• Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Olubanisoro se alaye lekunrere ohun ti a npe ni Ojo Ikehin ati awon orisirisi oruko ti Olohun Allah fun un ninu Alukuraani, Olubanisoro si tun se alaye awon nkan ti Ojo Igbehin ko sinu.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdul-jeleel Alagufon Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  1- Ibanisoro yii da lori awon ona abayo si asigbo esin ti o gbaye kan laarin awon Musulumi. 2- Ibanisoro je afikun lori awon okunfa ati ona abayo si awon asigbo tabi aseju ninu esin.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  1- Oro lori koko ohun ti Olohun fi ran ojise Re Muhammad, iranse ni o je si gbogbo aye patapata. 2- Pelu bi o ti je wipe awon osebo fi inira kan ojise Olohun ni ilu Makka sibe sibe o tun fi aanu bawon lo ti ko si fi ibi san ibi. 3- Apejuwe lori aanu ti ojise Olohun ni fun awon eranko. Ikilo si waye lori fifi iya je awon eranko. 4- Apejuwe nipa aanu re si awon ewe tabi awon omode. 5- Apejuwe nipa aanu ojise Olohun si awon obinrin, oro si waye lori bi awon eniyan se maa nse abosi si won ni igba aimokan. 6- Awon apejuwe nipa iteriba ati iwapele ojise Olohun. Bi o ti se ni aanu awon omoleyin re ti awon naa si ni ife si i.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdul-jeleel Alagufon Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Ibanisoro yii da lori awon majemu ti a gbodo ri lara musulumi kan ki a to le pe ni Keferi, ti Olubanisoro si bere pelu nkan ti pipe Musulumi kan ni keferi tumo si ninu Islam.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Eyi ni alaye Suratul Fatiha lati Aayah akoko titi de Aayah keta pelu awon eko l’oniranran.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Eyi ni alaye oro lekunrere nipa asigbo ati ero buburu ti awon eniyan ni si awon musulumi ati Esin Islam, ti olubanisoro si tun se alaye awon iruju die nipa iko “Boko Haram”.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Ibanisoro yi da lori alaye ni ekunrere nipa ohun ti a n pe ni kadara ati bi awon eniyan kan se sonu nitori re.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Olubanisọrọ tẹsiwaju ninu alaye awọn nkan ti o maa nse akoba fun Taoheed ninu iran Ẹbọ sise ati okunfa re, gẹgẹ bii Mima se ijọsin nibi saare oku, Gbigbẹ saare si inu mọsalaasi, Tita ẹjẹ silẹ fun nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah, Wiwa idaabobo tabi iranlọwọ lọdọ nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah. Ni akotan, wọn jẹ ki a mọ pe iru awọn nkan bayi le se akoba wiwọ Alujannah Musulumi.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Olubanisọrọ bẹrẹ pẹlu alaye orisirisi awọn alajẹ ede ti awọn eniyan fun Ọlọhun Allah, o si tun se alaye nipa Eni ti o tọ ki a maa jọsin fun laiwa orogun pẹlu Rẹ Ohun naa ni Ọlọhun .O si tun tẹsiwaju ninu sise alaye ohun ti wọn npe ni At-Taoheed (mimọ Ọlọhun lọkan soso) ati ẹka mẹtẹẹta ti o pin si.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Saheed Oran-kan Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Olubanisoro se alaye itumo gbolohun ijeri la ilaha illa Allah, o si tun so awon majemu ti o wa fun un ati awon nkan ti o maa nba gbolohun naa je.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Abdur-razaq Abdul-majeed Alaro Sise atunyewo : Hamid Yusuf

  Olubanisoro se ni alaye lekunrere nkan ti won npe ni Sunna, o so pelu akori wipe odidi esin Islam ni Sunna atipe Sunna gan an ni esin Islam. O tesiwaju ninu alaye re wipe agboye Alkurani ko rorun fun Musulumi bikose latari Sunna, bee si ni Sunna je aayan ongbifo fun Alkurani Alaponle.

 • Yoruba

  MP3

  Idanileko yi je alaye lori hadiisi eleekeje ninu tira “Umdatul Ahkaam”, koko oro idanileko naa ni alaye nipa bi ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o o maa ba a- se maa nse aluwala.

 • Yoruba

  MP3

  Ibanisoro yi da lori alaye ni ekunrere lori awon iruju ti o nbe fun awon eniyan kan nipa awon ohun ti o leto ki Musulumi maa fi se ategun si odo Olohun ati awon nkan ti ko leto nigbati o ba npe Olohun.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  Eleyi ni apa keji ibanisoro naa, olubanisoro nso eyi ti o ku ninu awon majemu ti o ye ki o wa fun eniti a fe fi se olori ninu Islam.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  Waasi yi so nipa bi o ti je wipe esin Islam menu ba gbogbo nkan patapata ti o fi de ibi eko bi a ti se n to tabi ya igbe, bawo ni Islam kose wa ni so nipa eto bi a se ndari ilu ati bi a se nse ijoba.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Isa Akindele Solahudeen Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  Ibanisoro yi da lori idahun fun ibeere ti o n so pe: kinni idi ti Olohun fi da awa erusin Re? Oniwaasi si dahun ni kukuru wipe nitori ijosin ni Olohun fi da awa eniyan ati alijonnu. Oju ona kan soso ti a si fi le sin Olohun naa ni esin Islam.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Qomorudeen Yunus Sise atunyewo : Saeed Jumua

  Olubanisoro se alaye bi ojise Olohun anabi Muhammad se je ike fun gbogbo aye, Olohun lo ojise naa lati se agbega fun awon iwa rere O si loo lati pa awon iwa buburu re. Olohun si da ojise re ni eniti o pe ni eda ati ni iwa.

 • Yoruba

  MP4

  Oludanileko : Qomorudeen Yunus Sise ogbifo : Saeed Jumua

  Ibanisoro yi da lori sise Olohun ni okan soso ati awon ipin re meteeta. Olubanisoro si se alaye ni ekunrere eyi ti o se pataki julo ninu awon ipin wonyi ti opolopo Musulumi ni asiko yi si nse asise ti o fi oju han nibe.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Rafiu Adisa Bello

  Alaye waye ninu ibanisoro yi nipa awon eko ti o nbe nibi ipepe Sheikh Muhammad ibn Abdul-wahab. Oniwaasi so nipa bi o se je wipe soki ohun ti ipepe Sheikh da le lori ni mimo Olohun ni okan soso ati dida oju ko O ni Oun nikan nibi awon ijosin.

 • Yoruba

  MP3

  Oludanileko : Abdur-rahman Adunola Abdul-wahab Sise atunyewo : Rafiu Adisa Bello

  Ibanisoro yi da lori oro nipa adiokan Imam Abu Haniifa, biotile je wipe olubanisoro menu ba adiokan awon Imaamu mereerin. Ohun ti o si se okunfa eleyi ni bi apa kan ninu awon alaimokan ni awujo se npe Imaam Abu Haniifa ni keeferi nitori awon iruju kan ti o nbe fun won nipa adiokan re. Eleyi ni oniwaasi yi se alaye re ni ekunrere, ki Olohun fi se awon Musulumi ni anfaani.

Irori re je wa logun