105 - Suuratul-Fiil ()

|

(1) Ṣé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni?

(2) Ṣé kò sọ ète wọn di òfo àti anù bí?

(3) Ó sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn.

(4) Wọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (tó ti gbaná sára).

(5) Ó sì sọ wọ́n di bíi pòpórò gbígbẹ tí ẹranko jẹ lájẹdàsílẹ̀.