102 - Suuratut-Takaathur ()

|

(1) Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín

(2) títí ẹ fi wọ inú sàréè.

(3) Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

(4) Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

(5) Ní ti òdodo, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).

(6) Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.

(7) Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa fi ojú rí i ní àrídájú.

(8) Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).