96 - Suuratul-Halaq ()

|

(1) Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

(2) Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

(3) Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

(4) Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

(5) Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

(6) Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

(7) nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

(8) Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

(9) Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

(10) fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

(11) Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

(12) tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

(13) Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

(14) Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

(15) Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.¹) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí² rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);
1. Ẹni yẹn ni Abu Jahl. 2. àásó orí; irun iwájú orí.

(16) àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

(17) Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

(18) Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

(19) Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).