56 - Suuratul-Waakiha ()

|

(1) Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,

(2) - kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-

(3) ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).

(4) Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,

(5) àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,

(6) - wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -

(7) ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé āyah tó pín ẹ̀dá sí mẹ́ta ní ọjọ́ Àjíǹde tako āyah tó pín wọn sí ìjọ méjì. Èsì: Kò sí ìtakora láààrin wọn. Nínú sūrah yìí, Allāhu - tó ga jùlọ - sọ pé oríṣi ìjọ mẹ́ta ni àwọn ẹ̀dá máa pín sí ní ọjọ́ Àjíǹde. Ìjọ ọ̀tún, ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18 - 19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6 - 8, Allāhu - tó ga jùlọ - pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì = = kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run, ìjọ ọ̀tún àti ìjọ òsì nítorí pé, Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún ìjọ ọ̀tún, Ọgbà Iná sì wá fún ìjọ òsì. Àmọ́, Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe àtúnpín ìjọ ọ̀tún sí ìjọ ọ̀tún àti ìjọ aṣíwájú nítorí pé, ìgbádùn ìkíní kejì yàtọ̀ gan-an síra wọn. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ nípa ìgbádùn ìjọ aṣíwájú láti āyah 10 sí āyah 26. Ó sọ nípa ìgbádùn ìjọ ọ̀tún láti āyah 27 sí āyah 40. Ó sì sọ nípa oníran-ànran ìyà ìjọ òsì láti āyah 41 sí āyah 56.

(8) Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?

(9) Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

(10) Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.

(11) Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)

(12) nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

(13) Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

(14) Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.

(15) (Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.

(16) Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.

(17) Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn

(18) pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).

(19) Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.

(20) Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).

(21) Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).

(22) Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).

(23) Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.

(24) (Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

(25) Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

(26) Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.

(27) Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?

(28) (Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,

(29) àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,

(30) àti ibòji tó gbòòrò,

(31) àti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,

(32) àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,

(33) tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).

(34) (Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.

(35) Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).

(36) A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,

(37) olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.

(38) (Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

(39) Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

(40) Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.¹
1. Àwọn ẹni àkọ́kọ́ dúró fún àwọn ènìyàn láti àsìkò Ànábì Ādam títí di àsìkò Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. Àwọn ẹni Ìkẹ́yìn sì dúró fún ìjọ Ànábì wa nìkan - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.

(41) Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

(42) (Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,

(43) àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,

(44) kò tutù, kò sì dára.

(45) Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.

(46) Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

(47) Wọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?

(48) Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”

(49) Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,

(50) dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”

(51) Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,

(52) dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).

(53) Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.

(54) Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.

(55) Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.

(56) Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.

(57) Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!

(58) Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),

(59) ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?

(60) Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara

(61) láti yí irú yín padà (láti inú erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì ṣẹ̀dá yín (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ (nínú àwọn ìrísí).
1. Ẹ tún wo sūrah al-Mọ̄‘rij; 70:40-41 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:3-4.

(62) Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?

(63) Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,

(64) ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?

(65) Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).

(66) (Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”

(67) (Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”

(68) Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,

(69) ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?

(70) Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?

(71) Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,

(72) ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?

(73) Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.

(74) Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

(75) Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.¹
1. “Mọwāƙi‘u-nnujūm” tún lè túmọ̀ sí “àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ nínú sánmọ̀”. Nítorí náà, ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí nìyí: “Nítorí náà, Mò ń fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ búra.” Ẹ wo sūrah an-Najm; 53:1 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.

(76) Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.

(77) Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.

(78) Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).

(79) Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).

(80) Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

(81) Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?

(82) Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.¹
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dúpẹ́ fún ìràwọ̀ nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́ pé òhun l’ó ń rọ̀jò lẹ́yìn Allāhu. Irọ́ àti àìgbàgbọ́ nínú Allāhu ni èyí. Allāhu - tó ga jùlọ - ni Ẹni t’Ó ń rọ̀jò fún ẹ̀dá Rẹ̀.

(83) Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,

(84) tí ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?

(85) Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah; 58:7.

(86) Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,

(87) kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

(88) Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),

(89) ìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).

(90) Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,

(91) àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

(92) Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,

(93) n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí

(94) àti wíwọ inú iná Jẹhīm.

(95) Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.

(96) Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.