109 - Suuratul-Kaafiruun ()

|

(1) Sọ pé: “Ẹ̀yin aláìgbàgbọ́,

(2) Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.

(3) Ẹ̀yin náà kò jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún.

(4) Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ jọ́sìn fún sẹ́.

(5) Ẹ̀yin náà kò kú jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún.

(6) Tiyín ni ẹ̀sìn yín, tèmi sì ni ẹ̀sìn mi.”