93 - Suuratu Duhaa ()

|

(1) Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra.

(2) Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.

(3) Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.

(4) Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.

(5) Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.

(6) Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.

(7) Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.

(8) Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.

(9) Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).

(10) Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).

(11) Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.