113 - Suuratul-Falaq ()

|

(1) Sọ pé: “Mo sá di Olúwa òwúrọ̀ kùtùkùtù

(2) níbi aburú ohun tí Ó dá,¹
1. Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan, ohun rere àti ohun burúkú. Ọ̀kan pàtàkì nínú ohun burúkú nínú àwọn ẹ̀dá tí Allāhu dá ni aṣ-Ṣaetọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí àjẹ́, oṣó, emèrè, àwọn n̄ǹkan olóró àti àwọn iwọ. Nítorí náà, Èṣù kọ́ ló dá owó àti dúkìá. Ẹni tí ó bá wá tọrọ owó ní ọ̀dọ̀ Èṣù, ó ti di ẹlẹ́bọ, ẹni Èṣù.

(3) àti níbi aburú òru nígbà tí ó bá ṣóòkùn,

(4) àti níbi aburú àwọn (òpìdán) tó ń fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú àwọn ońdè,

(5) àti níbi aburú onílara nígbà tí ó bá ṣe ìlara.”