Apa keji yi so nipa awon nkan wonyi: (1) Awon eko ti o dara julo ti o wa nibi ibasepo Ojise Olohun pelu awon Saabe re. (2) Sise awon Musulumi ni ojukokoro sibi kikose Ojise Olohun nibi awon iwa re fun oore aye ati orun.
Waasi yi je idahun fun awon ibeere wonyi: (1) Kinni paapaa itumo fiferan Ojise Olohun? (2) Kinni idi ti Olohun fi royin Ojise Re pelu iwa rere nibi ti O ti so wipe: {Dajudaju ire (Anabi) ni o ni iwa ti o dara julo}. (3) Tani eni ti o je dandan ki Musulumi mu ni awokose fun ara re lori gbogbo nkan?
Waasi yi so nipa awon nkan pataki, ninu won ni: (1) Awon ona ti esu (shatani) maa ngba lati dari eniyan si ona anu. (2) Awon ohun ti esin Islam toka Musulumi si lati maa fi wa iso Olohun.
Waasi yi so nipa awon nkan kan, ninu won niyi: (1) Musulumi ni eni ti iwa daradara ti Islam pepe si ba han ni ara re. (2) Ninu ohun ti esin Islam pase re ni ki Musulumi maa se aponle gbogbo eniyan, eni ti o je Musulumi ati eni ti kiise Musulumi, ki o si maa dun won ninu.
Alaye awon nkan ti awon eniyan fi nwa Alubarika ni ona eewo ati alaye awon nkan ti Alubarika wa nibe. Bakannaa ohun ti o fa asise awon eniyan nibi wiwa Alubarika, alaye si tun waye lori awon nkan eelo ti won so wipe Annabi- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- lo nigba aye re, pelu mimu oro ti awon onimimo so nipa awon nkan wonyi wa.
Alaye lekunrere nipa itumo Alubarika ninu Ede larubawa ati ninu Shari’ah, ati oro nipa pataki Alubarika ati idajo wiwa Alubarika latara nkan tabi nibi nkan.
Koko oro inu waasi yi ni alaye lori pataki imo ati pataki awon onimimo, bakannaa ni bi o se se pataki to ki apa kan ninu awon Musulumi gbiyanju lati wa imo leyinnaa ki won se awon eniyan ni anfaani pelu imo won fun atunse awujo.
Sise daadaa si awon obi je ojuse Pataki ti Olohun pa omo ni ase re leyin ti o pase wipe ko gbodo josin fun nkan miran yato si Oun Olohun. Eleyi ni ohun ti ibanisoro yi da lelori, olubanisoro si mu awon apejuwe lori oore ti o wa ninu ki eniyan maa se daadaa si awon obi ati aburu ti o wa nibi ki eniyan maa se aidaa si won.