111 - Suuratul-Masad ()

|

(1) Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò.

(2) Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

(3) Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò.

(4) Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná).

(5) Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná).