110 - Suuratun-Nas'r ()

|

(1) Nígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀,

(2) tí o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ,

(3) nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀.¹ Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.