n so nipa awon eko ti Islam ko wa nipa odun aawe. Ninu re ni ki Musulumi wo aso ti o dara ti o si wuyi ni ojo odun lati gbe ojo yi laruge. Ojise Olohun si pase wipe ki gbogbo Musulumi jade lo si aaye ikirun fun odun yii.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Sirajudeen Bilal Al-asrau Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Eyi ni abala ti o kun fun ibeere ati idahun, ti awọn ọrọ olowo-iye-biye si ti ibẹ yọ.

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Sirajudeen Bilal Al-asrau Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Ni apa keji yi: (1) Itẹsiwaju alaye lori igbati irori fifi opin si ọmọ bibi bẹrẹ. (2) Ọrọ nipa oyun nini ati awọn idajọ ẹsin ti o rọ mọ ọ

  • Yoruba

    MP4

    Oludanileko : Sirajudeen Bilal Al-asrau Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello Sise atunyewo : Hamid Yusuf

    Ibanisọrọ yi se alaye awọn koko wọnyi: (1) Iyatọ laarin ifeto sọmọ bibi ati ifopin sọmọ bibi. (2) Awọn ẹri pe Islam se wa lojukokoro lori ọmọ bibi. (3) Itan igba ti irori fifi opin si ọmọ bibi bẹrẹ.