• Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur Rahman Muhammadul Awwal Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Idanilẹkọ yi da lori wipe idakeji ẹbọ sise ni sise Ọlọhun Allah ni aaso tabi gbigba A ni okan soso pẹlu ẹri Alukuraani ati ẹgbawa hadisi. Alaye tẹsiwaju nipa itumọ ẹbọ sise pẹlu awọn ọna ti ẹbọ sise pin si.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur Rahman Muhammadul Awwal Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Alaye nipa awọn ọranyan aluwala, ati awọn ohun ti a fẹ ki Musulumi se ninu aluwala ati awọn ohun ti o nba aluwala jẹ.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur Rahman Muhammadul Awwal Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Idanilẹkọ yii da lori alaye bi a se nse aluwala ati awọn ẹsan (ọla) ti o nbẹ fun aluwala sise, bakannaa ọrọ nipa awọn ohun ti o nsọ aluwala di ọranyan fun musulumi.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur Rahman Muhammadul Awwal Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Ọrọ waye lori awọn nkan marun ti o maa nsọ iwẹ di dandan fun ni lati wẹ, alaye si tun waye ni soki lori bi a se le wẹ iwẹ naa.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Sharafuddeen Gbadebọ Raji Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  2- Alaye lori awon idajo ti o sopo mo irun Jimoh, ninu won ni: (1) Asiko wo ni irun Jimoh maa n wole. (2) Onka wo ni o ye ki o pe ki a to le ki irun Jimoh. (3) Rakah melo ni Musulumi gbodo ba ki o to le gba pe oun ba irun Jimoh. 3- Alaye lori wipe Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a maa n gbe ohun soke ni ti o ba n se khutuba ti o si maa n se khutuba ni iduro, gbogbo awon nkan wonyi ni o si maa n se okunfa ki khutuba ni ilapa lara awon ti won n gbo o. 4- Oro waye ni apa kerin yi lori Pataki yiyara lo si mosalasi ni ojo Jimoh ati Pataki titeti si Imam ni asiko khutuba, bakannaa ojuse eni ti o ba tete de mosalasi ati eni ti o pe de mosalasi nibi nafila ti a n pe ni "Tahiyyatul-masjid". 5- Oro waye ninu apa karun yi lori awon suura ti Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa n ka ninu irun Jimoh ati irun odun mejeeji pelu alaye awon eko ti o wa ninu awon suura naa, oludanileko si tun menu ba awon idajo ti o n be fun awon irun odun mejeeji ti odun ba bo si ojo Jimoh. 6- Alaye wa ninu apa kefa yi lori: (1) Nafila eyin irun Jimoh ati iye onka rakaa re. (2) Iwe fun irun Jimoh, se oranyan ni tabi kiise oranyan. (3) Awon ibeere lori oro Jimoh ati gbogbo ohun ti o ropo mo o pelu idahun lori won.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdul-jeleel Alagufon Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  1- Oro waye ninu waasi yi lori Itumo gbolohun Islam ati alaye bi o se je wipe ijosin Ojise Olohun, iwa re ati ise re je apejuwe ti o daju fun itumo paapaa esin Islam. Oro si tun waye lori bi ’waayi’ se maa n so kale fun Ojise Olohun. 2- Ninu awon Ewa esin Islam ti oniwaasi menu ba ninu apa keji yi ni bi Islam se je esin gbogbo abgaye, ti o tun je esin ti o pe perepere, bakannaa ti o si je esin ti o rorun julo.

 • Yoruba

  MP3

  Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  1- Eleyi ni iforowero laarin Ijo Ahmadiyyah ati Ijo Tadomun Muslimeen lori wipe se Annabi Isa- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- ku si ori igi agbelebu ni tabi ko ku, se won gbe gun Sanmo lo ni tabi o wa ni ibikan lori ile aye yii. 2- Eleyi ni itesiwaju iforowero laarin igun mejeeji pelu awon eri olukuluku won lati le fi oro won mule.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Olubanisoro se alaye lekunrere ohun ti a npe ni Ojo Ikehin ati awon orisirisi oruko ti Olohun Allah fun un ninu Alukuraani, Olubanisoro si tun se alaye awon nkan ti Ojo Igbehin ko sinu.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdul-jeleel Alagufon Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  1- Ibanisoro yii da lori awon ona abayo si asigbo esin ti o gbaye kan laarin awon Musulumi. 2- Ibanisoro je afikun lori awon okunfa ati ona abayo si awon asigbo tabi aseju ninu esin.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  1- Oro lori koko ohun ti Olohun fi ran ojise Re Muhammad, iranse ni o je si gbogbo aye patapata. 2- Pelu bi o ti je wipe awon osebo fi inira kan ojise Olohun ni ilu Makka sibe sibe o tun fi aanu bawon lo ti ko si fi ibi san ibi. 3- Apejuwe lori aanu ti ojise Olohun ni fun awon eranko. Ikilo si waye lori fifi iya je awon eranko. 4- Apejuwe nipa aanu re si awon ewe tabi awon omode. 5- Apejuwe nipa aanu ojise Olohun si awon obinrin, oro si waye lori bi awon eniyan se maa nse abosi si won ni igba aimokan. 6- Awon apejuwe nipa iteriba ati iwapele ojise Olohun. Bi o ti se ni aanu awon omoleyin re ti awon naa si ni ife si i.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdul-jeleel Alagufon Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Ibanisoro yii da lori awon majemu ti a gbodo ri lara musulumi kan ki a to le pe ni Keferi, ti Olubanisoro si bere pelu nkan ti pipe Musulumi kan ni keferi tumo si ninu Islam.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Eyi ni alaye Suratul Fatiha lati Aayah akoko titi de Aayah keta pelu awon eko l’oniranran.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Eyi ni alaye oro lekunrere nipa asigbo ati ero buburu ti awon eniyan ni si awon musulumi ati Esin Islam, ti olubanisoro si tun se alaye awon iruju die nipa iko “Boko Haram”.

 • Yoruba

  MP3

  Idanileko yi je alaye lori hadiisi eleekeje ninu tira “Umdatul Ahkaam”, koko oro idanileko naa ni alaye nipa bi ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o o maa ba a- se maa nse aluwala.

 • Yoruba

  MP3

  Ibanisoro yi da lori alaye ni ekunrere lori awon iruju ti o nbe fun awon eniyan kan nipa awon ohun ti o leto ki Musulumi maa fi se ategun si odo Olohun ati awon nkan ti ko leto nigbati o ba npe Olohun.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

  Alaye waye ninu ibanisoro yi nipa awon eko ti o nbe nibi ipepe Sheikh Muhammad ibn Abdul-wahab. Oniwaasi so nipa bi o se je wipe soki ohun ti ipepe Sheikh da le lori ni mimo Olohun ni okan soso ati dida oju ko O ni Oun nikan nibi awon ijosin.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur-rahman Adunola Abdul-wahab Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  Ibanisoro yi da lori oro nipa adiokan Imam Abu Haniifa, biotile je wipe olubanisoro menu ba adiokan awon Imaamu mereerin. Ohun ti o si se okunfa eleyi ni bi apa kan ninu awon alaimokan ni awujo se npe Imaam Abu Haniifa ni keeferi nitori awon iruju kan ti o nbe fun won nipa adiokan re. Eleyi ni oniwaasi yi se alaye re ni ekunrere, ki Olohun fi se awon Musulumi ni anfaani.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

  Ibanisoro yi so ni ekunrere nipa itumo adadaale ninu esin pelu awon eri lati inu Al-kurani ati Sunna Ojise. O si se alaye ewu ti o wa nibi ki musulumi maa tele awon ti won ba n da adadaale ninu esin. Ni afikun, o tun se alaye awon majemu ti a fi maa nmo adadaale nitori awon iruju ti o wa fun awon Musulumi kan lori re.

 • Yoruba
 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur Rahman Muhammadul Awwal Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Alaye lẹkunrẹrẹ nipa ohun ti o rọ mọ sisọkalẹ Anabi Isa [ Ọla Ọlọhun ki o maa ba a ].

Irori re je wa logun